Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Wa?
Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́, síbẹ̀ ìṣòro wọn ò yanjú. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà wọn ni? Rárá o! Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí wa tá a bá ń gbàdúrà sí i lọ́nà tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ.
ỌLỌ́RUN Ń GBỌ́.
“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn yóò wá.”—Sáàmù 65:2.
Àwọn kan máa ń gbàdúrà torí wọ́n gbà pé àdúrà máa ń mú kára àwọn yá gágá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbà pé ẹnì kan wà níbì kan tó jẹ́ olùgbọ́ àdúrà. Àmọ́ àdúrà kọjá pé kó kàn mára tuni nígbà ìṣòro. Bíbélì fi dá wa lójú pé “Jèhófàa wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́. . . . Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”—Sáàmù 145:18, 19.
Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà àwọn tó ń sìn ín. Ó fìfẹ́ sọ fún wa pé: “Ẹ ó pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, màá sì fetí sí yín.”—Jeremáyà 29:12.
ỌLỌ́RUN FẸ́ KÓ O MÁA GBÀDÚRÀ SÍ ÒUN.
“Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.”—Róòmù 12:12.
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” Ó hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun.—Mátíù 26:41; Éfésù 6:18.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun? Rò ó wò ná: Inú bàbá wo ni kì í dùn tí ọmọ ẹ̀ bá sọ pé, “Dádì, ẹ jọ̀ọ́, ẹ ràn mí lọ́wọ́”? Ó dájú pé bàbá náà ti lè mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ nílò tàbí ohun tó fẹ́, àmọ́ tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu ọmọ náà, ìyẹn á fi hàn pé ọmọ náà gbẹ́kẹ̀ lé bàbá rẹ̀, wọ́n sì sún mọ́ra. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, ìyẹn á fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e, a sì fẹ́ sún mọ́ ọn.—Òwe 15:8; Jémíìsì 4:8.
ỌLỌ́RUN Ń BÓJÚ TÓ Ẹ.
“Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”—1 Pétérù 5:7.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun torí ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. Ó mọ ìṣòro wa àtàwọn àníyàn tó wà lọ́kàn wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́.
Ọba Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì sọ èrò àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un. (Sáàmù 23:1-6) Kí ni Ọlọ́run rò nípa Dáfídì? Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, ó sì gbọ́ àwọn àdúrà rẹ̀. (Ìṣe 13:22) Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.
“MO NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ NÍTORÍ Ó Ń GBỌ́ OHÙN MI”
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù inú Bíbélì ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà rẹ̀, ìyẹn sì ti ràn án lọ́wọ́ gan-an. Ó ti mu kó sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì rí okun gbà tó fi lè borí àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀.—Sáàmù 116:1-9.
Tó bá dá wa lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa, àá máa gbàdúrà sí i nígbà gbogbo. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pedro tó ń gbé àríwá Sípéènì. Ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) kú nínú jàǹbá ọkọ̀. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni Pedro fi sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run, ó sì tẹra mọ́ àdúrà kó lè rí ìtùnú àti ìtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Pedro sọ pé: “Jèhófà dáhùn àdúrà mi torí ó lo ìyàwó mi àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni láti tù mí nínú, kí wọ́n sì tì mí lẹ́yìn.”
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àdúrà kò lè jí ọmọ náà dìde, àmọ́ ó ran Pedro àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ gan-an. Ìyàwó rẹ̀, María Carmen, sọ pé: “Àdúrà jẹ́ kí n fara dà á nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run mọ bó ṣe ń ṣe mí, torí nígbà tí mo gbàdúrà sí i, ara tù mí ọkàn mi sì balẹ̀.”
Ohun tá a rí nínú Bíbélì àti ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn fi hàn kedere pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà. Síbẹ̀, ó hàn gbangba pé kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń gbọ́ àwọn àdúrà kan, àmọ́ tí kì í gbọ́ àwọn àdúrà míì?
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.