“Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
“Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pétérù 2:17.
1, 2. (a) Kí ni akọ̀ròyìn kan sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (b) Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń làkàkà láti máa tẹ̀ lé ìlànà gíga ní ti ìwà híhù?
NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn, akọ̀ròyìn kan nílùú Amarillo, ní Texas, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, bẹ onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì wò lágbègbè náà ó sì sọ ohun tó rí. Ó rí i pé ìsìn kan wà tó yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó kù. Ó sọ pé: “Ọdún mẹ́ta gbáko ni mo fi lọ sí àpéjọ ọdọọdún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìlú Amarillo. Gbogbo bí mo ṣe wà láàárín wọn, mi ò rí i kí ẹnì kan ṣáná sí sìgá, mi ò rí i kí ẹnì kan mutí tàbí sọ̀rọ̀ àlùfààṣá. Nínú gbogbo èèyàn tí mo ti ń pàdé láyé yìí, àwọn lèèyàn tó mọ́ jù, tó ń hùwà ọmọlúwàbí jù, tí ìmúra wọn wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tí wọn kì í sì í kọjá àyè wọn.” Mélòó la fẹ́ kà nínú irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí táwọn èèyàn ti kọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ló mú káwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tàwọn Ẹlẹ́rìí máa gbóríyìn fún wọn látìgbàdégbà?
2 Ìwà rere àwọn èèyàn Ọlọ́run ló sábàá máa ń jẹ́ káwọn èèyàn kan sáárá sí wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ nìwà àwọn èèyàn túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i láyé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ìwà ọmọlúwàbí sí ọ̀ranyàn, àti pé ó jẹ́ apá kan ìjọsìn wọn. Wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn á máa fi ojú ohunkóhun táwọn bá ṣe wo Jèhófà àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, àti pé ìwà rere wọn á tún jẹ́ káwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni. (Jòhánù 15:8; Títù 2:7, 8) Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè máa hùwà tó dára nìṣó ká lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ káwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ Jèhófà àtàwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ní dáadáa, àti ọ̀nà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè gbà ṣe wá láǹfààní.
Ìdílé Kristẹni
3. Àwọn ewu wo ló ń bẹ táwọn ìdílé Kristẹni fi nílò ààbò?
3 Ẹ jẹ́ ká gbé ìwà wa láàárín agboolé yẹ̀ wò. Ìwé Die Neuen Inquisitoren: Religionsfreiheit und Glaubensneid (Àwọn Ṣẹ̀ṣẹ̀dé Olùwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀: Òmìnira Ìsìn àti Ìlara Ìsìn), látọwọ́ Gerhard Besier àti Erwin K. Scheuch, sọ pé: “Àwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kò fi ọ̀rọ̀ dídáàbò bo ìdílé ṣeré rárá.” Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí o, àní lásìkò tá a wà yìí ìdílé nílò ààbò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu tó ń bẹ lóde. Ọ̀pọ̀ ọmọ ló ti di “aṣàìgbọràn sí òbí,” àwọn àgbàlagbà míì sì ti di “aláìní ìfẹ́ni àdánidá” tàbí “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.” (2 Tímótì 3:2, 3) Ìdílé ti di ibi tí tọkọtaya ti ń hùwà ipá síra wọn, àwọn òbí ń han àwọn ọmọ wọn léèmọ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n tì pàápàá, àwọn ọmọ ń di ọlọ̀tẹ̀, wọ́n ń lo oògùn olóró, wọ́n sì ń hùwà pálapàla, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sá kúrò nílé pàápàá. Gbogbo èyí ò ṣẹ̀yìn ipa búburú tí ‘ẹ̀mí ayé’ ń ní. (Éfésù 2:1, 2) A gbọ́dọ̀ dáàbò bo ìdílé wa lọ́wọ́ ẹ̀mí yìí. Lọ́nà wo? Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ ni.
4. Ojúṣe wo ni àwọn èèyàn inú ìdílé Kristẹni ní láti máa ṣe fún ẹnì kìíní kejì wọn?
4 Àwọn tọkọtaya Kristẹni mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni láti máa gba ti ìmí ẹ̀dùn ọkọ tàbí aya àwọn rò, àti láti máa bójú tó wọn nípa tẹ̀mí àti nípa tara. (1 Kọ́ríńtì 7:3-5; Éfésù 5:21-23; 1 Pétérù 3:7) Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ní ẹrù iṣẹ́ tó wúwo láti gbé nípa àwọn ọmọ wọn. (Òwe 22:6; 2 Kọ́ríńtì 12:14; Éfésù 6:4) Bí àwọn ọmọ inú agboolé Kristẹni bá ṣe ń dàgbà làwọn náà ń rí i pé àwọn ohun kan wà táwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe. (Òwe 1:8, 9; 23:22; Éfésù 6:1; 1 Tímótì 5:3, 4, 8) Ṣíṣe ojúṣe ẹni nínú ìdílé ń béèrè ìsapá, ìpinnu tó lágbára, ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Àmọ́, bí gbogbo èèyàn inú ìdílé bá ṣe gbìyànjú tó láti ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run lànà fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á ṣe jẹ́ ìbùkún tó fún ara wọn àti fún ìjọ. Ohun tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ọ̀wọ̀ fún Ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Éfésù 3:15.
Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kristẹni
5. Ìbùkún wo là ń rí nínú bíbá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́?
5 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ojúṣe wa tún kan àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tá a jọ wà nínú ìjọ, kódà ó tún dé ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará . . . nínú ayé.” (1 Pétérù 5:9) Àjọṣe wa láàárín ìjọ ṣe pàtàkì nínú bí a ó ṣe ṣe dáadáa sí nípa tẹ̀mí. Tá a bá bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́, wọ́n á fún wa níṣìírí àá sì tún rí oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fúnni lókun gbà látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47) Tá a bá sì níṣòro, a lè lọ gbàmọ̀ràn tó mọ́yán lórí tá a gbé ka ìlànà Ìwé Mímọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará wa. (Òwe 17:17; Oníwàásù 4:9; Jákọ́bù 5:13-18) Àwọn arákùnrin wa kì í ta wá nù lákòókò tá a bá wà nípò àìní. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni láti jẹ́ apá kan ètò àjọ Ọlọ́run!
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé àwọn ojúṣe kan wà tó yẹ ká máa ṣe fáwọn Kristẹni mìíràn?
6 Àmọ́ ṣá, kì í ṣe tìtorí rírí nǹkan gbà nìkan la ṣe wà nínú ìjọ; ó yẹ kí àwa náà máa fún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan. Jésù tiẹ̀ sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ẹ̀mí fífúnni nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn, nítorí olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí. Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Hébérù 10:23-25.
7, 8. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí fífúnni hàn nínú ìjọ àti sáwọn Kristẹni ní ilẹ̀ mìíràn?
7 Nínú ìjọ, bí a bá ń dáhùn nínú ìpàdé tàbí tí à ń lọ́wọ́ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé láwọn ọ̀nà mìíràn, à ń ṣe “ìpolongo ìrètí wa” nìyẹn. Irú ìsapá wọ̀nyẹn máa ń fún àwọn ará wa níṣìírí. A tún ń fún wọn níṣìírí nípa bíbá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé. Ìwọ̀nyí jẹ́ àkókò tá a lè fún àwọn tára wọn ò le lókun, tá a lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tó sorí kọ́, ká sì tu àwọn tó ń ṣàìsàn nínú. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń pèsè fúnni dáadáa lọ́nà yìí, èyí ló ń mú kí ìfẹ́ tí àwọn tó wá sípàdé wa fúngbà àkọ́kọ́ ń rí láàárín wa máa wú wọn lórí.—Sáàmù 37:21; Jòhánù 15:12; 1 Kọ́ríńtì 14:25.
8 Síbẹ̀, kì í ṣe kìkì inú ìjọ tiwa ni ìfẹ́ wa parí sí o. Ó kan gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ìdí tí àpótí ọrẹ kan tá a yà sọ́tọ̀ fún Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba fi wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan. Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwa lè dára rèǹtè-rente, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni ò ní ibi tó dára láti máa ṣèpàdé. Tá a bá ń mú ọrẹ wá láti ṣètìlẹ́yìn fún Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí ńṣe ló ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bá ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n sójú.
9. Kí lohun náà gan-an tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn?
9 Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn? Jésù ló mà pa á láṣẹ fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ o. (Jòhánù 15:17) Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ lára wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára “èso ti ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:22, 23) Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n ń lọ sípàdé Kristẹni, tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ ń di omi ara àti ẹ̀jẹ̀ wọn láìka gbígbé tí wọ́n ń gbé nínú ayé tí “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ti di tútù” sí.—Mátíù 24:12.
Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn Ayé
10. Ojúṣe wo la ní sí àwọn èèyàn ayé?
10 “Ìpolongo ìrètí wa ní gbangba” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn yẹn rán wa létí ojúṣe mìíràn tá a tún ní. Ìpolongo ní gbangba yìí kan iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà fáwọn tí kò tíì di Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Róòmù 10:9, 10, 13-15) Ìwà fífúnni ni irú iṣẹ́ ìwàásù bẹ́ẹ̀ jẹ́ bákan náà. Kéèyàn tó kópa nínú rẹ̀, ó ń béèrè àkókò, okun, ìmúrasílẹ̀, ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìnáwó-nára. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú: nítorí náà, ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere pẹ̀lú fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù.” (Róòmù 1:14, 15) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, kí àwa náà má ṣe háwọ́ bá a ṣe ń san “gbèsè” yìí o.
11. Ìlànà méjì wo látinú Ìwé Mímọ́ ló ń darí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé, síbẹ̀síbẹ̀ kí lohun tá a mọ̀?
11 Ǹjẹ́ a tún ní ojúṣe mìíràn sí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa? Bẹ́ẹ̀ ni o. A kò ṣàìmọ̀ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) A mọ ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Síbẹ̀, inú ayé là ń gbé, ibẹ̀ la ti ń ṣe ọrọ̀ àtijẹ àtimu àtàwọn nǹkan mìíràn. (Jòhánù 17:11, 15, 16) Nítorí náà, a ní àwọn ojúṣe kan tó yẹ ká máa ṣe fáráyé. Kí làwọn ojúṣe yìí? Àpọ́sítélì Pétérù dáhùn ìbéèrè yẹn. Láìpẹ́ sí ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run, ó kọ lẹ́tà kan sáwọn Kristẹni tó wà ní Éṣíà Kékeré. Apá kan lẹ́tà yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì pẹ̀lú àwọn èèyàn inú ayé.
12. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà jẹ́ “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀,” kí ló sì yẹ kí èyí mú wọn yẹra fún?
12 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Pétérù sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo gbà yín níyànjú gẹ́gẹ́ bí àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ láti máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara, tí í ṣe àwọn ohun náà gan-an tí ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn.” (1 Pétérù 2:11) Tá a bá fojú tẹ̀mí wò ó, “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀” làwọn Kristẹni tòótọ́. Ìdí ni pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn, àwọn tá a fẹ̀mí yàn á gbádùn tiwọn lókè ọ̀run nígbà táwọn “àgùntàn mìíràn” á gbádùn tiwọn nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀. (Jòhánù 10:16; Fílípì 3:20, 21; Hébérù 11:13; Ìṣípayá 7:9, 14-17) Nígbà náà, kí làwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara? Èyí ní nínú fífẹ́ láti di ọlọ́rọ̀, fífẹ́ láti wà ní ipò ọlá, ṣíṣe ìṣekúṣe, àtàwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí Bíbélì pè ní “ìlara” àti “ojúkòkòrò.”—Kólósè 3:5; 1 Tímótì 6:4, 9; 1 Jòhánù 2:15, 16.
13. Báwo ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣe “ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn” wa?
13 Àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọ̀nyí ló “ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn” wa. Ńṣe ni wọ́n ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run yìnrìn wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ìrètí Kristẹni wa (ìyẹn “ọkàn” tàbí ìwàláàyè wa) sínú ewu. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ìṣekúṣe, báwo la ṣe máa fi ara wa fún “Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà”? Tá a bá jìn sí ọ̀fìn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, báwo la ṣe máa ‘wá Ìjọba náà’ lákọ̀ọ́kọ́? (Róòmù 12:1, 2; Mátíù 6:33; 1 Tímótì 6:17-19) Ohun tó ti dára jù ni pé ká ṣe bí Mósè ṣe ṣe, ká wo àwọn ohun tó ń fani mọ́ra nínú ayé láwòmọ́jú, ká sì fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. (Mátíù 6:19, 20; Hébérù 11:24-26) Ohun tó ṣe pàtàkì gan-an nìyẹn téèyàn bá fẹ́ ní àjọṣe tí ò kọjá ààlà pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé.
‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìwà Yín Dára’
14. Èé ṣe táwa Kristẹni fi ń sakun láti hùwà tó dára?
14 Ìlànà mìíràn tó ṣe pàtàkì wà nínú ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ tẹ̀ lé e: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pétérù 2:12) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, à ń sapá láti jẹ́ àwòkọ́ṣe. À ń kọjú mọ́ ẹ̀kọ́ wa nílé ìwé. Níbi iṣẹ́, a kì í ṣe ọ̀lẹ a kì í sì í ṣàbòsí, kódà kí ẹni tó gbà wá síṣẹ́ tiẹ̀ jẹ́ aláìgbatẹnirò. Nínú ìdílé tí tọkọtaya ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa ń sapá gidigidi láti fi àwọn ìlànà Kristẹni sílò. Èyí kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ìwà àwòkọ́ṣe tá à ń hù dùn mọ́ Jèhófà nínú àti pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa nípa rere lórí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.—1 Pétérù 2:18-20; 3:1.
15. Báwo la ṣe mọ̀ pé nílé lóko làwọn èèyàn ti mọ ìlànà gíga ti ìwà híhù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé?
15 Ọ̀rọ̀ táwọn akọ̀ròyìn ń gbé jáde nípa àwọn tó pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ń fi hàn pé lóòótọ́ ni ìwà tí wọ́n ń hù jẹ́ àwòkọ́ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Il Tempo, ti Ítálì sọ pé: “Àwọn tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ pọ̀ sọ pé òṣìṣẹ́ tí kì í ṣàbòsí ni wọ́n, pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ dá wọn lójú débi pé èèyàn lè máa ronú pé ó ti fẹ́ gbà wọ́n níyè pàápàá; síbẹ̀, ó yẹ ká gbóríyìn fún wọn nítorí ìwà mímọ́ wọn.” Ìwé ìròyìn Herald ti ìlú Buenos Aires, ní Ajẹntínà, sọ pé: “Látọdún pípẹ́ la ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àwọn èèyàn tí kì í ṣọ̀lẹ, tó kọjú mọ́ṣẹ́, tó mọ béèyàn ṣe ń ṣúnwó ná, tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ Rọ́ṣíà náà Sergei Ivanenko, sọ pé: “Gbogbo àgbáyé la ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń pa òfin mọ́ gan-an, àgàgà tó bá kan ti sísan owó orí.” Alábòójútó gbọ̀ngàn kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò fún àpéjọ àgbègbè wọn ní Zimbabwe sọ pé: “Mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ń ṣa bébà tí wọ́n sì tún ń fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Gbọ̀ngàn náà mọ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn èwe yín jẹ́ ọmọ dáadáa. Ì bá wù mí kó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kún inú gbogbo ayé.”
Ìtẹríba Kristẹni
16. Irú àjọṣe wo la ní pẹ̀lú àwọn aláṣẹ, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
16 Pétérù tún mẹ́nu kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn aláṣẹ. Ó sọ pé: “Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá: yálà sábẹ́ ọba gẹ́gẹ́ bí onípò gíga tàbí sábẹ́ àwọn gómìnà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó rán láti fi ìyà jẹ àwọn aṣebi ṣùgbọ́n láti yin àwọn olùṣe rere. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, pé nípa ṣíṣe rere kí ẹ lè dí ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan mọ́ àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú lẹ́nu.” (1 Pétérù 2:13-15) A mọrírì àǹfààní tá à ń gbádùn látọ̀dọ̀ ìjọba a sì ń pa òfin ìjọba mọ́, a sì ń san owó orí wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe kọ́ wa. Lóòótọ́ a mọ̀ pé Ọlọ́run fún ìjọba láṣẹ láti fìyà jẹ àwọn tó bá rúfin, àmọ́ lájorí ìdí tá a fi ń tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ jẹ́ “nítorí Olúwa.” Ọlọ́run ló fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, a ò fẹ́ dẹni tó kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà nípa ṣíṣe ohun tí kò tọ́ tí wọ́n á fi fìyà jẹ wá.—Róòmù 13:1, 4-7; Títù 3:1; 1 Pétérù 3:17.
17. Ìdánilójú wo la ní tí “àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú” bá tiẹ̀ ń ta kò wá?
17 Ó bani nínú jẹ́ pé “àwọn aláìlọ́gbọ́n-nínú” kan tí wọ́n jẹ́ aláṣẹ ń ṣenúnibíni sí wa tàbí kí wọ́n hàn wá léèmọ̀ láwọn ọ̀nà mìíràn, irú bíi kí wọ́n máa fẹ́ná sí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn táwọn èèyàn ń sọ kiri nípa wa. Síbẹ̀, ńṣe làṣírí irọ́ wọn máa ń tú tó bá tó àsìkò lójú Jèhófà, tẹnu wọn á wá wọhò, tí wọn ò ní lè sọ àwọn “ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan” yìí mọ́. Ìwà Kristẹni tá a ti ń hù látọjọ́ pípẹ́ ti jẹ́ káyé mọ̀ pé a ò sí nídìí irọ́. Ìdí rèé táwọn aláṣẹ tó lóòótọ́ lẹ́nu fi máa ń yìn wá pé iṣẹ́ rere là ń ṣe.—Róòmù 13:3; Títù 2:7, 8.
Ẹrú Ọlọ́run
18. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà yẹra fún ṣíṣi òmìnira wa lò?
18 Pétérù wá kìlọ̀ pé: “Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú fún ìwà búburú, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:16; Gálátíà 5:13) Ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì tá a ní lónìí ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké. (Jòhánù 8:32) Ìyẹn nìkan kọ́, a ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Àmọ́ ṣá, a kì í ṣi òmìnira wa lò. Tá a bá fẹ́ yan àwọn tá a fẹ́ máa bá rìn, aṣọ tá a ó wọ̀, ìmúra wa, eré ìnàjú, tó fi dórí jíjẹ mímu pàápàá, a máa ń rántí pé ẹrú Ọlọ́run làwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́, wọn kì í kàn án ṣe bó ṣe wù wọ́n. A yàn láti sin Jèhófà dípò tá à bá fi di ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tàbí àwọn àṣà ìgbàlódé àti ìṣe àwọn èèyàn ayé.—Gálátíà 5:24; 2 Tímótì 2:22; Títù 2:11, 12.
19-21. (a) Ojú wo la fi ń wo àwọn tó wà nípò àṣẹ? (b) Ọ̀nà wo làwọn kan gbà “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará”? (d) Kí ni ojúṣe wa tó ṣe pàtàkì jù lọ?
19 Pétérù tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ máa fi ọlá fún ọba.” (1 Pétérù 2:17) A máa ń bọlá fún àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ bó ṣe yẹ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ló yọ̀ǹda pé kéèyàn wà nípò wọ̀nyẹn. A tiẹ̀ máa ń gbàdúrà nípa wọn pàápàá, pé kí wọ́n lè jẹ́ ká rímú mí nídìí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká sì lè ṣe é pẹ̀lú ẹ̀mí ìfọkànsìn. (1 Tímótì 2:1-4) Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, a tún “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” Ohun tó máa ṣe àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa láǹfààní là ń lépa ní gbogbo ìgbà, kì í ṣe èyí tó máa pa wọ́n lára.
20 Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣe orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú, ìwà Kristẹni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hù yàtọ̀ gedegbe. Ìwé ìròyìn Reformierte Presse, ti Switzerland sọ pé: “Ní 1995, Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ilẹ̀ Áfíríkà . . . fi ẹ̀rí hàn pé, gbogbo ìsìn pátá ló lọ́wọ́ nínú [ogun náà], àyàfi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo.” Nígbà tí ìròyìn ogun náà lu sétí gbogbo aráyé, kíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Yúróòpù fi oúnjẹ àti oògùn ránṣẹ́ sáwọn ará wọn àtàwọn mìíràn ní ilẹ̀ tí ogun ti ń jà náà. (Gálátíà 6:10) Wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú Òwe 3:27 pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”
21 Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti sọ, a ṣì tún ní ojúṣe kan tó ṣe pàtàkì ju ọ̀wọ̀ tá à ń fún àwọn aláṣẹ àti ìfẹ́ tá a tiẹ̀ ní sáwọn ará wa pàápàá. Kí lojúṣe náà? Pétérù sọ pé: “Ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run.” Ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè máa ṣe ojúṣe wa sí Ọlọ́run ká sì máa ṣe tàwọn aláṣẹ náà fún wọn láìjẹ́ kí ọ̀kan pa èkejì lára? Àpilẹ̀kọ́ tó kàn á dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ojúṣe wo làwọn Kristẹni ní láti máa ṣe nínú ìdílé?
• Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí fífúnni hàn nínú ìjọ?
• Ojúṣe wo ló yẹ ká máa ṣe fáwọn èèyàn ayé?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tá à ń rí nínú bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà gíga ti ìwà híhù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Báwo ni ìdílé Kristẹni ṣe lè jẹ́ orísun ayọ̀ ńláǹlà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ǹjẹ́ a lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá ò mọ̀ rárá?