“Àjíǹde Èkíní” Ti Ń lọ Lọ́wọ́!
“Àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 4:16.
1, 2. (a) Ìrètí wo ló wà fáwọn tó ti kú? (b) Kí ló mú kó o gbà gbọ́ pé àjíǹde yóò ṣẹlẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
“ÀWỌN alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú.” Àtìgbà tí Ádámù ti ṣẹ̀ lọ̀rọ̀ yìí ti rí bẹ́ẹ̀. Gbogbo ẹni tí wọ́n ń bí látìgbà téèyàn ti wà lórí ilẹ̀ ayé ló mọ̀ pé òun máa kú lọ́jọ́ kan, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn béèrè pé: ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?’ Bíbélì dáhùn pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.
2 Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fáwọn tó ti kú? Bẹ́ẹ̀ ni, ìrètí wà. Àní, kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé tó lè nímùúṣẹ, ìrètí gbọ́dọ̀ wà fáwọn tó ti kú. Ó ti pẹ́ gan-an táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ti nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa Irú-Ọmọ kan tí yóò pa Sátánì run tí yóò sì mú gbogbo aburú tó fà kúrò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí ló ti kú. Kí wọ́n tó lè rí ìmúṣẹ ìlérí yìí àtàwọn ìlérí mìíràn tí Jèhófà ṣe, ó di dandan kí Ọlọ́run jí wọn dìde. (Hébérù 11:13) Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣeé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Nígbà kan, Pọ́ọ̀lù jí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yútíkọ́sì dìde. Láti àjà kẹta ilé kan ni ọmọkùnrin náà ti ṣubú lulẹ̀ tí wọ́n sì “gbé e ní òkú.” Èyí ló kẹ́yìn lára àjíǹde mẹ́sàn-án tí àkọsílẹ̀ wọn wà nínú Bíbélì.—Ìṣe 20:7-12.a
3. Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:28, 29 ti gbà tù ọ́ nínú, kí sì nìdí?
3 Àwọn àjíǹde mẹ́sàn-án yìí mú ká nígbàgbọ́ nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ. Wọ́n jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ balẹ̀ pé ìlérí tí Jésù ṣe yóò nímùúṣẹ, pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Ọ̀rọ̀ yìí mà múnú wa dùn gan-an o! Ó sì tún jẹ́ ìtùnú fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn táwọn èèyàn wọn ti sùn nínú ikú!
4, 5. Àwọn àjíǹde wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, èwo la sì máa jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó máa jí dìde yóò padà wá sórí ilẹ̀ ayé alálàáfíà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Sáàmù 37:10, 11, 29; Aísáyà 11:6-9; 35:5, 6; 65:21-23) Àmọ́, kí èyí tó rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjíǹde mìíràn ní láti ṣẹlẹ̀. Àkọ́kọ́, Jésù Kristi ní láti jí dìde kó sì gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ fún Ọlọ́run nítorí tiwa. Jésù kú, ó sì jíǹde lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni.
5 Lẹ́yìn èyí, àwọn tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ Olúwa Jésù Kristi nínú ògo ti ọ̀run, níbi tí wọn yóò ti “máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.” (Gálátíà 6:16; 1 Tẹsalóníkà 4:17) Èyí ni Bíbélì pè ní “àjíǹde àkọ́kọ́” tàbí “àjíǹde èkíní.” (Fílípì 3:10, 11; Ìṣípayá 20:6) Nígbà tí àjíǹde yìí bá parí ni àkókò á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá tó láti jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn dìde sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè. Nítorí náà, yálà ọ̀run ni ìrètí wa tàbí orí ilẹ̀ ayé, ó wù wá láti mọ̀ nípa “àjíǹde èkíní.” Irú àjíǹde wo ni? Ìgbà wo ló sì máa ṣẹlẹ̀?
“Irú Ara Wo Ni?”
6, 7. (a) Kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó lè lọ sí ọ̀run, kí ló gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀? (b) Irú ara wo ni wọ́n máa ní nígbà tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde?
6 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó béèrè ìbéèrè kan nípa àjíǹde àkọ́kọ́ pé: “Báwo ni a ó ṣe gbé àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?” Ó wá dáhùn ìbéèrè náà, ó ní: “Ohun tí o gbìn ni a kò sọ di ààyè láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ kú . . . ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún un ni ara gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú . . . Ògo àwọn ara ti ọ̀run jẹ́ oríṣi kan, ti àwọn ara ti ilẹ̀ ayé sì jẹ́ oríṣi ọ̀tọ̀.”—1 Kọ́ríńtì 15:35-40.
7 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn gbọ́dọ̀ kú kí wọ́n tó lè gba èrè wọn ti ọ̀run. Nígbà tí wọ́n bá kú, ara tí wọ́n ní lórí ilẹ̀ ayé á padà sí ekuru. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà tí àkókò bá tó lojú Ọlọ́run, yóò jí wọn dìde pẹ̀lú irú ara tó máa jẹ́ kí wọ́n lè gbé lọ́run. (1 Jòhánù 3:2) Ọlọ́run yóò tún fún wọn ní àìleèkú. Èyí kì í ṣe ohun kan tá a bí mọ́ wọn, bí ẹni pé Ọlọ́run ti fi ọkàn tí kì í kú sínú wọn gẹ́gẹ́ báwọn kan ṣe máa ń sọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.” Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àìleèkú jẹ́, èyí táwọn tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́ yóò ‘gbé wọ̀.’—1 Kọ́ríńtì 15:50, 53; Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 2 Kọ́ríńtì 5:1, 2, 8.
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò yan àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì látinú onírúurú ẹ̀sìn?
8 Kìkì àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì nìkan ni àjíǹde èkíní wà fún. Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yàn wọ́n, ìyẹn kété lẹ́yìn tó jí Jésù dìde. Gbogbo wọn ní “orúkọ [Jésù] àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.” (Ìṣípayá 14:1, 3) Nítorí náà, Ọlọ́run kò yàn wọ́n látinú onírúurú ẹ̀sìn. Kristẹni ni gbogbo wọn, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi ń jẹ́ orúkọ Baba, ìyẹn Jèhófà. Nígbà tí wọ́n bá jíǹde, Jèhófà yóò fún wọn ní iṣẹ́ lọ́run. Bí wọ́n ti ń fojú sọ́nà de ìgbà tí wọ́n á máa sin Ọlọ́run lọ́dọ̀ rẹ̀ gan-an lọ́run jẹ́ ohun tó ń mú wọn láyọ̀ gan-an.
Ǹjẹ́ Àjíǹde Èkíní Ti Ń Lọ Lọ́wọ́?
9. Báwo ni Ìṣípayá 12:7 àti 17:14 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti fojú bu ìgbà tí àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀?
9 Ìgbà wo ni àjíǹde èkíní máa ṣẹlẹ̀? Ẹ̀rí tó ṣe kedere gan-an wà pé ó ti ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, fi orí méjì nínú ìwé Ìṣípayá wéra. Àkọ́kọ́, wo Ìṣípayá orí 12. A kà níbẹ̀ pé Jésù Kristi tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fi jọba, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ mímọ́, bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun. (Ìṣípayá 12:7-9) Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn yìí ti sábà máa ń fi hàn, ogun yìí ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914.b Àmọ́, kíyè sí i pé, ẹsẹ Bíbélì yìí kò sọ pé ẹnì kankan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró wà pẹ̀lú Jésù nínú ogun yẹn. Wàyí o, wo orí 17 ìwé Ìṣípayá. Níbẹ̀, a kà pé lẹ́yìn ìparun “Bábílónì Ńlá,” Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà, ó wá fi kún un pé: “Àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” (Ìṣípayá 17:5, 14) “Àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́” yìí ti ní láti jí dìde bí wọ́n yóò bá wà pẹ̀lú Jésù láti lè ṣẹ́gun ayé Sátánì pátápátá. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n kú kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀ ti ń jí dìde láti àárín ọdún 1914 sí ìgbà Amágẹ́dọ́nì.
10, 11. (a) Àwọn wo làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún, kí sì ni ọ̀kan lára wọn ṣí payá fún Jòhánù? (b) Kí la lè fà yọ látinú èyí?
10 Ǹjẹ́ a lè sọ àkókò pàtó tí àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀? A rí ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an nínú Ìṣípayá 7:9-15, níbi tí àpọ́sítélì Jòhánù ti sọ ìran tó rí nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà.” Ọ̀kan lára àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún ló jẹ́ kí Jòhánù mọ irú ẹni táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú ògo wọn lọ́run ni àwọn alàgbà wọ̀nyí sì dúró fún.c (Lúùkù 22:28-30; Ìṣípayá 4:4) Ìrètí ti ọ̀run ni Jòhánù fúnra rẹ̀ ní, àmọ́ níwọ̀n ìgbà tó ṣì jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí alàgbà náà bá a sọ̀rọ̀, Jòhánù ti ní láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé tí wọn ò tíì gba èrè wọn ti ọ̀run.
11 Nítorí náà, kí la lè fà yọ nínú bó ṣe jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ló sọ ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá jẹ́ fún Jòhánù? Ó dà bí ẹni pé ó ṣeé ṣe káwọn tó ti jíǹde lára àwùjọ àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà máa kópa nínú sísọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí aráyé mọ̀ fún àwọn èèyàn lọ́jọ́ òní. Kí nìdí tí kókó yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé, ọdún 1935 ni Ọlọ́run fi ẹni táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jẹ́ han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé. Bó bá jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ni Ọlọ́run lò láti sọ kókó pàtàkì yìí di mímọ̀, ẹni náà ti ní láti jíǹde sí ọ̀run, ó pẹ́ tán, ní ọdún 1935. Èyí á sì fi hàn pé àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀ ní àkókò kan láàárín ọdún 1914 sí 1935. Ǹjẹ́ a lè sọ pé ìgbà báyìí gan-an ló jẹ́?
12. Ṣàlàyé ìdí tá a fi lè sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìrúwé ọdún 1918 ni àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀.
12 Níbi tá a ṣàlàyé dé yìí, tá a bá gbé ohun kan tó fara jọ kókó yìí yẹ̀ wò nínú Bíbélì, èyí lè ṣèrànwọ́. Nígbà ìwọ́wé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run fàmì òróró yan Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó máa jẹ́ Ọba fún Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹni ẹ̀mí tó lágbára gan-an. Ǹjẹ́ a wá lè sọ pé níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Jésù jọba nígbà ìwọ́wé ọdún 1914, àjíǹde àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ lọ́dún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn nígbà ìrúwé ọdún 1918? Èyí ṣeé ṣe dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí i ní tààràtà nínú Bíbélì, síbẹ̀ àlàyé yìí bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn mu, tó fi hàn pé kété lẹ́yìn tí wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀ ni àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀.
13. Báwo ni 1 Tẹsalóníkà 4:15-17 ṣe fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà wíwàníhìn-ín Kristi ni àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀?
13 Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa [kì í ṣe, ìparí ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa] kì yóò ṣáájú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde. Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú wọn, ni a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.” (1 Tẹsalóníkà 4:15-17) Nítorí náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ti kú kí wíwàníhìn-ín Kristi tó bẹ̀rẹ̀ yóò jíǹde sí ìwàláàyè ti ọ̀run ṣáájú àwọn tó wà láàyè nígbà wíwàníhìn-ín Kristi. Èyí túmọ̀ sí pé, ó ti ní láti jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín Kristi ni àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀ tó sì ń bá a nìṣó “nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:23) Dípò kí àjíǹde èkíní ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, sáà àkókò kan ló fi ṣẹlẹ̀.
‘A Fi Aṣọ Funfun Kan fún Ọ̀kọ̀ọ̀kan Wọn’
14. (a) Ìgbà wo làwọn ìran tó wà nínú Ìṣípayá orí 6 nímùúṣẹ? (b) Ìran wo ló wà nínú Ìṣípayá 6:9?
14 Tún wo ẹ̀rí tó wà nínú Ìṣípayá orí 6. Níbẹ̀, a rí Jésù tó ń gẹṣin lọ gẹ́gẹ́ bí Ọba tó ń ṣẹ́gun. (Ìṣípayá 6:2) Àwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jagun lọ́nà tá ò rírú rẹ̀ rí. (Ìṣípayá 6:4) Ìyàn ń mú káàkiri. (Ìṣípayá 6:5, 6) Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tó ń gbẹ̀mí èèyàn ń fojú aráyé rí màbo. (Ìṣípayá 6:8) Gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sàsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí bá ipò tí ayé wà látọdún 1914 mu rẹ́gí. Àmọ́ ohun mìíràn tún ń ṣẹlẹ̀. Ọkàn wa lọ síbi pẹpẹ ìrúbọ kan. Ìwé ìṣípayá sọ pé: “Ọkàn àwọn tí a fikú pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nítorí iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí wọ́n ti máa ń ṣe” wà níbi ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. (Ìṣípayá 6:9) Níwọ̀n bí “ọkàn [tàbí, ìwàláàyè] ara [ti] ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀,” nǹkan tí ohun tó wà níbi ìsàlẹ̀ pẹpẹ yìí dúró fún ni ẹ̀jẹ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jésù táwọn èèyàn ti pa nítorí pé wọ́n fi ìgboyà àti ìtara wàásù.—Léfítíkù 17:11.
15, 16. Ṣàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 6:10, 11 fi tọ́ka sí àjíǹde èkíní.
15 Bíi ti ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì olóòótọ́, ẹ̀jẹ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn yìí ń kígbe fún ìdájọ́ òdodo. (Jẹ́nẹ́sísì 4:10) “Wọ́n . . . ké pẹ̀lú ohùn rara, pé: ‘Títí di ìgbà wo, Olúwa Ọba Aláṣẹ mímọ́ àti olóòótọ́, ni ìwọ ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣèdájọ́ àti gbígbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?’” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? “A . . . fi aṣọ funfun kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi fún ìgbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn arákùnrin wọn pẹ̀lú tí a máa tó pa bí a ti pa àwọn náà yóò fi pé.”—Ìṣípayá 6:10, 11.
16 Ṣé àwọn ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ tó wà níbi ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà la fi àwọn aṣọ funfun wọ̀nyí fún? Rárá o! Àwọn èèyàn tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lórí pẹpẹ la fi àwọn aṣọ náà fún. Nítorí orúkọ Jésù ni wọ́n ṣe fi ìgbésí ayé wọn rúbọ, wọ́n sì wá jí dìde báyìí gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Níbẹ̀rẹ̀ ìwé Ìṣípayá, a kà pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni a ó fi ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun ṣe ní ọ̀ṣọ́ báyìí; dájúdájú, èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ lọ́nàkọnà kúrò nínú ìwé ìyè.” Tún rántí pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà “wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun, . . . adé wúrà sì ń bẹ ní orí wọn.” (Ìṣípayá 3:5; 4:4) Nítorí náà, lẹ́yìn tí ogun, ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn bẹ̀rẹ̀ sí í ba ilẹ̀ ayé jẹ́ ni àjíǹde àwọn tó ti kú lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bẹ̀rẹ̀, ìyẹn àwọn tí ẹ̀jẹ̀ tó wà níbi ìsàlẹ̀ pẹpẹ dúró fún, a sì fi aṣọ funfun tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ wọ̀ wọ́n.
17. Ọ̀nà wo làwọn tó gba aṣọ funfun fi gbọ́dọ̀ “sinmi”?
17 Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jí dìde yẹn gbọ́dọ̀ “sinmi.” Wọ́n gbọ́dọ̀ fi sùúrù dúró de ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run. “Àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣì ní láti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ àdánwò. Ìgbà tí àkókò ìdájọ́ Ọlọ́run bá dé ni ‘ìsinmi’ náà yóò dópin. (Ìṣípayá 7:3) Lákòókò náà, àwọn tó ti jí dìde yẹn yóò dára pọ̀ mọ́ Jésù Kristi Olúwa láti pa àwọn ẹni ibi run, títí kan àwọn tó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn Kristẹni aláìṣẹ̀ náà sílẹ̀.—2 Tẹsalóníkà 1:7-10.
Bó Ṣe Kàn Wá
18, 19. (a) Àwọn ìdí wo la fi lè sọ pé àjíǹde èkíní ti ń lọ lọ́wọ́ báyìí? (b) Kí ni èrò rẹ lórí òye tó o ní nípa àjíǹdé èkíní yìí?
18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ ọjọ́ náà pàtó tí àjíǹde èkíní bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé àárín sáà àkókò kan ni, ìyẹn nígbà wíwàníhìn-ín Kristi. Àwọn tó kọ́kọ́ jí dìde làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n kú kí wíwàníhìn-ín Kristi tó bẹ̀rẹ̀. Bí wíwàníhìn-ín Kristi ti ń bá a nìṣó, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ títí tí wọ́n fi parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé yóò dẹni tí a yí padà “ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́” sí ẹ̀dá ẹ̀mí tó lágbára gan-an. (1 Kọ́ríńtì 15:52) Ǹjẹ́ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ni yóò gba èrè wọn ti ọ̀run kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó jà? A kò mọ̀. Àmọ́ o, a mọ̀ pé tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni yóò dúró lórí Òkè Síónì ti ọ̀run.
19 A tún mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ti wà pẹ̀lú Kristi báyìí. Ìwọ̀nba díẹ̀ péré lára wọn ló ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀rí ńlá mà lèyí jẹ́ o pé àkókò tí Ọlọ́run máa mú ìdájọ́ rẹ̀ wá ti ń sún mọ́lé gan-an! Láìpẹ́, gbogbo ètò Sátánì pátá yóò di èyí tí a pa run. Sátánì fúnra rẹ yóò dẹni tá a jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Lẹ́yìn náà, àjíǹde gbogbo gbòò á lè wá bẹ̀rẹ̀, àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ á sì lè di ẹni pípé gẹ́gẹ́ bí Ádámù ṣe jẹ́ ẹni pípé kó tó pàdánù àǹfààní náà, èyí á sì jẹ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ń nímùúṣẹ lọ́nà àgbàyanu. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a wà láàyè nírú àkókò yìí!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn àjíǹde mẹ́jọ tó kù, wo 1 Àwọn Ọba 17:21-23; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:21; Máàkù 5:35, 41-43; Lúùkù 7:11-17; 24:34; Jòhánù 11:43-45; Ìṣe 9:36-42.
b Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 215 sí 218. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
c Bó o bá fẹ́ àlàyé lórí bá a ṣe mọ̀ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú ipò wọn lọ́run làwọn alàgbà náà dúró fún, wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ìwé 77. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
Báwo làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àkókò “àjíǹde èkíní”?
• 1 Kọ́ríńtì 15:23; 1 Tẹsalóníkà 4:15-17.
• Ìṣípayá 6:2, 9-11.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn àjíǹde wo ló ṣẹlẹ̀ kó tó di pé aráyé lápapọ̀ á jíǹde?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀nà wo la gbà fún àwọn kan tí wọ́n sùn nínú ikú ní aṣọ funfun?