Kí ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa Lónìí?
“Ohùn kan láti inú àwọsánmà náà, wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.’”—MÁTÍÙ 17:5.
1. Ìgbà wo ni Òfin náà mú ète rẹ̀ ṣẹ?
JÈHÓFÀ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Òfin, ó sì ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ka. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ọ̀pọ̀ ẹ̀ka wọ̀nyí, ó wí pé: “Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí òfin béèrè tí ó jẹmọ́ ẹran ara, a sì gbé wọn kani lórí títí di àkókò tí a yàn kalẹ̀ láti mú àwọn nǹkan tọ́.” (Hébérù 9:10) Nígbà tí Òfin náà ti ṣamọ̀nà ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, tàbí Kristi, ó ti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nítorí èyí ni Pọ́ọ̀lù ṣe polongo pé: “Kristi ni òpin Òfin.”—Róòmù 10:4; Gálátíà 3:19-25; 4:4, 5.
2. Àwọn wo ló wà lábẹ́ Òfin náà, ìgbà wo la sì mú wọn kúrò lábẹ́ rẹ̀?
2 Èyí ha túmọ̀ sí pé Òfin náà kò lágbára lórí wá lónìí bí? Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé ni kò fìgbà kan wà lábẹ́ Òfin náà, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ṣe ṣàlàyé pé: “[Jèhófà] ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù, ó ń sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn; àti ní ti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀, wọn kò mọ̀ wọ́n.” (Sáàmù 147:19, 20) Kò pọndandan fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàápàá láti pa Òfin náà mọ́ nígbà tí Ọlọ́run ti fìdí májẹ̀mú tuntun náà múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù. (Gálátíà 3:13; Éfésù 2:15; Kólósè 2:13, 14, 16) Tó bá jẹ́ pé Òfin náà kò lágbára lórí wa mọ́, kí wá ni Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ sìn ín lónìí?
Ohun Tí Jèhófà Ń Béèrè
3, 4. (a) Kí ni ohun náà gan-an tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa lónìí? (b) Èé ṣe tí a fi ní láti tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí?
3 Ní ọdún tó kẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù tẹ̀ lé e lọ sí òkè ńlá gíga kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá kan tó yọ gọnbu lórí Òkè Hámónì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí ìran alásọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù nínú ògo ọlọ́lá ńlá, tí wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tó polongo pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mátíù 17:1-5) Láìsí àní-àní, ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa nìyẹn—ká fetí sí Ọmọ rẹ̀, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 16:24) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi kọ̀wé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.
4 Èé ṣe tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí? Ìdí ni pé bí a bá ń fara wé Jésù, Jèhófà Ọlọ́run là ń fara wé. Jésù mọ Baba rẹ̀ dáradára, àìmọye ọdún ló fi wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run kó tó wá sáyé. (Òwe 8:22-31; Jòhánù 8:23; 17:5; Kólósè 1:15-17) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi bí Baba rẹ̀ ṣe rí gan-an hàn. Ó ṣàlàyé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” Ní tòótọ́, Jésù fara wé Jèhófà gan-an débi tó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 8:28; 14:9.
5. Abẹ́ òfin wo làwọn Kristẹni wà, ìgbà wo sì ni òfin yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?
5 Kí ló wé mọ́ fífetí sí Jésù àti fífara wé e? Ṣé wíwà lábẹ́ Òfin ló túmọ̀ sí ni? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi fúnra mi kò sí lábẹ́ òfin.” Ohun tó ń tọ́ka sí níhìn-ín ni “májẹ̀mú láéláé,” ìyẹn ni májẹ̀mú Òfin táa bá Ísírẹ́lì dá. Pọ́ọ̀lù jẹ́wọ́ ní ti tòótọ́ pé òun wà “lábẹ́ òfin sí Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 9:20, 21; 2 Kọ́ríńtì 3:14) Bí májẹ̀mú Òfin ògbólógbòó ṣe ń lọ sí òpin ni “májẹ̀mú tuntun” bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú “Òfin Kristi” rẹ̀ tó pọndandan fún gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí láti ṣègbọ́ràn sí.—Lúùkù 22:20; Gálátíà 6:2; Hébérù 8:7-13.
6. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe “òfin Kristi,” báwo la sì ṣe ń ṣègbọràn sí i?
6 Jèhófà kò mú kí “òfin Kristi” di èyí tí a kọ sílẹ̀ bí àkójọ òfin kan, tí a ṣètò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, bíi ti májẹ̀mú Òfin ògbólógbòó. Òfin tuntun tó wà fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi yìí kò ní àkọsílẹ̀ tó pọ̀ lọ jàra, tó ń sọ pé ṣèyí má ṣèyẹn. Àmọ́ ṣá o, àkọsílẹ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbésí ayé àti àwọn ẹ̀kọ́ Ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà pa mọ́ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Láfikún sí i, Ọlọ́run tún mí sí àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ìjímìjí láti ṣàkọsílẹ̀ ìtọ́ni tó jẹ mọ́ ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, àwọn ọ̀ràn ìjọ, ìṣesí ẹnì kan láàárín ìdílé, àti àwọn ọ̀ràn mìíràn. (1 Kọ́ríńtì 6:18; 14:26-35; Éfésù 5:21-33; Hébérù 10:24, 25) Báa bá mú ìgbésí ayé wa bá àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù Kristi mu, tí a sì ń fi ìmọ̀ràn tí àwọn tí a mí sí, tó kọ Bíbélì ní ọ̀rúndún kìíní fún wa sílò, a jẹ́ pé à ń ṣègbọràn sí “òfin Kristi” nìyẹn. Ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí nìyí.
Ìjẹ́pàtàkì Ìfẹ́
7. Báwo ní Jésù ṣe tẹnu mọ́ ohun tó ṣe kókó nínú òfin rẹ̀ nígbà tó ṣe àṣekẹ́yìn ayẹyẹ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì lábẹ́ Òfin, ohun gan-an ni kókó tàbí lájorí òfin Kristi. Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tí òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pàdé láti ṣayẹyẹ Ìrékọjá ti ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe ṣàkópọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ìgbà méjìdínlọ́gbọ̀n ni Jésù mẹ́nu kan ìfẹ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wọni lọ́kàn tó bá wọn sọ. Èyí tẹ ìjẹ́pàtàkì òfin rẹ̀ àti ohun tó túmọ̀ sí gan-an mọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́kàn. Èyí tó tún gba àfiyèsí ni bí Jòhánù ṣe bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ mánigbàgbé yẹn, ó wí pé: “Nítorí ó mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ ìrékọjá náà pé wákàtí òun ti dé fún òun láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba, bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.”—Jòhánù 13:1.
8. (a) Kí ló fi hàn pé awuyewuye kan ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn àpọ́sítélì? (b) Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìwà ìrẹ̀lẹ̀?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti gbìyànjú láti ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n lè borí ìṣòro fífẹ́ láti dọ̀gá àti láti di ipò gíga mú, àmọ́ tí wọn ò gbọ́, síbẹ̀síbẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Láwọn oṣù díẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó dé sí Jerúsálẹ́mù, “wọ́n ti jiyàn láàárín ara wọn lórí ẹni tí ó tóbi jù.” Bó sì tún ṣe kù díẹ̀ kí wọ́n wọ ìlú náà láti wá ṣayẹyẹ Ìrékọjá, awuyewuye lórí ọ̀ràn ipò tún bẹ́ sílẹ̀. (Máàkù 9:33-37; 10:35-45) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní gẹ́rẹ́ tí àwọn àpọ́sítélì wọnú yàrá òkè láti jùmọ̀ ṣayẹyẹ tó yẹ kó jẹ́ àṣekẹ́yìn ayẹyẹ Ìrékọjá tí wọn ó ṣe pa pọ̀ fi hàn pé ìṣòro yìí ti wà nílẹ̀ tipẹ́. Lọ́jọ́ náà, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó fẹ́ wẹ ẹsẹ̀ àwọn tó kù gẹ́gẹ́ bí àṣa wọn láti fi hàn pé àwọn gba àlejò kan tọwọ́tẹsẹ̀. Kí Jésù lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀, òun fúnra rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ wọn.—Jòhánù 13:2-15; 1 Tímótì 5:9, 10.
9. Báwo ni Jésù ṣe yanjú ìṣòro tó dìde lẹ́yìn ayẹyẹ Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn?
9 Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn yìí, lẹ́yìn tí wọ́n ṣe Ìrékọjá tán tó tún dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ tó sún mọ́lé sílẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tó tún ṣẹlẹ̀ o. Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé: “Awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” Dípò kí Jésù bínú sí àwọn àpọ́sítélì tàbí kó nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀, ó fi pẹ̀lẹ́tù gbà wọ́n nímọ̀ràn nípa ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ ẹni tó lẹ́mìí tó yàtọ̀ pátápátá sáwọn alákòóso ayé, àwọn tí wọ́n ń wá agbára lójú méjèèjì. (Lúùkù 22:24-27) Ìgbà yẹn ló wá sọ ohun tí a lè pè ní ìpìlẹ̀ òfin Kristi fún wọn, ó ní: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—Jòhánù 13:34.
10. Àṣẹ wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí ló sì wé mọ́ ọn?
10 Nígbà tó ṣe díẹ̀, lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù ṣàlàyé ibi tó yẹ kí ìfẹ́ tó dà bíi ti Kristi nasẹ̀ dé. Ó sọ pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:12, 13) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ ṣe tán láti kú nítorí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bí ipò nǹkan bá mú kó rí bẹ́ẹ̀? Bí Jòhánù tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe lóye rẹ̀ sí nìyẹn, nítorí ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni àwa fi wá mọ ìfẹ́, nítorí ẹni yẹn [Jésù Kristi] fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa; a sì wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.”—1 Jòhánù 3:16.
11. (a) Báwo la ṣe mú òfin Kristi ṣẹ? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀?
11 Nítorí náà, kì í ṣe fífi àwọn ẹ̀kọ́ Kristi kọ́ àwọn ènìyàn nìkan la fi lè mú òfin Kristi ṣẹ. A gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbésí ayé bíi ti Jésù, kí a sì máa hùwà bíi tirẹ̀. Lóòótọ́, Jésù lo àwọn ọ̀rọ̀ dídùnmọ́ni tó sì jẹ́ àṣàyàn, nínú àwọn àwíyé rẹ̀. Síbẹ̀, ó tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó lágbára gan-an ni Jésù jẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ọ̀run, síbẹ̀ ó lo àǹfààní náà láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi bí a óò ṣe máa gbé ìgbésí ayé hàn wá. Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onínúure ni, ó ń gba tẹni rò, ó sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí a di ẹrù rù, tí a sì ni lára. (Mátíù 11:28-30; 20:28; Fílípì 2:5-8; 1 Jòhánù 3:8) Jésù tún rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, gẹ́gẹ́ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.
12. Èé ṣe táa fi lè sọ pé òfin Kristi kò dín nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà kù?
12 Ipò wo ni ìfẹ́ fún Jèhófà—àṣẹ tó tóbi jù lọ nínú Òfin—wà nínú òfin Kristi. (Mátíù 22:37, 38; Gálátíà 6:2) Ṣé ipò kejì ni? Rárá o! Ìfẹ́ fún Jèhófà àti ìfẹ́ fún Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa so pọ̀ mọ́ra típẹ́típẹ́ ni. Kò ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti nífẹ̀ẹ́ tòótọ́ sí Jèhófà láìjẹ́ pé ó nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, nítorí àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,’ síbẹ̀ tí ó kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni. Nítorí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.”—1 Jòhánù 4:20; Fi wé 1 Jòhánù 3:17, 18.
13. Ipa wo ni ìgbọràn àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí àṣẹ tuntun tí Jésù fi lélẹ̀ ní?
13 Nígbà tí Jésù ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àṣẹ tuntun náà láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí òun ti nífẹ̀ẹ́ wọn, ó ṣàpèjúwe ipa tí èyí yóò ní. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Tertullian, tó gbé ayé ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ikú Jésù sọ, ipa tí ìfẹ́ ará tó wà láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí ní gan-an nìyẹn. Tertullian sọ pé bí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ṣe ń sọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi nìyí, wọn á máa wí pé: ‘Wọ́n mà nífẹ̀ẹ́ ara wọn o, kódà wọn ò kọ̀ láti kú nítorí ara wọn.’ A lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi láti fẹ̀rí hàn pé mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?’
Báa Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Wa Hàn
14, 15. Kí ló lè jẹ́ kó ṣòro láti ṣègbọràn sí òfin Kristi, ṣùgbọ́n kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
14 Ó ṣe pàtàkì kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa fi ìfẹ́ bíi ti Kristi hàn. Àmọ́, ǹjẹ́ kì í ṣòro fún ọ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ tí wọ́n láwọn ìwà tó fi hàn pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀? Tóò, gẹ́gẹ́ báa ti rí i, àwọn àpọ́sítélì pàápàá ṣawuyewuye, wọ́n sì gbìyànjú láti gbé ohun tí ọkàn wọ́n fẹ́ lárugẹ. (Mátíù 20:20-24) Àwọn ará Gálátíà náà tutọ́ síra wọn lójú. Lẹ́yìn títọ́ka tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i pé ìfẹ́ aládùúgbò mú Òfin ṣẹ, ó kìlọ̀ fún wọn pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní bíbu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín ní àjẹrun, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín rẹ́ ráúráú lẹ́nì kìíní-kejì.” Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn iṣẹ́ ti ara àti èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run, ó fi ìṣínilétí náà kún un pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Lẹ́yìn ìyẹn, àpọ́sítélì náà tún rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.”—Gálátíà 5:14–6:2.
15 Jèhófà ha béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ wa nípa sísọ pé ká ṣègbọ́ràn sí òfin Kristi bí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro fún wa láti fi inúure hàn sí àwọn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ burúkú sí wa rí, tí wọ́n sì ti mú ọkàn wa gbọgbẹ́, síbẹ̀ dandan ni fún wa láti “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí [a] sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” (Éfésù 5:1, 2) Ó yẹ ká túbọ̀ máa wo àpẹẹrẹ Ọlọ́run, ẹni tó “dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Nípa lílo ìdánúṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, títí kan àwọn tó ti ṣàìdáa sí wa pàápàá, ọkàn wa yóò balẹ̀ pé a ń fara wé Ọlọ́run, a sì ń ṣègbọràn sí òfin Kristi.
16. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Kristi?
16 A gbọ́dọ̀ rántí pé ohun tí a ń ṣe ló ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ohun tí a kàn ń sọ lásán. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣòro fún Jésù láti fara mọ́ ohun kan tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run nítorí gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn. Jésù gbàdúrà pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi.” Àmọ́, kíá ló tún fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Pẹ̀lú gbogbo ìyà tí Jésù jẹ, ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Hébérù 5:7, 8) Ìgbọràn ló ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́, òun ló sì ń fi hàn pé a ka ọ̀nà Ọlọ́run sí èyí tó dára jù lọ. Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3) Jésù tún sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́.”—Jòhánù 14:15.
17. Àṣẹ pàtàkì wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, báwo la ṣe mọ̀ pé ó kàn wá lónìí?
17 Yàtọ̀ sí pípàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àṣẹ pàtàkì wo ni Kristi tún fún wọn? Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí òun ti kọ́ wọn. Pétérù sọ pé: “Ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Jésù pàṣẹ ní pàtó pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Jésù fi hàn pé irú ìtọ́ni yẹn yóò tún wà fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ báyìí ní “àkókò òpin,” nítorí ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Dáníẹ́lì 12:4; Mátíù 24:14) Dájúdájú, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká wàásù. Síbẹ̀, àwọn kan lè ronú pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní ká ṣe yìí ti pọ̀ jù. Ṣé ó pọ̀ jù lóòótọ́?
Ìdí Tó Fi Lè Dà Bí Ohun Tó Ṣòro
18. Kí ló yẹ ká máa rántí nígbà tí a bá ń jìyà fún ṣíṣe ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa?
18 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, jálẹ̀ ìtàn ènìyàn, onírúurú nǹkan ni Jèhófà ti béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. Bí àwọn ohun tí a béèrè lọ́wọ́ wọn ṣe yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àdánwò tí wọ́n dojú kọ ṣe yàtọ̀. Ọmọ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run ni ẹni tó rí àdánwò tó ṣòro jù lọ, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pa á nípa ìkà nítorí pé ó ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé kó ṣe. Àmọ́, nígbà táa bá ń jìyà nítorí pé a ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ká ṣe, a gbọ́dọ̀ rántí pé òun kọ́ ló mú àdánwò wá bá wa. (Jòhánù 15:18-20; Jákọ́bù 1:13-15) Ọ̀tẹ̀ Sátánì ló mú ẹ̀ṣẹ̀, ìyà, àti ikú wá, òun ló sì ń fa àwọn ipò tó sábà máa ń mú kó ṣòro gan-an fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe.—Jóòbù 1:6-19; 2:1-8.
19. Èé ṣe tó fi jẹ́ àǹfààní fún wa láti máa ṣe ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀?
19 Nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jèhófà ti pàṣẹ pé ní àkókò òpin yìí, àwọn ìránṣẹ́ Òun yóò polongo kárí ayé pé ìṣàkóso Ìjọba òun ni ojútùú kan ṣoṣo sí ìyà tó ń jẹ aráyé. Ìjọba Ọlọ́run yìí yóò mú gbogbo ìṣòro ayé kúrò—àwọn nǹkan bí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, ọjọ́ ogbó, àìsàn, ikú. Ìjọba náà yóò tún mú párádísè ológo wá sáyé, níbi tí a óò jí àwọn òkú pàápàá dìde sí. (Mátíù 6:9, 10; Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:3, 4) Àǹfààní ńlá ló mà jẹ́ o, láti polongo ìhìn rere irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀! Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa kò fa ìṣòro rárá. Lóòótọ́ là ń dojú kọ àtakò, àmọ́, Sátánì Èṣù àti ayé rẹ̀ ló ń fà á.
20. Báwo la ṣe lè kojú ìpèníjà èyíkéyìí tí Èṣù bá gbé dìde?
20 Báwo la ṣe wá lè ṣàṣeyọrí ní kíkojú ìpèníjà èyíkéyìí tí Sátánì bá mú wá? Nípa fífi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́kàn pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Jésù fún Jèhófà ní ìdáhùn sí ìṣáátá Sátánì nípa fífi ààbò tó wà lọ́run sílẹ̀ láti wá ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 53:12; Hébérù 10:7) Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, Jésù fara da gbogbo àdánwò tó dé bá a, títí kan ikú lórí igi ìdálóró pàápàá. Bí a bá tẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, àwa náà lè fara da ìyà kí a sì ṣe ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa.—Hébérù 12:1-3.
21. Kí lèrò rẹ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa?
21 Ìfẹ́ ńlá mà ni Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa yìí o! Nítorí ẹbọ Jésù, àwọn ènìyàn onígbọràn lè fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ohunkóhun láyè láti da òwúsúwusù bo ìrètí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí àwa fúnra wa máa fi ohun tí Jésù mú kó ṣeé ṣe sọ́kàn, bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe, ẹni tó sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gálátíà 2:20) Ǹjẹ́ kí a máa fi ìmoore àtọkànwá hàn sí Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, tí kò fìgbà kan rí béèrè ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ wa.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
◻ Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa lónìí?
◻ Báwo ni Kristi ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́ ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
◻ Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
◻ Èé ṣe tó fi jẹ́ àǹfààní fún wa láti máa ṣe ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi wíwẹ̀ tí ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọ́ni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Láìfi àtakò pè, kíkópa nínú kíkéde ìhìn rere náà jẹ́ àǹfààní tó dùn mọ́ni