“Ìyèkooro Èrò Inú” Bí Òpin Ti Ń sún Mọ́lé
“Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú.”—PÉTÉRÙ KÍNÍ 4:7.
1. Kí ni ‘yíyè kooro ní èrò inú’ ní nínú?
Ó YẸ kí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù tí ó wà lókè yí ní ipa lílágbára lórí ọ̀nà tí àwọn Kristẹni ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn. Ṣùgbọ́n, Pétérù kò sọ fún àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti jáwọ́ nínú àwọn àìgbọ́dọ̀máṣe tí ó jẹ́ ti ayé àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fún ẹ̀mí ìbẹ̀rù bojo lórí ìparun tí ó ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ níṣìírí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rọni pé: “Ẹ yè kooro ní èrò inú.” Láti “yè kooro ní èrò inú” ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe ìpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu, jíjẹ́ onílàákàyè, olóye, kí a jẹ́ ẹni tí ń ronú lórí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Ó túmọ̀ sí jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣàkóso ìrònú àti ìgbésẹ̀ wa. (Róòmù 12:2) Níwọ̀n bí a ti ń gbé “ní àárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó,” ìyèkooro èrò inú ṣe pàtàkì láti yẹra fún àwọn ìṣòro àti ìnira.—Fílípì 2:15.
2. Báwo ni sùúrù Jèhófà ṣe ṣàǹfààní fún àwọn Kristẹni lónìí?
2 “Ìyèkooro èrò inú” tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara balẹ̀ yẹ ara wa wò fínnífínní, kí a sì mọ bí a ti rí gan-an. (Títù 2:12; Róòmù 12:3) Èyí ṣe kókó lójú ìwòye ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Pétérù Kejì 3:9 pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” Kíyè sí i pé Jèhófà ń mú sùúrù, kì í ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n “fún yín” pẹ̀lú—àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni. Èé ṣe? Nítorí “òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run.” Ó lè jẹ́ pé ó ṣì ṣe pàtàkì fún àwọn kan láti ṣe ìyípadà àti àtúnṣe, kí wọ́n baà lè tóótun fún ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí èyí, ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ibi tí ó ti ṣeé ṣe kí a nílò àtúnṣe.
“Ìyèkooro Èrò Inú” Nínú Ìbátan Ara Ẹni Wa
3. Àwọn ìbéèrè wo ni àwọn òbí lè bi ara wọn nípa àwọn ọmọ wọn?
3 Ó yẹ kí agboolé jẹ́ ibi tí ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún àwọn kan, ó máa ń jẹ́ “ilé tí ó kún fún . . . ìjà.” (Òwe 17:1) Ìdílé tìrẹ ńkọ́? Agboolé rẹ ha bọ́ lọ́wọ́ “ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” bí? (Éfésù 4:31) Àwọn ọmọ rẹ ńkọ́? Wọ́n ha ń nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, pé a sì mọrírì wọn bí? (Fi wé Lúùkù 3:22.) Ìwọ ha ń wá àyè láti tọ́ wọn sọ́nà àti láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ bí? Ìwọ ha ‘ń bá wọn wí nínú òdodo,’ dípò fífi ìrunú àti ìbínú bá wọn wí bí? (Tímótì Kejì 3:16) Níwọ̀n bí àwọn ọmọ ti jẹ́ “ìní Olúwa,” òun lọ́kàn ìfẹ́ gidigidi sí bí a ti ń bá wọn lò.—Orin Dáfídì 127:3.
4. (a) Kí ní lè yọrí sí bí ọkọ kan bá bá aya rẹ̀ lò lọ́nà rírorò? (b) Báwo ni àwọn aya ṣe lè gbé àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti ayọ̀ nínú agbo ìdílé náà lódindi lárugẹ?
4 Ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó ńkọ́? “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ẹran ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n òun a máa bọ́ ọ a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.” (Éfésù 5:28, 29) Kì í ṣe pé ọkùnrin kan tí ó jẹ́ òǹrorò, ajẹgàba léni lórí, tàbí ẹni tí kì í fòye báni lò ń fi títòrò agbo ilé rẹ̀ wewu nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń jin ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́sẹ̀. (Pétérù Kíní 3:7) Àwọn aya ńkọ́? Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ “wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bíi fún Olúwa.” (Éfésù 5:22) Ríronú nípa wíwu Ọlọ́run lè ran aya kan lọ́wọ́ láti gbójú fo àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó ọkọ rẹ̀, kí ó sì tẹrí ba fún un láìbínú. Nígbà míràn, ó lè pọn dandan fún aya kan láti sọ èrò rẹ̀ jáde. Òwe 31:26 sọ nípa aya tí ó dáńgájíá pé: “Ó fi ọgbọ́n ya ẹnu rẹ̀; àti ní ahọ́n rẹ̀ ni òfin ìṣeun.” Nípa fífi inú rere bá ọkọ rẹ̀ lò, àti bíbọ̀wọ̀ fún un, òun ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ayọ̀ ìdílé lódindi lárugẹ.—Òwe 14:1.
5. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn èwe tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì nípa ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n gbà bá àwọn òbí wọn lò?
5 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, báwo ni ẹ ṣe ń bá àwọn òbí yín lò? Ẹ ha máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn, tí ayé sábà máa ń gbà láyè bí? Àbí ẹ ń ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ èkíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé’”?—Éfésù 6:1-3.
6. Báwo ni a ṣe lè wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa?
6 A tún ń fi “ìyèkooro èrò inú” hàn nígbà tí a bá ‘wá àlàáfíà, tí a sì lépa rẹ̀’ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa. (Pétérù Kíní 3:11) Àìfohùnṣọ̀kan àti èdèkòyédè máa ń dìde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Jákọ́bù 3:2) Bí a bá yọ̀ǹda kí kèéta gbilẹ̀, a lè fi àlàáfíà ìjọ lódindi sínú ewu. (Gálátíà 5:15) Nítorí náà, ẹ tètè yanjú aáwọ̀; kí ẹ wá ojútùú tí ó lè mú àlàáfíà wá.—Mátíù 5:23-25; Éfésù 4:26; Kólósè 3:13, 14.
“Ìyèkooro Èrò Inú” àti Àwọn Ojúṣe Ìdílé
7. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fún fífi “ìyèkooro èrò inú” hàn nínú àwọn ohun ti ayé níṣìírí? (b) Ìṣarasíhùwà wo ni ó yẹ kí Kristẹni ọkọ àti aya ní sí àwọn ẹrù iṣẹ́ inú ilé?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú “láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.” (Títù 2:12) Ó dùn mọ́ni pé, nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn obìnrin níyànjú “láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, oníwàmímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé.” (Títù 2:4, 5) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé yẹn ní àwọn ọdún 61 sí 64 Sànmánì Tiwa, àwọn ọdún bíi mélòó kan ṣáájú òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù. Síbẹ̀, àwọn ohun ti ayé, irú bí iṣẹ́ ilé, ṣì ṣe pàtàkì. Nítorí náà, ó yẹ kí ọkọ àti aya ní ojú ìwòye tí ó dára, tí ó gbámúṣé nípa ojúṣe wọn nínú ilé, kí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má baà di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” Olórí ìdílé kan sọ pé kí àlejò rẹ̀ kan máà bínú nítorí ilé òun tí kò bójú mu. Ó ṣàlàyé pé, òun kò tí ì tún un ṣe “nítorí pé òun ń ṣe aṣáájú ọ̀nà.” Ohun tí ó dára ni nígbà tí a bá ṣèrúbọ nítorí ire Ìjọba, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra láti má ṣe fi ire ìdílé wa rúbọ.
8. Báwo ni àwọn olórí ìdílé ṣe lè bójú tó àwọn àìní ìdílé wọn lọ́nà tí ó wà déédéé?
8 Bíbélì rọ àwọn bàbá láti fi ìdílé wọn ṣáájú, ní sísọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kùnà láti pèsè fún ìdílé rẹ̀ “ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kíní 5:8) Ipò ìgbésí ayé yàtọ̀ síra jákèjádò ayé, ó sì dára láti jẹ́ kí ìfojúsọ́nà tí a ní fún ọrọ̀ àlùmọ́nì mọ níwọ̀nba. “Má ṣe fún mi ní òṣì, má ṣe fún mi ní ọrọ̀,” ni àdúrà ẹni tí ó kọ̀wé Òwe 30:8. Bí ó ti wù kí ó rí, kò yẹ kí àwọn òbí gbójú fo àìní àwọn ọmọ wọn nípa ti ará. Fún àpẹẹrẹ, yóò ha bọ́gbọ́n mu láti mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé du ìdílé ẹni, kí a baà lè lépa àwọn àǹfààní ti ìṣàkóso Ọlọ́run bí? Èyí kò ha lè mú kí àwọn ọmọ ẹni banújẹ́ gidigidi bí? Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Òwe 24:27 sọ pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì fi ìtara túlẹ̀ ní oko rẹ; níkẹyìn èyí, kí o sì kọ́ ilé rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni, bí àníyàn nípa ohun ti ara tilẹ̀ ní àyè tirẹ̀, ‘kíkọ́ ilé ẹni’—nípa ti ẹ̀mí àti ní ti ìmọ̀lára—ṣe kókó.
9. Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu fún àwọn olórí ìdílé láti gbé e yẹ̀ wò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kú tàbí kí àwọn ṣàìsàn?
9 O ha ti ṣètò fún bíbójú tó ìdílé rẹ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú lójijì bí? Òwe 13:22 sọ pé: “Ènìyàn rere fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀.” Ní àfikún sí ogún ìmọ̀ Jèhófà àti ipò ìbátan pẹ̀lú rẹ̀, àwọn òbí yóò fẹ́ láti pèsè nípa ti ara fún àwọn ọmọ wọn. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn olórí ìdílé tí ó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ yóò gbìyànjú láti tọ́jú owó díẹ̀ pa mọ́, láti ṣe ìwé ìhágún lọ́nà òfin, àti ìwé ìbánigbófò lórí ẹ̀mí. Ó ṣe tán, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” kò yọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run sílẹ̀. (Oníwàásù 9:11, NW) Owó jẹ́ “ààbò,” lọ́pọ̀ ìgbà, ìwéwèé àfẹ̀sọ̀ṣe sì lè múni bọ́ lọ́wọ́ ìnira. (Oníwàásù 7:12) Ní àwọn ilẹ̀ tí ìjọba kì í ti í bójú tó ìnáwó ìṣègùn, àwọn kan lè yàn láti tọ́jú owó pa mọ́ fún ìtọ́jú ìṣègùn tàbí kí wọ́n ṣètò fún irú àbójútó ètò ìlera kan.a
10. Báwo ni àwọn Kristẹni òbí ṣe lè “to nǹkan jọ pa mọ́” fún àwọn ọmọ wọn?
10 Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Kò yẹ fún àwọn ọmọ láti to nǹkan jọ pa mọ́ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:14) Nínú ayé, ó wọ́pọ̀ fún àwọn òbí láti to owó pa mọ́ fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti ìgbéyàwó àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n baà lè ní ìbẹ̀rẹ̀ tí ó dára nínú ìgbésí ayé. Ìwọ ha ti ronú nípa títo ìṣúra pa mọ́ fún ipò tẹ̀mí ọjọ́ ọ̀la ọmọ rẹ bí? Fún àpẹẹrẹ, kí a sọ pé ọmọ rẹ tí ó ti dàgbà ń lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kò gbọ́dọ̀ fi dandan béèrè fún tàbí retí ìtìlẹ́yìn nípa ti ara láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ lè yàn láti ‘ṣe àjọpín pẹ̀lú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní rẹ̀,’ kí wọ́n baà lè ràn án lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rẹ̀ lọ.—Róòmù 12:13; Sámúẹ́lì Kíní 2:18, 19; Fílípì 4:14-18.
11. Fífi ojú tí ó ṣe pàtàkì wo owó ha fi hàn pé a kò nígbàgbọ́ bí? Ṣàlàyé.
11 Fífi ojú tí ó ṣe pàtàkì wo owó kò túmọ̀ sí pé a kò ní ìgbàgbọ́ pé ètò ìgbékalẹ̀ búburú Sátánì ti sún mọ́ òpin rẹ̀. Ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn fífi “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” àti ìrònú yíyè kooro hàn. (Òwe 2:7, NW; 3:21, NW) Jésù sọ nígbà kan pé, ‘àwọn ọmọ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ ju bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ ti jẹ́’ nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo owó. (Lúùkù 16:8) Abájọ nígbà náà tí àwọn kan fi rí ìdí láti ṣàtúnṣe nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn, kí wọ́n baà lè túbọ̀ bójú tó àwọn àìní ìdílé wọn.
“Ìyèkooro Èrò Inú” Ní Ti Ojú Tí A Fi Ń Wo Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
12. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti mú ara wọn bá ipò tuntun mu?
12 “Ìrísí ìran ayé yìí ń yí pa dà,” àwọn ìyípadà ńlá ní ti ọrọ̀ ajé àti ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ sì ń wáyé lemọ́lemọ́. (Kọ́ríńtì Kíní 7:31) Ṣùgbọ́n, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ láti mú ara wọn bá ipò nǹkan mu. Ó sọ fún wọn nígbà tí ó rán wọn jáde nínú ìgbétáásì ìwàásù wọn àkọ́kọ́ pé: “Ẹ má ṣe ṣaáyan wá wúrà tàbí fàdákà tàbí bàbà sínú àpamọ́ àmùrè yín, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ fún ìrìnnà-àjò náà, tàbí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ méjì, tàbí sálúbàtà tàbí ọ̀pá ìtilẹ̀; nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀.” (Mátíù 10:9, 10) Ṣùgbọ́n, ní àkókò míràn, Jésù sọ pé: “Kí ẹni tí ó ní àpamọ́ gbé e, bákan náà pẹ̀lú ni àsùnwọ̀n oúnjẹ.” (Lúùkù 22:36) Kí ní ti yí pa dà? Àyíká ipò. Àyíká ipò ní ti ìsìn ti túbọ̀ di akanragógó, nísinsìnyí, wọ́n ní láti pèsè fún ara wọn.
13. Kí ni ète pàtàkì ìmọ̀ ẹ̀kọ́, báwo sì ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yí?
13 Bákan náà ni lónìí, àwọn òbí lè ní láti gbé bí ipò ọrọ̀ ajé ti òde òní ti rí gan-an yẹ̀ wò. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ ha ń rí sí i pé àwọn ọmọ rẹ ń gba ìwọ̀n ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tó bí? Ó yẹ kí ète pàtàkì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ jẹ́ láti mú èwe kan gbára dì láti jẹ́ ọ̀jáfáfá òjíṣẹ́ Jèhófà. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tẹ̀mí sì ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. (Aísáyà 54:13) Agbára àwọn ọmọ wọn láti lè gbọ́ bùkátà ara wọn tún yẹ kí ó jẹ àwọn òbí lógún. Nítorí náà, tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan àwọn kókó ẹ̀kọ́ tí ó yẹ nílé ẹ̀kọ́, kí o sì jíròrò pẹ̀lú wọn bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti lépa àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí kò bọ́gbọ́n mu. Irú ìpinnu yẹn jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ìdílé, kò sì yẹ kí àwọn ẹlòmíràn ṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí wọ́n bá tọ̀. (Òwe 22:6) Àwọn tí wọ́n yàn láti dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ilé ńkọ́?b Bí àwọn kan tilẹ̀ ti ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ kí a gbóríyìn fún, iṣẹ́ náà ti nira ju bí àwọn mìíràn ti rò lọ, àwọn ọmọ wọ́n sì ti jìyà rẹ̀. Nítorí náà, bí o bá ń gbé ìgbélékàwé yẹ̀ wò, rí i dájú pé o rò ó dáradára, ní fífi tòótọ́tòótọ́ gbé e yẹ̀ wò bóyá o ní òye iṣẹ́ àti ìfara-ẹni-rúbọ tí o nílò láti ṣe é parí.—Lúùkù 14:28.
‘Má Ṣe Wá Àwọn Ohun Ńláńlá’
14, 15. (a) Báwo ni Bárúkù ṣe sọ ìwàdéédéé rẹ̀ nípa tẹ̀mí nù? (b) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ fún un láti “wá àwọn ohun ńláńlá”?
14 Níwọ̀n bí òpin ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí kò tí ì dé, àwọn kan lè nítẹ̀sí láti lépa àwọn ohun tí ayé ní láti fi fúnni—iṣẹ́ tí ń buyì kúnni, iṣẹ́ tí ń mówó wọlé, àti ọrọ̀. Gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù, akọ̀wé Jeremáyà, yẹ̀ wò. Ó kédàárò pé: “Ègbé ni fún mi nísinsìnyí! nítorí tí Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìkáàánú mi; àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.” (Jeremáyà 45:3) Ó ti sú Bárúkù. Ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé Jeremáyà jẹ́ iṣẹ́ tí ó nira, tí ń kó àárẹ̀ báni. (Jeremáyà 36:14-26) Másùn máwo náà kò sì jọ bí èyí tí yóò dópin láìpẹ́. Yóò tó ọdún 18 kí a tó pa Jerúsálẹ́mù run.
15 Jèhófà sọ fún Bárúkù pé: “Wò ó! Ohun tí mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.” Bárúkù ti sọ ìwàdéédéé rẹ̀ nù. Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ‘wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ̀,’ bóyá ọrọ̀, òkìkí, tàbí àwọn ohun ti ara tí yóò fọkàn rẹ̀ balẹ̀. Níwọ̀n bí Jèhófà yóò ti ‘fa àní gbogbo ilẹ̀ náà tu,’ ọgbọ́n wo ni ó wà nínú wíwá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Nítorí náà, Jèhófà rán Bárúkù létí àwọn ohun pàtàkì yìí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara . . . , èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.” Àwọn ohun ìní ti ara kì yóò la ìparun Jerúsálẹ́mù já! Kìkì “ọkàn” rẹ̀ nìkan ni Jèhófà fi dá a lójú pé òun yóò gbà là gẹ́gẹ́ bí “ohun ìfiṣèjẹ.”—Jeremáyà 45:4, 5, NW.
16. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí lè rí kọ́ láti inú ìrírí Bárúkù?
16 Bárúkù ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún un, àti ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Jèhófà, Bárúkù là á já. (Jeremáyà 43:6, 7) Ẹ wo irú ẹ̀kọ́ ńlá tí èyí jẹ́ fún àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí! Àkókò yí kì í ṣe àsìkò láti ‘wá àwọn ohun ńláńlá fún ara wa.’ Èé ṣe? Nítorí “ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.”—Jòhánù Kíní 2:17.
Ọ̀nà Tí Ó Dára Jù Lọ Láti Gbà Lo Àkókò Tí Ó Ṣẹ́ Kù
17, 18. (a) Báwo ni Jónà ṣe hùwà pa dà nígbà tí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni Jèhófà kọ́ Jónà?
17 Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè lo àkókò tí ó ṣẹ́ kù lọ́nà tí ó dára jù lọ? Kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí wòlíì Jónà. Ó “lọ sí Nínéfè . . . , ó sì kéde, ó sì wí pé, Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a óò bi Nínéfè wó.” Sí ìyàlẹ́nu Jónà, àwọn ará Nínéfè kọbi ara sí ìhìn iṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ronú pìwà dà! Jèhófà kò pa ìlú náà run mọ́. Kí ni ìhùwàpadà Jónà? “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè.”—Jónà 3:3, 4; 4:3.
18 Lẹ́yìn náà, Jèhófà kọ́ Jónà ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan. Ó “pèsè ìtàkùn kan, ó sì ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jónà; kí ó lè ṣíji bò ó lórí . . . Jónà sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.” Ṣùgbọ́n Jónà kò yọ ayọ̀ náà pẹ́, nítorí kò pẹ́ tí ewéko náà fi rọ. Jónà “bínú” nítorí ipò tí ó wà kò bára dé. Jèhófà kan ọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣòó, ní sísọ pé: “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà . . . Kí èmi kí ó má sì dá Nínéfè sí, ìlú ńlá nì, nínú èyí tí ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà ènìyàn wà tí kò lè mọ ọ̀tún mọ òsì nínú ọwọ́ wọn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn?”—Jónà 4:6, 7, 9-11.
19. Ọ̀nà ìrònú ti anìkànjọpọ́n wo ni a óò fẹ́ láti yẹra fún?
19 Ẹ wo bí ìrònú Jónà ti jẹ́ ti anìkànjọpọ́n tó! Ó lè káàánú ewéko, ṣùgbọ́n kò níyọ̀ọ́nú kọ́bọ̀ fún àwọn ará Nínéfè—àwọn ènìyàn ‘tí kò mọ ọ̀tún mọ òsì nínú ọwọ́ wọn’ nípa tẹ̀mí. Àwa pẹ̀lú lè yán hànhàn fún ìparun ayé búburú yìí, kò sì burú láti ṣe bẹ́ẹ̀! (Tẹsalóníkà Kejì 1:8) Ṣùgbọ́n bí a ti ń dúró dè é, a ní ẹrù iṣẹ́ ríran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́, àwọn tí ‘kò mọ ọ̀tún mọ òsì nínú ọwọ́ wọn’ nípa tẹ̀mí. (Mátíù 9:36; Róòmù 10:13-15) Ìwọ yóò ha lo àkókò kúkúrú tí ó ṣẹ́ kù láti ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí wọ́n lè jèrè ìmọ̀ iyebíye nípa Jèhófà bí? Iṣẹ́ wo ni a lè fi wé ayọ̀ ríran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jèrè ìyè?
Máa Bá A Lọ Láti Gbé Pẹ̀lú “Ìyèkooro Èrò Inú”
20, 21. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fi “ìyèkooro èrò inú” hàn ní àwọn ọjọ́ tí ó wà níwájú? (b) Àwọn ìbùkún wo ni yóò wá láti inú gbígbé pẹ̀lú “ìyèkooro èrò inú”?
20 Bí ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì ti ń ré lọ sínú ìparun, ó dájú pé a óò máa rí àwọn ìpèníjà tuntun. Tímótì Kejì 3:13 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí ó “rẹ̀ yín kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.” (Hébérù 12:3) Ẹ gbára lé Jèhófà fún okun. (Fílípì 4:13) Kọ́ láti lè tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, láti mú ara rẹ bá àwọn ipò tí ó túbọ̀ ń burú sí i wọ̀nyí mu, dípò ríronú ṣáá nípa ìgbà tí ó ti kọjá sẹ́yìn. (Oníwàásù 7:10) Lo ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́, máa bá a lọ ní ṣíṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ń pèsè.—Mátíù 24:45-47.
21 A kò mọ bí àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti gùn tó. Síbẹ̀, a lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé, “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” Títí dìgbà tí òpin yẹn yóò fi dé, ẹ jẹ́ kí a máa gbé pẹ̀lú “ìyèkooro èrò inú” nínú ìbálò wa pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kíní kejì, nínú ọ̀nà tí a gbà ń bójú tó ìdílé wa, àti nínú àwọn ẹrù iṣẹ́ wa tí ó jẹ́ ti ayé. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo wa lè ní ìdánilójú pé a óò rí wa ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà” nígbẹ̀yìngbẹ́yín!—Pétérù Kejì 3:14.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àpẹẹrẹ, ní United States, ọ̀pọ̀ ní ètò abánigbófò àìlera, bí àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ gbówó lórí. Àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ti rí i pé àwọn dókítà kan máa ń ṣe tán láti gbé àwọn àfidípò tí kò lẹ́jẹ̀ nínú yẹ̀ wò, nígbà tí àwọn ìdílé bá ní ètò ìbánigbófò ìṣègùn. Ọ̀pọ̀ oníṣègùn yóò fara mọ́ iye tí ètò ìbánigbófò ìṣègùn fọwọ́ sí tàbí tí ètò ìlera ìjọba gbé ìnáwó rẹ̀.
b Bóyá ẹni kan lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ abẹ́ ilé jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbélékàwé—O Ha Wà fun Ọ Bi?,” tí ó yọ nínú ìtẹ̀jáde Jí! April 8, 1993.
Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni a ṣe lè fi “ìyèkooro èrò inú” hàn nínú àwọn ipò ìbátan wa?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi ìwàdéédéé hàn nínú bíbójútó àwọn ojúṣe ìdílé wa?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ti ayé?
◻ Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ láti inú ìrírí Bárúkù àti Jónà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nígbà tí ọkọ àti aya bá ń bá ara wọn lò lọ́nà tí kò dára, wọ́n ń jin ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà lẹ́sẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ó yẹ kí àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn