Ẹ Ṣọra fun Awọn Apẹhinda!
Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Lẹta Juuda
AWỌN iranṣẹ Jehofa gbọdọ “takété si ohun ti iṣe buburu” ki wọn sì “faramọ́ ohun ti iṣe rere.” (Roomu 12:9) Onkọwe Bibeli naa Juuda ran awọn ẹlomiran lọwọ lati ṣe eyi ninu lẹta rẹ̀ ti o fi ranṣẹ lati Palẹstini o ṣeeṣe ki o jẹ ni nǹkan bii 65 C.E.
Juuda pe ara rẹ̀ ni “iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu.” Jakọbu yii ni a mọ̀ daradara lọna ti o han kedere si ọmọ iya Jesu Kristi. (Maaku 6:3; Iṣe 15:13-21; Galatia 1:19) Juuda funraarẹ nipa bayii jẹ ọmọ iya Jesu. Bi o ti wu ki o ri, o ti lè ronu rẹ̀ bi ohun ti ko yẹ lati mẹnukan isopọ ti ara yii, niwọn bi Kristi ti jẹ ẹni ẹmi ologo kan ninu ọrun nigba naa. Lẹta Juuda ṣe taarata gan-an ninu fifunni ni imọran ti o le ran wa lọwọ lati “faramọ ohun ti iṣe rere” ki a sì ṣọra fun awọn apẹhinda.
“Ja Ija Lilekoko”
Bi o tilẹ jẹ pe Juuda nfẹ lati kọwe nipa igbala ti awọn Kristian dìmú ni apapọ, oun ri i pe o pọndandan lati rọ awọn onkawe rẹ̀ lati “ja ija lilekoko fun igbagbọ.” (Ẹsẹ 1-4, NW) Eeṣe? Nitori pe awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun ti yọ́ wọnu ijọ wọn sì ‘nyi inurere ailẹtọọsi Ọlọrun pada si awawi fun iwa ainijaanu.’ Wọn ronu lọna aitọ pe wọn lè rú awọn ofin Ọlọrun sibẹ ki wọn sì wà laaarin awọn eniyan rẹ̀. Njẹ ki awa maṣe juwọsilẹ fun iru ironu buruku bẹẹ lae ṣugbọn ki a lepa ododo nigba gbogbo, ki a kún fun ọpẹ pe nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọlọrun wẹ̀ wá nù lọna aanu kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa.—1 Kọrinti 6:9-11; 1 Johanu 1:7.
Awọn Ikilọ Ti A Gbeka Iwaju Wa
O pọndandan lati ṣọra lodisi iru awọn ẹmi-ironu, ìwà, ati awọn eniyan kan bayii. (Ẹsẹ 5-16) Nitori pe awọn ọmọ Israẹli melookan ti a gbala kuro ni Ijibiti ṣaini igbagbọ, a pa wọn run. Awọn angẹli ti wọn kọ ipò titọ wọn silẹ ni a ti “pamọ ninu ẹ̀wọ̀n ainipẹkun nisalẹ okunkun [tẹmi] de idajọ ọjọ nla ni.” Iwa palapala biburu lekenka mu “ijiya ina ainipẹkun” wa sori Sodomu ati Gomora. Nitori naa, ẹ jẹ ki a maa tẹ́ Ọlọrun lọrun nigba gbogbo ki a má sì ṣe fi “ipa ọna iye” silẹ lae.—Saamu 16:11.
Laidabi Maikẹli olori awọn angẹli, ẹni ti kò tilẹ ni mu idajọ wá lodisi Eṣu ni lilo awọn ọ̀rọ̀ eebu, awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun sọrọ lọna eebu si awọn “ẹni ologo,” ti o ṣe kedere pe wọn jẹ awọn wọnni ti a dá lọla pẹlu ògo kan bayii gẹgẹ bi awọn alagba ti a fami ororo yàn lati ọwọ́ Ọlọrun ati Kristi. Ẹ maṣe jẹ ki a fi àìlọ́wọ̀ hàn fun ọla aṣẹ ti Ọlọrun fifunni lae!
Awọn apẹẹrẹ buburu ti Keeni, Balamu, ati Kora ni awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun tẹle. Wọn gbe ihalẹmọni tẹmi ti o ṣee fiwe awọn okuta ti wọn farasin nisalẹ omi ka iwaju wọn wọ́n sì dabii awọn àwọ̀sánmà alailomi ati awọn òkú igi ti a fàtu tigbongbo tigbongbo, ti kò lè mu eso ti o ṣanfaani kankan jade. Awọn apẹhinda wọnni tun jẹ́ akùnsínú, olùráhùn, ati ‘awọn aṣojúsàájú nitori èrè.’
Maa Baa Lọ Ní Dídènà
Lẹhin naa Juuda funni ni amọran lori dídènà awọn agbara idari buburu. (Ẹsẹ 17-25) Awọn apẹgan yoo wà ni “igba ikẹhin,” awọn Kristian tootọ sì gbọdọ farada ati awọn ati ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn wọn lonii. Lati dena iru awọn agbara idari buburu bẹẹ, awa nilati gbé ara wa ró lori ‘igbagbọ wa ti o mọ́ julọ,’ ki a gbadura pẹlu ẹmi mimọ, ki a sì pa ara wa mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, nigba ti a nduro de ifihan sode aanu Jesu.
Lọna ti o han gbangba ninu ipa ti awọn olukọ eke nko, awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun ti mu ki awọn kan ṣiyemeji. (Fiwe 2 Peteru 2:1-3.) Kí sì ni awọn oniyemeji nilo? Họwu, iranlọwọ tẹmi lati já wọn gbà kuro ninu “iná,” iparun ainipẹkun! (Matiu 18:8, 9) Ṣugbọn awọn oniwa bi Ọlọrun ko nilati bẹru kadara yẹn, nitori Jehofa yoo daabobo wọn kuro ninu “ìkọ̀sẹ̀” sinu ẹ̀ṣẹ̀ ati iparun ti o nduro de awọn apẹhinda.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]
Awọn Àpáta Fifarasin: Juuda kilọ fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ nipa ‘awọn àpáta fifarasin labẹ omi ninu awọn àsè ifẹ wọn.’ (Juuda 12) Nipa dídíbọ́n fun awọn onigbagbọ pe wọn ni ifẹ, iru awọn apẹhinda bẹẹ dabi awọn àpáta págunpàgun abẹ omi ti o lè ri awọn ọkọ̀ tabi ya awọn omuwẹ lara pẹ́rẹpẹ̀rẹ ki o sì pa wọn. Awọn àsè ifẹ ti lè jẹ àsè nla eyi ti awọn Kristian ti wọn láásìkí lọna ohun ti ara ti pe awọn òtòṣì onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn wá sí. Fadà Ṣọọṣi naa Chrysostom (347?-407 C.E.) wipe: “Gbogbo wọn pade ni ibi àsè kan naa: awọn ọlọ́rọ̀ mú awọn ipese wá, ti a sì nkesi awọn òtòṣì ati awọn wọnni ti wọn kò ni ohunkohun, gbogbo wọn jàsè papọ bakan naa.” Ohunkohun ti o lè jẹ́ iru àsè ifẹ ti ijimiji, ikilọ Juuda ran awọn onigbagbọ lọwọ lati ṣọra fun ‘awọn àpáta fifarasin’ ti awọn apẹhinda tí o lè mu iku tẹmi wá. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Kristian ni a kò paṣẹ fun lati se awọn àsè ifẹ, ti a kìí sìí ṣe wọn lonii, awọn eniyan Jehofa nran araawọn lọwọ lọna ti ara ni awọn akoko aini wọn sì ńní àjọṣe onífàájì papọ.