ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18
Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nínú Ìjọ Kristẹni (Apá Kejì Nínú Mẹ́rin)
“Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo, nípa bẹ́ẹ̀, ẹ ó mú òfin Kristi ṣẹ.”—GÁL. 6:2.
ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àwọn nǹkan méjì wo ló dá wa lójú?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀. Àtìgbà tó ti dá àwa èèyàn sáyé ló ti nífẹ̀ẹ́ wa, títí ayé lá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Sm. 33:5) Torí náà, ohun méjì kan wà tó dá wa lójú: (1) Inú Jèhófà kì í dùn táwọn èèyàn bá fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ dù wọ́n. (2) Á rí i dájú pé àwọn ìránṣẹ́ òun rí ìdájọ́ òdodo gbà, ó sì máa fìyà jẹ àwọn tó ń fojú pọ́n wọn. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ yìí,b a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ ni Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá lé. Bákan náà, Òfin yẹn gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ, ìyẹn ìdájọ́ òdodo fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. (Diu. 10:18) Kò sí àní-àní pé Òfin yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ gan-an.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Òfin Mósè parí iṣẹ́ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. Ṣéyẹn túmọ̀ sí pé àwa Kristẹni kò ní máa tẹ̀ lé òfin tá a gbé karí ìfẹ́, tó sì tún gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Àwa Kristẹni ní òfin tuntun tá à ń tẹ̀ lé. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ jíròrò òfin tó wà fún àwa Kristẹni. Lẹ́yìn náà, àá dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tá a fi sọ pé orí ìfẹ́ la gbé òfin yìí kà? Kí nìdí tá a fi sọ pé òfin yẹn gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ? Báwo ló ṣe yẹ káwọn tó ń múpò iwájú máa ṣe sáwọn míì?
KÍ NI “ÒFIN KRISTI”?
3. Kí làwọn nǹkan tó wà nínú “òfin Kristi” tí Gálátíà 6:2 mẹ́nu kàn?
3 Ka Gálátíà 6:2. “Òfin Kristi” ló ń darí àwa Kristẹni. Ká sòótọ́, Jésù ò ṣe òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ ó fún wọn láwọn ìtọ́ni àtàwọn ìlànà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Torí náà, gbogbo ohun tí Jésù fi kọ́ni ló para pọ̀ jẹ́ “òfin Kristi.” Ká lè lóye òfin yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
4-5. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ni, ìgbà wo ló sì ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, ó kọ́ wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lágbára torí pé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi kọ́ni, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí wọ́n lè fayé wọn ṣe, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé. (Lúùkù 24:19) Jésù tún kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ mú káwọn ọmọlẹ́yìn náà rí bó ṣe yẹ kí wọ́n gbé ìgbé ayé wọn.—Jòh. 13:15.
5 Ìgbà wo ni Jésù kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àsìkò tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. (Mát. 4:23) Ó tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kété lẹ́yìn tó jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn tó lé lọ́gọ́rùn-ún márùn-ún (500), ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mát. 28:19, 20; 1 Kọ́r. 15:6) Torí pé Jésù ni orí ìjọ, ó ṣì ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni kódà lẹ́yìn tó pa dà sí ọ̀run. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣe ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni. Ó rán àpọ́sítélì Jòhánù pé kó fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró níṣìírí, kó sì tún fún wọn nímọ̀ràn.—Kól. 1:18; Ìfi. 1:1.
6-7. (a) Ibo la ti lè rí àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń tẹ̀ lé òfin Kristi?
6 Ibo la ti lè rí àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni? Àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni àtohun tó ṣe nígbà tó wà láyé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìwé tó kù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì náà tún jẹ́ ká mọ èrò Kristi. Ó ṣe tán, àwọn tó ní “èrò inú Kristi” ló kọ àwọn ìwé náà, ẹ̀mí mímọ́ ló sì darí wọn.—1 Kọ́r. 2:16.
7 Ohun tá a rí kọ́: Gbogbo apá ìgbésí ayé wa la ti lè fi ẹ̀kọ́ Jésù sílò. Torí náà, òfin Kristi kan ohun tá à ń ṣe nínú ilé, níbi iṣẹ́, nílé ìwé àti nínú ìjọ. Ká lè dojúlùmọ̀ òfin yìí, ó ṣe pàtàkì ká máa ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. A lè fi hàn pé à ń tẹ̀ lé òfin yìí tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni àtàwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa, tá a sì ń pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Tá a bá ń pa òfin Kristi mọ́, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí torí pé Òun ni orísun gbogbo nǹkan tí Jésù fi kọ́ni.—Jòh. 8:28.
ÌFẸ́ NI ÒFIN KRISTI DÁ LÉ
8. Orí ìpìlẹ̀ wo la gbé òfin Kristi kà?
8 Tí ìpìlẹ̀ ilé kan bá lágbára dáadáa, ọkàn àwọn tó ń gbé inú ẹ̀ máa balẹ̀. Lọ́nà kan náà, tí òfin kan bá ní ìpìlẹ̀ tó lágbára, ọkàn àwọn tó ń tẹ̀ lé òfin náà máa balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé á dáàbò bo àwọn. Orí ìpìlẹ̀ tó lágbára ni a gbé òfin Kristi kà, ìyẹn sì ni ìfẹ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
9-10. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
9 Lákọ̀ọ́kọ́, ìfẹ́ ló mú kí Jésù ṣe gbogbo ohun tó ṣe. Ìfẹ́ ló máa ń mú kéèyàn káàánú àwọn míì tàbí kéèyàn ṣe àwọn míì lóore. Torí pé Jésù káàánú àwọn èèyàn, ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn lára dá, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó sì jí àwọn òkú dìde. (Mát. 14:14; 15:32-38; Máàkù 6:34; Lúùkù 7:11-15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yẹn gbà á lákòókò, ó sì tán an lókun, síbẹ̀ Jésù fi ire àwọn èèyàn ṣáájú tiẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn nígbà tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.—Jòh. 15:13.
10 Ohun tá a rí kọ́: A lè fara wé Jésù tá a bá ń fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. A tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń káàánú àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Tó bá jẹ́ pé àánú àwọn èèyàn ló ń mú ká máa wàásù ká sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ pé òfin Kristi là ń tẹ̀ lé yẹn.
11-12. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an? (b) Báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà?
11 Ìkejì, Jésù jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ ká mọ bí Baba rẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ wa pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa la ṣeyebíye lójú Baba wa ọ̀run, ó sì mọyì wa gan-an. (Mát. 10:31) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn láti tẹ́wọ́ gba ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà tó sì pa dà sínú ìjọ. (Lúùkù 15:7, 10) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ láti kú fún wa.—Jòh. 3:16.
12 Ohun tá a rí kọ́: Báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà? (Éfé. 5:1, 2) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá mọyì àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tá a sì kà wọ́n sí ẹni ọ̀wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí inú wa máa dùn tí “àgùntàn tó sọ nù” tàbí tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Sm. 119:176) A tún lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá a bá ń fara wa jìn fún wọn, pàápàá nígbà ìṣòro. (1 Jòh. 3:17) Tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ṣe là ń pa òfin Kristi mọ́.
13-14. (a) Bó ṣe wà nínú Jòhánù 13:34, 35, àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí sì nìdí tó fi jẹ́ òfin tuntun? (b) Báwo la ṣe lè pa àṣẹ náà mọ́?
13 Ìkẹta, Jésù pàṣẹ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. (Ka Jòhánù 13:34, 35.) Òfin tuntun ni òfin yẹn torí pé ó yàtọ̀ sírú ìfẹ́ tí Òfin Mósè ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní síra wọn. Jésù sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Irú ìfẹ́ yìí gba pé ká ṣe tán àtifi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fáwọn míì.c Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ju ara wa lọ. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn débi pé àá ṣe tán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí wọn bíi ti Jésù.
14 Ohun tá a rí kọ́: Báwo la ṣe lè pa àṣẹ tuntun náà mọ́? Ní kúkúrú, ká máa fi nǹkan du ara wa nítorí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Kì í ṣe pé ká múra tán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ torí wọn nìkan ni, ó tún yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan kéékèèké míì táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣètò láti máa gbé àwọn àgbàlagbà wá sípàdé tàbí ká fi àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí du ara wa torí àwọn míì. Bákan náà, a lè gbàyè lẹ́nu iṣẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, òfin Kristi là ń pa mọ́ yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe là ń mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ kára sì tu gbogbo àwọn ará.
ÒFIN TÓ GBÉ ÌDÁJỌ́ ÒDODO LÁRUGẸ
15-17. (a) Kí làwọn nǹkan tí Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo? (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
15 Nínú Bíbélì, “ìdájọ́ òdodo” túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run láìṣe ojúsàájú. Kí nìdí tá a fi sọ pé òfin Kristi gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ?
16 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àwọn nǹkan tí Jésù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. Nígbà ayé Jésù, àwọn aṣáájú ìsìn Júù kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù, wọ́n ka àwọn Júù tí kò lọ sílé ìwé àwọn rábì sí gbáàtúù, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ka àwọn obìnrin sí. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ kò ṣojúsàájú, ó sì ṣojúure sí gbogbo èèyàn. Ó jẹ́ káwọn tó nígbàgbọ́ tẹ̀ lé òun, yálà wọ́n jẹ́ Júù tàbí wọn kì í ṣe Júù. (Mát. 8:5-10, 13) Gbogbo èèyàn ló wàásù fún, àtolówó àti tálákà. (Mát. 11:5; Lúùkù 19:2, 9) Kò tẹ́ńbẹ́lú àwọn obìnrin, bẹ́ẹ̀ sì ni kò hùwà ìkà sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin, títí kan àwọn táwọn míì kà sí aláìjámọ́ nǹkan kan.—Lúùkù 7:37-39, 44-50.
17 Ohun tá a rí kọ́: A lè fara wé Jésù tá a bá ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn láìṣe ojúsàájú, tá a sì ń wàásù fún gbogbo èèyàn láìka ipò wọn láwùjọ tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. Àwọn arákùnrin ń fara wé Jésù bí wọ́n ṣe ń fi ọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, òfin Kristi là ń tẹ̀ lé.
18-19. Kí ni Jésù fi kọ́ni nípa ìdájọ́ òdodo, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú ohun tó fi kọ́ni?
18 Ohun kejì tá a máa gbé yẹ̀ wò lohun tí Jésù fi kọ́ni nípa ìdájọ́ òdodo. Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láwọn ìlànà táá jẹ́ kí wọ́n máa hùwà tó tọ́ sáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ìlànà Pàtàkì tí àwọn kan máa ń pè ní Òfin Oníwúrà. (Mát. 7:12) Gbogbo wa la fẹ́ káwọn èèyàn hùwà tó dáa sí wa. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa hùwà tó dáa sí wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á yá wọn lára láti ṣe bákan náà sí wa. Táwọn èèyàn bá hùwà àìdáa sí wa ńkọ́? Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé á ‘dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru.’ (Lúùkù 18:6, 7) Ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ torí ó jẹ́ ká mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó rí gbogbo àdánwò tá à ń kojú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó sì máa gbèjà wa lásìkò tó tọ́ lójú rẹ̀.—2 Tẹs. 1:6.
19 Ohun tá a rí kọ́: Tá a bá ń fi àwọn ìlànà tí Jésù fi kọ́ni sílò, àá máa hùwà tó dáa sáwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá sì hùwà àìdáa sí wa nínú ayé Èṣù yìí, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ torí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa gbèjà wa.
BÁWO LÓ ṢE YẸ KÁWỌN TÓ Ń MÚPÒ IWÁJÚ MÁA ṢE SÁWỌN MÍÌ?
20-21. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ máa hùwà sáwọn míì? (b) Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi irú ìfẹ́ tí Kristi ní hàn sí ìyàwó rẹ̀, báwo ló ṣe yẹ kí bàbá máa ṣe sáwọn ọmọ rẹ̀?
20 Nínú òfin Kristi, báwo ló ṣe yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ máa hùwà sáwọn míì? Torí pé orí ìfẹ́ la gbé òfin Kristi kà, ó yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ máa buyì kún àwọn míì, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa rántí pé ìfẹ́ ni Kristi fẹ́ ká máa fi bá àwọn èèyàn lò.
21 Nínú ìdílé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn ọkọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó wọn “bí Kristi ti ń ṣe sí ìjọ.” (Éfé. 5:25, 28, 29) Irú ìfẹ́ tí Kristi ní ló yẹ káwọn ọkọ ní sáwọn ìyàwó wọn, kí wọ́n máa fi ire wọn ṣáájú tiwọn, ohun tí ìyàwó wọn nílò ló sì yẹ kó gbawájú. Àwọn ọkọ kan ò mọ bí wọ́n ṣe lè fìfẹ́ hàn bóyá torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà. Ó lè ṣòro fún wọn láti yíwà tó ti mọ́ wọn lára pa dà, àmọ́ ó di dandan kí wọ́n ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ tí wọ́n bá máa tẹ̀ lé òfin Kristi. Tí ọkọ kan bá ń fi irú ìfẹ́ tí Kristi ní hàn sí ìyàwó rẹ̀, ìyàwó náà á máa bọ̀wọ̀ fún un. Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dénú kò ní máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wọn, kò sì ní hùwà ìkà sí wọn. (Éfé. 4:31) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó máa fìfẹ́ hàn sí wọn, kó sì mọyì wọn. Èyí á mú kí ọkàn àwọn ọmọ náà balẹ̀ kára sì tù wọ́n. Ó dájú pé àwọn ọmọ náà máa nífẹ̀ẹ́ bàbá wọn, wọ́n á sì fọkàn tán an.
22. Ta ló làwọn “àgùntàn” tí 1 Pétérù 5:1-3 sọ, ọwọ́ wo ló sì yẹ káwọn alàgbà fi mú wọn?
22 Nínú ìjọ. Ó yẹ káwọn alàgbà máa rántí pé “àwọn àgùntàn,” ìyẹn àwọn ará ìjọ kì í ṣe tiwọn. (Jòh. 10:16; ka 1 Pétérù 5:1-3.) Gbólóhùn náà, “agbo Ọlọ́run,” “níwájú Ọlọ́run” àti “ogún Ọlọ́run” jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn alàgbà pé Jèhófà ló ni àwọn àgùntàn náà. Ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ló fẹ́ kí wọ́n fi máa mú agbo, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ bójú tó wọn. (1 Tẹs. 2:7, 8) Inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn alàgbà tó ń fìfẹ́ bójú tó agbo rẹ̀. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń mọyì àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn.
23-24. (a) Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? (b) Kí ló yẹ káwọn alàgbà fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń bójú tó irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀?
23 Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà tẹ́nì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? Ojúṣe wọn yàtọ̀ sí tàwọn onídàájọ́ àtàwọn àgbààgbà nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Nínú Òfin Mósè, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan làwọn tó wà nípò àṣẹ máa ń bójú tó, wọ́n tún máa ń bójú tó èdèkòyédè tó bá wáyé àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Àmọ́ ní ti òfin Kristi, ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn nìkan làwọn alàgbà láṣẹ láti bójú tó. Wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ìjọba nìkan ni Ọlọ́run gbà láyè láti bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Ìjọba ló sì láṣẹ láti fìyà tó tọ́ jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀, yálà kí wọ́n ní kó sanwó ìtanràn tàbí kí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n.—Róòmù 13:1-4.
24 Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì? Wọ́n máa ń lo Ìwé Mímọ́ láti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí wọ́n sì dórí ìpinnu. Bí wọ́n ṣe ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé orí ìfẹ́ la gbé òfin Kristi kà. Ìfẹ́ yìí lá mú káwọn alàgbà fẹ́ mọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tí wọ́n hùwà ìkà sí. Tí wọ́n bá sì fẹ́ bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó hùwà àìdáa náà, ìfẹ́ yìí kan náà lá mú káwọn alàgbà ronú lórí ìbéèrè bíi: Ǹjẹ́ ó ronú pìwà dà? Ṣé a lè ràn án lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
25. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
25 A mà dúpẹ́ o pé òfin Kristi ló ń darí wa! Tí gbogbo wa bá ń sa ipá wa láti tẹ̀ lé òfin yìí, ara máa tu gbogbo wa nínú ìjọ, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan á sì jọba. Bó ti wù kó rí, inú ayé tí “àwọn èèyàn burúkú” ti ń “burú sí i” là ń gbé. (2 Tím. 3:13) A ò gbọ́dọ̀ dẹra nù rárá. Kí ni ìjọ Ọlọ́run máa ṣe tẹ́nì kan bá bọ́mọdé ṣèṣekúṣe? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
a Àpilẹ̀kọ yìí àti méjì tó tẹ̀ lé e jẹ́ ara ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo. Kì í fẹ́ káwọn èèyàn inú ayé burúkú yìí fi ẹ̀tọ́ wa dù wá, tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, ó máa ń tu àwọn tó bá ṣẹlẹ̀ sí nínú.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nílẹ̀ Ísírẹ́lì Àtijọ́” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2019.
c ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ló máa ń jẹ́ ká fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Ìfẹ́ yìí máa ń mú ká fi àwọn nǹkan du ara wa torí àwọn míì, òun náà ló sì ń mú ká ran àwọn míì lọ́wọ́.
d ÀWÒRÁN: Jésù rí opó kan tó pàdánù ọmọ kan ṣoṣo tó ní. Àánú obìnrin náà ṣe Jésù, ó sì jí ọmọ náà dìde.
e ÀWÒRÁN: Jésù lọ jẹun nílé Farisí kan tó ń jẹ́ Símónì. Obìnrin kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣẹ́wó fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ Jésù, ó fi irun rẹ̀ nù ún, ó sì da òróró sí i lẹ́sẹ̀. Símónì ò fara mọ́ ohun tí obìnrin náà ṣe, àmọ́ Jésù gbèjà obìnrin náà.