Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ẹni Tó Mọyì Wa Gan-an
“ỌKÀN-ÀYÀ wa ti lè dá wa lẹ́bi.” Bíbélì lo gbólóhùn yìí láti fi hàn pé nígbà míì, nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, a lè máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kódà, èrò pé a ò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run lè ṣàánú fún tiẹ̀ lè má kúrò lọ́kàn wa bọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ ni pé: “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:19, 20) Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. Nǹkan tí Ọlọ́run ń rò nípa wa yàtọ̀ sí ohun tí à ń rò nípa ara wa. Nígbà náà, kí ni Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ pé èrò tiẹ̀ ló ṣe pàtàkì jù ń rò nípa wa? Àpèjúwe kan tó múni ronú jinlẹ̀ tí Jésù lò lẹ́ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
Nígbà kan, Jésù sọ pé, “ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré.” (Mátíù 10:29, 31) Jésù tún sọ nínú Lúùkù 12:6, 7 pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. . . . Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” Àpèjúwe kékeré tó múni ronú jinlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí ohun tí Jèhófà ń rò nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa ìránṣẹ́ rẹ̀.
Ológoṣẹ́ wà lára àwọn ẹyẹ tí kò níye lórí rárá táwọn èèyàn máa ń jẹ. Ohun tó dájú ni pé Jésù á ti máa kíyè sí àwọn obìnrin tó jẹ́ tálákà nígbà tí wọ́n bá ń ra àwọn ẹyẹ tín-tìn-tín yìí lọ́jà, kí ìdílé wọn lè rí oúnjẹ jẹ, ó ṣeé ṣe kí ìyá Jésù náà wà lára wọn. Bí ẹnì kán bá ní ẹyọ owó assarion kan, ìyẹn nǹkan bíi náírà mẹ́fà òde òní lọ́wọ́, ẹni yẹn lè ra ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì. Àwọn ẹyẹ yìí gbọ̀pọ̀ débi pé, béèyàn bá ní nǹkan bíi náírà méjìlá lọ́wọ́, ológoṣẹ́ márùn lèèyàn á mú lọ sílé dípò mẹ́rin, torí wọ́n á fi ọ̀kan ṣe èènì.
Jésù ṣàlàyé pé kò sí ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ náà “tí Ọlọ́run kò rántí” tàbí tí yóò jábọ́ “lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.” (Mátíù 10:29) Gbogbo ìgbà tí ológoṣẹ́ bá jábọ́ sílẹ̀, bóyá nítorí pé ó fara pa tàbí tí ó bá bà sílẹ̀ nítorí pé ó ń wá oúnjẹ ni Jèhófà mọ̀. Àwọn ẹyẹ tí ò fi bẹ́ẹ̀ níyè lórí yìí ò kéré jù fún Jèhófà láti ṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn ò kéré ju ohun tó lè rántí lọ. Ká sòótọ́, ó mọyì wọn gan-an ni, nítorí pé ẹ̀dá alààyè tó ṣeyebíye ni wọ́n. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ tí Jésù ń fi àpèjúwe yìí kọ́ wa?
Bí Jésù bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó sábà máa ń lo àfiwé, ó máa ń fi àwọn ohun tí a ti mọ̀ kọ́ wa ní àwọn ohun pàtàkì tí a kò tíì mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù tún sọ pé: “Àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Mélòómélòó ni ẹ fi níye lórí ju àwọn ẹyẹ?” (Lúùkù 12:24) Ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa nípa ẹyẹ ológoṣẹ́ ti wá ṣe kedere báyìí pé: Bí Jèhófà bá bìkítà tó báyìí nípa àwọn ẹyẹ tín-tìn-tín, mélòómélòó wá ni yóò bìkítà nípa àwa èèyàn tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tá a sì ń jọ́sìn rẹ̀!
Bá a bá lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyí, kò yẹ́ ká máa rò pé a ò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run, tó tóbi ju ‘ọkàn wa lọ,’ lè bìkítà nípa rẹ̀ tàbí ẹni tó máa ṣàánú fún. Ẹ ò ri pé ohun ìtùnú gbáà ló jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa lè rí ohun táwa fúnra wa ò mọ̀ nípa ara wa!
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Ológoṣẹ́: © ARCO/D. Usher/age fotostock