“Ìrísí Ìran Ayé Yìí Ń yí Padà”
“Èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 7:29.
1, 2. Àwọn ìyípadà wo ló ti ṣẹlẹ̀ tó o rí látìgbà tó o ti dáyé?
ÀWỌN ìyípadà wo ló ti ṣẹlẹ̀ tó o rí látìgbà tó o ti dáyé? Ṣé o lè sọ díẹ̀ nínú wọn? Bí àpẹẹrẹ, ìtẹ̀síwájú ti wà gan-an nínú ìmọ̀ ìṣègùn. Ọpẹ́lọpẹ́ ìwádìí tí wọ́n ṣe nínú ìmọ̀ ìṣègùn ló mú kí ìpíndọ́gba bí ẹnì kan ṣe lè wàláàyè pẹ́ tó lọ sókè láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ohun tó dín sí àádọ́ta ọdún ni ìpíndọ́gba yẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún lọ́nà ogun, ṣùgbọ́n ó ti lọ sókè sí ohun tó lé ní àádọ́rin ọdún lákòókò tá a wà yìí! Tún rò ó wò ná, ọ̀pọ̀ àǹfààní ni a ti jẹ́ látàrí lílo rédíò, tẹlifíṣọ̀n, tẹlifóònù alágbèérìn àti ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni. Ohun pàtàkì mìíràn tí kò ṣeé gbàgbé ni ìtẹ̀síwájú tó ti bá ètò ẹ̀kọ́, ètò ìrìnnà àtàwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, gbogbo ìwọ̀nyí ló ti mú ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn dára sí i.
2 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìyípadà tá a sọ yìí náà ló bímọ re o. Ó dájú pé ìwà ọ̀daràn ń gogò sí i, ìwà rere ń kásẹ̀ nílẹ̀, ìjoògùnyó ń peléke sí i, ìkọ̀sílẹ̀ gbòde kan, ọ̀wọ́n gógó ọjà àti ìpániláyà ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́, gbogbo èyí ló ń kó ìbànújẹ́ tí kò ṣeé fẹnu sọ bá àwọn èèyàn. Bó ṣe wù kórí, ó ṣeé ṣe kó o fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ pé: “Ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.”—1 Kọ́ríńtì 7:31.
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà”?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ yẹn, ńṣe ló ń fi ayé yìí wé orí ìtàgé. Àwọn tó wà lórí ìtàgé náà ni, àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olóṣèlú, àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn láwùjọ, gbogbo wọn ló fara hàn, wọ́n kópa tiwọn, wọ́n sì fi òrí ìtàgé náà sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Ọjọ́ ti pẹ́ tí èyí ti ń ṣẹlẹ̀. Láwọn àkókò kan sẹ́yìn, ìlà ọba kan lè ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọdún, kódà wọ́n lè ṣàkóso fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún pẹ̀lú, láìsí ìyípadà tó ṣe gbòógì. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ lónìí, tó jẹ́ pé ńṣe ni nǹkan tètè máa ń dọ̀rọ̀ ìtàn lẹ́yẹ-ò-sọkà! Bẹ́ẹ̀ ni o, láwọn àkókò onírúkèrúdò yìí, kó sí ẹ̀dá tó mọ ilẹ̀ tó máa mọ́ lọ́la.
4. (a) Èrò tó wà déédéé wo ló yẹ káwọn Kristẹni ní nípa àwọn ohun tó ǹ ṣẹlẹ̀ nínú ayé? (b) Ọ̀wọ́ ẹ̀rí méjì tí kò ṣeé já ní koro wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
4 Bó bá jẹ́ pé orí ìtàgé ni ayé yìí, táwọn aṣáájú rẹ̀ sì jẹ́ òṣèré, a jẹ́ pé àwọn Kristẹni ni òǹwòran.a Nítorí pé “wọn kì í ṣe apá kan ayé,” ìdí nìyẹn tí wọn kì í fi yọ ara wọn lẹ́nu jù nípa ohun tí àwọn èèyàn yẹn ń ṣe tàbí nípa àwọn òṣèré náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Jòhánù 17:16) Dípò tí wọ́n ó fi máa yọ ara wọn lẹ́nu, ńṣe ni wọ́n ń wọ̀nà fún àwọn àmì tó fi hàn pé ìran náà ti ń lọ sópin, ìyẹn òpin alájàálù kan. Wọ́n kúkú mọ̀ pé ó di dandan kí ètò àwọn nǹkan yìí dópin kí Jèhófà tó mú ayé tuntun òdodo tí a ti ń retí fún ọjọ́ pípẹ́ wá.b Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò ọ̀wọ́ ẹ̀rí méjì tó fi hàn pé à ń gbé ní àkókò òpin àti pé ayé tuntun ti sún mọ́lé gan-an. Àwọn ẹ̀rí yìí ni (1) Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àti (2) Ipò ayé tó túbọ̀ ń burú sí i.—Mátíù 24:21; 2 Pétérù 3:13.
Àdììtú Tó Lójútùú Nígbẹ̀yìn-Gbẹ́yín!
5. Kí ni àwọn “àkókò tí a ti yàn kalẹ̀,” kí sì nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa rẹ̀?
5 Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ jẹ́ mímọ bí ohun kan ṣe ṣẹlẹ̀ àti àkókò tó ṣẹlẹ̀. Jésù sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tó jẹ́ pé àwọn aṣáájú ayé nìkan ni yóò wà lórí ìtàgé náà tí Ìjọba Ọlọ́run kò sì ní dá sí i. Jésù pé àkókò yẹn ní “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Lúùkù 21:24) Lẹ́yìn tí “àkókò tí a yàn kalẹ̀” náà bá ti dópin, Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run yóò gbàkóso, Jésù ni yóò sì jẹ́ Alákòóso tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ní ìbẹ̀rẹ̀, Jésù yóò ṣàkóso “láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].” (Sáàmù 110:2) Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44, Ìjọba náà ‘yóò fọ́ gbogbo ìjọba ènìyàn túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn’ ṣùgbọ́n òun yóò dúró títí láé.
6. Ìgbà wo ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” bẹ̀rẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe gùn tó, ìgbà wo sì ni wọ́n parí?
6 Ìgbà wo ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” yóò dópin, tí Ìjọba Ọlọ́run yóò sì bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso? Ìdáhùn tí a ‘fi èdìdì dì títí di àkókò òpin’ náà ní í ṣe pẹ̀lú ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì. (Dáníẹ́lì 12:9) Bí “àkókò” yẹn ṣe ń sún mọ́lé, Jèhófà ṣe àwọn ohun kan láti fi ìdáhùn náà han àwùjọ àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ láti róye pé ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa ló bẹ̀rẹ̀ “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” àti pé àwọn “àkókò” yẹn jẹ́ ẹgbàá-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé okòó [2,520] ọdún. Látàrí èyí, wọ́n lè wá rí i pé ọdún 1914 ló sàmì sí òpin “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Wọ́n tún wá ri pé ọdún 1914 ni ìparí ètò àwọn nǹkan yìí bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé bí a ṣe ṣírò ọdún 1914 látinú Ìwé Mímọ́?c
7. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìbẹ̀rẹ̀, gígùn àti ìparí ìgbà méje tá a mẹ́nu kàn nínú ìwé Dáníẹ́lì?
7 A rí amọ̀nà kan nínú ìwé Dáníẹ́lì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ni Jèhófà lò láti pa Jerúsálẹ́mù run ní ìbẹ̀rẹ̀ “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀” ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run ṣí i payá nípasẹ̀ alákòóso yẹn pé àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa bá ṣíṣe àkóso lọ fún igbà méje lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tí Ọlọ́run kò sí ní dá si i. (Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27; Dáníẹ́lì 4:16, 23-25) Báwo ni ìgbà méje yẹn ṣe gùn tó? Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Ìṣípayá 11:2, 3, àti 12:6, 14, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́. Nígbà náà, a jẹ́ pé ìgbà méje yóò jẹ́ ìlọ́po méjì ìyẹn tàbí ẹgbàá-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé okòó [2,520] ọjọ́. Ṣé ibi tó parí sí náà wá nìyẹn? Rárá o, nítorí pé Jèhófà fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì tí òun àti Dáníẹ́lì jọ gbé ayé nígbà kan náà ní ìlànà tí yóò fi máa túmọ̀ àmì, ó sọ pé: “Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ni ohun tí mo fi fún ọ.” (Ìsíkíẹ́lì 4:6) Nítorí náà, ìgbà méje yóò jẹ́ ẹgbàá-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé okòó [2,520] ọdún. Bá a bá bẹ̀rẹ̀ sí ka ẹgbàá-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé okòó [2,520] ọdún, láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a lè wá rí i pé àkókò tí a yàn kalẹ̀ dópin ní ọdún 1914.
A Mọ “Àkókò Òpin”
8. Ẹ̀rí wo lo lè tọ́ka sí tó fi hàn pé ńṣe ni ipò ayé ń burú sí i láti ọdún 1914?
8 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé láti ọdún 1914 wá jẹ́rìí sí i pé òye tá a gbé karí ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì yìí tọ̀nà. Jésù alára sọ pé ogun, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn là ó fi mọ “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3-8; Ìṣípayá 6:2-8) Èyí sì ti rí bẹ́ẹ̀ láti ọdún 1914. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún tànmọ́lẹ̀ sórí ọ̀rọ̀ náà, nígbà tó sọ pé ìyàtọ̀ ńlá yóò wà nínú ìwà táwọn èèyàn ń hù sí ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. Bó ṣe ṣàpèjúwe ìyípadà náà ló rí gẹ́lẹ́.—2 Tímótì 3:1-5.
9. Kí làwọn alálàyé sọ lórí ipò ayé láti ọdún 1914?
9 Ṣé lóòótọ́ ni “ìrísí ìran ayé yìí” ti yí padà gan-an láti ọdún 1914? Nínú ìwé The Generation of 1914, Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Wohl sọ pé: “Àwọn tó bá wà láyé nígbà ogun náà kò lè ṣàìgbà pé ayé kan parí tí òmíràn sì bẹ̀rẹ̀ ní August 1914.” Nígbà tí Dókítà Jorge A. Costa e Silva to jẹ́ olùdarí ìlera ọpọlọ fún Àjọ Ìlera Àgbáyé ń jẹ́rìí sí èyí, ó kọ̀wé pé: “À ń gbé ní àkókò tí nǹkan ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó yára kánkán, èyí sì ń mú kí àníyàn àti wàhálà tó le koko pọ̀ sí i lọ́nà tí ìran ènìyàn kò tíì rí irú rẹ̀ rí .” Ṣe bó ṣe máa ń ṣe ìwọ náà nìyẹn?
10. Báwo ni Bíbélì ṣe là wá lóye lórí ohun tó fa ipò ayé tó ń bà jẹ́ sí i láti ọdún 1914?
10 Ta ni olubi ẹ̀dá tó wà nídìí bí ipò ayé ṣe ń burú sí i yìí? Ìṣípayá 12:7-9 fi olubi náà hàn, ó ní: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [Jésù Kristi] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà [Sátánì Èṣù] jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, . . . ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Nítorí náà, Sátánì Èṣù ni adárúgúdùsílẹ̀ tó lẹ̀bi gbogbo ọ̀ràn yìí, lílé tí a sì lé e jáde kúrò ní ọ̀run ní ọdún 1914 fi hàn pé “ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:10, 12.
Bí Ìran Tó Kẹ́yìn Yóò Ṣe Ṣẹlẹ̀
11. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì ń lò láti “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà”? (b) Ìsapá àrà ọ̀tọ̀ wo ni Sátánì ń ṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàfiyèsí sí?
11 Nítorí pé Sátánì mọ̀ pé òpin ti ń sún mọ́lé, láti ọdún 1914 ló ti túbọ̀ ń fi kún ìsapá rẹ̀ láti máa “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Sátánì tó jẹ́ ọ̀gá àwọn aṣinilọ́nà náà, ló wà lábẹ́lẹ̀ tó ń lu ìlù fún àwọn òṣèré jó, ìyẹn àwọn aṣáájú nínú ayé àtàwọn tó ń pinnu àṣà tó lòde. (2 Tímótì 3:13; 1 Jòhánù 5:19) Ọ̀kan nínú àwọn ohun tó ń lépa ni pé kó tan gbogbo èèyàn láti máa rò pé ọ̀nà tí òun gbà ń ṣàkóso nìkan ló lè mú àlàáfíà tòótọ́ wá. Ní gbogbo gbòò, ìgbékèéyíde rẹ̀ ti ṣàṣeyọrí, nítorí pé àwọn èèyàn ṣì gbà pé ọ̀la yóò dára bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé ipò nǹkan túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ṣáájú kí ètò àwọn nǹkan yìí tó pa run, Sátánì yóò mú kí ìgbékèéyíde rẹ̀ délé dóko. Ó kọ̀wé pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tẹsalóníkà 5:3; Ìṣípayá 16:13.
12. Àwọn ìsapá wo làwọn èèyàn ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láti mú àlàáfíà wá lákòókò wa?
12 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìgbàkúùgbà làwọn olóṣèlú máa ń lo gbólóhùn náà “àlàáfíà àti ààbò” láti ṣàpèjúwe oríṣiríṣi ète ènìyàn. Kódà wọ́n tiẹ̀ pe ọdún 1986 ní Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ kò ro ọdún yẹn nítorí àlàáfíà kò kárí ayé lọ́dún náà. Ǹjẹ́ akitiyan tí àwọn aṣáájú ayé ṣe yìí ti mú kí 1 Tẹsalóníkà 5:3 ṣẹ pátápátá àbí ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì kan tó máa gbàfiyèsí gbogbo ayé lọ́jọ́ iwájú ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
13. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa igbe “Àlàáfíà àti ààbò!,” kí ló fi ìparun tí yóò tẹ̀ lé e wé, ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa?
13 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bá ṣẹ tán tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ lọ́wọ́ la sábà máa ń lóye wọn ní kíkún, a jẹ́ pé a ní láti ṣe sùúrù ká lè rí ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí. Ẹ ò ri pé ó dára gan-an bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìparun òjijì tó máa tẹ̀lé igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” náà wé ìroragógó wàhálà tó máa ń bá obìnrin tó lóyún. Fún nǹkan bí odindi oṣù mẹ́sàn gbáko ni aboyún kan fi máa ń mọ̀ pé ọmọ ń dàgbà nínú òun. Ó ṣeé ṣe kó gbọ́ bí ọmọ náà ṣe ń mí tàbí kó mọ bí ọmọ náà ṣe ń yíra padà nínú rẹ̀. Ọmọ yẹn tiẹ̀ lè fi ìpá ta á níkùn. Àwọn àmì yẹn á túbọ̀ máa hàn sí i títí di ọjọ́ kan tí ọmọ yóò mú un, tí ìroragógó wàhálà yóò sì dé bá a, èyí tó fi hàn pé àkókò tó ti ń retí ti dé, àkókò ìbímọ ti dé. Nítorí náà, ọ̀nà yòówù tí àsọtẹ́lẹ̀ igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” i báà gbà nímùúṣẹ, ó dájú pé yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ òjijì tó ń fa ìroragógó ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ ni yóò jẹ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nítorí pé yóò yọrí sí ìparun gbogbo ìwà ibi, tí ayé tuntun yóò sì dé.
14. Báwo ni àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú yóò ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé ra, kí sì ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀?
14 Ìparun tó ń bọ̀ yìí yóò jẹ́ amúni kún fún ẹ̀rù fún àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ tó jẹ́ òǹwòran. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ọba ayé (ìyẹn ètò òṣèlú tó jẹ́ apá kan ètò Sátánì) yóò dojú kọ àwọn alátìlẹyìn Bábílónì Ńlá (ìyẹn ètò ìsìn) yóò sì pa wọ́n run. (Ìṣípayá 17:1, 15-18) Nípa bẹ́ẹ̀, nǹkan á yí padà bírí, ìjọba Sátánì yóò yapa sí ara rẹ̀, apá kan yóò dojú kọ apá kejì, agbára Sátánì kò sí ní ká a. (Mátíù 12:25, 26) Jèhófà yóò fi sínú àwọn ọba ayé “láti mú ìrònú òun ṣẹ,” ìyẹn ni láti pa gbogbo àwọn ọ̀tá ìjọsìn rẹ̀ run. Lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run tán, Jésù Kristi yóò ṣíwájú àwọn ogun ọ̀run láti ṣẹ́gun ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù nínú ètò Sátánì, ìyẹn ètò ìṣòwò àti ti ìṣèlú. Níkẹyìn, Sátánì fúnra rẹ̀ la ó fi sínú àhámọ́. Ìyẹn ni yóò gbẹ̀yìn nínú ìran yẹn, bí ìran gígùn náà yóò ṣe wá sópin nìyẹn.—Ìṣípayá 16:14-16; 19:11-21; 20:1-3.
15, 16. Ipa wo ló yẹ kí ìránnilétí náà pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù” ní lórí ìgbésí ayé wa?
15 Nígbà wo ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ? A kò mọ ọjọ́ àti wákàtí. (Mátíù 24:36) Àmọ́ ṣá ó, a mọ̀ pé, “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́ríńtì 7:29) Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fi ọgbọ́n lo àkókò tó ṣẹ́ kù. Lọ́nà wo? Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ ra ‘àkókò tí ó rọgbọ padà’ fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, ká jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì ká sì lo àkókò wa bó ṣe yẹ. Kí nìdí? “Nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” Bí a bá ń ‘bá a lọ láti máa róye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́’ fún wa, à kò ní fi àkókò kékeré ṣíṣeyebíye tó ṣẹ́ kù yìí ṣòfò.— Éfésù 5:15-17; 1 Pétérù 4:1-4.
16 Báwo ló ṣe yẹ́ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé ìparun ń dúró de gbogbo ètò àwọn nǹkan ayé yìí nípa lórí wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan? Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé fún àǹfààní wa pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!” (2 Pétérù 3:11) Bẹ́ẹ̀ ni, oníwà mímọ́ àti onífọkànsìn ló yẹ ká jẹ lóòótọ́! Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání tí Pétérù fún wa, ó yẹ́ ká (1) máa kíyè sí ìwà tá à ń hù, ká bàa lè rí dájú pé ó mọ́, àti (2) ká lè máa ri dájú pé iṣẹ́ tí à ń fi ìtara ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ń fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní fún un hàn nígbà gbogbo.
17. Ìdẹkùn Sátánì wo ni gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́ gbọ́dọ̀ yàgò fún?
17 Ìfẹ́ fún Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú ayé fà wá mọ́ra. Nítorí àjálù tó wà níwájú fún ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó léwu gan-an fún wa láti fẹ́ràn àwọn nǹkan yòyò tí ayé onífàájì lè fi fà wá mọ́ra. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé là ń gbé ibẹ̀ la sì ti ń ṣiṣẹ́, ó yẹ ká kọbi ara sí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó sọ pé kí á má ṣe lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:31) Ká sòótọ́, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo agbára wa kí afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé yìí má bàa ṣì wá lọ́nà. Ayé yìí kò lè dá yanjú wàhálà tó kó ara rẹ̀ sí. Kò lè máa wà títí lọ gbére. Báwo ló ṣe dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí sọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
Ọjọ́ Ọ̀la Tó Dára Jù Lọ Ṣì Ń Bọ̀ Lọ́nà!
18, 19. Àwọn ìyípadà wo lò ń wọ̀nà fún nínú ayé tuntun, kí sì nìdí tó fì tó ohun téèyàn ń dúró dè?
18 Jèhófà máa tó pa Sátánì àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ run. Lẹ́yìn ìyẹn, pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run, àwọn olóòótọ́ tó bá la òpin ètò nǹkan yìí já yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí “ìrísí” ayé tó ti yí padà náà, tí yóò sì wà títí láé. Ogun kò ní ba ìrísí náà jẹ́ mọ́; Ọlọ́run yóò mú kí “ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Dípò àìtó oúnjẹ, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; . . . àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà.” (Sáàmù 72:16) Kò ní sí ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ́, àgọ́ ọlọ́pàá yóò ti dọ̀rọ̀ ìtàn, àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ yóò ti dohun ìgbàgbé, àwọn tí ń fi oògùn olóró ṣayọ̀ yóò ti pòórá, kóòtù tí a ti ń jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ yóò ti kógbá sílé, kò ní sí pé à ń wọko gbèsè mọ́, àní ìpániláyà yóò sì ti dópin.—Sáàmù 37:29; Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3-5.
19 Ibojì ìrántí yóò ti ṣófo, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tí a jí dìde yóò fara hàn. Ẹ wo bí ìdùnnú yóò ṣe ṣubú lu ayọ̀ tó nígbà tí ìran ènìyàn kan bá tún dara pọ̀ mọ́ ìran mìíràn, nígbà táwọn ẹni ọ̀wọ́n tí wọ́n ti ya ara wọn fún àkókó pípẹ́ bá ń dì mọ́ ara wọn gbàgì! Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo àwọn tó wà láàyè ni yóò máa sin Jèhófà. (Ìṣípayá 5: 13) Nígbà tí gbogbo àwọn nǹkan bá ti yí padà tán, gbogbo ayé yóò wá di Párádísè. Báwo ni yóò ṣe rí lára rẹ nígbà tó o bá ń wo ìran náà? Kò sí iyèméjì pé wàá sọ̀rọ̀ tìtaratìtara pé ‘ọjọ́ ti pẹ́ tí mo ti ń wọ̀nà fún àkókò yìí, ṣùgbọ́n sùúrù mi tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!’
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní àyíká ọ̀rọ̀ mìíràn, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé wọ́n “di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn.”—1 Kọ́ríńtì 4:9.
b Bí àpẹẹrẹ, wo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 280 àti 281 láti lè dá “ọba àríwá” tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 11:40, 44, 45 mọ̀.
c Bíbélì fúnra rẹ̀ fi hàn pé Jerúsálẹ́mù ṣubú ní àádọ́rin ọdún ṣáájú ìgbà tí àwọn Júù tá a kó ní ìgbèkùn padà dé ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Jeremáyà 25:11, 12; Dáníẹ́lì 9:1-3) Fún àlàyé kíkún lórí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” wo ojú ìwé 95 sí 97 nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà” ṣe jóòótọ́ lákòókò tiwa yìí?
• Báwo ni ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì ṣe tọ́ka sí òpin “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè”?
• Báwo ni àwọn ipò ayé tó ń yí padà ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé ọdún 1914 ni “àkókò òpin” bẹ̀rẹ̀?
• Báwo ló ṣe yẹ kí òtítọ́ náà pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù” nípa lórí wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín—àdììtú náà lójútùú!