Ayé kan Laisi Ẹ̀ṣẹ̀—Bawo?
ÌBÒÒSÍ igberara ba ìparọ́rọ́ kutukutu òwúrọ̀ ìgbà òtútù kan jẹ́ ni adugbo alalaafia kan ni Tokyo. Fun nǹkan bii iṣẹju marun-un si mẹwaa ọpọlọpọ eniyan gbọ́ ìbòòsí oró tí obinrin kan ti ń ta iwe-irohin ti a ń lé kiri bi a ti ń fi ọ̀bẹ gún un leralera naa ń ké. Kò sí ẹnikankan ti ó bikita tó lati wadii ohun tí ń ṣẹlẹ sí i. Ó kú nitori ipadanu ẹ̀jẹ̀ tí ó pọ̀ jù. “Bi ọ̀kan ninu awọn eniyan wọnyi bá ti fi irohin iṣẹlẹ naa tó awọn ọlọpaa létí ní gbàrà ti wọn gbọ́ igbe rẹ̀ ni,” ni olùṣèwádìí kan sọ, “à bá ti gba ẹmi rẹ̀ là.”
Bi o tilẹ jẹ pe awọn wọnni ti wọn ti gbọ́ igbe obinrin tí ń kú lọ naa kò ṣe ohun ti ó buru ju pe wọn wulẹ ṣai kọbiara sii, wọn ha lè fi ẹ̀tọ́ sọ pe awọn jẹ́ aláìlẹ́bi bi? “Ẹ̀rí-ọkàn mi dá mi lóró ni gbogbo ọjọ Friday lẹhin ti mo gbọ́ nipa ipaniyan naa,” ni ọkunrin kan ti ó ti gbọ́ igbe rẹ̀ sọ. Eyi mú wa ṣe kayeefi pe, Ki ni ẹ̀ṣẹ̀ niti gidi?
Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀?
Ní titọka si ìnímọ̀lára ẹ̀ṣẹ̀, Hideo Odagiri, olùṣelámèyítọ́ iwe-kikọ ati ọjọgbọn ti ó ti fẹ̀hìntì lẹnu iṣẹ ni Hosei University ni Tokyo, Japan, sọ gẹgẹ bi a ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lati inu iwe-irohin Asahi Shimbun pe: “Emi kò lè pa iranti kòrókòró ti mo ní nipa ìnímọ̀lára ẹ̀ṣẹ̀ tì, iru bii ìgbéra-ẹni-lárugẹ oníhàlẹ̀ ti ó wà ninu ọmọde kan, owú akótìjúbáni, ìfọ̀bẹ-ẹ̀hìn jẹniníṣu. Ìnímọ̀lára yii ni ó dápàá sara ironu mi nigba ti mo wà ni ile-ẹkọ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ó sì ń mú mi ní ibanujẹ ọkàn sibẹ.” Iwọ ha ti niriiri iru awọn imọlara bẹẹ bi? Iwọ ha ni ohùn inú-lọ́hùn-ún tí ń dá ọ lẹbi bi o bá ṣe ohun kan ti o mọ̀ pe kò tọna bi? Boya o kò tíì ṣàìdáa kankan, ṣugbọn imọlara amáranini kan ń fínná mọ́ ọ ó sì ń da ọkàn rẹ̀ laamu gidigidi. Ẹ̀rí-ọkàn rẹ niyi tí ń ṣiṣẹ, Bibeli sì tọka sii ninu ọ̀rọ̀-àyọkà ti ó tẹle e yii: “Nitori nigba ti awọn Keferi, ti kò ni ofin, bá ṣe ohun tí ó wà ninu ofin nipa ẹ̀dá, awọn wọnyi ti kò ni ofin, jẹ́ ofin fun ara wọn: Awọn ẹni ti o fihàn pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn ni ọkàn, ti ọkàn wọn sì ń jẹ́ wọn lẹrii, ti ìró wọn laaarin ara wọn sì ń fi wọn sùn tabi ti o ń gbè wọn.” (Romu 2:14, 15) Bẹẹni, nipa ẹ̀dá ọpọ julọ eniyan nimọlara idaamu nipa iru awọn ìwà bii panṣaga, olè-jíjà, ati irọ́-pípa. Ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹrii si ẹ̀ṣẹ̀.
Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a bá ṣai kọbiara si ohùn ẹ̀rí-ọkàn lemọlemọ, kìí tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii adáààbòboni kan mọ. Ó lè di aláìnímọ̀lára ati eyi ti a sọ di ẹlẹ́gbin. (Titu 1:15) Ìnímọ̀lára fun ohun ti ó buru ni ó ti padanu. Nitootọ, ẹ̀rí-ọkàn ọpọ julọ eniyan lonii ti kú ti ó bá kan ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀.
Ẹ̀rí-ọkàn ha ni ìdíwọ̀n kanṣoṣo fun ẹ̀ṣẹ̀ bi, tabi ohun kan ha tun wà ti ó lè ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọ̀pá ìdíwọ̀n patapata niti ohun ti ó parapọ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati ohun ti kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bi? Ni ohun ti o ju 3,000 ọdun lọ sẹhin, Ọlọrun fun awọn eniyan àyànfẹ́ rẹ̀ ni àkójọ ofin kan, ati nipasẹ Ofin yii, ẹ̀ṣẹ̀ ni a wá “dámọ̀ gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀.” (Romu 7:13, New International Version) Ìwà ti ó ti figbakanri jẹ́ ohun ti ó dabii ohun ti ó ṣetẹwọgba paapaa ni a wá fihàn nisinsinyi gẹgẹ bi ohun ti ó jẹ́—ẹ̀ṣẹ̀. Awọn eniyan àyànfẹ́ Ọlọrun, awọn ọmọ Israeli, ni a túfó gẹgẹ bi ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn sì tipa bẹẹ wà labẹ ìdálẹ́bi.
Ki ni awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọnyi ti ẹ̀rí-ọkàn wa ń jẹ́ ki a mọ̀ ati eyi ti Ofin Mose tọ́ka ní pàtó ti ó sì tò lẹsẹẹsẹ? Gẹgẹ bi a ṣe lo ọ̀rọ̀ naa ninu Bibeli, ẹ̀ṣẹ̀ tumọsi kikuna lati dé ojú ìlà ohun ti Ẹlẹdaa beere fun. Ohunkohun tí kò wà ni ibamu pẹlu animọ-iwa, awọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n, ọ̀nà, ati ifẹ-inu rẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀. Oun kò lè yọnda wíwàláàyè niṣo fun ẹ̀dá eyikeyii ti kò dé oju ìlà tí oun ti gbekalẹ. Nitori naa ògbóǹtarìgì kan nipa ofin ni ọrundun kìn-ín-ní kilọ fun awọn Kristian Heberu pe: “Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ ki ó maṣe wà ninu ẹnikẹni yin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alaaye.” (Heberu 3:12) Bẹẹni, aini igbagbọ ninu Ẹlẹdaa ni ó papọ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Nipa bayii, ohun ti isin mú lọwọ gẹgẹ bi a ti ṣalaye rẹ̀ ninu Bibeli gbooro fíìfíì ju ohun ti a sábà ń kà sí ẹ̀ṣẹ̀ lọ. Bibeli lọ jinna débi wiwi pe: “Gbogbo eniyan ni ó sá ti ṣẹ̀, ti wọn sì kùnà ògo Ọlọrun.”—Romu 3:23.
Orisun Ẹ̀ṣẹ̀
Iyẹn ha tumọsi pe eniyan ni a dá ni ẹlẹ́ṣẹ̀ bi? Bẹẹkọ, Jehofa Ọlọrun, Olupilẹṣẹ iwalaaye eniyan, ṣe eniyan akọkọ ni ẹ̀dá pípé kan. (Genesisi 1:26, 27; Deuteronomi 32:4) Bi o ti wu ki o ri, tọkọtaya eniyan akọkọ tàsé ìlà naa nigba ti wọn pe ofin ìkọ̀fún kanṣoṣo ti Ọlọrun gbekalẹ níjà, nigba ti wọn jẹ ninu “igi ìmọ̀ rere ati buburu” ti a kàléèwọ̀ naa. (Genesisi 2:17) Bi o tilẹ jẹ pe a dá wọn ní pípé, wọn tàsé ìlà ti ìṣègbọràn patapata si Baba wọn nisinsinyi, wọn di ẹlẹ́ṣẹ̀, a sì dá wọn lẹ́bi ikú bi ó ti yẹ.
Ki ni ìtàn ìgbà laelae yii níí ṣe pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ lonii? Bibeli ṣalaye pe: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . ti ipa ọ̀dọ̀ eniyan kan wọ ayé, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ̀; bẹẹ ni ikú sì kọja sori eniyan gbogbo, lati ọ̀dọ̀ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹ́ṣẹ̀.” (Romu 5:12) Laisi àyàfi kankan gbogbo wa ni ẹlẹ́ṣẹ̀ nipasẹ àjogúnbá; fun idi yii, a ti wá sabẹ ìdálẹ́bi ikú.—Oniwasu 7:20.
Awọn Ìsapá Eniyan Lati Pa Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ́
Adamu ta àtaré ẹ̀ṣẹ̀ si awọn ọmọ rẹ̀, ṣugbọn oun tún ta àtaré òye nipa ẹ̀rí-ọkàn ti Ọlọrun fifunni pẹlu. Ẹ̀ṣẹ̀ lè ṣokunfa imọlara àìbalẹ̀ ara. Gẹgẹ bi a ti mẹnukan an ṣaaju, awọn eniyan ti ṣe oniruuru ìhùmọ̀ lati mú iru awọn imọlara bẹẹ dẹrùn. Bi o ti wu ki o ri, wọn ha gbéṣẹ́ niti gidi bi?
Ni Ila-oorun ati ni Iwọ-oorun, awọn eniyan ti gbiyanju lati bojuto ipa ẹ̀ṣẹ̀ nipa yíyí awọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n wọn pada tabi nipa sísẹ́ wíwà ẹ̀ṣẹ̀ gan-an. (1 Timoteu 4:1, 2) Ipo araye ti ó kún fun ẹ̀ṣẹ̀ ni a lè fiwe ti alaisan kan ti ó ni ibà. Ẹ̀ṣẹ̀ ni a lè fiwe kokoro àrùn ti ń ṣokunfa àmì-àrùn, nigba ti ẹ̀rí-ọkàn ti a dà laamu ṣeefiwe ibà ti kò dẹnilọ́rùn. Kíkán ohun eelo ti a fi ń wọn ìgbóná-àti-ìtutù ara kò yí otitọ naa pe alaisan naa ní akọ ibà pada. Gbígbé awọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n iwa-rere sọnu, gẹgẹ bi ọpọlọpọ ninu Kristẹndọm ti ṣe, ati ṣiṣainaani ijẹrii ẹ̀rí-ọkàn tẹni funra-ẹni kò ṣeranwọ ninu pípa ẹ̀ṣẹ̀ fúnraarẹ̀ rẹ́.
Ẹnikan lè lo àdìpọ̀ yìnyín lati wá itura kuro lọwọ ibà rẹ̀. Iyẹn dabii gbigbiyanju lati bọ́ lọwọ irora ẹ̀rí-ọkàn nipa lilọwọ ninu awọn pẹ́pẹ́fúrú ààtò ìsọdimímọ́ ti isin Shinto. Àdìpọ̀ yìnyín lè tu ẹnikan ti ibà mú lara fun ìgbà kukuru, ṣugbọn kò mú okunfa ibà kuro. Awọn alufaa ati wolii ni ọjọ Jeremiah gbiyanju imularada ti ó farajọ eyi fun awọn ọmọ Israeli ti akoko yẹn. Wọn ṣe iwosan “ráńpẹ́” ọgbẹ́ tẹmi ati ti iwa-rere awọn eniyan naa, ni wiwi pe, “Gbogbo rẹ̀ dara, gbogbo rẹ̀ dara.” (Jeremiah 6:14; 8:11, An American Translation) Wiwulẹ lọwọ ninu awọn igbokegbodo isin ati wíwí ohun kan wúyẹ́wúyẹ́ bii “gbogbo rẹ̀ dara” kò wo iwolulẹ iwa-rere ti awọn eniyan Ọlọrun sàn, ààtò-ìsìn ìsọdimímọ́ kò sì yí ilana iwa-rere awọn eniyan pada lonii.
Nipa lilo oogun ibà oníbà kan lè mú ki ibà rẹ̀ dawọ duro, ṣugbọn kokoro àrùn ṣì wà ninu ara rẹ̀ sibẹ. Ohun kan-naa ni ó jẹ otitọ pẹlu ọ̀nà ti onisin Confucius ń gbà bojuto ibi nipasẹ ẹkọ-iwe. Ní gbangba ó lè ran awọn eniyan lọwọ lati yí kuro ninu ibi, ṣugbọn ṣiṣe li wulẹ ń tẹ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọlẹ ni kò sì gba ẹnikan kuro lọwọ itẹsi rẹ̀ àbínibí ti ó kun fun ẹ̀ṣẹ̀, okunfa ti ó pilẹ ìwà ibi.—Genesisi 8:21.
Ki ni nipa ẹ̀kọ́ isin Buddha nipa wiwọnu Nirvana lati gba ara-ẹni silẹ kuro lọwọ awọn itẹsi ti o kun fun ẹ̀ṣẹ̀? Ipo Nirvana, ti a sọ pe ó tumọ si “fífẹ́pa,” ni a tànmọ́-ọ̀n pé ó jẹ́ eyi ti kò ṣeé ṣapejuwe, pípaná gbogbo ìfẹ́-àìníjàánu ati ìfẹ́-ọkàn. Awọn kan sọ pe ó jẹ́ ìfòpin sí wíwàláàyè onítọ̀hún. Iyẹn kò ha dún bii sisọ fun ọkunrin alaisan ibà kan lati kú ki ó baa lè rí itura bi? Siwaju sii pẹlu, dídé ori ipo Nirvana ni a kà sí ohun ti ó ṣoro, àní ti kò tilẹ ṣeeṣe. Ẹ̀kọ́ yii ha dún bi eyi ti ó ṣeranwọ fun ẹnikan ti ó ni ẹ̀rí-ọkàn ti a kó idaamu bá bi?
Isọdominira Kuro Lọwọ Ẹ̀ṣẹ̀
Ó ṣe kedere pe ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn eniyan lori igbesi-aye ati awọn itẹsi ti o kún fun ẹ̀ṣẹ̀, kò lè ṣe ju pípẹ̀rọ̀ sí ẹ̀rí-ọkàn ẹnikan lọ. Wọn kìí mú ipo ẹ̀ṣẹ̀ kuro. (1 Timoteu 6:20) Ọ̀nà eyikeyii ha wà lati gbà ṣe eyi bi? Ninu Bibeli, iwe laelae kan ti a kọ ni Near East, a rí kọkọrọ naa si isọdominira kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀. “Bi ẹ̀ṣẹ̀ yin bá rí bi òdòdó, wọn ó sì fun bi ojo dídì; . . . Bi ẹyin bá fẹ́ ti ẹ sì gbọran, ẹyin o jẹ ire ilẹ naa.” (Isaiah 1:18, 19) Nihin-in Jehofa ń bá awọn ọmọ Israeli sọrọ, awọn ti, bi ó tilẹ jẹ pe wọn jẹ́ eniyan àyànfẹ́ rẹ̀, ti tàsé ìlà iwatitọ sí i. Bi o ti wu ki o ri, ilana kan-naa ṣeé fisilo fun araye lodindi. Fifi imuratan lati fetisilẹ si awọn ọ̀rọ̀ Ẹlẹdaa naa hàn ni kọkọrọ naa si jijẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ̀ ẹni mọ́, ki a fọ̀ ọ́ kuro, ki a sọ ọ́ lọna bẹẹ.
Ki ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ fun wa nipa fífọ awọn ẹ̀ṣẹ̀ araye kuro? Gan-an gẹgẹ bi o ti jẹ pe nipasẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọkunrin kan gbogbo araye di ẹlẹ́ṣẹ̀, nipasẹ igbọran pípé ọkunrin miiran si Ọlọrun, araye onigbọran ni a o tú silẹ kuro ninu ibanujẹ wọn, ni Bibeli wí. (Romu 5:18, 19) Bawo? “Ọlọrun fi ifẹ Oun paapaa si wa hàn ni eyi pe, nigba ti awa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fun wa.” (Romu 5:8) Jesu Kristi, ti a bí gẹgẹ bi eniyan pípé ati aláìlẹ́ṣẹ̀, ìdọ́gba-rẹ́gí Adamu akọkọ ki iyẹn tó ṣẹ̀, wà ni ipo lati kó awọn ẹ̀ṣẹ̀ araye lọ. (Isaiah 53:12; Johannu 1:14; 1 Peteru 2:24) Nipa jíjẹ́ ẹni ti a pa lori òpó-igi ìdálóró gẹgẹ bi ẹni pe ọ̀daràn kan ni, Jesu tú araye silẹ kuro ninu ìdè-ìsìnrú si ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú. Paulu ṣalaye fun awọn Kristian ni Romu pe, “Nitori ìgbà tí awa jẹ́ alailera, ni akoko ti o yẹ, Kristi kú fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun. . . . Gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀ ti jọba nipa ikú, bẹẹ ni ki oore-ọfẹ sì lè jọba nipa ododo titi ìyè ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.”—Romu 5:6, 21.
Kíkú tí Kristi kú fun gbogbo araye ati mímú òṣùwọ̀n ti Adamu mú fì lọ silẹ pada báradọ́gba ni a ń pè ni iṣeto “irapada.” (Matteu 20:28) A lè fi í wé egboogi kan ti ń ṣiṣẹ fun kokoro àrùn tí ń ṣokunfa ibà. Nipa fifi ìtóye irapada Jesu fun araye silo, ipo òkùnrùn araye ti ẹ̀ṣẹ̀ fà—ti ó ni ikú fúnraarẹ̀ ninu—ni a lè wòsàn. Ọ̀nà imularada yii ni a ṣapejuwe lọna afiṣapẹẹrẹ ninu iwe ti ó kẹhin ninu Bibeli pe: “Ni aarin igboro rẹ̀, ati niha ikinni keji odò naa, ni igi ìyè gbé wà, tíí maa so oniruuru eso mejila, a sì maa so eso rẹ̀ ni oṣooṣu: ewé igi naa sì ni fun mímú awọn orilẹ-ede larada.” (Ìfihàn 22:2) Rò ó wò ná! Odò afiṣapẹẹrẹ kan ti omi ìyè ń ṣàn laaarin awọn igi ìyè pẹlu ewé wọn, gbogbo rẹ̀ fun imularada araye. Awọn àmì-ìṣàpẹẹrẹ onimiisi atọrunwa wọnyi duro fun ipese Ọlọrun fun mímú araye pada si ijẹpipe lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu.
Awọn ìran alásọtẹlẹ inu iwe Ìfihàn yoo di otitọ gidi laipẹ. (Ìfihàn 22:6, 7) Nigba naa, pẹlu ifisilo patapata ti ìtóye ẹbọ irapada Jesu fun araye, gbogbo awọn ọlọ́kàntítọ́ yoo di pípé a ó sì ‘sọ wọn di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.’ (Romu 8:21) Imuṣẹ awọn asọtẹlẹ Bibeli fihàn pe isọdominira ologo yii ti sunmọle. (Ìfihàn 6:1-8) Laipẹ Ọlọrun yoo mú iwa-buburu kuro ni ayé, awọn eniyan yoo sì gbadun ìyè ayeraye lori paradise ilẹ̀-ayé kan. (Johannu 3:16) Iyẹn nitootọ yoo jẹ́ ayé kan laisi ẹ̀ṣẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹbọ irapada Jesu yoo mú ki ó ṣeeṣe fun awọn idile bii eyi lati gbadun ayọ ayeraye