Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá
Nigba ti Jesu wà lori ilẹ-aye, oun sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati gbadura fun Ijọba Ọlọrun: “Ki ijọba rẹ de; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹ ni ni ayé.” (Matthew 6:9, 10) Nigba gbogbo ni oun si tun maa nsọrọ nipa “ihinrere ijọba” naa. (Matthew 4:23) Niti tootọ, oun sọ ọpọlọpọ ọrọ nipa Ijọba naa ju bi oun ti ṣe nipa ohunkohun miiran lọ. Eeṣe? Nitori Ijọba naa ni irin-iṣẹ ti Ọlọrun yoo lo lati yanju awọn iṣoro ti o mu ki igbesi-aye nira tobẹẹ lonii. Nipasẹ Ijọba naa, Ọlọrun yoo mu ogun, ebi, arun, ati iwa-ọdaran wá si opin patapata laipẹ jọjọ, ti oun yoo si mu ki iṣọkan ati alaafia de.
Iwọ yoo ha fẹ lati gbe inu iru ayé kan bẹẹ bi? Bi o ba ri bẹẹ, nigba naa iwọ nilati ka iwe pẹlẹbẹ yii. Ninu rẹ̀ iwọ yoo kẹkọọ pe Ijọba naa jẹ akoso kan, ṣugbọn ó dara ju akoso eyikeyi ti o tii ṣakoso lori araye ri. Iwọ yoo tun ri ọna amoriya ti Ọlọrun gba ṣalaye awọn ete rẹ̀ nipa Ijọba naa lẹsẹlẹsẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀. Ni afikun si i, iwọ yoo ri i bi Ijọba naa ṣe le ran ọ lọwọ ani lonii paapaa.
Niti tootọ, iwọ le di ọ̀kan lara awọn ọmọ-abẹ Ijọba Ọlọrun nisinsinyi gan-an. Ṣugbọn ṣaaju ki o to yan lati ṣe eyi, yoo yẹ fun ọ lati mọ si i nipa rẹ̀. Nitori naa a gba ọ niyanju lati yẹ iwe pẹlẹbẹ yii wo. Ohun gbogbo ti yoo sọ fun ọ nipa Ijọba naa ni a mu lati inu Bibeli.
Lakọkọ na, jẹ ki a wo idi naa ti a fi nilo Ijọba Ọlọrun pupọ tobẹẹ.
Ni ibẹrẹ ọrọ-itan ẹda-eniyan, Ọlọrun ṣẹda eniyan ni pipe ti o si fi i sinu paradise kan. Ni akoko yẹn kò si idi kankan fun Ijọba naa.
Ṣugbọn Adam ati Efa, awọn obi wa akọkọ, fetisilẹ si Satan, angeli ọlọtẹ kan. Oun pa irọ fun wọn nipa Ọlọrun ti o si mu ki awọn pẹlu di ọlọtẹ lodi si Ọlọrun. Nipa bayii wọn yẹ fun iku, nitori “iku ni ere ẹ̀ṣẹ̀.”—Romans 6:23.
Eniyan alaipe, ẹlẹṣẹ kan kò le ní awọn ọmọ pipe. Nitori naa gbogbo awọn ọmọ Adam ni a bi ni alaipe, ẹlẹṣẹ, ti nku.—Romans 5:12.
Lati igba naa wá, ni awọn ẹda-eniyan ti nilo Ijọba Ọlọrun lati ran wọn lọwọ lati bọ́ kuro ninu ègún ẹ̀ṣẹ̀ ati iku. Ijọba naa yoo tun fọ orukọ Ọlọrun mọ́ kuro ninu awọn irọ ti Satan ti pa lodi si i.
Jehofah Ọlọrun ṣeleri pe “iru-ọmọ” (tabi iran-ọmọ) pataki kan ni a o bi lati gba araye silẹ kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀. (Genesis 3:15) “Iru-ọmọ” yii ni yoo jẹ Ọba Ijọba Ọlọrun naa.
Tani ẹni yii yoo jẹ?
Ni nkan bii 2,000 ọdun lẹhin ti Adam ti dẹṣẹ, ni ọkunrin olootọ gidigidi kan gbe ayé ti orukọ rẹ̀ njẹ Abraham. Jehofah sọ fun Abraham lati fi ilu-nla tirẹ̀ silẹ ki o si maa gbe ninu awọn agọ ni ilẹ Palestine.
Abraham ṣe gbogbo ohun ti Jehofah sọ fun un lati ṣe, lara eyi ti ohun kan ti o nira gidigidi lati ṣe wà. Jehofah sọ fun un lati fi ọmọkunrin rẹ̀ Isaac rubọ lori pẹpẹ kan.
Niti gidi Jehofah kò fẹ irubọ ẹda-eniyan kan. Ṣugbọn oun fẹ lati mọ bi Abraham ṣe nifẹ oun to. Abraham ti wà lẹnu pipa Isaac nigba ti Jehofah da a duro.
Nitori igbagbọ titobi ti Abraham ní, Jehofah ṣeleri lati fun iran-ọmọ rẹ̀ ni ilẹ Palestine ti o si sọ pe Iru-ọmọ ti a ṣeleri naa yoo jẹ nipasẹ ila rẹ̀, ati ti ọmọkunrin rẹ̀ Isaac.—Genesis 22:17, 18; 26:4, 5.
Isaac bi awọn ibeji, Esau ati Jacob. Jehofah sọ pe Iru-ọmọ ti a ṣeleri naa yoo wá nipasẹ Jacob.—Genesis 28:13-15.
Jacob, ẹni ti Jehofah tun sọ orukọ rẹ̀ ni Israel, bi awọn ọmọkunrin mejila, gbogbo awọn ẹni ti lẹhin-ọ-rẹhin bí awọn ọmọ. Nitori naa awọn ọmọ Abraham ni a bẹrẹ si mu bisi i.—Genesis 46:8-27.
Nigba ti iyan buburu kan ṣẹlẹ ni agbegbe naa, Jacob ati idile rẹ̀ ṣi lọ si Egypt nigba ti Pharaoh alakoso Egypt ke si wọn.—Genesis 45:16-20.
Ni Egypt ni a ti ṣipaya rẹ̀ pe iru-ọmọ ti a ṣeleri naa yoo jẹ iran-atẹle Judah ọmọkunrin Jacob.—Genesis 49:10.
Asẹ̀hinwá-asẹ̀hinbọ̀ Jacob ku, awọn iran-ọmọ rẹ̀ si gbèrú ni iye titi wọn fi dabi orilẹ-ede kan. Nigba naa ni awọn ara Egypt bẹrẹ si bẹru wọn ti wọn si sọ wọn di awọn ẹru.—Exodus 1:7-14.
Asẹ̀hinwá-asẹ̀hinbọ̀ Jehofah ran Moses, ọkunrin olootọ gidigidi kan, lati beere pe ki Pharaoh ti igba naa jẹ ki awọn ọmọ Israel lọ ni ominira.—Exodus 6:10, 11.
Pharaoh kọ jalẹ, nitori naa Jehofah mu ki awọn iyọnu-ajakalẹ mẹwa wá sori awọn ara Egypt. Gẹgẹ bi iyọnu-ajakalẹ ti o kẹhin, oun ran angeli iku lati pa gbogbo awọn ọmọkunrin akọbi Egypt.—Exodus, ori 7 si 12.
Ọlọrun sọ fun awọn ọmọ Israel pe bi wọn ba pa ọ̀dọ̀-agutan fun ounjẹ alẹ wọn ti wọn si fi lara ẹjẹ rẹ̀ si ara awọn òpó ilẹkun wọn, angeli iku naa yoo ré awọn ile wọn kọja. Bayii ni a ṣe gba awọn akọbi Israel la.—Exodus 12:1-35.
Gẹgẹ bi àbárèbábọ̀, Pharaoh paṣẹ-itọni ijadelọ awọn ọmọ Israel kuro ni Egypt. Ṣugbọn lẹhin naa oun yi ero-inu rẹ̀ pada ti o si lepa wọn lati mu wọn pada.
Jehofah ṣi ọna silẹ fun awọn ọmọ Israel lati sa asala la Okun Pupa kọja. Nigba ti Pharaoh ati awọn ọmọ-ogun rẹ̀ gbiyanju lati tẹle wọn, wọn ba omi lọ.—Exodus 15:5-21.
Jehofah dari awọn ọmọkunrin Israel lọ si oke kan ti a pe orukọ rẹ̀ ni Sinai ninu aṣalẹ. Nibẹ ni oun ti fun wọn ni Ofin rẹ̀ ti o si sọ pe bi wọn yoo ba pa a mọ, wọn yoo di ijọba awọn alufaa ati orilẹ-ede mímọ́ kan. Nipa bayii, awọn ọmọ Israel ní ire-anfaani lati jẹ apa pataki kan nikẹhin ninu Ijọba Ọlọrun.—Exodus 19:6; 24:3-8.
Lẹhin ti awọn ọmọ Israel ti wà nibi Oke Sinai fun nkan bii ọdun kan, Jehofah dari wọn lọ si ọna Palestine, ilẹ naa ti oun ti ṣeleri rẹ̀ fun Abraham babanla wọn.
Ni Palestine, Ọlọrun lẹhin naa yọnda ki a ṣakoso awọn ọmọ Israel nipasẹ awọn ọba. Nigba naa ni Ọlọrun wa ní ijọba kan lori ilẹ-aye.
Ọba keji ilẹ Israel ni David, iran-atẹle Judah. David ṣẹgun gbogbo awọn ọta Israel, ó si sọ Jerusalem di olu-ilu nla orilẹ-ede naa.
Awọn iṣẹlẹ ni igba-ijọba David fihan pe nigba ti Jehofah ba tì ọba kan lẹhin, kò si oluṣakoso ori ilẹ-aye kankan ti o le ṣẹgun rẹ̀.
Jehofah wipe Iru-ọmọ ileri naa yoo jẹ ọ̀kan lara awọn iran-atẹle David.—1 Kronika 17:7, 11, 14.
Solomon, ọmọkunrin David, ṣakoso lẹhin rẹ̀. Oun jẹ ọlọgbọn ọba kan, Israel si ní aasiki labẹ akoso ijọba rẹ̀.
Solomon tun kọ temple rere kan fun Jehofah ni Jerusalem. Awọn ipo ni Israel labẹ akoso-ijọba Solomon fi awọn ibukun kan ti ijọba Ọlọrun ti nbọ wá yoo mu wá fun araye han.—1 Awọn Ọba 4:24, 25.
Bi o tiwu ki o ri, ọpọlọpọ awọn ọba ti o jẹ tẹle Solomon jẹ alaiṣootọ gidigidi.
Ṣugbọn nigba ti awọn iran-atẹle David ṣi nṣakoso sibẹ ni Jerusalem, Jehofah lo wolii rẹ̀ Isaiah lati sọ nipa Ọmọkunrin David ọjọ-ọla kan ti yoo ṣakoso gbogbo ayé ni iṣotitọ. Eyi yoo jẹ Iru-ọmọ ileri naa.—Isaiah 9:6, 7.
Wolii Isaiah sọ asọtẹlẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi eyi ti ó tilẹ logo ju ti Solomon lọ.—Isaiah, ori 11 ati 65.
Nisinsinyi, ju ti igbakigba ri lọ, awọn iranṣẹ Ọlọrun ti ṣe kayefi nipa ẹni ti “Iru-ọmọ” yii yoo jẹ.
Ṣaaju ki iru-ọmọ yii to de, bi o tiwu ki o ri, awọn ọba Israel di awọn eniyan buruku pupọ ti o fi jẹ pe ni 607 B.C.E. Jehofah fi àyè silẹ ki a ṣẹgun orilẹ-ede naa lati ọwọ awọn ara Babylon, ati pupọ julọ awọn eniyan naa ni a ko nigbekun lọ si Babylon. Ṣugbọn Ọlọrun kò tii gbagbe ileri rẹ̀. Iru-ọmọ naa yoo ṣi farahan sibẹ ninu ila David.—Ezekiel 21:25-27.
Ohun ti o ṣẹlẹ si Israel fihan pe bi o tilẹ jẹ pe ọba ẹda-eniyan kan ti o jẹ ọlọgbọn ati olootọ le mu awọn ere-anfaani wá, awọn ere-anfaani wọnyi ní opin-aala. Awọn ọkunrin olootọ maa nku ti awọn arọpo wọn si le ma jẹ olootọ. Kinni o ti jẹ iyanju-ọran naa? “Iru-ọmọ” ileri naa.
Asẹ̀hinwá-asẹ̀hinbọ̀, lẹhin ẹgbẹẹgbẹrun ọdun “Iru-ọmọ” naa farahan. Tani oun iṣe?
Angeli kan lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun fun ọmọbinrin Israel alailọkọ kan ti a pe orukọ rẹ̀ ni Mary ni idahun naa. Oun sọ fun un pe oun yoo bí ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ̀ yoo maa jẹ Jesu. Ohun ti angeli naa wi niyii:
“Ẹni yii yoo tobi-lọla a o si maa pe e ni Ọmọkunrin Ọga-ogo; Jehofah yoo si fi itẹ David baba rẹ̀ fun un, yoo si ṣakoso gẹgẹ bi ọba.”—Luke 1:32, 33.
Nitori naa Jesu ni yoo nilati jẹ Iru-ọmọ ileri naa ati nikẹhin Ọba Ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn eeṣe ti Jesu fi yatọ si awọn ọkunrin olootọ ti o ti walaaye ṣaaju?
A bí Jesu nipasẹ iṣẹ-iyanu. Iya rẹ̀ jẹ wundia kan, oun kò si ní baba ẹda-eniyan kankan. Jesu ti gbe ni ọrun tẹlẹtẹlẹ ti ẹmi mímọ́ Ọlọrun tabi ipá iṣiṣẹ rẹ̀ sì ta atare iwalaaye Jesu lati ọrun sinu ile-ọlẹ Mary. Fun idi eyiini, oun kò jogun ẹ̀ṣẹ̀ Adam. Jalẹjalẹ gbogbo igbesi-aye rẹ̀, Jesu kò dẹ́ṣẹ̀.—1 Peter 2:22.
Nigba ti ó pe ọmọ ọgbọn ọdun, a batisi Jesu.
Oun sọ fun awọn eniyan nipa Ijọba Ọlọrun ati nikẹhin ó fi ara rẹ̀ han gẹgẹ bi Ọba Ijọba naa.—Matthew 4:23; 21:4-11.
Oun tun ṣe ọpọlọpọ awọn iṣẹ-iyanu pẹlu.
Oun ṣe iwosan fun awọn alaisan.—Matthew 9:35.
Oun fi pẹlu iṣẹ-iyanu bọ́ awọn ti ebi npa.—Matthew 14:14-22.
Oun tilẹ ji awọn oku dide paapaa.—John 11:38-44.
Awọn iṣẹ-iyanu wọnyi fi iru awọn ohun ti Jesu yoo ṣe fun araye gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun han.
Iwọ ha ranti bi Ọba David ṣe sọ Jerusalem di olu-ilu nla ijọba rẹ̀? Jesu ṣalaye pe Ijọba Ọlọrun ki yoo wà lori ile-aye, ṣugbọn ni ọrun. (John 18:36) Idi niyii ti a fi pe Ijọba naa ní “Jerusalem ti ọrun.”—Hebrews 12:22, 28.
Jesu la awọn ofin lẹsẹẹsẹ ti awọn wọnni ti yoo jẹ ọmọ-abẹ Ijọba naa yoo nilati ṣe igbọran si. Awọn ofin wọnyi wà ninu Bibeli nisinsinyi. Awọn ofin ti o ṣe pataki julọ ni pe awọn eniyan gbọdọ fẹran Ọlọrun ki wọn si fẹran ara wọn lẹnikin-in-ni keji.—Matthew 22:37-39.
Jesu tun ṣipaya pe oun ki yoo danikan ṣakoso ninu Ijọba rẹ̀. Awọn ẹda-eniyan ti a yan yoo wà lati lọ si ọrun ki wọn si ṣakoso nibẹ pẹlu rẹ̀. (Luke 12:32; John 14:3) Awọn melo ni yoo wà nibẹ? Ifihan 14:1 dahùn pe: 144,000.
Bi o ba jẹ kìkì 144,000 ni yoo lọ si ọrun lati ṣakoso pẹlu Jesu, kinniiyoku araye le reti fun?
Bibeli wipe: “Olododo ni yoo jogun ayé, yoo si maa gbe inu rẹ̀ laelae.”—Psalm 37:29.
Awọn wọnni ti yoo gbe lori ilẹ-aye titilae ni a pe ni: “awọn agutan miiran.”—John 10:16.
Nitori naa awọn ireti meji ni o wà. 144,000 wà ti Jehofah Ọlọrun kesi lati lọ si ọrun lati ṣakoso pẹlu Jesu Kristi. Ṣugbọn araadọta ọkẹ awọn miiran ní ireti ti o daju ti gbigbe lori ilẹ-aye titilae gẹgẹ bi awọn ọmọ-abẹ Ijọba rẹ̀.—Ifihan 5:10.
Satan korira Jesu ó si kọjuja si i. Lẹhin ti Jesu ti waasu fun ọdun mẹta ati aabọ, Satan jẹ ki a fi aṣẹ ọba mu un a si pa a nipa kikan an mọ òpó igi kan. Eeṣe ti Ọlọrun fi yọnda eyi?
Ranti pe, nitori pe a jẹ iran-atẹle Adam, gbogbo wa ni ndẹṣẹ ti a si yẹ fun iku.—Romans 6:23.
Ranti, pẹlu, pe nitori ọna iyanu ti a gba bí Jesu, oun jẹ ẹni pipe ti kò si yẹ fun iku. Bi o tiwu ki o ri, Jehofah yọnda fun Satan lati ‘lu gigisẹ̀ Jesu fọ,’ lati pa a. Ṣugbọn Ọlọrun ji i dide si iye lẹẹkan si i gẹgẹ bi ẹmi alaileeku kan. Niwọn bi oun si ti ní ẹtọ si iwalaaye ẹda-eniyan pipe, oun nisinsinyi le lo eyi lati ra awọn ẹda-eniyan pada kuro lọwọ ẹ̀ṣẹ̀.—Genesis 3:15; Romans 5:12, 21; Matthew 20:28.
Lati ran wa lọwọ lati loye lẹkunrẹrẹ ohun ti ẹbọ Jesu tumọsi, Bibeli sọrọ nipa rẹ̀ nipasẹ awọn apẹẹrẹ-awokọṣe alasọtẹlẹ.
Fun apẹẹrẹ iwọ ha ranti bi Jehofah ṣe sọ fun Abraham lati fi ọmọkunrin rẹ̀ rubọ, gẹgẹ bi idanwo ifẹ rẹ̀?
Eyi jẹ apẹẹrẹ-awokọṣe alasọtẹlẹ kan ti ẹbọ Jesu. Ó fihan bi ifẹ Jehofah fun araye ṣe pọ tobẹẹ ti ó fi yọnda Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu lati ku fun wa ki a baa le ní iwalaaye.—John 3:16.
Iwọ ha ranti ọna ti Jehofah gbà gba awọn ọmọ Israel silẹ kuro ni Egypt ti ó si gba akọbi wọn la nipa jijẹ ki angeli iku naa ré wọn kọja?—Exodus 12:12, 13.
Eyi jẹ apẹẹrẹ-awokọṣe alasọtẹlẹ kan. Gan-an gẹgẹ bi ẹjẹ ọ̀dọ́-agutan naa ṣe tumọsi iye fun akọbi awọn ọmọ Israel, ẹjẹ Jesu ti a ta silẹ tumọsi iye fun awọn wọnni ti wọn gbagbọ ninu rẹ̀. Ati gẹgẹ bi awọn iṣẹlẹ alẹ ọjọ naa ṣe tumọsi ominira fun awọn ọmọ Israel, iku Jesu pese ominira kuro lọwọ ẹ̀ṣẹ̀ ati iku fun araye.
Idi niyii ti a fi pe Jesu ni “Ọ̀dọ́-agutan Ọlọrun, ẹni ti o ko ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”—John 1:29.
Bi o tiwu ki o ri, nigba ti Jesu wa lori ilẹ-aye oun pẹlu tun ko awọn ọmọ-ẹhin jọ ti o si kọ́ wọn lati waasu ihinrere Ijọba naa, ani lẹhin iku rẹ̀ paapaa.—Matthew 10:5; Luke 10:1.
Awọn wọnyi ni awọn ẹda-eniyan akọkọ ti Ọlọrun yan lati ṣakoso pẹlu Jesu ninu Ijọba rẹ̀.—Luke 12:32.
Iwọ ha ranti pe Ọlọrun ṣeleri fun awọn Jew pe bi wọn ba pa ofin naa mọ, wọn yoo jẹ “ijọba alufaa”? Nisinsinyi wọn ní anfaani kan lati jẹ apakan Ijọba Ọlọrun ki wọn si sin gẹgẹ bi awọn alufaa ti ọrun bi wọn yoo ba tẹwọgba Jesu. Ṣugbọn pupọ julọ ninu wọn ṣá Jesu tì.
Nitori naa lati akoko naa lọ, awọn Jew kii ṣe orilẹ-ede ti Ọlọrun yan mọ; Palestine kii tun iṣe Ilẹ-ileri naa mọ.—Matthew 21:43; 23:37, 38.
Lati ọjọ Jesu titi di ọjọ wa, Jehofah ti nko awọn wọnni ti yoo jọba ni ọrun pẹlu Jesu jọ. Awọn ẹgbẹrun diẹ ninu wọn ṣì wà laaye lori ilẹ-aye lonii. A npe wọn ni iyoku ẹni-ami-ororo.—Ifihan 12:17
Nisinsinyi, iwọ bẹrẹ si nri ohun ti Ijọba Ọlọrun jẹ. Ó jẹ akoso kan ni ọrun, Ọba rẹ̀ si ni Jesu Kristi, ti 144,000 eniyan lati ori ilẹ ayé si darapọ mọ ọn. Yoo ṣakoso lori araye olootọ lori ilẹ-aye ti yoo si ní agbara lati mu alaafia wá si ayé.
Lẹhin iku rẹ̀, a ji Jesu dide ó si lọ si ọrun. Nibẹ, ó duro de Ọlọrun lati sọ igba ti yoo to akoko fun oun lati bẹrẹ iṣakoso gẹgẹ bi Ọba Ijọba Ọlọrun. (Psalm 110:1) Nigba wo ni yoo jẹ?
Ni awọn akoko kan Jehofah nran awọn àlá si awọn eniyan lati le sọ awọn nkan fun wọn nipa Ijọba rẹ̀.
Ni ọjọ Daniel, Jehofah ran iru àlá bẹẹ si Nebuchadnezzar, ọba Babylon. Igi titobi kan ni.—Daniel 4:10-37.
Igi naa ni a ge lulẹ ti a si fi ide-irin de kùkùté rẹ̀fun ọdun meje.
Igi naa duro fun Nebuchadnezzar. Gan-an gẹgẹ bi a ti fi ide-irin de kùkùté naa fun ọdun meje, Nebu- chadnezzar padanu ori pipe rẹ̀ fun ọdun meje. Lẹhin naa ni a mu ori pipe rẹ̀ padabọ-sipo.
Gbogbo iwọnyi jẹ apẹẹrẹ-awokọṣe alasọtẹlẹ kan. Nebuchadnezzar ṣapẹẹrẹ iṣakoso Jehofah kari ayé. Lakọkọ ná, eyi ni a lo nipasẹ awọn iran-atẹle Ọba David ni Jerusalem. Nigba ti Babylon ṣẹgun Jerusalem ni 607 B.C.E., ila awọn ọba naa ni a di lọwọ. Kì yoo si ọba miiran lae ninu ila David “titi oun yoo fi de ẹni ti ó ní ẹtọ lọna ofin.” (Ezekiel 21:27) Eyinni ni Jesu Kristi.
Bawo ni yoo ti pẹ to lati 607 B.C.E. titi Jesu yoo fi bẹrẹ si jọba? Ọdun alasọtẹlẹ meje. Eyinni ni, 2,520 ọdun. (Ifihan 12:6, 14) 2,520 ọdun lati 607 B.C.E. mu wa de 1914 C.E.
Nitori naa Jesu bẹrẹ si ṣakoso ninu awọn ọrun ni 1914
Kinni ohun ti eyiini tumọsi?
Bibeli sọ fun wa nịpasẹ iran-ifihan kan ti apostle John ri.
Oun ri obinrin kan ni ọrun ti o bí ọmọ-ọkunrin kan.—Ifihan 12:1-12.
Obirin naa ṣapẹẹrẹ eto Ọlọrun ti ọrun, ti ó jẹ akojọ gbogbo awọn iranṣẹ angeli Ọlọrun ni ọrun. Ọmọ-ọkunrin naa ṣapẹẹrẹ Ijọba Ọlọrun. Eyi ni a bí ni 1914
Kinni ohun ti o ṣẹlẹ tẹle e? Ohun kin-in-ni, ti Jesu se gẹgẹ bi Ọba ni lati fi Satan ati awọn angeli wọnni ti wọn ṣọtẹ pẹlu rẹ̀, sọko kuro ni ọrun wá sori ilẹ-aye.—Ifihan 12:9.
Bibeli sọ iyọrisi eyi fun wa: “Nitori naa ẹ maa yọ ẹyin ọrun ati ẹyin ti ngbe inu wọn. Ègbé ni fun ayé ati fun okun! Nitori Eṣu sọkalẹ tọ yin wá ni ibinu nal, nitori ó mọ̀ pe igba kukuru ṣa ni oun ní.”—Ifihan 21:12.
Nitori naa nigba ti Jesu bẹrẹ si jọba ni ọrun, awọn ọta rẹ̀ wa di oṣiṣẹ karakara lori ilẹ-aye. Gẹgẹ bi Bibeli ṣe sọtẹlẹ, oun bẹrẹ si ṣakoso laarin awọn ọta rẹ̀.—Psalm 110:1, 2.
Kinni eyi tunmọsi fun araye?
Jesu sọ fun wa pe: ogun, ọwọn-gogo ounje, arun, ati isẹlẹ.—Matthew 24:7, 8; Luke 21:10, 11.
Iwe Ifihan sọ fun a pe awọn eniyan yoo maa ‘pa aye run.’ (Ifihan 11:18) A ti n rí eyi pẹlu, paapaa lati ọdún 1914 wa.
“Idaamu awọn orilẹ-ede, laimọ ọna abajade . . . nigba ti awọn eniyan yo maa daku lati inu ibẹru” yoo wà pẹlu. (Luke 21:25, 26, NW) Awa ti ri eyiini, pẹlu, lati 1914.
Apostle Paul fi kun un pe awọn eniyan yoo di olufẹ ara wọn, olufẹ owó, . . . aṣaigbọran si obi, . . . alaiṣeeba ṣe adehun, oluṣaata, alaini-ikora-ẹni-nijanu.”—2 Timothy 3:1-5, NW.
Nisinsinyi iwọ mọ idi ti igbesi-aye fi nira tobẹẹ lonii. Satan ti nṣṣẹ karakara gidigidi. Ṣugbọn Ijọba Ọlorun ti nṣiṣẹ gidigidi pẹlu.
Ni kete lẹhin 1914, iyoku awọn wọnni ti wọn nreti lati ṣakoso ninu ọrun pẹlu Jesu bẹrẹ si sọ ihinrere naa pe Ijọba naa ni a ti gbekalẹ. Iṣẹ yii ti wa tan kalẹ kari aye nisinsinyi, gẹgẹ bi Jesu ti sọ pe yoo ri.—Matthew 24:14.
Kinni ete iṣẹ iwaasu yii?
Lakọkọ, ó jẹ lati sọ fun awọn eniyan nipa Ijọba Ọlọrun.
Ikeji, ó jẹ lati ran awọn eniyan lọwọ lati pinnu yala wọn fẹ lati jẹ awọn ọmọ-abẹ Ijọba naa.
Jesu sọ pe ni awọn ọjọ wa gbogbo araye ni a o pin si awọn ẹni-bi-agutan ati awọn ẹni-bi-ewurẹ.—Matthew 25:31-46.
“Awọn agutan” yoo jẹ awọn wọnni ti wọn fẹran rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀. “Awọn ewurẹ” yoo jẹ awọn wọnni ti kò ṣe bẹẹ.
“Awọn agutan” yoo ri iye ainipẹkun gba nigba ti “awọn ewurẹ” kì yoo ri i gba.
Iṣẹ ipinya yii ni a nṣe laṣepe nipasẹ iwaasu ihinrere Ijọba naa.
Asọtẹlẹ kan niyii nipasẹ wolii Isaiah.
“Yoo si gbọdọ ṣẹlẹ ni apa igbẹhin awọn ọjọ pe oke-nla ile Jehofah ni a o fi idi rẹ̀ mulẹ gbọn-in-gbọn-in rekọja ori awọn oke-nla, dajudaju a o si gbe e ga rekọja awọn oke keekeeke; gbogbo orilẹ-ede yoo si maa wọ́ lọ sibẹ.”—Isaiah 2:2, NW.
Araye nisinsinyi ti dojukọ “apa igbẹhin awọn ọjọ.”
“Ile” ijọsin Jehofah ni a “gbe ga” rekọja awọn isin eke.
“Ọpọlọpọ eniyan yoo si lọ dajudaju wọn yoo si wipe: ‘Ẹ wá, ẹyin eniyan, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Jehofah, si ile Ọlọrun Jacob; oun yoo si kọ́ wa lẹkọọ nipa awọn ọna rẹ̀, awa o si rin ni awọn ipa-ọna rẹ̀.’”—Isaiah 2:3, NW.
Nitori naa, ọpọlọpọ lati gbogbo orilẹ-ede wá lati jọsin Jehofah wọn si kesi awọn ẹlomiran lati darapọ mọ wọn. Wọn kẹkọọ bi a ṣe le huwa ni ọna ti Jehofah fẹ.
“Wọn yoo si nilati fi awọn ida wọn rọ awọn ohun iroko ati awọn ọ̀kọ̀ wọn rọ awọn doje. Orilẹ-ede ki yoo gbe ida lodi si orilẹ-ede, bẹẹ ni wọn ki yoo kọ́ ogun jija mọ.”—Isaiah 2:4, NW.
Awọn wọnni ti wọn njọsin Jehofah wà ni iṣọkan wọn si jẹ alalaafia.
Iyọrisi igbokegbodo yii nipasẹ Ijọba Ọlọrun ni pe nisinsinyi ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù eniyan kari ayé ni nbẹ ti wọn jẹ ọmọ-abẹ Ijọba naa.
Wọn korajọ yika iyoku naa, awọn ẹni ti o ṣẹku lara awọn wọnni ti ireti wọn jẹ lati lọ si ọrun lati ṣakoso pẹlu Kristi.
Wọn ngba ounjẹ ti ẹmi nipasẹ ètò-àjọ Ọlọrun.—Matthew 24:45-47.
Wọn jẹ ẹgbẹ arakunrin ti awọn Kristian kari ayé ti wọn fẹran ara wọn nitootọ.—John 13:35.
Wọn ngbadun alaafia ero-inu, ireti kan fun ọjọ-ọla.—Filippi 4:7.
Laipẹ, ihinrere naa ni a o ti waasu rẹ̀. “Awọn agutan” ni a o ti kojọ. Nigba naa kinni Ijọba naa yoo ṣe?
Iwọ ha ranti pe Ọba David olootọ ṣẹgun gbogbo awọn ọta eniyan Ọlọrun? O dara, Ọba Jesu yoo ṣe bakan naa.
Ọba Nebuchadnezzar nigba kan lá àlá ere titobi kan ti o jẹ ami-apẹẹrẹ awọn ilẹ-ọba ayé lati ọjọ rẹ̀ titi de ọjọ wa.
Lẹhin naa oun ri okuta kan ti a gbẹ́ jade lati ara oke-nla kan, ó si fọ́ ere naa si wẹwẹ. Okuta naa duro fun Ijọba Ọlọrun.
Eyi tumọsi iparun samanni-eto awọn nkan buburu isinsinyi.—Daniel 2:44.
Awọn nkan diẹ niwọnyi ti Ijọba naa yoo parun:
Isin eke yoo poora, gẹgẹ bi ọlọ kan ti a ju sinu okun.—Ifihan 18:21.
Idi niyii ti a fi gba gbogbo awọn olufẹ Ọlọrun niyanju lati jade kuro ninu isin eke NISINSINYI.—Ifihan 18:4.
Tẹle eyi Ọba naa Jesu yoo “ṣá awọn orilẹ-ede . . . yoo si fi ọ̀pá irin ṣe akoso wọn.”—Ifihan 19:15.
Fun idi yii, awọn Ẹlẹrii Jehofah, bi o tilẹ jẹ pe wọn nsan owó-ori wọn ti wọn si nṣe igbọran si awọn ofin orilẹ-ede, kò lọwọ ninu iṣelu.
Nikẹhin, Satan funraarẹ̀, “dragon” nla naa, ni a o ju sinu ọgbun ainisalẹ.—Ifihan 20:2, 3.
Kìkì “awọn agutan,” awọn wọnni ti wọn juwọsilẹ-tẹriba fun Jesu gẹgẹ bi Ọba ni yoo la ipọnju yii ja.—Matthew 25:31-34, 41, 46.
Apostle John ri iran-ifihan kan ti awọn agutan ti wọn la ipọnju naa ja.
“Mo ri, si wò ó! ogunlọgọ nla kan, ti eniyan kankan kò le ka iye wọn, lati inu orilẹ-ede ati ẹya ati eniyan ati ahọn duro niwaju itẹ naa ati niwaju Ọ̀dọ́-agutan naa, wọn wọ aṣọ-igunwa funfun imọ-ọpẹ si nbẹ ni ọwọ wọn.”—Ifihan 7:9.
“Ogunlọgọ nla” naa parapọ jẹ gbogbo awọn wọnni ti wọn dahun si iwaasu ihinrere naa.
Wọn “jade lati inu ipọnju nla naa wá.”—Ifihan 7:14.
“Imọ-ọpẹ” fihan pe wọn kí Jesu kaabọ gẹgẹ bi Ọba wọn.
Wiwọ ti wọn wọ “awọn aṣọ-igunwa funfun” ṣapẹẹrẹ pe wọn ní igbagbọ ninu ẹbọ Jesu.
“Ọ̀dọ́-agutan” naa ni Jesu Kristi.
Awọn ibukun wo ni wọn ngbadun nigba naa? Iwọ ha ranti ayọ ti o wà ni Israel nigba ti olootọ Ọba Solomon jọba? Eyi funni ni aworan kekere kan nipa ayọ lori ilẹ-aye labẹ Ọba Jesu.
Alaafia gidi yoo wà laarin araye ati laarin awọn eniyan ati awọn ẹranko, gan-an gẹgẹ bi Isaiah ti sọtẹlẹ.—Psalm 46:9; Isaiah 11:6-9.
Gan-an gẹgẹ bi Jesu ṣe ṣe iwosan fun awọn alaisan nigba ti ó wà lori ilẹ-aye, bẹẹ naa ni oun yoo mu aisan kuro lọdọ gbogbo araye.—Isaiah 33:24.
Gan-an gẹgẹ bi oun ti bọ́ ogunlọgọ, bẹẹ naa ni oun yoo mu ọwọn-gogo ounjẹ dopin fun gbogbo araye.—Psalm 72:16.
Gan-an gẹgẹ bi oun ti ji oku dide bẹẹ naa ni oun yoo ṣe ji awọn oku wọnni dide ti wọn kò ní ẹkunrẹrẹ ire-anfaani lati juwọsilẹ-tẹriba funraawọn fun Ijọba Ọlọrun.—John 5:28, 29.
Kẹrẹkẹrẹ, oun yoo mu araye pada si ijẹpipe ti Adam gbe sọnu.
Eyiini kò ha iṣe ọjọ-ọla agbayanu kan bi? Iwọ yoo ha fẹ lati ri i bi? Bi o ba ri bẹẹ, ṣiṣẹ ki o ba le juwọsilẹ-tẹriba funraarẹ nisinsinyi fun Ijọba Ọlọrun ki o si di ọ̀kan lara “awọn agutan.”
Kẹkọọ Bibeli ki o si sapa lati mọ̀Jehofah Ọlọrun ati Jesu Kristi.—John 17:3.
Kẹgbẹpọ pẹlu awọn miiran ti wọn jẹ ọmọ-abẹ pẹlu fun Ijọba naa.—Hebrews 10:25.
Kẹkọọ awọn ofin Ijọba naa ki o si pa wọn mọ.—Isaiah 2:3, 4.
Ya igbesi-aye rẹ si mímọ́ lati sin Jehofah, ki o si ṣe baptism.—Matthew 28:19, 20.
Yẹra fun awọn ohun buburu, bii ole jija, irọ pipa, iwa-aimọ, imutipara ti o ṣaitẹ Jehofah Ọlọrun lọrun.—1 Korinti 6:9-11.
Ṣe ajọpin ninu wiwaasu ihinrere Ijọba naa.—Matthew 24:14.
Lẹhin naa pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, iwọ yoo ri i ti a mu Paradise ti Adam sọnu fun awọn iran-atẹle rẹ̀ padabọsipo, iwọ yoo si ri i ti a mu ileri yii ṣẹ: “Mo si gbọ ohùn nla kan lati ori itẹ naa wa, wipe: ‘Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn eniyan, oun o si maa ba wọn gbe, wọn o si maa jẹ eniyan rẹ̀, ati Ọlọrun tikaraarẹ̀ yoo wà pẹlu wọn, yoo si maa jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; kì yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni kì yoo si irora mọ. Nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.’”—Ifihan 21:3, 4.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 20]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
607 B.C.E. 1914 C.E.
B.C.E. | C.E.
500 1,000 1,500 2,000 2,520
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Abraham
Isaac
Jacob
Judah
David
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
144,000
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Adam
Jesus