-
Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | October 1
-
-
Ọ̀nà Ipadabọ Kristi
3. Kí ni ọpọ eniyan gbagbọ nipa ipadabọ Kristi?
3 Gẹgẹ bi iwe naa An Evangelical Christology ti wi, “ìpadàwá ẹlẹẹkeji tabi ipadabọ Kristi (parousia) fidii ijọba Ọlọrun mulẹ, nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín, ni gbangba, ati fun gbogbo ayeraye.” Igbagbọ ti gbogbo eniyan dimu ni pe ipadabọ Kristi yoo ṣee fojuri ni gbangba wálíà, tí gbogbo eniyan ti ń gbé planẹti yii yoo rí i niti gidi. Lati ti èrò yii lẹhin, ọpọlọpọ ń tọka si Ìfihàn 1:7 (NW), eyi ti ó kà pe: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹlu awọsanma, gbogbo ojú ni yoo sì rí i, ati awọn wọnni ti wọn gún un ní ọ̀kọ̀.” Ṣugbọn ó ha tumọsi pe ẹsẹ yii ni a nilati loye ni olówuuru bi?
4, 5. (a) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Ìfihàn 1:7 ni a kò nilati tumọ ni èrò olowuuru? (b) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu funraarẹ ṣe fi ẹ̀rí òye yii hàn?
4 Ranti, iwe Ìfihàn ni a gbekalẹ “nipa awọn àmì.” (Ìfihàn 1:1, NW) Nigba naa, àyọkà-ọ̀rọ̀ yii, gbọdọ jẹ́ afiṣapẹẹrẹ; ó ṣetan, bawo ni “awọn wọnni ti wọn gún un ní ọ̀kọ̀” ṣe lè rí ipadabọ Kristi? Wọn ti kú ni ohun tí ó fẹrẹẹ tó ọrundun lọna 20! Siwaju sii, awọn angẹli sọ pe Kristi yoo padabọ “ni iru ọ̀nà kan-naa” bi o ti lọ. Ó dara, ọ̀nà wo ni ó gbà lọ? Pẹlu araadọta-ọkẹ tí ń wò ó ni bi? Bẹẹkọ, iwọnba awọn oluṣotitọ diẹ pere ni wọn rí iṣẹlẹ naa. Nigba ti angẹli naa sì bá wọn sọrọ, awọn aposteli naa ha ń wo Kristi tí ń rinrin-ajo taarata lọ si ọrun niti gidi bi? Bẹẹkọ, bíbò ti awọsanma bo Jesu mú ki o pòórá mọ́ wọn loju. Ni akoko kan lẹhin ìgbà naa, oun ti nilati wọnu awọn ọrun tẹmi lọ gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi kan, ti kò ṣee fojuri fun eniyan. (1 Korinti 15:50) Nitori naa, patapata, awọn aposteli naa rí kìkì ibẹrẹ irin-ajo Jesu; wọn kò lè rí opin rẹ̀, ipadabọ rẹ̀ si iwaju Baba rẹ̀ lọrun, Jehofa. Eyi ni wọn lè foye mọ̀ kìkì pẹlu oju igbagbọ wọn.—Johannu 20:17.
5 Bibeli kọni pe Jesu ń padabọ ni ọ̀nà ti ó rí bakan-naa gan-an. Jesu funraarẹ sọ ni kété ṣaaju ikú rẹ̀ pe: “Nigba diẹ sii, ayé kì ó sì rí mi mọ́.” (Johannu 14:19) Ó tun sọ pe “ijọba Ọlọrun kò ní wá pẹlu ṣíṣeékíyèsí tí ń pàfiyèsí.” (Luku 17:20, NW) Ni èrò itumọ wo, nigba naa, ni ‘gbogbo oju yoo rí i’? Lati dahun, a kọ́kọ́ nilo òye kedere nipa ọ̀rọ̀ ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lò ni isopọ pẹlu ipadabọ rẹ̀.
6. (a) Eeṣe ti awọn ọ̀rọ̀ bii “ipadabọ,” “dídé,” “bíbọ̀wá,” ati “ìpadàwá” kìí fií ṣe itumọ kikunrẹrẹ ti o bá ọ̀rọ̀ Griki naa pa·rou·siʹa mu? (b) Kí ni o fihàn pe pa·rou·siʹa, tabi “wíwàníhìn-ín,” pẹ́ pupọ ju iṣẹlẹ onigba kukuru gan-an lasan lọ?
6 Otitọ naa ni pe, Kristi ṣe pupọ pupọ ju wiwulẹ “padabọ.” Ọ̀rọ̀ yẹn, bii “ìpadàwá,” “dídé,” tabi “bíbọ̀wá,” dọgbọn tumọsi iṣẹlẹ kanṣoṣo ni ìgbà kukuru gan-an. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ Griki naa ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lò tumọsi ohun ti ó pọ̀ jù bẹẹ lọ. Ọ̀rọ̀ naa ni pa·rou·siʹa, ti o tumọ ní olówuuru si “wíwà ni ìhà-ẹ̀gbẹ́” tabi “wíwàníhìn-ín.” Ọpọ julọ ninu awọn ọmọwe fohunṣọkan pe ọ̀rọ̀ yii ni ninu kìí ṣe kìkì dídé nikan bikoṣe wíwàníhìn-ín tí ó tẹle e pẹlu—gẹgẹ bii ti ibẹwo ọlọla-ọba Orilẹ-ede kan. Wíwàníhìn-ín yii kìí ṣe iṣẹlẹ onigba kukuru gan-an; sanmani akanṣe kan ni, sáà akoko kan ti a sàmì sí ni. Ni Matteu 24:37-39 (NW), Jesu sọ pe “wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Ọmọkunrin eniyan” yoo dabi “awọn ọjọ Noa” eyi ti ó pari sí Ikun-omi. Noa ń kan ọkọ̀ áàkì ó sì ń kilọ fun awọn eniyan buburu fun ọpọ ẹwadun ṣaaju ki Ikun-omi naa tó dé ti ó sì gbá eto igbekalẹ ayé oniwa-palapala yẹn lọ. Bẹẹ gẹgẹ, nigba naa, wíwàníhìn-ín alaiṣeefojuri ti Kristi wà fun ohun ti o ju sáà ọpọ ẹwadun lọ ṣaaju ki ó tó pari sí iparun ńláǹlà pẹlu.
7. (a) Kí ni fihàn pe pa·rou·siʹa naa ni eniyan kò le fojuri? (b) Bawo ati nigba wo ni imuṣẹ yoo deba awọn ẹsẹ iwe mimọ ti o ṣapejuwe ipadabọ Kristi gẹgẹ bi eyi ti “gbogbo oju” yoo rí?
7 Laiṣiyemeji, pa·rou·siʹa naa kò ṣeefojuri niti gidi fun oju eniyan. Bi ó bá rí bẹẹ ni, eeṣe ti Jesu yoo fi lo akoko pupọ tobẹẹ, gẹgẹ bi awa yoo ṣe rí i, ní fifun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni àmì lati ràn wọ́n lọwọ lati foyemọ wíwàníhìn-ín yii?a Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Kristi bá wá lati pa eto igbekalẹ ayé Satani run, otitọ wíwàníhìn-ín rẹ̀ ni yoo farahan fun gbogbo eniyan lọna ti o pabambari. Nigba naa ni “gbogbo oju yoo rí i.” Àní awọn alatako Jesu paapaa yoo lè foyemọ, si ìdààmú araawọn, pe iṣakoso Kristi jẹ́ otitọ gidi.—Wo Matteu 24:30; 2 Tessalonika 2:8; Ìfihàn 1:5, 6.
-
-
Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | October 1
-
-
a Pada sẹhin ni 1864 R. Govett ẹlẹkọọ-isin sọ ọ́ ni ọ̀nà yii: “Lójú temi eyi dabii ohun ti o ṣe pàtó gan-an. Fifunni ni àmì Wíwàníhìn-ín fihàn pe aṣiri ni. A kò nilo àmì ìtọ́ka kankan lati sọ wíwàníhìn-ín ohun ti a rí di mímọ̀ fun wa.”
-