ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43
Jèhófà Nìkan Ṣoṣo Ni Kó O Máa Jọ́sìn
“Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.”—NÁH. 1:2.
ORIN 51 A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn?
JÈHÓFÀ nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun sì ni Olùfúnni-Ní-Ìyè wa. (Ìfi. 4:11) Àmọ́ ìṣòro kan wà tó dojú kọ wá. Lóòótọ́ a lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un, síbẹ̀ àwọn nǹkan kan wà tó lè dí wa lọ́wọ́ àtimáa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo. Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn nǹkan náà. Àmọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tó túmọ̀ sí láti máa jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo.
2. Bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 34:14, tá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà nìkan ṣoṣo, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ máa jọ́sìn Jèhófà nìkan, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. A ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun gba ipò àkọ́kọ́ nínú ọkàn wa.—Ka Ẹ́kísódù 34:14.
3. Kí nìdí tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà?
3 A ní ìdí tó pọ̀ tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ nípa Jèhófà, a sì ti wá mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀. A mọ àwọn nǹkan tó fẹ́ àtàwọn nǹkan tó kórìíra, àwa náà sì fara mọ́ ọn. A mọ ohun tó ní lọ́kàn fáwa èèyàn, pé ká wà láàyè títí láé ká sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Bákan náà, a mọyì àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sm. 25:14) Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan tá à ń kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Jém. 4:8.
4. (a) Kí ni Èṣù ń ṣe láti dín ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà kù? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Èṣù ló ń darí ayé burúkú yìí, ó sì ń lo àwọn nǹkan tí ọkàn wa sábà máa ń fà sí láti dọdẹ wa. (Éfé. 2:1-3; 1 Jòh. 5:19) Ohun tó fẹ́ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan míì kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè dín kù. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tó máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun àkọ́kọ́ ni ìfẹ́ owó, ìkejì sì ni eré ìnàjú tí Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí.
MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌFẸ́ OWÓ GBÀ Ẹ́ LỌ́KÀN
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra kí ìfẹ́ owó má lọ gbà wá lọ́kàn?
5 Gbogbo wa la fẹ́ máa rí oúnjẹ tó dáa jẹ, ká rí aṣọ tó bójú mu wọ̀, ká sì ní ilé tó dáa tá a lè máa gbé. Àmọ́ o, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí ìfẹ́ owó má lọ gbilẹ̀ lọ́kàn wa. Ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí ló “nífẹ̀ẹ́ owó” àtàwọn nǹkan tí owó lè rà. (2 Tím. 3:2) Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ owó, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Tẹ́nì kan bá ń sin Jèhófà tó sì tún ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ, ṣe lẹni náà ń sin ọ̀gá méjì. Ìdí sì ni pé Jèhófà nìkan kọ́ ló ń jọ́sìn mọ́.
6. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún ìjọ Laodíkíà?
6 Nígbà tó ku díẹ̀ kí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni parí, àwọn kan nínú ìjọ Laodíkíà ń fọ́nnu pé: “Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo ti kó ọrọ̀ jọ, mi ò sì nílò nǹkan kan.” Àmọ́ lójú Jèhófà àti Jésù, “akúṣẹ̀ẹ́ ni [wọ́n], ẹni téèyàn ń káàánú, òtòṣì, afọ́jú àti ẹni tó wà ní ìhòòhò.” Kì í ṣe torí pé wọ́n lówó lọ́wọ́ ni Jésù ṣe bá wọn wí, àmọ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Ìfi. 3:14-17) Táwa náà bá kíyè sí i pé gbogbo àkókò wa la fi ń wá bá a ṣe máa di olówó, a gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe sí i kó tó pẹ́ jù. (1 Tím. 6:7, 8) Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní lè sin Jèhófà tọkàntọkàn mọ́, Jèhófà ò sì ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, torí pé “òun nìkan ṣoṣo” ló fẹ́ ká máa jọ́sìn. (Diu. 4:24) Àmọ́, kí ló lè jẹ́ kí ìfẹ́ owó bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ lọ́kàn wa?
7-9. Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí alàgbà kan tó ń jẹ́ David?
7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ David, òṣìṣẹ́ kára ni, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sì ń gbé. Ó sọ pé òun máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an níbi tóun ti ń ṣiṣẹ́. Wọ́n fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, kódà orílẹ̀-èdè rẹ̀ gbà pé ó wà lára àwọn tó mọ iṣẹ́ yẹn jù. David sọ pé: “Nígbà yẹn, mo máa ń rò pé Jèhófà ló ń bù kún mi.” Àmọ́ ṣé òótọ́ ni ṣá?
8 Nígbà tó yá, David rí i pé iṣẹ́ yẹn ti ń jẹ́ kóun jìnnà sí Jèhófà. Ó sọ pé: “Tí mo bá wà nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí, ọ̀rọ̀ iṣẹ́ mi ni mo máa ń rò ṣáá. Lóòótọ́ owó ńlá ló ń wọlé fún mi, àmọ́ ilé mi ò tòrò, èmi náà ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ara mi.”
9 David wá rí i pé nǹkan míì lòun fi sípò àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Mo pinnu láti wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, ohun tí mo sì ṣe nìyẹn.” David lọ bá ẹni tó gbà á síṣẹ́, ó sì ṣàlàyé fún un pé òun fẹ́ ṣàtúnṣe sí bí òun ṣe ń ṣiṣẹ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀! Àmọ́ kí ni David ṣe? Ó sọ pé: “Ọjọ́ kejì ni mo gba fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó ń bá a lọ.” Kí wọ́n lè máa rówó gbọ́ bùkátà, David àti ìyàwó ẹ̀ ń bá àwọn èèyàn tún ilé ṣe. Kò pẹ́ sígbà yẹn, David bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyàwó ẹ̀ náà sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tó yá. Iṣẹ́ tí kò gbayì ni tọkọtaya yìí ń ṣe láti gbọ́ bùkátà, àmọ́ wọ́n gbà pé irú iṣẹ́ táwọn ń ṣe kọ́ ló ṣe pàtàkì jù. Tá a bá pín owó tí wọ́n ń gbà tẹ́lẹ̀ sọ́nà mẹ́wàá, ìdá kan péré ló ń wọlé fún wọn báyìí, síbẹ̀ kò sígbà tí wọn ò rówó gbọ́ bùkátà wọn. Wọ́n fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́, wọ́n sì ti wá rí i pé lóòótọ́ ni Jèhófà máa ń pèsè fún àwọn tó bá fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́.—Mát. 6:31-33.
10. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa?
10 Yálà a jẹ́ olówó tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà ẹ́ lọ́kàn. Má sì jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ gba ipò àkọ́kọ́ láyé rẹ, kí ìjọsìn Jèhófà wá gba ipò kejì. Báwo lo ṣe lè mọ̀ tírú ẹ̀ bá ti ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? O lè bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ọ̀rọ̀ iṣẹ́ mi ni mo máa ń rò tí mo bá wà nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí? Ṣé ọ̀rọ̀ bí màá ṣe rówó tó pọ̀ kó jọ kí n má bàa jìyà lọ́jọ́ ọ̀la ló máa ń gbà mí lọ́kàn? Ṣé owó àti nǹkan ìní máa ń fa wàhálà láàárín èmi àti ìyàwó tàbí ọkọ mi? Ṣé mo lè ṣe iṣẹ́ tó máa fún mi láyè láti sin Jèhófà tí kò bá tiẹ̀ gbayì?’ (1 Tím. 6:9-12) Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí, fi sọ́kàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì ti ṣèlérí fún gbogbo ẹni tó bá ń sìn ín tọkàntọkàn pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín.”—Héb. 13:5, 6.
FỌGBỌ́N YAN ERÉ ÌNÀJÚ TÍ WÀÁ MÁA ṢE
11. Kí ni eré ìnàjú lè sọ wá dì?
11 Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ara wa, eré ìnàjú sì wà lára ohun tá a fi máa ń gbádùn ara wa. Bíbélì náà sọ pé: “Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì gbádùn iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníw. 2:24) Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn eré ìnàjú tó wà lónìí ló lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Kì í jẹ́ káwọn èèyàn fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìṣekúṣe wò ó, ó sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra.
12. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:21, 22, kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n yan eré ìnàjú tá a máa ṣe?
12 Jèhófà nìkan la fẹ́ máa jọ́sìn, torí náà a ò lè máa “jẹun lórí tábìlì Jèhófà àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:21, 22.) Ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ la máa ń bá jẹun. Lọ́nà kan náà, tá a bá yan eré ìnàjú tó ní ìwà ipá nínú, ìbẹ́mìílò, ìṣekúṣe tàbí àwọn nǹkan míì tí kò dáa, ṣe là ń jẹ oúnjẹ táwọn ọ̀tá Ọlọ́run pèsè. Ìyẹn máa ṣàkóbá fún wa, àárín àwa àti Jèhófà ò sì ní gún mọ́.
13-14. (a) Ṣàlàyé bí eré ìnàjú ṣe jọra pẹ̀lú oúnjẹ. (b) Bó ṣe wà nínú Jémíìsì 1:14, 15, kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú tá a máa wò?
13 A lè fi eré ìnàjú wé oúnjẹ. Àwa fúnra wa la máa ń pinnu irú oúnjẹ tá a máa jẹ. Àmọ́ tá a bá ti lè jẹ oúnjẹ náà tá a sì gbé e mì, a ò lè pinnu bí oúnjẹ náà ṣe máa ṣiṣẹ́ lára wa. Tó bá sì yá, àwọn èròjà tó wà nínú ẹ̀ máa wọnú ara wa lọ. Tá a bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ara wa máa le dáadáa, tó bá sì jẹ́ oúnjẹ tí kò dáa là ń jẹ, ó máa ṣàkóbá fún ìlera wa. Lóòótọ́ a lè má tètè mọ̀, àmọ́ bó pẹ́ bó yá ó máa hàn.
14 Lọ́nà kan náà, a lè pinnu irú eré ìnàjú tá a máa wò. Àmọ́ ká má gbàgbé pé tá a bá ti wò ó tán, a ò lè pinnu ipa tó máa ní lórí wa. Tá a bá yan eré ìnàjú tó dáa, a máa gbádùn ẹ̀, àmọ́ tó bá jẹ́ pé èyí tí kò dáa la yàn láàyò, ó máa kó bá wa. (Ka Jémíìsì 1:14, 15.) A lè má tètè mọ àkóbá tó máa ṣe, àmọ́ bó pẹ́ bó yá ó máa hàn. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn. Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká; torí pé ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ara rẹ̀ máa ká ìdíbàjẹ́ látinú ara rẹ̀.” (Gál. 6:7, 8) Àbí ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká yẹra fún gbogbo eré ìnàjú tí Jèhófà kórìíra.—Sm. 97:10.
15. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti pèsè fún ìgbádùn wa?
15 Ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Jèhófà ló máa ń gbádùn JW Broadcasting® ìyẹn, Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marilyn sọ pé: “Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá ń wò ó torí kò sí nǹkan kan tó lè ṣàkóbá fún mi níbẹ̀. Nígbà tí mo bá dá wà tàbí tí inú mi ò dùn, mo máa ń gbọ́ àwọn àsọyé tàbí Ìjọsìn Òwúrọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn sì máa ń gbé mi ró gan-an. Ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀. Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ti jẹ́ kí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀.” Ṣé ìwọ náà ń jadùn ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí? Yàtọ̀ sí ètò tuntun tí wọ́n máa ń gbé jáde lóṣooṣù, ọ̀pọ̀ fídíò àtàwọn ohun tá a lè tẹ́tí sí ló wà lórí Tẹlifíṣọ̀n JW títí kan àwọn orin lóríṣiríṣi.
16-17. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ iye àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
16 Kì í ṣe irú eré ìnàjú tá à ń wò nìkan ló yẹ ká kíyè sí, ó tún yẹ ká kíyè sí iye àkókò tá à ń lò nídìí ẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, iye àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú máa pọ̀ ju èyí tá a fi ń jọ́sìn Jèhófà lọ. Ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti dín iye àkókò tí wọ́n ń lò nídìí eré ìnàjú kù. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Abigail tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún (18) sọ pé: “Tí mo bá délé tó sì ti rẹ̀ mí gan-an, tẹlifíṣọ̀n ni mo máa ń fi najú. Àmọ́ tí mi ò bá ṣọ́ra, mo lè lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí ẹ̀.” Arákùnrin Samuel tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) sọ pé: “Mo máa ń wo àwọn fídíò tí kò gùn púpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà míì, mo lè sọ pé fídíò kan péré ni mo fẹ́ wò, àmọ́ kí n tó mọ̀ wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin ti kọjá.”
17 Báwo lo ṣe lè dín iye àkókò tó ò ń lò nídìí eré ìnàjú kù? Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o mọ iye wákàtí tó ò ń lò nídìí ẹ̀. O ò ṣe gbìyànjú láti mọ iye àkókò tó o lò nídìí ẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ kan? Kọ iye wákàtí tó o lò nídìí tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì àti iye àkókò tó o lò nídìí géèmù sílẹ̀. Tíwọ náà bá rí i pé ọ̀pọ̀ wákàtí lò ń lò, gbìyànjú àbá yìí wò. Ṣe àkọsílẹ̀ bí wàá ṣe máa lo àkókò rẹ, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà ni kó o fi sípò àkọ́kọ́, ẹ̀yìn ìyẹn ni kó o wá pinnu iye àkókò tó o fẹ́ máa lò nídìí eré ìnàjú. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó o pinnu yìí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ọ̀pọ̀ àkókò àti okun tí wàá fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé, tí wàá sì fi lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, wàá túbọ̀ gbádùn eré ìnàjú, torí o mọ̀ pé o ti fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́.
JÈHÓFÀ NÌKAN NI KÓ O MÁA SÌN TÍTÍ LÁÉ
18-19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn?
18 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa bí ayé Sátánì yìí ṣe máa dópin àti bí ayé tuntun ṣe máa wọlé wá, ó ní: “Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pét. 3:14) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, tá a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn, a máa fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn.
19 Ojoojúmọ́ ni Sátánì ń wá bó ṣe máa mú káwọn nǹkan míì gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. (Lúùkù 4:13) Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Jèhófà la máa fi sípò àkọ́kọ́, a ò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun gba ipò rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé Jèhófà nìkan làá máa jọ́sìn!
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
a Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ ṣé òun nìkan là ń sìn? Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe ló máa jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò nǹkan méjì táá jẹ́ ká mọ̀ bóyá Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn.
b ÀWÒRÁN: Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ jẹ oúnjẹ tó ti bà jẹ́ tí wọ́n sè nínú ilé ìdáná tó dọ̀tí. Torí náà ṣó wá yẹ ká máa fi àwọn eré ìnàjú tó ní ìwà ipá, ìbẹ́mìílò àti ìṣekúṣe dára yá?