-
Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ ÒṣèlúGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Bíi ti Jésù, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Nígbà táwọn kan rí ọ̀kan lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n fẹ́ fi jọba, àmọ́ kò gbà fún wọn. (Jòhánù 6:15) Kí nìdí tí Jésù ò fi gbà? Ó sọ pé, “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún ká lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a kì í lọ́wọ́ sí ogun. (Ka Míkà 4:3.) A máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àmì orílẹ̀-èdè bí àsíá, àmọ́ a kì í júbà wọn. (1 Jòhánù 5:21) A kì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, bẹ́ẹ̀ la kì í ta kò wọ́n. Bákan náà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú láwọn ọ̀nà èyíkéyìí míì. Ńṣe ni èyí ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan la fara mọ́.
-
-
Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ ÒṣèlúGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
4. Má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò àti ìṣe rẹ
Ka 1 Jòhánù 5:21. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tí Ayenge fi pinnu pé òun ò ní dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú, òun ò sì ní tẹrí ba fún àsíá orílẹ̀-èdè?
Ṣé o rò pé ìpinnu tó ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu?
Àwọn nǹkan míì wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Tó bá dọ̀rọ̀ eré ìdárayá, kí la lè ṣe ká má bàa ṣohun tó fi hàn pé a ka orílẹ̀-èdè wa sí pàtàkì ju àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ?
Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn olóṣèlú fẹ́ ṣe máa pa wá lára tàbí ṣe wá láǹfààní?
Báwo ni ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde àtàwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
-