Ẹ Jẹ́ Kí A Di Ìgbàgbọ́ Wa Ṣíṣeyebíye Mú Ṣinṣin!
“Sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti gba ìgbàgbọ́ kan, tí a dì mú nínú ọlá àǹfààní dídọ́gba pẹ̀lú tiwa.”—PÉTÉRÙ KEJÌ 1:1.
1. Kí ni Jésù sọ ní kíkìlọ̀ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, síbẹ̀ báwo ni Pétérù ṣe fọ́nnu?
NÍ ALẸ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ pé gbogbo àwọn àpọ́sítélì òun ni yóò fi òun sílẹ̀. Pétérù, ọ̀kan lára wọn, fọ́nnu pé: “Bí a bá tilẹ̀ mú gbogbo àwọn yòó kù kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, dájúdájú a kì yóò mú èmi kọsẹ̀ láé!” (Mátíù 26:33) Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi sọ fún Pétérù ní àkókò kan náà yẹn pé: “Èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ kí ìgbàgbọ́ rẹ má baà yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti pa dà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”—Lúùkù 22:32.
2. Láìka pé Pétérù dá ara rẹ̀ lójú jù sí, àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ wo ni ó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́ ahẹrẹpẹ?
2 Pétérù, tí ó dá ara rẹ̀ lójú jù nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, sẹ́ Jésù ní òru ọjọ́ yẹn gan-an. Ìgbà mẹ́ta ni ó sẹ́ pé òun tilẹ̀ mọ Kristi rárá! (Mátíù 26:69-75) Nígbà tí ó “pa dà,” ọ̀rọ̀ náà tí Ọ̀gá rẹ̀ sọ pé, “fún àwọn arákùnrin rẹ lókun,” ti gbọ́dọ̀ máa dún gbọnmọgbọnmọ létí rẹ̀. Ìṣílétí yẹn ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé Pétérù láti ìgbà yẹn wá, gẹ́gẹ́ bíi lẹ́tà méjèèjì tí ó kọ, tí a pa mọ́ nínú Bíbélì, ti fi hàn.
Ìdí Tí Pétérù Fi Kọ Lẹ́tà Rẹ̀
3. Èé ṣe tí Pétérù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́?
3 Ní nǹkan bí 30 ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, sí àwọn arákùnrin rẹ̀ ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà, àti Bítíníà, àwọn àgbègbè tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ àríwá àti ìwọ̀ oòrùn Turkey nísinsìnyí. (Pétérù Kíní 1:1) Kò sí iyè méjì pé àwọn Júù, tí ó lè jẹ́ pé Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni díẹ̀ lára wọn di Kristẹni, wà lára àwọn tí Pétérù kọ̀wé sí. (Ìṣe 2:1, 7-9) Ọ̀pọ̀ jẹ́ Kèfèrí tí wọ́n dojú kọ àdánwò gbígbóná janjan láti ọ̀dọ̀ àwọn alátakò. (Pétérù Kíní 1:6, 7; 2:12, 19, 20; 3:13-17; 4:12-14) Nítorí náà, Pétérù kọ̀wé sí àwọn ará wọ̀nyí láti fún wọn níṣìírí. Ète rẹ̀ jẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba ‘òpin ìgbàgbọ́ wọn, ìgbàlà ọkàn wọn.’ Nípa báyìí, nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére tí ó fi ṣí wọn létí, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—Pétérù Kíní 1:9; 5:8-10.
4. Èé ṣe tí Pétérù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì?
4 Lẹ́yìn náà, Pétérù kọ lẹ́tà kejì sí àwọn Kristẹni wọ̀nyí. (Pétérù Kejì 3:1) Èé ṣe? Nítorí pé ewu ńláǹlà kan wà lórí wọn. Àwọn oníwà pálapàla yóò gbìyànjú láti gbé ìwà wọn tí ń sọni dẹlẹ́gbin lárugẹ láàárín àwọn onígbàgbọ́, wọn yóò sì ṣi àwọn kan lọ́nà! (Pétérù Kejì 2:1-3) Ní àfikún sí i, Pétérù kìlọ̀ nípa àwọn olùyọṣùtì. Ó kọ ọ́ sínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ pé “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé,” nísinsìnyí, ó sì hàn gbangba pé àwọn kan ń kẹ́gàn èrò náà. (Pétérù Kíní 4:7; Pétérù Kejì 3:3, 4) Ẹ jẹ́ kí a gbé lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ yẹ̀ wò, kí a sì rí bí ó ṣe fún àwọn ará náà lókun láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ yìí, a óò gbé Pétérù Kejì orí 1 yẹ̀ wò.
Ète Orí 1
5. Báwo ni Pétérù ṣe múra àwọn òǹkàwé rẹ̀ sílẹ̀ fún jíjíròrò ìṣòro?
5 Kì í ṣe lẹ́sẹ̀ kan náà ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro ńlá náà. Dípò èyí, ó múra sílẹ̀ fún jíjíròrò àwọn ìṣòro wọ̀nyí nípa mímú kí ìmọrírì wọ́n pọ̀ sí i fún ohun tí wọ́n rí gbà nígbà tí wọ́n di Kristẹni. Ó rán wọn létí àwọn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe àti bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ṣeé gbára lé tó. Ó ṣe èyí nípa sísọ fún wọn nípa ìyípadà ológo, ìran tí òun fúnra rẹ̀ rí nípa Kristi nínú agbára Ìjọba.—Mátíù 17:1-8; Pétérù Kejì 1:3, 4, 11, 16-21.
6, 7. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ lẹ́tà Pétérù? (b) Bí a bá ń fúnni nímọ̀ràn, kí ni ó yẹ kí a gbà pé a jẹ́, tí ó sì lè ranni lọ́wọ́ nígbà míràn?
6 A ha lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ láti inú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ Pétérù bí? Ìmọ̀ràn kì í ha ń túbọ̀ rọrùn láti gbà, bí a bá kọ́kọ́ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn apá kíkọyọyọ ti ìrètí Ìjọba tí àwa àti àwọn tí a ń fún nímọ̀ràn jọ ṣìkẹ́ bí? Lílo àwọn ìrírí tiwa fúnra wa ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn ikú Jésù, Pétérù ti sọ nípa rírí tí ó rí ìran Kristi nínú ògo Ìjọba fún àwọn ènìyàn lọ́pọ̀ ìgbà.—Mátíù 17:9.
7 Rántí pẹ̀lú pé, ó ṣeé ṣe dáadáa pé, nígbà tí Pétérù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì, a ti pín Ìhìn Rere Mátíù àti lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Gálátíà káàkiri. Nítorí náà, àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó Pétérù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn àti àkọsílẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti lè di ohun tí ó ti di mímọ̀ fún àwọn alájọgbáyé rẹ̀. (Mátíù 16:21-23; Gálátíà 2:11-14) Ṣùgbọ́n, èyí kò gba òmìnira rẹ̀ láti sọ̀rọ̀ fàlàlà lọ́wọ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, ó ti lè mú kí lẹ́tà rẹ̀ túbọ̀ fa àwọn tí àìlera wọn jẹ wọ́n lọ́kàn mọ́ra. Nítorí náà, nígbà tí a bá ń ran àwọn tí wọ́n ní ìṣòro lọ́wọ́, kò ha ní dára láti gbà pé àwa pẹ̀lú lè ṣàṣìṣe bí?—Róòmù 3:23; Gálátíà 6:1.
Ìkíni Tí Ń Fúnni Lókun
8. Ọ̀nà wo ni Pétérù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìgbàgbọ́”?
8 Wàyí o, gbé ìkíni Pétérù yẹ̀ wò. Lójú ẹsẹ̀ ni ó mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, ní pípe àwọn òǹkàwé rẹ̀ ní “àwọn wọnnì tí wọ́n ti gba ìgbàgbọ́ kan, tí a dì mú nínú ọlá àǹfààní dídọ́gba pẹ̀lú tiwa.” (Pétérù Kejì 1:1) Níhìn-ín, ọ̀rọ̀ náà, “ìgbàgbọ́ kan,” ṣeé ṣe kí ó túmọ̀ sí “ìyíniléròpadà fífẹsẹ̀ múlẹ̀,” ó sì ń tọ́ka sí àgbájọ ìgbàgbọ́ tàbí ẹ̀kọ́ Kristẹni, tí a pè ní “òtítọ́” nínú Ìwé Mímọ́ nígbà míràn. (Gálátíà 5:7; Pétérù Kejì 2:2; Jòhánù Kejì 1) Ọ̀rọ̀ náà “ìgbàgbọ́” ni a sábà máa ń lò lọ́nà yí dípò ọ̀nà tí a sábà máa ń gbà lò ó, ní ìtumọ̀ ti ìgbẹ́kẹ̀lé tàbí ìgbọ́kànlé tí a ní nínú ẹnì kan tàbí ohun kan.—Ìṣe 6:7; Kọ́ríńtì Kejì 13:5; Gálátíà 6:10; Éfésù 4:5; Júúdà 3.
9. Èé ṣe tí ìkíni Pétérù ti lè jẹ́ èyí tí ó mú inú àwọn Kèfèrí dùn gan-an?
9 Ní pàtàkì, ìkíni Pétérù ti gbọ́dọ̀ mú inú àwọn Kèfèrí tí wọ́n kàwé rẹ̀ dùn gan-an. Àwọn Júù kì í bá àwọn Kèfèrí da ohunkóhun pọ̀, wọ́n tilẹ̀ ń ṣáátá wọn, ẹ̀tanú sí àwọn Kèfèrí sì ń bá a lọ láàárín àwọn Júù tí wọ́n ti di Kristẹni. (Lúùkù 10:29-37; Jòhánù 4:9; Ìṣe 10:28) Síbẹ̀, Pétérù, tí a bí gẹ́gẹ́ bíi Júù kan, tí ó sì jẹ́ àpọ́sítélì Jésù Kristi, sọ pé àwọn òǹkàwé òun—àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí—ní ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú òun, wọ́n sì gbádùn ọlá àǹfààní dídọ́gba pẹ̀lú òun.
10. Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ nínú ìkíni Pétérù?
10 Ronú nípa ẹ̀kọ́ àtàtà tí ìkíni Pétérù kọ́ wa lónìí. Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú; kì í fojú rere hàn sí ẹ̀yà ìran kan tàbí orílẹ̀-èdè kan ju èkejì lọ. (Ìṣe 10:34, 35; 11:1, 17; 15:3-9) Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ti kọ́ni, gbogbo Kristẹni jẹ́ ará, kò sì yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa rò pé ẹ̀yà tòun ni ó ṣe pàtàkì jù. Ní àfikún sí i, ìkíni Pétérù tẹnu mọ́ ọn pé ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni wá, tí a di “àǹfààní dídọ́gba” mú, ìgbàgbọ́ tí Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní.—Mátíù 23:8; Pétérù Kíní 5:9.
Ìmọ̀ àti Ìlérí Ọlọ́run
11. Lẹ́yìn ìkíni rẹ̀, kí ni àwọn ohun tí ó ṣe kókó tí Pétérù tẹnu mọ́?
11 Lẹ́yìn ìkíni rẹ̀, Pétérù kọ̀wé pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín.” Báwo ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà ṣe lè pọ̀ sí i fún wa? Pétérù fèsì pé: “Nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti nípa Jésù Olúwa wa.” Lẹ́yìn náà ó sọ pé: “Agbára àtọ̀runwá rẹ̀ ti fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ gbogbo ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìyè àti ìfọkànsin Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe rí àwọn ohun tí ó ṣe kókó wọ̀nyí gbà? “Nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa ẹni náà tí ó pè wá nípasẹ̀ ògo àti ìwà funfun.” Nípa báyìí, ìgbà méjì ni Pétérù tẹnu mọ́ ọn pé ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe kókó.—Pétérù Kejì 1:2, 3; Jòhánù 17:3.
12. (a) Èé ṣe tí Pétérù fi tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ pípéye? (b) Láti gbádùn ìlérí Ọlọ́run, kí ni a ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe?
12 “Àwọn olùkọ́ èké” tí Pétérù kìlọ̀ nípa wọn ní orí 2 lo “àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀” láti tan àwọn Kristẹni jẹ. Lọ́nà yí, wọ́n gbìyànjú láti ré wọ́n lọ pa dà sínú ìwà pálapàla tí a ti dá wọn nídè kúrò nínú rẹ̀. Ohun tí yóò yọrí sí fún ẹnikẹ́ni tí a ti gbà là nípasẹ̀ “ìmọ̀ pípéye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà wa,” tí ó wá juwọ́ sílẹ̀ fún irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kò ní dára rárá. (Pétérù Kejì 2:1-3, 20) Ó ṣe kedere pé ní híháragàgà láti jíròrò ìṣòro yìí nígbà tí ó bá yá, ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀, Pétérù tẹnu mọ́ ipa tí ìmọ̀ pípéye ń kó nínú dídi ìdúró mímọ́ mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Pétérù ṣàkíyèsí pé Ọlọ́run “ti fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye àti títóbilọ́lá gan-an, kí [àwa] lè tipasẹ̀ ìwọ̀nyí di alájọpín ìwà ẹ̀dá ti ọ̀run.” Síbẹ̀, Pétérù sọ pé, láti gbádùn àwọn ìlérí wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbàgbọ́ wa, a gbọ́dọ̀ ti kọ́kọ́ “yè bọ́ kúrò nínú ìdíbàjẹ́ tí ó wà nínú ayé nípasẹ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.”—Pétérù Kejì 1:4.
13. Kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn míràn” ní láti pinnu láti dì mú ṣinṣin?
13 Ojú wo ni o fi ń wo ìlérí Ọlọ́run? Ṣe ojú tí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró Kristẹni fi ń wò ó ni? Ní 1991, Frederick Franz, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, tí ó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ohun tí ó lé ní ọdún 75, ṣàkópọ̀ ìmọ̀lára àwọn wọnnì tí wọ́n retí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi pé: “A ń dúró gbọn-ingbọn-in títí di wákàtí yìí, a óò sì dúró gbọn-ingbọn-in títí di ìgbà tí Ọlọ́run bá fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ sí ‘àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye àti títóbilọ́lá rẹ̀ gan-an.’” Arákùnrin Franz di ìgbọ́kànlé rẹ̀ mú nínú ìlérí Ọlọ́run nípa àjíǹde sí ọ̀run, ó sì di ìgbàgbọ́ náà mú ṣinṣin títí di ìgbà tí ó fi kú ní ẹni ọdún 99. (Kọ́ríńtì Kíní 15:42-44; Fílípì 3:13, 14; Tímótì Kejì 2:10-12) Bákan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń di ìgbàgbọ́ náà mú ṣinṣin, ní pípọkàn wọn pọ̀ sórí ìlérí Ọlọ́run nípa párádísè ilẹ̀ ayé nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò máa gbé títí láé nínú ayọ̀. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí bí?—Lúùkù 23:43; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìdáhùnpadà sí Àwọn Ìlérí Ọlọ́run
14. Èé ṣe tí Pétérù fi mẹ́nu kan ìwà funfun gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ àkọ́kọ́ tí a ní láti fi kún ìgbàgbọ́?
14 A ha kún fún ìmoore sí Ọlọ́run fún ohun tí ó ṣèlérí bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Pétérù ṣàlàyé pé, a gbọ́dọ̀ fi í hàn. “Bẹ́ẹ̀ ni, fún ìdí yìí gan-an” (nítorí pé Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye fún wa), o yẹ kí a sapá gidigidi láti gbégbèésẹ̀. Wíwà nínú ìgbàgbọ́ nìkan tàbí wíwulẹ̀ mọ òtítọ́ Bíbélì kò lè tẹ́ wa lọ́rùn. Ìyẹn kò tó! Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ní ọjọ́ Pétérù, àwọn kan nínú ìjọ sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla. Ó yẹ kí ìwà wọn jẹ́ ìwà funfun, nítorí náà Pétérù rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ pèsè ìwà funfun kún ìgbàgbọ́ yín.”—Pétérù Kejì 1:5; Jákọ́bù 2:14-17.
15. (a) Èé ṣe tí a fi mẹ́nu kan ìmọ̀ lẹ́yìn ìwà funfun, gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ kan tí a óò fi kún ìgbàgbọ́? (b) Àwọn ànímọ́ mìíràn wo ni yóò mú wa gbára dì láti di ìgbàgbọ́ wa mú ṣinṣin?
15 Lẹ́yìn mímẹ́nukan ìwà funfun, Pétérù to àwọn ànímọ́ mẹ́fà tí a ní láti pèsè tàbí fi kún ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹẹsẹ. A nílò ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyí bí a óò bá “dúró gbọn-ingbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 16:13) Nítorí àwọn apẹ̀yìndà “ń lọ́ àwọn Ìwé Mímọ́,” tí wọ́n sì ń gbé “àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ” kalẹ̀, Pétérù mẹ́nu kan ìmọ̀ ṣèkejì gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe kókó, ní sísọ pé: “[Ẹ pèsè] ìmọ̀ kún ìwà funfun yín.” Lẹ́yìn náà ó ń bá a nìṣó pé: “Ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín, ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfẹ́ni ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín.”—Pétérù Kejì 1:5-7; 2:12, 13; 3:16.
16. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá fi àwọn ànímọ́ tí Pétérù mẹ́nu kàn kún ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀?
16 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá fi àwọn nǹkan méje wọ̀nyí kún ìgbàgbọ́ wa? Pétérù fèsì pé: “Bí àwọn nǹkan wọnnì bá wà nínú yín tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ di yálà aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.” (Pétérù Kejì 1:8) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Pétérù sọ pé: “Bí àwọn nǹkan wọ̀nyí kò bá sí nínú ẹnikẹ́ni, òun fọ́jú, ó di ojú rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀, ó sì ti di ẹni tí ó gbàgbé ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” (Pétérù Kejì 1:9) Ṣàkíyèsí pé Pétérù kò lo “yín” àti “wa” mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lo “ẹnikẹ́ni,” “ó,” àti “rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn kan fọ́jú, wọ́n jẹ́ alákọ̀ọ́gbàgbé, àti aláìmọ́, lọ́nà tí ó fi inú rere hàn, Pétérù kò dọ́gbọ́n sọ pé òǹkàwé náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí.—Pétérù Kejì 2:2.
Fífún Àwọn Ará Rẹ̀ Lókun
17. Kí ni ó ti lè súnná sí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Pétérù ṣe láti máa ṣe “àwọn nǹkan wọ̀nyí”?
17 Bóyá nítorí tí ó mọ̀ pé àwọn ẹni tuntun ní pàtàkì rọrùn láti tàn jẹ, Pétérù fún wọn níṣìírí lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè àti yíyàn yín dájú fún ara yín; nítorí bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ẹ kì yóò kùnà lọ́nàkọnà láé.” (Pétérù Kejì 1:10; 2:18) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí ń fi àwọn nǹkan méje wọ̀nyí kún ìgbàgbọ́ wọn yóò gbádùn èrè kíkọyọyọ, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ pé: “A óò pèsè fún yín lọ́pọ̀ jaburata ìwọlé sínú ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (Pétérù Kejì 1:11) “Àwọn àgùntàn míràn” yóò rí ogún ayérayé gbà lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 10:16; Mátíù 25:33, 34.
18. Èé ṣe ti Pétérù fi múra tán “nígbà gbogbo láti rán” àwọn arákùnrin rẹ̀ “létí”?
18 Pétérù fi gbogbo ọkàn fẹ́ kí àwọn ará òun rí irú èrè títóbilọ́lá bẹ́ẹ̀ gbà. Ó kọ̀wé pé: “Fún ìdí yìí èmi yóò múra tán nígbà gbogbo láti rán yín létí àwọn nǹkan wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin mọ̀ wọ́n tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú òtítọ́ tí ó wà nínú yín.” (Pétérù Kejì 1:12) Pétérù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ste·riʹzo, tí a tú sí “ẹ . . . fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” níhìn-ín, ṣùgbọ́n tí a tú sí ‘fún lókun’ nínú ọ̀rọ̀ ìsílétí Jésù sí Pétérù ní ìṣáájú pé: “Fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) Ìlò ọ̀rọ̀ náà lè fi hàn pé Pétérù rántí ọ̀rọ̀ ìṣílétí lílágbára tí ó gbà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wàyí o, Pétérù sọ pé: “Mo kà á sí pé ó tọ̀nà, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nínú àgọ́ yìí [ara ẹ̀dá ènìyàn], láti ta yín jí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rán yín létí, bí mo ti mọ̀ ní tòótọ́ pé bíbọ́ àgọ́ mi kúrò yóò wáyé láìpẹ́.”—Pétérù Kejì 1:13, 14.
19. Ìrànlọ́wọ́ wo ni a nílò lónìí?
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù fi inú rere sọ pé àwọn òǹkàwé òun “fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú òtítọ́,” ó mọ̀ pé ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn lè rì. (Tímótì Kíní 1:19) Níwọ̀n bí ó ti mọ̀ pé òun kò ní pẹ́ kú, ó fún àwọn ará rẹ̀ lókun nípa mímẹ́nukan àwọn nǹkan tí wọ́n lè máa rántí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti mú wọn máa jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. (Pétérù Kejì 1:15; 3:12, 13) Bákan náà, àwa lónìí pẹ̀lú nílò ìránnilétí ìgbà gbogbo láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Ẹni yòó wù tí a lè jẹ́ tàbí bí ó ti wù kí àkókò tí a ti wà nínú òtítọ́ ti pẹ́ tó, a kò lè pa kíka Bíbélì déédéé, dídákẹ́kọ̀ọ́, àti wíwá sí àwọn ìpàdé ìjọ tì. Àwọn kan ń wá àwáwí fún pípa ìpàdé jẹ, ní sísọ pé ó rẹ̀ àwọn jù tàbí pé ohun kan náà ṣáá ni a ń sọ ní àwọn ìpàdé tàbí pé àwọn ọ̀rọ̀ náà kò tani jí, ṣùgbọ́n Pétérù mọ̀ bí ẹnikẹ́ni nínú wa ṣe lè tètè sọ ìgbàgbọ́ nú bí a bá dá ara wa lójú jù.—Máàkù 14:66-72; Kọ́ríńtì Kíní 10:12; Hébérù 10:25.
Ìdí Tí Ó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ fún Ìgbàgbọ́ Wa
20, 21. Báwo ni ìyípadà ológo ṣe fún ìgbàgbọ́ Pétérù àti àwọn tí wọ́n ka lẹ́tà rẹ̀ lókun, títí kan àwa náà lónìí?
20 A ha gbé ìgbàgbọ́ wa karí àwọn ìtàn àròsọ tí a fọgbọ́n hùmọ̀ bí? Pétérù fèsì lọ́nà ti ó sọjú abẹ níkòó pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípa dídi ẹlẹ́rìí olùfojúrí ọlá ńlá rẹ̀.” Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù nígbà tí wọ́n rí ìran rẹ̀ nínú agbára Ìjọba. Pétérù ṣàlàyé pé: “Òun gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá, nígbà tí ògo ọlọ́lá ńlá gbé àwọn ọ̀rọ̀ bí irú ìwọ̀nyí wá fún un pé: ‘Èyí ni ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi ti fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà.’ Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwa gbọ́ tí a gbé wá láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè ńlá mímọ́ náà.”—Pétérù Kejì 1:16-18.
21 Nígbà tí Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù rí ìran yẹn, Ìjọba náà di ohun gidi sí wọn! Pétérù sọ pé: “Nítorí náà a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ̀yin sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí wọ́n ka lẹ́tà Pétérù, títí kan àwa pẹ̀lú lónìí, ní ìdí lílágbára láti fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀nà wo ni a lè gbà fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀? Pétérù fèsì pé: “Gẹ́gẹ́ bíi fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn àyà yín.”—Pétérù Kejì 1:19; Dáníẹ́lì 7:13, 14; Aísáyà 9:6, 7.
22. (a) Ibo ni ọkàn àyà wa gbọ́dọ̀ wà? (b) Báwo ni a ṣe ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀?
22 Ọkàn àyà wa yóò ṣókùnkùn láìsí ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa fífiyè sí i, ọkàn àyà àwọn Kristẹni ti wà nínú ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ náà nígbà tí “ìràwọ̀ ojúmọ́,” Jésù Kristi, dìde nínú ògo Ìjọba. (Ìṣípayá 22:16) Báwo ni a ṣe ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ lónìí? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nípa mímúrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé àti kíkópa nínú wọn, àti nípa ‘sísinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí, àti fífi ara wa fún wọn pátápátá.’ (Tímótì Kíní 4:15) Bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yóò bá dà bí ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ ní “ibi tí ó ṣókùnkùn,” (ọkàn àyà wa), a gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda fún un kí ó nípa lórí wa—ìfẹ́ ọkàn wa, ìmọ̀lára wa, ìsúnniṣe wa, àti góńgó wa lọ́nà tí ó jinlẹ̀. A ní láti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí Pétérù mú orí 1 wá sí ìparí ní sísọ pé: “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ kankan tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí. Nítorí a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ inú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—Pétérù Kejì 1:20, 21.
23. Kí ni orí àkọ́kọ́ Pétérù Kejì múra àwọn tí ó kà á sílẹ̀ fún?
23 Nínú orí àkọ́kọ́ lẹ́tà rẹ̀ kejì, Pétérù pèsè ìsúnniṣe lílágbára fún wa láti di ìgbàgbọ́ wa ṣíṣeyebíye mú ṣinṣin. A ti gbára dì nísinsìnyí fún àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn pàtàkì tí ó tẹ̀ lé e. Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò orí 2 ti Pétérù Kejì, níbi tí àpọ́sítélì náà ti sọ̀rọ̀ nípa ìpèníjà ìwà tí ń sọni dìbàjẹ́, tí ó ti yọ́ wọnú ìjọ.
Ìwọ Ha Rántí Bí
◻ Èé ṣe tí Pétérù fi tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ pípéye?
◻ Kí ni ó lè jẹ́ ìdí tí a fi mẹ́nu kan ìwà funfun gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ àkọ́kọ́ tí a óò fi kún ìgbàgbọ́?
◻ Èé ṣe tí Pétérù fi múra tán nígbà gbogbo láti fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ìránnilétí?
◻ Ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wo ni Pétérù pèsè fún ìgbàgbọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó Pétérù kò mú kí ó pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tì