Dúró Sínú Ìfẹ́ Ọlọ́run!
“Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, . . . ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”—JÚÚDÀ 20, 21.
1, 2. Báwo lo ṣe lè dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
JÈHÓFÀ fẹ́ràn aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi fi Ọmọ bíbí kan ṣoṣo rẹ̀ fúnni káwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Ohun àgbàyanu mà ni pé Ọlọ́run ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí wa o! Bó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, ó dájú pé títí láé ni wàá fẹ́ kí Ọlọ́run ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ọ.
2 Ọmọ ẹ̀yìn náà, Júúdà sọ bó o ṣe lè dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 20, 21) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti wíwàásù ìhìn rere á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ìgbàgbọ́ “mímọ́ jù lọ,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni gbé ara rẹ ro. Kó o bàa lè dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà “pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́,” tàbí lábẹ́ agbára rẹ̀. Kó o bàa lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, o tún gbọ́dọ̀ fi hàn pó o nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.—1 Jòhánù 4:10.
3. Kí ló fà á táwọn kan kì í fi í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́?
3 Àwọn kan ti nígbàgbọ́ rí, àmọ́ wọn ò dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nítorí pé ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ ló wù wọ́n láti máa tọ̀. Kí lo lè ṣe tírú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Bó o bá ronú lórí àwọn kókó tá a fẹ́ jíròrò yìí, ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe gba ẹ̀ṣẹ̀ láàyè, kó o sì dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Fi Ìfẹ́ Tó O Ní fún Ọlọ́run Hàn
4. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run?
4 Fi ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣègbọràn sí i. (Mátíù 22:37) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Bó o bá ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa pa òfin Ọlọ́run mọ́, wàá lókun tí wàá fi dènà ìdẹwò ìyẹn á sì mú kó o láyọ̀. Onísáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, . . . ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà.”—Sáàmù 1:1, 2.
5. Kí ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á mú kó o ṣe?
5 Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á mú kó o sá fún dídẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, èyí tó máa kẹ́gàn bá orúkọ rẹ̀. Ágúrì gbàdúrà pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi, kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́, kí n sì wí pé: ‘Ta ni Jèhófà?’ kí n má sì di òtòṣì kí n sì jalè ní ti tòótọ́ kí n sì kọjú ìjà sí orúkọ Ọlọ́run mi.” (Òwe 30:1, 8, 9) Ìwọ náà pinnu pé o ò ní “kọjú ìjà sí orúkọ Ọlọ́run” nípa kíkó ẹ̀gàn bá a. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa sapá ní gbogbo ìgbà láti máa ṣe àwọn nǹkan tó tọ́, èyí táá máa fògo fún un.—Sáàmù 86:12.
6. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bó o bá mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀?
6 Máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà, Baba rẹ ọ̀run onífẹ̀ẹ́, pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa kó sínú ìdẹwò tó lè mú kó o dẹ́ṣẹ̀. (Mátíù 6:13; Róòmù 12:12) Má ṣe dẹ́kun títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run kí àdúrà rẹ má bàa ní ìdènà. (1 Pétérù 3:7) Bó o bá mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ wá ò ní dáa rárá. Ìdí ni pé ńṣe ni Jèhófà máa dí ọ̀nà táwọn ọlọ̀tẹ̀ lè bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí àdúrà wọn má bàa lè dé ibi tó wà, ṣe ló máa dà bíi pé ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ló fi dí i. (Ìdárò 3:42-44) Nítorí náà, fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kó o sì gbà á ládùúrà pé kí Ọlọ́run má ṣe jẹ́ kó o ṣe ohunkóhun tí ò ní jẹ́ kó o lè gbàdúrà sí i mọ́.—2 Kọ́ríńtì 13:7.
Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Ọmọ Ọlọ́run
7, 8. Báwo ni títẹ̀lé ìmọ̀ràn Jésù ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti má máa hùwà ẹ̀ṣẹ̀?
7 Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀, nítorí pé èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má máa hùwà ẹ̀ṣẹ̀. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:10) Báwo ni fífi ọ̀rọ̀ Jésù sílò ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
8 Fífiyè sí ọ̀rọ̀ Jésù lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà tó tọ́. Nínú Òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.” (Ẹ́kísódù 20:14) Àmọ́ Jésù jẹ́ ká rí ìlànà tó wà nínú òfin yẹn nípa sísọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:27, 28) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn kan nínú ìjọ ní ọ̀rúndún kìíní ní “ojú tí ó kún fún panṣágà,” wọ́n sì “ń ré àwọn ọkàn tí kò dúró sójú kan lọ.” (2 Pétérù 2:14) Àmọ́, dípò tí wàá fi máa fara wé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, o lè sá fún ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn lè tibi ìbálòpọ̀ dá bó o bá fẹ́ràn Ọlọ́run àti Kristi, tó ò ń ṣègbọràn sí wọn, tó o sì pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àárín ìwọ àtàwọn méjèèjì jẹ́.
Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Jèhófà Máa Darí Rẹ
9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kan bá tẹra mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá?
9 Máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì jẹ́ kó máa darí rẹ. (Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:19-25) Bó o bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run lè gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Lẹ́yìn tí Dáfídì ti dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé ó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó bẹ Ọlọ́run pé: “Má ṣe gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ; ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.” (Sáàmù 51:11) Àmọ́, nítorí pé Sọ́ọ̀lù Ọba jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, ó pàdánù ẹ̀mí Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ tí Sọ́ọ̀lù dá ni pé ó rú ẹbọ sísun, ó dá agbo ẹran tí Ọlọ́run ní kó pa run sí, ó sì dá ọba àwọn ará Ámálékì sí. Lẹ́yìn náà ni Jèhófà gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kúrò lára Sọ́ọ̀lù.—1 Sámúẹ́lì 13:1-14; 15:1-35; 16:14-23.
10. Kí ló dé tí ò fi yẹ kó o jẹ́ kó wá sínú ọkàn ẹ rárá láti máa hùwà ẹ̀ṣẹ̀?
10 Má ṣe jẹ́ kó wá sínú ọkàn ẹ rárá láti máa hùwà ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.” (Hébérù 10:26-31) Wo bó ṣe máa burú tó bó o bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ débi tó fi wá di àṣà ẹ!
Fi Ìfẹ́ Tòótọ́ Hàn Sáwọn Ẹlòmíràn
11, 12. Láwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ àti fífọwọ́ pàtàkì mú ètò ìgbéyàwó lè gbà mú kéèyàn má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe?
11 O ò ní ṣèṣekúṣe bó o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. (Mátíù 22:39) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ á mú kó o pa ọkàn rẹ mọ́ kó má bàa tàn ọ́ débi tí wàá fi máa fa ojú ọkọ ọlọ́kọ tàbí aya aláya mọ́ra. Torí pé bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè dẹ́ṣẹ̀ panṣágà. (Òwe 4:23; Jeremáyà 4:14; 17:9, 10) Fara wé Jóòbù tó jẹ́ adúróṣinṣin, tí kò tẹjú mọ́ obìnrin mìíràn yàtọ̀ sí ìyàwó rẹ̀.— Jóòbù 31:1.
12 Ètò mímọ́ ní ètò ìgbéyàwó, bó o bá fọwọ́ pàtàkì mú un, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti sá fún ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ìgbéyàwó tó lọ́lá àti ìbálòpọ̀ jẹ́ ọ̀nà táwọn èèyàn á lè gbà máa bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28) Má sì ṣe gbàgbé pé ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwàláàyè làwọn ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálòpọ̀ wà fún, ohun mímọ́ sì ni ìwàláàyè. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Ọlọ́run làwọn panṣágà àti àgbèrè ń ṣàìgbọràn sí, wọ́n ń tàbùkù sí ìbálòpọ̀, wọn ò sì fojú pàtàkì wo jíjẹ́ tí ètò ìgbéyàwó jẹ́ mímọ́, wọ́n ń ṣẹ̀ sí ara wọn. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Àmọ́, ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò ẹni tó fi mọ́ ìgbọràn sí Ọlọ́run ni kì í jẹ́ kéèyàn lọ́wọ́ nínú ìwà tó lè mú kí wọ́n yọni lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Kristẹni.
13. Lọ́nà wo ni oníṣekúṣe èèyàn gbà “ń pa àwọn ohun tí ó níye lórí run”?
13 Ó pọn dandan pé ká má ṣe gba èrò tí ń súnni dẹ́ṣẹ̀ láàyè ká má bàa kó ẹ̀dùn ọkàn bá tẹbí tará wa. Òwe 29:3 sọ pé: “Ẹni tí ń bá kárùwà kẹ́gbẹ́ ń pa àwọn ohun tí ó níye lórí run.” Ẹní bá ń ṣe panṣágà tí kò sì ronú pìwà dà ń ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sì ń tú ìdílé ká. Ìyàwó irú onípanṣágà bẹ́ẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Ì báà jẹ́ ọkọ tàbí aya ló ń hùwà àìtọ́, bí ìgbéyàwó wọn bá tú ká, ó lè fa ìrora ọkàn ńláǹlà fún èyí tára ẹ̀ mọ́ nínú àwọn méjèèjì, fáwọn ọmọ, àti fáwọn ẹlòmíì. Ǹjẹ́ o ò gbà pé bá a bá mọ bí ìpalára tí ìṣekúṣe lè fà ṣe pọ̀ tó, ó máa mú ká sá fóhun tó bá máa dẹ wá wò láti lọ́wọ́ nínú ẹ̀?
14. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa ìwà àìtọ́ nínú Òwe 6:30-35?
14 Nítorí a mọ̀ pé kò sí béèyàn tó dẹ́ṣẹ̀ panṣágà ṣe lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe, ó yẹ́ ká yẹra fún ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tó burú jáì yìí. Òwe 6:30-35 fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ṣì lè káàánú olè tó jí nǹkan nítorí pé ebi ń pa á, ńṣe ni wọ́n máa ń tẹ́ńbẹ́lú ẹní bá ṣe panṣágà nítorí pé èrò ọkàn rẹ̀ ò mọ́. Ńṣe ló “ń run ọkàn [tàbí, ìwàláàyè] ara rẹ̀.” Bó bá jẹ́ pé lábẹ́ Òfin Mósè ni, pípa ni wọn máa pa á. (Léfítíkù 20:10) Ẹní bá ṣe panṣágà ń kó ìrora ọkàn bá àwọn ẹlòmíràn kó bàa lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ni, bẹ́ẹ̀ sì rèé, onípanṣágà tí kò ronú pìwà dà ò lè dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run, nítorí náà yíyọ la ó yọ ọ́ nínú ìjọ Kristẹni mímọ́.
Máa Jẹ́ Kí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Mọ́
15. Kí ni ẹ̀rí ọkàn tá a sàmì sí “gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì” ò ní ṣe mọ́?
15 Tá ò bá fẹ́ kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀. Èyí fi hàn gbangba pé a ò gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìwàkíwà táráyé ń hù, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra bó bá dọ̀ràn irú àwọn tá a ó máa bá kẹ́gbẹ́, irú ìwé tá a ó máa kà àti irú eré ìnàjú tá a ó máa ṣe. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù, nípasẹ̀ àgàbàgebè àwọn ènìyàn tí ń purọ́, àwọn tí a ti sàmì sí inú ẹ̀rí-ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì.” (1 Tímótì 4:1, 2) Ẹ̀rí ọkàn tá a sàmì sí “gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì” dà bí ẹran ara tí iná jó, tó dápàá, tó sì ti yigbì. Irú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ ò tún ní kìlọ̀ fún wa mọ́ pé ká má ṣe bá àwọn apẹ̀yìndà da nǹkan pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sọ fún wa pé ká máà sún mọ́ ohunkóhun tó lè mú ká ṣubú kúrò nínú ìgbàgbọ́.
16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ pé kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́?
16 Ká tó lè rí ìgbàlà, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́. (1 Pétérù 3:21) Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀, a ti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ nínú àwọn òkú iṣẹ́, “kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè.” (Hébérù 9:13, 14) Bá a bá mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, a ó sọ ẹ̀rí ọkàn wa di ẹlẹ́gbin, a ò sì ní jẹ́ èèyàn mímọ́ tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run mọ́. (Títù 1:15) Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́.
Àwọn Ọ̀nà Míì Tá A Lè Gbà Sá fún Ìwà Àìtọ́
17. Àǹfààní wo ló wà nínú ‘títọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún’?
17 “Tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún,” bí Kálébù ti ṣe ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Diutarónómì 1:34-36) Máa ṣé ohun tí Ọlọ́run bá fẹ́ kó o ṣe, má sì ṣe ronú láé pé wàá jẹun lórí “tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Kọ́ríńtì 10:21) Má ṣe báwọn apẹ̀yìndà da ohunkóhun pọ̀. Máa fi ìmọrírì jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó jẹ́ pé orí tábìlì Jèhófà nìkan lèèyàn ti lè rí i, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn olùkọ́ èké tàbí àwọn ẹ̀mí búburú ò ní lè ṣì ẹ́ lọ́nà. (Éfésù 6:12; Júúdà 3, 4) Máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, bíi kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí ìpàdé àti kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ó dájú pé wàá láyọ̀ bó o bá ń tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún tó o sì ń ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
18. Ìwà wo ni ìbẹ̀rù Jèhófà á mú kó o máa hù?
18 Fi ṣe ìpinnu rẹ láti “ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.” (Hébérù 12:28) Bó o bá ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà, wàá lè kọ ìwà búburú èyíkéyìí sílẹ̀. Ó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí Pétérù fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Bí ẹ bá ń ké pe Baba tí ń ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ olúkúlùkù, ẹ hùwà pẹ̀lú ìbẹ̀rù nígbà tí ẹ ń ṣe àtìpó.”—1 Pétérù 1:17.
19. Kí nìdí tó fi yẹ kó máa fi àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ní gbogbo ìgbà?
19 Gbogbo ìgbà ni kó o máa fi àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe gba ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì láàyè nítorí pé wàá wà lára “àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Dípò tí wàá fi máa sọ ohunkóhun tó bá ṣáà ti bá ẹ lẹ́nu tàbí tí wàá fi máa hùwà tó bá ṣáà ti wù ẹ́, ṣe ni kó o máa ṣọ́ra kó o bàa lè máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọlọgbọ́n, kó o sì máa ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ láwọn ọjọ́ búburú wọ̀nyí. “Máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó.—Éfésù 5:15-17; 2 Pétérù 3:17.
20. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká gba ojúkòkòrò láàyè?
20 Má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ṣíṣe ojúkòkòrò sí nǹkan ẹlòmíràn. Ọ̀kan lára àwọn Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ, tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ tẹni ni Òfin yìí ń dáàbò bò, tó fi mọ́ ilé, ìyàwó, ìránṣẹ́, ẹranko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ojúkòkòrò máa ń sọni di ẹlẹ́gbin.—Máàkù 7:20-23.
21, 22. Àwọn ọ̀nà wo ni Kristẹni kan lè gbà dáàbò bo ara ẹ̀ kó má bàa dẹ́ṣẹ̀?
21 Wá ọ̀nà tó o lè gbà dáàbò bo ara ẹ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ má bàa sún ọ dẹ́ṣẹ̀. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ti ní ìṣòro ọtí mímu nígbà kan rí, ó lè pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí ọtí líle máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó òun tàbí kó máa wà nínú ilé òun. Kí Kristẹni kan má bàa fàyè gba ìdẹwò tó lè wáyé láàárín òun àti ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ, ó lè pọn dandan pé kó yí ààyè ẹ̀ níbi iṣẹ́ padà tàbí kó wá iṣẹ́ síbòmíì.—Òwe 6:23-28.
22 Má ṣe ṣe ohunkóhun táá sún ọ dé bèbè ẹ̀ṣẹ̀. Títage àti ríro èròkerò lọ́kàn lè yọrí sí panṣágà àti àgbèrè. Píparọ́ kéékèèké lè mú kẹ́nì kan gbójú gbóyà débi táá fi máa parọ́ ńlá, ìyẹn lè mú kó sọ irọ́ pípa dàṣà, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì nìyẹn jẹ́. Fífẹ́wọ́ lè mú kí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan yigbì débi táá kúkú fi bẹ̀rẹ̀ sí í jí nǹkan ńláńlá. Kódà, béèyàn bá ṣèèṣì gba èrò dídi apẹ̀yìndà láàyè pẹ́nrẹ́n, ó lè jẹ́ ìyẹn gan-an ló máa bá ẹni náà dórí dídi apẹ̀yìndà pátápátá.—Òwe 11:9; Ìṣípayá 21:8.
Bó O Bá Ti Dẹ́ṣẹ̀ Ńkọ́ O?
23, 24. Ìtùnú wo la lè rí látinú 2 Kíróníkà 6:29, 30 àti Òwe 28:13?
23 Gbogbo èèyàn ni aláìpé. (Oníwàásù 7:20) Àmọ́ bó o bá ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, o lè rí ìtùnú látinú àdúrà tí Sólómọ́nì Ọba gbà nígbà tó ń ya tẹ́ńpìlì Jèhófà sí mímọ́. Sólómọ́nì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Àdúrà yòówù, ìbéèrè fún ojú rere yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé olúkúlùkù wọn mọ ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀; nígbà tí ó bá tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ní tòótọ́ síhà ilé yìí, nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí o ń gbé, kí o sì dárí jì, kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn-àyà rẹ̀ (nítorí ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn-àyà ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú).”—2 Kíróníkà 6:29, 30.
24 Òótọ́ ni pé Ọlọ́run mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ó sì máa ń dárí jini. Òwe 28:13 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” Béèyàn bá ronú pìwà dà, tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tó sì kọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀, onítọ̀hún á rí àánú Ọlọ́run gbà. Síbẹ̀, bó o bá ti di aláìlera nípa tẹ̀mí, kí ló tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo là ṣe lè dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
• Báwo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti Kristi ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ dídá?
• Kí nìdí tí ojúlówó ìfẹ́ tá a ní sáwọn ẹlòmíì ò fi ní jẹ́ ká fẹ́ láti ṣèṣekúṣe?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà sá fún ìwà àìtọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Júúdà fi ọ̀nà tá a lè gbà dúró sínú ìfẹ́ Ọlọ́run hàn wá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bí ìgbéyàwó bá tú ká, ó lè fa ìrora ọkàn fún èyí tára ẹ̀ mọ́ nínú àwọn méjèèjì àti fáwọn ọmọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bíi ti Kálébù, ṣó o ti pinnu láti “tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Máa gbàdúrà déédéé pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe fàyè gba ìdẹwò