-
‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
-
-
4. Àwọn wo ló ń bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run lóde òní, irú ẹ̀mí wo ló sì yẹ kí wọ́n máa fi bójú tó wọn?
4 Jésù Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn Jèhófà, ẹni tó di Orí ìjọ Kristẹni, ló mú ìlérí Ọlọ́run yìí ṣẹ ní pàtàkì. Ó lóun ni “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” tó ń fi ìyọ́nú bójú tó àwọn tó wà níkàáwọ́ rẹ̀. (Jòh. 10:11-15) Lóde òní, àwọn tí Jèhófà ń lò láti bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń sìn lábẹ́ Kristi, yálà àwọn ẹni àmì òróró ti ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni o tàbí àwọn alàgbà tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ látinú “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” (Ìṣí. 7:9) Bí Jésù ṣe fi gbogbo ara jin iṣẹ́ yìí làwọn náà ṣe máa ń gbìyànjú láti fi gbogbo ara wọn jin iṣẹ́ náà. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti bọ́ ìjọ, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀ bíi ti Kristi. Èyíkéyìí lára wọn tó bá pa àwọn arákùnrin rẹ̀ tì tàbí ó jẹ olúwa lé wọn lórí tàbí ó le koko mọ́ wọn tàbí ó ń fẹlá lé wọn lórí, gbé! (Mát. 20:25-27; 1 Pét. 5:2, 3) Kí ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ máa ṣe lóde òní? Nínú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ, kí la rí kọ́ nípa irú ìwà àti ẹ̀mí tó yẹ káwọn alàgbà ní bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ wọn? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àti olùpèsè ìrànwọ́, gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ nínú ìjọ àti láwọn ibòmíì àti gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́.
-
-
‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
-
-
6 Bíi tàwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran náà lọ̀rọ̀ àwọn alábòójútó ìjọ Kristẹni ṣe rí, wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àbójútó ìjọ. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ o máa ń wà lójúfò kó o lè rí àmì èyíkéyìí tó bá fi hàn pé ìnira ń bá àwọn ará kan, ṣé ó sì máa ń yá ọ lára láti tètè ràn wọ́n lọ́wọ́? Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Ó yẹ kí o mọ ìrísí agbo ẹran rẹ ní àmọ̀dunjú. Fi ọkàn-àyà rẹ sí àwọn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ.” (Òwe 27:23) Lóòótọ́, ṣe ni ẹsẹ yìí ń fi hàn pé ó dára gan-an kí olùṣọ́ àgùntàn jẹ́ aláápọn; síbẹ̀, a lè fi ṣàlàyé ọ̀nà tó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí tó wà nínú ìjọ máa gbà ṣe àbójútó ìjọ. Tó o bá jẹ́ alàgbà, ǹjẹ́ o ń sa gbogbo ipá rẹ láti rí i pé ò ń yàgò fún ẹ̀mí jíjẹ gàba lórí àwọn ará? Níwọ̀n bí Pétérù ti sọ̀rọ̀ nípa ‘jíjẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí,’ ìyẹn fi hàn pé ó ṣeé ṣe dáadáa kí alàgbà kan fẹ́ jẹ olúwa lé wọn lórí. Báwo lo ṣe máa wá ṣe ipa tìrẹ láti mú kí ohun tí Jeremáyà 33:12 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣeé ṣe? (Kà á.) Nígbà míì, òbí anìkantọ́mọ, opó, àwọn àgbàlagbà, ìdílé tí ọkọ tàbí aya ti lọ́mọ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ra, tàbí àwọn ọ̀dọ́, máa ń nílò àbójútó àti ìrànlọ́wọ́ àrà ọ̀tọ̀.
-