Wọ́n Tòṣì Síbẹ̀ Wọ́n Lọ́rọ̀ Báwo ni Ó Ṣe Lè Rí Bẹ́ẹ̀?
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọkùnrin ọlọgbọ́n kan gbàdúrà pé kí òun má ṣe tòṣì. Èé ṣe tí ó fi bẹ̀bẹ̀ fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Nítorí ó bẹ̀rù pé òṣì lè mú kí òun hùwà tàbí gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí yóò fẹ́ ba ipò ìbátan tí òun ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Èyí hàn gbangba nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Fi oúnjẹ tí ó tó fún mi bọ́ mi . . . kí èmi má baà tòṣì, kí èmi sì jalè, kí èmi sì ṣẹ̀ sí orúkọ Ọlọ́run mi.”—ÒWE 30:8, 9.
ÈYÍ ha túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe fún ẹnì kan tí ó jẹ́ òtòṣì láti sin Ọlọ́run ní tòótọ́ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Jálẹ̀ ìtàn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ti pa ìwà títọ́ wọn mọ́ láìka ìnira tí òṣì mú wá sí. Bákan náà, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì ń pèsè fún wọn.
Àwọn Olùṣòtítọ́ Ní Ìgbà Àtijọ́
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ nírìírí àwọn àkókò àìní. (Kọ́ríńtì Kejì 6:3, 4) Ó tún ṣàpèjúwe ‘àwọ sánmà tí ó pọ̀’ ti àwọn olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ṣáájú sànmánì ẹ̀sìn Kristẹni, àwọn tí àwọn kan lára wọn “lọ káàkiri nínú awọ àgùntàn, nínú awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà nínú àìní . . . Wọ́n rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò àti àwọn ihò ibùgbé ilẹ̀ ayé.”—Hébérù 11:37, 38; 12:1.
Wòlíì Èlíjà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí. Nígbà tí ọ̀dá kan dá fún ọdún mẹ́ta ààbọ̀, Jèhófà pèsè oúnjẹ fún un déédéé. Lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run rán ẹyẹ ìwò láti gbé àkàrà àti ẹran wá fún wòlíì náà. (Àwọn Ọba Kìíní 17:2-6) Lẹ́yìn náà, lọ́nà ìyanu, Jèhófà kò jẹ́ kí ìpèsè ìyẹ̀fun àti òróró láti inú èyí tí opó kan ti pèsè fún Èlíjà gbẹ. (Àwọn Ọba Kìíní 17:8-16) Oúnjẹ ṣákálá ni oúnjẹ náà, ṣùgbọ́n ó gbé ìwàláàyè wòlíì náà, ti obìnrin náà, àti ti ọmọkùnrin rẹ̀ ró.
Bákan náà Jèhófà kò jẹ́ kí ebi pa wòlíì olùṣòtítọ́ náà, Jeremáyà, kú, nígbà tí nǹkan le koko. Jeremáyà là á já nígbà tí àwọn ará Bábílónì gbógun ti Jerúsálẹ́mù, nígbà tí àwọn ènìyàn ní láti “jẹ oúnjẹ nípa ìwọ̀n, àti nínú àníyàn ṣíṣe.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 4:16, NW) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìyàn mú ní ìlú náà débi pé àwọn obìnrin kan jẹ àwọn ọmọ tí ó ti inú àwọn fúnra wọn jáde. (Ẹkún Jeremáyà 2:20) Bí Jeremáyà tilẹ̀ wà ní àhámọ́ nítorí pé kò bẹ̀rù láti wàásù, Jèhófà rí sí i pé wọ́n ń fún un ní “ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan” lójoojúmọ́ “títí gbogbo àkàrà fi tán ní ìlú.”—Jeremáyà 37:21.
Nítorí náà bíi tí Èlíjà, ìwọ̀nba ni oúnjẹ tí ó wà fún Jeremáyà láti jẹ. Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun tí Jeremáyà jẹ fún wa lẹ́yìn tí àkàrà tán ní Jerúsálẹ́mù tàbí bí ó ṣe jẹun déédéé tó. Síbẹ̀, a mọ̀ pé Jèhófà kò jẹ́ kí ebi pa á kú àti pé ó la àkókò ìyàn tí ó mú gan-an náà já.
Lónìí, òṣì ń bẹ ni apá ibi gbogbo lágbàáyé. Gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti sọ, ilẹ̀ Áfíríkà ni òṣì pọ̀ sí jù lọ. Àtẹ̀jáde àjọ UN kan ní 1996 sọ pé: “Ó kéré tán ìlàjì lára àwọn olùgbé Áfíríkà jẹ́ òtòṣì.” Láìka ipò ọrọ̀ ajé tí ó túbọ̀ ń le koko sí i sí, iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn olùgbé Áfíríkà ń fi ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì ń fi òtítọ́ sin Ọlọ́run, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé òun kì yóò jẹ́ kí ebi pa wọ́n kú. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò láti apá ibì kan nínú ayé wa oníwàhálà.
Bíbá A Lọ Ní Jíjẹ́ Aláìlábòsí
Michael,a tí ń gbé ní Nàìjíríà, jẹ́ àgbẹ̀ kan tí ó ní ọmọ mẹ́fà láti gbọ́ bùkátà lé lórí. Ó sọ pé: “Ó ṣòro láti jẹ́ aláìlábòsí bí o kò bá ní owó lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó bá ṣe mí bíi pé kí n hùwà àbòsí, mo máa ń rán ara mi létí Éfésù 4:28, tí ó sọ pé: ‘Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.’ Nítorí náà bí àdánwò bá dojú kọ mí, mo máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé, ‘Ṣé mo ṣiṣẹ́ fún owó yìí?’”
Michael fi kún un pé: “Fún àpẹẹrẹ, bí mo ṣe ń lọ lọ́jọ́ kan, mo rí àpò kan tí ó jábọ́ lẹ́yìn tatapùpù he. Kò ṣeé ṣe fún mi láti dá onítatapùpù náà dúró, nítorí náà mo gbé àpò náà, mo sì rí i pé owó ni ó kún inú rẹ̀ bámúbámú! Ní lílo ohun ìdánimọ̀ tí ó wà nínú àpò náà, mo rí ẹni tí ó ni í, mo sì dá àpò rẹ̀ pa dà fún un.”
Gbígbógun Ti Ìsoríkọ́
Ọkùnrin kan ní Àríwá Áfíríkà sọ pé: “Òṣì [dà bíi] jíjìn sí kòtò, síbẹ̀ tí o lè rí ìmọ́lẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ń rìn káàkiri fàlàlà, ṣùgbọ́n tí ohùn rẹ kò jákè tó láti kígbe fún ìrànlọ́wọ́ tàbí béèrè fún àkàsọ̀ tí o lè gùn jáde.” Abájọ tí òṣì fi lè mú ìmọ̀lára ìsoríkọ́ àti ìjákulẹ̀ wá! Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá lè rí ọrọ̀ àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pè gbígbé ìgbésí ayé oníwà títọ́ kò lè ṣeni láǹfààní. (Fi wé Orin Dáfídì 73:2-13.) Báwo ni a ṣe lè ṣẹ́pá irú ìrònú bẹ́ẹ̀?
Peter, ará Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà kan, fẹ̀yìn tì lẹ́yìn ọdún 19 lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba. Owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀ tí kò tó nǹkan nìkan ni ó fi ń gbéra báyìí. Peter sọ pé: “Nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá bá mi, mo máa ń rán ara mi létí ohun tí mo ti kà nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Ètò ìgbékalẹ̀ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá lọ, a sì ń dúró dé ètò ìgbékalẹ̀ tí ó dára ju èyí lọ.
“Bákan náà, mo máa ń ronú nípa Pétérù Kíní 5:9, tí ó sọ pé: ‘Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Sátánì], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí nínú gbogbo ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin yín nínú ayé.’ Nítorí náà, èmi nìkan kọ ni ìnira ń bá. Àwọn ìránnilétí wọ̀nyí ń ràn mí lọ́wọ́ láti kó àwọn ìrònú tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì, tí ó sì ń múni sorí kọ́ kúrò lọ́kàn.”
Peter fi kún un pé: “Ó ṣe tán, Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, bí kò tilẹ̀ sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́rọ̀ nípa ti ara. Èé ṣe tí èmi yóò fi retí pé kí ó sọ mí di ọlọ́rọ̀?”
Agbára Àdúrà
Sísúnmọ́ Jèhófà Ọlọ́run nínú àdúrà ni ọ̀nà míràn láti kojú ìrònú òdì. Nígbà tí Mary di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní 1960, ìdílé rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Kò lọ́kọ, ó sì ti lé ní 50 ọdún nísinsìnyí, ara rẹ̀ kò le, kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.
Mary sọ pé: “Nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá bá mi, mo máa ń tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà. Mo mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó lè ràn mí lọ́wọ́ tó bí òun ti lè ṣe. Mo mọ̀ pé nígbà tí o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Dáfídì, tí a rí nínú Orin Dáfídì 37:25 pé: ‘Èmi ti wà ní èwe, èmi sì dàgbà; èmi kò tí ì rí kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ kí ó máa ṣagbe oúnjẹ.’
“Mo tún ń rí ìṣírí gbà láti inú ìrírí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ti dàgbà, tí a sọ nínú Ilé Ìṣọ́. Jèhófà Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí náà mo mọ̀ pé yóò túbọ̀ máa ran èmi náà lọ́wọ́. Ó ń bù kún iṣẹ́ kékeré ti fùfú tí mo ń tà, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti gbọ́ bùkátà ojoojúmọ́. Nígbà kan, tí kò sówó lọ́wọ́ mi, tí mo sì ń ronú ohun tí n óò ṣe, Jèhófà rán ẹnì kan sí mi, tí ó fún mi ní ẹ̀bùn, ó sì sọ pé, ‘Arábìnrin, jọ̀wọ́ gba kiní yìí.’ Jèhófà kò já mi kulẹ̀ rí.”
Ìníyelórí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ ìníyelórí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, èyí kò sì yọ àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì láàárín wọn sílẹ̀. John ẹni ọgọ́ta ọdún ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà (oníwàásù Ìjọba alákòókò kíkún), ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Ó ń gbé inú ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ahẹrẹpẹ kan tí ìdílé 13 ń gbé inú rẹ̀. Iyàrá rẹ̀ jẹ́ apá kan ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè, tí a fi pákó gé. Àga ògbólógbòó méjì wà nínú rẹ̀ pẹ̀lú tábìlì kan tí a to àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí lórí gègèrè. Orí ẹní òré ni ó ń sùn.
John ń pa nǹkan bíi dọ́là kan lójúmọ́ nídìí búrẹ́dì tí ó ń tà, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé kíkó àlìkámà wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, ó pàdánù iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ yìí. Ó sọ pé: “Nígbà míràn, nǹkan máa ń nira fún mi gidigidi, ṣùgbọ́n mo ń bá ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà lọ. Jèhófà ni ó ń tọ́jú mi. Iṣẹ́kíṣẹ́ tí mo bá rí ni mò ń ṣe, n kò sì gbára lé ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí láti ràn mí lọ́wọ́ tàbí láti bọ́ mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará nínú ìjọ ń ràn mí lọ́wọ́ gidigidi. Wọ́n bá mi wáṣẹ́, nígbà míràn wọ́n sì ń fún mi lówó.
“Mo máa ń wá àkókò láti ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdájí nígbà tí ilé ṣì pa rọ́rọ́, n óò sì kàwé lálẹ́ nígbà tí iná bá wà. Mo mọ̀ pé n kò gbọ́dọ̀ fi ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi ṣeré.”
Títọ́ Àwọn Ọmọ Láti Rí Ìyè
Aya Daniel ti kú, ó sì ní ọmọ mẹ́fà. Ní 1985, ó pàdánù iṣẹ́ tí ó ti ń ṣe fún ọdún 25, ṣùgbọ́n ó rí iṣẹ́ abánitajà ní ilé ìtajà. Ó sọ pé: “Ní ti ọrọ̀ ajé, nǹkan kò fara rọ rárá fún ìdílé mi. Báyìí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a ń jẹun lójúmọ́. Nígbà kan, a kò jẹun fún ọjọ́ mẹ́ta. Omi nìkan ni a fi ń gbéra.”
Alàgbà ni Daniel nínú ìjọ. Ó sọ pé: “N kò pa ìpàdé Kristẹni jẹ rí, ọwọ́ mi sì dí fọ́fọ́ fún àwọn iṣẹ́ àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbàkígbà tí iṣẹ́ bá wà láti ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo máa ń rí i dájú pé mo wà níbẹ̀. Nígbà tí nǹkan bá sì nira, mo máa ń rán ara mi létí àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù sí Jésù, tí a kọ sílẹ̀ nínú Jòhánù 6:68 pé: ‘Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ?’ Bí n kò bá sin Jèhófà mọ́, níbo ni n óò lọ? Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Róòmù 8:35-39 pẹ̀lú jẹ́ kí n ṣe ìpinnu lílágbára nítorí pé wọ́n fi hàn pé kò sí ohun tí yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti Kristi. Ẹ̀mí ìrònú tí mo gbìn sínú àwọn ọmọ mi nìyí. Mo máa ń sọ fún wọn nígbà gbogbo pé a kò gbọ́dọ̀ fi Jèhófà sílẹ̀.” Ìtara Daniel, pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìdílé tí ń lọ déédéé, ti ní ipa rere lórí àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹ̀míi Fífúnni
Ẹnì kan lè rò pé kò ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n ń gbé ní ipò òṣì paraku láti fi owó ṣètọrẹ láti gbé ire Ìjọba lárugẹ. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. (Fi wé Lúùkù 21:1-4.) Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ní Gánà, tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ àgbẹ̀ àrojẹ ni wọ́n ń ṣe jẹun, ya apá kan ilẹ̀ wọn sọ́tọ̀ fún gbígbé ire Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ. Nígbà tí wọ́n ta irè oko yẹn, ète yẹn ni wọ́n lo gbogbo owó náà fún, tí ó ní ṣíṣètọrẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò nínú.
Joan, tí ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà, jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó ń ta búrẹ́dì láti lè tọ́jú ọkọ rẹ̀ tí ó ní àrùn ẹ̀gbà àti àwọn mẹ́rin mìíràn tí ń gbọ́ bùkátà. Nígbà tí ìjọ tí ó ń dara pọ̀ mọ́ nílò ìjókòó fún Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìdílé Joan pinnu láti fi gbogbo owó tí wọ́n ní sílé ṣètọrẹ. Wọn kò ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, lọ́jọ́ kejì, ẹnì kan tí ó ti jẹ wọ́n lówó tipẹ́tipẹ́ wá san gbèsè, ó fún wọn lówó tí wọ́n ti gbà pé àwọn kò lè rí gbà mọ́!
Joan jẹ́ ọlọ́yàyà, kì í sì í dààmú kọjá ààlà nípa owó. “N óò ṣàlàyé bí ipò nǹkan ti rí fún Jèhófà nínú àdúrà, lẹ́yìn náà n óò sì gba ẹnu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lọ. A mọ̀ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìrètí pé àwọn nǹkan yóò dára nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí. Síbẹ̀, a mọ̀ pé Jèhófà yóò bójú tó àwọn àìní wa.”
Títẹpá Mọ́ṣẹ́
Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ẹnì kíní kejì ni a fi ń dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀. (Jòhánù 13:35) Àwọn tí wọ́n lówó ń ran àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọn kò ní lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí ń wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn, nígbà míràn gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ láti báni wáṣẹ́.
Mark, tí ń gbé ní Congo, ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Ọmọọ̀kawọ́ àti ọmọọ̀kasẹ̀ rẹ̀ ti re. Nítorí èyí, ọ̀pá ìkẹ́sẹ̀ ni ó fi ń rìn. Nígbà tí Mark pinnu láti sin Jèhófà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Dípò títọrọ oúnjẹ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbin tirẹ̀. Ó tún máa ń yọ bíríkì àfamọ̀ṣe, tí ó máa ń tà.
Láìka àbùkù ara rẹ̀ sí, Mark ń bá a nìṣó láti máa tẹpá mọ́ṣẹ́. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ra ilẹ̀ kan, ó sì kọ́ ilé kékeré kan sórí rẹ̀. Lónìí, Mark ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ, a sì bọ̀wọ̀ fún un gidigidi ní ìlú tí ó ń gbé. Nísinsìnyí, ó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn mìíràn tí wọ́n ṣaláìní.
Àmọ́ ṣáá o, ní ọ̀pọ̀ ibi, ó ṣòro gidigidi láti ríṣẹ́. Kristẹni alàgbà kan tí ń sìn ní ọ̀kan nínú àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ arákùnrin tí ń bẹ níhìn-ín kò níṣẹ́ lọ́wọ́. Àwọn kan gbìyànjú láti dá iṣẹ́ tiwọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí kò rọrùn rárá. Ọ̀pọ̀ ronú pé, níwọ̀n bí àwọn yóò ti jìyà láìka ohun tí àwọn bá ṣe sí, àwọn yóò fi ohun ti ara rúbọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ rí i pé a túbọ̀ bù kún àwọn ní yanturu ju bí à bá ti ṣe ká ní àwọn níṣẹ́ tí ń mówó díẹ̀ wọlé tàbí tí kì í mówó wọlé rárá.”
Jèhófà Ń Pèsè fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
Jésù Kristi sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò ibùgbé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọkùnrin ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:58) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Títí di wákàtí yìí gan-an àwa ń bá a lọ nínú ebi àti òùngbẹ pẹ̀lú tí ó sì jẹ́ pé ekukáká ni a fi ń rí aṣọ wọ̀ tí a sì ń gbá wa káàkiri tí a sì jẹ́ aláìnílé.”—Kọ́ríńtì Kíní 4:11.
Jésù àti Pọ́ọ̀lù yàn láti gbé ìgbésí ayé mẹ̀kúnnù, kí wọ́n baà lè túbọ̀ lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún. Ọ̀pọ̀ Kristẹni òde òní jẹ́ òtòṣì nítorí pé kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe sí i. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń fi ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé, wọ́n sì ń fi ìtara wá ọ̀nà láti sin Ọlọ́run. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn gidigidi, bí wọ́n ti ń nírìírí ìjótìítọ́ ohun tí Jésù mú dáni lójú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo [ohun ti ara] mìíràn wọ̀nyí ni a óò sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:25-33) Ní àfikún sí i, àwọn òtòṣì ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí ní ẹ̀rí pé “ìbùkún Olúwa ní í múni là.”—Òwe 10:22.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn orúkọ àfidípò ni a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Wo Ni “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Náà”?
NÍ ÌBÁMU pẹ̀lú ìwádìíkiri èrò ará ìlú tí a ṣe ní ọdún 1994, ìpín 96 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará America “nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí nínú ẹ̀mí kan tí ó wà níbi gbogbo.” Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Iye ṣọ́ọ̀ṣì tí ó wà ní United States ní ìpíndọ́gba fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ju ti orílẹ̀-èdè míràn lórí Ilẹ̀ Ayé lọ.” Láìka irú ìtara ìsìn aláṣehàn bẹ́ẹ̀ sí, ògbógi nínú ìwádìíkiri èrò ará ìlú, George Gallup, Kékeré, sọ pé: “Òtítọ́ pọ́ńbélé tí ó wà níbẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará America kò mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbí ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́.”
Àkójọ ìsọfúnni tún fi hàn pé ìyàtọ̀ ńláǹlà wà láàárín ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ìgbésẹ̀ wọn. Fún àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Jeffery Sheler sọ pé: “Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé àwọn àgbègbè tí ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn ti lágbára jù lọ ni ibi tí ìwà ọ̀daràn ti ń ṣẹlẹ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà.”
Kò yẹ kí èyí yani lẹ́nu. Èé ṣe? Nítorí tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn láti ọ̀rúndún kìíní ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti ṣọ́ra fún àwọn tí wọ́n “polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n [tí] wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.” (Títù 1:16) Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà, Tímótì, pé àwọn ènìyàn tí wọ́n “ní ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀,” yóò sàmì sí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—Tímótì Kejì 3:1, 5.
Ṣùgbọ́n, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń sa gbogbo ipá wọn láti pa àṣẹ Jésù Kristi mọ́ láti ‘lọ kí wọ́n sì sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mátíù 28:19) Ní ọ̀nà yí, wọ́n “di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.”—Jákọ́bù 1:22.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ènìyàn kárí ayé mọ ìníyelórí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì