Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Ọ̀ràn Àṣírí
“OJÚ JÈHÓFÀ Ń BẸ NÍ IBI GBOGBO, Ó Ń ṢỌ́ ÀWỌN ẸNI BÚBURÚ ÀTI ÀWỌN ẸNI RERE.”—Òwe 15:3.
ṢÀṢÀ lẹni tó máa fara mọ́ ọn pé kí ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ òun kan máa ṣọ́ gbogbo ìgbésẹ̀ òun, kó máa díwọ̀n ìrònú òun, kó sì máa pinnu ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn òun. Síbẹ̀, gbogbo nǹkan yìí ni Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lágbára láti ṣe. Ní Hébérù 4:13, Bíbélì sọ pé: “Kò . . . sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” Ṣé kì í ṣe pé títojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn lèyí jẹ́? Rárá o. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń lúwẹ̀ẹ́ ní etíkun, agbẹ̀mílà kan lè máa ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. O ò lè ka èyí sí pé ó ń wo àṣírí rẹ. Ká sọ tòótọ́, ńṣe ni wíwà tó wà nítòsí ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. O mọ̀ pé bí o bá bọ́ sínú ìṣòro èyíkéyìí, ńṣe ló máa bẹ́ sómi ní wàrà-ǹ-ṣe-ṣà láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Bákan náà ni ìyá ọmọ kan ṣe máa ń mójú tó ọmọ ọwọ́ rẹ̀, tá á sì máa ṣọ́ ọ lójú méjèèjì. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á kà á sí ẹni tí kò bìkítà.
Lọ́nà kan náà, Jèhófà Ọlọ́run máa ń ṣọ́ àwọn ìrònú àti ìṣe wa nítorí pé ó fẹ́ kó dáa fún wa. Wòlíì Bíbélì kan sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Ṣùgbọ́n, mélòó nínú àwọn èrò àti ìṣe wa ìkọ̀kọ̀ ni Jèhófà ń rí ní ti tòótọ́? Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó kan Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ yìí.
Agbára Láti Ṣàyẹ̀wò Èrò Ọkàn
Nígbà tí Jésù ń jẹun nínú ilé Farisí kan, obìnrin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ wọlé, ó sì kúnlẹ̀ sẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sunkún, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu omijé rẹ̀ kúrò lẹ́sẹ̀ Jésù. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ní rírí èyí, Farisí tí ó ké sí i sọ nínú ara rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin yìí, bí ó bá jẹ́ wòlíì ni, ì bá mọ ẹni àti irú obìnrin tí ẹni tí ń fọwọ́ kan òun jẹ́.’” Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lẹ́yìn èyí fi hàn pé kì í ṣe pé ó mọ irú èèyàn tí obìnrin náà jẹ́ látilẹ̀wá nìkan ni àmọ́ ó tún mọ ohun tí Farisí náà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán “nínú ara rẹ̀.”—Lúùkù 7:36-50.
Ní àkókò mìíràn, àwọn kan tó ń ta ko bí Jésù ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìyanu kò ó lójú. Àkọsílẹ̀ Mátíù 9:4 sọ pé: “Ní mímọ ìrònú wọn, Jésù . . . wí pé: ‘Èé ṣe tí ẹ fi ń ro àwọn ohun burúkú nínú ọkàn-àyà yín?’” Agbára tí Jésù ní láti mọ èrò ọkàn àwọn ẹlòmíràn kọjá wíwulẹ̀ máa dọ́gbọ́n méfò.
Ríronú lórí àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde Lásárù fi hàn pé agbára yìí kọjá míméfò lásán. Ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ ti kú. Ìrònú rẹ̀ ti di asán, ara rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí jẹrà. (Sáàmù 146:3, 4) Nígbà tí Jésù sọ pé kí wọ́n gbé ohun tí wọ́n fi dí ẹnu ọ̀nà sàréè tí wọ́n sin Lásárù sí kúrò, Màtá arábìnrin rẹ̀ sọ pé: “Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn.” Síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ agbára Ọlọ́run, Jésù jí Lásárù dìde, títí kan gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti nínú agbára ìrántí rẹ̀, èyí tó máa mú kó ṣeé ṣe fún Lásárù láti di ẹni tó jẹ́ kó tó kú.—Jòhánù 11:38-44; 12:1, 2.
Jésù fi ẹ̀rí agbára tí Jèhófà Ọlọ́run ní láti mọ ohun tó wà nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún hàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ nípa àdúrà. Ṣáájú kí Jésù tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòkọ́ṣe, ó sọ pé: “Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” Jésù tún sọ pé: “Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.”—Mátíù 6:6, 8.
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Mímọ̀ Pé Ọlọ́run Ń Ṣọ́ Wa
Ǹjẹ́ mímọ̀ pé Ọlọ́run ń wádìí gbogbo ọkàn àti pé ó ń fi òye mọ “gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú” ń ṣèdíwọ́ fún wa láti ṣe ohun tó wù wá tàbí ó ha ń dín òmìnira wa kù? (1 Kíróníkà 28:9) Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, mímọ̀ pé kò sí ohunkóhun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run lè máa sún wa ṣe ohun rere.
Elizabeth tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ pé, kì í ṣe torí pé àwọn kámẹ́rà ń ṣọ́ òun nibi iṣẹ́ ni lájorí ohun tó ń mú kí òun máa hùwà títọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Jèhófà ń wo ìṣesí mi ló ń sún mi láti máa hùwà títọ́ nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe, kódà nígbà tí mi ò bá sí níbi iṣẹ́ pàápàá.”
Jim náà sọ ohun tó fara jọ èyí. Ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan níbi tó ti jẹ́ àṣà àwọn òṣìṣẹ́ láti máa jalè. Àmọ́ Jim kọ̀ láti máa jí nǹkan ọ̀gá rẹ̀. Ó sọ pé: “Òótọ́ ni pé mo lè jí nǹkan ní iléeṣẹ́ wa láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni á rí mi, ṣùgbọ́n mo fojú pàtàkì wo àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run mo sì mọ̀ pé gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe ló ń rí.”
Mímọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ nípa gbogbo ohun tá a bá ń ṣe, àti ìfẹ́ láti ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú rẹ̀, lè sún ẹnì kan láti ṣe àwọn ìyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Doug jẹ́ ọkùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé Kristẹni, àmọ́ ó fojú kéré mímọ̀ tó mọ̀ pé Ọlọ́run lè rí àwọn ohun tó ń ṣe. Látàrí èyí, ó ń gbé ìgbésí ayé méjì. Ó máa ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn èyí ló tún máa lọ lo oògùn olóró pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sí gígun alùpùpù sún un láti lọ dara pọ̀ mọ́ àjọ ìpàǹpá oníwà ipá kan tó ń gun alùpùpù. Káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lè tẹ́wọ́ gbà á, Doug máa ń hu àwọn ìwà ọ̀daràn tó burú jáì.
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni Doug tún bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì padà. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lóye pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi kan tó mọ ohun táwọn èèyàn ń ṣe, àti pé ìwà wọn lè múnú rẹ̀ dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Èyí sún Doug láti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ìwà rere títayọ tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìnà ìkà làwọn ọmọ ìta náà máa ń na ẹnikẹ́ni tó bá fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀, Doug lọ sí ìpàdé àjọ ìpàǹpá náà ó sì ṣàlàyé lójú gbogbo wọn pé òún ti fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo dìde dúró láti sọ̀rọ̀, ńṣe ni àyà mi ń lù kì-kì-kì. Ó ṣe mí bíi ti Dáníẹ́lì nígbà tó wà nínú ihò kìnnìún. Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà sí Jèhófà nínú ọkàn mi, mo sì fara balẹ̀ ṣàlàyé àwọn ohun tó fà á tí mo ṣe fẹ́ fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀. Nígbà tí mo fibẹ̀ sílẹ̀, gbogbo wọn ló bọ̀ mí lọ́wọ́, tí wọ́n sì sọ pé á dára fún mi, àyàfi ẹnì kan ṣoṣo ni kò kí mi. Mo wá rí i pé ọ̀rọ̀ Aísáyà 41:13 ṣẹ sí mi lára, èyí tó sọ pé: ‘Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, “Má fòyà, èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”’” Doug gbà pé Jèhófà fún òun ní okun tí òún nílò láti yí ìgbésí ayé òun padà.
Èrò Tó Yẹ Kéèyàn Ní Nípa Ọ̀ràn Àṣírí
Kò bọ́gbọ́n mu láti máa ronú pé a lè máa ṣe àwọn ohun kan tí ojú Ọlọ́run kò ní tó. Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé: “Òpònú sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: ‘Jèhófà kò sí.’” (Sáàmù 14:1) Gẹ́gẹ́ bí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ti ṣàlàyé, àwọn ẹ̀dá èèyàn ti ṣe àwọn kámẹ́rà tó lágbára láti dá ojú ẹnì kan pàtó mọ̀ láàárín èrò. Wọ́n ti ṣe àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò láti fetí kọ́ ọ̀rọ̀ téèyàn ń sọ láṣìírí, èyí tó lágbára láti dá ohùn ẹnì kan pàtó mọ̀ láàárín ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ń lo tẹlifóònù. Ó dájú nígbà náà pé, Ẹlẹ́dàá tó dá ọpọlọ ẹ̀dá èèyàn lágbára láti ṣàyẹ̀wò ìrònú ẹnikẹ́ni, nígbàkigbà tó bá rí i pé ó tọ́ kí Òun ṣe bẹ́ẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa ní ẹ̀tọ́ láti mọ gbogbo ohun téèyàn ń ṣe níkọ̀kọ̀, àwa ẹ̀dá èèyàn kò ní ẹ̀tọ́ yẹn. Àpọ́sítélì Pétérù gba gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run níyànjú pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí . . . aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.” (1 Pétérù 4:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kìlọ̀ nípa títojúbọ “àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn.”—1 Tímótì 5:13.
Àpẹẹrẹ búburú jáì kan nípa jíjẹ́ “olùyọjúràn” àti títojúbọ “àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn” ni àṣà kan tó ń gbilẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìyẹn ni kí àwọn aráàlú kan máa lo àwọn ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ tàbí kámẹ́rà tó kéré gan-an láti fi ṣe amí àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Japan, obìnrin sárésáré kan tó ń jẹ́ Naoko Takahashi, ẹni tó gba àmì ẹ̀yẹ wúrà níbi Eré Ìdárayá Olympic tó wáyé ní ìlú Sydney, ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé àwọn kan ti fi kámẹ́rà kékeré kan pa mọ́ sínú ilé ìwẹ̀ rẹ̀, èyí sì ti yàwòrán rẹ̀ láìjẹ́ pé ó mọ̀ rárá. Wọ́n ṣe àwòrán yìí sínú kásẹ́ẹ̀tì fídíò, wọ́n sì ti ta ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n ṣe láìbófinmu.
Ohun mìíràn tó tún gbòde báyìí ni jíjí ohun ìdánimọ̀ ẹni, ìyẹn ni àṣà lílo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ láti fi jí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa ẹni kàn. Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe àwọn ohun tó bá yẹ láti pa àwọn ìsọfúnni nípa ara rẹ mọ́ kí àwọn ẹlòmíràn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i má bàa mọ̀ nípa rẹ̀.a Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.
Híhùwà ní Ìkọ̀kọ̀—Ṣíṣe Ìjíhìn ní Gbangba
Bí ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, àti ìpániláyà ṣe ń peléke sí i, kò sí àní-àní pé àwọn ìjọba yóò túbọ̀ máa ṣọ́ àwọn aráàlú wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Àmọ́ o, láìpẹ́, kò ní sídìí èyíkéyìí láti máa lo kámẹ́rà tó ń ṣọ́ni tàbí láti máa lo àwọn ẹ̀rọ láti fetí kọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí ẹni. Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Jèhófà Ọlọ́run yóò pe gbogbo ìran èèyàn láti wá jíhìn àwọn ohun tí wọ́n ṣe, ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀.—Jóòbù 34:21, 22.
Látìgbà náà lọ, ayé yóò bọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá, ìkórìíra, àti ìwà ọ̀daràn tó ti ń da aráyé láàmú látọjọ́ pípẹ́. Báwo lèyí yóò ṣe ṣeé ṣe? Nítorí pé nígbà yẹn, kì í ṣe pé Jèhófà yóò mọ gbogbo ẹni tó wà láàyè lámọ̀dunjú nìkan ni, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tó wà láàyè náà yóò mọ Jèhófà dunjú. Ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà yóò nímùúṣẹ: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí náà, “Ṣọ́ra O!”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
Mímọ̀ pé kò sí ohunkóhun tó pa mọ́ lójú ọlọ́run lè máa sún wa ṣe ohun rere
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣọ́ra o!
WÍWÁṢẸ́ LÓRÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ LÈ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN MỌ ÀṢÍRÍ RẸ: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa mọ àwọn ohun tó jẹ́ àṣírí àwọn tó ń wáṣẹ́ bí wọ́n bá fi àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ tí wọ́n mọ̀ àti bí wọ́n ṣe tóótun sí sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn tí ń báni wáṣẹ́ lè wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n sì lè di orísun ìsọfúnni fún àwọn tó ń jí àwọn nǹkan ìdánimọ̀ ẹni. Àwọn ibi tí wọ́n ti ń báni wáṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń gba àwọn ìsọfúnni àwọn tó ń wáṣẹ́, irú bí orúkọ, àdírẹ́sì, ọjọ́ orí, àti ìwé àkọsílẹ̀ nípa ìrírí tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì máa ń fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn tí kì í ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ wọn, irú bí àwọn olùpolówó ọjà.
ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀ ORÍ TẸLIFÓÒNÙ ALÁGBÈÉRÌN ÀTI Ọ̀RÀN ÀṢÍRÍ: Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, kò sọ́gbọ́n téèyàn lè dá tó lè fi pa gbogbo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ láṣìírí tó bá ń lo tẹlifóònù tí kò ní wáyà tàbí tẹlifóònù alágbèérìn. Bó o bá fẹ́ jíròrò ọ̀rọ̀ àṣírí kan, ohun tó dára jù ni pé kó o lo tẹlifóònù gidi, ìyẹn tẹlifóònù oníwáyà. Rí i dájú pé tẹlifóònù oníwáyà ni ìwọ àti ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ ń lò. Àwọn kan lè lo àwọn rédíò tó ń bá ìgbì afẹ́fẹ́ ṣiṣẹ́ láti fi gbọ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yín, kódà àwọn tẹlifóònù tí kò ní wáyà mìíràn tàbí àwọn ẹ̀rọ tó ń ṣọ́ bí àwọn ọmọ ọwọ́ ṣe ń mí lè gba ìsọfúnni yín. Bó o bá ra ọjà kan lórí tẹlifóònù, tó o sì sọ nọ́ńbà káàdì ìrajà àwìn rẹ àti ọjọ́ tí káàdì náà máa ṣiṣẹ́ parí, àwọn kan lè máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ lórí tẹlifóònù tí kò ní wáyà tàbí tẹlifóònù alágbèérìn rẹ, o sì lè di ẹni táwọn gbájú-ẹ̀ máa lù ní jìbìtì.b
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b A ṣàkójọ ìsọfúnni yìí látinú ibi ìkósọfúnnisí orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ ti Àjọ Privacy Rights Clearinghouse.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
O ò lè ka ṣíṣọ́ tí agbẹ̀mílà kan ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì sí pé ó ń wo àṣírí rẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Mímọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ nípa gbogbo ohun tá a bá ń ṣe sún Doug láti ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀