Ẹ Ṣọ́ra Fún “Ohùn Àwọn Àjèjì”
“Àjèjì ni wọn kì yóò tẹ̀ lé lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n wọn yóò sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé wọn kò mọ ohùn àwọn àjèjì.”—JÒHÁNÙ 10:5.
1, 2. (a) Kí ni Màríà ṣe nígbà tí Jésù dárúkọ ẹ̀, kí sì ni Jésù sọ ṣáájú ìgbà yẹn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàpèjúwe rẹ̀? (b) Kí lohun tó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jésù?
NÍGBÀ tí Jésù jíǹde, ó rí obìnrin kan tó dúró sítòsí ibojì rẹ̀. Ó mọ obìnrin yìí dáadáa. Màríà Magidalénì lórúkọ obìnrin náà. Nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára rẹ̀. Látìgbà yẹn ní obìnrin yìí ti ń bá Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ káàkiri, tó sì ń pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn lójoojúmọ́. (Lúùkù 8:1-3) Àmọ́, lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ńṣe ni Màríà ń sunkún tí ìbànújẹ́ sì dorí rẹ̀ kodò nítorí pé ìṣojú rẹ̀ ni Jésù kú, àti pé òkú Jésù ọ̀hún pàápàá ti dàwátì báyìí! Jésù wá bi í léèrè pé: “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sunkún? Ta ni ìwọ ń wá?” Ó rò pé olùṣọ́gbà ló ń bá òun sọ̀rọ̀, ló bá fèsì pé: “Ọ̀gá, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e lọ.” Jésù wá sọ pé: “Màríà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló rántí bí Jésù ṣe máa ń pe òun. Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Olùkọ́!” Bó ṣe dì mọ́ Jésù nìyẹn.—Jòhánù 20:11-18.
2 Ìtàn yìí ṣàpèjúwe ohun tí Jésù sọ ṣáájú ìgbà yẹn lọ́nà tó wọni lọ́kàn. Jésù fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé àgùntàn, ó wá sọ pé olùṣọ́ àgùntàn fi orúkọ pe àwọn àgùntàn rẹ̀, àwọn àgùntàn náà sì dá ohùn rẹ̀ mọ̀. (Jòhánù 10:3, 4, 14, 27, 28) Ó dájú pé bí àwọn àgùntàn ṣe dá olówó wọn mọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Màríà dá Kristi, Olùṣọ́ Àgùntàn rẹ̀ mọ̀. Bákan náà làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí ń bẹ lóde òní dá olùṣọ́ àgùntàn wọn mọ̀. (Jòhánù 10:16) Gẹ́gẹ́ bí etí tí àgùntàn kan fi ń dá ohùn mọ̀ ṣe máa ń ràn án lọ́wọ́ láti sún mọ́ olùṣọ́ rẹ̀, bákan náà ni òye tá a fi ń mọ nǹkan nípa tẹ̀mí ṣe máa ń jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, Olùṣọ́ Àgùntàn wa Àtàtà.—Jòhánù 13:15; 1 Jòhánù 2:6; 5:20.
3. Kí ni àwọn ìbéèrè tí àpèjúwe Jésù nípa agbo àgùntàn gbé sí wa lọ́kàn?
3 Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe yìí ṣe fi hàn, agbára táwọn àgùntàn ní láti dá ohùn èèyàn mọ̀ kì í ṣe láti fi mọ àwọn ọ̀rẹ́ wọn nìkan, wọ́n tún lè fi dá ohùn àwọn ọ̀tá wọn mọ̀ pẹ̀lú. Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé a ní àwọn ọ̀tá. Ta làwọn ọ̀tá yìí? Iṣẹ́ burúkú wo ni wọ́n sì ń ṣe? Báwo la sì ṣe lè dáàbò bo ara wa? Láti lè mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mìíràn tí Jésù sọ nínú àpèjúwe tó ṣe nípa agbo àgùntàn.
‘Ẹni Tí Kò Bá Gba Ẹnu Ọ̀nà Wọlé’
4. Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe nípa olùṣọ́ àgùntàn, ta ni àwọn àgùntàn náà tẹ̀ lé, ta ni wọn ò sì tẹ̀ lé?
4 Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. Olùṣọ́nà ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí, àwọn àgùntàn sì fetí sí ohùn rẹ̀, ó sì fi orúkọ pe àwọn àgùntàn tirẹ̀, ó sì ṣamọ̀nà wọn jáde. Nígbà tí ó ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn sì tẹ̀ lé e, nítorí pé wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Àjèjì ni wọn kì yóò tẹ̀ lé lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n wọn yóò sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé wọn kò mọ ohùn àwọn àjèjì.” (Jòhánù 10:2-5) Ẹ kíyè sí i pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “ohùn.” Ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ̀rọ̀ nípa ohùn olùṣọ́ àgùntàn àmọ́ lẹ́ẹ̀kẹta, ó tọ́ka sí “ohùn àwọn àjèjì.” Irú àjèjì wo wá ni Jésù ń tọ́ka sí?
5. Kí nìdí tá ò fi lè ṣe irú àjèjì tí Jòhánù orí kẹwàá mẹ́nu kàn lálejò?
5 Kì í ṣe àjèjì tá a máa ṣe lálejò ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀—ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà aájò àlejò tí Bíbélì lò túmọ̀ sí “ìfẹ́ àjèjì.” (Hébérù 13:2) Àjèjì tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àpèjúwe rẹ̀ kì í ṣe àlejò tá a dìídì pè. Àjèjì náà “kò . . . gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn ṣùgbọ́n . . . ó gun ibòmíràn.” “Olè àti olùpiyẹ́” ni. (Jòhánù 10:1) Ta lẹni tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó kọ́kọ́ di olè àti olùpiyẹ́? Sátánì Èṣù ni. Inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì la ti rí ẹ̀rí pé òun ni.
Ìgbà Àkọ́kọ́ Tá A Gbọ́ Ohùn Àjèjì Kan
6, 7. Kí nìdí tá a fi lè pe Sátánì ní àjèjì àti olè?
6 Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5 sọ béèyàn ṣe gbọ́ ohùn àjèjì kan lórí ilẹ̀ ayé ní ìgbà àkọ́kọ́. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé Sátánì tipa ejò lọ sọ́dọ̀ Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, ó sì tàn án jẹ. Lóòótọ́, àkọsílẹ̀ yìí ò dìídì pe Sátánì ní “àjèjì.” Síbẹ̀ náà, àwọn nǹkan tó ṣe fi hàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló fi jọ àjèjì tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àpèjúwe rẹ̀ tó wà nínú Jòhánù orí kẹwàá. Gbé àwọn nǹkan tí Sátánì fi jọ àjèjì yìí yẹ̀ wò.
7 Jésù sọ pé ọ̀nà ẹ̀bùrú ni àjèjì náà gba lọ sáàárín àgbò àgùntàn láti lọ bá àgùntàn tó fẹ́ ji gbé. Bákan náà, ọ̀nà ẹ̀bùrú ni Sátánì gbà lọ bá ẹni náà tí ó tàn jẹ́, ó lo ejò. Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì lò yìí jẹ́ ká mọ irú ẹ̀dá tí Sátánì jẹ́—oníbékebèke ẹ̀dá. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tó wà lọ́kàn àjèjì tó wọ àárín agbo àgùntàn náà ni láti gba àgùntàn mọ́ olówó rẹ̀ lọ́wọ́. Àní, ó tiẹ̀ burú ju olè lọ nítorí pé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni láti “pani àti láti pa run.” (Jòhánù 10:10) Bákan náà, olè ni Sátánì. Nígbà tí ó tan Éfà, ńṣe ló jí ìṣòtítọ́ Éfà mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́. Ìyẹn nìkan kọ́ ni Sátánì ṣe o, òun ló tún fa ikú ẹ̀dá èèyàn. Nítorí èyí, apààyàn ni Sátánì.
8. Báwo ni Sátánì ṣe yí ọ̀rọ̀ Jèhófà àtohun tó ní lọ́kàn padà?
8 Ọ̀nà tí Sátánì gbà yí nǹkan tí Jèhófà sọ àtohun tó ní lọ́kàn padà jẹ́ ká rí i pé alábòsí ẹ̀dá ni. Ó bi Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Sátánì ṣe bíi pé ọ̀rọ̀ náà yà òun lẹ́nu, nǹkan tó sì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘Báwo ni Ọlọ́run á ṣe máa sọ irú nǹkan báyẹn?’ Ó tún wá sọ pé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là.” Kíyè sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ọlọ́run mọ̀ pé.” Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ níbẹ̀ yẹn ni pé: ‘Mo mọ ohun tí Ọlọ́run mọ̀. Mo mọ ohun tó ní lọ́kàn, kì í sì ṣe nǹkan tó dáa ló ní lọ́kàn.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1, 5) Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà àti Ádámù kò gbé etí kúrò pé àwọn ò fẹ́ gbọ́ ohùn àjèjì yìí. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n tẹ́tí sí i, wọ́n sì tipa báyìí fa àjálù sórí ara wọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn.—Róòmù 5:12, 14.
9. Kí nìdí tá a fi lè retí pé àwọn èèyàn yóò máa gbọ́ ohùn àwọn àjèjì lóde òní?
9 Irú ọgbọ́n yìí kan náà ni Sátánì ń lò láti tan àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. (Ìṣípayá 12:9) Òun ni “baba irọ́,” ọmọ rẹ̀ sì làwọn tó ń gbìyànjú láti ṣi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà gẹ́gẹ́ bí òun náà ti ń ṣe. (Jòhánù 8:44) Ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan tí ohùn àwọn àjèjì gbà ń dún lóde òní.
Ọ̀nà Tí Ohùn Àwọn Àjèjì Gbà Ń Dún Lóde Òní
10. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí ohùn àwọn àjèjì gbà ń dún?
10 Ìrònú ẹ̀tàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí a má ṣe fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbé yín lọ.” (Hébérù 13:9) Irú àwọn ẹ̀kọ́ wo? Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀kọ́ náà ti lè ‘gbé wa lọ,’ ó ṣe kedere pé àwọn ẹ̀kọ́ tó lè dín agbára wa kù nípa tẹ̀mí ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn wo ló ń kéde irú àwọn ẹ̀kọ́ àjèjì bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà pé: “Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30) Lóde òní bíi ti ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn kan wà tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń gbìyànjú láti tan àwọn àgùntàn nípa sísọ àwọn “ohun àyídáyidà,” ìyẹn kí wọ́n máa yí irọ́ pọ̀ mọ́ òótọ́ tàbí kí wọ́n máa parọ́ gidi. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé wọ́n ń lo “ayédèrú ọ̀rọ̀,” ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ òótọ́ àmọ́ tó jẹ́ pé kò wúlò bí ayédèrú owó kò ṣe wúlò.—2 Pétérù 2:3.
11. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ 2 Pétérù 2:1, 3 ṣe táṣìírí ọgbọ́n táwọn apẹ̀yìndà máa ń lò àti ohun tó wà lọ́kàn wọn?
11 Pétérù tún táṣìírí ọgbọ́n táwọn apẹ̀yìndà máa ń lò, ó ní wọn “yóò yọ́ mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé wá.” (2 Pétérù 2:1, 3) Gẹ́gẹ́ bí olè inú àpèjúwe Jésù nípa agbo àgùntàn, olè yẹn kò “gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn ṣùgbọ́n . . . ó gun ibòmíràn,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn apẹ̀yìndà ṣe máa yọ́ kẹ́lẹ́ wá sọ́dọ̀ wa. (Gálátíà 2:4; Júúdà 4) Kí lohun tó wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fẹ́ ṣe? Pétérù sọ pé: “Wọn yóò fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà.” Ní ti tòótọ́, kò sí báwọn apẹ̀yìndà ṣe lè díbọ́n tó, ohun tí wọ́n torí ẹ̀ wá ni “láti jalè àti láti pani àti láti pa run.” (Jòhánù 10:10) Torí náà, ẹ ṣọ́ra fún irú àwọn àjèjì bẹ́ẹ̀!
12. (a) Báwo ni àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè jẹ́ ká máa gbọ́ ohùn àwọn àjèjì? (b) Ọ̀nà wo ni ọgbọ́n tí Sátánì máa ń lò àtèyí táwọn àjèjì máa ń lò lónìí gbà jọra?
12 Ẹgbẹ́ búburú. A tún lè tipasẹ̀ àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ gbọ́ ohùn àwọn àjèjì. Àwọn ọ̀dọ́ sì ni ẹgbẹ́ búburú máa ń ṣàkóbá fún jù lọ. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Rántí pé Éfà ni Sátánì dájú sọ, torí pé òun lọ́jọ́ orí rẹ̀ kéré jù nínú àwọn ẹ̀dá èèyàn méjì àkọ́kọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Sátánì mú kí Éfà gbà gbọ́ pé Jèhófà kò fún un lómìnira tó bó ṣe yẹ, irọ́ gbuu sì ni. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá èèyàn tó dá, ó sì ń bìkítà fún wọn. (Aísáyà 48:17) Bákan náà lónìí, àwọn àjèjì ń gbìyànjú láti mú kí ẹ̀yin ọ̀dọ́ gbà pé àwọn òbí yín tó jẹ́ Kristẹni kò fún yín lómìnira tó. Báwo làwọn àjèjì bẹ́ẹ̀ ṣe lè nípa lórí rẹ? Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Ìgbà kan wa táwọn ọmọ kíláàsì mi sọ ìgbàgbọ́ mi di aláìlágbára. Wọn ò yéé sọ pé ẹ̀sìn mi ti le jù, pé kì í gba téèyàn rò.” Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí rẹ fẹ́ràn rẹ. Torí náà, nígbà táwọn ọmọ iléèwé rẹ bá rọ̀ ọ́ pé kí o má fọkàn tán àwọn òbí rẹ, má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ jẹ bíi ti Éfà.
13. Kí ni nǹkan tó mọ́gbọ́n dání tí Dáfídì ṣe, ọ̀nà wo la sì lè gbà fára wé e?
13 Onísáàmù náà Dáfídì sọ nípa ẹgbẹ́ búburú pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.” (Sáàmù 26:4) Ǹjẹ́ ó kíyè sí nǹkan mìíràn táwọn àjèjì máa ń ṣe? Wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́—nǹkan tí Sátánì sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nípa lílo ejò. Lónìí, àwọn oníwàkiwà kan máa ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an pa mọ́ nípa lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nínú àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí kọ̀ǹpútà, àwọn àgbàlagbà kan tó ti ya ìyàkuyà máa ń ṣe bí ọ̀dọ́ kí wọ́n bàa lè dẹkùn mú yín. Ẹ̀yín ọ̀dọ́, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣọ́ra kẹ́ ẹ máa bàa ko àgbákò nípa tẹ̀mí.—Sáàmù 119:101; Òwe 22:3.
14. Báwo ni ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ṣe máa ń gbé ohùn àwọn àjèjì jáde nígbà míì?
14 Ẹ̀sùn Èké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde máa ń sọ ohun tó dáa nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìgbà mìíràn wà táwọn èèyàn máa ń lò wọ́n láti kéde ohùn àwọn àjèjì tó fi ẹ̀tanú hàn. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan báyìí, ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé ìròyìn èké kan jáde tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti ìjọba Hitler lẹ́yìn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ní orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìròyìn kan pé wọ́n ń ba ilé ìjọsìn jẹ́. Láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan, wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìròyìn pé wọ́n kì í gbé àwọn ọmọ wọn lọ sílé ìwòsàn nígbà tára wọn ò bá le, wọ́n tún ní wọ́n máa ń mọ̀ọ́mọ̀ gbojú fo ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá dá. (Mátíù 10:22) Bí wọ́n tiẹ̀ ń gbé àwọn ìròyìn wọ̀nyíjáde, síbẹ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n mọ irú ẹni tá a jẹ́ mọ̀ pé irọ́ gbuu làwọn ẹ̀sùn wọ̀nyẹn.
15. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti gba gbogbo ohun tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde bá ń sọ gbọ́?
15 Kí lohun tó yẹ ká ṣe nígbà tí ohùn àwọn àjèjì bá gbé ẹ̀sùn èké nípa wa jáde fáyé gbọ́? Á dára ká fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe 14:15 sọ́kàn, ó kà pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Kò ní bọ́gbọ́n mu tó bá jẹ́ pé gbogbo ìròyìn tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde bá sọ là ń gbà gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ pé irọ́ ni gbogbo ìsọfúnni táwọn èèyàn ń gbé jáde, síbẹ̀ a mọ̀ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.
“Ẹ Dán Àwọn Àgbéjáde Onímìísí Wò”
16. (a) Báwo ni ìṣesí àwọn àgùntàn ṣe fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 10:4? (b) Kí ni Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká ṣe?
16 Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá ẹni tá a bá da nǹkan pọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí ọ̀tá wa? Jésù sọ pé àwọn àgùntàn máa ń tẹ̀ lé olùṣọ́ àgùntàn “nítorí pé wọ́n mọ ohùn rẹ̀.” (Jòhánù 10:4) Kì í ṣe ìrísí olùṣọ́ àgùntàn ló ń mú káwọn àgùntàn máa tẹ̀ lé e; ohùn rẹ̀ ni. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kan fi tó ni létí pé ọkùnrin kan tó lọ síbi tí agbo àgùntàn wà sọ pé aṣọ táwọn olùṣọ́ àgùntàn bá wọ̀ làwọn àgùntàn fi máa ń dá wọn mọ̀, pé kì í ṣe ohùn wọn. Olùṣọ́ àgùntàn kan sọ pé ohùn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n bá mọ̀ ni wọ́n fi máa ń dá a mọ̀. Kí olùṣọ́ àgùntàn yìí lè fi yé ọkùnrin náà pé òótọ́ lòun ń sọ, ó ní kí wọ́n jọ pààrọ̀ aṣọ. Nísinsìnyí tí ọkùnrin náà ti wọ aṣọ olùṣọ́ àgùntàn, ó wá pe àwọn àgùntàn náà, àmọ́ wọn ò dá a lóhùn. Wọn ò mọ ohùn rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn náà pè wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ aṣọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ làwọn àgùntàn náà tọ̀ ọ́ wá. Abájọ tó fi jẹ́ pé ẹnì kan lè jọ olùṣọ́ àgùntàn, àmọ́ ìyẹn ò ní káwọn àgùntàn má mọ̀ pé kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn gidi. Nǹkan táwọn àgùntàn náà ṣe ni pé, wọ́n dán ohùn ẹni tó ń pè wọ́n wò, wọ́n wò ó bóyá ó jọ ti olùṣọ́ wọn. Irú nǹkan tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ká ṣe gan-an nìyẹn, pé ká “dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1; 2 Tímótì 1:13) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
17. (a) Báwo la ṣe lè mọ ohùn Jèhófà dáadáa? (b) Kí ni ìmọ̀ nípa Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe?
17 Lóòótọ́, bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ ohùn Jèhófà tàbí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí i la ó máa tètè dá ohùn àwọn àjèjì mọ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní irú ìmọ̀ yẹn. Ó sọ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.’” (Aísáyà 30:21) Inú Bíbélì ni “ọ̀rọ̀” náà tí à ń gbọ́ lẹ́yìn wa wà. Gbogbo ìgbà tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ńṣe ló dà bíi pé à ń gbọ́ ohùn Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá. (Sáàmù 23:1) Nítorí náà, bá a bá ṣe túbọ̀ ń ka Bíbélì la ó ṣe máa mọ ohùn Ọlọ́run sí i. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká lè tètè dá ohùn àwọn àjèjì mọ̀ ní gbàrà tá a bá gbọ́ ọ.—Gálátíà 1:8.
18. (a) Kí ni àwọn nǹkan mìíràn tó wé mọ́ mímọ ohùn Jèhófà? (b) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Mátíù 17:5 sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbọ́rọ̀ sí Jésù lẹ́nu?
18 Kí ni àwọn nǹkan mìíràn tó wé mọ́ mímọ ohùn Jèhófà? Yàtọ̀ sí pé ká máa gbọ́ ọ̀rọ̀, ó kan pé ká máa ṣègbọràn. Kíyè sí ohun tí Aísáyà 30:21 sọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ipasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la fi ń gbọ́ ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa. Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa á láṣẹ pé: “Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” Jèhófà fẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ tá à ń gbọ́ ṣèwà hù. Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù, ńṣe là ń fi hàn pé kì í ṣe pé à kàn ń gbọ́ ohùn Jèhófà nìkan, àmọ́ a tún ń ṣègbọràn sí i pẹ̀lú. (Diutarónómì 28:1) Ṣíṣe ìgbọràn sí Jèhófà tún kan pé ká máa gbọ́rọ̀ sí Jésù lẹ́nu, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 17:5) Kí ni Jésù, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ní ká ṣe? Ó kọ́ wa pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ó tún ní ká fọkàn tán “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45; 28:18-20) Tá a bá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, a óò rí ìyè àìnípẹ̀kun.—Ìṣe 3:23.
“Wọn Yóò Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Rẹ̀”
19. Kí lohun tó yẹ ká ṣe nígbà tá a bá gbọ́ ohùn àwọn àjèjì?
19 Kí wá lohun tó yẹ ká ṣe nígbà tá bá a gbọ́ ohùn àwọn àjèjì? Bí àwọn àgùntàn ṣe ń ṣe gẹ́lẹ́ ló yẹ káwa náà ṣe. Jésù sọ pé: “Àjèjì ni wọn kì yóò tẹ̀ lé lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n wọn yóò sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jòhánù 10:5) Ọ̀nà méjì ni ohun tó yẹ ká ṣe pín sí. Ìkíní, a “kì yóò tẹ̀ lé [àjèjì] lọ́nàkọnà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe la máa pa àjèjì tì pátápátá. Àní, nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ náà “lọ́nàkọnà” gbé yọ fi bí ẹnì kan ṣe kọ nǹkan sílẹ̀ pátápátá tó hàn. (Mátíù 24:35; Hébérù 13:5) Èkejì, a óò “sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,” tàbí ká yà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ohun tó dára jù lọ tá a lè ṣe nìyẹn sí àwọn tí ẹ̀kọ́ wọn kò bá ohùn Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà mu.
20. Kí la máa ṣe nígbà tá a bá dojú kọ (a) àwọn apẹ̀yìndà ẹlẹ̀tàn, (b) ẹgbẹ́ búburú, (d) tàbí tá a bá gbọ́ ìròyìn èké?
20 Nítorí náà, nígbà tá a bá bá àwọn tó ń sọ èrò àwọn apẹ̀yìndà pàdé, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lò yẹ ká ṣe, ó ní: “[Ẹ máa] ṣọ́ àwọn tí ń fa ìpínyà àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀ lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ sì yẹra fún wọn.” (Róòmù 16:17; Títù 3:10) Bákan náà, bí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ti ń dojú kọ́ ewú ẹgbẹ́ búburú ó yẹ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì pé: “Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” Nígbà tí wọ́n bá sì fẹ̀sùn èké kàn wá nínú ìròyìn, ó yẹ ká rántí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, ó ní: “A óò mú wọn [ìyẹn àwọn tó ń tẹ́tí sí ohùn àwọn àjèjì] yà sínú ìtàn èké. Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo.” (2 Tímótì 2:22; 4:3-5) Bó ti wù kí ohùn àwọn àjèjì dùn tó, a óò sá fún gbogbo nǹkan tó lè dojú ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa dé.—Sáàmù 26:5; Òwe 7:5, 21; Ìṣípayá 18:2, 4.
21. Kí ni èrè tó wà fún àwọn tí kò bá tẹ́tí sí ohùn àwọn àjèjì?
21 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe ohun tí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ní kí wọ́n ṣe nínú Lúùkù 12:32, wọ́n kò tẹ́tí sí ohùn àwọn àjèjì rárá. Níbẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” Bákan náà, “àwọn àgùntàn mìíràn” ń hára gàgà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:34) Ìbùkún tí a óò rí á mà pọ̀ gan-an o, tí a kò bá tẹ́tí sí “ohùn àwọn àjèjì”!
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni Sátánì ṣe bá àjèjì tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe rẹ̀ nípa agbo àgùntàn mu?
• Báwo la ṣe ń gbọ́ ohùn àwọn àjèjì lóde òní?
• Báwo la ṣe lè dá ohùn àwọn àjèjì mọ̀?
• Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tá a bá gbọ́ ohùn àwọn àjèjì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Màríà dá Kristi mọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni àjèjì náà gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn àgùntàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kí lohun tó yẹ ká ṣe nígbà tá a bá gbọ́ ohùn àwọn àjèjì?