OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ta ló ń darí ayé yìí?
Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run ló ń darí ayé yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ òun ni lóòótọ́, ṣé ayé á kún fún ìyà bó ṣe rí lónìí? (Diutarónómì 32:4, 5) Bíbélì jẹ́ ka mọ̀ pé ẹni burúkú kan ló ń ṣàkóso ayé yìí tó sì ń darí rẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 5:19.
Báwo ni ẹni burúkú kan ṣe lè máa ṣàkóso ayé? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn àwa èèyàn. Áńgẹ́lì kan ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó tún tan àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ìyẹn Ádámù àti Éfà láti ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Àwọn tọkọtaya yìí yàn láti tẹ̀lé áńgẹ́lì burúkú náà, ìyẹn Sátánì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di alákòóso wọn. Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló yẹ kó jẹ́ alákòóso wa, síbẹ̀ kò fi tipátipá mú wa láti jọ́sìn òun, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ ká yàn láti jọ́sìn òun torí ìfẹ́ tá a ní sí i. (Diutarónómì 6:6; 30:16, 19) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni Sátánì ti tàn jẹ, tí àwọn náà sì ti ṣìnà bíi tàwọn tọkọtaya àkọ́kọ́.—Ka Ìṣípayá 12:9.
Ta ló máa yanjú ìṣòro aráyé?
Ǹjẹ́ Ọlọ́run á gba Sátánì láàyè láti máa bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ títí? Rárá o! Ọlọ́run máa lo Jésù láti tún gbogbo nǹkan tí Sátánì ti bàjẹ́ ṣe.—Ka 1 Jòhánù 3:8.
Jésù máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti pa Sátánì run. (Róòmù 16:20) Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa ṣàkóso aráyé, á mú ká láyọ̀ ká sì máa gbé ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bó ṣe fẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀.—Ka Ìṣípayá 21:3-5.