O Lè Bá Sátánì Jà Kó o sì Borí!
“Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Sátánì], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1 PÉT. 5:9.
1. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lásìkò yìí pé ká túbọ̀ múra sí ìjà tá à ń bá Sátánì jà? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé a lè borí nínú ìjà tá à ń bá Sátánì jà?
SÁTÁNÌ ń bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” jagun. (Jòh. 10:16) Ohun tó wà lọ́kàn Èṣù ni bó ṣe máa pa púpọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ kí sáà àkókò kúkúrú tó ní tó parí. (Ka Ìṣípayá 12:9, 12.) Ǹjẹ́ a lè borí Sátánì nínú ìjà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíbélì sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Ják. 4:7.
2, 3. (a) Ọ̀nà wo ni èrò tí àwọn èèyàn ní pé kò sí Sátánì gbà mú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ṣẹ? (b) Kí nìdí tó o fi gbà pé Sátánì wà lóòótọ́?
2 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé Sátánì wà. Lérò tiwọn, wọ́n gbà pé inú ìwé, àwọn fíìmù tó ń dẹ́rù bani àtàwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù ni wọ́n ti máa ń sọ ìtàn àròsọ nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn èèyàn yẹn gbà pé kò sẹ́ni tí orí ẹ̀ pé tó máa gbà pé àwọn ẹ̀mí búburú wà. Lójú tìẹ, ṣé o rò pé inú Sátánì bà jẹ́ pé àwọn èèyàn gbà pé òun àtàwọn ẹmẹ̀wà òun jẹ́ ẹ̀dá inú ìtàn àròsọ lásán, pé àwọn kì í ṣe ẹni gidi? Kò dájú pé inú rẹ̀ bà jẹ́! Ó ṣe tán, ó rọrùn fún Sátánì láti fọ́ ojú inú àwọn èèyàn tí kò gbà pé ó wà. (2 Kọ́r. 4:4) Bí àwọn èèyàn ṣe ń tan èrò náà kiri pé kò sí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà tàn àwọn èèyàn jẹ.
3 Ní ti àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, a kò sí lára àwọn tí Sátánì tàn jẹ. Àwá mọ̀ pé Sátánì Èṣù wà, torí pé òun ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. (Jẹ́n. 3:1-5) Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà nípa Jóòbù. (Jóòbù 1:9-12) Sátánì kan náà yìí ló dẹ Jésù wò. (Mát. 4:1-10) Nígbà tá a sì bí Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, Sátánì lẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró “ja ogun.” (Ìṣí. 12:17) Sátánì kò tíì dáwọ́ ogun yìí dúró torí pé ó ṣì ń wá bó ṣe máa pa iná ìgbàgbọ́ àṣẹ́kù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àtàwọn àgùntàn mìíràn. Tá a bá máa borí nínú ogun yìí, a gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sí Sátánì ká sì rí i pé a di ìgbàgbọ́ wa mú. A máa jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí.
MÁ ṢE MÁA GBÉRA GA
4. Báwo ni Sátánì ṣe fi hàn pé agbéraga ni òun?
4 Sátánì kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ rárá àti rárá. Ká sòótọ́, ìgbéraga àti ìkọjá-àyè gbáà ló máa jẹ́ bí áńgẹ́lì kan bá lè gbójúgbóyà sọ pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, tí irú áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ sì wá sọ ara rẹ̀ di ọlọ́run níbi tí Jèhófà Ọlọ́run wà. Torí náà, ọ̀nà kan tá a lè gbà kọjú ìjà sí Sátánì ni pé ká má ṣe máa gbéra ga, kàkà bẹ́ẹ̀, ká jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.—Ka 1 Pétérù 5:5.
5, 6. (a) Ṣó burú kéèyàn mọyì ara rẹ̀? Ṣàlàyé. (b) Sọ àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbéraga léwu.
5 Ohun kan wà tó yàtọ̀ sí ìgbéraga, ohun náà ni ìyangàn. Téèyàn bá ń yangàn, ó túmọ̀ sí pé ‘èèyàn mọyì ara rẹ̀, ó ń pọ́n ara rẹ̀ lé àti pé inú rẹ máa ń dùn torí pé òun tàbí àwọn tó sún mọ́ ọn ṣe nǹkan ire tàbí torí pé ọwọ́ wọn ba nǹkan ire.’ Kò sì sí ohun tó burú nínú ìyẹn. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Tẹsalóníkà pé: “Àwa fúnra wa ń fi yín yangàn láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni yín àti àwọn ìpọ́njú tí ẹ ń mú mọ́ra.” (2 Tẹs. 1:4) Torí náà, kò burú tí inú wa bá ń dùn nítorí ohun táwọn míì ṣe tàbí kéèyàn fi ohun dáadáa téèyàn ṣe yangàn. Ojú kì í tì wá láti sọ fáwọn èèyàn nípa ìdílé tá a ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wa tàbí ibi tá a dàgbà sí.—Ìṣe 21:39.
6 Àmọ́, ìgbéraga burú, ó lè ba àárín àwa àtàwọn èèyàn jẹ́, ó sì lè já okùn ọ̀rẹ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà. Ìgbéraga lè mú kéèyàn kọ etí dídi sí ìmọ̀ràn tàbí kéèyàn pa ìmọ̀ràn náà tì, dípò kéèyàn gbà á tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 141:5) Ìwé kan sọ pé ìgbéraga máa ń jẹ́ “kéèyàn jọ ara rẹ̀ lójú,” ó sì “jẹ́ ìwà tí àwọn tó gbà pé àwọn sàn ju àwọn èèyàn míì lọ máa ń hù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìdí tó fi hàn pé wọ́n sàn jù.” Jèhófà kórìíra ìgbéraga. (Ìsík. 33:28; Ámósì 6:8) Àmọ́, ó dájú pé inú Sátánì máa ń dùn nígbà táwọn èèyàn bá ń fọ́nnu, torí pé òun ni wọ́n fìwà ìgbéraga bẹ́ẹ̀ jọ. Ẹ wo bí inú Sátánì ṣe dùn tó nígbà táwọn èèyàn bíi Nímírọ́dù, Fáráò àti Ábúsálómù ń fọ́nnu, torí pé agbéraga ẹ̀dá ni wọ́n! (Jẹ́n. 10:8, 9; Ẹ́kís. 5:1, 2; 2 Sám. 15:4-6) Ìgbéraga náà ló fà á tí Kéènì fi di ẹni ẹ̀tẹ́. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gba Kéènì nímọ̀ràn, àmọ́ ìgbéraga kò jẹ́ kó fi ìmọ̀ràn náà sílò. Kéènì lo agídí, torí bẹ́ẹ̀ kò gba ìmọ̀ràn Jèhófà, ó sì kàgbákò.—Jẹ́n. 4:6-8.
7, 8. (a) Kí là ń pè ní kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà? Ọ̀nà wo ló gbà jẹ́ ìgbéraga? (b) Ṣàlàyé bí ìgbéraga ṣe lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́.
7 Lóde òní, onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà fi hàn pé àwọn jẹ́ agbéraga. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbéraga ló máa ń mú káwọn èèyàn ní ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ìwé atúmọ̀ èdè kan ṣàlàyé ohun tí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà jẹ́, ó sọ pé, “kéèyàn ní ẹ̀tanú sí àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀yà míì tàbí kéèyàn kórìíra wọn.” Ó tún sọ pé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà jẹ́ “ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé àwọn ìwà tàbí ìṣe kan wà tá a fi ń dá ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan mọ̀ àti pé àwọn ẹ̀yà kan lọ́lá ju àwọn míì lọ.” Ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà yìí ti fa rògbòdìyàn àti ogun, kódà ó ti mú kí wọ́n fi ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣòfò.
8 Àmọ́ o, irú àwọn nǹkan yìí kò gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Síbẹ̀, èdèkòyédè lè wáyé láàárín àwa Kristẹni, lọ́pọ̀ ìgbà ó lè jẹ́ pé ìgbéraga ló fà á, tó bá sì rí bẹ́ẹ̀ ó lè ṣòro láti yanjú rẹ̀. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn láàárín àwọn Kristẹni kan tí Jákọ́bù kọ̀wé sí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ó béèrè ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀, pé: “Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín?” (Ják. 4:1) Kò sí àní-àní, tá a bá kórìíra àwọn èèyàn, tá a sì gbà pé a lọ́lá jù wọ́n lọ, ó lè mú ká sọ̀rọ̀ tàbí hùwà àìdáa sí wọn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. (Òwe 12:18) Ó dájú pé ìgbéraga lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́.
9. Báwo ni Bíbélì ṣe ràn wá lọ́wọ́ ká má ṣe ní ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìgbéraga? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Tá a bá ní in lọ́kàn pé a lọ́lá ju àwọn ẹlòmíì lọ, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé, “olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Òwe 16:5) Ó tún máa dáa ká kíyè sí èrò wa nípa àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà míì, àwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa tàbí tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì. Tá a bá ní in lọ́kàn pé ẹ̀yà wa tàbí orílẹ̀-èdè wa lọ́lá ju tàwọn míì, á jẹ́ pé a ò gbà pé ‘láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.’ (Ìṣe 17:26) Tá a bá fi ohun tí Bíbélì sọ yìí sọ́kàn, a ó rí i pé ẹ̀yà kan péré ló wà, torí pé láti ara Ádámù tó jẹ́ baba ńlá wa ni gbogbo wa ti ṣẹ̀ wá. Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé àwọn ẹ̀yà kan lọ́lá ju àwọn míì lọ. Irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ṣètìlẹyìn fún ètekéte Sátánì láti ba ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni jẹ́. (Jòh. 13:35) Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká má ṣe máa gbéra ga lọ́nàkọnà.—Òwe 16:18.
MÁ ṢE NÍFẸ̀Ẹ́ ỌRỌ̀ ÀTI AYÉ
10, 11. (a) Kí nìdí tó fi rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ayé? (b) Kí ló fà á tí Démà fi nífẹ̀ẹ́ ayé?
10 Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí,” ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ayé yìí wà. (Jòh. 12:31; 1 Jòh. 5:19) Torí bẹ́ẹ̀, èyí tó pọ̀ jú lára ohun tí ayé ń gbé lárugẹ ló lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì. Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ohun tó wà láyé ló burú. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé Sátánì máa fẹ́ lo ayé yìí láti tàn wá jẹ, kó sì mú kí ọkàn wa máa fà sí ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ká nífẹ̀ẹ́ ayé, ká sì pa ìjọsìn Jèhófà tì.—Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.
11 Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nífẹ̀ẹ́ ayé. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Démà ti ṣá mi tì nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (2 Tím. 4:10) Bíbélì kò sọ ohun náà gan-an tí Démà nífẹ̀ẹ́ nínú ayé tó mú kó pa Pọ́ọ̀lù tì. Ó ṣeé ṣe kí Démà bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara ju àwọn nǹkan tẹ̀mí. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé Démà pàdánù àwọn àǹfààní àgbàyanu tẹ̀mí nìyẹn. Tìtorí kí ni? Kí ni Démà máa rí gbà nínú ayé yìí tó lè dà bí ìbùkún táá rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà bó ṣe ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́?—Òwe 10:22.
12. Àwọn ọ̀nà wo ni “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè gbà dẹkùn mú wa?
12 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Démà yẹn lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí pé a jẹ́ Kristẹni, ó máa ń wù wá pé ká pèsè ohun tara tí àwa àti ìdílé wa nílò. (1 Tím. 5:8) Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ara wa, èyí sì ṣe kedere tá a bá rántí pé inú ọgbà tó lẹ́wà ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà sì. (Jẹ́n. 2:9) Àmọ́, Sátánì máa ń lo “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” láti mú kí ọkàn wa máa fà sí ohun tí kò tọ́. (Mát. 13:22) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé owó ló ń mú kéèyàn láyọ̀ tàbí pé ìgbà téèyàn bá kó nǹkan tara jọ lèèyàn rọ́wọ́ mú láyé. Ńṣe lẹni tó bá nírú èrò bẹ́ẹ̀ ń tan ara rẹ̀ jẹ, ó sì lè mú kéèyàn pàdánù ohun tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn jíjẹ́ tá a jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tó bá jẹ́ pé Ọrọ̀ là ń lé lójú méjèèjì, a jẹ́ pé a ò sin Jèhófà mọ́, ohun tí Sátánì sì fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn! A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí owó tàbí àwọn nǹkan tí owó lè rà mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà ọ̀rẹ́ wa. Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan tara gbà wá lọ́kàn.—Ka 1 Tímótì 6:6-10.
MÁ ṢE FÀYÈ GBA ÌṢEKÚṢE
13. Báwo ni ayé yìí ṣe ń mú káwọn èèyàn máa fọwọ́ tí kò tọ́ mú ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀?
13 Ìdẹkùn míì tó wà nínú ayé tí Sátánì ń darí ni ìṣekúṣe. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni kò ní jẹ́ káwọn gbádùn ayé àwọn àti pé kò bóde mu mọ́, kódà wọn ò ka ìgbéyàwó sí ohun tó ṣe pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó jẹ́ eléré orí ìtàgé sọ pé: “Kò ṣeé ṣe kéèyàn jẹ́ aláya kan tàbí ọlọ́kọ kan. Mi ò tíì rí ẹnikẹ́ni tó máa sọ pé òun ò lójú síta.” Ọkùnrin kan tí òun náà jẹ́ eléré orí ìtàgé sọ pé: “Kò dá mi lójú pé Ọlọ́run dá wa pé ká ṣáà máa gbé pẹ̀lú ẹnì kan péré láyé wa.” Ẹ wo bí inú Sátánì á ti máa dùn bí àwọn tó lẹ́nu láwùjọ ṣe ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa. Ó dájú pé Èṣù ò nífẹ̀ẹ́ sí ètò ìgbéyàwó, kò sì fẹ́ káwọn tó ṣègbéyàwó máa gbé pọ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run fi lélẹ̀.
14, 15. Kí la lè ṣe tá ò fi ní fàyè gba ìṣekúṣe?
14 Yálà a ti lọ́kọ tàbí láya tàbí a ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi ká má ṣe fàyè gba ìṣekúṣe. Ṣé ó rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé kò rọrùn! Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè gbọ́ táwọn ọmọléèwé rẹ̀ ń fọ́nnu pé àwọn máa ń gbé ara wọn sùn tàbí pé àwọn máa ń fi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònú, èyí táwọn kan kà sí wíwo àwòrán ìhòòhò ọmọdé. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́r. 6:18) Àwọn àrùn táwọn èèyàn máa ń kó látinú ìṣekúṣe ti fojú àwọn èèyàn rí màbo, ó sì ń pa wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ti mọ ọkùnrin tàbí tó ti mọ obìnrin láìtíì ṣègbéyàwó ni wọ́n sọ pé àwọn kábàámọ̀ ohun táwọn ṣe. Kì í ṣe ohun tí ìwà ìṣekúṣe jẹ́ gan-an làwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n, rédíò, àwọn fíìmù àtàwọn ìwé máa ń gbé jáde, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń mú káwọn èèyàn gbà pé kò sóhun tó máa tìdí rẹ̀ yọ béèyàn bá rú àwọn òfin Ọlọ́run. Irú èrò yìí ti mú kí “agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀” dẹkùn mú àwọn èèyàn.—Héb. 3:13.
15 Tó o bá dojú kọ ìdẹwò tó lè mú ẹ ṣèṣekúṣe, kí lo lè ṣe? Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ. (Róòmù 7:22, 23) Bẹ Ọlọ́run pé kó fún ẹ lókun. (Fílí. 4:6, 7, 13) Máa sá fún àwọn nǹkan tàbí ipò tó lè mú ẹ ṣèṣekúṣe. (Òwe 22:3) Tó o bá sì dojú kọ ìdẹwò, tètè sá fún un.—Jẹ́n. 39:12.
16. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí Sátánì dẹ ẹ́ wò, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
16 Àpẹẹrẹ rere ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká borí ìdẹwò. Kò jẹ́ kí àwọn ìlérí tí Sátánì ṣe tan òun jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò fàyè sílẹ̀ láti ro ọ̀rọ̀ náà síwá sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dá a lóhùn pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Ka Mátíù 4:4-10.) Jésù mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú, ìyẹn mú kó tètè gbé ìgbésẹ̀ tó sì fa ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yọ nígbà tí ìdẹwò dé. Tá a bá máa ṣẹ́gun Sátánì, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohun tó lè mú wa ṣèṣekúṣe.—1 Kọ́r. 6:9, 10.
TÓ O BÁ Ń FARA DÀ Á, WÀÁ ṢẸ́GUN
17, 18. (a) Àwọn ohun ìjà míì wo ni Sátánì ń lò, kí sì nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì? Báwo nìyẹn á ṣe mú kó o máa fara dà á?
17 Ìgbéraga, ìfẹ́ ọrọ̀ àti ìṣekúṣe wulẹ̀ jẹ́ mẹ́ta péré lára àwọn ohun ìjà tí Sátánì ń lò. Àìmọye ohun ìjà ló ṣì wà lọ́wọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan ń dojú kọ inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn ará ilé wọn, àwọn ọmọléèwé wọn ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, kódà àwọn ìjọba ti fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù táwọn ará wa ń ṣe. Kò yà wá lẹ́nu pé à ń dojú kọ àwọn ìpọ́njú yìí, torí pé Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó . . . jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mát. 10:22.
18 Báwo la ṣe lè bá Sátánì jà ká sì borí? Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.” (Lúùkù 21:19) Kò sí ìpalára tí ẹ̀dá èèyàn kan lè ṣe sí wa tó máa kọjá àtúnṣe. Kò sẹ́ni tó lè ba àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́ àyàfi tá a bá fàyè gbà á. (Róòmù 8:38, 39) Kódà bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá tiẹ̀ kù, ìyẹn ò fi hàn pé Sátánì ti jáwé olúborí, torí pé Jèhófà á rí i pé òun jí wọn dìde! (Jòh. 5:28, 29) Àmọ́ ọjọ́ iwájú Sátánì kò ní dáa rárá. Lẹ́yìn tí ayé búburú yìí bá ti pa run, Jésù máa fi Sátánì sẹ́wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. (Ìṣí. 20:1-3) Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Jésù, a máa ‘tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀’ fúngbà díẹ̀ láti gbìyànjú ìkẹyìn bóyá á lè ṣi aráyé tó ti di pípé lọ́nà. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù máa pa Èṣù run. (Ìṣí. 20:7-10) Ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Sátánì, àmọ́ ó dájú pé mìmì kan kò ní mì ọ́! Torí náà, gbéjà ko Sátánì, dúró gbọin nínú ìgbàgbọ́. Ó dájú pé o lè bá Sátánì jà, kó o sì borí!