Dahunpada Si Awọn Ileri Ọlọrun Nipa Lilo Igbagbọ
“Ó [Jehofa Ọlọrun] ti fi awọn ileri rẹ̀ tí ó tobi pupọ tí ó sì ṣe iyebiye fun wa.”—2 PETERU 1:4.
1. Ki ni ń ràn wá lọwọ lati lo igbagbọ tootọ?
JEHOFA ń fẹ́ ki a lò igbagbọ ninu awọn ileri rẹ̀. Sibẹ, “kìí ṣe gbogbo eniyan ni ó gbagbọ.” (2 Tessalonika 3:2) Animọ yii jẹ́ eso ti ẹmi mímọ́, tabi ipá agbekankanṣiṣẹ Ọlọrun. (Galatia 5:22, 23) Fun idi eyi, kìkì awọn wọnni ti ẹmi Jehofa ń dari ni wọn lè lo igbagbọ.
2. Bawo ni aposteli Paulu ṣe tumọ “igbagbọ”?
2 Ṣugbọn ki ni igbagbọ? Aposteli Paulu pè é ni “àṣefihàn ti o hàn gbangba ti awọn otitọ gidi bi a kò tilẹ rí wọn.” Ẹ̀rí awọn otitọ gidi ti a kò rí wọnyi lagbara debi pe igbagbọ ni a mú bá a dọgba. Igbagbọ ni a tún sọ pe ó jẹ́ “ìfojúsùn ti a mu daniloju ti awọn ohun ti a ń reti” nitori pe awọn wọnni ti wọn ní animọ yii ní ẹ̀rí-ìdánilójú pe gbogbo ohun ti Jehofa Ọlọrun ṣeleri daju hán-ún-hán-ún debi pe ń ṣe ni o dabi pe ó ti ní imuṣẹ.—Heberu 11:1, NW.
Igbagbọ ati Awọn Ileri Jehofa
3. Ki ni awọn Kristian ẹni-ami-ororo yoo niriiri rẹ̀ bi wọn bá lo igbagbọ?
3 Lati wu Jehofa, a gbọdọ lo igbagbọ ninu awọn ileri rẹ̀. Aposteli Peteru fi eyi hàn ninu lẹta rẹ̀ keji ti a mísí, ti a kọ ni nǹkan bi 64 C.E. Ó ṣalaye pe bi awọn Kristian ẹni-ami-ororo ẹlẹgbẹ oun bá lo igbagbọ, wọn yoo rí imuṣẹ “awọn ileri [Ọlọrun] ti o tobi pupọ ti o sì ṣe iyebiye.” Gẹgẹ bi iyọrisi, wọn yoo di “alabaapin ninu iwa Ọlọrun” gẹgẹ bi ajumọjogun pẹlu Jesu Kristi ninu Ijọba ti ọ̀run. Pẹlu igbagbọ ati iranlọwọ Jehofa Ọlọrun, wọn ti bọ́ lọwọ wíwà ninu oko-ẹrú si awọn ihuwa ati aṣa idibajẹ ayé yii. (2 Peteru 1:2-4) Sì ró ó wò ná! Awọn wọnni ti wọn ń lo igbagbọ tootọ ń gbadun ominira alaiṣeediyele kan-naa lonii.
4. Awọn animọ wo ni a nilati fi kún igbagbọ wa?
4 Igbagbọ ninu awọn ileri Jehofa ati imoore fun ominira ti Ọlọrun fifun wa nilati sún wa lati ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe lati jẹ́ Kristian awofiṣapẹẹrẹ. Peteru sọ pe: “Nipa fifi gbogbo ìsapá onifọkansi yin ṣeranlọwọ-afikun ni idahunpada, ẹ fi iwafunfun kún igbagbọ yin, ìmọ̀ kún iwafunfun yin, ikora-ẹni-nijaanu kún ìmọ̀ yin, ifarada kún ikoraẹni-nijaanu yin, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun kún ifarada yin, ifẹni ará kún ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun yin, ifẹ kún ifẹni ará yin.” (2 Peteru 1:5-7, NW) Peteru tipa bayii fun wa ni itolẹsẹẹsẹ ti awa yoo ṣe daradara lati há sori. Ẹ jẹ ki a wo awọn animọ wọnyi timọtimọ sii.
Awọn Apá Ṣiṣekoko ti Igbagbọ
5, 6. Ki ni iwafunfun, bawo sì ni a ṣe lè fikún igbagbọ wa?
5 Peteru sọ pe iwafunfun, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ ni a nilati fi kún araawọn ati kún igbagbọ wa. A gbọdọ ṣiṣẹ kára lati mú ki awọn animọ wọnyi jẹ́ apá ṣiṣekoko ninu igbagbọ wa. Fun apẹẹrẹ, iwafunfun kìí ṣe animọ ti a ń fihàn laisi igbagbọ. Olutumọ-ede W. E. Vine ṣalaye pe ni 2 Peteru 1:5, “iwafunfun ni a fikun un gẹgẹ bi animọ ṣiṣekoko kan ninu lilo igbagbọ.” Ọkọọkan ninu awọn animọ yooku ti Peteru mẹnukan ni ó tun nilati jẹ́ apá kan igbagbọ wa.
6 Lakọọkọ, a gbọdọ fi iwafunfun kún igbagbọ wa. Jíjẹ́ oniwafunfun tumọsi ṣiṣe ohun ti o dara ni oju Ọlọrun. Fun ọ̀rọ̀ Griki naa ti a tumọ nihin-in si “iwafunfun,” awọn ẹ̀dà-ìtumọ̀ kan lo “iwarere-iṣeun.” (New International Version; The Jerusalem Bible; Today’s English Version) Iwafunfun ń sún wa lati yẹra fun ṣiṣe ohun ti o buru tabi fifa ipalara fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa. (Orin Dafidi 97:10) Ó tún ń ru igbesẹ onigboya soke ninu ṣiṣe rere fun anfaani tẹmi, tara, ati ti ero-imọlara awọn ẹlomiran.
7. Eeṣe ti a fi nilati fi ìmọ̀ kún igbagbọ ati iwafunfun wa?
7 Eeṣe ti Peteru fi rọ̀ wá lati fi ìmọ̀ kún igbagbọ ati iwafunfun wa? Ó dara, bi a ti ń dojukọ awọn ipenija titun si igbagbọ wa, a nilo ìmọ̀ bi a bá nilati dá ohun ti o tọ́ mọ̀ yatọ si ohun ti kò tọ́. (Heberu 5:14) Nipasẹ ikẹkọọ Bibeli ati iriri ninu fifi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun si ìlò ati ninu lilo ọgbọ́n ti o ṣeefisilo ninu igbesi-aye ojoojumọ, a mú ìmọ̀ wa pele sii. Lẹhin naa, eyi mú ki o ṣeeṣe fun wa lati pa igbagbọ wa mọ́ ki a sì maa baa lọ ni ṣiṣe ohun ti o jẹ́ iwafunfun nigba ti a bá wà labẹ adanwo.—Owe 2:6-8; Jakọbu 1:5-8.
8. Ki ni ikora-ẹni-nijaanu, bawo sì ni a ṣe so ó mọ ifarada?
8 Lati ràn wá lọwọ lati koju awọn adanwo pẹlu igbagbọ, a nilati fi ikora-ẹni-nijaanu kún ìmọ̀ wa. Ọ̀rọ̀ Griki naa fun “ikora-ẹni-nijaanu” jẹ́ àmì agbara lati fi araawa sabẹ akoso. Eso ẹmi Ọlọrun yii ń ràn wá lọwọ lati fi ìkálọ́wọ́kò ninu èrò, ọ̀rọ̀, ati iwa hàn. Nipa ìtẹpẹlẹ ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu, a ń fi ifarada kun un. Èdè-ìsọ̀rọ̀ Griki fun “ifarada” duro fun ìfẹsẹ̀múlẹ̀ṣinṣin onigboya, kìí ṣe ìyọwọ́-yọsẹ̀ oníbojújẹ́ kuro ninu inira ti kò ṣeé sá fun. Ó jẹ́ nitori ayọ ti a gbeka iwaju rẹ̀ ni Jesu fi farada òpó igi-idaloro. (Heberu 12:2) Okun ti Ọlọrun ń fifunni ni isopọ pẹlu ifarada ń fun igbagbọ wa lokun ó sì ń ràn wá lọwọ lati yọ̀ ninu ipọnju, dena adanwo, ki a sì yẹra fun jijuwọsilẹ nigba ti a bá ń ṣe inunibini si wa.—Filippi 4:13.
9. (a) Ki ni ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun? (b) Eeṣe ti a fi nilati fi ifẹni kún ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun wa? (c) Bawo ni a ṣe lè fi ifẹ kún ifẹni ará wa?
9 Ni afikun si ifarada wa ni a gbọdọ pese ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun—ọ̀wọ̀, ijọsin, ati iṣẹ-isin si Jehofa. Igbagbọ wa ń dagba bi a ti ń sọ ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun daṣa ti a sì ń ri bi Jehofa ṣe ń ba awọn eniyan rẹ̀ lò. Sibẹ, lati fi iwa-bi-Ọlọrun hàn, a nilo ifẹni ará. Ó ṣetan, “ẹni ti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o rí, bawo ni yoo ti ṣe lè fẹran Ọlọrun ti oun kò rí?” (1 Johannu 4:20) Ọkan-aya wa nilati sún wa lati fi ifẹni tootọ hàn fun awọn iranṣẹ Jehofa miiran ki a sì wá ire-alaafia wọn ni gbogbo ìgbà. (Jakọbu 2:14-17) Ṣugbọn eeṣe ti a fi sọ fun wa lati fi ifẹ kún ifẹni ará wa? Lọna ti o ṣe kedere Peteru ní i lọ́kàn pe a gbọdọ fi ifẹ hàn fun gbogbo araye, kìí ṣe kìkì awọn arakunrin wa. Ifẹ yii ni a fihàn ni pataki julọ nipa wiwaasu ihinrere ati ríran awọn eniyan lọwọ nipa tẹmi.—Matteu 24:14; 28:19, 20.
Awọn Iyọrisi ti Wọn Yatọ Ni Ifiwera
10. (a) Bawo ni a o ṣe huwa bi a bá fi iwafunfun, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ kún igbagbọ wa? (b) Ki ni yoo ṣẹlẹ bi ẹnikan ti o sọ pe Kristian ni oun bá ṣaini awọn animọ wọnyi?
10 Bi a bá fi iwafunfun, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ kún igbagbọ wa, awa yoo ronu, sọrọ, a o sì huwa ni awọn ọ̀nà ti Ọlọrun fọwọsi. Ni odikeji, bi ẹnikan ti o sọ pe Kristian ni oun bá kuna lati fi awọn animọ wọnyi hàn, oun di afọju nipa tẹmi. Ó ‘di oju rẹ̀ si ìmọ́lẹ̀’ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ó sì gbagbe pe oun ni a ti wẹ̀nù kuro ninu awọn ẹṣẹ ìgbà atijọ. (2 Peteru 1:8-10; 2:20-22) Ẹ maṣe jẹ ki a kuna ni ọ̀nà yẹn lae ki a sì wá tipa bẹẹ sọ igbagbọ ninu awọn ileri Ọlọrun nù.
11. Ki ni a lè fi ẹ̀tọ́ reti lọdọ awọn ẹni-ami-ororo aduroṣinṣin?
11 Awọn Kristian ẹni-ami-ororo aduroṣinṣin ní igbagbọ ninu awọn ileri Jehofa wọn sì ń lo araawọn dé gongo lati mú ki ìpè ati yíyàn wọn daju. Laika awọn okuta idigbolu eyikeyii sí ninu ipa-ọna wọn, a lè reti pe ki wọn fi awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun hàn. Fun awọn ẹni-ami-ororo oluṣotitọ ‘ni ipese lọpọlọpọ wà lati wọ ijọba ainipẹkun ti Jesu Kristi’ nipasẹ ajinde wọn si ìyè tẹmi ninu ọ̀run.—2 Peteru 1:11.
12. Bawo ni a ṣe nilati loye awọn ọ̀rọ̀ 2 Peteru 1:12-15?
12 Peteru mọ̀ pe oun yoo kú laipẹ, ó sì reti lati gba ajinde si ìyè ti ọ̀run ni asẹhinwa-asẹhinbọ. Ṣugbọn niwọn ìgbà ti o ṣì walaaye ninu “àgọ́ yii”—ara eniyan rẹ̀—ó gbiyanju lati gbé igbagbọ ró ninu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ o sì ru wọn soke nipa rírán wọn létí awọn ohun ti wọn nilo fun ojurere atọrunwa. Lẹhin ìlọkúrò rẹ̀ ninu ikú, awọn arakunrin ati arabinrin tẹmi Peteru lè gbé igbagbọ wọn ró nipa pípe awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada sọkan.—2 Peteru 1:12-15.
Igbagbọ Ninu Ọ̀rọ̀ Asọtẹlẹ
13. Bawo ni Ọlọrun ṣe pese ẹ̀rí ti ń fun igbagbọ lokun nipa bíbọ̀ Kristi?
13 Ọlọrun fúnraarẹ̀ fi ẹ̀rí ti ń fun igbagbọ lokun hàn nipa ìjẹ́ dajudaju bíbọ̀ Jesu “ti oun ti agbara ati ògo.” (Matteu 24:30; 2 Peteru 1:16-18) Lalaini ẹ̀rí, awọn alufaa abọriṣa ń sọ ìtàn èké nipa awọn ọlọrun wọn, nigba ti o jẹ pe Peteru, Jakọbu, ati Johannu jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí fun itobilọla iparada Kristi. (Matteu 17:1-5) Wọn rí i ti a ṣe é lógo wọn sì gbọ́ ohùn Ọlọrun fúnraarẹ̀ ti ń jẹwọ Jesu gẹgẹ bi Ọmọkunrin Rẹ̀ aayo-olufẹ. Ìjẹ́wọ́ yẹn ati ifarahan dídán yanranyanran ti a fifun Kristi nigba naa jẹ́ bíbu ọlá ati ògo lé e lori. Nitori ìfihàn atọrunwa yii, Peteru pe ibẹ, ti o ṣeeṣe ki o jẹ́ ni pẹtẹlẹ ori-oke Hermoni ni, “oke mímọ́.”—Fiwe Eksodu 3:4, 5.
14. Bawo ni iparada Jesu ṣe nilati nipa lori igbagbọ wa?
14 Bawo ni iparada Jesu ṣe nilati nipa lori igbagbọ wa? Peteru sọ pe: “Awa sì ni ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ ju bẹẹ lọ; eyi ti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ń tàn ni ibi okunkun, titi ilẹ yoo fi mọ́, ti irawọ owurọ yoo sì yọ ni ọkàn yin.” (2 Peteru 1:19) “Ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ” lọna ti o hàn gbangba ní ninu kìí ṣe kìkì awọn asọtẹlẹ Iwe Mimọ Lede Heberu nipa Messia naa ṣugbọn gbolohun-ọrọ Jesu pe oun yoo wá “ti oun ti agbara ati ògo.” Bawo ni ọ̀rọ̀ naa ṣe di eyi ti o “fẹsẹmulẹ” nipasẹ iparada naa? Iṣẹlẹ yẹn jẹrii si otitọ ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ nipa bíbọ̀ ológo ti Kristi ninu agbara Ijọba.
15. Ki ni fifiyesi ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ ni ninu?
15 Lati mú igbagbọ wa lokun, a gbọdọ fi iyè si ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ. Eyi wémọ́ kikẹkọọ ọ̀rọ̀ yẹn, jijiroro rẹ̀ ni awọn ipade Kristian, ati fifi imọran rẹ̀ silo. (Jakọbu 1:22-27) A gbọdọ jẹ ki o jẹ́ “fitila ti ń tàn ni ibi okunkun,” ni títan ìmọ́lẹ̀ sinu ọkan-aya wa. (Efesu 1:18) Kìkì nigba naa ni yoo tó dari wa titi di ìgbà ti “irawọ ọ̀sán,” tabi, “irawọ owurọ ti ń tàn,” Jesu Kristi, bá fi araarẹ̀ hàn ninu ògo. (Ìfihàn 22:16) Ìfihàn yẹn yoo tumọ si iparun fun awọn alainigbagbọ ati ibukun fun awọn wọnni ti wọn ń lo igbagbọ.—2 Tessalonika 1:6-10.
16. Eeṣe ti a fi lè ni igbagbọ pe gbogbo awọn ileri alasọtẹlẹ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yoo ni imuṣẹ?
16 Awọn wolii Ọlọrun kìí ṣe awọn ọmọran lasan ti wọn ń sọ awọn asọtẹlẹ ọlọgbọn, nitori Peteru sọ pe: “Kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ ti o ní itumọ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ eniyan wá rí; ṣugbọn awọn eniyan ń sọrọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bi a ti ń dari wọn lati ọwọ ẹmi mimọ wá.” (2 Peteru 1:20, 21) Fun apẹẹrẹ, Dafidi sọ pe: “Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ̀ nipa mi.” (2 Samueli 23:1, 2) Paulu sì kọwe pe: “Gbogbo iwe-mimọ [ni] o ní imisi Ọlọrun.” (2 Timoteu 3:16) Niwọn bi a ti mísí awọn wolii Ọlọrun nipasẹ ẹmi rẹ̀, a lè ní igbagbọ pe gbogbo awọn ileri ti o wà ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yoo ni imuṣẹ.
Wọn Ní Igbagbọ Ninu Awọn Ileri Ọlọrun
17. Ileri wo ni o jẹ́ ipilẹ fun igbagbọ Abeli?
17 Awọn ileri Jehofa ni ipilẹ fun igbagbọ ‘awọsanma ńlá’ ti awọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ ṣaaju akoko Kristian. (Heberu 11:1–12:1) Fun apẹẹrẹ, Abeli ní igbagbọ ninu ileri Ọlọrun nipa “iru-ọmọ” kan ti yoo fọ́ “ejo naa” ni ori. Ẹ̀rí wà nipa imuṣẹ idajọ Ọlọrun lori awọn òbí Abeli. Lẹhin ode Edeni, Adamu ati idile rẹ̀ jẹun ninu òógùn oju wọn nitori pe ilẹ ti a gégùn-ún fun mú awọn ẹ̀gún oun oṣùṣú jade. Ó ṣeeṣe ki Abeli ṣakiyesi òòfà-ọkàn Efa fun ọkọ rẹ̀ ki o sì rí i pe Adamu ti ń jẹgaba lé e lori. Dajudaju ó sọrọ nipa irora iloyun rẹ̀. Ẹnu-ọna abawọle sinu ọgbà Edeni ni awọn kerubu ati abẹ idà oníná sì ń ṣọ́. (Genesisi 3:14-19, 24) Gbogbo eyi papọ jẹ́ “aṣefihan ẹ̀rí” ti ń mú un dá Abeli loju pe idande yoo wá nipasẹ Iru-Ọmọ ti a ṣeleri naa. Ni hihuwa pẹlu igbagbọ, Abeli rú ẹbọ ti o jasi eyi ti o niyelori ju ti Kaini lọ si Ọlọrun.—Heberu 11:1, 4.
18, 19. Ni awọn ọ̀nà wo ni Abrahamu ati Sara gba lo igbagbọ?
18 Baba awọn Heberu, Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu tun ni igbagbọ ninu awọn ileri Jehofa. Abrahamu lo igbagbọ ninu ileri Ọlọrun pe gbogbo idile ti o wà lori ilẹ yoo bukun araawọn nipasẹ rẹ̀ ati pe iru-ọmọ rẹ̀ ni a o fun ni ilẹ kan. (Genesisi 12:1-9; 15:18-21) Ọmọkunrin rẹ̀ Isaaki ati ọmọ-ọmọ rẹ̀ Jakọbu jẹ́ “ajogun ileri kan-naa pẹlu rẹ̀.” Nipa igbagbọ, Abrahamu “ṣe àtìpó ni ilẹ ileri” ó sì duro de “ilu ti o ni ipilẹ,” Ijọba Ọlọrun ti ọ̀run labẹ eyi ti a o jí i dide si ìyè lori ilẹ̀-ayé. (Heberu 11:8-10) Iwọ ha ni iru igbagbọ bi eyi bi?
19 Aya Abrahamu, Sara, jẹ́ nǹkan bi 90 ọdun ti o sì ti kọja ọjọ-ori ọmọ-bibi daadaa nigba ti o lo igbagbọ ninu ileri Ọlọrun ti a sì fun un ni agbara “lati lóyún” ki o sì bí Isaaki. Nipa bayii, lati ọ̀dọ̀ Abrahamu ẹni 100 ọdun, “ara ẹni ti o dabi òkú” nipa ti ìmúrújáde, ni asẹhinwa-asẹhinbọ ‘ni a bí awọn ọmọ ti wọn wulẹ dabi irawọ oju ọ̀run ni ọpọlọpọ.’—Heberu 11:11, 12; Genesisi 17:15-17; 18:11; 21:1-7.
20. Bi o tilẹ jẹ pe awọn babanla Heberu kò rí imuṣẹ awọn ileri Ọlọrun fun wọn patapata, ki ni wọn ṣe?
20 Baba awọn Heberu oluṣotitọ naa kú lairi imuṣẹ awọn ileri Ọlọrun fun wọn patapata. Sibẹ, “wọn rí wọn [awọn ohun ti a ṣeleri] ni okeere réré, ti wọn sì gbá wọn mú, ti wọn sì jẹ́wọ́ pe alejo ati àtìpó ni awọn lori ilẹ̀-ayé.” Ọpọ iran kọja ṣaaju ki Ilẹ Ileri naa tó di ohun-ìní awọn ọmọ Abrahamu. Jalẹ igbesi-aye wọn, bi o ti wu ki o ri, baba awọn Heberu olubẹru Ọlọrun lo igbagbọ ninu awọn ileri Jehofa. Nitori pe wọn kò sọ igbagbọ nù rí, a o jí wọn dide laipẹ si ìyè ni ayika ori ilẹ̀-ayé ti “ilu” Ọlọrun ti o ti ṣe silẹ ni sẹpẹ́ fun wọn, Ijọba ti Messia naa. (Heberu 11:13-16) Ni ọ̀nà ti o jọra, igbagbọ lè mú ki a jẹ́ aduroṣinṣin ti Jehofa àní bi a kò bá tilẹ rí imuṣẹ gbogbo awọn ileri agbayanu rẹ̀ ni kiakia. Igbagbọ wa yoo tun sún wa lati ṣegbọran si Ọlọrun, àní gẹgẹ bi Abrahamu ti ṣe. Bi o sì ti ta àtaré ogún tẹmi kan sori awọn ọmọ rẹ̀, bẹẹ ni a lè ran awọn ọmọ wa lọwọ lati lo igbagbọ ninu awọn ileri ṣiṣeyebiye ti Jehofa.—Heberu 11:17-21.
Igbagbọ Ṣekoko fun Awọn Kristian
21. Lati di ẹni ti o ṣetẹwọgba fun Ọlọrun lonii, ki ni a gbọdọ fikun lílò ti a lo igbagbọ?
21 Nitootọ, pupọ sii ni o wà fun igbagbọ, ju níní igbọkanle ninu imuṣẹ awọn ileri Jehofa lọ. Jalẹ ìtàn eniyan, ó ti pọndandan lati lo igbagbọ ninu Ọlọrun ni oniruuru ọ̀nà bi a bá nilati gbadun itẹwọgba rẹ̀. Paulu ṣalaye pe “ni aisi igbagbọ ko ṣeeṣe lati wu [Jehofa Ọlọrun]; nitori ẹni ti o bá ń tọ Ọlọrun wá kò lè ṣaigbagbọ pe o ń bẹ, ati pe oun ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.” (Heberu 11:6) Lati di ẹni itẹwọgba fun Jehofa lonii, ẹnikan gbọdọ lo igbagbọ ninu Jesu Kristi ati ninu ẹbọ irapada ti Ọlọrun ti pese nipasẹ rẹ̀. (Romu 5:8; Galatia 2:15, 16) Ń ṣe ni ó ri gẹgẹ bi Jesu fúnraarẹ̀ ti wi pe: “Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹ́ẹ́, ti o fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ má baà ṣegbe, ṣugbọn ki o lè ni ìyè ainipẹkun. Ẹni ti o bá gba Ọmọ gbọ́, o ni ìyè ainipẹkun: ẹni ti kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yoo rí ìyè; ṣugbọn ibinu Ọlọrun ń bẹ lori rẹ̀.”—Johannu 3:16, 36.
22. Ijọba Messia yoo mú imuṣẹ ileri wo wá?
22 Jesu kó ipa ṣiṣekoko ninu imuṣẹ awọn ileri Ọlọrun nipa Ijọba naa ti awọn Kristian ń gbadura fun. (Isaiah 9:6, 7; Danieli 7:13, 14; Matteu 6:9, 10) Gẹgẹ bi Peteru ti fihàn, iparada naa jẹrii si ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ nipa bíbọ̀ Jesu ninu agbara ati ògo Ijọba. Ijọba ti Messia yoo mú imuṣẹ ileri Ọlọrun miiran wá, nitori ti Peteru kọwe pe: “Gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa ń reti awọn ọ̀run titun ati ayé titun, ninu eyi ti òdodo ń gbé.” (2 Peteru 3:13) Asọtẹlẹ bi iru eyi ni a muṣẹ nigba ti a mú awọn igbekun Ju pada si ilẹ-ibilẹ wọn ni 537 B.C.E. labẹ ijọba kan ti o ní Serubbabeli gẹgẹ bi gomina ati Joṣua gẹgẹ bi olori alufaa. (Isaiah 65:17) Ṣugbọn Peteru tọka si akoko ọjọ-ọla kan nigba ti “ọrun titun”—Ijọba Messia ti ọ̀run—yoo ṣakoso lori “ayé titun,” awujọ eniyan olódodo lori obirikiti ilẹ̀-ayé yii.—Fiwe Orin Dafidi 96:1.
23. Awọn ibeere wo nipa iwafunfun ni a o jiroro tẹlee?
23 Gẹgẹ bi iranṣẹ aduroṣinṣin ti Jehofa ati ọmọlẹhin Ọmọkunrin rẹ̀ aayo-olufẹ, Jesu Kristi, a yánhànhàn fun ayé titun ti Ọlọrun ṣeleri. A mọ̀ pe ó ti sunmọle, a sì nigbagbọ pe gbogbo awọn ileri ṣiṣeyebiye Jehofa ni yoo ni imuṣẹ. Lati rìn lọna ti o ṣetẹwọgba niwaju Ọlọrun wa, a gbọdọ mú igbagbọ wa lokun nipa fifi iwafunfun, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ kún un.a Lori koko yii, a lè beere pe, Bawo ni a ṣe lè fi iwafunfun hàn? Bawo sì ni jíjẹ́ oniwafunfun wa ṣe lè ṣanfaani fun wa ati fun awọn ẹlomiran, ni pataki awọn Kristian alabaakẹgbẹ wa, ti wọn ti dahunpada si awọn ileri Ọlọrun nipa lilo igbagbọ?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Igbagbọ ati iwafunfun ni a jiroro ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà yii. Ìmọ̀, ikora-ẹni-nijaanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ ni a o gbeyẹwo ni kikun sii ninu awọn itẹjade ọjọ iwaju.
Ki Ni Awọn Idahun Rẹ?
◻ Bawo ni a ṣe lè tumọ “igbagbọ”?
◻ Gẹgẹ bi 2 Peteru 1:5-7 ti wi, awọn animọ wo ni a nilati fi kún igbagbọ wa?
◻ Iyọrisi wo ni iparada Jesu nilati ní lori igbagbọ wa?
◻ Awọn apẹẹrẹ igbagbọ wo ni a fifun wa lati ọ̀dọ̀ Abeli, Abrahamu, Sara, ati awọn miiran ni ìgbà ijimiji?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Iwọ ha mọ bi iparada Jesu ṣe lè nipa lori igbagbọ ẹnikan bi?