Ẹ Fi Iduroṣinṣin Ṣiṣẹsin Jehofa
“Fun ẹni iduroṣinṣin ni òdodo ni iwọ [Jehofa] ó fi ara rẹ hàn ni iduroṣinṣin ni òdodo.”—2 SAMUELI 22:26.
1. Bawo ni Jehofa ṣe ń huwa si awọn wọnni ti wọn jẹ aduroṣinṣin sí i?
AKÒ le san asanpada fun Jehofa fun gbogbo ohun ti o ti ṣe fun awọn eniyan rẹ̀. (Orin Dafidi 116:12) Ẹ wo bi awọn ẹbun rẹ̀ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara ati aanu onijẹlẹnkẹ rẹ̀ ti jẹ agbayanu tó! Ọba Dafidi ti Israeli igbaani mọ̀ pe Ọlọrun tun ń huwa ni iduroṣinṣin pẹlu awọn ti wọn fi iduroṣinṣin hàn si i. Dafidi sọ bẹẹ ninu orin kan ti o kojọ “ni ọjọ ti Oluwa gbà á kuro ni ọwọ́ gbogbo awọn ọ̀tá rẹ̀, ati kuro ni ọwọ [Ọba] Saulu.”—2 Samueli 22:1.
2. Ki ni diẹ lara awọn koko tí orin Dafidi ti a ṣe akọsilẹ rẹ̀ ni 2 Samueli ori 22 gbekalẹ?
2 Dafidi bẹrẹ orin rẹ̀ (eyi ti o wà ni ibaradọgba pẹlu Orin Dafidi 18) nipa yíyin Jehofa gẹgẹ bi “olugbala” ni idahun si adura. (2 Samueli 22:2-7) Lati tẹmpili rẹ̀ ni ọrun, Ọlọrun gbegbeesẹ lati dá awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin nídè kuro lọwọ awọn ọ̀tá alagbara nla. (Ẹsẹ 8-19) Dafidi ni a tipa bayii san lẹsan rere fun lilepa ipa-ọna diduroṣanṣan ati pípa awọn ọ̀nà Jehofa mọ́. (Ẹsẹ 20-27) Lẹhin naa ni o ṣe ilalẹsẹẹsẹ awọn iṣẹ ti o ṣeeṣe pẹlu okun ti Ọlọrun fifunni. (Ẹsẹ 28-43) Nikẹhin, Dafidi tọkasi ìdáǹdè kuro lọwọ awọn alariiwisi ni ile ati awọn ọ̀tá lati orilẹ-ede miiran o si fi ọpẹ́ fun Jehofa gẹgẹ bii “ile-iṣọ igbala fun ọba rẹ: o si fi aanu han fun ẹni-ami-ororo rẹ̀.” (Ẹsẹ 44-51) Jehofa le dá wa nídè bakan naa bi a ba lepa ipa-ọna iduroṣanṣan ti a si gbarale e fun okun.
Ohun Ti O Tumọsi Lati Jẹ Aduroṣinṣin
3. Lati oju-iwoye Iwe Mimọ, ki ni o tumọsi lati jẹ aduroṣinṣin?
3 Orin idande Dafidi fun wa ni idaniloju onitunu yii: “Fun ẹni iduroṣinṣin ni òdodo ni iwọ [Jehofa] ó fi ara rẹ hàn ni iduroṣinṣin ni òdodo.” (2 Samueli 22:26) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé Heberu naa cha·sidhʹ ni o tumọ ni ipilẹ si “ẹni diduroṣinṣin,” tabi “ẹni iṣeun-ifẹ.” (Orin Dafidi 18:25, akiyesi ẹsẹ iwe) Ọ̀rọ̀ orukọ naa cheʹsedh ni ero naa inurere ti o fi ifẹ so araarẹ̀ pọ̀ mọ́ ohun ti o ṣeefojuri kan titi di ìgbà ti ète rẹ̀ ni isopọ pẹlu iyẹn bá ni imuṣẹ ninu. Jehofa fi iru inurere bẹẹ hàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀, àní gan-an bi wọn ti fi í hàn si i. Iduroṣinṣin olódodo, mimọ yii ni a ṣetumọ si “iṣeun-ifẹ” ati “ifẹ aduroṣinṣin.” (Genesisi 20:13; 21:23, NW) Ninu Iwe Mimọ lede Griki, “iduroṣinṣin” gbe ero ijẹmimọ ati ọwọ jijinlẹ, ti a sọjade ninu ọ̀rọ̀ orukọ naa ho·si·oʹtes ati ọ̀rọ̀ ajuwe naa hoʹsi·os jade. Iru iduroṣinṣin bẹẹ ni ninu iṣotitọ ati ifọkansin ti o si tumọsi jijẹ olufọkansin ti ń fi tiṣọratiṣọra bojuto gbogbo ila-iṣẹ siha Ọlọrun. Lati jẹ aduroṣinṣin si Jehofa tumọsi lati tòròmọ́ ọ pẹlu ifọkansin ti o lagbara tobẹẹ ti o fi dabii àtè lilagbara.
4. Bawo ni Jehofa ṣe fi iduroṣinṣin rẹ̀ hàn?
4 Iduroṣinṣin ti Jehofa ni a fihàn ni ọpọ ọ̀nà. Fun apẹẹrẹ, ó gbé igbesẹ idajọ lodisi awọn ẹni buruku nitori ifẹ aduroṣinṣin fun awọn eniyan rẹ̀ ati iduroṣinṣin fun idajọ-ododo ati ododo. (Ìfihàn 15:3, 4; 16:5) Iduroṣinṣin rẹ̀ fun majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu sun un lati ni ipamọra siha awọn ọmọ Israeli. (2 Ọba 13:23) Awọn wọnni ti wọn duroṣinṣin si Ọlọrun le gbarale iranlọwọ rẹ̀ titi de opin ipa-ọna iduroṣinṣin wọn wọn si lè ni idaniloju pe oun yoo ranti wọn. (Orin Dafidi 37:27, 28; 97:10) Jesu ni a fun lokun nipasẹ imọ naa pe gẹgẹ bi olu-olori “ẹni iduroṣinṣin” fun Ọlọrun, ọkàn rẹ̀ ni a kì yoo fi silẹ ni ipo-oku.—Orin Dafidi 16:10; Iṣe 2:25, 27.
5. Niwọn bi Jehofa ti jẹ aduroṣinṣin, ki ni ohun ti o beere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn ibeere wo ni a o sì gbeyẹwo?
5 Niwọn bi Jehofa Ọlọrun ti jẹ aduroṣinṣin, o beere iduroṣinṣin lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀. (Efesu 4:24) Fun apẹẹrẹ, awọn ọkunrin nilati jẹ aduroṣinṣin ki wọn tó le tootun fun iyansipo bi alagba ninu ijọ. (Titu 1:8) Ki ni awọn kókó abajọ ti o gbọdọ sun awọn eniyan Jehofa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin in?
Imọriri fun Awọn Ohun Ti A Ti Kọ́
6. Bawo ni o ṣe yẹ ki a nimọlara nipa awọn ohun ti a ti kọ́ lati inu Iwe Mimọ, ki ni o si yẹ ki a ranti nipa iru ìmọ̀ bẹẹ?
6 Imoore fun awọn ohun ti o bá Iwe Mimọ mu ti a ti kọ́ gbọdọ sun wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa. Aposteli Paulu rọ Timoteu pe: “Duro ninu nǹkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ da ṣáṣá si, ki iwọ ki o si mọ ọ̀dọ̀ ẹni ti iwọ gbe kọ́ wọn; ati pe lati ìgbà ọmọde ni iwọ ti mọ iwe-mimọ, ti o lè sọ ọ́ di ọlọgbọn si igbala nipasẹ igbagbọ ninu Kristi Jesu.” (2 Timoteu 3:14, 15) Ranti pe iru ìmọ̀ bẹẹ wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa.”—Matteu 24:45-47, NW.
7. Bawo ni o ṣe yẹ ki awọn alagba nimọlara nipa ounjẹ tẹmi ti Ọlọrun ń pese nipasẹ ẹrú oluṣotitọ naa?
7 Awọn alagba ti a yansipo paapaa ni pataki gbọdọ mọriri ounjẹ tẹmi ti ń gbeniro ti Ọlọrun pese nipasẹ ẹrú oluṣotitọ naa. Ni awọn ọdun diẹ sẹhin awọn alagba melookan ṣaini iru imọriri bẹẹ. Oluṣkiyesi kan kiyesi pe awọn ọkunrin wọnyi “ń ṣe lameyitọ awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ninu Ilé-Ìṣọ́nà, laifẹ tẹwọgba a gẹgẹ bii . . . ipa-oju ọna otitọ ti Ọlọrun, ni gbígbiyanju nigba gbogbo lati lo agbara idari lori awọn ẹlomiran ninu ọ̀nà igbaronu wọn.” Bi o ti wu ki o ri, awọn alagba aduroṣinṣin kìí gbiyanju lae lati lo agbara idari lori awọn ẹlomiran lati ṣá ounjẹ tẹmi eyikeyii ti Ọlọrun pese nipasẹ ẹrú oluṣotitọ naa tì.
8. Ki ni bi a kò bá ní ẹkunrere òye nipa awọn koko kan ti a gbekari Iwe Mimọ ti ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa gbekalẹ?
8 Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ fun Jehofa, gbogbo wa gbọdọ jẹ́ aduroṣinṣin si i ati si eto-ajọ rẹ̀. A kò nilati gbèròwò lae lati yipada kuro ninu ìmọ́lẹ̀ agbayanu ti Ọlọrun, ni lilepa ipa-ọna ipẹhinda ti ó lè ṣamọna si iku nipa tẹmi nisinsinyi ati iparun lẹhin-ọ-rẹhin. (Jeremiah 17:13) Ṣugbọn ki a sọ pe ó nira fun wa lati tẹwọgba tabi lóye ni kikun awọn koko kan ti a gbekari Iwe Mimọ ti a pese nipasẹ ẹrú oluṣotitọ naa ń kọ́? Nigba naa ẹ jẹ ki a fi irẹlẹ fi ọpẹ́ hàn fun ibi ti a ti kẹkọọ otitọ naa ki a sì gbadura fun ọgbọ́n lati bá adanwo yii lò titi ti yoo fi dopin nipasẹ alaye imuṣekedere ti a tẹjade lori awọn naa.—Jakọbu 1:5-8.
Mọriri Ẹgbẹ́-ará Awọn Kristian Wa
9. Bawo ni 1 Johannu 1:3-6 ṣe fihàn pe awọn Kristian gbọdọ ni ẹmi ifararora?
9 Imọriri atọkanwa fun ẹmi ifararora ti o wa laaarin ẹgbẹ́-ara awọn Kristian wa pese isunniṣe miiran lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa. Niti tootọ, ibatan wa pẹlu Ọlọrun ati Kristi kò lè lagbara nipa tẹmi laisi ẹmi yii. Aposteli Johannu sọ fun awọn Kristian ẹni-ami-ororo pe: “Eyi ti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ ni awa ń sọ fun yin, ki ẹyin pẹlu ki o lè ni idapọ [“ifararora,” Diaglott] pẹlu wa: nitootọ idapọ wa sì ń bẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Awa si kọwe nǹkan wọnyi si yin, ki ayọ yin ki o le di kikun. Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si ń jẹ fun yin, pe imọlẹ ni Ọlọrun, okunkun ko sì sí lọdọ rẹ̀ rara. Bi awa bá wi pe awa ni idapọ pẹlu rẹ̀, ti awa sì ń rìn ninu okunkun, awa ń ṣeke, awa kò si ṣe otitọ.” (1 Johannu 1:3-6) Ilana yii ṣeefisilo fun gbogbo awọn Kristian, yala ireti wọn jẹ ti ọrun tabi ti ori ilẹ̀-ayé.
10. Bi o tilẹ hàn gbangba pe Euodia ati Sintike ni iṣoro ni yiyanju ọran-iṣoro ara-ẹni kan, oju wo ni Paulu fi wo awọn obinrin wọnyi?
10 Isapa ni a nilo lati mú ki ẹmi ifararora wà titi. Fun apẹẹrẹ, awọn obinrin Kristian naa Euodia ati Sintike ni ó hàn gbangba pe wọn ri i bi ohun ti o ṣoro lati yanju ọran-iṣoro kan laaarin araawọn. Paulu nipa bayii gbà wọn niyanju lati “ni inu kan-naa ninu Oluwa.” O fikun un pe: “Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alájọru-àjàgà mi tootọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori wọn ń ba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti ń bẹ ninu iwe ìyè.” (Filippi 4:2, 3) Awọn obinrin oniwa-bi-Ọlọrun wọnni ti jà ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Paulu ati awọn miiran “ninu ihinrere,” ó sì dá a loju pe wọn wà lara awọn wọnni ‘ti orukọ wọn ń bẹ ninu iwe ìyè.’
11. Bi Kristian aduroṣinṣin kan bá dojukọ ọran-iṣoro nipa tẹmi, ki ni yoo bọgbọnmu lati fi sọkan?
11 Awọn Kristian kìí wọ àmì-oyè lati fi ohun ti wọn ti ni anfaani lati ṣe ninu eto-ajọ Jehofa ati bi wọn ti ṣe ri ṣiṣẹsin in iduroṣinṣin hàn. Bi wọn bá ni ọran-iṣoro nipa tẹmi, ẹ wo bi yoo ti jẹ alainifẹẹ tó lati ṣaifiyesi ọpọ ọdun iṣẹ-isin oniduroṣinṣin wọn si Jehofa! O ṣeeṣe, ki ó jẹ pe eyi ti ó pè ni “alájọru-àjàgà tootọ” jẹ arakunrin aduroṣinṣin ti o ń haragaga lati ṣeranwọ fun awọn ẹlomiran. Bi iwọ ba jẹ alagba kan, iwọ ha jẹ “alájọru-àjàgà tootọ,” ti o ṣetan lati funni ni iranlọwọ ni ọ̀nà oníyọọ́nú bi? Ǹjẹ́ ki gbogbo wa gbé rere ti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ti ṣe yẹwo, àní bi Ọlọrun ti ṣe, ki a si fi tifẹtifẹ ràn wọ́n lọwọ lati gbé awọn ẹrù-ìnira wọn.—Galatia 6:2; Heberu 6:10.
Kò Si Ibomiran Kankan Lati Lọ
12. Nigba ti ọ̀rọ̀ Jesu mú ki ‘ọpọ awọn ọmọ-ẹhin pada sẹhin,’ iduro wo ni Peteru mú?
12 A o sún wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu eto-ajọ rẹ̀ bi a ba ranti pe ko si ibomiran kankan lati lọ fun ìyè ayeraye. Nigba ti ọ̀rọ̀ Jesu mú ki ‘ọpọ awọn ọmọ-ẹhin pada sẹhin,’ o beere lọwọ awọn aposteli rẹ̀ pe: “Ẹyin pẹlu ń fẹ lọ bi?” Peteru fesipada pe: “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni awa ó lọ? iwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun. Awa si ti gbagbọ, a sì mọ pe, iwọ ni Kristi naa, Ọmọ Ọlọrun alaaye.”—Johannu 6:66-69.
13, 14. (a) Eeṣe ti isin Ju ọrundun kìn-ín-ní fi kuna ojurere Ọlọrun? (b) Ki ni ohun ti Ẹlẹ́rìí ọlọjọ pipẹ fun Jehofa kan sọ nipa eto-ajọ Ọlọrun ti o ṣeefojuri?
13 “Ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun” ni wọn kò rí ninu isin Ju ti ọrundun kìn-ín-ní Sanmani Tiwa. Olori ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni ṣíṣá Jesu tì gẹgẹ bii Messia naa. Kò si eyikeyii ninu awọn apá ti isin Ju pín si ti a gbekari Iwe Mimọ Lede Heberu patapata. Awọn Sadusi sẹ́ wiwa awọn angeli wọn kò si gbagbọ ninu ajinde. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Farisi kò fohunṣọkan pẹlu wọn lori eyi, wọn sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun di alailẹṣẹnilẹ lọna ti o kun fun ẹ̀ṣẹ̀ nitori awọn ẹ̀kọ́ atọwọdọwọ wọn tí kò bá iwe mimọ mu. (Matteu 15:1-11; Iṣe 23:6-9) Awọn ẹ̀kọ́ atọwọdọwọ wọnyi sọ awọn Ju di ẹrú ó sì mu ki o ṣoro fun ọpọ lati tẹwọgba Jesu Kristi. (Kolosse 2:8) Itara fun ‘ẹ̀kọ́ atọwọdọwọ awọn baba rẹ̀’ mú ki Saulu (Paulu) ninu aimọkan rẹ̀ ṣe inunibini rírorò si awọn ọmọlẹhin Kristi.—Galatia 1:13, 14, 23.
14 Isin Ju kuna ojurere Ọlọrun, ṣugbọn Jehofa bukun eto-ajọ naa ti o ni ninu awọn ọmọlẹhin Ọmọkunrin rẹ̀—“awọn onitara iṣẹ rere.” (Titu 2:14) Eto-ajọ yẹn ṣì wa sibẹ, ati nipa rẹ̀ Ẹlẹ́rìí fun Jehofa ọlọjọ pipẹ kan sọ pe: “Bi ohun kan bá wà ti ó ṣe pataki fun mi julọ, o ti jẹ́ ọ̀ràn wíwà timọtimọ pẹlu eto-ajọ Jehofa ti o ṣeefojuri. Iriri mi akọkọbẹrẹ ti kọ́ mi bi o ti jẹ alaiyekooro tó lati gbarale ironu ẹda eniyan. Ni kete ti ọkan mi ti de ori ipinnu lori koko yẹn, mo pinnu lati duro ti eto-ajọ oluṣotitọ naa. Ọ̀nà wo tun ni ẹnikan le gba ni ojurere ati ibukun Jehofa?” Ko si ibomiran lati lọ fun ojurere atọrunwa ati ìyè ayeraye.
15. Eeṣe ti a fi nilati fọwọsowọpọ pẹlu eto-ajọ Jehofa ti o ṣeefojuri ati awọn ti wọn ń bojuto ẹrù-iṣẹ́ ninu rẹ̀?
15 Ọkan-aya wa gbọdọ sún wa lati fọwọsowọpọ pẹlu eto-ajọ Jehofa nitori pe a mọ̀ pe oun nikanṣoṣo ni ẹmi rẹ̀ ń dari ti o si ń sọ orukọ ati awọn ète rẹ̀ di mímọ̀. Dajudaju nitootọ, awọn ti wọn ń bojuto ẹrù-iṣẹ́ ninu rẹ̀ jẹ alaipe. (Romu 5:12) Ṣugbọn “ibinu Oluwa si ru” lodisi Aaroni ati Miriamu nigba ti wọn bá Mose ṣe awuyewuye ti wọn si gbagbe pe oun, kìí ṣe awọn, ni a fi ẹrù-iṣẹ́ ti Ọlọrun fifunni si ni ikawọ. (Numeri 12:7-9) Lonii, awọn Kristian aduroṣinṣin ń fọwọsowọpọ pẹlu “awọn ti wọn ń mu ipo iwaju” nitori eyi ni ohun ti Jehofa beere fun. (Heberu 13:7, 17) Ẹ̀rì iduroṣinṣin wa ni ninu pipesẹ si awọn ipade Kristian deedee ati sisọ awọn ọ̀rọ̀ ilohunsi ti ‘ń ru awọn ẹlomiran si ifẹ ati si iṣẹ rere.’—Heberu 10:24, 25.
Ẹ Maa Gbeniro
16. Ìfẹ́-ọkàn lati ṣe ki ni fun awọn ẹlomiran ni o tun nilati sun wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa?
16 Ìfẹ́-ọkàn lati maa gbe awọn ẹlomiran ro nilati sún wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa. Paulu kọwe pe: “Ìmọ̀ a maa fẹ̀, ṣugbọn ifẹ nii gbeniro.” (1 Korinti 8:1) Niwọn bi iru ìmọ̀ kan ti ń mu ki awọn ti o ní in maa fẹ̀, Paulu ti gbọdọ ni in lọkan pe ifẹ tun ń gbe awọn wọnni ti wọn ń fi animọ yẹn hàn ró. Iwe kan lati ọwọ́ awọn Ọjọgbọn Weiss ati English sọ pe: “Ẹni naa ti o ni agbara lati nifẹẹ ni a sábà maa ń nifẹẹ ni isanpada. Agbara naa lati nawọ inurere ati igbatẹniro si gbogbo apa-iha igbesi-aye . . . ní iyọrisi ṣiṣanfaani kan ti ó hàn ketekete lori ẹni naa ti o nawọ iru imọlara bẹẹ síni ati bakan naa lori ẹni naa ti o gba wọn ó sì tipa bayii mu idunnu wa fun awọn mejeeji.” Nipa fifi ifẹ han, a ń gbe awọn ẹlomiran ati ara tiwa funraawa ró, gẹgẹ bi Jesu ti pẹ́ ẹ sọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe: “Ati funni o ni ibukun ju ati gba lọ.”—Iṣe 20:35.
17. Bawo ni ifẹ ṣe ń gbeniro, ki ni yoo si ṣediwọ fun wa lati ṣe?
17 Ni 1 Korinti 8:1, Paulu lo ọ̀rọ̀ Griki naa a·gaʹpe, ti o tumọ ni ipilẹ si ifẹ ti a gbekari ilana. O ń gbeniro, nitori ti o ni ipamọra o si ni inurere, o ń mu ohun gbogbo mọra, o si ń farada ohun gbogbo, kìí sìí kuna. Ifẹ yii ń mu ero-imọlara òdì ti ń panirun kuro, iru bii igberaga ati owú. (1 Korinti 13:4-8) Iru ifẹ bẹẹ yoo fà wá sẹhin kuro ninu ríráhùn nipa awọn arakunrin wa, ti wọn jẹ alaipe bii tiwa. Yoo ṣedilọwọ fun wa lodisi didabii “awọn alaiwa-bi-Ọlọrun” ti wọn “ń yọ́ wọle” laaarin awọn Kristian tootọ ti ọrundun kìn-ín-ní. Awọn ọkunrin wọnyi “ń gan ijoye, wọn sì ń sọrọ buburu si awọn ọlọla,” o ṣe kedere pe wọn ń ṣe keeta ọkàn si awọn ẹnikọọkan bii awọn Kristian ẹni-ami-ororo alaboojuto ti a ti fi iru ògo kan pàtó dálọ́lá. (Juda 3, 4, 8) Ni iduroṣinṣin si Jehofa, ẹ maṣe jẹ ki a juwọsilẹ lae fun idẹwo eyikeyii lati ṣe ohunkohun ti o jọ bẹẹ.
Ẹ Kọjú Ìjà si Eṣu!
18. Ki ni Satani yoo fẹ lati ṣe fun awọn eniyan Jehofa, ṣugbọn eeṣe ti oun kò fi ni le ṣe bẹẹ?
18 Ìmọ̀ pe Satani ń fẹ lati pa iṣọkan wa run gẹgẹ bi awọn eniyan Ọlọrun nilati fikun igberopinnu wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa. Satani yoo tilẹ fẹ lati fopin si iwalaaye gbogbo awọn eniyan Ọlọrun, awọn iranṣẹ Eṣu lori ilẹ̀-ayé nigba miiran sì maa ń pa awọn olujọsin tootọ. Ṣugbọn Ọlọrun kì yoo yọnda ki Satani nu gbogbo wọn nù kuro. Jesu ku lati “ti ipa iku pa ẹni ti o ni agbara iku run, eyiini ni Eṣu.” (Heberu 2:14) Ni pataki ni a ti pààlà si ilẹ-akoso Satani fun lilo agbara lati ìgbà ti a ti le e jade kuro ni ọrun lẹhin ti Kristi ti di Ọba ni 1914. Ati ni akoko ti o yẹ loju Jehofa, Jesu yoo pa Satani ati eto-ajọ rẹ̀ run.
19. (a) Ikilọ wo nipa isapa Satani ni iwe agberohinjade yii pese ni ọpọ ọdun sẹhin? (b) Lati yẹra fun idẹkun Satani, iṣọra wo ni a nilati mulo ni biba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa lo?
19 Iwe agberohinjade yii kilọ nigba kan pe: “Bi Satan, eṣu, bá le ṣokunfa rudurudu laaarin awọn eniyan Ọlọrun, ti o lè fà á ki wọn ni aáwọ̀ ati ìjà laaarin araawọn, tabi lati fihàn ki wọn si mú itẹsi ifẹ-inu onimọtara-ẹni-nikan ti ó lè ṣamọna si iparun ifẹ fun ará dagba, oun yoo tipa bayii ṣaṣeyọri ni jijẹ wọn raurau.” (Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1921, oju-iwe 134, [Gẹẹsi]) Ẹ maṣe jẹ ki a yọnda fun Eṣu lati pa iṣọkan wa run, boya nipa rírọ̀ wa lọkan lati fọ̀rọ̀ èké banijẹ, tabi bá ẹnikinni keji ja. (Lefitiku 19:16) Ǹjẹ́ ki Satani maṣe tú wa jẹ ni iru ọ̀nà kan ti a o fi ṣepalara ara-ẹni fun awọn wọnni ti wọn ń fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa tabi mú ki ayé tubọ lekoko fun wọn. (Fiwe 2 Korinti 2:10, 11.) Kaka bẹẹ, ẹ jẹ ki a fi ọ̀rọ̀ Peteru silo pe: “Ẹ maa wa ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọ̀tá yin, bii kinniun ti ń ke ramuramu, ó ń rin kaakiri, o ń wa ẹni ti yoo pajẹ kiri: ẹni ti ki ẹyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ.” (1 Peteru 5:8, 9) Nipa mimu iduro gbọnyin lodisi Satani, a lè di iṣọkan onibukun wa mú bi awọn eniyan Jehofa.—Orin Dafidi 133:1-3.
Ẹ Fi Taduratadura Gbarale Ọlọrun
20, 21. Bawo ni gbigbọkanle Jehofa taduratadura ṣe tan mọ́ fi iduroṣinṣin ṣiṣiṣẹsin in?
20 Gbigbarale Ọlọrun taduratadura yoo ran wa lọwọ lati maa baa lọ ni fifi iduroṣinṣin ṣiṣiṣẹsin Jehofa. Nigba ti a bá ri i pe o ń dahun awọn adura wa, a tubọ ń fa wa sunmọ ọ. Gbigbarale Jehofa Ọlọrun taduratadura ni aposteli Paulu damọran nigba ti o kọwe pe: “Mo fẹ ki awọn ọkunrin maa gbadura nibi gbogbo, ki wọn maa gbe ọwọ́ mímọ́ soke, ni aibinu ati ni aijiyan.” (1 Timoteu 2:8) Fun apẹẹrẹ, ẹ wo bi o ti ṣe pataki tó pe ki awọn alagba maa gbarale Ọlọrun taduratadura! Fifi iduroṣinṣin hàn si Jehofa lọna bẹẹ nigba ti wọn bá pade lati jiroro awọn ọ̀ràn ti o jẹmọ ijọ yoo ṣeranwọ lati ṣediwọ fun awọn ijiyan alailopin ati ìbújáde ìrunú ti o ṣeeṣe.
21 Gbigbarale Jehofa Ọlọrun taduratadura ń ràn wá lọwọ lati bojuto awọn anfaani ninu iṣẹ-isin rẹ̀. Ọkunrin kan ti o ti fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa fun ọpọ ẹwadun le sọ pe: “Fifi imuratan tẹwọgba iṣẹ-ayanfunni eyikeyii tí a bá fun wa ninu eto-ajọ Ọlọrun kari-aye, ati diduro sibi ti a yàn wá sí, laiyẹsẹ, ń mu ẹrin musẹ itẹwọgba Ọlọrun wá sori awọn isapa onifọkansi wa. Koda bi iṣẹ naa ba jọ bi alainilaari, ó sábà maa ń yọrisi pe bi a kò bá fi iṣotitọ mú un ṣẹ ni kikun ọpọ awọn iṣẹ-isin ṣiṣekoko miiran ni a ko ni le ṣe. Nipa bayii bi a ba jẹ onirẹlẹ ti a sì lọ́kàn ifẹ taarata ninu ṣiṣe orukọ Jehofa logo ti kìí sìí ṣe tiwa funraawa, nigba naa a le ni idaniloju pe awa yoo ‘maa duroṣinṣin, laiyẹsẹ, a o maa ṣe pupọ sii ninu iṣẹ Oluwa nigbagbogbo.’”—1 Korinti 15:58.
22. Bawo ni ọpọ awọn ibukun Jehofa ṣe yẹ ki o nipa lori iduroṣinṣin wa?
22 Laika ohun yoowu ti a ba ṣe ninu iṣẹ-isin Jehofa si, dajudaju, a ko le san asanpada fun un fun awọn ohun ti o ṣe fun wa. Ẹ wo bi a ti wà lailewu tó ninu eto-ajọ Ọlọrun, tí awọn ọ̀rẹ́ Ọlọrun rọ̀gbà yi wa ka! (Jakọbu 2:23) Jehofa ti fi iṣọkan ti o ń rúyọ lati inu ifẹ ará ti o ta gbongbo jinlẹ bukun wa ti o fi jẹ pe Satani funraarẹ ko le fà á tu. Nigba naa ẹ jẹ ki a tòròmọ́ Baba wa ọrun aduroṣinṣin ki a si ṣiṣẹ papọ gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ̀. Nisinsinyi ati titilae, ẹ jẹ ki a fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni o tumọsi lati jẹ aduroṣinṣin?
◻ Ki ni awọn koko abájọ diẹ ti o yẹ ki o sún wa lati fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jehofa?
◻ Eeṣe ti o fi yẹ ki a dena Eṣu?
◻ Bawo ni adura ṣe lè ràn wá lọwọ lati jẹ iranṣẹ aduroṣinṣin Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn aduroṣinṣin iranṣẹ Jehofa ko yọnda ki Elenini wọn ti o rí bii kinniun naa, Eṣu, dí iṣọkan wọn lọwọ