-
Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
3. (a) Kí nìdí tí “áńgẹ́lì ìjọ tó wà ní Sádísì” fi ní láti fún jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ “ìràwọ̀ méje” ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀? (b) Ìmọ̀ràn líle wo ni Jésù fún ìjọ tó wà ní Sádísì?
3 Jésù tún rán “áńgẹ́lì ìjọ ní Sádísì” létí pé Òun lẹni tó ní “ìràwọ̀ méje.” Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ló fi di àwọn alàgbà ìjọ wọ̀nyẹn mú, ní ti pé òun ló ní àṣẹ láti darí wọn ní bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Wọ́n ní láti fi ọkàn wọn sí ‘bó ṣe yẹ kí wọ́n mọ ìrísí agbo ní àmọ̀dunjú.’ (Òwe 27:23) Fún ìdí yìí, kò sóhun tó dáa tó pé kí wọ́n fetí sílẹ̀ dáradára sí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó tẹ̀ lé e: “Máa kíyè sára, kí o sì fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun, nítorí èmi kò rí i pé ìwọ ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ ní kíkún níwájú Ọlọ́run mi. Nítorí náà, máa bá a lọ ní fífi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn, sì máa bá a lọ ní pípa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà. Dájúdájú, láìjẹ́ pé o jí, èmi yóò wá gẹ́gẹ́ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá ní ti wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.”—Ìṣípayá 3:2, 3.
4. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ Pétérù yóò ṣe ran ìjọ tó wà ní Sádísì lọ́wọ́ láti ‘fún àwọn ohun yòókù lókun’?
4 Ó pọn dandan pé káwọn alàgbà tó wà ní Sádísì rántí ayọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ ní nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti àwọn ìbùkún tí wọ́n rí gbà nígbà náà. Ṣùgbọ́n ní báyìí, wọ́n ti jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Fìtílà ìjọ wọn ń jó bàìbàì torí àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́ tí wọn ò ṣe mọ́. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà (tó ṣeé ṣe kó ní Sádísì nínú) láti túbọ̀ máa ní ìmọrírì fún ìhìn rere ológo táwọn Kristẹni gbà gbọ́ èyí tí “ẹ̀mí mímọ́ tí a rán jáde láti ọ̀run” polongo—gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ̀mí méje inú ìran Jòhánù túmọ̀ sí. Pétérù tún rán àwọn Kristẹni ara Éṣíà wọnnì létí pé wọ́n jẹ́ ‘ẹ̀yà ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí wọ́n lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni náà tí ó pè wọ́n jáde kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.’ (1 Pétérù 1:12, 25; 2:9) Ṣíṣe àṣàrò lórí irú àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì yìí á máa ran ìjọ tó wà ní Sádísì lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì “fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù . . . lókun.”—Fi wé 2 Pétérù 3:9.
5. (a) Báwo ni ẹ̀mí ìmọrírì táwọn Kristẹni tó wà ní Sádísì ní ṣe rí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó wà ní Sádísì bí wọn ò bá fi ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn sílò?
5 Ní báyìí ná, ìmọrírì àti ìfẹ́ wọn fún òtítọ́ dà bí iná tí ń kú lọ. Kìkì ìwọ̀nba ẹ̀ṣẹ́ná díẹ̀ ló kù tó ń tàn. Jésù fún wọn níṣìírí láti ko iná náà, ìyẹn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti inú èyí tí ìwà àìnáání wọn ti sìn wọ́n lọ, kí wọ́n sì di ìjọ tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. (Fi wé 2 Tímótì 1:6, 7.) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí Jésù bá dé lójijì—“gẹ́gẹ́ bí olè”—láti mú ìdájọ́ ṣẹ, àìròtẹ́lẹ̀ ló máa bá ìjọ tó wà ní Sádísì.—Mátíù 24:43, 44.
-
-
Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
7. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé káwa Kristẹni lónìí wà lójúfò?
7 Kristẹni ní láti wà lójúfò, èyí kò sì dópin ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fa kíki tí Jésù sọ èyí tó dá lórí “àmì ìgbà tí . . . gbogbo nǹkan wọ̀nyí” yóò ṣẹ, ó fúnni ní ìkìlọ̀ kan tó lágbára pé: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n . . . Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:4, 32, 33, 37) Bẹ́ẹ̀ ni o, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ yìí, dandan ni kí kálukú wa wà lójúfò ká sì rí i dájú pé a ò sùn ní ti ọwọ́ tá a fi mú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run yálà á jẹ ẹni àmì òróró tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá. Nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá dé “gẹ́gẹ́ bí olè ní òru,” ǹjẹ́ ká rí wa pé a wà lójúfò rekete ká bàa lè gba ìdájọ́ tó bára mu.—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3; Lúùkù 21:34-36; Ìṣípayá 7:9.
8. Ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí gbà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí láti túbọ̀ máa fi ọwọ́ tó yẹ mú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run?
8 Ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí fúnra rẹ̀ wà lójúfò, ó sì mọ̀ pé dandan ni kóun máa ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi ọwọ́ tó yẹ mú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Kó bàa lè ṣeé ṣe, a máa ń ṣètò àwọn àkànṣe àpéjọ jákèjádò ayé láwọn ìgbà mélòó kan lọ́dún. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n wá sí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó dín mọ́kàndínlógún [2,981] àpéjọ àgbègbè tá a ṣe jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méje ọ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìnlélógójì [10,953,744], a sì batisí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá ó lé ẹyọ kan [122,701]. Fún ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún, ẹgbẹ́ Jòhánù lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti kéde orúkọ Jèhófà àti ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Látàrí àwọn inúnibíni burúkú tí wọ́n ṣe sí wa lákòókò ogun àgbáyé méjèèjì, Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ bíi “Ìbùkún ni fún Àwọn Aláìbẹ̀rù” (1919), “Ìpè Láti Ṣe Ohun Tó Yẹ Ní Ṣíṣe” (1925), àti “Bíborí Inúnibíni” (1942) fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níṣìírí láti túbọ̀ fi ìtara ṣiṣẹ́ náà.
9. (a) Kí ló yẹ kí gbogbo Kristẹni máa béèrè lọ́wọ́ ara wọn? (b) Ìyànjú wo ni Ilé Ìṣọ́ ti fúnni?
9 Bó ṣe rí ní Sádísì, bẹ́ẹ̀ náà ló rí láwọn ìjọ lónìí, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwa Kristẹni rí i pé à ń ṣàyẹ̀wò ara wa. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ maa bi ara wa nígbà gbogbo pé: Ǹjẹ́ à ń ‘ṣe àwọn iṣẹ́ wa ní kíkún’ níwájú Ọlọ́run wa? Bá a ṣe ń sapá láti fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run, ǹjẹ́ àwa fúnra wa máa ń lo ara wa fáwọn ẹlòmíì láìdá wọn lẹ́jọ́? Lórí ọ̀ràn yìí, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti pèsè ọ̀rọ̀ ìyànjú nígbà tó jíròrò àwọn àkòrí bí “Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́” àti “Bí A Ò Ṣe Ní Wà Láàyè fún Ara Wa Mọ́.”a Pẹ̀lú irú àwọn ìrànlọ́wọ́ yìí látinú Ìwé Mímọ́, ẹ jẹ́ ká máa yẹ ọkàn wa wò bá a ṣe ń gbìyànjú láti máa rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ń gbàdúrà nínú ìwà títọ́ níwájú Jèhófà.—Sáàmù 26:1-3; 139:23, 24.
-