Eeṣe ti a Fi Nilati Ṣọra fun Ibọriṣa?
“Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa araayin mọ́ kuro ninu oriṣa.”—1 JOHANNU 5:21.
1. Eeṣe ti ijọsin Jehofa fi wà laisi ibọriṣa?
JEHOFA kìí ṣe oriṣa onirin, onigi, tabi olokuuta. Oun ni a kò lè wá ibugbe fun ninu tẹmpili ori ilẹ̀-ayé kan. Niwọn bi oun ti jẹ Ẹmi titobi julọ, eyi ti o jẹ alaiṣeefojuri fun eniyan, kò ṣeeṣe lati gbẹ́ ère rẹ̀. Nipa bayii, ijọsin mimọ gaara Jehofa kò gbọdọ wémọ́ ibọriṣa.—Eksodu 33:20; Iṣe 17:24; 2 Korinti 3:17.
2. Awọn ibeere wo ni wọn yẹ fun igbeyẹwo wa?
2 Bi iwọ bá jẹ́ olujọsin Jehofa, nigba naa, iwọ lè fi ẹ̀tọ́ beere pe, ‘Ki ni ibọriṣa jẹ́? Bawo ni awọn iranṣẹ Jehofa ti ṣe yẹra fun un ni ìgbà atijọ? Eesitiṣe ti a fi nilati ṣọra fun ibọriṣa lonii?’
Ohun ti Ibọriṣa Jẹ́
3, 4. Bawo ni a ṣe lè tumọ ibọriṣa?
3 Ni gbogbogboo, ibọriṣa wémọ́ ayẹyẹ tabi aato kan. Ibọriṣa jẹ́ ikunlẹbọ, ifẹ fun, ijọsin, tabi ijuba oriṣa kan. Ki sì ni oriṣa kan jẹ́? O jẹ́ ère kan, aworan ohun kan, tabi ami-apẹẹrẹ, ti o jẹ́ ohun ijọsin fun kan. Lọpọ ìgbà, ibọriṣa ni a dari siha agbara gidi kan tabi eyi ti a rò pe o jẹ́ bẹẹ ti a gbagbọ pe o ni iwalaaye ẹlẹmii (eniyan kan, ẹranko kan, tabi eto-ajọ kan). Ṣugbọn ibọriṣa ni a lè ṣe pẹlu ni ibatan pẹlu awọn nǹkan ti o jẹ alailẹmii (agbara kan tabi ohun iṣẹda alailẹmii kan).
4 Ninu Iwe Mimọ, awọn ọ̀rọ̀ Heberu ti ń tọkasi oriṣa lọpọ ìgbà maa ń tẹnumọ ainilaari, tabi ti wọn jẹ ede-isọrọ ìṣáátá. Lara awọn wọnyi ni awọn ọ̀rọ̀ ti a tumọ si “ère gbígbẹ́ tabi fínfín” (ni ọ̀nà olowuuru, ohun kan ti a gbẹ́ jade); “aworan, ère, tabi oriṣa yíyọ́” (ohun kan ti a mọ); “oriṣa ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀”; “oriṣa asán” (ni ọ̀nà olowuuru, òfo); ati “oriṣa ẹlẹ́bọ́tọ.” Ọ̀rọ̀ Griki naa eiʹdo·lon ni a tumọ si “oriṣa.”
5. Eeṣe ti a fi lè sọ pe kìí ṣe gbogbo ère ni o jẹ́ oriṣa?
5 Kìí ṣe gbogbo ère ni oriṣa. Ọlọrun funraarẹ sọ fun awọn ọmọ Israeli lati ṣe kerubu oniwura meji fun apoti majẹmu ati lati ṣọnà awọn aworan iru ẹ̀dá ẹmi bẹẹ sara aṣọ ti ó wà nisalẹ aṣọ mẹwaa ti a fi ń bo àgọ́ fun agọ-isin ati sara ìkéle ti o ya ibi Mimọ kuro lara ibi Mimọ Julọ. (Eksodu 25:1, 18; 26:1, 31-33) Kiki awọn alufaa ti a fi joye nikan ni wọn rí awọn aworan wọnyi ti o wà ni pataki gẹgẹ bi ami-apẹẹrẹ awọn kerubu ti ọrun. (Fiwe Heberu 9:24, 25.) O ṣe kedere pe awọn aworan kerubu ti agọ-isin ni a kò gbọdọ kunlẹbọ, niwọn bi awọn angẹli olododo funraawọn kì yoo ti tẹwọgba ijọsin.—Kolosse 2:18; Ìfihàn 19:10; 22:8, 9.
Oju-iwoye Jehofa Nipa Ibọriṣa
6. Ki ni oju-iwoye Jehofa nipa ibọriṣa?
6 Awọn iranṣẹ Jehofa ṣọra fun ibọriṣa nitori pe oun lodisi gbogbo aṣa ibọriṣa. Ọlọrun paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati maṣe yá ère gẹgẹ bi ohun akunlẹbọ ki wọn sì jọsin wọn. Lara awọn Ofin Mẹwaa ni a ti ri awọn ọ̀rọ̀ wọnyi pe: “Iwọ kò gbọdọ yá ère fun araarẹ, tabi aworan ohun kan ti ń bẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ninu omi ni iṣalẹ ilẹ. Iwọ kò gbọdọ tẹ ori araarẹ ba fun wọn, bẹẹ ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti ń bẹ ẹṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati kẹrin ninu awọn ti o koriira mi; emi a si maa fi aanu han ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti wọn si ń pa ofin mi mọ́.”—Eksodu 20:4-6.
7. Eeṣe ti Jehofa fi tako gbogbo ibọriṣa?
7 Eeṣe ti Jehofa fi lodi si gbogbo ibọriṣa? Ni pataki nitori pe oun beere fun ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé, gẹgẹ bi a ti fihàn loke ninu ekeji ninu awọn Ofin Mẹwaa. Siwaju sii, o sọ lati ẹnu wolii rẹ̀ Isaiah pe: “Emi ni [Jehofa, NW]: eyi ni orukọ mi: ògo mi ni emi ki yoo fifun ẹlomiran, bẹẹ ni emi ki yoo fi iyin mi fun ère gbígbẹ́.” (Isaiah 42:8) Ni akoko kan, ibọriṣa dẹkùn mú awọn ọmọ Israeli de iwọn ààyè ti o fi jẹ́ pe “wọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa.” (Orin Dafidi 106:36, 37) Kìí ṣe kiki pe awọn abọriṣa kọ Jehofa gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ nikan ni ṣugbọn wọn tun ń ṣiṣẹ fun ire anfaani olori Elenini rẹ̀, Satani, papọ pẹlu awọn ẹmi eṣu.
Wọn Duroṣinṣin Labẹ Idanwo
8. Idanwo wo ni awọn Heberu mẹta naa Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dojukọ?
8 Iduroṣinṣin ti Jehofa tun ń mu ki a ṣọra fun ibọriṣa pẹlu. Eyi ni a ṣapejuwe nipa iṣẹlẹ ti a kọsilẹ ni Danieli ori 3. Lati ṣèfilọ́lẹ̀ ère oniwura nla kan ti oun ti gbekalẹ, Nebukadnessari ọba Babiloni pe gbogbo awọn oloye ilẹ-ọba rẹ̀ papọ. Àṣẹ rẹ̀ fi Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego—awọn Heberu mẹta ti wọn jẹ́ olùdari agbegbe sakaani ilẹ̀-oyè Babiloni kun un. Gbogbo awọn ti ó wà nibẹ ni a paṣẹ fun lati tẹriba niwaju ère naa lẹhin ìró awọn ohun-eelo orin kan. Eyi jẹ igbidanwo kan lati ọwọ́ ọlọrun Babiloni gidi, Satani, lati mú ki awọn Heberu mẹta naa tẹriba niwaju ère ti ń ṣoju fun Ilẹ-ọba awọn ará Babiloni. Ronu pe iwọ wà nibẹ.
9, 10. (a) Ipo wo ni awọn Heberu mẹta naa mú, bawo ni a si ṣe san èrè fun wọn? (b) Iṣiri wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè rigba lati inu ipa-ọna awọn Heberu mẹta naa?
9 Wo o! Awọn Heberu mẹta naa wà ni iduro. Wọn ranti ofin Ọlọrun lodisi ṣiṣe ati ṣiṣiṣẹsin awọn oriṣa tabi ère gbígbẹ́. Nebukadnessari fun wọn ni òté kan—itẹriba tabi iku! Ṣugbọn ni iduroṣinṣin si Jehofa, wọn sọ pe: “Bi o ba ri bẹẹ, Ọlọrun wa ti awa ń sin, lè gbà wá lọwọ iná ileru naa ti ń jo, oun o sì gbà wá lọwọ rẹ, ọba. Ṣugbọn bi bẹẹ kọ, ki o yé ọ, ọba pe, awa kì yoo sin oriṣa rẹ, bẹẹ ni awa ki yoo sì tẹriba fun ère wura ti iwọ gbekalẹ.”—Danieli 3:16-18.
10 Awọn iranṣẹ Ọlọrun aduroṣinṣin wọnyi ni a jù sinu iná ileru ti ń jo fòfò naa. Bi o ti yà á lẹnu lati ri awọn eniyan mẹrin ti ń rin ninu iná ileru naa, Nebukadnessari pe awọn Heberu mẹta naa jade, wọn si jade wa laini ipalara. Nigba naa ni ọba kigbe jade pe: “Olubukun ni Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹni ti o rán angẹli rẹ̀ ti o sì gba awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹle e, wọn si pa ọ̀rọ̀ ọba dà, wọn si fi ara wọn jin, ki wọn ki o maṣe sin, tabi ki wọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikaraawọn. . . . Nitori kò si Ọlọrun miiran ti o lè gbanila bi iru eyi.” (Danieli 3:28, 29) Ipawatitọmọ awọn Heberu mẹta wọnni pese iṣiri fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ọjọ oni lati jẹ aduroṣinṣin si Ọlọrun, pa ipo aidasitọtuntosi mọ́ siha ayé, ki wọn si yẹra fun ibọriṣa.—Johannu 17:16.
Awọn Oriṣa Padanu ni Ile-ẹjọ
11, 12. (a) Akọsilẹ wo ti o wémọ́ Jehofa ati awọn ọlọrun oriṣa ni Isaiah kọ? (b) Bawo ni awọn ọlọrun orilẹ-ede ti ṣe nigba ti Jehofa pè wọn níjà?
11 Idi miiran lati ṣọra fun ibọriṣa ni pe ikunlẹbọ awọn oriṣa jẹ alaiwulo. Bi o tilẹ jẹ pe diẹ lara awọn oriṣa àtọwọ́dá eniyan lè dabi eyi ti o walaaye—ti wọn sábà maa ń ní ẹnu kan, oju, ati etị—wọn kò lè sọrọ, ríran, tabi gbọran wọn kò si lè ṣe ohunkohun fun awọn olujọsin wọn. (Orin Dafidi 135:15-18) Eyi ni a fihàn ni ọrundun kẹjọ B.C.E., nigba ti wolii Ọlọrun ṣe akọsilẹ ohun ti o wá jasi, igbẹjọ ile-ẹjọ kan laaarin Jehofa ati awọn ọlọrun oriṣa ninu Isaiah 43:8-28. Ninu rẹ̀ awọn eniyan Ọlọrun Israeli wà ni ẹ̀gbẹ́ kan, awọn orilẹ-ede ayé sì wà ni ẹ̀gbẹ́ keji. Jehofa pe awọn ọlọrun èké ti awọn orilẹ-ede níjà lati sọ “ohun atijọ,” lati ṣasọtẹlẹ lọna pipeye. Kò si ọ̀kan lara wọn ti o lè ṣe bẹẹ. Ni yiyijusi awọn eniyan rẹ̀, Jehofa sọ pe: “Ẹyin ni ẹlẹ́rìí mi . . . emi ni Ọlọrun.” Awọn orilẹ-ede naa kò lè fi ẹ̀rí hàn pe awọn ọlọrun wọn walaaye ṣaaju Jehofa tabi pe wọn lè sọtẹlẹ. Ṣugbọn Jehofa sasọtẹlẹ iparun Babiloni ati idasilẹ awọn eniyan rẹ̀ ti a kó nigbekun.
12 Siwaju sii, awọn iranṣẹ Ọlọrun ti a dasilẹ yoo sọ pe awọn jẹ́ “ti Oluwa” bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ni Isaiah 44:1-8. Oun funraarẹ sọ pe: “Emi ni ẹni ikinni, ati ẹni ikẹhin; ati lẹhin mi kò si Ọlọrun kan.” Kò si ijiyan kankan lati ọ̀dọ̀ awọn ọlọrun oriṣa. “Ẹyin naa ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Jehofa tun sọ nipa awọn eniyan rẹ̀ lẹẹkan sii, ni fifikun un pe: “Ọlọrun kan ń bẹ lẹhin mi bi? Kò si Apata kan.”
13. Ki ni ibọriṣa fihàn nipa abọriṣa kan?
13 A tun ń ṣọra fun ibọriṣa nitori pe lilọwọ ninu rẹ̀ fi ailọgbọn hàn. Pẹlu apakan igi kan ti oun yan, abọriṣa kan ṣe ọlọrun kan lati jọsin, ati pẹlu apa miiran oun dáná lati se ounjẹ rẹ̀. (Isaiah 44:9-17) O ti jẹ́ iwa omugọ tó! Oluṣe ati olujọsin awọn ọlọrun oriṣa kan ń niriiri itiju bakan naa nitori ailefunni ni ẹ̀rí ti ń yinilọkanpada eyi ti ń fi ipo jijẹ ọlọrun wọn hàn. Ṣugbọn ipo jijẹ Ọlọrun Jehofa jẹ alaiṣeejanikoro, nitori pe kìí ṣe kiki pe oun sasọtẹlẹ ominira awọn eniyan rẹ̀ kuro ni Babiloni nikan ni ṣugbọn o tun mú ki eyi ṣẹlẹ pẹlu. Jerusalemu ni awọn eniyan pada gbe inu rẹ̀, awọn ilu-nla Juda ni a túnkọ́, ti “ibú” Babiloni—Odò Euferate—sì gbẹ gẹgẹ bi orisun idaabobo kan. (Isaiah 44:18-27) Gẹgẹ bi Ọlọrun pẹlu ṣe sọtẹlẹ, Kirusi ara Persia ṣẹgun Babiloni.—Isaiah 44:28–45:6.
14. Ni Ile-ẹjọ Gigajulọ Agbaye, ki ni a o fẹrii rẹ̀ hàn titilae?
14 Awọn ọlọrun oriṣa padanu ninu igbẹjọ lọna ofin naa eyi ti o níí ṣe pẹlu ipo jijẹ ọlọrun. Ohun ti o si ṣubu lu Babiloni ni o daju pe yoo ṣubu lu alabaadọgba rẹ̀ ode-oni, Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin èké agbaye. Oun ati gbogbo awọn ọlọrun rẹ̀, awọn ohun èèlò-ọ̀ṣọ́ isin, ati awọn ohun ibọriṣa ni yoo parẹ titilae laipẹ. (Ìfihàn 17:12–18:8) Ni Ile-ẹjọ Gigajulọ Agbaye, a o fihàn titilae nigba naa pe Jehofa nikan ni Ọlọrun tootọ ti o walaaye ati pe o ń mu awọn Ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ rẹ̀ ṣẹ.
Ẹbọ si Awọn Ẹmi Eṣu
15. Ki ni ẹmi mimọ ati ẹgbẹ́ oluṣakoso ọrundun kìn-ín-ní tọkasi nipa awọn eniyan Jehofa ati ibọriṣa?
15 Awọn eniyan Jehofa tun ń ṣọra fun ibọriṣa pẹlu nitori pe a ń dari wọn lati ọwọ ẹmi ati eto-ajọ Ọlọrun. Ẹgbẹ́ oluṣakoso awọn iranṣẹ Jehofa ti ọrundun kin-in-ni sọ fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ wọn pe: “Nitori o dara loju ẹmi mimọ, ati loju wa, ki a maṣe di ẹrù kà yin, ju nǹkan ti a kò lè ṣe alaiṣe wọnyi lọ: Ki ẹyin ki o fasẹhin kuro ninu ẹran àpa-bọ-òrìṣà, ati ninu ẹ̀jẹ̀ ati ninu ohun ilọlọrunpa, ati ninu agbere: ninu ohun ti, bi ẹyin bá pa araayin mọ́ kuro, ẹyin ó ṣe rere. Alaafia.”—Iṣe 15:28, 29.
16. Ni ọ̀rọ̀ tirẹ funraarẹ, bawo ni iwọ yoo ṣe sọ ohun ti Paulu sọ nipa awọn nǹkan ti a fi rubọ si oriṣa?
16 Idi miiran fun ṣiṣọra fun ibọriṣa jẹ́ lati yẹra fun iṣẹ́ ẹmi eṣu. Niti Ounjẹ Alẹ Oluwa, aposteli Paulu sọ fun awọn Kristian ará Korinti pe: “Ẹ sá fun ibọriṣa. . . . Ago ibukun ti awa ń sure si, idapọ ẹ̀jẹ̀ Kristi kọ iṣe? Akara ti awa ń bù, idapọ ara Kristi kọ́ iṣe? Nitori pe awa tii ṣe ọpọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitori pe gbogbo wa ni o jumọ ń pin ninu akara kan nì. Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti ń jẹ ohun ẹbọ, wọn kìí ha iṣe alabaapin pẹpẹ? Ǹjẹ́ ki ni mo ń wi? Pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nǹkan, tabi pe oriṣa jẹ nǹkan? Ṣugbọn ohun ti mo ń wi ni pe, ohun ti awọn keferi fi ń rubọ, wọn fi ń rubọ si awọn ẹmi eṣu, kìí sii ṣe si Ọlọrun: emi kò sì fẹ ki ẹyin ki o bá awọn ẹmi eṣu ṣe ajọpin. Ẹyin kò lè mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi eṣu: ẹyin kò lè ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi eṣu. Awa ha ń mu Oluwa jowu bi? Awa ha ni agbara jù ú lọ bi?”—1 Korinti 10:14-22.
17. Ni ọrundun kìn-ín-ní C.E., labẹ awọn ipo wo ni Kristian kan ti lè jẹ ẹran ti a fi rubọ si awọn oriṣa, eesitiṣe?
17 Apakan ẹran kan ni a fi rubọ si oriṣa, apakan lọ sọdọ awọn alufaa, olujọsin sì gba diẹ fun àsè. Bi o ti wu ki o ri, apakan ninu ẹran naa ni a lè tà ni ọja. O jẹ́ ohun ti a kò fun ni iṣiri fun Kristian kan lati lọ si tẹmpili oriṣa kan lati jẹ ẹran àní bi o tilẹ jẹ pe oun kò jẹ ẹ́ gẹgẹ bi apakan aato-isin, nitori pe eyi lè mú awọn miiran kọsẹ tabi ki o fà á sinu ijọsin èké. (1 Korinti 8:1-13; Ìfihàn 2:12, 14, 18, 20) Fifi ẹran kan rubọ si oriṣa kò yí ẹran naa pada, nitori naa Kristian kan lè ra diẹ lọja. Oun kò ni lati beere nipa orisun ẹran ti a gbekalẹ funnijẹ ninu ile kan pẹlu. Ṣugbọn bi ẹnikan bá sọ pe “a ti fi eyi ṣẹbọ,” oun kì yoo jẹ ẹ, lati yẹra fun mimu ẹnikẹni kọsẹ.—1 Korinti 10:25-29.
18. Bawo ni awọn wọnni ti wọn ń jẹ ohun ti a fi rubọ si oriṣa kan ṣe lè ṣajọpin pẹlu awọn ẹmi eṣu?
18 A sábà maa ń lero pe lẹhin aato irubọ naa, ọlọrun naa wà ninu ẹran naa ti o si wọnu ara awọn wọnni ti wọn jẹ ẹ nibi àsè awọn olujọsin. Gẹgẹ bi awọn eniyan ti wọn jẹun papọ ṣe mú ki ide kan wa laaarin araawọn, bẹẹ ni awọn wọnni ti wọn ṣajọpin awọn ẹran irubọ naa jẹ́ alabaapin ninu pẹpẹ ti wọn sì ni paṣipaarọ èrò ati imọlara pẹlu ọlọrun ẹmi eṣu ti oriṣa naa ṣoju fun. Nipasẹ iru ibọriṣa bẹẹ, awọn ẹmi eṣu ń dí awọn eniyan lọwọ jijọsin Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa. (Jeremiah 10:1-15) Abajọ ti awọn eniyan Jehofa fi gbọdọ pa araawọn mọ́ kuro ninu awọn nǹkan ti a fi rubọ si awọn oriṣa! Iduroṣinṣin si Ọlọrun, titẹwọgba idari nipasẹ ẹmi mimọ ati eto-ajọ rẹ̀, ati igberopinnu lati yẹra fun lilọwọ ninu biba ẹmi eṣu lò tun ti jasi iṣiri-isunniṣe alagbara lati ṣọra fun ibọriṣa lonii.
Eeṣe Ti Aini Fi Wà Fun Iṣọra?
19. Iru ibọriṣa wo ni o wà ni Efesu igbaani?
19 Awọn Kristian ń fi taapọntaapọn ṣọra fun ibọriṣa nitori pe o pín si oniruuru, tí ṣiṣe ibọriṣa kanṣoṣo paapaa sì lè mu ki igbagbọ wọn di eyi ti a fi bánidọ́rẹ̀ẹ́. Aposteli Johannu sọ fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ẹ pa araayin mọ́ kuro ninu oriṣa.” (1 Johannu 5:21) Imọran yii ni wọn nilo nitori pe oloniruuru ibọriṣa ni o yí wọn ká. Johannu kọwe lati Efesu, ilu-nla ti o ringbingbin fun awọn aṣa onidan ati ẹkọ-atọwọdọwọ nipa awọn ọlọrun èké. Efesu ní ọ̀kan ninu awọn ohun iyanu ayé meje naa—tẹmpili Atemisi, ibi ìsádi kan fun awọn ọdaran ati ibùdó awọn aato oniwa palapala. Ọlọgbọn imọ-ọran naa Heracleitus ti Efesu fi ọ̀nà ṣiṣokunkun ti o lọ sibi pẹpẹ tẹmpili yẹn wé okùnkùn ti ohun buburu jai, o sì ka iwarere tẹmpili naa si eyi ti o buru ju ti awọn ẹranko ìgbẹ́ lọ. Nipa bayii, awọn Kristian ará Efesu nilati duro gbọnyin lodisi biba ẹmi eṣu lò, iwa palapala, ati ibọriṣa.
20. Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati yẹra fun ibọriṣa ti o kere julọ paapaa?
20 Awọn Kristian nilo igberopinnu ti o lagbara lati yẹra fun ibọriṣa ti o kere julọ paapaa nitori pe kìkì ijọsin kanṣoṣo ti a fifun Eṣu yoo ṣetilẹhin fun ipenija rẹ̀ pe awọn eniyan kò ni duro bi olùṣòtítọ́ si Ọlọrun labẹ idanwo. (Jobu 1:8-12) Nigba ti o ń fi “gbogbo ilẹ-ọba ayé ati gbogbo ògo wọn han” Jesu, Satani sọ pe: “Gbogbo nǹkan wọnyi ni emi o fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi.” Ikọjalẹ Kristi gbé iha Jehofa nipa ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ agbaye larugẹ ó si fi Eṣu hàn bi elékèé.—Matteu 4:8-11; Owe 27:11.
21. Niti olu-ọba Romu, ki ni awọn Kristian aduroṣinṣin kọ̀ jalẹ lati ṣe?
21 Bẹẹ sì ni awọn ọmọlẹhin Jesu akọkọbẹrẹ kì yoo ṣe ohun kan bi ijọsin ni itilẹhin fun iha Satani nipa ariyanjiyan naa. Bi o tilẹ jẹ pe wọn ni ọ̀wọ̀ ti o ga fun ‘awọn alaṣẹ giga’ ti ijọba, wọn kì yoo jó turari ni bibọla fun olu-ọba Romu, àní bi o tilẹ ná wọn ni iwalaaye wọn paapaa. (Romu 13:1-7) Ni isopọ pẹlu eyi, Daniel P. Mannix kọwe pe: “Iwọnba ti o kere jọjọ ninu awọn Kristian ni wọn yẹhun, bi o tilẹ jẹ pe pẹpẹ kan pẹlu iná ti ń jo lori rẹ̀ ni a sábà maa ń gbekalẹ ni ibi ère fun irọrun wọn. Kiki ohun ti ẹlẹwọn kan nilati ṣe ni lati fọ́n turari ṣín-ún kan sori ọwọ́ iná naa a o sì fun un ni Iwe-ẹri Irubọ yoo si di ominira. A o salaye fun un tiṣọratisọra bakan naa pẹlu pe oun kò jọsin olu-ọba naa; ó kàn wulẹ tẹwọgba animọ atọrunwa olu-ọba naa gẹgẹ bi ori orilẹ-ede Romu lasan ni. Ṣibẹ, ó fẹrẹ jẹ pe kò si awọn Kristian kankan ti wọn lo anfaani lati jàjàbọ́ yii fun araawọn.” (Those About to Die, oju-iwe 137) Bi a bá dán ọ wò bakan naa, iwọ yoo ha yẹra fun gbogbo ibọriṣa patapata bi?
Iwọ Yoo Ha Ṣọra fun Ibọriṣa Bi?
22, 23. Eeṣe ti o fi nilati ṣọra fun ibọriṣa?
22 Lọna ti o ṣe kedere, awọn Kristian gbọdọ ṣọra fun gbogbo iru-oriṣi ibọriṣa. Jehofa ń beere ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé. Awọn Heberu olusotitọ mẹta naa pese apẹẹrẹ didara ni kíkọ̀ lati bọ ère nla ti a gbekalẹ lati ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babiloni bi oriṣa. Ninu igbẹjọ ile-ẹjọ agbaye ti wolii Isaiah kọ silẹ, Jehofa nikan ni a fihàn gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ ati alaaye. Awọn Kristian ẹlẹ́rìí rẹ igbaani nilati maa pa araawọn mọ́ kuro ninu awọn nǹkan ti a fi rubọ si oriṣa. Ọpọ awọn aduroṣinṣin ninu wọn kò juwọsilẹ fun ikimọlẹ lati ṣe àní ibọriṣa kanṣoṣo péré paapaa eyi ti ó lè tumọsi kikọ Jehofa silẹ.
23 Bi o bá ri bẹẹ, nigba naa, iwọ gẹgẹ bi ẹnikan ha ń ṣọra fun ibọriṣa bi? Iwọ ha ń fun Ọlọrun ni ifọkansin ti a yasọtọ gédégbé bi? Iwọ ha ti ipo ọba-alaṣẹ Jehofa lẹhin ki o sì gbe e ga gẹgẹ bi Ọlọrun otitọ ati alààyè bi? Bi o bá ri bẹẹ, o gbọdọ jẹ igberopinnu rẹ lati maa baa lọ ni diduro gbọnyin lodisi awọn aṣa ibọriṣa. Ṣugbọn awọn koko Iwe Mimọ siwaju sii wo ni o lè ràn ọ́ lọwọ lati ṣọra fun gbogbo oniruuru ibọriṣa?
Ki Ni Èrò Rẹ?
◻ Ki ni ibọriṣa jẹ?
◻ Eeṣe ti Jehofa fi lodisi gbogbo ibọriṣa?
◻ Ipo wo ni awọn Heberu mẹta naa mú nipa ibọriṣa?
◻ Bawo ni awọn wọnni ti wọn ń jẹ awọn ohun ti a fi rubọ si oriṣa ṣe lè ṣajọpin pẹlu awọn ẹmi eṣu?
◻ Eeṣe ti a fi nilati ṣọra fun ibọriṣa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bi o tilẹ jẹ pe a halẹ mọ iwalaaye wọn, awọn Heberu mẹta naa kì yoo lọwọ ninu ibọriṣa