ORÍ KẸRIN
“Wò Ó! Kìnnìún Tí Ó Jẹ́ ti Ẹ̀yà Júdà”
1-3. Inú ewu wo ni Jésù bá ara rẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣe?
ÀWỌN jàǹdùkú kan ń wá Jésù bọ̀. Wọ́n pọ̀ bí eéṣú, wọ́n kó idà àti ọ̀gọ dání, àwọn ọmọ ogun sì wà lára wọn. Rìkíṣí ló pa wọ́n pọ̀, àárín òru ni gbogbo wọn sì gbéra kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n gba Àfonífojì Kídírónì yọ sí Òkè Ólífì. Pẹ̀lú bí òṣùpá ṣe mọ́lẹ̀ rekete tó, wọ́n tún gbé ògùṣọ̀ àti fìtílà dání. Ṣé pé ìkùukùu bo òṣùpá lójú tí wọn ò sì lè ríran ni wọ́n ṣe gbéná dání ni? Àbí wọ́n rò pé ẹni tí àwọn ń dọdẹ rẹ̀ lọ lè mù sínú òkùnkùn? Bá ò tiẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi gbéná dání, ohun kan dájú: Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé Jésù á ṣojo, a jẹ́ pé onítọ̀hún ò tíì mọ ẹni tó ń jẹ́ Jésù.
2 Jésù mọ̀ pé ewu rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Síbẹ̀ ó dúró dè wọ́n. Àwọn jàǹdùkú náà ń sún mọ́ tòsì, Júdásì tí Jésù fọkàn tán ló ń kó wọn bọ̀. Pẹ̀lú ìwà ọ̀dájú ni Júdásì fi da Jésù, ó fi í hàn lọ́nà àgàbàgebè nígbà tó fi ẹnu ko ọ̀gá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ yìí lẹ́nu. Síbẹ̀ Jésù ò bara jẹ́. Ẹ̀yìn èyí ló wá jáde sí àwọn jàǹdùkú náà. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárétì ni.”
3 Èyí tó pọ̀ lára àwọn èèyàn láá ti máa tọ̀ sára bó bá jẹ́ pé àwọn nirú àwọn jàǹdùkú bẹ́ẹ̀ ń wá bọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn ogunlọ́gọ̀ náà retí nìyẹn. Ṣùgbọ́n Jésù ò gbọ̀n níwájú wọn, kò sá, kò sì tìtorí ìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í tò bòròbòrò bí ẹní ń wá irọ́ tó máa pa. Dípò ìyẹn, ńṣe ló kàn sọ pé “Èmi ni ẹni náà.” Ọ̀nà tó gbà fèsì yìí fi hàn pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀, ó ní ìgboyà, débi tó fi jọ àwọn tó wá mú un lójú. Wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lura wọn!—Jòhánù 18:1-6; Mátíù 26:45-50; Máàkù 14:41-46.
4-6. (a) Kí la lè fi ìgboyà Ọmọ Ọlọ́run wé, kí sì nìdí? (b) Ọ̀nà mẹ́ta wo ni Jésù gbà jẹ́ onígboyà?
4 Kí ló mú kí Jésù lè kojú irú ewu dẹdẹ bẹ́ẹ̀ tọ́kàn rẹ̀ sì balẹ̀ digbí tó sì tún lè kó ara rẹ̀ níjàánu? Lọ́rọ̀ kan, ìgboyà ni. Ó jẹ́ ànímọ́ pàtàkì kan tó yẹ kí ẹni tó bá máa jẹ́ aṣáájú ní. Kò sì tíì sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó ní ìgboyà tó Jésù, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ẹnì kan á nígboyà jù ú lọ. Ní Orí 3 tá a kà kọjá, a kọ́ nípa bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni pẹ̀lẹ́ tó. Ìdí nìyẹn tó fi tọ́ láti pè é ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn.” (Jòhánù 1:29) Àmọ́, ọ̀nà míì wà tá a lè gbà ṣàpèjúwe irú ìgboyà tí Jésù ní yìí. Bíbélì sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run pé: “Wò ó! Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà.”—Ìṣípayá 5:5.
5 A sábà máa ń fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìgboyà. Ǹjẹ́ o ti dúró níwájú akọ kìnnìún rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé inú àkámọ́ tó wà nínú ọgbà ẹranko ni wọ́n fi ẹranko ẹhànnà yìí sí, tí ìwọ sì wà lódìkejì. Pẹ̀lú ìyẹn náà, kì í ṣe pé kẹ́rù má máa bà ọ́. Bó o ṣe ń wo ojú ẹranko ńlá tó lágbára púpọ̀ yìí tóun náà sì ń wò ẹ́ ṣùn-ùn, o ò ní rò ó láéláé pé nǹkan kan lè dẹ́rù ba kìnnìún tó ò ń wò yìí débi tó fi máa sá. Bíbélì sọ pé kìnnìún ni “alágbára ńlá jù lọ láàárín àwọn ẹranko, tí kì í sì í yí padà kúrò níwájú ẹnikẹ́ni.” (Òwe 30:30) Irú ìgboyà tí Kristi ní nìyẹn.
6 Ọ̀nà mẹ́ta ni Jésù gbà fi ìgboyà tó jọ ti kìnnìún hàn. Ọ̀nà kìíní ni bó ṣe dúró lórí òtítọ́; ọ̀nà kejì ni bó ṣe ń ṣẹ̀tọ́; ọ̀nà kẹta sì ni ti bó ṣe kojú àtakò. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Ká tún wá wo bí àwa náà ṣe lè fìwà jọ Jésù nípa jíjẹ́ onígboyà, láìwo ti pé a láyà tàbí pé a ò láyà.
Ó Fìgboyà Dúró Lórí Òtítọ́
7-9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, kí ló sì mú kó o rò pé ó lè kà ọ́ láyà ká ní ìwọ ni? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ìgboyà hàn nígbà tó ń bá àwọn olùkọ́ inú tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀?
7 Nínú ayé tí Sátánì “baba irọ́” ń ṣàkóso yìí, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè dúró lórí òtítọ́. (Jòhánù 8:44; 14:30) Jésù ò dúró kóun dàgbà kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lórí òtítọ́. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àjọyọ̀ Ìrékọjá tí wọ́n lọ ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni Màríà àti Jósẹ́fù fi ń wá a káàkiri. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì. Ẹ̀ bá béèrè pé kí ló ń ṣe níbí tí wọ́n ti rí i. Ńṣe ló “jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” (Lúùkù 2:41-50) Ìwọ náà wo irú àwọn tó wà níbi ìjíròrò yẹn.
8 Àwọn òpìtàn sọ pé àwọn kan lára àwọn lóókọlóókọ láàárín àwọn aṣáájú ìsìn sábà máa ń dúró sínú tẹ́ńpìlì lẹ́yìn àjọyọ̀ láti lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ibi ìloro fífẹ̀ tó wà níbẹ̀. Àwọn èèyàn á jókòó sẹ́bàá ẹsẹ̀ wọn, wọ́n á sì máa bi wọ́n ní ìbéèrè. Àwọn olùkọ́ wọ̀nyí mọ jẹ̀jẹ̀rẹ̀ ìwé. Ìjìmì ni wọ́n nínú Òfin Mósè, wọn ò sì kẹ̀rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ àìlóǹkà àwọn òfin àdáṣe àtàwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n ti ń kó jọ látọdúnmọdún. Ká ní ìwọ lo jókòó sáàárín irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Ṣé àyà rẹ ò ní máa já? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó ṣeé ṣe kí àyà rẹ já. Ká wá sọ pé ọmọ ọdún méjìlá péré ni ọ́ ńkọ́? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lojú máa ń tì. (Jeremáyà 1:6) Gbogbo ohun táwọn ọ̀dọ́ kan bá lè ṣe ni wọ́n máa ń ṣe láti rí i pé àwọn olùkọ́ àwọn nílé ẹ̀kọ́ ò mọ àwọn; irú àwọn wọ̀nyí ń bẹ̀rù kí wọ́n má lọ ní káwọn sọ nǹkan kan, kí wọ́n má lọ máa fojú sáwọn lára, àti pé káwọn má lọ tibẹ̀ dẹni yẹ̀yẹ́ tàbí ẹni ẹ̀gàn.
9 Àmọ́ Jésù rèé tó jókòó sáàárín àwọn ọ̀mọ̀wé tó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè tó lè mú wọn ronú jinlẹ̀. Kódà ó tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àkọsílẹ̀ náà fi yé wa pé: “Gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” (Lúùkù 2:47) Bíbélì ò sọ àwọn ohun tó sọ níbẹ̀ yẹn fún wa, àmọ́ ó dá wa lójú pé kò jẹ́ bá wọn ṣàpọ́nlé ẹ̀kọ́ èké táwọn olùkọ́ òfin yẹn fi ń kọ́ àwọn èèyàn. (1 Pétérù 2:22) Kò bá wọn tú irọ́ tà rárá, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló dúró tì, ìyẹn ló ṣe ya àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lẹ́nu pé ọmọ ọdún méjìlá péré lè máa fi irú òye àti ìgboyà bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ kalẹ̀.
10. Ọ̀nà wo làwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lónìí gbà ní ìgboyà bíi Jésù?
10 Lónìí, ẹgbàágbèje ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ohun kan ni pé wọn kì í ṣe ẹni pípé bíi tí Jésù. Àmọ́ bíi ti Jésù, àwọn náà ò dúró dìgbà tí wọ́n bá di àgbàlagbà kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lórí òtítọ́. Níléèwé wọn tàbí ládùúgbò wọn, wọ́n máa ń lo òye nígbà tí wọ́n bá ń bi àwọn èèyàn ní ìbéèrè tí wọ́n sì ń fetí sílẹ̀, wọ́n sì máa ń wàásù òtítọ́ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (1 Pétérù 3:15) Lápapọ̀, àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ti ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ọmọ iléèwé bíi tiwọn, àwọn olùkọ́ wọn àtàwọn aládùúgbò wọn láti lè máa tẹ̀ lé Kristi. Ẹ wo bí ìgboyà wọn yẹn á ti ṣe máa mú inú Jèhófà dùn tó! Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pe irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ní ìrì tó ń sẹ̀, tó ń tuni lára, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì lóǹkà.—Sáàmù 110:3.
11, 12. Báwo ni Jésù ṣe fi ìgboyà dúró lórí òtítọ́ nígbà tó dàgbà?
11 Nígbà tí Jésù sì tún dàgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń fi ìgboyà dúró lórí òtítọ́. Kódà nígbà tó máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àtakò tó lè mú kéèyàn sọ pé òun ò ṣe mọ́ ló kọ́kọ́ bá pàdé. Ẹ má gbàgbé pé nígbà yẹn kì í ṣe olú-áńgẹ́lì mọ́ bí kò ṣe èèyàn ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀. Pẹ̀lú ìyẹn náà ló kojú Sátánì, ẹ̀dá tó tíì lágbára jù lọ tó sì ya olubi jù lọ lára àwọn ọ̀tá Jèhófà. Jésù kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tí Sátánì fẹ́, kò sì gbà fún un láti jẹ́ kó tú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí sọ́nà òdì. Jésù fòpin sí ìjíròrò náà láìṣojo pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!”—Mátíù 4:2-11.
12 Nípa báyìí, Jésù fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tìgboyàtìgboyà ló fi kọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti lọ́ Ọ̀rọ̀ Bàbá rẹ̀ lọ́rùn tàbí láti lò ó nílòkulò. Báwọn onísìn ṣe ń fi dúdú pe funfun nígbà yẹn náà ni wọ́n ṣì ń ṣe lónìí. Jésù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn lákòókò yẹn pé: “Ẹ . . . sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín tí ẹ fi léni lọ́wọ́.” (Máàkù 7:13) Ńṣe làwọn èèyàn máa ń wárí fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn, ṣùgbọ́n Jésù ò bẹ̀rù láti bẹnu àtẹ́ lù wọ́n torí pé wọ́n jẹ́ afọ́jú amọ̀nà àti alágàbàgebè.a (Mátíù 23:13, 16) Báwo la ṣe lè máa fìgboyà hàn nírú ọ̀nà tí Jésù gbà fi hàn yìí?
13. Kí la ò gbọ́dọ̀ gbàgbé bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, síbẹ̀ àǹfààní wo la ní?
13 A ò ní gbàgbé pé àwa ò ní agbára tí Jésù ní láti mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ẹlòmíì, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní àṣẹ tó ní láti dájọ́. Síbẹ̀ náà, a ṣì lè dúró lórí òtítọ́ láìṣojo bíi tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bá a bá ń tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké tí ìsìn fi ń kọ́ni, ìyẹn àwọn irọ́ kan tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa Ọlọ́run, nípa ohun tó fẹ́ ṣe àti nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ńṣe là ń tànmọ́lẹ̀ sínú ayé táwọn irọ́ Sátánì ti mú kó ṣókùnkùn. (Mátíù 5:14; Ìṣípayá 12:9, 10) A tún ń tipa bẹ́ẹ̀ tú àwọn èèyàn sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú tí ẹ̀kọ́ èké ti fi wọ́n sí, èyí tó mú kí ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì gbà wọ́n lọ́kàn, tó sì tún ti ba àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run jẹ́. Àǹfààní kékeré kọ́ la ní láti rí bí ohun tí Jésù sọ ṣe ń nímùúṣẹ, pé: “Òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira”!—Jòhánù 8:32.
Ó Ń Fìgboyà Ṣe Ẹ̀tọ́
14, 15. (a) Kí ni ọ̀nà kan tí Jésù gbà mú kí “ohun tí ìdájọ́ òdodo,” tàbí ẹ̀tọ́ jẹ́ ṣe kedere? (b) Ẹ̀tanú wo ni Jésù ò tẹ̀ lé tó fi lè bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀?
14 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi yé wa pé Mèsáyà máa jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè mọ “ohun tí ìdájọ́ òdodo,” tàbí ẹ̀tọ́ jẹ́. (Mátíù 12:18; Aísáyà 42:1) Orí ilẹ̀ ayé ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ. Pẹ̀lú ìgboyà tírú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n, gbogbo ìgbà ló máa ń rí i pé òun ṣe ẹ̀tọ́ fáwọn èèyàn, kì í sì í ṣègbè. Bí àpẹẹrẹ, kò bá wọn lọ́wọ́ sí ẹ̀tanú àti ìtara òdì tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, èyí tó wọ́pọ̀ láyé ìgbà yẹn.
15 Ẹnu ya àwọn ọmọ ẹyìn Jésù nígbà tó ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ nídìí kànga Síkárì. Kí ló yà wọ́n lẹ́nu ńbẹ̀? Ìdí ni pé, nígbà yẹn àwọn Júù kì í bá àwọn Samáríà ṣe; ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ látọdún gbọ́nhan. (Ẹ́sírà 4:4) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn rábì ò fojú èèyàn gidi wo àwọn obìnrin. Àwọn rábì ní àwọn òfin kan tí wọ́n wá kọ sílẹ̀ nígbà tó yá. Ó wà nínú àwọn òfin wọ̀nyẹn pé ọkùnrin èyíkéyìí ò ní láti bá obìnrin sọ̀rọ̀; wọ́n tiẹ̀ sọ pé àwọn obìnrin ò yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń kọ́ ní Òfin Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ará Samáríà tiẹ̀ tún yọyẹ́, torí aláìmọ́ ni wọ́n ka gbogbo ará Samáríà sí. Jésù ò tẹ̀ lé irú ẹ̀tanú tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu yìí, ó sì kọ́ obìnrin Samáríà (tó tún jẹ́ oníṣekúṣe) yẹn lẹ́kọ̀ọ́, kódà ó fi ara rẹ̀ hàn fún un gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.—Jòhánù 4:5-27.
16. Kí nìdí tó fi pọn dandan fáwọn Kristẹni láti ní ìgboyà tò bá dọ̀rọ̀ ẹ̀tanú?
16 Ǹjẹ́ o ti bára rẹ láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n ní ẹ̀tanú kíkorò rí? Bóyá ṣe ni wọ́n máa ń fi àwọn ẹ̀yà tàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n máa tẹ́ńbẹ́lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn tàbí kí wọ́n fojú burúkú wo àwọn tí ò rí já jẹ tàbí tí ò sí nípò kan náà bíi tiwọn. Àwọn tó ń tọ Kristi lẹ́yìn kì í báwọn lọ́wọ́ sírú àṣà ìkórìíra bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń rí i pé àwọn ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti fa ẹ̀tanú yòówù kó wà lọ́kàn àwọn fúnra wọn tu kúrò. (Ìṣe 10:34) Gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ ní ìgboyà tó máa jẹ́ ká lè máa bá gbogbo èèyàn lò lọ́nà tó tọ́.
17. Ìgbésẹ̀ wo ni Jésù gbé nínú tẹ́ńpìlì, kí sì nìdí?
17 Ìgboyà tún mú kí Jésù jà fitafita láti rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti wà ní mímọ́, ó sì rí i pé ìṣètò tó wà fún ìjọsìn mímọ́ ò yingin. Níbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó wọnú ọgbà tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, inú sì bí i nígbà tó rí àwọn oníṣòwò àtàwọn onípàṣípààrọ̀ owó tí wọ́n ń ṣòwò ní ilé Ọlọ́run. Ìfẹ́ fún òdodo mú kó bínú, ó sì taari àwọn oníṣòwò oníwọra yẹn àtàwọn ọjà wọn síta. (Jòhánù 2:13-17) Nígbà tó yá, tó kù díẹ̀ kó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó tún ṣe irú nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. (Máàkù 11:15-18) Àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé wọ̀nyí mú kó di ọ̀tá àwọn alágbára, síbẹ̀ kò mikàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé àtikékeré ló ti pe tẹ́ńpìlì yẹn ní ilé Bàbá òun, ìṣe rẹ̀ sì fi hàn bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 2:49) Ìwà àìṣẹ̀tọ́ ni tí wọ́n bá sọ ìjọsìn mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì di eléèérí, Jésù ò sì ní fàyè gba irú ìwà bẹ́ẹ̀.
18. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè lo ìgboyà tó bá dọ̀rọ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́?
18 Bákan náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi òde òní máa ń rí i pé ní gbogbo ọ̀nà, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wà ní mímọ́ àti pé ìṣètò tó wà fún ìjọsìn mímọ́ kò yingin. Bí wọ́n bá rí i pé Kristẹni bíi tiwọn kan hu ìwà àìtọ́ tó burú jáì, wọn kì í fojú pa á rẹ́. Tìgboyàtìgboyà ni wọ́n máa bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n fi tó àwọn alàgbà ìjọ létí. (1 Kọ́ríńtì 1:11) Wọ́n á rí i dájú pé àwọn alàgbà ìjọ gbọ́ sí i. Àwọn alàgbà lè ran àwọn tó bá ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́, wọ́n sì tún máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti rí i pé àwọn àgùntàn Jèhófà wà ní mímọ́.—Jákọ́bù 5:14, 15.
19, 20. (a) Àwọn àìṣẹ̀tọ́ wo ló wọ́pọ̀ láyé Jésù, kí làwọn èèyàn sì fẹ́ kó ṣe? (b) Kí nìdí táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kì í fi í ṣe òṣèlú tí wọn kì í sì í fi í bá wọn hùwà ipá, èrè wo ni wọ́n sì ti rí nídìí rẹ̀?
19 Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé gbogbo àìṣẹ̀tọ́ tó wà láyé nígbà yẹn ni Jésù gbógun tì? Rárá o, ọ̀pọ̀ àìṣẹ̀tọ́ ló ń ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ̀ nígbà yẹn. Abẹ́ ìjọba ilẹ̀ òkèèrè ni ìlú tí wọ́n ti bí i wà. Àwọn ará Róòmù ń fi ọmọ ogun wọn tẹ àwọn Júù lórí ba, wọ́n ń bu owó orí tó ju agbára wọn lọ lé wọn lórí, kódà wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe ẹ̀sìn wọn bó ṣe wù wọ́n. Ìyẹn ni ò ṣe yà wá lẹ́nu pé èyí tó pọ̀ lára wọn ń fẹ́ kí Jésù di olóṣèlú. (Jòhánù 6:14, 15) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó gba ìgboyà kó tó lè sọ pé òun ò ṣe.
20 Jésù ṣàlàyé pé Ìjọba òun kò pa pọ̀ mọ́ ti ayé yìí. Látinú àpẹẹrẹ rẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìjà òṣèlú, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run làwọn gbọ́dọ̀ gbájú mọ́. (Jòhánù 17:16; 18:36) Ó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kan tó rinlẹ̀ nígbà táwọn jàǹdùkú fẹ́ wá fòfin ìjọba gbé e. Ojú ẹsẹ̀ ni Pétérù ti hùwà akin, láìronújinlẹ̀ ó yọ idà rẹ̀, ó sì ṣe ọkùnrin kan léṣe. Ó rọrùn láti lóye ohun tó wà lọ́kàn Pétérù. Bí àkókò kan bá wà tó yẹ kéèyàn hùwà ipá, òru ọjọ́ yẹn ló gbọ́dọ̀ jẹ́, ìyẹn lóru ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ gbé Ọmọ Ọlọ́run tí ò mọwọ́ mẹ́sẹ̀. Síbẹ̀, níbẹ̀ yẹn ni Jésù ti fi ìlànà kan lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé, kódà títí dòní. Jésù sọ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:51-54) Bó ṣe gba ìgboyà fáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi láti má ṣe gbèjà ara wọn nígbà yẹn ló gba ìgboyà fáwọn Kristẹni òde òní pẹ̀lú. Torí pé àwọn Kristẹni kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ọwọ́ wọn ò sí nínú àìmọye ogun, ìpakúpa rẹpẹtẹ, ìwọ́de, àtàwọn ìwà jàgídíjàgan èyíkéyìí. Báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ní orúkọ rere yìí kò ṣẹ̀yìn ìgboyà tí wọ́n ní.
Ó Fìgboyà Kojú Àtakò
21, 22. (a) Ìrànlọ́wọ́ wo ni Jésù rí gbà nígbà tó kù díẹ̀ kó bẹ̀rẹ̀ sí í kojú àwọn èyí tó le jù nínú àdánwò rẹ̀? (b) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ onígboyà títí dópin?
21 Ọmọ Jèhófà mọ̀ lámọ̀dájú pé òun á kojú àtakò tó gbóná janjan lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 50:4-7) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sún mọ́ bèbè ikú, bí irú èyí tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ onígboyà síbẹ̀ lójú gbogbo ewu wọ̀nyẹn? Ó dáa, kí ni Jésù ń ṣe nígbà táwọn jàǹdùkú yẹn dé láti fi àṣẹ ọba mú un? Ṣe ló ń gbàdúrà sí Jèhófà kíkankíkan. Kí sì ni Jèhófà ṣe? Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà “gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere.” (Hébérù 5:7) Jèhófà rán áńgẹ́lì kan látọ̀run pé kó fún Ọmọ rẹ̀ tó láyà yìí lókun.—Lúùkù 22:42, 43.
22 Kò pẹ́ tí áńgẹ́lì yẹn fún Jésù lókun ni Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ.” (Mátíù 26:46) Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé gbólóhùn yìí fi ìgboyà hàn. Ó ní “ẹ jẹ́ kí a lọ,” láìṣe pé kò mọ̀ pé òun máa ní láti sọ fáwọn jàǹdùkú tó ń bọ̀ pé kí wọ́n má ṣe fọwọ́ kan àwọn ọ̀rẹ́ òun, tí kò sì ṣàìmọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun yẹn á pa òun tì tí wọ́n á sá lọ̀, tó sì tún mọ̀ pé òun àti etí òun nìkan ló máa kù láti kojú ìṣòro tó máa nira jù lọ fún òun láti fara dà láyé òun. Ńṣe ló dá kojú ìgbẹ́jọ́ èrú tí ò bófin mu yẹn, ó dá kojú ẹ̀sín, ìdálóró àti ikú oró yẹn. Nínú gbogbo ìṣòro wọ̀nyẹn náà, Jésù jẹ́ onígboyà.
23. Ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe pé Jésù wulẹ̀ fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nínú ọ̀nà tó gbà kojú ewu àti ikú tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí rẹ̀.
23 Ṣé kì í ṣe pé Jésù wulẹ̀ ń fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu? Rárá o; ọ̀rọ̀ fífẹ̀mí ara ẹni wewu kọ́ léyìí tó bá dọ̀rọ̀ pé ká ní ìgboyà tòótọ́. Ṣebí nígbà kan, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa ṣọ́ra lójú méjèèjì, kí wọ́n mọ̀gbà tó bá yẹ kí wọ́n yẹra fún ewu kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó. (Mátíù 4:12; 10:16) Jésù mọ̀ pé kì í dé báni ká yẹrí ni ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yìí. Ó mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. Jésù pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀, bíyẹn bá sì máa ṣeé ṣe, àfi kó yáa kojú àdánwò tó délẹ̀ yẹn.
24. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé àwa náà lè fìgboyà kojú àdánwò èyíkéyìí?
24 Èèyàn ò lè ka iye ìgbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti fìgboyà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọ̀gá wọn! Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti dúró ṣinṣin nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wọn, tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wọn, tí wọ́n fi ọlọ́pàá mú wọn, tí wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, tí wọ́n ń dá wọn lóró àní nígbà tí wọ́n ṣekú pa àwọn kan lára wọn pàápàá. Ibo làwọn èèyàn aláìpé ti ń rí irú ìgboyà bẹ́ẹ̀? Kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe ẹ̀dá. Ọlọ́run tó fún Jésù nígboyà ló ń fún àwọn náà. (Fílípì 4:13) Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Pinnu pé wàá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀, Jèhófà á sì fún ọ nígboyà tí wàá fi lè ṣe bẹ́ẹ̀. Máa bá a lọ láti jẹ́ kí àpẹẹrẹ Jésù, Aṣíwájú wa, máa fún ọ lókun bó ṣe sọ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—Jòhánù 16:33.
a Àwọn òpìtàn ti sọ pé ńṣe làwọn èèyàn sọ ojú oórì àwọn rábì di òòṣà àkúnlẹ̀bọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe ní ibojì àwọn wòlíì àtàwọn baba ńlá ìgbàanì.