Àwọn Alábòójútó Arìnrìn Àjò—Àwọn Ẹ̀bùn Nínú Ènìyàn
“Nígbà tí ó gòkè sí ibi gíga ó kó àwọn òǹdè lọ; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn nínú ènìyàn.”—ÉFÉSÙ 4:8.
1. Iṣẹ́ tuntun wo ni a kéde rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde yìí ní ọdún 1894?
NÍ OHUN tí ó lé ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kéde ohun tuntun kan. A ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ẹ̀ka Tuntun Nínú Iṣẹ́ Náà.” Kí ni ìgbòkègbodò tuntun yìí ní nínú? Ó jẹ́ ìfilọ́lẹ̀ òde òní ti iṣẹ́ àwọn alábòójútó arìnrìn àjò. Ìtẹ̀jáde ìwé agbéròyìnjáde yìí ti September 1, 1894 (lédè Gẹ̀ẹ́sì), ṣàlàyé pé láti ìgbà náà lọ, àwọn arákùnrin tí wọ́n tóótun yóò máa bẹ àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wò, ‘fún ète gbígbé wọn ró nínú òtítọ́.’
2. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè ní?
2 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn alábòójútó bíi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bẹ àwọn ìjọ Kristẹni wò. Àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ní ète ‘gbígbé’ àwọn ìjọ ‘ró’ lọ́kàn. (Kọ́ríńtì Kejì 10:8) Lónìí, a ti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin tí ń ṣe èyí lọ́nà tí a wéwèé bù kún wa. Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yàn wọ́n sípò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká àti àgbègbè. Alábòójútó àyíká kan máa ń bẹ ìjọ bí 20 wò, ọ̀sẹ̀ kan fún ìjọ kan, nǹkan bí ìgbà méjì nínú ọdún kan, nípa yíyẹ àkọsílẹ̀ wò, sísọ àsọyé, àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pẹ̀lú àwọn akéde Ìjọba. Alábòójútó àgbègbè ni ó máa ń ṣe alága ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpéjọ àyíká ọdọọdún fún àwọn àyíká mélòó kan, ó máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pẹ̀lú ìjọ tí ó bá gbà á lálejò, ó sì máa ń pèsè ìṣírí nínú àwọn àsọyé tí a gbé karí Bíbélì.
Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ Tí Wọ́n Ní
3. Èé ṣe tí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò fi ní láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?
3 Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò máa ń wà lórí ìrìn nígbà gbogbo. Èyí fúnra rẹ̀ ń béèrè ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Rírìnrìn àjò láti ìjọ kan sí òmíràn lè ṣòro lọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí àti aya wọn ń fi ìṣarasíhùwà onídùnnú ṣe bẹ́ẹ̀. Alábòójútó àyíká kan wí pé: “Aya mi ń tì mí lẹ́yìn gidigidi, kì í sì í ráhùn . . . Ó yẹ kí a gbóríyìn fún un nítorí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí ó ní.” Àwọn alábòójútó àyíká kan ń rìnrìn àjò tí ó lé ní 1,000 kìlómítà láti ìjọ dé ìjọ. Ọ̀pọ̀ ń wakọ̀, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ń lọ láti ibì kan sí ibì kejì nípa wíwọkọ̀ èrò, gígun kẹ̀kẹ́ ológeere, gígun ẹṣin, tàbí fífẹsẹ̀ rìn. Alábòójútó àyíká kan tí ó jẹ́ ará Áfíríkà tilẹ̀ ní láti fẹsẹ̀ la omi kọjá pẹ̀lú aya rẹ̀ léjìká rẹ̀, láti baà lè dé ìjọ kan. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní láti fara da ooru àti òtútù, ebi àti òùngbẹ, àìsùn lóru, onírúurú ewu, àti inúnibíni oníwà ipá. Ó tún ní “àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ”—ìrírí kan tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lónìí.—Kọ́ríńtì Kejì 11:23-29.
4. Ipa wo ni ìṣòro àìlera lè ní lórí ìgbésí ayé àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn?
4 Gẹ́gẹ́ bíi Tímótì, alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn aya wọn máa ń ní ìṣòro àìlera nígbà míràn. (Tímótì Kìíní 5:23) Èyí ń dá kún másùn máwo wọn. Aya alábòójútó àyíká kan ṣàlàyé pé: “Wíwà pẹ̀lú àwọn ará nígbà gbogbo nígbà tí ara mi kò bá dá máa ń fa pákáǹleke fún mi. Nígbà tí nǹkan oṣù mi sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í dáwọ́ dúró, èyí ti wá ṣòro gidigidi fún mi. Ìpèníjà gidi ni pípalẹ̀ gbogbo ohun ìní wa mọ́ àti ṣíṣí lọ sí ibòmíràn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo ní láti dúró, kí n sì gbàdúrà sí Jèhófà, kí ó fún mi ní okun láti lè máa bá a nìṣó.”
5. Láìka onírúurú ìṣòro sí, ẹ̀mí wo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn ń fi hàn?
5 Láìka àwọn ìṣòro àìlera àti àwọn àdánwò míràn sí, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn aya wọn ń rí ìdùnnú nínú iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n sì ń fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn. Àwọn kan ti fi ẹ̀mí wọn wewu láti ṣèrànwọ́ nípa tẹ̀mí ní àkókò inúnibíni tàbí ogun. Nígbà tí wọ́n ń bẹ ìjọ wò, wọ́n ti fi irú ẹ̀mí kan náà tí Pọ́ọ̀lù ní hàn, ẹni tí ó sọ fún àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà pé: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ ní àárín yín, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀. Nítorí náà, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fi fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.”—Tẹsalóníkà Kìíní 2:7, 8.
6, 7. Agbára ìdarí rere wo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tí ń ṣiṣẹ́ kára lè ní?
6 Bíi ti àwọn alàgbà yòó kù nínú ìjọ Kristẹni, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.” Gbogbo irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ “kí a kà . . . yẹ fún ọlá onílọ̀ọ́po méjì.” (Tímótì Kìíní 5:17) A lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ wọn bí ‘a bá fara wé ìgbàgbọ́ wọn’ lẹ́yìn tí ‘a bá ti fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọn ti rí.’—Hébérù 13:7.
7 Ipa wo ni àwọn alàgbà kan tí wọ́n jẹ́ arìnrìn àjò ti ní lórí àwọn ẹlòmíràn? Ẹnì kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà kọ̀wé pé: “Ẹ wo irú ipa àgbàyanu tí Arákùnrin P—— ní lórí ìgbésí ayé mi! Ó jẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò ní Mexico láti ọdún 1960 síwájú. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, mo máa ń fi ìháragàgà àti ìdùnnú dúró de ìbẹ̀wò rẹ̀. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó wí fún mi pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú yóò di alábòójútó àyíká.’ Ní àwọn àkókò tí kò rọrùn, ti ọ̀dọ́langba, ìgbà gbogbo ni mo máa ń wá a kiri, nítorí pé, ìgbà gbogbo ni ó máa ń ní ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n láti bá mi sọ. Ohun tí ó jẹ ẹ́ lógún jù lọ ni ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo! Nísinsìnyí tí mo jẹ́ alábòójútó àyíká, mo máa ń fìgbà gbogbo yọ̀ọ̀da àkókò mi fún àwọn ọ̀dọ́, mo sì máa ń fi àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run síwájú wọn gẹ́gẹ́ bí òún ti ṣe fi wọ́n síwájú mi. Àní ní àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn ìwàláàyè rẹ̀, láìka ìṣòro ọkàn-àyà tí kò lè ṣiṣẹ́ dáradára tí ó ní sí, Arákùnrin P—— máa ń fìgbà gbogbo fẹ́ láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìṣírí. Ní ọjọ́ kan ṣáájú ikú rẹ̀ ní February 1995, ó bá mi lọ sí àpéjọ àkànṣe kan, ó sì fi àwọn góńgó àtàtà síwájú arákùnrin kan tí ó jẹ́ ayàwòrán ilé. Kíá ni arákùnrin náà fi iwé ìbéèrè láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀.”
A Mọrírì Wọn
8. Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn nínú ènìyàn” tí a ṣàpèjúwe nínú Éfésù orí 4, báwo sì ni wọ́n ṣe ń ṣe ìjọ láǹfààní?
8 Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti àwọn alàgbà míràn tí a fi iṣẹ́ ìsìn ṣojú rere sí nípasẹ̀ inú rere Ọlọ́run tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, ni a ń pè ní “àwọn ẹ̀bùn nínú ènìyàn.” Gẹ́gẹ́ bí aṣojú Jèhófà àti Orí ìjọ, Jésù ti pèsè àwọn ọkùnrin tẹ̀mí wọ̀nyí láti baà lè gbé wa ró lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kí a sì lè dé ìdàgbàdénú. (Éfésù 4:8-15) Ó yẹ kí a fi ìmọrírì hàn fún ẹ̀bùn èyíkéyìí. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì bí ẹ̀bùn náà bá jẹ́ èyí tí ń fún wa lókun láti máa bá ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà nìṣó. Nígbà naa, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ṣe lè fi ìmọrírì wa fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò hàn? Ní àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fi hàn pé a ‘ka àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ẹni ọ̀wọ́n’?—Fílípì 2:29.
9. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà fi ìmọrírì hàn fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò?
9 Nígbà tí a bá kéde ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í wéwèé láti nípìn-ín kíkún nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ fún ọ̀sẹ̀ yẹn. Bóyá a lè ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ láti kọ́wọ́ ti ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́yìn nígbà ìbẹ̀wò náà. Ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù yẹn. Dájúdájú, a óò fẹ́ láti fi àwọn ìmọ̀ràn alábòójútó àyíká sílò láti baà lè sunwọ̀n sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Irú ẹ̀mí tí ó ṣí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò ṣàǹfààní fún wa, yóò sì mú un dá a lójú pé, ìbẹ̀wò rẹ̀ ti wúlò gidigidi. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alábòójútó àyíká ń bẹ ìjọ wò láti gbé wa ró, ṣùgbọ́n ó yẹ kí a gbé àwọn pẹ̀lú ró nípa tẹ̀mí. Àwọn àkókò kan ń bẹ nígbà tí Pọ́ọ̀lù nílò ìṣírí, ó sì sábà máa ń rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti gbàdúrà fún òun. (Ìṣe 28:15; Róòmù 15:30-32; Kọ́ríńtì Kejì 1:11; Kólósè 4:2, 3; Tẹsalóníkà Kìíní 5:25) Bákan náà, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lóde òní nílò àdúrà àti ìṣírí wa.
10. Báwo ni a ṣe lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ àwọn alábòójútó arìnrìn àjò mú inú wọn dùn?
10 A ha ti sọ fún alábòójútó àyíká àti aya rẹ̀ bí a ṣe mọrírì ìbẹ̀wò wọn tó bí? A ha dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìmọ̀ràn arannilọ́wọ́ tí ó fún wa bí? A ha jẹ́ kí ó mọ ìgbà tí àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá mú kí ìdùnnú wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i bí? Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláyọ̀. (Hébérù 13:17) Alábòójútó àyíká kan ní Sípéènì ní pàtàkì sọ̀rọ̀ lórí bí òun àti aya rẹ̀ ṣe mọrírì ìwé ìdúpẹ́ tí wọ́n rí gbà lẹ́yìn tí wọ́n bẹ àwọn ìjọ wò. Ó sọ pé: “A máa ń tọ́jú àwọn káàdì wọ̀nyí, a sì máa ń kà wọ́n nígbà tí a bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n jẹ́ orísun ìṣírí gidi.”
11. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a jẹ́ kí aya àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé a mọrírì wọn?
11 Dájúdájú, aya alábòójútó arìnrìn àjò máa ń jàǹfààní láti inú àwọn ọ̀rọ̀ oríyìn. Ó ti ṣe ìrúbọ ńláǹlà láti lè ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Àwọn arábìnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí yááfì ìfẹ́ ọkàn àdánidá láti ní ilé tiwọn àti, nínú àwọn ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, níní ọmọ pẹ̀lú. Ọmọbìnrin Jẹ́fútà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó fínnúfíndọ̀ yọ̀ọ̀da àǹfààní rẹ̀ láti ní ọkọ àti ìdílé nítorí ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ ti jẹ́. (Onídàájọ́ 11:30-39) Ojú wo ni a fi wo ìrúbọ rẹ̀? Onídàájọ́ 11:40 sọ pé: “Kí àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì máa lọ ní ọdọọdún láti pohùn réré ọmọbìnrin Jẹ́fútà ará Gílíádì ní ọjọ́ mẹ́rin ní ọdún.” Ẹ wo bí ó ti dára tó nígbà tí a bá sapá láti sọ fún aya àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì mọrírì wọn!
“Ẹ Má Ṣe Gbàgbé Aájò Àlejò”
12, 13. (a) Ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó wà fún fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn? (b) Ṣàkàwé bí irú ẹ̀mí aájò àlejò bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣe tọ̀tún tòsì láǹfààní.
12 Fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn jẹ́ ọ̀nà míràn láti fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn àjò Kristẹni. (Hébérù 13:2) Àpọ́sítélì Jòhánù gbóríyìn fún Gáyọ́sì, fún nínawọ́ aájò àlejò sí àwọn tí wọ́n bẹ ìjọ wò gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì arìnrìn àjò. Jòhánù kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, iṣẹ́ ìṣòtítọ́ ni ìwọ́ ń ṣe nínú ohun yòó wù tí ìwọ́ ń ṣe fún àwọn ará, pẹ̀lúpẹ̀lù bí wọ́n ti jẹ́ àjèjì, àwọn tí wọ́n ti jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ níwájú ìjọ. Àwọn wọ̀nyí ni kí ìwọ́ jọ̀wọ́ rán lọ ní ọ̀nà wọn ní irú ọ̀nà kan tí ó yẹ Ọlọ́run. Nítorí pé tìtorí orúkọ rẹ̀ ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (Jòhánù Kẹta 5-8) Lónìí, a lè mú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà tẹ̀ síwájú nípa nínawọ́ irú aájò àlejò kan náà sí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn. Àmọ́ ṣáá o, àwọn alàgbà àdúgbò ní láti rí i dájú pé ibùgbé wọ́n tẹ́ wọn lọ́rùn, ṣùgbọ́n, alábòójútó àgbègbè kan wí pé: “Ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ará kò sinmi lórí ẹni tí ó lè ṣe nǹkan fún wa. A kò tilẹ̀ ní fẹ́ láti gbin èrò yẹn sí wọn lọ́kàn. A gbọ́dọ̀ múra tán láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀mí aájò àlejò tí èyíkéyìí nínú àwọn arákùnrin wa bá fi hàn, yálà wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.”
13 Ẹ̀mí aájò àlejò lè ṣe tọ̀tún tòsì láǹfààní. Jorge, alábòójútó àyíká nígbà kan rí, tí ó ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí ní Bẹ́tẹ́lì, rántí pé: “Nínú ìdílé mi, a ní àṣà kíké sí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò láti dé sọ́dọ̀ wa. Mo nímọ̀lára pé àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyẹn ràn mí lọ́wọ́ ju bí mo ṣe rò lọ nígbà náà lọ́hùn-ún. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, mo ní àwọn ìṣòro nípa tẹ̀mí. Màmá mi dààmú nítorí èyí, ṣùgbọ́n kò mọ bí òún ṣe lè ṣèrànwọ́, nítorí náà, ó ní kí alábòójútó àyíká bá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, mò ń sá fún un, níwọ̀n bí mo ti ń bẹ̀rù pé kí a má ṣe lámèyítọ́ mi. Ṣùgbọ́n ìwà bí ọ̀rẹ́ tí ó hù yí mi lọ́kàn padà láti sọ èrò mi jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ó ké sí mi láti wá bá òun jẹun pọ̀ ní ọjọ́ Monday kan, mo sì sọ ọkàn mi jáde fún un nítorí mo ní ìdánilójú pé, a lóye mi. Ó tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Àwọn àbá rẹ̀ tí ó ṣeé mú lò ṣiṣẹ́ gan-an, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.”
14. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fi ìmọrírì hàn fún àwọn alàgbà arìnrìn àjò dípò ṣíṣe lámèyítọ́ wọn?
14 Alábòójútó arìnrìn àjò máa ń gbìyànjú láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn ọ̀dọ́ àti àgbàlagbà. Dájúdájú, nígbà náà, ó yẹ kí a fi ìmọrírì wa hàn fún ìsapá rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí a bá ń ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ nítorí àwọn àìlera rẹ̀ tàbí bí a bá ń fi í wé àwọn mìíràn tí wọ́n ti bẹ ìjọ wò ńkọ́, lọ́nà tí kò bára dé? Ó ṣeé ṣe pé, èyí yóò bà á lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Kò fún Pọ́ọ̀lù níṣìírí rárá láti gbọ́ lámèyítọ́ tí a ṣe nípa iṣẹ́ rẹ̀. Ó hàn gbangba pé, àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ ará Kọ́ríńtì sọ̀rọ̀ ìtẹ́ḿbẹ́lú nípa ìrísí àti ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ rẹ̀. Òun fúnra rẹ̀ ṣàyọlò irú ìṣelámèyítọ́ bẹ́ẹ̀, ní sísọ pé: “Àwọn lẹ́tà rẹ̀ wúwo wọ́n sì lágbára, ṣùgbọ́n wíwà níhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì níláárí.” (Kọ́ríńtì Kejì 10:10) Ṣùgbọ́n, ó dùn mọ́ni nínú pé, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò sábà máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì onífẹ̀ẹ́.
15, 16. Báwo ni ìfẹ́ àti ìtara tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn fi hàn ṣe ń nípa lórí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn?
15 Alábòójútó àyíká kan ní Latin America fẹsẹ̀ fọ́ inú ẹrẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ kan láti baà lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ń gbé ní ẹkùn tí àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ń darí. Ó kọ̀wé pé: “Ó ń mórí ẹni wú láti rí bí àwọn arákùnrin wa ṣe fi ìmọrírì wọn hàn fún ìbẹ̀wò náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní láti sapá gidigidi láti lè wà níbẹ̀, ní dídojú kọ ọ̀pọ̀ ewu àti ìnira, ìfẹ́ àti ìtara tí àwọn ará fi hàn san èrè fún èyí.”
16 Alábòójútó àyíká kan ní Áfíríkà kọ̀wé pé: “Nítorí ìfẹ́ tí àwọn ará fi hàn sí wa, a nífẹ̀ẹ́ agbègbè ìpínlẹ̀ Tanzania púpọ̀! Àwọn ará ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wa, inú wọ́n sì dùn láti rí wa nínú ilé wọn.” Ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ àti aláyọ̀ wà láàárín àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn tọkọtaya Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, Ákúílà àti Pírísíkà. Ní tòótọ́, Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé: “Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jésù, tí wọ́n fi ọrùn ara wọn wewu nítorí ọkàn mi, àwọn ẹni tí kì í ṣe èmi nìkan ṣùgbọ́n tí gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń fi ọpẹ́ fún.” (Róòmù 16:3, 4) Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn dúpẹ́ láti ní àwọn Ákúílà àti Pírísíkà òde òní gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ wọn, tí ń sa gbogbo ipá wọn láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn àti láti pèsè ìbákẹ́gbẹ́pọ̀.
Fífún Ìjọ Lókun
17. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ọgbọ́n ń bẹ lẹ́yìn ìṣètò fún àwọn alábòójútó arìnrìn àjò, níbo sì ni wọ́n ti ń gba ìtọ́ni wọn?
17 Jésù wí pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Ọgbọ́n tí ó wà lẹ́yìn ìṣètò fún níní àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ṣe kedere ní ti pé, ó ń ṣèrànwọ́ láti fún ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lókun. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì Pọ́ọ̀lù, òun àti Sílà kẹ́sẹ járí nínú ‘líla Síríà àti Sìlíṣíà já, ó ń fún àwọn ìjọ lókun.’ Ìwé Ìṣe sọ fún wa pé: “Bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já wọ́n a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn wọnnì tí ń bẹ níbẹ̀ kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́. Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Ìṣe 15:40, 41; 16:4, 5) Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn Kristẹni yòó kù, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lóde òní ń gba ìtọ́ni nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.”—Mátíù 24:45.
18. Báwo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ṣe ń fún àwọn ìjọ lókun?
18 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alàgbà arìnrìn àjò gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa jẹun lórí tábìlì tẹ̀mí ti Jèhófà. Wọ́n gbọ́dọ̀ dojúlùmọ̀ àwọn ọ̀nà àti ìlànà tí ètò àjọ Ọlọ́run ń tẹ̀ lé. Nígbà náà ni irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ìbùkún gidi fún àwọn mìíràn. Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ rere wọn ní ti ìtara nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn láti sunwọ̀n sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àwọn àsọyé tí a gbé karí Bíbélì, tí àwọn alàgbà wọ̀nyí tí ń ṣèbẹ̀wò ń sọ máa ń gbé àwọn olùgbọ́ ró nípa tẹ̀mí. Nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, láti ṣiṣẹ́ sìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jèhófà yíká ayé, àti láti lo àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè nípasẹ̀ ‘olùṣòtítọ́ ẹrú,’ àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń fún àwọn ìjọ tí wọ́n láǹfààní láti bẹ̀ wò lókun.
19. Àwọn ìbéèrè wo ni ó ń fẹ́ ìgbéyẹ̀wò?
19 Nígbà tí ètò àjọ Jèhófà dá iṣẹ́ àwọn alàgbà arìnrìn àjò sílẹ̀ láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé agbéròyìnjáde yìí sọ pé: “A óò máa wọ̀nà fún àwọn àbájáde àti fún ìdarí Olúwa síwájú sí i.” Ìdarí Jèhófà ti fara hàn ní kedere. Nítorí ìbùkún rẹ̀ àti nítorí wíwà lábẹ́ àmójútó Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, iṣẹ́ yìí ti gbòòrò, a sì ti tún un ṣe jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ó hàn gbangba pé, Jèhófà ń bù kún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí àwọn ẹ̀bùn nínú ènìyàn wọ̀nyí ní. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ wọn? Kí ni ète wọn? Báwo ni wọ́n ṣe lè mú àǹfààní wá fún ìjọ lọ́nà gíga jù lọ?
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?
◻ Kí ni díẹ̀ nínú ẹrù iṣẹ́ àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi ìmọrírì hàn fún iṣẹ́ ti àwọn alàgbà arìnrìn àjò àti àwọn aya wọn ń ṣe?
◻ Kí ni àwọn alábòójútó arìnrìn àjò lè ṣe láti mú kí àwọn ìjọ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Wíwà lórí ìrìn nígbà gbogbo ń béèrè fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìwọ́ ha ti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn alábòójútó arìnrìn àjò àti aya wọn bí?