“Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
“[Jésù] wí fún wọn pé: ‘. . . Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.’’”—ÌṢE 1:7, 8.
1, 2. (a) Ta ló ta yọ jù lọ nínú àwọn ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? (b) Kí ni orúkọ náà Jésù túmọ̀ sí? Báwo ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe ṣe ohun tó bá orúkọ rẹ̀ mu?
“NÍTORÍ èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Ka Jòhánù 18:33-37.) Ìgbà tí Jésù Kristi ń jẹ́jọ́ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù ará Róòmù tí í ṣe gómìnà Jùdíà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Kò tíì pẹ́ tí Jésù sọ fún un pé ọba ni òun. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí bí Jésù ṣe lo ìgboyà lọ́jọ́ yẹn, ó sọ pé Jésù ni “ẹni tí ó ṣe ìpolongo àtàtà ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí níwájú Pọ́ńtíù Pílátù.” (1 Tím. 6:13) Ká sòótọ́, ó máa ń gba ìgboyà gidigidi nígbà míì kéèyàn tó lè jẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́” nínú ayé Sátánì tí wọ́n ti kórìíra wa bí ìgbẹ́ yìí!—Ìṣí. 3:14.
2 Látilẹ̀ ni Jésù ti jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà torí pé Júù ni. (Aísá. 43:10) Kódà, òun ló wá di ẹlẹ́rìí tó ta yọ jù lọ nínú gbogbo àwọn tí Ọlọ́run tíì lò láti jẹ́rìí sí orúkọ Rẹ̀. Jésù fi ọwọ́ gidi mú ìtumọ̀ orúkọ tí Ọlọ́run fún un yìí. Nígbà tí áńgẹ́lì kan ń bá Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù sọ̀rọ̀, ó sọ fún un pé ẹ̀mí mímọ́ ló mú kí Màríà lóyún, áńgẹ́lì náà wá fi kún un pé: “Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” (Mát. 1:20, 21) Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé inú orúkọ Hébérù náà, Jéṣúà ni orúkọ náà Jésù, ti wá. Wọ́n gbà pé ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run wà nínú orúkọ náà, ó sì túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Jésù ṣe ohun tó bá ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mu, ó ran “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí wọ́n sì pa dà rí ojú rere Jèhófà. (Mát. 10:6; 15:24; Lúùkù 19:10) Torí bẹ́ẹ̀, Jésù fi ìtara jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run. Òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà Máàkù, sọ pé: “Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run, ó sì ń wí pé: ‘Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.’” (Máàkù 1:14, 15) Jésù tún fìgboyà dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù, ohun tó ṣe yẹn sì wà lára ìdí tí wọ́n fi kàn án mọ́gi.—Máàkù 11:17, 18; 15:1-15.
“ÀWỌN OHUN ỌLÁ ŃLÁ ỌLỌ́RUN”
3. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kẹta lẹ́yìn ikú Jésù?
3 Àmọ́ ohun ìyàlẹ́nu tó pabanbarì ṣẹlẹ̀! Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí Jésù kú ikú oró, Jèhófà jí i dìde, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́. (1 Pét. 3:18) Ṣùgbọ́n, káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Jésù Olúwa ti jíǹde, ó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, ó sì mú kí wọ́n mọ̀ pé òun tún ti wà láàyè. Lọ́jọ́ tó jíǹde gan-an, ó kéré tán ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara hàn tí onírúurú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì rí i.—Mát. 28:8-10; Lúùkù 24:13-16, 30-36; Jòh. 20:11-18.
4. Ìpàdé wo ni Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe lọ́jọ́ tó jíǹde, iṣẹ́ wo ló sì mú kó ṣe kedere pé wọ́n máa ṣe?
4 Jésù fara hàn ní ìgbà karùn-ún kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn míì tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ lè rí i. Lọ́jọ́ mánigbàgbé yẹn, ká kúkú sọ pé ńṣe ló kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí Bíbélì ṣe sọ, ó “ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n wá lóye pé ńṣe ni bí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ṣe pa Jésù tó sì tún jíǹde lọ́nà ìyanu mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ ṣẹ. Nígbà tí ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ yẹn ń parí lọ, Jésù mú kó ṣe kedere fún àwọn tó pé jọ náà pé iṣẹ́ wà fún wọn láti ṣe. Ó sọ fún wọn pé ‘ní orúkọ òun, a ó máa wàásù ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè—bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ.’ Ó fi kún un pé: “Ẹ óò jẹ́ ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.”—Lúùkù 24:44-48.
5, 6. (a) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi”? (b) Kí ni ohun tuntun nínú ète Jèhófà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti sọ di mímọ̀?
5 Látàrí èyí, ní ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kẹ́yìn, ó pàṣẹ kan fún wọn. Àṣẹ yìí kò lọ́jú pọ̀ àmọ́ ó lágbára, ó sì dájú pé wọ́n lóye rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi” dípò kó sọ pé wọ́n á jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? Jésù ì bá ti sọ pé wọ́n á jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, àmọ́ ọmọ Ísírẹ́lì làwọn tó ń bá sọ̀rọ̀, ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni wọ́n látilẹ̀ wá.
6 Ní báyìí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa mú káwọn èèyàn mọ̀ nípa ohun tuntun kan nínú ète Jèhófà, ohun tuntun yìí kọjá bí Ọlọ́run ṣe kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì àti bó ṣe dá wọn nídè kúrò ní Bábílónì. Ikú àti àjíǹde Jésù Kristi ló mú kí àwọn èèyàn rí ìdáǹdè gbà lọ́wọ́ ìsìnrú tó burú jù lọ, ìyẹn ìsìnrú lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀mí yàn mú kí àwọn èèyàn mọ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run,” ọ̀pọ̀ tó gbọ́ wọn ló sì di ọmọlẹ́yìn. Nípa bẹ́ẹ̀, láti ibi tí Jésù wà lọ́wọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí bí orúkọ rẹ̀ ṣe ń ní ipa rere nígbèésí ayé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n ń ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí Jèhófà máa tipasẹ̀ rẹ̀ mú kí wọ́n rí ìgbàlà.—Ìṣe 2:5, 11, 37-41.
“ÌRÀPADÀ NÍ PÀṢÍPÀÀRỌ̀ FÚN Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÈNÌYÀN”
7. Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni fi hàn?
7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni fi hàn pé Jèhófà ti fayọ̀ gba ìtóye ẹbọ tí Jésù fi ara pípé rẹ̀ rú gẹ́gẹ́ bí ètùtù tàbí ohun tó lè bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. (Héb. 9:11, 12, 24) Jésù náà ṣàlàyé pé, òun wá, ‘kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún òun, bí kò ṣe kí òun lè ṣe ìránṣẹ́, kí òun sì fi ọkàn òun fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Mát. 20:28) Kì í ṣe ìwọ̀nba àwọn Júù tó ronú pìwà dà yẹn nìkan ni “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” tó máa jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là” torí pé ìràpadà náà “kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!”—1 Tím. 2:4-6; Jòh. 1:29.
8. Ibo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ́rìí dé, kí ló sì mú kí ìyẹn ṣeé ṣe?
8 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà yẹn lọ́hùn-ún nílò ìgboyà kí wọ́n lè máa jẹ́rìí nípa rẹ̀? Ó dájú pé wọ́n nílò ìgboyà, àmọ́ kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣe iṣẹ́ náà. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó lágbára ló sún wọn láti máa wàásù, òun náà ló sì fún wọn lókun. (Ka Ìṣe 5:30-32.) Ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, a lè sọ pé “òtítọ́ ìhìn rere yẹn” ti dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:5, 23.
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Kristẹni nígbà yẹn, tó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ?
9 Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ìjọ Kristẹni nígbà yẹn wá di èyí tí wọ́n sọ dìbàjẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:29, 30; 2 Pét. 2:2, 3; Júúdà 3, 4) Bí Jésù ṣe sọ, ìpẹ̀yìndà tí Sátánì, “ẹni burúkú náà” ṣagbátẹrù rẹ̀ máa gbèrú, á sì bo ìsìn tòótọ́ mọ́lẹ̀ títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 13:37-43) Nígbà náà ni Jèhófà máa gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí aráyé. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní oṣù October ọdún 1914, ó sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò búburú Sátánì.—2 Tím. 3:1.
10. (a) Ọdún mánigbàgbé wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró òde òní ti ń kéde rẹ̀ tipẹ́? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní oṣù October ọdún 1914, báwo nìyẹn sì ṣe túbọ̀ ṣe kedere?
10 Kó tó di oṣù October ọdún 1914 ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró òde òní ti ń kéde pé ọdún yẹn máa yàtọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa igi ràgàjì kan tí wọ́n gé lulẹ̀ tó sì tún máa sọjí lẹ́yìn “ìgbà méje” ni wọ́n gbé ọ̀rọ̀ wọn kà. (Dán. 4:16) Jésù pe àsìkò kan náà yìí ní “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Láti ọdún 1914 tó jẹ́ mánigbàgbé yẹn, “àmì wíwàníhìn-ín [Kristi]” gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fi jọba lórí aráyé ti túbọ̀ ṣe kedere fún gbogbo èèyàn láti rí. (Mát. 24:3, 7, 14; Lúùkù 21:24) Torí náà, látìgbà yẹn, ara “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” tá à ń polongo ni pé Jèhófà ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí aráyé.
11, 12. (a) Kí ni Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe lẹ́yìn tí ogun parí lọ́dún 1919? (b) Àwọn ohun míì wo ló túbọ̀ ṣe kedere látọdún 1935 lọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
11 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù Kristi Ọba náà gorí ìtẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 18:2, 4) Lẹ́yìn tí ogun parí lọ́dún 1919, àǹfààní wá ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí láti máa wàásù kárí ayé nípa ẹni tí Ọlọ́run máa tipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là àti nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí, èyí tó mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹni àmì òróró míì dara pọ̀ mọ́ wọn kí wọ́n lè di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.
12 Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1935, ó wá ṣe kedere pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àkójọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” rẹ̀, tí wọ́n máa para pọ̀ di “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó ti orílẹ̀-èdè gbogbo wá. Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí náà ń tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn náà ń fì ìgboyà wàásù bíi ti Jésù, wọ́n sì ń kéde fún aráyé pé Ọlọ́run àti Kristi ló mú kí àwọn rí ìgbàlà. Bí wọ́n ṣe ń fara dà á nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí tí wọn ò sì dẹ́kun lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, wọ́n máa láǹfààní láti la “ìpọ́njú ńlá” tó máa fòpin sí ayé Sátánì já.—Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9, 10, 14.
‘MÁYÀLE KÓ O LÈ SỌ ÌHÌN RERE’
13. Kí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pinnu láti ṣe? Kí ló mú kó dá wa lójú pé a máa ṣàṣeyọrí?
13 Ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti mọyì àǹfààní tá a ní pé à ń jẹ́rìí nípa “àwọn ohun ọlá ńlá” tí Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe àtàwọn ìlérí tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Ká sòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti máa jẹ́rìí nípa àwọn nǹkan yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló jẹ́ pé ẹ̀mí ìdágunlá, ìfiniṣẹ̀sín tàbí inúnibíni ni wọ́n ń kojú láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Àwa náà lè ṣe bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: ‘A máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì’ tàbí ‘láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtakò.’ (1 Tẹs. 2:2, Ìròhìn Ayọ̀) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ bí ètò Sátánì ṣe ń lọ sópin. (Aísá. 6:11) Agbára wa ò gbé e láti dá iṣẹ́ yìí ṣe, àmọ́ ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ká bẹ Jèhófà pé kó fún wá ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:1, 7; Lúùkù 11:13.
14, 15. (a) Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní? Kí ni àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn Kristẹni? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tí wọ́n bá hùwà àìtọ́ sí wa torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
14 Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń pe ara wọn ní Kristẹni, “ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú [Ọlọ́run] nípa àwọn iṣẹ́ wọn, nítorí tí wọ́n jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí àti aláìgbọràn, a kò sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n fún iṣẹ́ rere èyíkéyìí.” (Títù 1:16) Ó dára ká máa rántí pé ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ àwọn tó gbáyé nígbà yẹn ló kórìíra àwọn Kristẹni tòótọ́, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ ló kórìíra wọn. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé . . . ẹ̀mí Ọlọ́run . . . ti bà lé yín.”—1 Pét. 4:14.
15 Ṣé a lè sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bá wa mu, torí pé à ń jẹ́rìí pé Jésù ti di ọba. Torí náà, bí àwọn èèyàn bá kórìíra wa torí pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, ohun kan náà ló jẹ́ pé wọ́n “ń gàn [wá] nítorí orúkọ [Jésù] Kristi.” Jésù pàápàá sọ fún àwọn alátakò rẹ̀ pé: “Mo wá ní orúkọ Baba mi, ṣùgbọ́n ẹ kò gbà mí.” (Jòh. 5:43) Torí náà, nígbàkigbà táwọn èèyàn bá ṣe àtakò sí ẹ lóde ẹ̀rí, má ṣe fòyà. Ńṣe ni ìwà àìdáa tí wọ́n ń hù sí ẹ yẹn ń fi hàn pé inú Ọlọ́run dùn sí ẹ àti pé ẹ̀mí rẹ̀ ‘ti bà lé ẹ.’
16, 17. (a) Ìrírí wo làwa èèyàn Jèhófà ń ní lọ́pọ̀ ibi láyé? (b) Kí lo pinnu láti ṣe?
16 Lẹ́sẹ̀ kan náà, máa fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ ń wá sínú òtítọ́ lọ́pọ̀ ibi láyé. Kódà láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn ará wa ti máa ń wàásù déédéé, a ṣì ń rí àwọn tó ṣe tán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tá a sì tún lè sọ ìhìn àgbàyanu nípa ìgbàlà fún. Ǹjẹ́ ká máa sa gbogbo ipá wa láti máa pa dà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, tó bá sì ṣeé ṣe ká máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú títí tí wọ́n á fi ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Ọ̀rọ̀ rẹ lè jọ ti arábìnrin kan tó ń gbé ní South Africa, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sarie. Ọgọ́ta [60] ọdún rèé tí arábìnrin yìí ti ń wàásù, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá pé lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, mò ń gbádùn àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, inú mi sì ń dùn pé mò ń sọ orúkọ ológo rẹ̀ di mímọ̀.” Arábìnrin yìí àti ọkọ rẹ̀ Martinus, ti ran àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà, wọ́n sì tún ti ran ọ̀pọ̀ àwọn míì náà lọ́wọ́. Arábìnrin Sarie wá fi kún un pé: “Kò sí iṣẹ́ míì tó lè fúnni ní irú ìtẹ́lọ́rùn yìí, Jèhófà sì ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún gbogbo wa ní agbára tá a nílò láti máa bá iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí nìṣó.”
17 Yálà Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi ni wá tàbí à ń wọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ pé a ní àǹfààní láti máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Torí náà, máa bá a nìṣó láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná fáwọn èèyàn bó o ṣe ń sapá láti wà ní mímọ́ nínú ayé aláìmọ́ tí Sátánì ń darí yìí. Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa bọlá fún Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, tá a ní àǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́.