Mú Sùúrù
OLÙṢỌ́ àgùntàn tí ó bá ń kígbe pé “Ìkookò ti dé o!” nígbà tí ìkookò kankan kò sí nítòsí kò ní rí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́ nígbà tí ìkookò bá wá dé. Lọ́nà jíjọra lónìí, ọ̀pọ̀ ń dágunlá sí ìsúnmọ́lé ọjọ́ Jèhófà nítorí pé wọ́n ti gbọ́ àìmọye ìkìlọ̀ tí kò ṣẹ. Òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ kùnà láti fòye mọ ìkìlọ̀ tòótọ́, kí wọ́n sì kọbi ara sí i, ti mú kí wọ́n kó sọ́wọ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run, Sátánì, “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀” èké yẹn.—2 Kọ́ríńtì 11:4.
Ẹ̀mí àìbìkítà léwu pàápàá fún àwọn tí wọ́n ti sin Jèhófà fún ọdún mélòó kan. Èé ṣe? Gbé ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
Ronú Jinlẹ̀
Lẹ́tà onímìísí kejì tí Pétérù kọ jẹ́ ìránnilétí fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ fún wa pẹ̀lú. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ní báyìí o, èyí ni lẹ́tà kejì tí mo ń kọ sí yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú èyí tí mo kọ́kọ́ kọ, nínú èyí tí èmi ń ru agbára ìrònú yín ṣíṣe kedere sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí.” (2 Pétérù 3:1) Kí ní fa gbogbo àníyàn tí Pétérù ń ṣe yìí? Pétérù tẹnu mọ́ wíwà tí àwọn olùyọṣùtì wà nítòsí, àwọn tí ìyọṣùtì wọn ń dín òye ìjẹ́kánjúkánjú tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nílò kù, lójú ìwòye àkókò tí wọ́n ń gbé. Àkókò yìí ni ó yẹ kí a ṣọ́ra fún dídi ẹni tí àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn lè tàn jẹ. Pétérù tipa báyìí rán àwọn òǹkàwé rẹ̀ létí láti “rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú.” (2 Pétérù 3:2; Ìṣe 3:22, 23) Kí ni àwọn wòlíì náà sọ?
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pe àfiyèsí sí bí ìdájọ́ àtọ̀runwá ṣe mú òpin dé bá ìwà burúkú. Pétérù rán àwọn òǹkàwé rẹ̀ létí Ìkún Omi ọjọ́ Nóà tí Ọlọ́run lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtidá sí ọ̀ràn ayé nígbà tí ó kún fún ìwà ibi. Lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, Àkúnya ríru gùdù náà fòpin sí ayé ìgbà yẹn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú ẹ̀dá alààyè kọ̀ọ̀kan láti inú “gbogbo onírúurú ẹran” nínú áàkì. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu káàkiri àgbáyé jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí.a—Jẹ́nẹ́sísì 6:19; 2 Pétérù 3:5, 6.
Pétérù pe dídá tí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà ni ‘òtítọ́ tí ó bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí’ àwọn ènìyàn kan. Lẹ́yìn náà ni àwọn olùyọṣùtì ìgbà náà mú kí àwọn mìíràn di aláìbìkítà. Ṣùgbọ́n, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tí Jèhófà ti ṣe láé. Pétérù sọ fún wa pé: “Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:7) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run yóò dá sí i lẹ́ẹ̀kan sí i.
Ọlọ́run Kò Jáfara
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi dúró fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀ láti yanjú ìṣòro aráyé? Lẹ́ẹ̀kan sí i, Pétérù darí àfiyèsí sí kókó mìíràn. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.” (2 Pétérù 3:8) Ojú ìwòye Jèhófà nípa àkókò yàtọ̀ sí tiwa. Lójú Ọlọ́run ayérayé, ìgbà tí a dá Ádámù títí di ìsinsìnyí kò tilẹ̀ tí ì tó ọ̀sẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n láìka ojú ìwòye tí a lè ní nípa àkókò sí, ẹgbẹ̀rúndún kọ̀ọ̀kan àti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí ń kọjá ń mú wa sún mọ́ àkókò tí Jèhófà yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ.
Àṣàyàn ọ̀rọ̀ náà, “jíjókòó ti omi orí ààrò, kì í jẹ́ kí ó hó bọ̀rọ̀,” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó fi hàn pé wíwulẹ̀ dúró de ìṣẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kí ó dà bí pé ó ń falẹ̀. Ṣùgbọ́n, Pétérù dámọ̀ràn “dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.” (2 Pétérù 3:12) Báwo ni a ṣe lè mú ẹ̀mí ìrònú tí ń mú kí a wà lójúfò nípa ìsúnmọ́lé dídá tí Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn ayé dàgbà?
Ìwà Ń Sọ Púpọ̀ Nípa Wa Ju Ọ̀rọ̀ Ẹnu Lásán Lọ
Pétérù darí àfiyèsí sí ìṣe àti iṣẹ́. Ó tọ́ka sí “ìṣe ìwà mímọ́” àti “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11) Kí ni ìwọ̀nyí túmọ̀ sí?
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ máa ń hùwà lọ́nà tí yóò mú inú Rẹ̀ dùn. Ìgbàgbọ́ irú olùjọsìn tòótọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń hàn nínú ìṣe rẹ̀. Èyí ń mú kí ó yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa gbígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀. Bóyá o ti ṣàkíyèsí pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún gbogbo ènìyàn mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá. Wọ́n ń kàn sí ọ nínú ilé rẹ láti darí àfiyèsí sí àwọn ìlérí Ọlọ́run tí a là lẹ́sẹẹsẹ sínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n wọ́n tún ń jẹ́rìí sí ìrètí àti ìgbàgbọ́ wọn níbikíbi tí wọ́n bá ti bá àwọn ènìyàn pàdé.
Ìgbàgbọ́ Ẹlẹ́rìí tí ọwọ́ rẹ̀ dí fún pípolongo ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn máa ń lágbára sí i, ó sì tún ń lókun sí i. Ọ̀rọ̀ tí a sọ jáde máa ń tẹ èrò mọ́ni lọ́kàn, ó ń mú inú ẹni dùn, ó sì ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá. Nígbà tí a bá ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a ń mú inú Jèhófà dùn pẹ̀lú. A mọ̀ pé òun ‘kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a ti fi hàn fún orúkọ rẹ̀,’ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì ẹlẹgbẹ́ Pétérù ti sọ.—Hébérù 6:10; Róòmù 10:9, 10.
Kí ni ìyọrísí àníyàn yìí nípa títan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀ ní àkókò tí ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí ti ń kógbá sílé? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn aláìlábòsí ọkàn ń kọ́ bí wọn yóò ṣe wá sínú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n lè jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, kí wọ́n sì rí ayọ̀ tòótọ́ nínú ìfojúsọ́nà fún ìyè ayérayé nínú párádísè ilẹ̀ ayé.
Ìmọ̀tẹ́lẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ kí a mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn ayé nígbà tí ó bá tó àkókò lójú rẹ̀, ó pọndandan pé kí a kọbi ara sí ìkìlọ̀ mìíràn tí Pétérù fún wa. “Bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.”—2 Pétérù 3:17.
Dájúdájú, Jèhófà mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan tí ìgbàgbọ́ wọn kò lágbára lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí fífalẹ̀ tí ó dà bí pé dídásí ọ̀ràn náà falẹ̀. Ó tún mọ̀ pé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lè sọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́ dìbàjẹ́ tàbí, ó kéré tán, kí wọ́n jin ìgbàgbọ́ wọn pé ìsọdimímọ́ orúkọ Ọlọ́run ti sún mọ́lé lẹ́sẹ̀. Ẹ wo bí yóò ti bani nínú jẹ́ tó láti wá ṣubú lójú ọ̀nà ìdúróṣinṣin ní àwọn àkókò òpin wọ̀nyí!
Àkókò kọ́ yìí láti ṣiyèméjì tàbí ṣe kámi-kàmì-kámi nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe. (Hébérù 12:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, àkókò nìyí láti mú ìmọrírì wa dàgbà fún ohun tí sùúrù Jèhófà ti mú wá—ìfojúsọ́nà ìgbàlà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó ti di apá kan ogunlọ́gọ̀ ńlá kárí ayé, tí ó sì ń fojú sọ́nà láti la ìpọ́njú ńlá náà tí ń bọ̀ já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Pétérù gbani níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nísinsìnyí àti títí dé ọjọ́ ayérayé.”—2 Pétérù 3:18.
“Ẹ Pa Ara Yín Mọ́ Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
Jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí fún wíwàásù Ìjọba náà àti wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé fún ìjọsìn àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dáàbò bò wá. Nípa báyìí, a kò ní ní àyè láti di ẹni tí ń ṣàníyàn jù nípa ipò tí ń bà jẹ́ sí i nínú ètò búburú ti òde òní. Kò yẹ kí ìbẹ̀rù àti àníyàn gba àyè nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni tòótọ́. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Bí ọwọ́ wa bá ṣe ń dí tó nínú sísin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ní àkókò yóò ṣe máa sáré tete lọ.
Júúdà, tí ó jẹ́ alájọgbáyé Pétérù àti iyèkan Jésù, gbà wá níyànjú pé: “Ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 20, 21) Ṣàkíyèsí ìjẹ́pàtàkì ẹ̀mí rere tí gbígbàdúrà láìdábọ̀ ń mú kí a mú dàgbà. (1 Tẹsalóníkà 5:17) Júúdà wá fi kún un pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn fún àwọn kan tí wọ́n ní iyèméjì; ẹ gbà wọ́n là nípa jíjá wọn gbà kúrò nínú iná. Ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn fún àwọn ẹlòmíràn, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ní àkókò kan náà kí ẹ kórìíra ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí ara ti kó àbààwọ́n bá.” (Júúdà 22, 23) Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì lókun ní àkókò lílekoko yìí! Ẹ sì wo bí ó ti ṣe pàtàkì láti má ṣe ṣubú sínú ìdánwò, ní lílo “ọjọ́ ìgbàlà” yìí tí a mú kí ó gùn sí i gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún “ìwà àìníjàánu,” tí ó gbalégbòde nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ ti òde òní.—Júúdà 4; 2 Kọ́ríńtì 6:1, 2.
Nípa kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Pétérù, Pọ́ọ̀lù, àti Júúdà fúnni àti nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, àti jíjẹ́ aláápọn nínú rẹ̀, o lè mú sùúrù di ìgbà tí Jèhófà yóò dá sí ọ̀ràn ayé. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
Má ṣe jáfara láti kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ládùúgbò rẹ pé kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ nínú ìlérí Ẹlẹ́dàá nípa ìyè àìnípẹ̀kun lókun. Kọ́ ohun àbéèrèfún kí a tó lè tóótun láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí kárí ayé, tí a kò tún ní padà ṣe mọ́ láé yìí, tí yóò parí nígbà ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀. (Máàkù 13:10) Nígbà náà, ìwọ yóò ní ìfojúsọ́nà fún gbígbé nínú ayé tuntun òdodo tí Jèhófà ṣèlérí. (2 Pétérù 3:13) Kọbi ara sí ìránnilétí rẹ̀! Mú sùúrù! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jọ̀wọ́ wo ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, ojú ìwé 116, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run fún Párádísè nísinsìnyí
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìkookò: Àwọn ẹranko/Jim Harter/Dover Publications, Inc.; ọ̀dọ́mọdé olùṣọ́ àgùntàn: Àwọn ọmọdé: A Pictorial Archive from Nineteenth-Century Sources/Grafton/Dover Publications, Inc.