Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Di Àtúnbí Kó Tó Lè Nígbàlà?
TẸ́NÌ kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣó o ti di àtúnbí”? Kí lo máa sọ? Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló máa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Wọ́n gbà gbọ́ pé téèyàn ò bá tíì di àtúnbí, kò tíì di Kristẹni gidi àti pé àfi kéèyàn di àtúnbí kó tó lè nígbàlà. Èrò wọn bá tàwọn aṣáájú ìsìn mu, irú bí Ọ̀gbẹ́ni Robert C. Sproul tó kọ̀wé pé: “Bẹ́nì kan kì í bá ṣe àtúnbí, . . . á jẹ́ pé onítọ̀hún kì í ṣe Kristẹni nìyẹn.”
Ṣéwọ náà gbà gbọ́ pé tó o bá ti dàtúnbí, o ti wà lójú ọ̀nà tó máa jẹ́ kó o nígbàlà nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá fẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ náà mọ ojú ọ̀nà yẹn, kí wọ́n sì máa rìn níbẹ̀. Àmọ́, kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹnì kan tó ti di àtúnbí àtẹni tí kì í ṣe àtúnbí. Torí náà, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti di àtúnbí fún wọn?
Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé ẹni tó ti di “àtúnbí” lẹni tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run àti Kristi, tíyẹn sì ti wá jẹ́ kó ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Kódà, ìwé atúmọ̀ èdè kan tó dé kẹ́yìn sọ pé ẹni tó ti di àtúnbí “sábà máa ń jẹ́ Kristẹni tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ ti túbọ̀ lágbára sí i tàbí kónítọ̀hún ti rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti pe òun lẹ́yìn tóun bá Ọlọ́run pàdé.”—Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary—Eleventh Edition.
Ṣé kò ní yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àtúnbí yàtọ̀ sóhun tí ìwé atúmọ̀ èdè yẹn sọ? Ṣé wàá fẹ́ mohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni nípa dídi àtúnbí? Ó dájú pé wàá jàǹfààní gan-an tó o bá fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. Ìdí sì ni pé mímọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àtúnbí máa nípa lórí ìgbésí ayé ẹ àti ohun tó ò ń retí lọ́jọ́ ọ̀la.
Kí Ni Bíbélì Kọ́ni?
Ọ̀kan lára ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àtúnbí lèyí tó wà nínú Jòhánù 3:1-12, ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣàlàyé ìjíròrò tó lárinrin kan tó wáyé láàárín Jésù àti aṣáájú ẹ̀sìn kan nílùú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé tó tẹ̀ lé e. A fẹ́ kó o fara balẹ̀ kà á.
Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jésù sọ̀rọ̀ lórí oníruúrú ọ̀nà tí àtúnbí pín sí.a Kódà, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ jẹ́ ká mọ ìdáhùn tó tọ̀nà sáwọn ìbéèrè pàtàkì márùn-ún yìí:
◼ Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó láti di àtúnbí?
◼ Ṣéèyàn fúnra ẹ̀ ló máa ń pinnu póun fẹ́ di àtúnbí?
◼ Kí nìdí táwọn kan fi ní láti di àtúnbí?
◼ Báwo lèèyàn ṣe lè di àtúnbí?
◼ Àjọṣe tuntun wo lèèyàn máa ní pẹ̀lú Ọlọ́run téèyàn bá di àtúnbí?
Ẹ jẹ́ ká wá jíròró àwọn ìbéèrè yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àtúnbí nínú 1 Pétérù 1:3, 23, ó pè é ní “ìbí tuntun.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní gen·naʹo la tú sí ìbí tuntun, òun náà làwọn èèyàn sì mọ̀ sí àtúnbí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“A Gbọ́dọ̀ Tún Yín Bí”
“Wàyí o, ọkùnrin kan wà nínú àwọn Farisí, Nikodémù ni orúkọ rẹ̀, olùṣàkóso kan fún àwọn Júù. Ẹni yìí wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru, ó sì wí fún un pé: ‘Rábì, àwa mọ̀ pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe láìjẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.’ Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: ‘Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.’ Nikodémù wí fún un pé: ‘Báwo ni a ṣe lè bí ènìyàn nígbà tí ó ti dàgbà? Kò lè wọ inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ní ìgbà kejì kí a sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?’ Jésù dáhùn pé: ‘Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí a ti bí láti inú ẹran ara jẹ́ ẹran ara, ohun tí a sì ti bí láti inú ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀mí. Kí ẹnu má ṣe yà ọ́ nítorí mo sọ fún ọ pé, A gbọ́dọ̀ tún yín bí. Ẹ̀fúùfù ń fẹ́ síbi tí ó wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti inú ẹ̀mí.’ Ní ìdáhùn, Nikodémù wí fún un pé: ‘Báwo ní nǹkan wọ̀nyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?’ Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: ‘Ìwọ ha jẹ́ olùkọ́ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ tí o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Ohun tí àwa mọ̀ ni a ń sọ, ohun tí a sì ti rí ni a ń jẹ́rìí rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gba ẹ̀rí tí àwa jẹ́. Bí mo bá ti sọ àwọn ohun ti ilẹ̀ ayé fún yín, síbẹ̀ tí ẹ kò sì gbà gbọ́, báwo ni ẹ ó ṣe gbà gbọ́ bí mo bá sọ àwọn ohun ti ọ̀run fún yín?’”—Jòhánù 3:1-12.