Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
“Gbogbo wọn kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?”—HÉB. 1:14.
1. Báwo ni Mátíù 18:10 àti Hébérù 1:14 ṣe tù wá nínú?
JÉSÙ KRISTI kìlọ̀ fún ẹnikẹ́ni tó lè fẹ́ mú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọsẹ̀ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 18:10) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́, ó ní: “Gbogbo wọn kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?” (Héb. 1:14) Ọ̀rọ̀ yìí tù wá nínú, torí ó mú kó dáwa lójú pé Ọlọ́run ń lo àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa àwọn áńgẹ́lì? Báwo ni wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Kí la lè rí kọ́ lára wọn?
2, 3. Kí ni díẹ̀ lára iṣẹ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run?
2 Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ló wà lọ́run. Gbogbo wọn ló “tóbi jọjọ nínú agbára, tí [wọ́n] ń pa ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run] mọ́.” (Sm. 103:20; ka Ìṣípayá 5:11.) Àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí yìí láwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ síra, wọ́n fìwà jọ Ọlọ́run, wọ́n sì lómìnira. Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ ni Jèhófà gbà ṣètò wọn, ipò gíga ni wọ́n sì wà nínú ètò Ọlọ́run. Máíkẹ́lì ni olú-áńgẹ́lì (ìyẹn orúkọ tí Jésù ń jẹ́ lọ́run). (Dán. 10:13; Júúdà 9) “Àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” yìí ni “Ọ̀rọ̀ náà,” tàbí Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run. Jèhófà sì lò ó láti dá gbogbo àwọn nǹkan tó kù.—Kól. 1:15-17; Jòh. 1:1-3.
3 Àwọn séráfù ló wà lábẹ́ olú-áńgẹ́lì, àwọn ló máa ń polongo pé mímọ́ ni Jèhófà, wọ́n sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti máa gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn kérúbù ló máa ń gbé ọlá ńlá Jèhófà ga. (Jẹ́n. 3:24; Isa. 6:1-3, 6, 7) Àwọn áńgẹ́lì yòókù tá a tún lè pè ní òjíṣẹ́, máa ń mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní onírúurú ọ̀nà.—Héb. 12:22, 23.
4. Nígbà tí Ọlọ́run fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, báwo ló ṣe rí lára àwọn áńgẹ́lì, kí sì ni ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní Ádámù àti Éfà lo òmìnira wọn lọ́nà tó dáa?
4 Gbogbo àwọn áńgẹ́lì yọ̀ nígbà tí Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀,” wọ́n sì fi ìdùnnú ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn láti mú kí ilẹ̀ ayé di ibùgbé àwa èèyàn. (Jóòbù 38:4, 7) Jèhófà dá èèyàn lọ́nà “rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì,” àmọ́ ó dá wa ní “àwòrán” ara rẹ̀, èyí ló mú ká lè fìwà jọ Ẹlẹ́dàá wa. (Héb. 2:7; Jẹ́n. 1:26) Ká ní Ádámù àti Éfà lo òmìnira wọn lọ́nà tó dáa ni, ńṣe làwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn ì bá máa gbádùn nínú Párádísè gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé Jèhófà ti àwọn ẹ̀dá onílàákàyè.
5, 6. Ọ̀tẹ̀ wo ló wáyé lọ́run, kí sì ni Ọlọ́run ṣe sí i?
5 Ó dájú pé inú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ á bà jẹ́ gidigidi nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nínú ìdílé Ọlọ́run. Kò tẹ́ ọ̀kan lára wọn lọ́rùn mọ́ pé kó máa yin Jèhófà, ńṣe ló fẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun. Ó sọ ara ẹ̀ di Sátánì (tó túmọ̀ sí “Alátakò”) nípa sísọ pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso, ó sì fẹ́ dá ìṣàkóso tiẹ̀ sílẹ̀. Sátánì lẹni àkọ́kọ́ tó parọ́ nínú Bíbélì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fọgbọ́n mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ ọn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́.—Jẹ́n. 3:4, 5; Jòh. 8:44.
6 Ojú ẹsẹ̀ ni Jèhófà ti ṣèdájọ́ Sátánì, nípa sísọ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ó ní: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́n. 3:15) Ìṣọ̀tá ò ní yéé wà láàárín Sátánì àti “obìnrin” Ọlọ́run. Jèhófà ka àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀ sí ìyàwó rẹ̀ ọ̀wọ́n. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fi hàn pé ìrètí tó dájú wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa rẹ̀ ṣì jẹ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀,” èyí tí Ọlọ́run á máa ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ni pé kí ẹnì kan lára apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀ pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ run, kí á sì kó “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” jọpọ̀ nípasẹ̀ ẹni yẹn.—Éfé. 1:8-10.
7. Kí làwọn áńgẹ́lì kan ṣe nígbà ayé Nóà, kí ni Jèhófà sì ṣe fún wọn?
7 Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì kan ò dúró ní “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” wọ́n sì gbé ẹran ara wọ̀ kí wọ́n lè wá máa ṣe bó ṣe wù wọ́n lórí ilẹ̀ ayé. (Júúdà 6; Jẹ́n. 6:1-4) Jèhófà sọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn sínú òkùnkùn biribiri, wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di “agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” àti ọ̀tá eléwu fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.—Éfé. 6:11-13; 2 Pét. 2:4.
Báwo Làwọn Áńgẹ́lì Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?
8, 9. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo àwọn áńgẹ́lì láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
8 Lára àwọn táwọn áńgẹ́lì ràn lọ́wọ́ ni Ábúráhámù, Jákọ́bù, Mósè, Jóṣúà, Aísáyà, Dáníẹ́lì, Jésù, Pétérù, Jòhánù àti Pọ́ọ̀lù. Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ, wọ́n sàsọtẹ́lẹ̀, wọ́n fàwọn ìtọ́ni jíṣẹ́, tó fi mọ́ Òfin Mósè. (2 Ọba 19:35; Dán. 10:5, 11, 14; Ìṣe 7:53; Ìṣí. 1:1) Ní báyìí tá a ti ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lódindi, ó lè má pọn dandan pé kí Ọlọ́run máa rán àwọn áńgẹ́lì láti jíṣẹ́ fún wa. (2 Tím. 3:16, 17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí àwọn áńgẹ́lì yìí, wọ́n ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ, wọ́n sì ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn.
9 Bíbélì fi dáwa lójú pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sm. 34:7; 91:11) Nítorí pé Sátánì sọ pé àwọn èèyàn ò ní sin Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n bá wà lábẹ́ àdánwò, Jèhófà gbà á láyé láti mú onírúurú àdánwò bá wa. (Lúùkù 21:16-19) Àmọ́ ṣá, nígbà àdánwò, Ọlọ́run mọ ibi tí agbára wa lè gbé e dé láti fi hàn pé a ó ṣì máa jẹ́ olóòótọ́ sí i. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Àwọn áńgẹ́lì wà ní sẹpẹ́ nígbàkigbà láti dá sí ọ̀rọ̀ wa níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n gba Ṣádírákì, Méṣákì, Àbẹ́dínígò, Dáníẹ́lì àti Pétérù lọ́wọ́ ikú, àmọ́ wọn ò ṣèdíwọ́ fáwọn ọ̀tá láti má ṣe pa Sítéfánù àti Jákọ́bù. (Dán. 3:17, 18, 28; 6:22; Ìṣe 7:59, 60; 12:1-3, 7, 11) Ipò táwọn nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀ àtàwọn nǹkan to ṣẹlẹ̀ yàtọ̀ síra. Bákan náà, wọ́n pa àwọn kan lára àwọn ará wa ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì, nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn là á já.
10. Láfikún sí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì, ìrànlọ́wọ́ wo la tún lè rí gbà?
10 Ìwé Mímọ́ ò kọ́ wa pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà láyé ló ní áńgẹ́lì kan tó ń dáàbò bò ó. Àmọ́, ó dá wa lójú pé “ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, [Ọlọ́run] ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòh. 5:14) Òótọ́ ni pé Jèhófà lè rán áńgẹ́lì kan láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ a tún lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́nà míì. Ọlọ́run lè fọwọ́ tọ́ ọkàn ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì tù wá nínú. Ọlọ́run lè fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá mú ká lè fara da ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ tó ń báwa fínra, tó mú kó dà bíi pé “áńgẹ́lì Sátánì” ń gbá wa lábàrá.—2 Kọ́r. 12:7-10; 1 Tẹs. 5:14.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
11. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ran Jésù lọ́wọ́, kí sì ni jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run fi hàn?
11 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe lo àwọn áńgẹ́lì nínú ọ̀ràn ti Jésù. Wọ́n kéde ìbí àti àjíǹde rẹ̀, wọ́n tún ṣe ìránṣẹ́ fún un nígbà tó wà láyé. Kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì ò lè dáàbò bo Jésù káwọn ọ̀tá má ṣe rí i mú, kí wọ́n sì gbà á lọ́wọ́ ikú oró. Àmọ́, ńṣe ni Jèhófà ní kí áńgẹ́lì kan lọ fún un lókun. (Mát. 28:5, 6; Lúùkù 2:8-11; 22:43) Níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà, Jésù kú ikú ìrúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀rí hàn pé ẹ̀dá èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka àdánwò lílekoko sí. Nítorí náà, Jèhófà jí Jésù dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀rún, ó fún un ní “gbogbo ọlá àṣẹ,” ó sì mú káwọn áńgẹ́lì wà lábẹ́ rẹ̀. (Mát. 28:18; Ìṣe 2:32; 1 Pét. 3:22) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ni olórí lára “irú ọmọ” “obìnrin” Ọlọ́run.—Jẹ́n. 3:15; Gál. 3:16.
12. Báwo ni Jésù ṣe lo ìyèkooro èrò inú, báwo sì la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
12 Jésù mọ̀ pé kò dáa kóun dán Jèhófà wò nípa fífi ẹ̀mí ara ẹ̀ wewu kó wá máa retí pé káwọn áńgẹ́lì gba òun. (Ka Mátíù 4:5-7.) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, nípa gbígbé ìgbé ayé wa pẹ̀lú “ìyèkooro èrò inú,” ká má máa fọwọ́ ara wa fa wàhálà, síbẹ̀ ká má ṣe mikàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa.—Títù 2:12.
Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Àwọn Áńgẹ́lì Olóòótọ́
13. Kí la lè rí kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì, bó ṣe wà nínú 2 Pét. 2:9-11?
13 Nígbà tí Pétérù ń bá àwọn kan wí, ìyẹn àwọn tó ń “sọ̀rọ̀” àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ẹni àmì òróró “tèébútèébú,” ó tọ́ka sí àpẹẹrẹ rere àwọn áńgẹ́lì olódodo. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì lágbára púpọ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọn kì í fẹ̀sùn kanni pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ èébú “nítorí ọ̀wọ̀ fún Jèhófà.” (Ka 2 Pétérù 2:9-11.) Ẹ jẹ́ káwa náà yẹra fún ṣíṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí kò tọ́, ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ, ká sì fi ìdájọ́ sílẹ̀ fún Jèhófà, Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ.—Róòmù 12:18, 19; Héb. 13:17.
14. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
14 Àpẹẹrẹ tó dáa làwọn áńgẹ́lì fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn. Àwọn áńgẹ́lì kan ò sọ orúkọ ara wọn fáwọn èèyàn. (Jẹ́n. 32:29; Oníd. 13:17, 18) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà lọ́run, Máíkẹ́lì àti Gébúrẹ́lì nìkan ni Bíbélì dárúkọ wọn. Èyí ò ní jẹ́ ká máa bọlá tí kò yẹ fáwọn áńgẹ́lì. (Lúùkù 1:26; Ìṣí. 12:7) Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù wólẹ̀ láti jọ́sìn áńgẹ́lì kan, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ.” (Ìṣí. 22:8, 9) Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan la sì gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí.—Ka Mátíù 4:8-10.
15. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀rọ̀ ká ní sùúrù?
15 Àwọn áńgẹ́lì tún fàpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa sùúrù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wù wọ́n gan-an láti mọ àwọn àṣírí ọlọ́wọ́ ti Ọlọ́run, síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ẹ̀ ni wọ́n mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Nǹkan wọ̀nyí gan-an ni àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wò ní àwòfín.” (1 Pét. 1:12) Kí ni wọ́n wá ṣe? Wọ́n fi sùúrù dúró de ìgbà tí “oríṣiríṣi ọgbọ́n” Ọlọ́run máa di mímọ̀ “nípasẹ̀ ìjọ.”—Éfé. 3:10, 11.
16. Ipa wo ni ìwà wa lè ní lórí àwọn áńgẹ́lì?
16 Àwọn Kristẹni tí wọ́n ń fara da àdánwò jẹ́ ‘ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún àwọn áńgẹ́lì.’ (1 Kọ́r. 4:9) Inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń kíyèsí ìwà títọ́ wa, wọ́n tiẹ̀ máa ń yọ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:10) Àwọn áńgẹ́lì ń kíyè sí bí àwọn Kristẹni obìnrin ṣe ń hùwà tínú Ọlọ́run dùn sí. Bíbélì sọ pé ó “yẹ kí obìnrin ní àmì ọlá àṣẹ ní orí rẹ̀ nítorí àwọn áńgẹ́lì.” (1 Kọ́r. 11:3, 10) Ó dájú pé inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn tí wọ́n bá rí àwọn Kristẹni obìnrin àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí. Ìránnilétí tó yẹ ni ṣíṣègbọràn lọ́nà bẹ́ẹ̀ jẹ́ fáwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí.
Àwọn Áńgẹ́lì Ń Fìtara Ṣètìlẹ́yìn fún Iṣẹ́ Ìwàásù
17, 18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
17 Àwọn áńgẹ́lì ń lọ́wọ́ nínú àwọn kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ń wáyé ní “ọjọ́ Olúwa.” Lára wọn ni, ìbí Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914 àti bí “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” ṣe lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. (Ìṣí. 1:10; 11:15; 12:5-9) Àpọ́sítélì Jòhánù rí “áńgẹ́lì [kan] tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé.” Áńgẹ́lì yẹn wá ké ní ohun rara pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣí. 14:6, 7) Èyí mú kó dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú pé àwọn áńgẹ́lì ń ti àwọn lẹ́yìn bí àwọn ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, láìkà àtakò gbígbóná janjan látọwọ́ Èṣù sí.—Ìṣí. 12:13, 17.
18 Lóde òní, àwọn áńgẹ́lì kì í darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa bíbá wa sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì kan ṣe bá Fílípì sọ̀rọ̀, tó sì darí ẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ìwẹ̀fà ara Etiópíà náà. (Ìṣe 8:26-29) Àmọ́ ṣá ó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí àwọn áńgẹ́lì, ọ̀pọ̀ ìrírí lóde òní ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”a (Ìṣe 13:48) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé, ká bàa lè ṣe ipa tiwa nínú wíwá àwọn tó ń fẹ́ láti “jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́” rí!—Jòh. 4:23, 24.
19, 20. Ipa wo làwọn áńgẹ́lì máa kó nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa sàmì sí “ìparí ètò àwọn nǹkan”?
19 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ wa, ó sọ pé “ní ìparí ètò àwọn nǹkan,” àwọn áńgẹ́lì máa “ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo.” (Mát. 13:37-43, 49) Àwọn áńgẹ́lì ń lọ́wọ́ nínú kíkó àwọn tó kù lára àwọn ẹni àmì òróró jọ àti nínú fifi èdìdì ìkẹyìn dì wọ́n. (Ka Mátíù 24:31; Ìṣí. 7:1-3) Síwájú sí i, àwọn áńgẹ́lì máa wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó bá “ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.”—Mát. 25:31-33, 46.
20 “Nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára,” gbogbo “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa” ló máa pa run. (2 Tẹs. 1:6-10) Nígbà tí Jòhánù rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà nínú ìran, ó ṣàpèjúwe Jésù àtàwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun ọ̀run bíi pé wọ́n gun ẹṣin funfun, kí wọ́n bàa lè máa jagun lọ ní òdodo.—Ìṣí. 19:11-14.
21. Kí ni áńgẹ́lì kan tó ní “kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀” máa ṣe fún Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀?
21 Jòhánù tún “rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀.” Ó dájú pé áńgẹ́lì yìí ni Máíkẹ́lì, olú-áńgẹ́lì, ẹni tó máa de Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, tó sì máa sọ wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. A máa tú wọn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí aráyé tó ti di pípé máa rí ìdánwò ìkẹyìn. Lẹ́yìn èyí, Jésù Kristi á wá pa Sátánì àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ tó kù run. (Ìṣí. 20:1-3, 7-10; 1 Jòh. 3:8) Nígbà yẹn, gbogbo àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ló máa dàwátì.
22. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe máa kópa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé láìpẹ́, kí ló sì yẹ ká máa ṣe nítorí èyí?
22 Ìdáǹdè pátápátá kúrò lọ́wọ́ ètò burúkú Sátánì ti dé tán. Àwọn áńgẹ́lì máa kópa pàtàkì nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó fakíki tó máa mú kí gbogbo èèyàn gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run, tó sì máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ nípa ayé àti èèyàn ṣẹ. Kò sí àní-àní pé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ jẹ́ “ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run fún bó ṣe ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ká sì lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 549 sí 551.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣètò àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run?
• Kí làwọn áńgẹ́lì kan ṣe nígbà ayé Nóà?
• Ọ̀nà wo ni Ọlọrun ti gbà lo àwọn áńgẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́?
• Ipa wo làwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ń kó lóde òní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Inú àwọn áńgẹ́lì ń dùn bí wọ́n ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì ṣe fi hàn, àwọn áńgẹ́lì wà ní sẹpẹ́ láti dá sí ọ̀rọ̀ wa níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọrun
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Má fòyà, torí pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run!
[Credit Line]
Àwòrán òbìrí ayé látọwọ́ NASA fọ́tò