Ẹ Fetí Sí Ohun Tí Ẹ̀mí Ń Sọ!
“Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”—ÌṢÍPAYÁ 3:22.
1, 2. Ìmọ̀ràn wo ló ń wáyé léraléra nínú iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn ìjọ méje tá a dárúkọ nínú ìwé Ìṣípayá?
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ darí Jésù Kristi láti sọ fún àwọn ìjọ méje tá a dárúkọ nínú ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì. Àní, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ló ní ìmọ̀ràn tó sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”—Ìṣípayá 2:7, 11, 17, 29; 3:6, 13, 22.
2 A ti gbé àwọn iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn alábòójútó ní Éfésù, Símínà, àti Págámù yẹ̀ wò. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tó tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sọ fáwọn ìjọ mẹ́rin tó kù?
Sí Áńgẹ́lì ní Tíátírà
3. Ibo ni Tíátírà wà, kí sì ni ohun tí gbogbo èèyàn mọ̀ pé wọ́n ń ṣe níbẹ̀?
3 Oríyìn àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni “Ọmọ Ọlọ́run” fún ìjọ tó wà ní Tíátírà. (Ka Ìṣípayá 2:18-29.) Ẹ̀bá odò kan tí ń ṣàn sínú Odò Gediz (Hermus ìgbàanì) ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré ni wọ́n kọ́ Tíátírà (tó ti di Akhisar báyìí) sí. Onírúurú iṣẹ́ ọnà ni wọ́n ń ṣe nínú ìlú ńlá náà. Inú gbòǹgbò igi madder làwọn tó ń ṣe aró níbẹ̀ ti máa ń mú ohun pupa tàbí ohun aláwọ àlùkò tí gbogbo èèyàn mọ̀ wọ́n mọ́ jáde. Lìdíà, tó di Kristẹni nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sí ìlú Fílípì ní Gíríìsì, jẹ́ “ẹni tí ń ta ohun aláwọ̀ àlùkò, ará ìlú ńlá Tíátírà.”—Ìṣe 16:12-15.
4. Tìtorí kí la ṣe gbóríyìn fún ìjọ tó wà ní Tíátírà?
4 Jésù gbóríyìn fún ìjọ tó wà ní Tíátírà nítorí àwọn iṣẹ́ rere rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀, ìfaradà rẹ̀, àti bó ṣe ń sakun nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àní sẹ́, ‘àwọn iṣẹ́ wọn ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.’ Kódà ká ní àtọdún gbọ́n-han la ti ń ṣe dáadáa bọ̀, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ ṣàìbìkítà nípa ìwà wa.
5-7. (a) Ta ni “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì,” kí ló sì yẹ ní ṣíṣe nípa ipa tó ní? (b) Kí ni iṣẹ́ tí Kristi rán sí ìjọ Tíátírà ran àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ṣe?
5 Ìjọ tó wà ní Tíátírà ń fàyè gba ìbọ̀rìṣà, ẹ̀kọ́ èké, àti ìwà pálapàla láàárín takọtabo. Àárín wọn ni “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì” wà—ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin kan tí wọ́n ní àwọn ànímọ́ tó fara jọ ti Jésíbẹ́lì, Ayaba burúkú ti ẹ̀yà mẹ́wàá Ìjọba Ísírẹ́lì yẹn. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fi hàn pé ‘àwọn wòlíì obìnrin’ tó wà ní Tíátírà gbìyànjú láti mú kí àwọn Kristẹni jọ́sìn àwọn ọlọ́run àtàwọn abo-ọlọ́run ẹgbẹ́ ìṣòwò kí wọ́n sì kópa nínú àwọn àjọyọ̀ tó ní oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà nínú. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó yan ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì obìnrin gbìyànjú láti darí àwọn mìíràn nínú ìjọ Kristẹni òde òní!
6 Kristi ‘máa tó fi àìsàn gbé obìnrin náà Jésíbẹ́lì dè, yóò sì sọ àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà sínú ìpọ́njú ńlá, àyàfi bí wọ́n bá ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ rẹ̀.’ Àwọn alábòójútó ò gbọ́dọ̀ fara mọ́ irú ẹ̀kọ́ àti ipa búburú bẹ́ẹ̀ láé, kò sì sí Kristẹni tó ní láti ṣe àgbèrè nípa tẹ̀mí tàbí nípa ti ara tàbí kó lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà kó tó lè mọ̀ pé ohun búburú gbáà ni “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì” jẹ́. Bí a bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jésù, ‘a ó di ohun tí a ní mú ṣinṣin,’ ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ní gbilẹ̀ láàárín wa. Nítorí pé àwọn ẹni àmì òróró tá a jí dìde kọ àwọn àṣà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àti àwọn góńgó tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n gba “ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè,” wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ Kristi láti fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Àwọn ìjọ tó wà lóde òní ní àwọn ìràwọ̀ ìṣàpẹẹrẹ, a ó sì fún àwọn ẹni àmì òróró ní “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò,” ìyẹn ni ọkọ ìyàwó náà, Jésù Kristi, nígbà tá a bá jí wọn dìde sí ọ̀run.—Ìṣípayá 22:16.
7 A kìlọ̀ fún ìjọ Tíátírà láti má ṣe fàyè gba ipa búburú ti àwọn obìnrin tí ń pẹ̀yìn dà yìí. Iṣẹ́ tí ẹ̀mí darí Kristi láti rán sí ìjọ yẹn ṣèrànwọ́ fáwọn obìnrin olùṣèfẹ́ Ọlọ́run láti má ṣe kọjá ibi tí Ọlọ́run yàn wọ́n sí lónìí. Wọn kì í gbìyànjú láti lo ọlá àṣẹ lórí àwọn ọkùnrin wọn ò sì sún arákùnrin èyíkéyìí ṣe àgbèrè nípa tẹ̀mí tàbí nípa ti ara. (1 Tímótì 2:12) Dípò ìyẹn, ńṣe ni irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà àti iṣẹ́ ìsìn sí ìyìn Ọlọ́run. (Sáàmù 68:11; 1 Pétérù 3:1-6) Bí ìjọ bá dáàbò bo ohun tó ní—ìyẹn ẹ̀kọ́ àti ìwà mímọ́ tó sì ka iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà sí ohun tó ṣeyebíye—Kristi yóò fi ìbùkún yàbùgà yabuga jíǹkí rẹ̀, kò ní pa á run.
Sí Áńgẹ́lì ní Sádísì
8. (a) Ibo ni Sádísì wà, kí sì ni àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí nìdí tí ìjọ tó wà ní Sádísì fi nílò ìrànlọ́wọ́?
8 Ìjọ tó wà ní Sádísì nílò ìrànlọ́wọ́ ojú ẹsẹ̀, nítorí pé ó ti kú nípa tẹ̀mí. (Ka Ìṣípayá 3:1-6) Nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí ìhà gúúsù Tíátírà ni Sádísì wà, ó sì jẹ́ ìlú ńlá kan tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù. Àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, bí àgbègbè náà ṣe jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá, àti bí wọ́n ṣe ń ṣe aṣọ àti kápẹ́ẹ̀tì níbẹ̀ ṣèrànwọ́ láti mú kí ibẹ̀ jẹ́ ìlú ọlọ́rọ̀ tó ti fìgbà kan ní nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ èèyàn nínú. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Josephus, òpìtàn nì wí, àwọn Júù pọ̀ gan-an ní Sádísì ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa. Sínágọ́gù kan àti tẹ́ńpìlì abo-ọlọ́run Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù wà lára ohun tó pa run pọ̀ mọ́ ìlú ńlá náà.
9. Kí ló yẹ ká ṣe bí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wa bá jẹ́ èyí tá à ń ṣe lọ́nà tí kò dénú?
9 Kristi sọ fún áńgẹ́lì ìjọ Sádísì pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ ní orúkọ pé o wà láàyè, ṣùgbọ́n o ti kú.” Táwọn èèyàn bá ń wò wá bí ẹni pé a wà lójúfò nípa tẹ̀mí àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe là ń dágunlá sáwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn táwa Kristẹni ní, tá a sì ń ṣe ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wa lọ́nà tí kò dénú, tá a tiẹ̀ ti “fẹ́rẹ̀ẹ́ kú” nípa tẹ̀mí ńkọ́? Nígbà náà, a ní láti ‘máa bá a lọ ní fífi bá a ṣe gbà àti bá a ṣe gbọ́’ iṣẹ́ Ìjọba náà sọ́kàn, a sì gbọ́dọ̀ fi kún ìsapá wa nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́. A tún gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi tọkàntọkàn kópa nínú àwọn ìpàdé Kristẹni. (Hébérù 10:24, 25) Kristi kìlọ̀ fún ìjọ tó wà ní Sádísì pé: “Láìjẹ́ pé o jí, èmi yóò wá gẹ́gẹ́ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá ní ti wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.” Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ yìí kàn wá lónìí? Láìpẹ́ láìjìnnà, àwa náà yóò jíhìn.
10. Kódà nínú irú ipò tó fara jọ ti Sádísì, kí ni àwọn Kristẹni díẹ̀ ṣì lè ṣe?
10 Kódà nínú irú ipò tó fara jọ ti Sádísì yẹn, àwọn díẹ̀ ṣì lè wà tí wọn ‘kò sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin, tí wọ́n sì lè bá Kristi rìn nínú èyí tí ó funfun, nítorí wọ́n yẹ.’ Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé Kristẹni làwọn ní gbogbo ìgbà, wọ́n wà láìlẹ́gbin, láìní èérí nípa ti ìwà rere àti ìsìn látinú ayé yìí. (Jákọ́bù 1:27) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù ‘kò ní pa orúkọ wọn rẹ́ lọ́nàkọnà kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n yóò jẹ́wọ́ wọn níwájú Baba rẹ̀ àti àwọn áńgẹ́lì.’ Nítorí pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti bá Kristi rìn, a ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ ìyàwó rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, èyí tó dúró fún àwọn ìṣe òdodo tàwọn ẹni mímọ́. (Ìṣípayá 19:8) Àwọn àgbàyanu àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ń dúró dè wọ́n ní ọ̀run ló ń fún wọn níṣìírí láti ṣẹ́gun ayé yìí. Ìbùkún tún wà fáwọn tó nírètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. A kọ orúkọ àwọn náà sínú ìwé ìyè.
11. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí sùn nípa tẹ̀mí?
11 Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa táá fẹ́ bára rẹ̀ nínú ipò bíbaninínújẹ́ nípa tẹ̀mí tí ìjọ Sádísì wà. Àmọ́ tá a bá fòye mọ̀ pé a ti ń sùn nípa tẹ̀mí ńkọ́? A gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ ní kíá fún àǹfààní ara wa. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ti fẹ́ máa rìn ní ọ̀nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tàbí tá ò fi bẹ́ẹ̀ jára mọ́ lílọ sáwọn ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí mọ́ ńkọ́? Ẹ jẹ́ ká bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà àtọkànwá. (Fílípì 4:6, 7, 13) Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ “olùṣòtítọ́ ìríjú” náà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jí nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 12:42-44) Ìgbà yẹn la óò wá dà bí àwọn tó rí ojú rere Kristi ní Sádísì, a ó sì jẹ́ ìbùkún fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
Sí Áńgẹ́lì ní Filadẹ́fíà
12. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ipò tí ọ̀ràn ìsìn wà ní Filadẹ́fíà ìgbàanì?
12 Jésù gbóríyìn fún ìjọ Filadẹ́fíà. (Ka Ìṣípayá 3:7-13) Filadẹ́fíà (tó ti di Alasehir báyìí) jẹ́ ibùdó lílókìkí kan ní àgbègbè tí wọ́n ti ń ṣe wáìnì ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Kódà, ọlọ́run tí wọ́n ń júbà fún jù níbẹ̀ ni Dionysus, tó jẹ́ ọlọ́run wáìnì. Ó dájú pé àwọn Júù tó wà ní Filadẹ́fíà á ti gbìyànjú láti pàrọwà sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù níbẹ̀ pé kí wọ́n padà sórí àwọn àṣà kan nínú Òfin Mósè, àmọ́ àwọn yẹn ò gbà fún wọn.
13. Báwo ni Kristi ṣe lo “kọ́kọ́rọ́ Dáfídì”?
13 Kristi “ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì,” ó sì ti tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí a fi gbogbo ire Ìjọba àti ìṣàbójútó agboolé ìgbàgbọ́ lé lọ́wọ́. (Aísáyà 22:22; Lúùkù 1:32) Jésù fi kọ́kọ́rọ́ yẹn ṣí àǹfààní àti àwọn iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba náà sílẹ̀ fáwọn Kristẹni tó wà ní Filadẹ́fíà ìgbàanì àti láwọn ibòmíràn. Àtọdún 1919 ló ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá” tó ń ṣamọ̀nà sí wíwàásù Ìjọba náà, èyí tí alátakò kankan ò lè tì sílẹ̀ fún “olùṣòtítọ́ ìríjú” náà. (1 Kọ́ríńtì 16:9; Kólósè 4:2-4) Àmọ́ ṣá o, ilẹ̀kùn sí àwọn àǹfààní Ìjọba náà wà ní títì gbọn-in fún àwọn tó jẹ́ ti “inú sínágọ́gù Sátánì,” nítorí pé wọn kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí.
14. (a) Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà? (b) Báwo la ò ṣe ní ṣubú ní “wákàtí ìdánwò”?
14 Jésù ṣèlérí yìí fáwọn Kristẹni tó wà ní Filadẹ́fíà ìgbàanì pé: “Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Iṣẹ́ ìwàásù gba kéèyàn ní irú ìfaradà tí Jésù ní. Kò fìgbà kan juwọ́ sílẹ̀ fún ọ̀tá àmọ́ ó ń bá a lọ láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi jí Kristi dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Tá a bá dúró lórí ìpinnu wa láti jọ́sìn Jèhófà tá a sì kọ́wọ́ ti Ìjọba náà lẹ́yìn nípa wíwàásù ìhìn rere, a ò ní ṣubú ní àkókò ìdánwò tá a wà yìí, ìyẹn “wákàtí ìdánwò.” A ó ‘máa bá a lọ ní dídi ohun tá a ní mú ṣinṣin’ látọ̀dọ̀ Kristi nípa sísapá láti jẹ́ kí ire Ìjọba náà túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Ṣíṣe èyí yóò yọrí sí adé ṣíṣeyebíye ti òkè ọ̀run fún àwọn ẹni àmì òróró àti ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn adúróṣinṣin alábàákẹ́gbẹ́ wọn.
15. Kí la retí pé káwọn tó máa jẹ́ “ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run” ṣe?
15 Kristi fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun-ṣe ni èmi yóò fi í ṣe ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mi, . . . èmi yóò sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi àti orúkọ ìlú ńlá Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù tuntun tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti orúkọ mi tuntun yẹn sára rẹ̀.” Àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ alábòójútó gbọ́dọ̀ gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní títóótun láti jẹ́ ara “Jerúsálẹ́mù tuntun” nípa wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì wà ní mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí. Èyí ṣe pàtàkì gan-an bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì ti ọ̀run tá a ṣe lógo, tí wọ́n bá sì fẹ́ máa jẹ́ orúkọ ìlú ńlá ti Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn aráàlú rẹ̀ ti ọ̀run kí wọ́n sì máa jẹ́ orúkọ mọ́ Kristi gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀. Àti pé, láìsí àní-àní, wọ́n gbọ́dọ̀ ní etí tó ń “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”
Sí Áńgẹ́lì ní Laodíkíà
16. Kí làwọn kókó àlàyé díẹ̀ nípa Laodíkíà?
16 Jésù bá ìjọ Laodíkíà tí kì í ka nǹkan sí wí. (Ka Ìṣípayá 3:14-22.) Nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà sí ìhà ìlà oòrùn Éfésù, ní ìkóríta ọ̀nà táwọn oníṣòwò sábà máa ń gbà ní àfonífojì ọlọ́ràá ti Odò Lycus ni ìlú yìí wà. Laodíkíà jẹ́ ìlú aláásìkí tó ní àwọn ilé iṣẹ́ àtàwọn ilé ìfowópamọ́ nínú. Gbogbo èèyàn ló mọ àwọn ẹ̀wù tí wọ́n ń fi òwú dúdú tó wà lágbègbè yẹn hun. Nítorí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn lílókìkí kan tó wà ní Laodíkíà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ṣe oògùn ojú kan tí wọ́n ń pè ní àtíkè Phrygian níbẹ̀. Asclepius, ọlọ́run ìṣègùn, sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń sìn jù níbẹ̀. Ó dà bíi pé àwọn Júù pọ̀ gan-an ní Laodíkíà, àwọn kan lára wọn sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀.
17. Kí nìdí tá a fi bá àwọn ará Laodíkíà wí?
17 Nígbà tí Jésù ń bá ìjọ tó wà ní Laodíkíà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ “áńgẹ́lì” rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Kólósè 1:13-16) A bá àwọn ará Laodíkíà wí nítorí pé wọn ‘kò tutù bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbóná’ nípa tẹ̀mí. Nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ kò gbóná kò tutù yẹn, Kristi máa pọ̀ wọ́n jáde kúrò ní ẹnu rẹ̀. Kò yẹ kó ṣòro fún wọn láti lóye kókó yẹn rárá. Hirapólísì tó wà nítòsí wọn ní ìsun omi gbígbóná, Kólósè náà sì ní omi tútù. Àmọ́ nítorí pé páìpù ni wọ́n máa fi fa omi dé Laodíkíà láti ọ̀nà jíjìn, ó ṣeé ṣe kó ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́ nígbà tó bá fi máa dé ìlú ńlá náà. Ojú ìṣàn omi kan wà lára ọ̀nà tó máa ń gbà. Nígbà to bá kù díẹ̀ kó wọ Laodíkíà, á wá gba àárín pàlàpálá òkúta tó so pọ̀ mọ́ra wọn kọjá.
18, 19. Báwo la ṣe lè ran àwọn Kristẹni òde òní tí wọ́n dà bí àwọn ará Laodíkíà lọ́wọ́?
18 Àwọn tó dà bí àwọn ará Laodíkíà lóde òní ò gbóná lọ́nà tí n runi sókè bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ò tutù lọ́nà tó ń tuni lára. Bí omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ la ó ṣe tu àwọn náà jáde! Jésù ò fẹ́ kí wọ́n ṣe agbẹnusọ fún òun, gẹ́gẹ́ bí “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 5:20) Àyàfi kí wọ́n ronú pìwà dà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọ́n á pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba. Àwọn ará Laodíkíà ń gbìyànjú àtidi ọlọ́rọ̀ nínú ayé, wọn ‘ò mọ̀ pé akúùṣẹ́ làwọn àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.’ Láti bọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì, ipò ìfọ́jú, àti ìhòòhò tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí yẹn, lọ́dọ̀ Kristi ni ẹnikẹ́ni tó bá dà bíi tiwọn lónìí gbọ́dọ̀ ra “wúrà tí a fi iná yọ́ mọ́” ti ìgbàgbọ́ tí a ti dán wò, “ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun” ti òdodo, àti “oògùn ojú” tó ń jẹ́ kí ojú tẹ̀mí túbọ̀ mọ́lẹ̀ sí i. Àwọn Kristẹni alábòójútó múra tán láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn kí wọ́n lè di “ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Jákọ́bù 2:5; Mátíù 5:3) Síwájú sí i, àwọn alábòójútó tún ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo “oògùn ojú” nípa tẹ̀mí—ìyẹn ni pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkọ́ni, ìmọ̀ràn, àpẹẹrẹ, àti èrò Jésù, kí wọ́n sì mú un lò. Èyí jẹ́ ìwòsàn kúrò nínú “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.”—1 Jòhánù 2:15-17.
19 Gbogbo àwọn tí Jésù nífẹ̀ẹ́ ló ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà. Àwọn alábòójútó tó wà lábẹ́ rẹ̀ náà gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn ṣe ohun kan náà. (Ìṣe 20:28, 29) Àwọn ará Laodíkíà ní láti ‘jẹ́ onítara, kí wọ́n sì ronú pìwà dà,’ kí wọ́n yí padà nínú ìrònú wọn àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Tóò, ǹjẹ́ àwọn kan lára wa ti dẹni tí ọ̀nà ìgbésí ayé tó ń sọ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa sí Ọlọ́run di yẹpẹrẹ ti mọ́ lára? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ‘ra oògùn ojú lọ́dọ̀ Jésù’ ká lè rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti fi ìtara wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.—Mátíù 6:33.
20, 21. Àwọn wo ló ń kọ ìhà tó tọ́ sí kíkàn tí Jésù “ń kànkùn” lóde òní, kí sì ni ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà dè?
20 Kristi sọ pé: “Wò ó! Mo dúró lẹ́nu ilẹ̀kùn, mo sì ń kànkùn. Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tí ó sì ṣí ilẹ̀kùn, dájúdájú, èmi yóò wọ ilé rẹ̀, èmi yóò sì jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ àti òun pẹ̀lú mi.” Jésù sábà máa ń fúnni nítọ̀ọ́ni tẹ̀mí nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́. (Lúùkù 5:29-39; 7:36-50; 14:1-24) Ó wá ń kan ilẹ̀kùn àwọn ìjọ tó dà bíi ti Laodíkíà báyìí. Ǹjẹ́ àwọn tó wa níbẹ̀ á ṣílẹ̀kùn fún un, kí wọ́n mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un sọ jí, kí wọ́n kí i káàbọ̀ sáàárín wọn, kí wọ́n sì jẹ́ kó kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́? Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Kristi á bá wọn jẹun lọ́nà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní ńlá nípa tẹ̀mí.
21 Àwọn “àgùntàn mìíràn” òde òní ti ń jẹ́ kí Jésù wọlé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ń yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:34-40, 46) Ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan tó bá ṣẹ́gun ni Kristi yóò fún láǹfààní láti ‘jókòó pẹ̀lú rẹ̀ lórí ìtẹ́ rẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí òun náà ti ṣẹ́gun, tó sì jókòó pẹ̀lú Baba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Rẹ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù ti ṣèlérí èrè àgbàyanu ti fífún àwọn ẹni àmì òróró tó bá ṣẹ́gun ní ìtẹ́ kan lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀ lókè ọ̀run. Àwọn àgùntàn mìíràn tó bá ṣẹ́gun pẹ̀lú ń fojú sọ́nà de ibi àgbàyanu kan lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Gbogbo Wa Lè Kọ́
22, 23. (a) Báwo ni gbogbo Kristẹni ṣe lè jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn ìjọ méje náà? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
22 Kò sí àní-àní pé gbogbo Kristẹni ló lè jàǹfààní tó ga látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré. Bí àpẹẹrẹ, nípa kíkíyèsí bí Kristi ṣe gbóríyìn fún wọn níbi tó ti yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ náà á máa gbóríyìn fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn ìjọ tó bá ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí. Níbi tí àìlera bá wà, àwọn alàgbà máa ń ran àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn lọ́wọ́ láti wá ojútùú tó bá Ìwé Mímọ́ mu sí ọ̀ràn náà. Gbogbo wa la lè máa bá a lọ láti jàǹfààní látinú onírúurú apá tí ìmọ̀ràn tí Kristi fún àwọn ìjọ méjèèje náà ní, tá a bá sáà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà láìjáfara.a
23 Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí kì í ṣe àkókò láti dágunlá, kì í ṣe àkókò láti nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tàbí láti ṣe ohunkóhun mìíràn tó lè mú ká máa ṣe iṣẹ́ ìsìn tí kò tọkàn wa wá fún Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo ìjọ máa tàn yòò gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀pá fìtílà tí Jésù yóò fi sílẹ̀ sí àyè wọn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, ǹjẹ́ kí a máa pinnu láti pọkàn pọ̀ nígbà tí Kristi bá ń sọ̀rọ̀, ká sì fetí sílẹ̀ sí ohun tí ẹ̀mí ń sọ. Nígbà náà, la óò ní ayọ̀ pípẹ́ títí gẹ́gẹ́ bí atànmọ́lẹ̀ fún ògo Jèhófà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tún jíròrò ìwé Ìṣípayá 2:1–3:22 ní orí keje sí ìkẹtàlá ìwé Ìṣípayá–Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ta ni “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì,” kí sì nìdí táwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run ò fi ń fara wé e?
• Báwo ni ipò àwọn nǹkan ṣe rí nínú ìjọ tó wà ní Sádísì, kí la sì lè ṣe láti yẹra fún dídà bí ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó ń gbé níbẹ̀?
• Àwọn ìlérí wo ni Jésù ṣe fún ìjọ Filadẹ́fíà, báwo sì ni wọ́n ṣe kàn wá lónìí?
• Kí nìdí tá a fi bá àwọn ará Laodíkíà wí, àmọ́ kí làwọn Kristẹni onítara lè máa fojú sọ́nà fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A gbọ́dọ̀ yẹra fún ipa ọ̀nà búburú ti “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù ti ṣí “ilẹ̀kùn ńlá” tó ń ṣamọ̀nà sí àǹfààní Ìjọba sílẹ̀ níwájú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ǹjẹ́ ò ń gba Jésù sílé tó o sì ń fetí sílẹ̀ sí i?