ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fífi Èdìdì Di Ísírẹ́lì Ọlọ́run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • Ẹ̀fúùfù Mẹ́rin Náà

      3. (a) Àkànṣe iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì ṣe wo ni Jòhánù rí? (b) Kí ni “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” náà ṣàpẹẹrẹ?

      3 Kí Jèhófà tó tú ìhónú yìí jáde, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan. Ìyẹn ni Jòhánù wá rí nínú ìran báyìí, ó sọ pé: “Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin, kí ẹ̀fúùfù kankan má bàa fẹ́ sórí ilẹ̀ ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí.” (Ìṣípayá 7:1) Kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Lọ́nà tó ṣe kedere, “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” yìí ń ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ ìparun tí Jèhófà máa tóó tú jáde sórí ẹgbẹ́ àwùjọ ilẹ̀ ayé burúkú kan, sórí “òkun” ríru ti aráyé aláìlófin, àti sórí àwọn olùṣàkóso bí igi gíga fíofío táwọn èèyàn ilẹ̀ ayé ń gbárùkù tì tí wọ́n sì tún jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún.—Aísáyà 57:20; Sáàmù 37:35, 36.

      4. (a) Kí làwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà dúró fún? (b) Táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù mẹ́rin yìí sílẹ̀, kí ló máa yọrí sí fún ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé?

      4 Láìsí iyè méjì, àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin yìí dúró fún àwùjọ àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin, àwọn ẹni tí Jèhófà ń lò láti dá ìmúṣẹ ìdájọ́ dúró títí di àkókò tó ti yàn. Nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù ìkannú Ọlọ́run wọ̀nyẹn sílẹ̀ láti fẹ́ ní àfẹ́yíká lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti àríwá, gúúsù, ìlà oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn, ìparun náà yóò pọ̀ rẹpẹtẹ. Yóò fara jọ lílò tí Jèhófà lo ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti tú àwọn ará Élámù ká, tó fọ́ wọn túútúú, tó sì pa wọ́n run; lílò tí Jèhófà tún wá fẹ́ lò ó yìí a pabanbarì. (Jeremáyà 49:36-38) Ẹ̀fúùfù ìjì tí ìtóbi rẹ̀ kàmàmà lèyí á jẹ́, agbára ìparun rẹ̀ á pọ̀ ju ti ‘ẹ̀fúùfù líle’ tí Jèhófà fi pa orílẹ̀-èdè Ámónì run. (Ámósì 1:13-15) Kò sí apá kankan lára ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé tí yóò lágbára láti dúró ní ọjọ́ ìhónú Jèhófà, nígbà tó bá dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre títí láé fáàbàdà.—Sáàmù 83:15, 18; Aísáyà 29:5, 6.

      5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run yóò kan gbogbo ilẹ̀ ayé?

      5 Ṣó dájú pé ìdájọ́ Ọlọ́run á kan gbogbo ilẹ̀ ayé? Tún tẹ́tí sílẹ̀ sí wòlíì rẹ̀ Jeremáyà: “Wò ó! Ìyọnu àjálù kan ń jáde lọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì líle sì ni a ó ru dìde láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé. Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 25:32, 33) Àkókò ìjì ẹlẹ́fùúùfù líle yìí ni òkùnkùn yóò bo ayé. Ọlọ́run á mi àwọn aṣojú rẹ̀ tí ń ṣàkóso, wọ́n á sì dẹni ìgbàgbé. (Ìṣípayá 6:12-14) Àmọ́ ṣá o, gbogbo èèyàn kọ́ lọjọ́ ọ̀la máa ṣókùnkùn fún o. Nítorí àwọn wo la ṣe wá dá “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” náà dúró?

      Fífi Èdìdì Di Àwọn Ẹrú Ọlọ́run

      6. Ta ló sọ fáwọn áńgẹ́lì náà pé kí wọ́n dá ẹ̀fúùfù mẹ́rin náà dúró, kí nìyẹn sì ṣí ààyè sílẹ̀ fún?

      6 Jòhánù ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe bá a ó ṣe sàmì sí àwọn kan fún lílà á já, ó wí pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè láti ibi yíyọ oòrùn, ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké pẹ̀lú ohùn rara sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a yọ̀ǹda fún láti pa ilẹ̀ ayé àti òkun lára, pé: ‘Ẹ má ṣe pa ilẹ̀ ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.’”—Ìṣípayá 7:2, 3.

      7. Ẹni wo gan-an ni áńgẹ́lì karùn-ún yìí, kí ló sì ràn wá lọ́wọ́ láti fìdí ẹni tó jẹ́ múlẹ̀?

      7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò dárúkọ áńgẹ́lì karùn-ún yìí, gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé kò lè jẹ́ ẹlòmíì yàtọ̀ sí Jésù Olúwa tá a ti ṣe lógo. A fi hàn níbí pé ó ní ọlá àṣẹ lórí àwọn áńgẹ́lì yòókù, ìyẹn sì bá ipò rẹ̀ mu gẹ́gẹ́ bí olú áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16; Júúdà 9) Ó gòkè wá láti ìlà oòrùn, bí “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn” ìyẹn, Jèhófà àti Kristi rẹ̀, tí wọ́n dé láti mú ìdájọ́ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ọba Dáríúsì àti Kírúsì ti ṣe nígbà tí wọ́n rẹ Bábílónì ìgbàanì sílẹ̀. (Ìṣípayá 16:12; Aísáyà 45:1; Jeremáyà 51:11; Dáníẹ́lì 6:1) Áńgẹ́lì yìí tún jọ Jésù pẹ̀lú ní ti pé ìkáwọ́ rẹ̀ ni fífi èdìdì di àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wà. (Éfésù 1:13, 14) Síwájú sí i, nígbà tá a tú àwọn ẹ̀fúùfù náà sílẹ̀, Jésù lẹni tó ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run láti mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣípayá 19:11-16) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kó jẹ́ Jésù lẹni tí yóò pàṣẹ pé kí a dá ìparun ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé dúró títí tí a óò fi fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run.

  • Fífi Èdìdì Di Ísírẹ́lì Ọlọ́run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́