Ori 14
Lẹhin Majẹmu Titun Naa—Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun
1, 2. (a) Awọn wo ni a le fi araadọta ọkẹ awọn olujanfaani ninu iṣiṣẹ majẹmu titun naa wera pẹlu rẹ̀ lonii? (b) Ki ni awọn ilana ọpa idiwọn majẹmu titun naa wi?
ARAADỌTA ọkẹ awọn eniyan yipo ilẹ̀-ayé ni wọn ti bẹrẹsii gba anfaani gigadabu lati inu ìgbéṣẹ́ṣe majẹmu titun naa, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò si ninu rẹ̀. Wọn dabi awọn atipo ti kii ṣe ọmọ Israeli ti wọn ń gbe ní Israeli igbaani laaarin akoko ìgbà ti majẹmu Ofin Mose ṣi ń ṣiṣẹ. (Eksodu 20:10) Bawo ni ọran naa ṣe ri bẹẹ pẹlu araadọta ọkẹ awọn olujanfaani ti wọn ń darapọ mọ́ àṣẹ́kù awọn ọmọ Israeli lonii?
2 Ninu asọtẹlẹ Jeremiah 31:31-34, Ẹni naa ti ń fi awọn ilana ọpa idiwọn majẹmu titun naa lélẹ̀ wi pe: “Emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aya wọn; emi yoo si jẹ́ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ́ eniyan mi.”
3. (a) Ní ọna wo ni a gbà fun Israeli ní majẹmu Ofin Mose ogbologboo? (b) Ṣaaju ki a to bẹrẹsii kọ awọn Iwe Mímọ́ Kristian Lede Griki, nibo ni Ọlọrun mu ki a kọ awọn ofin majẹmu titun naa si?
3 Niti ọran majẹmu Ofin, Jehofa Ọlọrun, nipasẹ wolii Mose gẹgẹ bi alarina, fun awọn Israeli abinibi ní “iwe majẹmu . . . , ti a kọ ninu ofin.” (Kolosse 2:14) Ki ni nipa ti ofin majẹmu titun naa, nigba naa? Alarina rẹ̀ kò nilati kọ ọ sori okuta, tabi kọ ọ sinu iwe afọwọdakọ. Alarina rẹ̀ kò fi ikọwe eyikeyii ti ó jẹ́ ti araarẹ̀ silẹ. A mọ ohun ti ofin majẹmu titun naa jẹ́ lati inu awọn Iwe Mímọ́ Kristian Lede Griki ti a misi. (2 Timoteu 3:16) Ṣugbọn ṣaaju ki a to bẹrẹsii kọ awọn Iwe Mímọ́ Lede Griki wọnni paapaa, lati nnkan bii 41 C.E., Jehofa Ọlọrun ti bẹrẹsii kọ ofin rẹ̀ ti majẹmu titun. Nigba wo? Ní ọjọ Pentekosti, 33 C.E. Nibo? Ní ibi gan-an ti ó ti ṣeleri tipẹtipẹ lati kọ ọ si: “Emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkan wọn.”—Heberu 8:10.
4. Awọn iyọrisi rere wo ni kikọ ti Ọlọrun kọ awọn ofin rẹ̀ sinu ọkan-aya ati fifi wọn sinu awọn iranṣẹ rẹ̀ yoo ní?
4 Nitori pe a kọ ọ sinu ọkan-aya, kò ni fi bẹẹ ṣeeṣe fun awọn wọnni ti wọn ṣegbọran si awọn ofin yẹn lati dẹkun fifẹran wọn. Bi a ba fi awọn ofin yẹn “si inu wọn,” ko ni fi bẹẹ ṣeeṣe fun wọn lati gbagbe rẹ̀. Nitori naa, awọn olupa ofin wọnyi mọ wi, ninu awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 119:97 pe: “Emi ti fẹ ofin rẹ tó! iṣaro mi ni ní ọjọ gbogbo.” Lati inu isalẹ ikun wọn, wọn gbé ifẹni wọn lé awọn ofin Jehofa bi a ti funni nipasẹ Alarina rẹ̀, Jesu Kristi. Nipa bayii, pẹlu isunniṣe ti ó tọ́, wọn pinnu lati pa awọn ofin oniyebiye wọnni mọ́. Eyi kan “agbo kekere” ti wọn wà ninu majẹmu titun naa pẹlu “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran,” awọn ti kò si ninu majẹmu titun naa, ṣugbọn ti wọn wa labẹ rẹ̀.—Fiwe 1 Johannu 5:3; Johannu 14:15.
Ọran Ijọba naa Léwájú!
5. Ki ni Alarina majẹmu titun naa sọtẹlẹ ninu Matteu 24:12-14?
5 Awọn olupa ofin majẹmu titun naa mọ́ kò gbọdọ juwọsilẹ fun ohun ti Alarina naa, Jesu Kristi, sọ asọtẹlẹ rẹ̀ gẹgẹ bi apakan “ami . . . opin ayé [“ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” NW]”: “Nitori ẹ̀ṣẹ̀ yoo di pupọ, ifẹ ọpọlọpọ yoo di tutu. Ṣugbọn ẹni ti ó ba foriti i titi de opin, oun naa ni a o gbala. A o si waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede.”—Matteu 24:3, 12-14.
6. (a) Matteu 24:14 ha wulẹ jẹ́ asọtẹlẹ lasan kan bi? (b) Awọn wo ni o ti gbà á bi eyi ti ó ju ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ kan lọ, ki ni a si lè sọ niti iforiti wọn?
6 Alaye ti ó kẹhin yii ti ó nii ṣe pẹlu ijẹrii si Ijọba naa kárí-ayé kii ṣe asọtẹlẹ ṣakala kan. Aṣẹ kan ni fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti ń gbe ní “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” Itọsọna kan ni ó jẹ́ fun wọn lati tọ ipa ọna igbesẹ titọ lọ dé ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ó jẹ́ alainifẹẹ ti ó si ti rin gbingbin ninu iwa ailofin ní gbogbogboo, ti kii wulẹ ṣe ṣiṣaibọwọ fun ofin Ọlọrun. Awọn wo lonii ni wọn fihan pe awọn jẹ́ Kristian tootọ ti wọn gba awọn ọ̀rọ̀ Jesu Kristi wọnni bi aṣẹ fun wọn? Otitọ itan ti ó pọ̀ yanturu lati 1919 ń fi tootọtootọ dahun pe, “awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni”! Ipolongo ikọnilẹkọọ Bibeli wọn nipa Ijọba naa ni eyi ti ó gadabu julọ ninu akọsilẹ, wọn si ti fi iforiti hàn ninu rẹ̀ lati 74 ọdun ti ó ti kọja. Lọdọọdun nisinsinyi, o ń dagba sii ní iye ati agbara.
7, 8. (a) Nigba Ogun Agbaye I, ki ni Satani gbiyanju lati ṣe si awọn wọnni ti wọn wa ninu majẹmu titun naa? (b) Nigba sáà ọdun ẹhin ogun, bawo ni ọran Ijọba naa ṣe gba ipo iwaju?
7 Satani Eṣu gbiyanju lati dí ipolongo idanilẹkọọ Bibeli agbayanu yii lọwọ nipa mimu ki àṣẹ́kù kekere awọn ọmọ Israeli nipa tẹmi naa di eyi ti a parẹ́ nigba Ogun Agbaye I. O kuna! Ní kánmọ́, lẹhin isọji wọn lati inu ipo bi oku ní ìgbà ẹrun 1919, wọn ṣe apejọpọ wọn akọkọ lẹhin ogun ní Cedar Point, Ohio, ní September ọdun yẹn. Ní apejọpọ wọn keji ní Cedar Point ní September 1922, ọran Ijọba naa ni o gba ipo iwaju. Ní ọjọ kẹrin apejọpọ naa, ti ó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ naa “Ọjọ Naa,” aarẹ Watch Tower Society mú ọ̀rọ̀ awiye ti ń runilọkansoke wa si otente titobilọla nipa kikede pe:
8 “Nigba naa, ẹ pada sí pápá, óò ẹyin ọmọkunrin Ọlọrun Ọga Ogo Julọ! Ẹ dihamọra yin! Ẹ jẹ́ alairekọja, ẹ wà lojufo, ẹ jẹ́ alakitiyan, ẹ jẹ́ akikanju. Ẹ jẹ́ ẹlẹ́rìí oluṣotitọ ati oloootọ fun Oluwa. Ẹ tẹsiwaju ninu ija naa titi ti gbogbo ipasẹ̀ Babiloni yoo fi di ahoro. Ẹ kede ihin iṣẹ naa jìnnà réré. Ayé gbọdọ mọ̀ pe Jehofa ni Ọlọrun ati pe Jesu Kristi ni Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa. Eyi jẹ́ ọjọ ninu gbogbo awọn ọjọ. Kiyesi i, Ọba naa ti ń jọba! Ẹyin ni aṣoju olupolongo rẹ̀. Nitori naa ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, ẹ fọnrere Ọba naa ati Ijọba rẹ̀.”
Fifi Òye Pupọ Sii Mọ Jehofa
9. (a) Nitori ibisi ẹri nipa ijọba ododo yẹn, iduro wo ni awọn eniyan ní lati mú? (b) Awọn wọnni ti ń mu iduro rere ni a ń fun ní iru imọ wo?
9 O ti wá ju 70 ọdun lọ nisinsinyi ti a ti gbé Kristi gun ori itẹ ninu agbara Ijọba ní 1914. Lati ìgbà naa wá, awọn ẹri nipa ijọba ododo Ọlọrun ti pọ̀ sii lọna kikọyọyọ. Awọn eniyan ayé iran eniyan gbọdọ mu iduro wọn ṣe kedere niti ọran Ijọba naa, boya fun Ijọba naa tabi lodisi i. Awọn wọnni ti wọn mu iduro wọn niha ọdọ ijọba atọrunwa naa ni a ń mu awọn ọ̀rọ̀ pataki inu majẹmu titun naa ṣẹ si lara pe: “Wọn kii yoo si kọni mọ́ ẹnikinni ẹnikeji rẹ̀, ati ẹgbọn, aburo rẹ̀, wi pe, Mọ [Jehofa! NW]: nitori pe gbogbo wọn ni yoo mọ̀ mi, lati ẹni kekere wọn de ẹni nla wọn.”—Jeremiah 31:34.
10. (a) Nitori naa labẹ orukọ wo ni àṣẹ́kù awọn ọmọ Israeli tẹmi bẹrẹsii kí “awọn agutan miiran” kaabọ? (b) Iru imọ wo ni “awọn agutan miiran” ri gbà?
10 Ní 1935 àṣẹ́kù awọn ọmọ Israeli tẹmi bẹrẹsii kí “awọn agutan miiran” ti Oluṣọ-Agutan Rere naa kaabọ ní ikojọpọ alaapọn pẹlu wọn ninu “agbo kan” labẹ Jesu Kristi, niwọn bi gbogbo wọn ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nigba naa “awọn agutan miiran” yẹn, ti wọn bẹrẹsii kojọpọ lati di “ogunlọgọ nla” ti a kò mọ iye wọn tẹ́lẹ̀, bẹrẹ, ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu àṣẹ́kù naa ti a fi ẹmi bi, lati maa “pa ofin Ọlọrun mọ” ti wọn sì ń ṣe iṣẹ jijẹ “ẹ̀rí Jesu.” (Ìfihàn 7:9-17, NW; 12:17) Nipa bayii lati ibẹrẹ ní 1935, “awọn agutan miiran” wọnyi bakan naa wá bẹrẹsii mọ Jehofa “lati ẹni kekere wọn de ẹni nla wọn.”
11. Bawo ni imọ Kristian nipa Jehofa ṣe yatọ ti ó si dara ju ti awọn Ju labẹ majẹmu Ofin?
11 Ní ọna wo, bi o ti wu ki o ri, ni imọ Kristian nipa Jehofa ṣe yatọ ti ó si dara ju imọ tí awọn Ju ní labẹ majẹmu Ofin Mose ogbologboo naa? Ẹni ọrun ti ó jẹ Oluṣe majẹmu titun naa ń baa lọ lati sọ fun wa pe: “Nitori emi o dari aiṣedeedee wọn jì, emi ki o ranti ẹṣẹ wọn mọ́.” (Jeremiah 31:34; Heberu 8:12) Eyi jẹ́ nitori otitọ naa pe majẹmu titun naa ni a gbekari irubọ ti ó dara ju nipasẹ Alarina ti ó dara ju. (Heberu 8:6; 9:11, 12, 22, 23) Irubọ didara ju naa ti Alarina ti o dara ju kò nilo titunṣe, bii ti Ọjọ Iwẹnumọ ti ọlọdọọdun naa labẹ majẹmu Ofin Mose ti ogbologboo. (Heberu 10:15-18) Ní oju-iwoye gbogbo eyi, imọ Jehofa tí awọn wọnni ti wọn wà ninu ati labẹ majẹmu titun naa ní dara, o lọ́ràá, o laniloye, o kunrẹrẹ niti tootọ ju imọ Ọlọrun tí awọn Ju ní labẹ majẹmu Ofin.
12. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ipo wo ni Jehofa wà si awọn wọnni ti a mú wọnú majẹmu titun naa ati awọn wọnni ti wọn wà labẹ rẹ̀?
12 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jehofa Ọlọrun, Oluda-Majẹmu naa, ni Ọba lori gbogbo awọn ti ó mu wa sinu majẹmu titun naa ati lori awọn wọnni ti oun mu wa sabẹ rẹ̀. (Matteu 5:34, 35; Jeremiah 10:7) Aposteli Paulu, ní 1,850 ọdun ṣaaju ki a to gbé Jesu gun ori itẹ bi Ọba ní ọ̀run ní 1914, tọkasi ipo ọba Jehofa lori awọn wọnni ti ń ṣegbọran si awọn ofin majẹmu titun naa, ní wiwi pe: “Njẹ fun Ọba ayeraye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọla ati ogo wà fun lae ati laelae. Amin.”—1 Timoteu 1:17.
Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun Lẹhin “Ipọnju Nla” Naa
13. (a) Nigba wo ati labẹ awọn ayika ipo wo ni “ogunlọgọ nla” yoo fi wọnú awọn ibukun ti ń ṣan wá lati inu majẹmu titun naa lẹkun-unrẹrẹ? (b) Ète titobilọla wo ni majẹmu titun naa yoo ti muṣẹ?
13 “Ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran,” ti wọn kò si ninu majẹmu titun naa ṣugbọn ti wọn wà labẹ rẹ̀, ń fojusọna fun jijade wá laaye la “ipọnju nla” naa já. Lẹhin pipa eto awọn nǹkan isinsinyi ti a ti dalẹbi run, wọn yoo gbadun, iṣakoso Jesu Kristi ati awọn ajumọjogun rẹ̀ fun ẹgbẹrun ọdun, lori ilẹ̀-ayé ti a ti sọ di mímọ́ tonitoni. (Ìfihàn 7:9-14) Nigba naa ète majẹmu titun naa ni a o ti muṣẹ, iyẹn ni mimu awọn “eniyan ọ̀tọ̀” jade lati di awọn ajumọjogun Ijọba ọ̀run ti Ọlọrun. (1 Peteru 2:9; Iṣe 15:14) Nipasẹ Ijọba Ọlọrun, ibukun yoo maa ṣan lẹkun-unrẹrẹ sọdọ “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti wọn laaja. Satani Eṣu ati ètò-àjọ awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ti a kò lè fojuri ni a o ti semọ inu ọgbun ainisalẹ ti wọn ki yoo si lè dasi ọran mọ́.—Ìfihàn 21:1-4; 20:1-3.
14. Igbaradi rere wo ni “ogunlọgọ nla” olulaaja naa yoo ti ni?
14 “Ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti wọn laaja yoo ti ní igbaradi rere fun gbigbe igbesi-aye ninu eto-igbekalẹ awọn nǹkan titun. Gẹgẹ bi àṣẹ́kù Israeli tẹmi, wọn yoo ti wá mọ Ọlọrun “lati ẹni kekere wọn de ẹni nla wọn.” (Jeremiah 31:34) Ninu adura si Ọlọrun, Ọba ti ń ṣakoso naa wi nigba kan pe: “Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́n, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi ẹni ti iwọ ran.” (Johannu 17:3) Nitori naa imọ kárí-ayé nipa Jehofa Ọlọrun yii yoo ṣaṣeyọri fun igbala ayeraye. Eyi yoo jẹ́ otitọ kii ṣe kiki niti “ẹran ara” ti a o gbala laaye la “ipọnju nla” ja nikan ni ṣugbọn ati fun ọgọọrọ billion awọn oku eniyan ti wọn yoo gbọ́ ohùn Ọba naa ti wọn yoo si jade wa lati inu iboji iranti wọn. Gbogbo imọ Jehofa ti ó yẹ ni wọn yoo fi kọ awọn ẹni ti a ji dide bẹẹ.—Matteu 24:21, 22; Johannu 5:28, 29; Ìfihàn 20:11-15.
15. Eeṣe ti mimu majẹmu titun naa ṣẹ ki yoo fi yọrisi ipadanu kankan fun “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” naa?
15 Lọna ti o muni layọ, mimu majẹmu titun Ọlọrun ṣẹ si aṣeyọri titobilọla ki yoo yọrisi ipadanu fun “ogunlọgọ nla” awọn ẹni bi agutan ti wọn la iparun eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii ti a ti dalẹbi ja. Kaka bẹẹ, yoo ṣi ọna silẹ fun awọn ibukun ti ó tubọ tobilọla ju bẹẹ lọ nihin-in lori ilẹ̀-ayé ti a ti fọ̀ mọ́ ti yoo jẹ́ tiwọn lati jogun ati pe wọn yoo ní ipin akọkọ ninu ṣiṣe atunṣebọsipo sinu paradise agbaye kan. (Matteu 25:34; Luku 23:43) Laipẹ si isinsinyi, awọn wọnni ti ń run ayé yoo poora, “ṣugbọn awọn ti ó duro de Oluwa ni yoo jogun ayé. . . . Awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun ayé; wọn o si maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.” (Orin Dafidi 37:9-11) Ki gbogbo eniyan kókìkí Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun Jehofa Ọlọrun nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ti ó ṣaṣepari mimu majẹmu titun naa ṣẹ!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]
Ihinrere Ijọba Ọlọrun ni a o si waasu jakejado ayé ṣaaju ki eto-igbekalẹ isinsinyi tó dopin