Ẹ Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn Pẹ́kípẹ́kí
“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn olùyọṣùtì yóò wá.”—PÉTÉRÙ KEJÌ 3:3.
1. Òye ìjẹ́kánjúkánjú wo ni Kristẹni òde òní kan ní?
ÒJÍṢẸ́ alákòókò kíkún kan tí ó ti sìn fún ohun tí ó lé ní ọdún 66 kọ̀wé pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ní ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú tí ó jinlẹ̀. Lọ́kàn mi, ó máa ń dà bíi pé ọ̀la ni ó bo Amágẹ́dọ́nì lójú. (Ìṣípayá 16:14, 16) Gẹ́gẹ́ bíi bàbá mi, àti bàbá rẹ̀ tí ó wà ṣáájú rẹ̀, mo ti gbé ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì [Pétérù] ti rọni, ‘ní fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ Mo sábà máa ń wo ìlérí ayé tuntun gẹ́gẹ́ bí ‘ohun gidi bí a ò tilẹ̀ rí wọn.’”—Pétérù Kejì 3:11, 12; Hébérù 11:1; Aísáyà 11:6-9; Ìṣípayá 21:3, 4.
2. Kí ni ó túmọ̀ sí láti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí?
2 Gbólóhùn Pétérù náà, ‘fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ ní títọ́ka sí ọjọ́ Jèhófà túmọ̀ sí pé a kò mọ́kàn wa kúrò níbẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ọjọ́ náà tí Jèhófà yóò pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí run gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ ìṣáájú fún gbígbé ayé tuntun rẹ̀ tí ó ṣèlérí kalẹ̀ ti sún mọ́lé gidigidi. Ó yẹ kí ó jẹ́ gidi sí wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a óò fi lè rí i kedere, bí ẹni pé ó wà gẹ́rẹ́ níwájú wa. Bí ó ti jẹ́ gidi sí àwọn wòlíì Ọlọ́run ìgbàanì nìyẹn, wọ́n sì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó sún mọ́lé.—Aísáyà 13:6; Jóẹ́lì 1:15; 2:1; Ọbadáyà 15; Sefanáyà 1:7, 14.
3. Kí ni ó hàn gbangba pé ó sún Pétérù láti fúnni nímọ̀ràn nípa ọjọ́ Jèhófà?
3 Èé ṣe tí Pétérù fi rọ̀ wá láti wo ọjọ́ Jèhófà bí ẹni pé “ọ̀la ni ọjọ́ tí ó bò ó lójú,” kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀? Nítorí ó hàn gbangba pé àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ṣùtì sí èrò wíwàníhìn-ín Kristi tí a ti ṣèlérí, nígbà tí a óò fìyà jẹ àwọn oníwà àìtọ́. (Pétérù Kejì 3:3, 4) Nítorí náà, ní orí 3 lẹ́tà rẹ̀ kejì, tí a óò gbé yẹ̀ wò nísinsìnyí, Pétérù dáhùn ẹ̀sùn àwọn olùyọṣùtì wọ̀nyí.
Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Ọlọ́yàyà Tí Ó Yẹ Láti Rántí
4. Kí ni Pétérù fẹ́ kí a rántí?
4 Pétérù fi ìfẹ́ni tí ó ní fún àwọn ará rẹ̀ hàn nípa pípè wọ́n ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n” léraléra nínú orí yìí. Ní jíjírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti má ṣe gbàgbé ohun tí wọ́n ti kọ́, Pétérù bẹ̀rẹ̀ ní sísọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . èmi ń ru agbára ìrònú yín ṣíṣe kedere [sókè] gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí kan, pé kí ẹ̀yin máa rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín.”—Pétérù Kejì 3:1, 2, 8, 14, 17; Júúdà 17.
5. Kí ni àwọn wòlíì kan sọ nípa ọjọ́ Jèhófà?
5 Kí ni “àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú” ti Pétérù rọ àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti rántí? Họ́wù, àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wíwàníhìn-ín Kristi nínú agbára Ìjọba àti ìdájọ́ àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ni. Pétérù ti darí àfiyèsí sí àwọn àsọjáde wọ̀nyí níṣàájú. (Pétérù Kejì 1:16-19; 2:3-10) Júúdà tọ́ka sí Énọ́kù, tí ó jẹ́ wòlíì àkọ́kọ́ nínú àkọsílẹ̀ tí ó kìlọ̀ nípa ìdájọ́ mímúná tí Ọlọ́run yóò mú wá sórí àwọn olubi. (Júúdà 14, 15) Àwọn wòlíì míràn tẹ̀ lé Énọ́kù, Pétérù kò sì fẹ́ kí a gbàgbé ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀.—Aísáyà 66:15, 16; Sefanáyà 1:15-18; Sekaráyà 14:6-9.
6. Àwọn ọ̀rọ̀ Kristi àti ti àwọn àpọ́sítélì wo ni ó túbọ̀ là wá lóye nípa ọjọ́ Jèhófà?
6 Ní àfikún sí i, Pétérù sọ fún àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti rántí “àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà.” Àṣẹ Jésù ní ìṣílétí náà nínú pé: “Ẹ kíyè sí ara yín kí ọkàn àyà yín má baà di èyí tí a dẹrù pa . . . lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn.” “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ máa wà lójúfò, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Lúùkù 21:34-36; Máàkù 13:33) Pétérù tún rọ̀ wá láti kọbi ara sí ọ̀rọ̀ àwọn àpọ́sítélì. Fún àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòó kù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—Tẹsalóníkà Kíní 5:2, 6.
Ìfẹ́ Ọkàn Àwọn Olùyọṣùtì
7, 8. (a) Irú àwọn ènìyàn wo ni wọ́n ń yọ ṣùtì sí ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọ́run? (b) Kí ni àwọn olùyọṣùtì ń sọ?
7 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, ìdí tí Pétérù fi sọ ọ̀rọ̀ ìṣílétí yìí ni pé àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gàn irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ìjímìjí ṣe fi àwọn wòlíì Jèhófà ṣẹlẹ́yà. (Kíróníkà Kejì 36:16) Pétérù ṣàlàyé pé: “Nítorí ẹ̀yin mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn ti ara wọn.” (Pétérù Kejì 3:3) Júúdà sọ pé ìfẹ́ ọkàn àwọn olùyọṣùtì wọ̀nyí jẹ́ “fún àwọn ohun tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.” Ó pè wọ́n ní “àwọn ẹni bí ẹran, tí wọn kò ní ìfẹ́ ohun ti ẹ̀mí.”—Júúdà 17-19.
8 Ó ṣeé ṣe kí àwọn olùkọ́ èké tí Pétérù sọ pé wọ́n “ń tọ ẹran ara lẹ́yìn pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin” wà lára àwọn olùyọṣùtì wọ̀nyí tí wọn kò ní ojú ìwòye tẹ̀mí. (Pétérù Kejì 2:1, 10, 14) Wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ lọ́nà ìfiṣẹlẹ́yà pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yí tí a ti ṣèlérí náà dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”—Pétérù Kejì 3:4.
9. (a) Èé ṣe tí àwọn olùyọṣùtì fi ń fojú kéré òye ìjẹ́kánjúkánjú tí ó kún inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo ni fífi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí ṣe jẹ́ ààbò fún wa?
9 Kí ní fa ìyọṣùtì yí? Èé ṣe tí wọ́n fi sọ pé wìwàníhìn-ín Kristi lè má ṣẹlẹ̀ mọ́, pé Ọlọ́run kò dá sí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn rí àti pé kò sì ní dá sí i láé? Toò, nípa fífojúkéré òye ìjẹ́kánjúkánjú tí ó kún inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ẹni bí ẹran tí wọ́n ń yọ ṣùtì wọ̀nyí ń wọ́nà láti mú kí àwọn mìíràn jọ̀gọnù, kí wọ́n má bìkítà nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì tipa báyìí mú kí wọ́n di ẹran ọdẹ tí ó rọrùn fún ẹ̀tàn onímọtara-ẹni-nìkan. Ẹ wo irú ìṣírí lílágbára tí èyí jẹ́ fún wa lónìí láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí! Ǹjẹ́ kí a fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, kí a sì máa rántí nígbà gbogbo pé ojú rẹ̀ wà lára wa! Nípa báyìí, a óò sún wa láti fi ìtara ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, kí a sì pa ìjẹ́mímọ́ wa ní ti ìwà híhù mọ́.—Orin Dáfídì 11:4; Aísáyà 29:15; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 8:12; 12:27; Sefanáyà 1:12.
Ìwà Àmọ̀ọ́mọ̀hù àti Akóninírìíra
10. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé àwọn olùyọṣùtì kò tọ̀nà?
10 Irú àwọn olùyọsùtì bẹ́ẹ̀ kò ka òkodoro òtítọ́ tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn sí. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìkà á sí, wọ́n sì gbìyànjú láti mú kí àwọn ẹlòmíràn gbàgbé rẹ̀. Èé ṣe? Kí ó baà lè túbọ̀ rọrùn fún wọn láti tan àwọn ènìyàn jẹ. Pétérù kọ̀wé pé: “Nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òkodoro òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn.” Òkodoro òtítọ́ wo? “Pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbídigbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ àwọn ohun àmúlò wọnnì ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” (Pétérù Kejì 3:5, 6) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé nígbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, òkodoro òtítọ́ tí Jésù pẹ̀lú tẹnu mọ́. (Mátíù 24:37-39; Lúùkù 17:26, 27; Pétérù Kejì 2:5) Nítorí náà, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí àwọn olùyọṣùtì sọ, ohun gbogbo kò bá a lọ “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”
11. Kí ni àwọn ohun tí àwọn Kristẹni ìjímìjí ń retí, tí àkókò rẹ̀ kò tí ì tó, tí ó mú kí àwọn kan yọ ṣùtì sí wọn?
11 Àwọn olùyọṣùtì ti lè máa fi àwọn Kristẹni olùṣòtìtọ́ ṣẹlẹ́yà nítorí pé ohun tí àwọn wọ̀nyí ti ń retí kò tí ì dé síbẹ̀síbẹ̀. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Jésù kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “lérò pé ìjọba Ọlọ́run yóò fi ara rẹ̀ hàn sóde ní ìṣẹ́jú akàn.” Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, wọ́n béèrè bóyá a óò gbé Ìjọba náà kalẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Bákan náà, ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ṣáájú kí Pétérù tó kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì, “ìhìn iṣẹ́ àfẹnusọ” tàbí “lẹ́tà kan” tí àwọn kan gbà gbọ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, “tí ń wí pé ọjọ́ Jèhófà ti dé,” “ru” àwọn kan “sókè.” (Lúùkù 19:11; Tẹsalóníkà Kejì 2:2; Ìṣe 1:6) Ṣùgbọ́n, irú ìrètí bẹ́ẹ̀, tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní, kì í ṣe ìrètí asán, ó wulẹ̀ jẹ́ ríretí ohun tí àkókò rẹ̀ kò tí ì tó ni. Ọjọ́ Jèhófà yóò dé!
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣeé Gbára Lé
12. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òun tó gbára lé nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà”?
12 Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án ṣáájú, àwọn wòlíì tí wọ́n wà ṣáájú sànmánì Kristẹni sábà máa ń kìlọ̀ pé ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà ti sún mọ́lé. “Ọjọ́ Jèhófà” lọ́nà kékeré dé ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jèhófà mú ẹ̀san wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ oníwà wíwọ́. (Sefanáyà 1:14-18) Lẹ́yìn náà, àwọn orílẹ̀-èdè míràn, títí kan Bábílónì àti Íjíbítì, jìyà irú “ọjọ́ Jèhófà” bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 13:6-9; Jeremáyà 46:1-10; Ọbadáyà 15) A tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní pẹ̀lú, ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jùdíà run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. (Lúùkù 19:41-44; Pétérù Kíní 4:7) Ṣùgbọ́n “ọjọ́ Jèhófà” tí ó wà níwájú, ọ̀kan tí yóò mú kí Ìkún Omi àgbáyé dà bí erémọdé ni Pétérù ń tọ́ka sí!
13. Àpẹẹrẹ ìtàn wo ni ó fi hàn pé òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí dájú ṣáká?
13 Pétérù nasẹ̀ àpèjúwe rẹ̀ nípa ìparun náà tí ń bọ̀, ní sísọ pé: “Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà.” Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé “nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ilẹ̀ ayé tí ó wà ṣáájú Ìkún Omi dúró “láti inú omi àti ní àárín omi.” Ipò yí, tí a ṣàpèjúwe nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá mú kí Àkúnya náà ṣeé ṣe nígbà tí omi náà ya lulẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ tàbí sọ bẹ́ẹ̀. Pétérù ń bá a nìṣó pé: “Nípa ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run] kan náà àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (Pétérù Kejì 3:5-7; Jẹ́nẹ́sísì 1:6-8) Fún èyí, a ní ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ṣeé gbára lé! Yóò mú òpin dé bá “àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé”—ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí—nínú ìrunú gbígbóná janjan ti ọjọ́ ńlá rẹ̀! (Sefanáyà 3:8) Ṣùgbọ́n nígbà wo?
Ìháragàgà Pé Kí Òpin Náà Dé
14. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ni a ń gbé nísinsìnyí?
14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ mọ ìgbà tí òpin náà yóò dé, nítorí náà wọ́n bi í pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” Ó hàn gbangba pé wọ́n ń béèrè ìgbà tí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù yóò wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìdáhùn Jésù darí àfiyèsí ní pàtàkì sí ìgbà tí “àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” ìsinsìnyí yóò pa run. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa irú àwọn nǹkan bí ogun ńlá, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àrùn, àti ìwà ọ̀daràn. (Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:5-36) Láti ọdún 1914, a ti rí i bí àmì tí Jésù fúnni fún “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” àti àwọn nǹkan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn pé yóò sàmì sí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ń nímùúṣẹ. (Tímótì Kejì 3:1-5) Lóòótọ́, ẹ̀rí náà pọ̀ rẹpẹtẹ pé a ń gbé ní àkókò òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí!
15. Kí ni àwọn Kristẹni ti ṣe láìka ìkìlọ̀ Jésù sí?
15 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń hára gàgà láti mọ ìgbà ti ọjọ́ Jèhófà yóò dé. Nínú ìháragàgà wọn, wọ́n ti gbìdánwò nígbà míràn láti fojú díwọ̀n ìgbà tí yóò dé. Ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ti kùnà láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọ̀gá wọn pé a “kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́,” gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ti ṣe. (Máàkù 13:32, 33) Àwọn olùyọṣùtì ti fi àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ṣẹlẹ́yà nítorí tí wọ́n ń retí ohun tí àkókò rẹ̀ kó tí ì tó. (Pétérù Kejì 3:3, 4) Síbẹ̀síbẹ̀, Pétérù mú un dáni lójú pé, ọjọ́ Jèhófà yóò dé, ní àkókó tí Òun ṣètò pé yóò dé.
Ìjẹ́pàtàkì Níní Ojú Ìwòye Jèhófà
16. Ìṣílétí wo ni ó bọ́gbọ́n mu kí a kọbi ara sí?
16 Ó ṣe pàtàkì pé kí a ní ojú ìwòye Jèhófà nípa àkókò, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti rán wa létí nísinsìnyí pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ má ṣe jẹ́ kí òkodoro òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.” Ẹ wo bí àkókò ìgbésí ayé wa tí ó jẹ́ 70 tàbí 80 ọdún ti kúrú tó ní ìfiwéra! (Pétérù Kejì 3:8; Orin Dáfídì 90:4, 10) Nítorí náà, bí ó bá dà bíi pé ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run ń falẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a tẹ́wọ́ gba ìṣílétí wòlíì Ọlọ́run pé: “Bí [àkókò tí a yàn kalẹ̀] tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
17. Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tilẹ̀ ń gùn ju bí ọ̀pọ̀ ti retí lọ, kí ni a lè ní ìdánilójú nípa rẹ̀?
17 Èé ṣe tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí fi gùn ju bí ọ̀pọ̀ ti retí lọ? Ó jẹ́ fún ìdí rere kan, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (Pétérù Kejì 3:9) Jèhófà máa ń gba ohun tí ó ṣàǹfààní jù lọ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn yẹ̀ wò. Ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni ó jẹ ẹ́ lógún, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé: “Èmi kò ní inú dídùn ní ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n kí ènìyàn búburú yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀ kí ó sì yè.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:11) Nítorí náà, a lè ní ìdánilójú pé òpin náà yóò dé ní àkókò gan-an tí ó yẹ kí ó dé láti lè mú ète Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n gbogbo ṣẹ!
Kí Ni Yóò Kọjá Lọ?
18, 19. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi pinnu láti pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí run? (b) Báwo ni Pétérù ṣe ṣàpèjúwe òpin ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí, kí sì ni a óò pa run ní ti gidi?
18 Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí àwọn tí ń sìn ín ní tòótọ́, òun yóò mú gbogbo àwọn tí ń mú ìrora ọkàn bá wọn kúrò. (Orin Dáfídì 37:9-11, 29) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ níṣàájú pé ìparun yìí yóò dé ní àkókò tí a kò retí, Pétérù kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a óò sì wá rí.” (Pétérù Kejì 3:10; Tẹsalóníkà Kíní 5:2) Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí a lè fojú rí kò pa run nínú Àkúnya náà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní pa run ní ọjọ́ Jèhófà. Nígbà náà, kí ni yóò “kọjá lọ” tàbí tí a óò pa run?
19 Àwọn ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti jẹ gàba lé aráyé lórí, tí ó dà bí “àwọn ọ̀run” yóò wá sópin, bẹ́ẹ̀ náà sì ni “ilẹ̀ ayé,” tàbí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí “ariwo ṣì-ì-ì” náà tọ́ka sí bí àwọn ọ̀run náà yóò ṣe yára kọjá lọ féhú. “Àwọn ohun ìpìlẹ̀” tí ó para pọ̀ jẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti bà jẹ́ lónìí yóò “di yíyọ́,” tàbí pa run. “Ilẹ̀ ayé” títí kan “àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀,” ni a óò sì “wá rí.” Jèhófà yóò tú ìwà búburú àwọn ènìyàn fó pátápátá bí ó ṣe ń mú ètò ìgbékalẹ̀ ayé látòkè délẹ̀ wá sí òpin tí ó yẹ ẹ́.
Pọkàn Pọ̀ Sórí Ìrètí Rẹ
20. Báwo ni òye wa nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wà níwájú ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa?
20 Níwọ̀n bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnitagìrì wọ̀nyí ti ń sún mọ́lé, Pétérù sọ pè ó yẹ kí a lọ́wọ́ “nínú àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsìn Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà.” Kò lè sí iyè méjì kankan nípa rẹ̀! “Àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́ tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́!” (Pétérù Kejì 3:11, 12) Òkodoro òtítọ́ náà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnitagìrì wọ̀nyí lè ṣẹlẹ̀ lọ́la yẹ kí ó nípa lórí gbogbo ohun tí a bá ń ṣe tàbí tí a ń wéwèé láti ṣe.
21. Kí ni yóò rọ́pò àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí?
21 Wàyí o, Pétérù sọ ohun tí yóò rọ́pò ètò ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó fún wa, ní sísọ pé: “Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (Pétérù Kejì 3:13; Aísáyà 65:17) Áà, ìtura ńláǹlà ní èyí mà jẹ́ o! Kristi àti àwọn 144,000 àjùmọ̀ṣàkóso rẹ̀ ni yóò para pọ̀ jẹ́ “àwọn ọ̀run” ìṣàkóso “tuntun,” àwọn ènìyàn tí wọ́n la òpin ayé yìí já ni yóò sì para pọ̀ jẹ́ “ilẹ̀ ayé tuntun.”—Jòhánù Kíní 2:17; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3.
Pa Òye Ìjẹ́kánjúkánjú àti Ìjẹ́mímọ́ Ní Ti Ìwà Híhù Mọ̀
22. (a) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀gbin tàbí àbààwọ́n èyíkéyìí nípa tẹ̀mí? (b) Ewu wo ni Pétérù kìlọ̀ nípa rẹ̀?
22 Pétérù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà. Síwájú sí i, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” Fífi ìháragàgà dúró àti kíka ohunkóhun tí ó lè jọ bíi ìjáfara ọjọ́ Jèhófà sí ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà fi sùúrù rẹ̀ hàn, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀gbin tàbí àbààwọ́n nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, ewu ń bẹ! Pétérù kìlọ̀ pé nínú àwọn lẹ́tà “Pọ́ọ̀lù arákùnrin wa olùfẹ́ ọ̀wọ́n . . . àwọn ohun kan tí ó nira láti lóye wà nínú wọn, èyí tí àwọn aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn aláìdúrósójúkan ń lọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń lọ́ àwọn Ìwé Mímọ́ yòó kù pẹ̀lú, sí ìparun ara wọn.”—Pétérù Kejì 3:14-16.
23. Báwo ni Pétérù ṣe mú ìṣílétí rẹ̀ wá sí ìparí?
23 Ó hàn gbangba pé àwọn olùkọ́ èké lọ́ àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ní lílò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún ìwà àìníjàánu. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù ní èyí lọ́kàn nígbà tí ó kọ ọ̀rọ̀ ìṣílétí rẹ̀ tí ó fi dágbére pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí á má baà mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn ènìyàn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín fúnra yín.” Lẹ́yìn náà, ó parí lẹ́tà rẹ̀, ní rírọni pé: “Ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.”—Pétérù Kejì 3:17, 18.
24. Ìṣarasíhùwà wo ni ó yẹ kí gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ní?
24 Ó ṣe kedere pé, Pétérù fẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ lókun. Ó fẹ́ kí gbogbo wọn ní irú ìṣarasíhùwà tí Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ ẹni ọdún 82 tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ yẹn ní, ẹni tí ó sọ pé: “Mo ti lo ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì ti rọni, ‘ní fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ Mo sábà máa ń wo ìlérí ayé tuntun gẹ́gẹ́ bí ‘ohun gidi bí a ò tilẹ̀ rí wọn.’” Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà kan náà.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Kí ni “fífi” ọjọ́ Jèhófà “sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí” túmọ̀ sí?
◻ Kí ni àwọn olùyọṣùtì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìkà sí, èé sì ti ṣe?
◻ Èé ṣe tí àwọn olùyọṣùtì fi fi àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ṣẹlẹ́yà?
◻ Ojú ìwòye wo ni ó ṣe pàtàkì pé kí a dì mú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí . . .
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
. . . àti ayé tuntun tí yóò tẹ̀ lé e