‘Ẹ Wà Lójúfò’
‘Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Kí ẹ wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.’—1 PÉT. 4:7.
1. Orí kí ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé?
NÍGBÀ tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, orí Ìjọba Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ dá lé. Ìjọba yẹn ni Jèhófà yóò lò láti fi hàn pé òun lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, Ìjọba yẹn ni yóò sì lò láti fi sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 4:17; 6:9, 10) Ìjọba yẹn yóò fòpin sí ayé Sátánì yìí láìpẹ́ yóò sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe jákèjádò ayé. Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba [òde òní] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dán. 2:44.
2. (a) Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe máa mọ̀ pé ó ti wà níhìn-ín àti pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso? (b) Ohun mìíràn wo ni àmì náà á tún jẹ́ ká mọ̀?
2 Nítorí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ka dídé Ìjọba Ọlọ́run sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, wọ́n bi Jésù pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3) Kristi fún wọn ní àmì tí wọ́n máa lè rí nítorí pé àwọn èèyàn tó wà ní ayé kò ní lè fojú rí Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ ló para pọ̀ jẹ́ àmì yẹn. Torí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó bá wà láyé nígbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn bá ń ṣẹlẹ̀ yóò fòye mọ̀ pé Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Àmì yẹn tún jẹ́ ohun tá a fi máa mọ ìbẹ̀rẹ̀ àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú tó ń darí ayé nísinsìnyí.—2 Tím. 3:1-5, 13; Mát. 24:7-14.
Ẹ Wà Lójúfò Láwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí
3. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni wà lójúfò?
3 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.” (1 Pét. 4:7) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti wà lójúfò, kí wọ́n máa kíyè sí àwọn ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ láyé, èyí tó máa fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín, àti pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Bí òpin ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí yìí sì ti ń sún mọ́lé, wọ́n yóò ní láti túbọ̀ wà lójúfò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀ [láti wá dá ayé Sátánì lẹ́jọ́].”—Máàkù 13:35, 36.
4. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì àti àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. (Fi àlàyé inú àpótí kún un.)
4 Àwọn èèyàn ayé wà lábẹ́ ìdarí Sátánì, wọn kò sì kíyè sí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé kí wọ́n lè mọ ìtumọ̀ wọn. Wọn kò fòye mọ̀ pé Kristi ti wà níhìn-ín, àti pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Àmọ́ lóde òní, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ wà lójúfò, wọ́n sì fòye mọ ìtumọ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí. Láti ọdún 1925 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ pé Ogun Àgbáyé Kìíní àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó tẹ̀ lé e jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914. Èyí fi hàn pé ètò àwọn nǹkan búburú tó wà níkàáwọ́ Sátánì yìí ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀. Àwọn èèyàn tó lákìíyèsí rí i pé ìyàtọ̀ tó kàmàmà ló wà láàárín bí ayé ṣe rí ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní àti bó ṣe wá rí látìgbà yẹn títí di báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ ohun tí ìyàtọ̀ yẹn túmọ̀ sí.—Wo àpótí náà, “Sànmánì Yánpọnyánrin Bẹ̀rẹ̀.”
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò?
5 Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jáì, tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé ti ń fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà yóò fi pàṣẹ fún Kristi pé kó ṣáájú àwọn áńgẹ́lì alágbára láti lọ bá ayé Sátánì jà. (Ìṣí. 19:11-21) Jésù sọ pé kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ṣọ́nà. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣọ́nà lójú méjèèjì bá a ti ń retí òpin ètò nǹkan yìí. (Mát. 24:42) A gbọ́dọ̀ wà lójúfò, àti pé iṣẹ́ pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe kárí ayé bí Kristi ti ń darí wa.
Iṣẹ́ Kan Tó Kárí Ayé
6, 7. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú tó láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?
6 Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù fi hàn pé iṣẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ṣe jẹ́ ara àmì tá a máa fi mọ̀ pé a ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Jésù mẹ́nu kan iṣẹ́ tó máa kárí ayé yìí nígbà tó ń sọ àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lákòókò òpin. Ó sọ gbólóhùn tó nítumọ̀ gidi yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.
7 Ìwọ wo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn ṣe ń ṣẹ. Iye àwọn èèyàn tó ń polongo ìhìn rere náà kéré gan-an nígbà táwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Nísinsìnyí iye wa ti pọ̀ gan-an. Ó ti lé ní mílíọ̀nù méje [7,000,000] àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wàásù kárí ayé. Iye ìjọ wa sì lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Mílíọ̀nù mẹ́wàá [10,000,000] èèyàn míì ló wá bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé jọ lọ́dún 2008 nígbà tá a ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Iye yẹn sì pọ̀ gan-an ju iye àwọn tó wá lọ́dún 2007 lọ.
8. Kí nìdí tí àtakò kò fi lè dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró ká má lè ṣe é láṣeyọrí?
8 Ẹ ò ri pé a ti fi iṣẹ́ ìwàásù yìí jẹ́ ẹ̀rí tó rinlẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin ètò nǹkan yìí tó dé! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ojú Sátánì, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” la ti ń ṣe gbogbo èyí. (2 Kọ́r. 4:4) Òun ló ń darí gbogbo ètò ìṣèlú, ìsìn, àti ìṣòwò ayé yìí títí kan gbogbo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìsọfúnni jáde. Kí ló wá ń jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà láṣeyọrí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀? Àtìlẹ́yìn Jèhófà ni. Ìyẹn ló ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù náà máa tẹ̀ síwájú lọ́nà àgbàyanu lójú gbogbo ìsapá Sátánì láti dá a dúró.
9. Kí nìdí tá a fi lè pe àṣeyọrí tá à ń ṣe nínú ìjọsìn wa ní iṣẹ́ ìyanu?
9 Àṣeyọrí tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, pípọ̀ tá à ń pọ̀ sí i àti ìmọ̀ tá a ní nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé jẹ́ iṣẹ́ ìyanu. Láìsí àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, títí kan ìtọ́sọ́nà rẹ̀ àti ààbò rẹ̀ lórí àwa èèyàn rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù náà ì bá má ṣeé ṣe rárá. (Ka Mátíù 19:26.) Ó dá wa lójú pé bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́kàn àwọn èèyàn tó wà lójúfò tí wọ́n múra tán láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, a ó ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí títí dé ìparí, “nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àkókò tí èyí sì máa ṣẹlẹ̀ ti dé tán.
“Ìpọ́njú Ńlá”
10. Kí ni Jésù sọ nípa ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀?
10 Ètò nǹkan búburú yìí yóò dópin nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣí. 7: 14) Bíbélì kò sọ fún wa bí ìgbà ìpọ́njú ńlá náà yóò ṣe gùn tó, àmọ́ Jésù sọ pé: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mát. 24:21) Tá a bá wo ti ìpọ́njú tó ti bá ayé yìí, irú bíi tìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tí nǹkan bí àádọ́ta sí ọgọ́ta mílíọ̀nù ẹ̀mí ti ṣòfò, a ó rí i pé ìpọ́njú ńlá ni ìpọ́njú tó ń bọ̀ yóò jẹ́ lóòótọ́. Ìgbà ogun Amágẹ́dọ́nì ni ìpọ́njú ńlá yìí yóò dé ògógóró rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Jèhófà yóò tú agbo ọmọ ogun rẹ̀ sílẹ̀ láti pa gbogbo ìyókù ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé run.—Ìṣí. 16:14, 16.
11, 12. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló máa fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀?
11 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kò sọ ọjọ́ tí apá àkọ́kọ́ nínú ìpọ́njú ńlá náà máa bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó sọ ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tí yóò fi hàn pé ó ti bẹ̀rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó sọ pé ó máa bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni pé àwọn orílẹ̀-èdè alágbára yóò pa gbogbo ẹ̀sìn èké run. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn ní Ìṣípayá orí 17 àti 18, fi ìsìn èké wé aṣẹ́wó kan tí àwọn ìjọba ayé ń bá ṣe ìṣekúṣe. Ìṣípayá 17:16 fi hàn pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àkókò tí àwọn ìjọba ayé yìí “yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.”
12 Nígbà tó bá tó àkókò tí ìyẹn máa ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run yóò “fi í sínú ọkàn-àyà [àwọn aláṣẹ ìṣèlú] láti mú ìrònú òun ṣẹ” pé kí wọ́n pa gbogbo ìsìn èké run. (Ìṣí. 17:17) Nítorí náà, a lè sọ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìparun náà ti wá. Ó jẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn ìsìn alágàbàgebè tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Aráyé lápapọ̀ kò rí i pé ìparun ń bọ̀ wá bá ìsìn èké láìpẹ́. Àmọ́ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé ó ń bọ̀. Wọ́n sì ti ń sọ ọ́ fún gbogbo èèyàn látìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí títí di ìsinsìnyí.
13. Kí ló fi hàn pé ìparun ìsìn èké yóò yára kánkán?
13 Ìyàlẹ́nu gbáà ló máa jẹ́ fáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá rí i tí ìsìn èké pa run. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àní àwọn kan lára “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” yóò tiẹ̀ máa sọ nípa ìparun rẹ̀ pé: “Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, . . . nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!” (Ìṣí. 18:9, 10, 16, 19) Lílò tí Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “wákàtí kan” fi hàn pé ìparun rẹ̀ yìí yóò yára kánkán.
14. Nígbà táwọn ọ̀tá Jèhófà bá gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí ni Jèhófà yóò ṣe?
14 A mọ̀ pé ní àkókò kan lẹ́yìn tí ìsìn èké bá ti pa run, Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ yóò gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run. (Ìsík. 38:14-16) Nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, wọ́n á rí i pé ńṣe làwọn ń tọ́jà Jèhófà, ẹni tó ṣèlérí pé òun á dáàbò bo àwọn èèyàn òun olóòótọ́. Jèhófà sọ pé: “Nínú ìgbóná-ọkàn mi, ní iná ìbínú kíkan mi, ni èmi yóò sọ̀rọ̀. . . . Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:18-23.) Ọlọ́run sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín [ìyẹn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́] ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:8) Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọ̀tá bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kárí ayé, Jèhófà kò ní máa wò wọ́n níran. Yóò dìde sáwọn ọ̀tá náà, ìyẹn ló sì máa fa apá tó kẹ́yìn tó sì le jù nínú ìpọ́njú ńlá náà, ìyẹn Amágẹ́dọ́nì. Ìgbà yẹn ni Kristi yóò kó àwọn áńgẹ́lì alágbára wá láti mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí ayé Sátánì.
Ipa Tó Yẹ Kó Ní Lórí Wa
15. Ipa wo ló yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé òpin ètò búburú yìí ti dé tán ní lórí wa?
15 Ipa wo ló yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé òpin ètò búburú yìí ti dé tán ní lórí wa? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!” (2 Pét. 3:11) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká kíyè sára gidigidi, ká máa rí i pé ìwà wa ń bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu àti pé à ń ṣe iṣẹ́ ìfọkànsìn Ọlọ́run, èyí táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ara irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa sa gbogbo ipá wa láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí òpin tó dé. Pétérù tún sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. . . . Kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.” (1 Pét. 4:7) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo, tá à ń bẹ̀ ẹ́ pé kó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ tó kárí ayé tọ́ wa sọ́nà, àá lè túbọ̀ sún mọ́ ọn yóò sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká rí i dájú pé à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run?
16 Ní àkókò eléwu tá a wà yìí, a ní láti rí i dájú pé à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfé. 5:15, 16) Ìwà burúkú wá pọ̀ lápọ̀jù lákòókò tiwa yìí. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Sátánì ti gbé kalẹ̀ torí káwọn èèyàn má lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà tàbí láti lè máa fi fa ìpínyà ọkàn fún wọn. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ èyí, kò sì ní dára pé ká gbà kí ohunkóhun mú wa yẹsẹ̀ nínú ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run. A tún mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe.—Ka 1 Jòhánù 2:15-17.
17. Nígbà táwọn òkú bá ń jíǹde, báwo ló ṣe máa rí lára àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já?
17 Ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò jí àwọn òkú dìde sí ìyè yóò ṣẹ, nítorí pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Kíyè sí bí Bíbélì ṣe sọ ọ̀rọ̀ yẹn pẹ̀lú ìdánilójú, ó ní: ‘Àjíǹde yóò wà’! Kò sí iyèméjì rárá nípa rẹ̀, Jèhófà ti ṣe ìlérí yẹn ná! Aísáyà 26:19 ṣèlérí pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! . . . Ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ, bó ṣe ṣẹ ni pé Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà wá sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Èyí sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó ń bọ̀ wá ní ìmúṣẹ bí Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́, nínú ayé tuntun. Ẹ wo bí ayọ̀ náà ṣe máa pọ̀ tó nígbà táwọn òkú bá ń jíǹde tí wọ́n sì ń pa dà wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wọn! Dájúdájú, òpin ayé Sátánì yìí ti sún mọ́lé, ayé tuntun Ọlọ́run sì ti dé tán. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wà lójúfò!
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Orí kí ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé?
• Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ti gbilẹ̀ tó nísinsìnyí?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò?
• Ìṣírí wo lo rí nínú ìlérí tó wà nínú Ìṣe 24:15?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
SÀNMÁNÌ YÁNPỌNYÁNRIN BẸ̀RẸ̀
Ọ̀gbẹ́ni Alan Greenspan kọ ìwé kan lọ́dún 2007 tó sọ̀rọ̀ nípa bí ayé ṣe bọ́ sínú sànmánì yánpọnyánrin. Ọ̀gbẹ́ni yìí fi bí ogún ọdún jẹ́ alága àjọ tó ń bójú tó ọ̀ràn àwọn ilé ìfowópamọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó sọ ìyàtọ̀ ńlá tó wà láàárín bí ayé ṣe rí ṣáájú ọdún 1914 àti bó ṣe rí lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ní:
“Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìròyìn tá a gbọ́, ṣáájú ọdún 1914, ó jọ pé aráyé ti ń kúrò nínú sànmánì ojú dúdú, àti pé wọ́n túbọ̀ ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn síwájú sí i, ìtẹ̀síwájú sì ń bá àṣà ìbílẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó tún jọ pé àjọṣe láàárín àwọn èèyàn dára gan-an débi pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ipò pípé. Ọ̀rúndún kọkàndínlógún yìí sì ni wọ́n fòpin sí òwò ẹrú tó burú jáì. Ó jọ pé ìwà ìkà tó burú jáì ń kásẹ̀ nílẹ̀ láàárín aráyé. . . . Onírúurú ìtẹ̀síwájú ń bá ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe àwọn ẹ̀rọ kárí ayé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan bí ọ̀nà rélùwéè, tẹlifóònù, iná mànàmáná, sinimá, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àti àìlóǹkà ohun èlò inú ilé tó ń máyé dẹrùn. Ìmọ̀ ìṣègùn, ètò oúnjẹ tó dára, àti omi tó dára sì ń mú kí ẹ̀mí àwọn èèyàn máa gùn sí i . . . Gbogbo aráyé ló ń rò pé ìtẹ̀síwájú náà yóò sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.”
Àmọ́ . . . “Àkóbá tí Ogún Àgbáyé Kìíní ṣe fún ọ̀wọ̀, ìtẹ̀síwájú sí rere nínú àṣà ìbílẹ̀ àti nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ayé burú ju ìparun tí Ogún Àgbáyé Kejì ṣe lọ: ogun àkọ́kọ́ yẹn ló ba ẹ̀mí rere tọ́mọ aráyé ní láàárín ara wọn jẹ́. Mi ò lè gbàgbé àwọn ọdún tó ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní nígbà tí ìtẹ̀síwájú ọmọ aráyé túbọ̀ ń yára kánkán, tó sì jọ pé ńṣe ni ayé yìí yóò máa dára sí i. Àmọ́ ní báyìí, èrò tàwa èèyàn òde òní ti yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn èèyàn tó gbé ayé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Lójú tiwa, ńṣe ni ayé yìí á máa bà jẹ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ó sì dà bíi pé ipò ayé yìí ò lè dáa mọ́ lóòótọ́. Ǹjẹ́ kì í ṣe irú àkóbá tí Ogun Àgbáyé Kìíní ṣe fún ayé nígbà yẹn lọ́hùn-ún náà ni ìkópayàbáni, gbígbóná tí ilé ayé ń gbóná, pípọ̀ tí ẹgbẹ́ àwọn ajàjàgbara ń pọ̀ sí i, máa ṣe fún ayé ọ̀làjú wa yìí? Kò sẹ́ni tó mọ̀ o.”
Ọ̀gbẹ́ni Greenspan rántí pé nígbà tóun wà nílé ẹ̀kọ́ Yunifásítì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin M. Anderson, tó gbé ayé lọ́dún 1886 sí 1949, tó sì jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣúnná owó, sọ ọ̀rọ̀ kan pé: “Àwọn tí wọ́n ti tójúúbọ́ ṣáájú ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, tí wọ́n sì lè rántí bí ayé ṣe rí ṣáájú ogun náà, sábà máa ń sọ bí ayé ìgbà yẹn ṣe dára tó. Láyé ìgbà yẹn, àwọn èèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀, èyí tí kò sì mọ́ látìgbà ogun náà títí di ìsinsìnyí.”—Economics and the Public Welfare.
Ohun kan náà ló wà nínú ìwé kan tí Ọ̀gbẹni G. J. Meyer ṣe jáde ní ọdún 2006. A rí i kà níbẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé àwọn ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ti ‘yí ohun gbogbo pa dà.’ Àmọ́ Ogun Ńlá tó wáyé lọ́dún 1914 sí 1918 yìí gan-an ni ọ̀rọ̀ yìí bá mu. Ohun gbogbo ni ogun náà sì ti yí pa dà lóòótọ́: kì í ṣe ààlà ibodè, ìjọba àti ọjọ́ iwájú àwọn orílẹ̀-èdè nìkan logun náà yí pa dà, àní ó tiẹ̀ ti yí ojú táwọn èèyàn fi ń wo ayé yìí àti ara àwọn fúnra wọn pa dà látìgbà yẹn. Ó wá sọ ayé ìsinsìnyí dèyí tó yàtọ̀ pátápátá sí ayé aláàbò tó ti wà ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní.”—A World Undone.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà yóò tú agbo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára sílẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì