Orí 1
Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Aláyọ̀!
1. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ ká jẹ́ aláyọ̀?
ÌṢÍPAYÁ FÚN JÒHÁNÙ—ìwé tó fa kíki yìí ló mú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá sí ìparí rẹ̀ aláyọ̀. Èé ṣe tá a fi sọ pé ó jẹ́ ìparí “aláyọ̀”? Ó dára, Ẹni tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì gan-an la pè ní “Ọlọ́run aláyọ̀,” ẹni tó fi “ìhìnrere ológo” sí ìkáwọ́ àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ń fẹ́ káwa náà jẹ́ aláyọ̀. Ìdí nìyẹn tí ìwé Ìṣípayá fi mú un dá wa lójú ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ gan-an pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí.” Ní orí rẹ̀ tó gbẹ̀yìn ó tún sọ fún wa pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́.”—1 Tímótì 1:11; Ìṣípayá 1:3; 22:7.
2. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ayọ̀ nípasẹ̀ ìwé Ìṣípayá?
2 Báwo la ṣe lè rí ayọ̀ nípasẹ̀ ìwé Ìṣípayá? Ó jẹ́ nípa wíwá ìtumọ̀ àwọn àmì, tàbí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tó ṣe ketekete tó wà nínú rẹ̀ ká sì máa hùwà ní ìbámu pẹ̀lú wọn. Hílàhílo tó ń wáyé láàárín ọmọ aráyé yóò dópin láìpẹ́ nígbà tí Ọlọ́run àti Jésù Kristi bá mú ìdájọ́ wá sórí ètò búburú ìsinsìnyí, tí wọ́n sì fi “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun,” níbi tí “ikú” pàápàá “kì yóò [ti] sí mọ́,” rọ́pò rẹ̀. (Ìṣípayá 21:1, 4) Ǹjẹ́ gbogbo wa ò fẹ́ láti gbé nínú irú ayé tuntun kan bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a ò fẹ́ gbé nínú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́? Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ fún wa bá a bá ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, títí kan àsọtẹ́lẹ̀ amúnilóríyá inú ìwé Ìṣípayá.
Kí Ló Ń Jẹ́ Àpókálíìsì?
3. Kí ni ọ̀pọ̀ rò pé Àpókálíìsì àti Amágẹ́dọ́nì túmọ̀ sí?
3 Ǹjẹ́ kì í ṣe ìwé Ìṣípayá la tún ń pè ní Àpókálíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, òun ni. Ìdí ni pé “ìṣípayá” la túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·po·kaʹly·psis sí lédè Yorùbá. Ọ̀pọ̀ ló máa ń fi Àpókálíìsì wé ìparun ayé nípasẹ̀ ogun tí wọ́n á ti lo bọ́ǹbù runlé-rùnnà. Ní ìlú Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ti ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn sọ pé, “Àwa ni yóò kọ́kọ́ pa run.” Ìròyìn sọ pé àwọn àlùfáà tó wà ní àgbègbè náà “gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe pé Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìkan ni ṣùgbọ́n ó ti sún mọ́lé pẹ̀lú, àti pé ogun tí wọ́n á ti lo bọ́ǹbù runlé-rùnnà ló máa jẹ́ ìjà àjàkẹ́yìn láàárín ire àti ibi, ìyẹn ẹgbẹ́ ogun ti Ọlọ́run àti ti Sátánì.”a
4. Kí lọ̀rọ̀ náà “àpókálíìsì” túmọ̀ sí ní ti gidi, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé “Ìṣípayá” ni àkọlé tó bá a mu rẹ́gí fún ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì?
4 Ṣùgbọ́n kí ló ń jẹ́ àpókálíìsì ní ti gidi? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ túmọ̀ rẹ̀ nípa lílo irú àwọn èdè bí “àjálù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí kò ní í pẹ́ ṣẹlẹ̀,” ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·po·kaʹly·psis ní ìpìlẹ̀ ni “ṣíṣíbòjú” tàbí “rírí ìdí.” Nítorí náà, àkọlé tó bá a mu tá a fún ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì ni “Ìṣípayá.” Kì í ṣe ìkéde ègbé tó ń bọ̀ wá sórí ayé tí aráyé ò lè yí padà ló wà nínú ìwé Ìṣípayá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí tó yẹ kó mú kí ìrètí ológo àti ìgbàgbọ́ tí ò lè bà jẹ́ wà nínú ọkàn wa.
5. (a) Àwọn wo ni yóò pa run ní Amágẹ́dọ́nì, àwọn wo ni yóò sì là á já? (b) Ọjọ́ ọ̀la ológo wo ló ń dúró de àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já?
5 Lóòótọ́, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ni ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì pè ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ṣùgbọ́n yóò yàtọ̀ pátápátá sí ogun tí wọ́n á ti máa ju bọ́ǹbù runlé-rùnnà! Ó ṣeé ṣe kí fífi bọ́ǹbù runlé-rùnnà pààyàn nípakúpa bẹ́ẹ̀ yọrí sí pípa gbogbo ẹ̀dá alààyè orí ilẹ̀ ayé run ráúráú. Àmọ́ kì í ṣe ìyẹn ni ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú un dáni lójú pé kìkì àwọn olubi, àwọn alátakò Ọlọ́run, ni ẹgbẹ́ ogun ọ̀run máa pa run. (Sáàmù 37:9, 10; 145:20) Ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò la ìdájọ́ Ọlọ́run, èyí tó máa dé ìparí rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, já. Nígbà náà, Kristi Jésù yóò wá ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì ṣamọ̀nà wọn sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o ò ní fẹ́ láti jẹ́ ọ̀kan lára wọn? Ó múni láyọ̀ pé ìwé Ìṣípayá fi hàn pé o lè jẹ́ ọ̀kan lára wọn!—Ìṣípayá 7:9, 14, 17.
Wíwádìí Àwọn Àṣírí Ọlọ́run
6. Láwọn ọdún tó ti kọjá sẹ́yìn, àwọn ìwé wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde láti tànmọ́lẹ̀ sórí ìwé Ìṣípayá?
6 Ọdún 1917 lọ́hùn-ún ni Watch Tower Society tẹ ìwé náà The Finished Mystery. Èyí jẹ́ àlàyé lẹ́sẹẹsẹ lórí ìwé Ìsíkíẹ́lì àti ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì. Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé sì ṣe ń bá a lọ láti máa mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ ní kedere, ìwé aládìpọ̀ méjì kan tó bákòókò mu tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Light la ṣe tá a sì tẹ̀ jáde lọ́dún 1930. Èyí pèsè ẹ̀kọ́ tá a túbọ̀ mú ṣe kedere lórí ìwé Ìṣípayá. Ìmọ́lẹ̀ ń bá a lọ láti máa ‘kọ mànà fún àwọn olódodo’ tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé lọ́dún 1963, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìwé olójú ewé mẹ́rìnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [704] náà, “Babylon the Great Has Fallen!” God’s Kingdom Rules! Ní kúlẹ̀kúlẹ̀, ìwé yìí sọ bí Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe ṣubú, a sì fi ìjíròrò orí mẹ́sàn-án tó kẹ́yìn ìwé Ìṣípayá parí rẹ̀. Bí ‘ipa ọ̀nà àwọn olódodo ti túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i,’ ní pàtàkì ní ti ọ̀ràn ìgbòkègbodò ìjọ, ní 1969, a ṣe ìdìpọ̀ ìwé olójú ewé irinwó dín mẹ́rìndínlógún [384] kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Then Is Finished the Mystery of God.” Ìwé yìí jíròrò orí mẹ́tàlá àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣípayá.—Sáàmù 97:11; Òwe 4:18.
7. (a) Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi pèsè ìwé yìí lórí Ìṣípayá? (b) Àwọn ohun tí ń ranni lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ wo la pèsè nínú ìwé yìí fún àǹfààní àwọn òǹkàwé?
7 Kí wá nìdí tá a fi tún tẹ ìwé mìíràn jáde lórí Ìṣípayá tá a sì tún ṣe àtúntẹ̀ rẹ̀ lákòókò yìí? Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tó wà nínú àwọn ìwé tá a ti tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀ lórí ìwé Ìṣípayá pọ̀, kò sì ṣeé ṣe láti túmọ̀ rẹ̀ ká sì tẹ̀ wọ́n jáde ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè jákèjádò ayé. Nítorí ìdí yìí, a rí i pé ó yẹ ká ṣe ìwé kan ṣoṣo jáde lórí ìwé Ìṣípayá ká sì ṣe é lọ́nà táá fi rọrùn láti mú un jáde ní ọ̀pọ̀ èdè. Yàtọ̀ síyẹn, a lo àǹfààní ìwé kan ṣoṣo tá a ṣe yìí láti pèsè àwọn ohun tí ń ranni lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, irú bíi àwọn àwòrán, àtẹ ìsọfúnni, àti àkópọ̀, èyí tó yẹ kó ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ fífakíki tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yíyani lẹ́nu yì.
8. Ìdí tó tiẹ̀ tún lágbára jù wo la fi tẹ ìwé yìí jáde?
8 Ìdí kan tó tiẹ̀ túbọ̀ lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a fi tẹ ìwé yìí jáde ni pé a rí i pé ó jẹ́ dandan pé ká mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Jèhófà kò yéé tan ìmọ́lẹ̀ púpọ̀ sí i jáde sórí ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a sì mọ̀ pé òye wa lórí ìwé Ìṣípayá àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù á túbọ̀ máa dára sí i ni bá a ti ń sún mọ́ ìgbà ìpọ́njú ńlá. (Mátíù 24:21; Ìṣípayá 7:14) Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun púpọ̀ nípa èyí. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run pé: ‘Ẹ̀ ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tó ṣókùnkùn, títí tí ojúmọ́ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́ yóò sì yọ, nínú ọkàn yín.’—2 Pétérù 1:19.
9. (a) Bíi tàwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì, kí ni Ìṣípayá fi hàn pé Ọlọ́run yóò dá? (b) Kí ni ayé tuntun, báwo lo sì ṣe lè là á já sínú rẹ̀?
9 Ìwé Ìṣípayá fi ẹ̀rí tiẹ̀ kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì, ó fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ní in lọ́kàn láti dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun. (Aísáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1-5) Àwọn tí iṣẹ́ tí Jésù rán nínú ìwé Ìṣípayá wà fún ní pàtàkì ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Jésù ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rà láti di alájùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run tuntun. (Ìṣípayá 5:9, 10) Síbẹ̀, ìhìn rere yìí yóò tún fún ìgbàgbọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí ń wọ̀nà fún ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ Ìjọba Kristi lágbára. Ṣé ọ̀kan lára wọn ni ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwé Ìṣípayá yóò mú kí ìrètí rẹ lágbára, ìyẹn ìrètí tó o ní láti gbé nínú Párádísè gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn tó para pọ̀ di ayé tuntun, pẹ̀lú ìgbádùn ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà, ara dídá ṣáṣá, àti àkúnwọ́sílẹ̀ àwọn ìpèsè Ọlọ́run tí kì yóò dópin. (Sáàmù 37:11, 29, 34; 72:1, 7, 8, 16) Bó o bá fẹ́ là á já sínú ayé tuntun yẹn, ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú ó sì tún jẹ́ dandan gbọ̀n pé kó o fiyè sí àpèjúwe kedere tó wà nínú ìwé Ìṣípayá nípa ìparí tó máa jẹ́ mánigbàgbé, èyí tó kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí.—Sefanáyà 2:3; Jòhánù 13:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé ìròyìn Süddeutsche Zeitung, Munich, Jámánì, January 24, 1987.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]