Ọlọ́run Kò Fi Nǹkan Falẹ̀ Ní Ti Ìlérí Rẹ̀
“YÓÒ ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò gbọ́?” Wòlíì Hébérù nì, Hábákúkù, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n, ṣe lọ̀rọ̀ yẹn dà bí ohun tí à ń gbọ́ lẹ́nu àwọn èèyàn lójoojúmọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá pé kí ohun tí a ti ń yán hànhàn fún tipẹ́tipẹ́ tètè tẹ̀ wá lọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀ tàbí kó tètè tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní kíákíá. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí pàápàá jù lọ nínú sànmánì onígírímọ́káì táa ń gbé yìí.—Hábákúkù 1:2.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan wà tí wọ́n rò pé ó yẹ kí Ọlọ́run ti tètè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ṣáájú ìsinsìnyí. Ojú ń kán wọn débi pé wọ́n tilẹ̀ gbà pé Ọlọ́run ń fi nǹkan falẹ̀ tàbí pé ó ti ń pẹ́ jù. Fún ìdí yìí, àpọ́sítélì Pétérù ní láti rán wọn létí pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àkókò yàtọ̀ pátápátá sí tiwa. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.”—2 Pétérù 3:8.
Ní fífi ojú yìí wo àkókò, ẹni ọgọ́rin ọdún ṣẹ̀ṣẹ̀ lo nǹkan bí wákàtí méjì ni, gbogbo ìgbà tí aráyé sì ti wà níhìn-ín ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ sí ọjọ́ mẹ́fà ni. Báa bá fojú yìí wò ó, yóò túbọ̀ rọrùn fún wa láti lóye ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá wa lò.
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé Ọlọ́run kò ka àkókò sí. Ní òdìkejì pátápátá, Ọlọ́run kì í fi àkókò ṣeré rárá. (Ìṣe 1:7) Nítorí náà, Pétérù ń bá a lọ láti sọ pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ọlọ́run kò dà bí àwa èèyàn, òun kì í kánjú ṣe nǹkan bí ẹni pé àkókò tó ní ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bù ṣe. Gẹ́gẹ́ bí “Ọba ayérayé,” ó ní ojú ìwòye tó ga lọ́lá, ó sì lè pinnu pẹ̀lú bí àkókò ti ń lọ sí, ìgbà tí ìgbésẹ̀ òun yóò ṣe gbogbo àwọn tọ́ràn kàn láǹfààní rẹpẹtẹ.—1 Tímótì 1:17.
Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé ìdí tó fi jọ pé Ọlọ́run ń fi nǹkan falẹ̀, Pétérù ṣèkìlọ̀ yìí: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” Ìyẹn ni pé, ọjọ́ ìjíhìn yóò dé nígbà tí àwọn ènìyàn kò retí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, Pétérù tọ́ka sí ìfojúsọ́nà àgbàyanu fún àwọn tó bá ṣàfihàn “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” ìyẹn ni pé, kí wọ́n bàa lè là á já bọ́ sínú “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tí Ọlọ́run ti ṣèlérí.—2 Pétérù 3:10-13.
Èyí yóò mú kí a túbọ̀ mọrírì ìdí tí ìdájọ́ Ọlọ́run kò fi tí ì dé. Sùúrù rẹ̀ ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ète rẹ̀ àti láti mú ìgbésí ayé wa bá a mu, ká lè rí ìbùkún tó ti ṣèlérí gbà. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti ṣàlàyé, kò ha yẹ kí a ka “sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà” bí? (2 Pétérù 3:15) Ṣùgbọ́n, kókó mìíràn tún wà nínú sùúrù Ọlọ́run.
Òṣùwọ̀n Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Yẹ Kó Kún
Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá aráyé lò nígbà àtijọ́, a kíyè sí i pé ó sábà máa ń fawọ́ ìdájọ́ rẹ̀ sẹ́yìn títí di ìgbà tí wọn kò bá lè ṣàtúnṣe mọ́. Fún àpẹẹrẹ, nípa ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn ará Kénáánì, tipẹ́tipẹ́ ló ti sọ fún Ábúráhámù nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àtimú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí wọn kò tí ì tó. Èé ṣe? Bíbélì sọ pé: “Nítorí pé ìṣìnà àwọn Ámórì kò tí ì parí síbẹ̀,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Knox ṣe sọ ọ́: “Ìwà burúkú àwọn ará Ámórì kò tí ì dé ìpẹ̀kun.”—Jẹ́nẹ́sísì 15:16.a
Àmọ́ ṣá o, ní nǹkan bí irínwó ọdún [400] lẹ́yìn náà, ìdájọ́ Ọlọ́run dé, àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ náà. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ará Kénáánì, àwọn bí Ráhábù àti àwọn ará Gíbéónì, ni a gbà là nítorí ìwà àti ìṣe wọn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn òde òní ti fi hàn, àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló jẹ́ pé ìwà àìmọ́ wọn ti pàpọ̀jù. Wọ́n ń jọ́sìn ẹ̀yà ìbímọ, wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì ń fọmọ rúbọ. Ìwé náà, Halley’s Bible Handbook, sọ pé: “Àwọn awalẹ̀pìtàn tí wọ́n walẹ̀ ibi òkìtì àlàpà àwọn ìlú ńlá Kénáánì ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi pa wọ́n run ṣáájú àkókò yẹn.” Lópin rẹ̀, ‘òṣùwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Kénáánì kún’; ìwà burúkú wọn ti “dé ìpẹ̀kun.” Kò sẹ́ni tó lè dá Ọlọ́run lẹ́bi fún jíjẹ́ kí a fọ ilẹ̀ náà mọ́, tó sì dá àwọn oníwà rere sí.
Irú ohun kan náà la tún rí lọ́jọ́ Nóà. Láìka ti pé àwọn èèyàn tó wà ṣáájú Ìkún Omi jẹ́ oníwà ibi sí, Ọlọ́run fi tàánútàánú pinnu pé àkókò wọn yóò máa bá a lọ fún ọgọ́fà ọdún [120] sí i. Ní apá kan àkókò yẹn, Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pétérù 2:5) Bí àkókò ti ń lọ, ìwà ibi wọ́n wá dójú ẹ̀. “Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́, nítorí pé gbogbo ẹlẹ́ran ara ti ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:3, 12) ‘Òṣùwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti kún’; àkókò tó ti kọjá ti jẹ́ kí ìwà ibi wọn dé ògógóró rẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run wá gbégbèésẹ̀, kò sẹ́ni tó lè dá a lẹ́bi rárá. Èèyàn mẹ́jọ péré ló jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run, ó sì gbà wọ́n là.
Bákan náà ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá Ísírẹ́lì lò. Yàtọ̀ sí ti pé wọ́n hùwà àìṣòótọ́ àti ìwà ìbàjẹ́, Ọlọ́run mú sùúrù fún wọn fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà . . . ń ránṣẹ́ lòdì sí wọn ṣáá nípasẹ̀ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń ránṣẹ́ léraléra, nítorí pé ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ . . . Ṣùgbọ́n . . . wọ́n . . . ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:15, 16) Àwọn èèyàn náà ti dé àyè kan tí wọn kò lè ṣàtúnṣe mọ́. Jeremáyà pẹ̀lú àwọn díẹ̀ nìkan ló lè rí ìgbàlà. A kò lè sọ pé Ọlọ́run kò ṣe ohun tó tọ́ nígbà tó mú ìdájọ́ wá sórí àwọn yóòkù nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Àkókò Ọlọ́run Láti Gbégbèésẹ̀ Ti Dé Tán
Láti inú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí a lè rí i pé Ọlọ́run ṣì ń fawọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn lórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí títí di ìgbà tí àkókò bá tó. A fi èyí hàn nínú àṣẹ tí a fún ẹni tó fẹ́ mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àṣẹ náà lọ báyìí: “‘Ti dòjé mímú rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kó àwọn òṣùṣù àjàrà ilẹ̀ ayé jọ, nítorí èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.’ Áńgẹ́lì náà sì ti dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì kó àjàrà ilẹ̀ ayé jọ, ó sì fi í sọ̀kò sínú ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run.” Ṣàkíyèsí pé ìwà ibi aráyé ti “pọ́n,” ìyẹn ni pé, ó ti dé àyè kan tí kò lè sí àtúnṣe mọ́. Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ, kò ní sí àní-àní pé kò sẹ́ni tí yóò lè dá a lẹ́bi fún dídásí ọ̀ràn ayé.—Ìṣípayá 14:18, 19.
Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò ohun tó wà lókè yìí, ó ṣe kedere pé ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ayé yìí ti sún mọ́lé nítorí pé ayé ti ń hu àwọn ìwà tó jẹ́ kí ìdájọ́ Ọlọ́run dé sórí rẹ̀ láyé ọjọ́sí. Kò síbi táa yíjú sí lónìí tí ilé ayé ò kún fún ìwà ipá, gẹ́gẹ́ bó ti rí ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Ìwà àwọn ènìyàn túbọ̀ ń jọ èyí táa ṣàpèjúwe nínú Jẹ́nẹ́sísì 6:5, tó sọ pé: “Gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” Àní àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì tó mú kí ìdájọ́ Ọlọ́run dé sórí àwọn ará Kénáánì pàápàá ti di ohun tó wọ́pọ̀ lóde òní.
Ní pàtàkì láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, aráyé ti rí ọ̀pọ̀ ìyípadà yíyanilẹ́nu. Ó ti rí i tí ẹ̀jẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn rin ilẹ̀ ayé gbingbin. Ogun, ìpẹ̀yàrun, ìpániláyà, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà ta-ni-yóò-mú-mi ti gba gbogbo ayé kan. Ìyàn, àìsàn, àti ìṣekúṣe sì wà káàkiri ayé. Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé a ń gbé láàárín ìran burúkú tí Jésù sọ nípa rẹ̀ pé: “Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” (Mátíù 24:34) “Òṣùwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀” ayé yìí sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kún báyìí o. “Àwọn òṣùṣù àjàrà ilẹ̀ ayé” sì ti ń pọ́n fún ìkórè o.
Àkókò Tó fún Ẹ Láti Gbégbèésẹ̀
A sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù pé bí àkókò ìdájọ́ ti ń sún mọ́lé, oríṣi pípọ́n méjì ni yóò wáyé. Lọ́wọ́ kan, “ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀; kí a sì sọ ẹni tí ó jẹ́ eléèérí di eléèérí síbẹ̀.” Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, “kí olódodo máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.” (Ìṣípayá 22:10, 11) Ohun táa mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí ń wáyé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Ète iṣẹ́ yìí ni láti kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn kí a bàa lè kà wọ́n yẹ ni ẹni tó lè gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ìgbòkègbodò yìí ń dé nǹkan bí igba ilẹ̀ ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [233] nínú àwọn ìjọ bí ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [87,000].
Ọlọ́run kò fi nǹkan falẹ̀. Pẹ̀lú sùúrù, ó ti yọ̀ǹda àkókò fún olúkúlùkù láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀” kí wọ́n bàa lè jàǹfààní látinú àwọn ìlérí rẹ̀. (Éfésù 4:24) Lónìí, Ọlọ́run ṣì ń mú sùúrù, láìka ipò ayé tó túbọ̀ ń bà jẹ́ lójoojúmọ́ sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣàjọpín ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn. (Jòhánù 17:3, 17) Ó dùn mọ́ni pé, lọ́dọọdún ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn tí wọ́n ń dáhùn padà, tí wọ́n sì ń ṣe ìrìbọmi.
Pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun tó wà níwájú wa yìí, èyí kì í ṣe àkókò láti káwọ́ gbera, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkókò láti gbé ìgbésẹ̀. Nítorí nígbà díẹ̀ sí i, a óò rí ìmúṣẹ ìlérí Jésù náà pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.”—Jòhánù 11:26.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lórí ẹsẹ yìí nínú ìwé náà, The Soncino Chumash sọ pé: “Wọ́n yẹ ni ẹni lílé jù nù, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kò jẹ́ fìyà jẹ orílẹ̀-èdè kan láìjẹ́ pé òṣùwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti kún.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
A sọ fún ẹni tí yóò mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ pé kí ó ti dòjé rẹ̀ bọ àjàrà ilẹ̀ ayé nígbà tó ti pọ́n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tí yóò rí ìbùkún ayérayé látọwọ́ Ọlọ́run gbà