Aye Titun Kan Ti Sunmọle!
AWỌN aṣaaju oṣelu ti sọ ohun pupọ nipa eto aye titun kan ti o jẹ atọwọda tiwọn funraawọn. Wọn sọrọ nipa gbigba aye silẹ kuro lọwọ awọn ibẹru ati idena si ifọwọsowọpọ laaarin eniyan ati ijọba. Ṣugbọn awọn eniyan ni yoo ha pinnu lati mu aye titun kan wa bi?
Araye ti ni ọpọlọpọ ọrundun lati fidi aye alalaafia ati ailewu mulẹ. Laisi iyemeji, ọpọlọpọ ti jẹ ọlọkan rere gan an ninu iru awọn isapa bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, laika iru igbekalẹ ijọba ti awọn eniyan ro pe o le mu iru awọn ète bẹẹ ṣẹ, awọn ọrọ Bibeli naa ti jasi otitọ pe: “Ko si ni ipa eniyan ti nrin lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.”—Jeremaya 10:23.
A Ṣeleri Aye Titun Kan
Sibẹ, Ọrọ onimiisi Ọlọrun kan naa pese idaniloju pe aye titun kan yoo wà. Lẹhin sisọ asọtẹlẹ opin eto igbekalẹ awọn nǹkan ogbologbo, Kristian apọsteli Peteru polongo pe: “Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ, awa nreti awọn ọrun titun ati aye titun, ninu eyi ti ododo ngbe.”—2 Peteru 3:10-13.
Ileri ta ni eyi? Ohun ni a ko ṣe lati ọwọ elomiran ju Jehofa, “Ọga-ogo lori aye gbogbo.” (Saamu 83:18) Oun yoo ṣaṣepari ohun ti awọn eniyan ko le ṣe. Bẹẹni, Jehofa Ọlọrun yoo mu aye titun kan wá. Ṣugbọn nigba wo?
Aye Titun Kan Ti Wà Nitosi Gan an!
Saaju ki ileri aye titun ti Ọlọrun ṣeleri to di ẹkunrẹrẹ otitọ, “aye,” tabi “eto igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi, gbọdọ wa sopin rẹ. Nipa eyi, awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi beere pe: “Sọ fun wa, nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹ? Ki ni yoo si ṣe ami wiwa rẹ, ati ti opin aye?” (Matiu 24:3) Gẹgẹ bi New World Translation ti o ṣe rẹgi ju ṣe tumọ rẹ, awọn ọmọlẹhin Jesu beere pe: “Sọ fun wa, nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo jẹ́, ki ni yoo si ṣe ami wíwà níhìn-ín rẹ ati ti ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan?”
Ni ifesi pada, Jesu sọ asọtẹlẹ ọpọlọpọ awọn apa iha ami wíwà níhìn-ín rẹ ti a ko le foju ri gẹgẹ bi ẹni ẹmi kan ninu agbara Ijọba ti ọrun. (1 Peteru 3:18) Fun apẹẹrẹ, oun wipe: “Orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede ati ijọba si ijọba, aito ounjẹ yoo si wà ati isẹlẹ ni ibi kan tẹle omiran.” Lati “ibẹrẹ awọn irora hílàhílo” ni 1914, “iran yii” ti Jesu tọka si ti niriiri ija ogun, aito ounjẹ, ati awọn isẹlẹ ti nbaa lọ gẹgẹ bi apakan ami wíwà níhìn-ín alaiṣee fojuri rẹ̀.—Matiu 24:7, 8, 34, NW.
Ija ogun ti rọgba yi iran yii ká ni ọna ti ko lẹgbẹ lati ọdun 1914. Ogun Agbaye Kìn-ínní gba ifojudiwọn 14 million ẹmi. Lakooko Ogun Agbaye Keji, 55 million awọn jagunjagun ati ara ilu ni a pa. Họwu, lati 1914 iye ẹmi ti o ju 100 million ni a ti padanu ninu ogun! Dajudaju, eyi jẹ apakan ami wíwà níhìn-ín Jesu.
Aito ounjẹ, ti Jesu tun sọ asọtẹlẹ rẹ, pa ọpọlọpọ ilẹ run lẹhin ọkọọkan awọn ogun agbaye mejeeji. Laika awọn itẹsiwaju ti imọ ijinlẹ si, ohun ti o sunmọ idamẹrin awọn eniyan ni gbogbo aye ni ebi npa lonii. Lọdọọdun, araadọta ọkẹ awọn ọmọ ati awọn miiran nku nitori aijẹun-unre kánú. The World Book Encyclopedia wi pe: “Ọpọjulọ awọn orilẹ-ede ti ngoke agba ti Africa, Asia, ati Latin America ko ni ounjẹ ti o tó fun awọn eniyan wọn. Araadọta ọkẹ ninu awọn orilẹ-ede wọnyi ni ebi npa. Nigba ti ipese tabi ikowọle ounjẹ ba lọ silẹ fun idi eyikeyi, iyan le bẹ́ silẹ tí ẹgbẹẹgbẹrun tabi araadọta ọkẹ awọn eniyan si le ku.”
Awọn isẹlẹ ti fa ipadanu awọn ẹmi ninu iran yii ni sisami si “igba ikẹhin.” (Daniẹli 12:4) Ifojudiwọn awọn ti o ku ninu isẹlẹ yatọ sira. Ṣugbọn lati 1914 iparun nipasẹ isẹlẹ ti ga fiofio jakejado ilẹ-aye, iwọn yii si ti gba ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun ẹmi. Ni sisọrọ lori meji pere ninu awọn wọnyi, Yorkshire Post ti October 19, 1989, wi pe: “Ni 1920 isẹlẹ kan ni ẹkun Jiangsu ti China pa 180,000, ati ni July 28, 1976, China jiya isẹlẹ ti o buru ju ninu itan ode oni rẹ. O keretan 240,000 ku nigba ti isẹlẹ ti o wọn 7.8 lori iwọn Richter ti a ko dèmọ́lẹ̀ pinpin fẹrẹẹ sọ ilu Tangshan ariwa iha ila-oorun di pẹrẹsẹ.” Iwe irohin naa ṣakọsilẹ iye ti o ju 30 awọn isẹlẹ ṣiṣekoko miiran ni ọgọrun un ọdun lọna ogun.
Igbokegbodo iwaasu Ijọba ni a tun sọtẹlẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn apa oke ami wíwà níhìn-ín alaiṣee fojuri ti Jesu. O sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ ti wọn nṣewadii pe: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si de.” (Matiu 24:14) Gẹgẹbi Jesu ti sọ tẹlẹ, iṣẹ iwaasu yii ni a nba lọ yika ilẹ-aye ni ilẹ 212 nipasẹ iye ti o ju 4,000,000 awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Awọn imuṣẹ iwọnyi ati awọn asọtẹlẹ miiran lode oni fi ẹri han pe a ngbe ni “ikẹhin ọjọ.” (2 Timoti 3:1-5) Niwaju wa ti ko jinna mọ gan an ni “ipọnju nla” ti a tun sọtẹlẹ lati ẹnu Jesu Kristi. Eyi yoo de opin ní “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ni Amagẹdọn, yoo mu opin wa si ori eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu isinsinyi. (Matiu 24:21; Iṣipaya 16:14-16) Nigba naa ileri aye titun Ọlọrun yoo wa di otitọ gan an.a
Awọn Ibukun Ti Eniyan Ko Le Mu Wa
Awọn aṣaaju oṣelu fọ́nnu nipa eto aye titun kan ti o jẹ atọwọda tiwọn funraawọn. Ṣugbọn Jehofa, Ọlọrun ọrun oun ilẹ-aye, ko sọ fun eniyan rí lati fi aye titun kan rọpo eto igbekalẹ isinsinyi. Oun funraarẹ yoo ṣe iyẹn ni ọjọ ati wakati ti oun nikan ṣoṣo mọ. (Matiu 24:34, 36) Apọsteli Johanu ọlọjọ lori ti ri aritẹlẹ ohun yii ti Ọlọrun, kii ṣe eniyan, yoo ṣe:
“Mo si ri ọrun titun ati aye titun kan: nitori pe ọrun ti iṣaaju ati aye iṣaaju ti kọja lọ; okun ko sì sí mọ. Mo si ri ilu mimọ nì, Jerusalẹmu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọọ fun ọkọ rẹ. Mo si gbọ ohùn ńlá kan lati ori itẹ ni wa, nwipe, kiyesi i, agọ Ọlọrun wa pẹlu awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ eniyan rẹ, ati Ọlọrun tikaraarẹ yoo wa pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo sì sí iku mọ, tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ: nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ. Ẹni ti o jokoo lori itẹ nì sì wipe, kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtun. O si wí fun mi pe, kọwe rẹ: nitori ọrọ wọnyi ododo ati otitọ ni wọn.”—Iṣipaya 21:1-5.
“Ọrun titun” jẹ Ijọba ọrun ti Jesu Kristi. “Aye titun” kii ṣe àgbáálá aye miiran ṣugbọn o jẹ awujọ titun ti awọn eniyan lori planẹti yii—ti gbogbo wọn jẹ ọmọ abẹ́ onigbọran ti Ijọba Kristi, laisi iyapa niti ẹya iran, ti orilẹ-ede, tabi ti ede. (Fiwe Saamu 96:1.) Ọrun ati ilẹ-aye iṣapẹẹrẹ isinsinyi—eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Eṣu pẹlu igbekalẹ ti ijọba rẹ tí Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ nipa lé lori—ni a o ti parun. (1 Johanu 5:19) Bi o tilẹ jẹ pe awọn òkun gidi yoo ṣì wà, òkun afiṣapẹẹrẹ alaifararọ, araye buburu yoo kuro. Awọn alajumọ ṣakoso pẹlu Jesu ni ọrun parapọ di Jerusalẹmu Titun ati ni isopọ pẹlu rẹ di olu-ilu eto-ajọ ti yoo ṣakoso awujọ eniyan olododo. Ọlọrun yoo ‘pagọ pẹlu’ araye onigbọran lọna apẹẹrẹ nigba ti a nmu wọn laja ni kikun pẹlu rẹ nipasẹ Kristi laaarin Ọjọ Idajọ ẹlẹgbẹrun ọdun naa.—Iṣipaya 14:1-4; 20:6.
Labẹ iṣakoso Ijọba ọpọlọpọ idi ni yoo wa fun ayọ. Ọ̀fọ̀, ẹkun, ati irora ti o njẹ jade lati inu amodi, ẹdun ọkan, ati awọn nǹkan bẹẹ yoo jẹ iriiri ti o ti kọja. Ani iku paapaa ti o tàn kalẹ de ọdọ araye lati ọdọ obi wa akọkọ, Adamu ẹlẹṣẹ, ki yoo si mọ. (Roomu 5:12) Ẹ wo iru ayọ ti yoo gbodekan nigba ti awọn ohun ti nfa omije yika aye ba di ohun ti ko si mọ titilae!
Kii ṣe awọn eniyan ti o le ku ṣugbọn Ọlọrun funraarẹ ni o funni ni ẹri idaniloju nipa awọn ibukun wọnyi. Oun ni Ẹni naa ti o wi pe: “Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtun.” Bẹẹni, Jehofa Ọlọrun si sọ fun apọsteli Johanu pe: “Kọwe rẹ: nitori ọrọ wọnyi ododo ati otitọ ni wọn.”
Awọn Aini Ṣiṣekoko Ni A Tẹ́ Lọrun
Ninu aye titun ti Ọlọrun ṣe, ilẹ-aye yoo di paradise nikẹhin. Eyi daju, nitori Jesu ṣeleri fun oluṣebuburu onirobinujẹ kan ti a kan mọgi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pe: “Lootọ ni mo sọ fun ọ lonii, iwọ yoo pẹlu mi ni paradise.” (Luuku 23:43, NW) Laaarin awọn ipo ti paradise, iru awọn aini eniyan gẹgẹ bi ounjẹ ati ibugbe ni a o pese ni kikun.
Aito ounjẹ ngba araadọta ọkẹ ẹmi lonii. Bi o ti wu ki awọn isapa lati fi ounjẹ bọ́ awọn ti ebi npa ti le yẹ fun igboriyin tó, iwọra ati awọn okunfa miiran dí awọn eniyan lọwọ lati ma lè yanju iru awọn iṣoro bẹẹ. Fun apẹẹrẹ, Saturday Star, iwe irohin Johannesburg kan, ni South Africa, rohin pe: “Awọn ariyanjiyan oṣelu, owo epo tí npọ sii ati àárẹ̀ gbogbogboo pẹlu awọn iforigbari ni Africa ti o jọ bi ẹni pe ko lopin nparapọ lati fa ọwọ itura alaafia sẹhin . . . Ni Sudan, ọkan lara awọn orilẹ-ede ti iyan kọ lù julọ, laaarin 5 million si 6 million awọn eniyan dojukọ àìróúnjẹ jẹ ni 1991.” Ṣugbọn iyan ni a o gbagbe ninu aye titun Ọlọrun. Labẹ iṣakoso Ijọba “ikunwọ ọka ni yoo maa wà lori ilẹ; lori awọn oke nla ni eso rẹ yoo maa mì.”—Saamu 72:16.
Ibugbe ni aini eniyan miiran ti o jinna si eyi ti a npese lọna ti o tó fun ọpọlọpọ ni ọjọ wa. Araadọta ọkẹ ngbe ninu ile àlàpà tabi ki wọn tilẹ jẹ alainile lori rara. Gẹgẹ bi The New York Times ti wi, ni ilẹ Gabasi kan, “ni ile iṣẹ awọn ẹ̀rọ onina manamana . . . , awọn ẹni agbàsíṣẹ́ ọlọjọ ori 20 dojukọ títò fun 73 ọdun ki won tó lè rílé,” irohin ijọba kan si fihan pe awọn eniyan kan gbọdọ gbe “ninu awọn ile ẹrù, ọfiisi tabi ile igbọnsẹ paapaa.” Ṣugbọn ẹ wo bi eyi yoo ṣe yatọ tó ninu aye titun! Ninu Paradise ọjọ ọla, “wọn o sì kọ́ ilé, wọn o sì gbé inú wọn; wọn o sì gbin ọgbà àjàrà, wọn o sì jẹ eso wọn. Wọn ki yoo kọ́ ile fun ẹlomiran gbé, wọn ki yoo gbin fun ẹlomiran jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi ni ọjọ awọn eniyan mi rí, awọn ayanfẹ mi yoo si jifa iṣẹ ọwọ wọn.”—Aisaya 65:21, 22.
Awọn iṣoro ibugbe awọn ohun alaaye yoo pòórá ninu aye titun ti Ọlọrun ṣeleri. Ibajẹ afẹfẹ ti nhalẹ mọ ilera ti o si nba irugbin jẹ́ ki yoo si mọ́. Ibajẹ ati iparun ibugbe awọn ohun alaaye ti nfi ọgọọrọ awọn iru eweko ati ẹranko sinu ewu ki yoo jẹ ihalẹ kankan nigba naa. Iru awọn okunfa gẹgẹ bi ìpòórá ibori afẹfẹ ozone ki yoo fa iṣoro fun iwalaaye lori ilẹ-aye. A le ni idaniloju pe Jehofa Ọlọrun yoo yanju gbogbo iṣoro wọnyi, nitori Ọrọ rẹ mu un dá wa loju pe laipẹ oun yoo “run awọn ti npa aye run.”—Iṣipaya 11:18.
Ninu aye titun naa, ija ogun pẹlu yoo jẹ́ ohun atijọ ṣugbọn kii ṣe nitori pe awọn aṣaaju oṣelu ti ṣaṣeyọri ninu gbigba awọn ohun ija ogun kuro lọwọ awọn orilẹ-ede. Kaka bẹẹ, Ọlọrun yoo gbegbeesẹ nibi ti awọn oluṣakoso oṣelu ti kuna. Oun yoo mu alaafia wa fun araye onigbọran ni pipa awọn ọrọ wọnyi ti onisaamu naa mọ pe: “Ẹ wa wo awọn iṣẹ Oluwa [“Jehofa,” NW], iru ahoro ti o ṣe ni aye. O mu ọ̀tẹ̀ tán de opin aye; o sẹ́ ọrun, o si ké ọkọ meji; o si fi kẹkẹ ogun jona.” (Saamu 46:8, 9) Ninu aye titun ti Ọlọrun ṣeleri ti o ti sunmọle gan an, awọn eniyan ki yoo ja ogun mọ ṣugbọn wọn yoo gbadun alaafia ati ailewu tootọ.—Mika 4:2-4.
Iwọ Yoo Ha Wà Nibẹ Bi?
Iwọ le ni igbọkanle ninu aye titun ti Jehofa Ọlọrun ṣeleri. Oun kò ṣèké. (Heberu 6:17, 18) Ọrọ rẹ, Bibeli, jẹ otitọ, ohun ti o si ṣeleri maa nṣẹlẹ nigba gbogbo.—Johanu 17:17.
Ihinrere awọn ibukun agbayanu fun araye onigbọran ni ohun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nsapa lati ṣajọpin pẹlu gbogbo awọn eniyan alailabosi ọkan. Iwọ nilati sapa nisinsinyi lati gba imọ ete atọrunwa naa, ki o si gbegbeesẹ lori awọn ileri agbayanu ti a ri ninu Iwe mimọ. Ipa-ọna yii le ṣamọna si iye ti ko lopin, nitori Jesu wipe: “Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o le mọ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ ran.” (Johanu 17:3) Nigba naa iwọ yoo lanfaani lati gbadun akooko alayọ ti o wà niwaju gan an, nitori aye titun Ọlọrun ti sunmọle!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ori 17 ati 18 iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, ti a tẹ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.