‘Jèhófà, Dán Mi Wò’
“JÈHÓFÀ ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 17:3) Ńṣe ló yẹ kí gbólóhùn yìí máa fi gbogbo wá lọ́kàn balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Baba wa ọ̀run kì í fi ìrísí òde ara lásán dáni lẹ́jọ́ bíi tàwa èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń “wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Ká sòótọ́, kò sí báwa fúnra wa ṣe lè ṣàyẹ̀wò ara wa ká sì mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà lọ́kàn wa àtohun tó wà lódò ikùn wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” Ọlọ́run mọ̀ ọ́n, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín.” (Jeremáyà 17:9, 10) Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọ “ọkàn-àyà” àti ohun tó wà lódò ikùn wa, bákan náà ló mọ “kíndìnrín,” ìyẹn kúlẹ̀kúlẹ̀ èrò ọkàn wa.
Kí Nìdí Táwọn Kristẹni Fi Ní Láti Rí Ìdánwò?
Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé Dáfídì Ọba sọ fún Ọlọ́run láyé ìgbàanì pé: “Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò; yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.” (Sáàmù 26:2) Ṣé ìwà àti ìṣe Dáfídì mọ́ láìkù síbì kan ni, tí ò fi bẹ̀rù rárá láti sọ fún Jèhófà pé kó dán òun wò? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀! Aláìpé bíi tiwa lòun náà, kò sì sí bó ṣe lè tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run láìkù síbì kan. Torí pé òun náà níbi tó kù sí, ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì mélòó kan, àmọ́ ohun kan ni pé ó “rìn pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà.” (1 Àwọn Ọba 9:4) Báwo ló ṣe ṣe é? Ó máa ń gba ìbáwí, ó sì máa ń ṣàtúnṣe. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tinútinú. Kò sì jẹ́ kí ìfọkànsìn òun já létí.
Àwa tá à ń gbé lónìí wá ń kọ́ o? Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá àti pé a lè dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe. Àmọ́, kì í lo agbára tó ní láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́la láti fi wo gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bá a ṣe máa gbé ìgbésí ayé wa. Ó dá wa pẹ̀lú òmìnira láti pinnu ohun tó wù wá, ó sì máa ń ro ti òmìnira tá a ní yẹn mọ́ wa lára. Òmìnira náà jẹ́ àǹfààní tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí tóun fúnra rẹ̀ fi jíǹkí wa.
Síbẹ̀, ó ní bí Jèhófà ṣe máa ń dán wa wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kó bàa lè mọ irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún àti ohun tó ń mú ká ṣe àwọn nǹkan kan. Ó lè ṣe èyí nípa jíjẹ́ ká ṣe àwọn nǹkan tó máa fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Ó sì tún lè fàyè gba onírúurú ipò tàbí ìṣòro tó máa fi irú ẹni tá a jẹ́ nínú hàn. Èyí máa ń fún wa láǹfààní láti jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a fẹ́ sin òun tọkàntọkàn àti pé tiẹ̀ là ń ṣe lọ́jọ́kọ́jọ́. Irú àwọn àdánwò tí Jèhófà bá gbà láyè bẹ́ẹ̀ lè fi bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó hàn, ó sì máa mú kó hàn bóyá lóòótọ́ ni ìfọkànsìn wa “pé pérépéré,” tá a “sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.”—Jákọ́bù 1:2-4.
Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Kan Tó Wáyé Nígbà Láéláé
Dídán ìgbàgbọ́ àtohun tó wà lọ́kàn ẹni wò kì í ṣe ohun tuntun fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Wàá rántí Ábúráhámù baba ńlá. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:1) Lásìkò tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ yẹn, ó ti dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò kọjá. Lọ́pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yẹn, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kóun àti ìdílé rẹ̀ ṣí kúrò ní Úrì, ìlú tí nǹkan ti ń ṣẹnuure fún wọn, kí wọ́n sì forí lé ilẹ̀ kan tí wọn ò mọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31; Ìṣe 7:2-4) Ilẹ̀ Kénáánì ni Jèhófà ní kó ṣí lọ. Ní gbogbo nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ábúráhámù sì fi gbébẹ̀, kò dá ilé ara rẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé òun fúnra rẹ̀ ló ni ilé tó ń gbé ní Úrì tẹ́lẹ̀. (Hébérù 11:9) Inú ewu ńláǹlà ni Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ wà bí wọ́n ṣe ń ṣí kiri. Ewu kí ìyàn má pa wọ́n, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, àti ewu lọ́wọ́ àwọn kèfèrí olùṣàkóso tí wọ́n wà ládùúgbò náà. Ní gbogbo àkókò tí Ábúráhámù fi ń ṣí kiri yìí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ ń lágbára sí i.
Nígbà tó yá, Jèhófà gbé ìdánwò tó jùyẹn lọ síwájú Ábúráhámù. Ó ní: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì . . . fi í rúbọ . . . gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Ọmọlójú Ábúráhámù ni Ísákì jẹ́. Òun lọmọ kan ṣoṣo tí Sárà bí fún Ábúráhámù. Ọmọ ìlérí ni Ísákì, òun ni ìrètí kan ṣoṣo tí Ábúráhámù ní pé “irú ọmọ” òun ni yóò jogún ilẹ̀ Kénáánì tí yóò sì di ìbùkún fún ọ̀pọ̀ èèyàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí. Ó ṣe tán, Ísákì ni ọmọ náà tí Ábúráhámù ti ń retí àtibí, tí Ọlọ́run sì jẹ́ kó bí i nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu!—Jẹ́nẹ́sísì 15:2-4, 7.
O lè wá rí i pé Ábúráhámù lè má tètè mọ ìdí tí Ọlọ́run fi ní láti pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀. Ṣé pé Jèhófà lè sọ pé kí wọ́n fèèyàn rúbọ sóun? Kí nìdí tí Jèhófà á fi kọ́kọ́ múnú Ábúráhámù dùn nípa mímú kóun náà tipasẹ̀ Sárà rọ́mọ gbé jó lọ́jọ́ ogbó wọn, kó tún wá sọ pé kó fi ọmọ kan ṣoṣo ọ̀hún rúbọ?a
Pẹ̀lú bí Ábúráhámù ò ṣe tíì mọ̀dí tí Jèhófà fi sọ pé kó fọmọ ẹ̀ rúbọ yìí, ojú ẹsẹ̀ ló ṣègbọràn. Ọjọ́ mẹ́tà gbáko ló gbà á láti dé orí òkè tí Ọlọ́run ti ní kó ṣe ìrúbọ náà. Nígbà tó débẹ̀, ó mọ pẹpẹ, ó sì kó igi ìdáná sí i lórí. Ẹ̀yin ìyẹn ló wá kan ìdánwò tó ju ìdánwò lọ. Ábúráhámù mú ọ̀bẹ tó fi máa dúńbú Ísákì, àmọ́ bó ṣe kù díẹ̀ kó pa ọmọ ẹ̀, Jèhófà tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan sọ pé kó dáwọ́ dúró, ó wá sọ fún un pé: “Nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:3, 11, 12) Gbólóhùn tí Ábúráhámù gbọ́ yìí á mà múnú rẹ̀ dùn gan-an ni o! Bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́ lórí, pé ẹni ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5, 6) Dípò Ísákì, àgbò tí Jèhófà pèsè ni Ábúráhámù fi rúbọ. Jèhófà wá fìdí májẹ̀mú ìlérí tó ṣe nípa irú ọmọ Ábúráhámù múlẹ̀. A wá lè rí ìdí tí Bíbélì fi pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Jèhófà.—Jẹ́nẹ́sísì 22:13-18; Jákọ́bù 2:21-23.
Àwa Náà Ń Rí Ìdánwò Ìgbàgbọ́
Ó yé gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní pé àwa náà máa rí ìdánwò. Nínú ọ̀ràn tiwa, dípò kí irú ìdánwò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí Jèhófà máa ní ká ṣe, èyí tó pọ̀ lára àwọn ìdánwò náà lè jẹ́ ohun tí Jèhófà yọ̀ǹda pé kó ṣẹlẹ̀ sí wa.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ lè wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ wà nílé ẹ̀kọ́, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn aládùúgbò tàbí látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ tí wọ́n gba ẹ̀sùn táwọn èèyàn fi kàn wá gbọ́ láìwádìí. Wọ́n lè máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lù wá, wọ́n sì lè mú ilé ayé le fún wa láwọn ọ̀nà míì. Bákan náà, àwọn ìṣòro tó ń bá aráyé fínra ń kan àwọn Kristẹni tòótọ́ náà, ìyẹn àwọn ìṣòro bí àìsàn, ìjákulẹ̀ àti ìrẹ́jẹ. Gbogbo àwọn ìṣòro yìí ló máa ń dán ìgbàgbọ́ ẹni wò.
Àpọ́sítélì Pétérù rán wa létí àǹfààní tó wà nínú kí àwọn nǹkan kan dán ìgbàgbọ́ ẹni wò, ó ní: “A ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín, kí ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín tí a ti dán wò, tí ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dán an wò sí, lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pétérù 1:6, 7) Bó ṣe rí nìyẹn o, ṣe ni àdánwò dà bí iná tí wọ́n fi ń yọ́ góòlù. Fífi tí wọ́n bá fi iná yọ́ ọ ló máa ń jẹ́ kí ojúlówó góòlù fara hàn, tí wọ́n á sì yọ ìdọ̀tí sọ́tọ̀. Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ìgbàgbọ́ wa nígbà tá a bá rí àdánwò.
Bí àpẹẹrẹ, ìjàǹbá tàbí àjálù kanlè kó ìṣòro bá wa. Síbẹ̀, àwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ kì í gba àníyàn láyè. Ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jèhófà sọ ni wọ́n fi máa ń tu ara wọn nínú, èyí tó sọ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Ńṣe ni wọ́n máa ń bá a lọ láti máa fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, torí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà Ọlọ́run á ran àwọn lọ́wọ́ láti rí ohun táwọn ṣaláìní. Ìgbàgbọ́ wọn ló máa ń gbé wọn ró lákòókò ìṣòro, kì í sì í jẹ́ kí wọ́n dá kún ìṣòro ọ̀hún nípa ṣíṣàníyàn láìnídìí.
Àdánwò tún lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ wa lágbára tàbí kò lágbára, àǹfààní mìíràn sì nìyẹn jẹ́ bá a bá lè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ṣàtúnṣe. Ó yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára? Ǹjẹ́ kó yẹ kí n máa lo àkókò púpọ̀ sí i láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí n sì máa ṣàṣàrò lé e lórí? Ǹjẹ́ mo máa ń lo àǹfààní tí mo ní láti bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé jọ sí ìpàdé? Ṣé n kì í gbọ́kàn lé ara mi nígbà tó yẹ kí n sọ gbogbo ohun tó jẹ́ àníyàn ọkàn mi fún Jèhófà Ọlọ́run nínú àdúrà?’ Ìbẹ̀rẹ̀ lásán nirú àyẹ̀wò ara ẹni bí ìyẹn jẹ́ ṣá o.
Béèyàn bá máa mú kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára, àfi kó túbọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kó máa “ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ tí ọ̀rọ̀ náà.” (1 Pétérù 2:2; Hébérù 5:12-14) A gbọ́dọ̀ sapá láti dà bí ọkùnrin tí onísáàmù sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.”—Sáàmù 1:2.
Èyí ju ká wulẹ̀ máa ka Bíbélì lọ o. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ronú lórí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá sọ pé ká ṣe, ká sì máa fàwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò. (Jákọ́bù 1:22-25) Àwọn nǹkan yìí ló máa mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i, kí àdúrà wa túbọ̀ máa ṣe pàtó, ká máa tú ọkàn wa jáde fún Ọlọ́run, kí ìgbàgbọ́ wa sì máa lágbára sí i.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Rí Ìdánwò Ìgbàgbọ́
Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lára ohun tá a gbọ́dọ̀ ní láti lè rí ojú rere Ọlọ́run, ó yẹ kí ìyẹn sún wa láti máa wá bí ìgbàgbọ́ wa ṣe máa lágbára sí i. Bíbélì rán wa létí pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Nítorí náà, ṣe ló yẹ kó máa ṣe wá bíi ti ọkùnrin tó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jésù pé: “Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”—Máàkù 9:24.
Ìdánwò ìgbàgbọ́ tó bá wa tún lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí èèyàn Kristẹni kan bá kú, ìgbàgbọ́ lílágbára tó ní nínú ìrètí àjíǹde tí Ọlọ́run ṣèlérí ló máa gbé e ró. Kì í ṣe pé kò ní ṣọ̀fọ̀ o, àmọ́ kò ní “kárísọ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹ̀lú.” (1 Tẹsalóníkà 4:13, 14) Àwọn tó bá sì ń rí bí ìgbàgbọ́ tí Kristẹni náà ní ṣe gbé e ró lè wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé ohun tó ṣeyebíye gan-an ni ìgbàgbọ́ tó ní. Èyí sì lè mú káwọn náà fẹ́ nírú ìgbàgbọ́ yẹn, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á dẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n á sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.
Jèhófà mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tó bá ti la ìdánwò kọjá níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀. Láfikún sí i, ìdánwò ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ ká lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni ìgbàgbọ́ wa lágbára tó láti gbé wa ró. Ó máa ń jẹ́ ká lè mọ̀ bí ìgbàgbọ́ wa ò bá lágbára tó, ó sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣàtúnṣe. Lákòótán, bá a bá yege ìdánwò ìgbàgbọ́, ó lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti dọmọ ẹ̀yìn Jésù. Nítorí náà, ǹjẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí i pé ìgbàgbọ́ wa ò yingin, dípò ìyẹn, ńṣe ni kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí ìgbàgbọ́ wa bá ti la onírúurú ìdánwò kọjá, kó jẹ́ “èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.”—1 Pétérù 1:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti lè mọ ohun tí fífi Ísákì “rúbọ” túmọ̀ sí, wo Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1989, ojú ìwé 22.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Iṣẹ́ tí Ábúráhámù fi kún ìgbàgbọ́ rẹ̀ ló sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìdánwò ìgbàgbọ́ lè fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa lágbára láti gbé wa ró
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Látinú Bíbélì Illustrated Edition of the Holy Scriptures tí Cassell, Petter, àti Galpin ṣe