Ẹgbẹ́ Àlùfáà Aládé Tó Máa Ṣe Gbogbo Aráyé Láǹfààní
“Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.’”—1 PÉT. 2:9.
1. Kí nìdí tá a tún fi ń pe “oúnjẹ alẹ́ Olúwa” ní Ìrántí Ikú Kristi, kí ló sì wà fún?
NÍ ÌRỌ̀LẸ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ti àwọn Júù, èyí tó bá wọn ṣe kẹ́yìn. Lẹ́yìn tí Jésù ti ní kí Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ máa lọ, ó dá ohun ìrántí míì sílẹ̀, èyí tí Bíbélì wá pè ní “oúnjẹ alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 11:20) Ìgbà méjì ni Jésù sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Torí náà, a tún mọ̀ ọ́n sí Ìrántí Ikú Kristi. (1 Kọ́r. 11:24, 25) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé máa ń pa àṣẹ yìí mọ́ nípa ṣíṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. Ní ọdún 2012, Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àwọn Júù, máa bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ Thursday, April 5.
2. Kí ni Jésù sọ nípa búrẹ́dì àti wáìnì tó lò?
2 Nínú Lúùkù 22:19, 20, Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ ohun tí Jésù ṣe àti ohun tó sọ nígbà tó dá Ìrántí Ikú Kristi sílẹ̀. Ó ní: “Ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Àti ife pẹ̀lú, lọ́nà kan náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: ‘Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.’” Òye wo ni àwọn àpọ́sítélì ní nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí?
3. Òye wo ni àwọn àpọ́sítélì ní nípa búrẹ́dì àti wáìnì?
3 Torí pé Júù ni àwọn àpọ́sítélì, wọ́n mọ̀ nípa àwọn ẹbọ tí àwọn àlùfáà máa ń fi ẹran rú sí Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń mú irú àwọn ọrẹ ẹbọ bẹ́ẹ̀ wá fún Jèhófà kí wọ́n lè rí ojúure rẹ̀, wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹbọ náà tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. (Léf. 1:4; 22:17-29) Torí náà, nígbà tí Jésù sọ pé òun máa ‘fi ara òun fún wọn àti pé wọ́n máa tú ẹ̀jẹ̀ òun jáde nítorí wọn,’ ó yé àwọn àpọ́sítélì pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé ó máa fi ìwàláàyè pípé rẹ̀ rúbọ. Ó máa jẹ́ ẹbọ tó níye lórí gan-an ju ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú.
4. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi”?
4 Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi”? Àwọn àpọ́sítélì mọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun tó wà nínú Jeremáyà 31:31-33. (Kà á.) Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé ńṣe ló ń dá májẹ̀mú tuntun yẹn sílẹ̀, èyí tó máa rọ́pò májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá nípasẹ̀ Mósè. Ṣé májẹ̀mú méjèèjì náà jọra?
5. Àǹfààní wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nínú májẹ̀mú Òfin?
5 Kò sí àní-àní pé ohun tí májẹ̀mú méjèèjì wà fún jọra. Nígbà tí Jèhófà ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin, ó sọ fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi. Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.” (Ẹ́kís. 19:5, 6) Òye wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nípa àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
ÌLÉRÍ TÍ ỌLỌ́RUN ṢE NÍPA ẸGBẸ́ ÀLÙFÁÀ ALÁDÉ
6. Ìlérí Ọlọ́run wo ló ní ìmúṣẹ nípasẹ̀ májẹ̀mú Òfin?
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí “májẹ̀mú” túmọ̀ sí, torí pé Jèhófà ti bá àwọn baba ńlá wọn bíi Nóà àti Ábúráhámù ṣe irú àwọn àdéhùn pàtàkì bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 6:18; 9:8-17; 15:18; 17:1-9) Gẹ́gẹ́ bí ara májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá, Ó ṣèlérí fún un pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́n. 22:18) Kí ìlérí yìí bàa lè ní ìmúṣẹ ni Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin. Májẹ̀mú yìí lè wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di “àkànṣe dúkìá” fún Jèhófà “nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” Kí nìdí? Kí wọ́n bàa lè di “ìjọba àwọn àlùfáà” fún Jèhófà.
7. Kí ni “ìjọba àwọn àlùfáà” túmọ̀ sí?
7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ àwọn ọba àti àwọn àlùfáà dáadáa, àmọ́ Melikisédékì nìkan ni ẹni tí Jèhófà yọ̀ǹda fún látijọ́ pé kó jẹ́ ọba àti àlùfáà lẹ́ẹ̀kan náà. (Jẹ́n. 14:18) Jèhófà wá fún orílẹ̀-èdè náà ní àǹfààní láti pèsè “ìjọba àwọn àlùfáà.” Bí àwọn àkọ́sílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí lẹ́yìn náà ṣe fi hàn, èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti pèsè ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, ìyẹn ni àwọn ọba tí wọ́n tún máa jẹ́ àlùfáà.—1 Pét. 2:9.
8. Àwọn iṣẹ́ wo ni àwọn àlùfáà tí Ọlọ́run yàn máa ń ṣe?
8 Ọba ló máa ń ṣàkóso. Àmọ́ kí ni iṣẹ́ àlùfáà? Ìwé Hébérù 5:1 ṣàlàyé pé: “Olúkúlùkù àlùfáà àgbà tí a mú láàárín àwọn ènìyàn ni a yàn sípò nítorí ènìyàn lórí àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run, kí ó lè fi àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ohun ẹbọ rúbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” Torí náà, ńṣe ni àlùfáà tí Jèhófà yàn máa ń ṣojú fún àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Ó máa ń bá wọn tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa rírú àwọn ẹbọ tí Ọlọ́run pa láṣẹ. Bákan náà, àlùfáà máa ń ṣojú fún Jèhófà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, ó máa ń kọ́ wọn ní òfin Ọlọ́run. (Léf. 10:8-11; Mál. 2:7) Láwọn ọ̀nà yìí, iṣẹ́ àlùfáà tí Ọlọ́run yàn ni pé kó mú àwọn èèyàn pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.
9. (a) Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣe kí wọ́n bàa lè di “ìjọba àwọn àlùfáà”? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sípò gẹ́gẹ́ bí àlùfáà? (d) Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi di “ìjọba àwọn àlùfáà” lábẹ́ májẹ̀mú Òfin?
9 Májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá mú kí wọ́n ní àǹfààní láti di ẹgbẹ́ àlùfáà aládé tó máa ṣe “gbogbo àwọn ènìyàn yòókù” láǹfààní. Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣe ohun kan kí ọwọ́ wọn tó lè tẹ àǹfààní àgbàyanu yìí. Ọlọ́run sọ pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi.” Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ‘ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn Jèhófà’? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Ǹjẹ́ wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìkù síbì kan? Rárá o. (Róòmù 3:19, 20) Nítorí èyí ni Jèhófà ṣe yan àwọn kan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà yẹn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Ojúṣe wọn yàtọ̀ sí ti ọba, ńṣe ni wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Léf. 4:1–6:7) Èyí kan ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn àlùfáà fúnra wọn bá dá. (Héb. 5:1-3; 8:3) Jèhófà tẹ́wọ́ gba irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọn kò lè mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn tó rúbọ náà dá kúrò. Àwọn àlùfáà tó wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin kò lè mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ pàápàá pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ láìkù síbì kan. Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” (Héb. 10:1-4) Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rú Òfin, ńṣe ni wọ́n wá sábẹ́ ègún. (Gál. 3:10) Ní irú ipò tí wọ́n wà yẹn, wọn kò lè jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà aládé fún aráyé.
10. Kí nìdí tí Jèhófà fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin?
10 Ṣé èyí wá mú kí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè di “ìjọba àwọn àlùfáà” já sí asán? Rárá o. Bí wọ́n bá sapá tọkàntọkàn láti ṣègbọràn, wọ́n á ní àǹfààní yìí, àmọ́ kì í ṣe lábẹ́ Òfin. Kí nìdí? (Ka Gálátíà 3:19-25.) Àwọn tó ń sapá láti pa Òfin mọ́ tọkàntọkàn mọ̀ pé Òfin kì í jẹ́ kí ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin. Ó jẹ́ kí àwọn Júù mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn àti pé àwọn nílò ẹbọ kan tó ju èyí tí àlùfáà àgbà wọn lè rú. Ó jẹ́ akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa sìn wọ́n lọ sọ́dọ̀ Kristi tàbí Mèsáyà, tó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró.” Àmọ́ nígbà tí Mèsáyà bá dé, ó máa bá wọn dá májẹ̀mú tuntun tí Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn tó gba Kristi ni Ọlọ́run pè láti wọnú májẹ̀mú tuntun náà, wọn yóò sì di “ìjọba àwọn àlùfáà.” Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa rí bẹ́ẹ̀.
ÀWỌN TÓ WÀ NÍNÚ MÁJẸ̀MÚ TUNTUN DI ẸGBẸ́ ÀLÙFÁÀ ALÁDÉ
11. Báwo ni Jésù ṣe di ìpìlẹ̀ fún ẹgbẹ́ àlùfáà aládé?
11 Ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù ará Násárétì di Mèsáyà. Ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ni Jésù nígbà tó ṣe ìrìbọmi. Èyí sì fi hàn pé ó ti ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe. Jèhófà fi hàn pé ọmọ òun ni lóòótọ́ nígbà tó sọ pé, “Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ó sì sọ ọ́ di ẹni àmì òróró nípa fífi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yàn án. (Mát. 3:13-17; Ìṣe 10:38) Bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí yan Jésù yìí mú kó di Àlùfáà Àgbà àti Ọba lọ́la fún gbogbo èèyàn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Héb. 1:8, 9; 5:5, 6) Òun gan-an ló máa jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ẹgbẹ́ àlùfáà aládé.
12. Kí ni ẹbọ Jésù mú kó ṣeé ṣe?
12 Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, ẹbọ wo ni Jésù lè rú tó máa ṣe àfọ̀mọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ti jogún? Bí Jésù ṣe sọ nígbà tó ń dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, ìwàláàyè pípé tirẹ̀ fúnra rẹ̀ ló fi rú ẹbọ náà. (Ka Hébérù 9:11, 12.) Láti ìgbà tí Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ti ṣe ìrìbọmi ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni títí di ìgbà ikú rẹ̀, ó gbà kí a dán òun wò, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tó jìyà rẹ̀. (Héb. 4:15; 5:7-10) Lẹ́yìn tó jíǹde, ó gòkè re ọ̀run ó sì gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ fún Jèhófà. (Héb. 9:24) Láti ìgbà náà wá, Jésù lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nítorí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà, kó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa sin Ọlọ́run kí wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Héb. 7:25) Ẹbọ tí Jésù rú náà tún fìdí májẹ̀mú tuntun múlẹ̀.—Héb. 8:6; 9:15.
13. Ìrètí wo ni àwọn tí Ọlọ́run pè láti wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ní?
13 Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn tó pè láti wà nínú májẹ̀mú tuntun náà. (2 Kọ́r. 1:21) Àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ wà lára wọn, lẹ́yìn náà Ọlọ́run fún àwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní àǹfààní náà. (Éfé. 3:5, 6) Ìrètí wo ni àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ní? Wọ́n máa rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà pátápátá. Jèhófà ti ṣèlérí pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jer. 31:34) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti wọ́gi lé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ́nà tó bá òfin mu, wọ́n máa lè di “ìjọba àwọn àlùfáà.” Nígbà tí Pétérù ń bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sọ̀rọ̀, ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tó ń fún wọn ní Òfin ni Pétérù lò níbí yìí, ó wá sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kan àwọn Kristẹni tó wà nínú májẹ̀mú tuntun.—Ẹ́kís. 19:5, 6.
ẸGBẸ́ ÀLÙFÁÀ ALÁDÉ TÓ ṢE GBOGBO ARÁYÉ LÁǸFÀÀNÍ
14. Ibo ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn?
14 Ibo ni àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun ti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn? Orí ilẹ̀ ayé ni wọ́n ti máa kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, wọ́n máa sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, wọ́n á máa ṣojú fún Jèhófà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn nípa ‘pípolongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá rẹ̀’ àti nípa pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí. (Mát. 24:45; 1 Pét. 2:4, 5) Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde wọn, wọ́n máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ojúṣe méjèèjì ní kíkún. (Lúùkù 22:29; 1 Pét. 1:3-5; Ìṣí. 1:6) Ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí mú kí èyí túbọ̀ dá wa lójú. Nínú ìran náà ó rí ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí nítòsí ìtẹ́ Jèhófà lókè ọ̀run. Nínú “orin tuntun kan” tí wọ́n kọ fún “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” wọ́n wí pé: “O sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣí. 5:8-10) Nínú ìran mìíràn tí Jòhánù rí, ó sọ nípa àwọn tó máa ṣàkóso wọ̀nyí pé: “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣí. 20:6) Gbogbo wọn àti Kristi máa para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà aládé tó máa ṣe aráyé láǹfààní.
15, 16. Báwo ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ṣe máa ṣe aráyé láǹfààní?
15 Báwo ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ṣe máa ṣe àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé láǹfààní? Ìwé Ìṣípayá orí 21 ṣàpèjúwe wọn bí ìlú kan ní ọ̀run, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí Bíbélì pè ní “aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣí. 21:9) Ẹsẹ 2 sí 4 sọ pé: “Mo rí ìlú ńlá mímọ́ náà pẹ̀lú, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’” Ìbùkún àgbàyanu mà lèyí o! Ọlọ́run máa mú ikú tó sábà máa ń fa omijé, ọ̀fọ̀, igbe ẹkún àti ìrora kúrò. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ máa di pípé, a ó sì mú wọn pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ pátápátá.
16 Nígbà tí ìwé Ìṣípayá 22:1, 2, ń ṣàlàyé síwájú sí i nípa àwọn ìbùkún tí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé náà máa mú wá, ó sọ pé: “Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mí, tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wá sí ìsàlẹ̀ gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ [Jerúsálẹ́mù Tuntun]. Àwọn igi ìyè tí ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde sì wà níhà ìhín odò náà àti níhà ọ̀hún, tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” Ìran tí Jòhánù rí yìí fi hàn pé àìpé tí “àwọn orílẹ̀-èdè” tàbí àwùjọ ìdílé aráyé ti jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ni a ó ṣe àwòtán rẹ̀ pátápátá. Ní tòótọ́ ‘àwọn ohun àtijọ́ á ti kọjá lọ.’
ẸGBẸ́ ÀLÙFÁÀ ALÁDÉ PARÍ IṢẸ́ RẸ̀
17. Kí ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé á ti ṣe láṣeyọrí ní òpin ẹgbẹ́rùn ọdún?
17 Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún tí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n á ti mú kí gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé di pípé. Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà àti Ọba á wá fa ìdílé aráyé tó ti di pípé yìí lé Jèhófà lọ́wọ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:22-26.) Nípa báyìí, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé náà á ti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láṣeyọrí.
18. Lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé bá ti parí iṣẹ́ wọn, báwo ni Jèhófà ṣe máa lo àwọn tó ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú Kristi yìí?
18 Lẹ́yìn náà, báwo ni Jèhófà ṣe máa lo àwọn tó ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti bá Kristi ṣiṣẹ́ pa pọ̀ yìí? Ìwé Ìṣípayá 22:5 sọ pé, “wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” Àwọn wo ni wọ́n máa ṣàkóso lé lórí? Bíbélì kò sọ. Àmọ́ irú ìwàláàyè tí wọ́n ní àti ìrírí tí wọ́n ti ní látàrí bí wọ́n ṣe ran àwọn èèyàn aláìpé lọ́wọ́ máa jẹ́ kí wọ́n lè kó ipa pàtàkì gẹ́gẹ́ bí ọba, Jèhófà á sì lò wọ́n láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ títí láé.
19. Kí la máa rán àwọn tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi létí?
19 Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí máa wọ̀ wá lọ́kàn tá a bá pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọjọ́ Thursday, April 5, ọdún 2012. Àwọn kéréje tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa jẹ búrẹ́dì aláìwú, wọ́n á sì mu wáìnì pupa, èyí tó fi hàn pé wọ́n wà nínú májẹ̀mú tuntun náà. Búrẹ́dì àti wáìnì tó ṣàpẹẹrẹ ẹbọ tí Kristi rú yìí máa rán wọn létí àwọn àǹfààní àgbàyanu tí wọ́n ní àti ojúṣe wọn nínú ète ayérayé Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí nítorí ìmọrírì àtọkànwá tá a ní fún ẹgbẹ́ àlùfáà aládé tí Jèhófà Ọlọ́run ti yàn láti ṣe gbogbo aráyé láǹfààní.
ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?
․․․․․
Ìgbà wo ni Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣèlérí pé ẹgbẹ́ àlùfáà aládé máa wà?
․․․․․
Báwo ni àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun ṣe di ẹgbẹ́ àlùfáà aládé?
․․․․․
Báwo ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ṣe máa ṣe aráyé láǹfààní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ẹgbẹ́ àlùfáà aládé máa ṣe aráyé láǹfààní títí láé