Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣípayá—Apá Kejì
KÍ LÓ ń bẹ ní iwájú fáwọn olùjọsìn Jèhófà Ọlọ́run, kí ló sì ń bọ̀ wá sórí àwọn tí kò sìn ín? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù lọ́jọ́ iwájú? Àwọn ìbùkún wo làwọn ọmọ aráyé tó bá jẹ́ onígbọràn máa rí gbà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi? A rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì mìíràn nínú Ìṣípayá 13:1–22:21.a Inú àwọn orí ìwé Ìṣípayá yìí la ti rí ìran mẹ́sàn-án tó gbẹ́yìn lára ìran mẹ́rìndínlógún tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nígbà tí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ń parí lọ.
Jòhánù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́.” (Ìṣí. 1:3; 22:7) Tá a bá ń ka ìwé Ìṣípayá tá a sì ń fi ẹ̀kọ́ tá a kọ́ níbẹ̀ sílò, yóò mú ká máa fi ọkàn tó dára sin Ọlọ́run, yóò mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ lágbára, yóò sì mú kó dá wa lójú pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dára.b—Héb. 4:12.
WỌ́N DA ÀWOKÒTÒ MÉJE ÌBÍNÚ ỌLỌ́RUN JÁDE
Ìṣípayá 11:18 sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú [Ọlọ́run] sì dé, àti àkókò tí a yàn kalẹ̀ . . . láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Ìran kẹjọ jẹ́ ká rí ìdí tí ìrunú Ọlọ́run yìí fi dé, ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbòkègbodò “ẹranko ẹhànnà kan tí . . . ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje.”—Ìṣí. 13:1.
Nínú ìran kẹsàn-án, Jòhánù rí i tí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì,” àwọn “ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì” sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn tí “a rà lára aráyé.” (Ìṣí. 14:1, 4) Ìkéde látẹnu awọn áńgẹ́lì ló tẹ̀ lé èyí. Nínú ìran kẹwàá, Jòhánù rí “áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu àjàkálẹ̀ méje.” Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ pé káwọn áńgẹ́lì yìí da “àwokòtò méje ìbínú Ọlọ́run” sórí onírúurú ẹ̀ka tí ayé Sátánì pín sí. Ìpolongo àti ìkìlọ̀ nípa àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run yóò ṣe ló wà nínú àwọn àwokòtò náà. (Ìṣí. 15:1; 16:1) Ìran kẹsàn-án àti ìkẹwàá yìí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ìdájọ́ míì tí Ìjọba Ọlọ́run tún máa ṣe, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ègbé kẹta àti fífun kàkàkí keje.—Ìṣí. 11:14, 15.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
13:8—Kí ni “àkájọ ìwé ìyè ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà? Àkájọ ìwé ìṣàpẹẹrẹ ni, orúkọ àwọn tó máa bá Jésù Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run nìkan ló sì wà nínú rẹ̀. Orúkọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n ń retí àtigba ìyè ti ọ̀run, àmọ́ tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, náà wà níbẹ̀.
13:11-13—Báwo ni ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà ṣe ń ṣe bíi dírágónì tó sì tún ń mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run? Ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà, ìyẹn Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, ń sọ̀rọ̀ bíi dírágónì ní ti pé ó ń halẹ̀ mọ́ni, ó ń fúngun mọ́ni, ó sì ń fipá múni fara mọ́ ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso. Ó ń mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run ní ti pé ó ń ṣe bíi wòlíì tòótọ́, nípa sísọ tó ń sọ pé òun ti rẹ́yìn ẹgbẹ́ ogun olubi nínú ogun àgbáyé méjèèjì tó wáyé ní ọ̀rúndún ogún, àti pé òun ti ṣẹ́gun ètò ìjọba Kọ́múníìsì.
16:17—Kí ni “afẹ́fẹ́” tí wọ́n da àwokòtò keje sí? “Afẹ́fẹ́” yìí dúró fún èrò tí Sátánì ń gbé jáde, ìyẹn “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Gbogbo àwọn tó wà nínú ètò àwọn nǹkan Sátánì pátá ló ń mí afẹ́fẹ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí yìí símú.—Éfé. 2:2.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
13:1-4, 18. “Ẹranko ẹhànnà kan” tó dúró fún àwọn ìjọba ẹ̀dá èèyàn, jáde wá “láti inú òkun,” ìyẹn látinú aráyé oníjàgídíjàgan. (Aísá. 17:12, 13; Dán. 7:2-8, 17) Sátánì ló ṣẹ̀dá ẹranko yìí, òun ló sì gbé agbára lé e lọ́wọ́. Ẹranko yìí ní nọ́ńbà náà 666, tó fi hàn pé àìpé rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù. Mímọ̀ tá a mọ bí ẹranko ẹhànnà yìí ṣe jẹ́, kò ní jẹ́ ká máa tẹ̀ lé e, tàbí ká máa kan sáárá sí i, ká sì máa jọ́sìn rẹ̀ báwọn ọmọ aráyé ṣe ń ṣe.—Jòh. 12:31; 15:19.
13:16, 17. Bó ti wù kó ṣòro fún wa tó láti máa bá àwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ bíi ‘rírà tàbí títà’ lọ, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyẹn sọ wá dẹni tí ẹranko ẹhànnà náà á máa darí. Gbígba ‘àmì ẹranko ẹhànnà náà sí ọwọ́ tàbí iwájú orí wa’ máa túmọ̀ sí pé a jẹ́ kó máa darí ìṣesí wa tàbí kó nípa lórí ìrònú wa.
14:6, 7. Ìpolongo áńgẹ́lì yìí ń jẹ́ ká rí i pé a ò gbọ́dọ̀ jáfara lẹ́nu iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ yìí. A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti dẹni tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa fògo fún un.
14:14-20. Nígbà tí “ìkórè ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ìkórè àwọn tí yóò rí ìgbàlà, bá parí, àkókò yóò tó fún áńgẹ́lì náà láti kó “àjàrà ilẹ̀ ayé” kó sì fi sọ̀kò “sínú ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run.” Àjàrà náà, ìyẹn gbogbo ètò ìjọba oníwà ìbàjẹ́ tí Sátánì ń lò láti fi ṣàkóso aráyé, tóun ti “àwọn òṣùṣù,” ìyẹn èso ibi rẹ̀, la óò wá pa run títí láé. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní jẹ́ kí àjàrà ayé yìí kó àbààwọ́n bá wa.
16:13-16. “Àwọn àgbéjáde onímìísí àìmọ́” yìí dúró fún ìpolongo ẹ̀tàn tí Sátánì ń lò láti rí i dájú pé dídà táwọn áńgẹ́lì da àwokòtò méje ìbínú Ọlọ́run jáde kò mú káwọn ọba ayé yí èrò wọn pa dà, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń tì wọ́n kí wọ́n máa ṣàtakò sí Jèhófà.—Mát. 24:42, 44.
16:21. Bí òpin ayé ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ó lè jẹ́ pé àwọn gbólóhun ìdájọ́ Jèhófà tó wúwo tó sì rinlẹ̀ la ó fi máa kéde ìdájọ́ rẹ̀ sórí ètò nǹkan burúkú ti Sátánì yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí ni àwọn omi dídì tó ń já bọ́ yẹn ṣàpẹẹrẹ. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú aráyé yóò ṣì máa sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nìṣó.
ỌBA AJAGUNṢẸ́GUN Ń ṢÀKÓSO
“Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbàyé, jẹ́ apá tó ń ríni lára nínú ayé burúkú ti Sátánì yìí. Ìran kọkànlá ṣàpéjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí obìnrin “aṣẹ́wó ńlá” kan “tí ó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò.” “Ìwo mẹ́wàá” ẹranko ẹhànnà tí aṣẹ́wó náà gùn gan-an ni yóò pa á run pátápátá. (Ìṣí. 17:1, 3, 5, 16) Ìran kejìlá fi obìnrin aṣẹ́wó náà wé ìlú ńlá, ó sì kéde pé ìlú náà ti ṣubú, ó sì wá ní káwọn èèyàn Ọlọ́run tètè “jáde kúrò nínú rẹ̀” kíákíá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣọ̀fọ̀ lórí ìṣubú ìlú náà. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń bẹ lọ́run ń yọ̀ nítorí “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn.” (Ìṣí. 18:4, 9, 10, 15-19; 19:7) Nínú ìran kẹtàlá, ẹni tó gun “ẹṣin funfun kan” lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè ayé jagun. Ó wá fòpin sí ayé burúkú tí Sátánì ń ṣàkóso yìí.—Ìṣí. 19:11-16.
Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì”? Ìgbà wo la máa ‘fi sọ̀kò sínú adágún iná’? Ọ̀kan lára ohun tí ìran kẹrìnlá dá lé lórí nìyẹn. (Ìṣí. 20:2, 10) Ìran kẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ìkẹrìndínlógún jẹ́ ká mọ díẹ̀ nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Ní ìparí “ìṣípayá,” Jòhánú rí ‘odò omi ìyè kan tí ń ṣàn gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ náà.’ Ìpè àgbàyanu sì dún jáde pé kí “ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ” máa bọ̀.—Ìṣí. 1:1; 22:1, 2, 17.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
17:16; 18:9, 10—Kí nìdí tí “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tún fi ń ṣọ̀fọ̀ lórí ohun tó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ló pa á run? Ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú wọn ṣọ̀fọ̀. Lẹ́yìn ìparun Bábílónì Ńlá, ó dájú pé àwọn ọba ilẹ̀ ayé yóò wá mọ bó ṣe wúlò fún àwọn tó. Ìdí ni pé ìsìn ni wọ́n fi ń bojú bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Bábílónì Ńlá tún ń bá wọn wàásù fáwọn èwe pé kí wọ́n lọ máa jagun. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń kó ipa pàtàkì nínú mímú kí àwọn èèyàn wà nítẹríba lábẹ́ àwọn ọba ilẹ̀ ayé.
19:12—Báwo ló ṣe jẹ́ pé yàtọ̀ sí Jésù kò sí ẹnì kankan tó mọ orúkọ rẹ̀ tí a kò sọ yìí? Ó dà bíi pé orúkọ yẹn dúró fún ipò tí Jésù wà àtàwọn ànfààní tó ní ní ọjọ́ Olúwa, irú èyí tí Aísáyà 9:6 mẹ́nu kàn. Yàtọ̀ sí Jésù, kò sí ẹnì kankan tó mọ orúkọ yẹn ní ti pé àwọn àǹfààní tó ní ṣàrà ọ̀tọ́, òun nìkan ṣoṣo ló sì lè mọ ohun tí wíwà ní irú ipò gíga bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí. Àmọ́ ṣá, Jésù fún àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ìyàwó rẹ̀ ní díẹ̀ lára àwọn ànfààní náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘kọ orúkọ rẹ̀ tuntun yẹn sára wọn.’—Ìṣí. 3:12.
19:14—Àwọn wo ni yóò gẹṣin tẹ̀ lé Jésù nígbà Amágẹ́dọ́nì? Àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ti di aṣẹ́gun tí wọ́n sì ti gba èrè wọn lọ́run yóò wà lára ‘àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run’ tó máa tẹ̀ lé Jésù lọ láti ja ogun Ọlọ́run.—Mát. 25:31, 32; Ìṣí. 2:26, 27.
20:11-15—Orúkọ àwọn wo ni a kọ sínú “àkájọ ìwé ìyè”? Àwọn tí orúkọ wọn wà nínú àkájọ ìwé yìí ni gbogbo àwọn tí Jèhófà máa fún láǹfààní láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ tó máa ní “àjíǹde àwọn olódodo.” (Ìṣe 24:15; Ìṣí. 2:10; 7:9) Kí orúkọ àwọn tí wọ́n máa ní ‘àjíǹdè àwọn aláìṣòdodo’ tó lè wọnú “àkájọ ìwé ìyè” náà, wọn yóò ní láti máa tẹ̀ lé àwọn “nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé” ìtọ́ni tó máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Àmọ́ orúkọ tí wọ́n kọ síbẹ̀ ṣì ṣeé pa rẹ́ o. Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, orúkọ wọn tó wà nínú ìwé yìí kò ní lè pa rẹ́ mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú. (Ìṣí. 3:5) Ní ti àwọn tó ní ìyè lórí ilẹ̀ ayé, orúkọ tiwọn náà yóò dèyí tó wà nínú ìwé yẹn títí gbére tí wọ́n bá ti yege ìdánwò ìkẹyìn lópin ẹgbẹ̀rún ọdún.—Ìṣí. 20:7, 8.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
17:3, 5, 7, 16. “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” mú ká lóye ‘ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà àti ti ẹranko ẹhànnà [aláwọ̀ rírẹ̀dòdò] tí ń gbé e.’ (Ják. 3:17) Ẹranko ẹ̀hànnà ìṣàpẹẹrẹ náà jẹ́ àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ní ìbẹ̀rẹ̀, ó sì wá di àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n mú un sọ jí. Bá a ṣe wá rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ yìí, ṣé kò yẹ kí ìyẹn mú wa máa fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa pòkìkí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà?
21:1-6. Ó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé àwọn ìbùkún tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wà nínú Ìjọba Ọlọ́run máa rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé ohun tí Jèhófà sọ nípa wọn ni pé: “Wọ́n ti ṣẹlẹ̀!”
22:1, 17. “Odò omi ìyè” náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe láti fi gba àwọn tó jẹ́ onígbọràn nínú aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. À ń mu nínú omi odò náà nísinsìnyí. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé bá a ṣe fi ẹ̀mí ìmọrírì jẹ́ ìpè náà pé ká wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́” a tún ń ké sí àwọn míì náà pé kí wọ́n wá gbà á!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá ń fẹ́ àlàyé nípa Ìṣípayá 1:1–12:17, wo “Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣípayá—Apá Kìíní” nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2009.
b Tó o bá fẹ́ rí ibi tá a ti ṣàlàyé ìwé Ìṣípayá ní ẹsẹ-ẹsẹ, wo ìwé náà, Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn ìbùkún àgbàyanu làwọn ọmọ aráyé tó jẹ́ onígbọràn máa rí gbà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run!