Orí 23
Ègbé Kejì—Agbo Àwọn Agẹṣinjagun
1. Pẹ̀lú ìsapá àwùjọ àwọn àlùfáà láti pa àwọn eéṣú náà run, kí ló ti ṣẹlẹ̀, kí sì ni bíbọ̀ táwọn ègbé méjì sí i ṣì ń bọ̀ fi hàn?
LÁTI ọdún 1919 wá, ogun táwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ ń gbé ti ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti fa ìnira tó pọ̀ fún àwùjọ àwọn àlùfáà. Wọ́n ti gbìyànjú láti pa àwọn eéṣú náà run pátápátá, ṣùgbọ́n ṣe làwọn eéṣú yìí túbọ̀ wá ń di alágbára sí i ju ti tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí lọ. (Ìṣípayá 9:7) Kò wá tán síbẹ̀ o! Jòhánù kọ̀wé pé: “Ègbé kan ti kọjá. Wò ó! Ègbé méjì sí i ń bọ̀ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí.” (Ìṣípayá 9:12) Àwọn ìyọnu adánilóró púpọ̀ sí i wà níwájú fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.
2. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kẹfà fun kàkàkí rẹ̀? (b) Kí ni “ohùn kan látinú àwọn ìwo orí pẹpẹ wúrà” náà dúró fún? (d) Kí ló dé tá a fi mẹ́nu kan áńgẹ́lì mẹ́rin?
2 Ibo ni ègbé kejì ti wá? Jòhánù kọ̀wé pé: “Áńgẹ́lì kẹfà sì fun kàkàkí rẹ̀. Mo sì gbọ́ tí ohùn kan láti inú àwọn ìwo orí pẹpẹ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọ́run wí fún áńgẹ́lì kẹfà, tí ó ní kàkàkí lọ́wọ́ pé: ‘Tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a dè síbi odò ńlá Yúfírétì sílẹ̀.’” (Ìṣípayá 9:13, 14) Ohùn tó wá láti ibi àwọn ìwo pẹpẹ wúrà náà ló pàṣẹ pé kí wọ́n tú àwọn áńgẹ́lì náà sílẹ̀. Èyí ni pẹpẹ tùràrí wúrà, ó di ẹ̀ẹ̀mejì sẹ́yìn tí tùràrí àwọn àwokòtò wúrà láti orí pẹpẹ yìí ti ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àdúrà àwọn ẹni mímọ́. (Ìṣípayá 5:8; 8:3, 4) Torí náà, ohùn kan ṣoṣo yìí dúró fún àdúrà táwọn ẹni mímọ́ lórí ilẹ̀ ayé ń gbà níṣọ̀kan. Wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé ká dá àwọn nídè káwọn lè máa fi aápọn ṣe iṣẹ́ ìsìn àwọn lọ bí “àwọn òjíṣẹ́” Jèhófà, níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, “àwọn áńgẹ́lì” ní ìpìlẹ̀ ti túmọ̀ sí “àwọn òjíṣẹ́.” Kí ló dé táwọn áńgẹ́lì náà fi jẹ́ mẹ́rin? Nọ́ńbà ìṣàpẹẹrẹ yìí jọ bí ẹni ń fi hàn pé wọn yóò wà létòlétò tó bẹ́ẹ̀ tí wọn yóò fi kárí ilẹ̀ ayé pátápátá, ìyẹn igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.—Ìṣípayá 7:1; 20:8.
3. Ọ̀nà wo la gbà “de” áńgẹ́lì mẹ́rin náà “síbi odò ńlá Yúfírétì”?
3 Ọ̀nà wo la gbà “de” àwọn áńgẹ́lì yẹn “síbi odò ńlá Yúfírétì”? Odò Yúfírétì ìgbàanì ni ààlà tó wà ní ìhà àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 15:18; Diutarónómì 11:24) Ó hàn gbangba pé àwọn áńgẹ́lì náà la ti ṣèdíwọ́ fún ní ààlà ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi fún wọn, tó túmọ̀ sí àgbègbè ìgbòkègbodò orí ilẹ̀ ayé. A dá wọn dúró láti má ṣe bọ́ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà ti gbé lé wọn lọ́wọ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Yúfírétì sábà máa ń ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Bábílónì gan-an, pẹ̀lúpẹ̀lù, lẹ́yìn ìṣubú Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo 70 ọdún níbẹ̀ nínú oko òǹdè, àwọn ni wọ́n “dè síbi odò ńlá Yúfírétì.” (Sáàmù 137:1) Lọ́dún 1919, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí wà nínú ìkálọ́wọ́kò tó jọ ìyẹn, wọ́n ń banú jẹ́, wọ́n sì ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà.
4. Iṣẹ́ wo làwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà ní í ṣe, báwo ló sì ṣe di ṣíṣe?
4 Ó múni láyọ̀, láti gbọ́ tí Jòhánù ròyìn pé: “A sì tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, àwọn tí a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún náà, láti pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà.” (Ìṣípayá 9:15) Jèhófà máa ń ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ gẹ́ẹ́. Ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò, ó sì ń pa á mọ́. Fún ìdí yìí, ìgbà tó tó àkókò tó ti ṣètò tẹ́lẹ̀, tó bá a mu wẹ́kú láti parí ohun tàwọn òjíṣẹ́ yìí ní í ṣe, ló tú wọn sílẹ̀. Fojú inú wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó bí wọ́n ti ń kúrò nínú ìdè lọ́dún 1919, tí wọ́n sì ti ṣe tán láti ṣiṣẹ́! Iṣẹ́ wọn ò mọ sórí dídáni lóró nìkan, àmọ́ ó kan kí wọ́n “pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn.” Èyí tan mọ́ àwọn ìyọnu tí ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ kéde, tó pọ́n ìdá mẹ́ta ilẹ̀ ayé, òkun, àti ẹ̀dá inú òkun, àwọn ìsun omi àti àwọn odò, àtàwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ọ̀run lójú. (Ìṣípayá 8:7-12) Áńgẹ́lì mẹ́rin náà ṣe jù báyẹn lọ. Wọ́n “pa” ní ìtumọ̀ ti pé wọ́n tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé òkú ni wọ́n nípa tẹ̀mí. Àwọn ìkéde tó dún jáde bíi kàkàkí, ìyẹn àwọn ìkéde tá a ti ń ṣe látọdún 1922 wá títí di ìsinsìnyí, ló ṣe èyí.
5. Lórí ọ̀ràn ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, báwo ni ìró kàkàkí kẹfà ṣe dún lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́dún 1927?
5 Rántí pé áńgẹ́lì ọ̀run náà ṣẹ̀ṣẹ̀ fun kàkàkí kẹfà ni. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ìkẹfà nínú ọ̀wọ́ àwọn àpéjọ tí wọ́n ń ṣe lọ́dọọdún nílùú Tòróńtò, Ontario, lórílẹ̀-èdè Kánádà, lọ́dún 1927. A gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday July 24, ọdún 1927 sáfẹ́fẹ́ nípasẹ̀ ilé iṣẹ́ rédíò mẹ́tàléláàádọ́ta tí wọ́n so kọ́ra, èyí ni ètò ìròyìn alápapọ̀ tó tíì gbòòrò jù lọ títí di àkókò yẹn. Ọ̀kẹ́ àìmọye làwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn lórí ètò yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ìpinnu alágbára kan tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n ti kú nípa tẹ̀mí, ìpinnu náà sì ké sáwọn èèyàn pé: “Ní wákàtí tí nǹkan dojú rú yìí, Jèhófà Ọlọ́run ń ké sáwọn èèyàn láti pa ‘ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì’ tàbí ‘ìsìn Kristẹni àtọwọ́dá’ tì kí wọ́n sì kọ̀ ọ́ lákọ̀tán kí wọ́n sì kẹ̀yìn sí i pátápátá . . . ; [jẹ́ kí] àwọn èèyàn fún Jèhófà Ọlọ́run àti Ọba tó yàn àti ìjọba rẹ̀ ní ìfọkànsìn wọn pátápátá kí wọ́n sì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run, Ọba àti ìjọba rẹ̀ nìkan làwọn tẹrí ba fún.” “Òmìnira fún Àwọn Èèyàn” ni àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tó tẹ̀ lé e. J. F. Rutherford sọ èyí tagbáratagbára gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, èyí sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú “iná àti èéfín àti imí ọjọ́” tí Jòhánù rí tẹ̀ lé e nínú ìran.
6. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe agbo àwọn agẹṣinjagun tó rí tẹ̀ lé e?
6 “Iye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti agbo agẹṣinjagun náà sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún: mo gbọ́ iye wọn. Báyìí sì ni mo ṣe rí àwọn ẹṣin náà nínú ìran náà, àti àwọn tí wọ́n jókòó lórí wọn: wọ́n ní àwo ìgbàyà pupa bí iná àti búlúù bí háyásíǹtì àti yẹ́lò bí imí ọjọ́; orí àwọn ẹṣin náà sì dà bí orí kìnnìún, iná àti èéfín àti imí ọjọ́ sì jáde wá láti ẹnu wọn. Ìyọnu àjàkálẹ̀ mẹ́ta wọ̀nyí ni a fi pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà, láti inú iná àti èéfín àti imí ọjọ́ tí ó jáde wá láti ẹnu wọn.”—Ìṣípayá 9:16-18.
7, 8. (a) Abẹ́ ìdarí atọ́nisọ́nà ta ni agbo agẹṣinjagun yìí tí ń sán jáde wá bí ààrá? (b) Láwọn ọ̀nà wo ni agbo agẹṣinjagun yìí gbà jọ àwọn eéṣú tó ṣáájú rẹ̀?
7 Ó ṣe kedere pé lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà ni agbo agẹṣinjagun yìí fi sán jáde bí ààrá. Ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ mà lèyí o! Fojú inú wo ohun tí wàá ṣe ká ní ìwọ ni irú agbo agẹṣinjagun kan báyẹn fẹ́ wá dojú kọ! Ìrísí wọn lásán gan-an ti tó mú kí ọkàn ẹ là gààrà. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí bí agbo agẹṣinjagun yìí ṣe jọ àwọn eéṣú tó ṣáájú wọn? Àwọn eéṣú náà dà bí ẹṣin; àwọn ẹṣin wà nínú agbo agẹṣinjagun yìí. Èyí fi hàn nígbà náà pé àwọn méjèèjì ń lọ́wọ́ nínú ogun tí Ọlọ́run ń darí. (Òwe 21:31) Àwọn eéṣú náà ní eyín tó dà bíi ti kìnnìún; àwọn ẹṣin agbo agẹṣinjagun yìí náà ní orí tó dà bíi ti kìnnìún. Nítorí náà ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì ní í ṣe pẹ̀lú Kìnnìún onígboyà ti ẹ̀yà Júdà náà, Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ Aṣáájú, Balógun, àti Àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn.—Ìṣípayá 5:5; Òwe 28:1.
8 Àtàwọn eéṣú àti agbo agẹṣinjagun náà ni wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ ìdájọ́ Jèhófà. Àwọn eéṣú náà ṣẹ́ yọ láti inú èéfín tó ṣàpẹẹrẹ ègbé àti iná apanirun fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì; iná, èéfín, àti imí ọjọ́ sì ń jáde látẹnu àwọn ẹṣin náà. Àwọn eéṣú náà ní àwo ìgbàyà irin, tó túmọ̀ sí pé ìfọkànsìn tí ò ṣeé tẹ̀ fún òdodo ló dáàbò bo ọkàn wọn; agbo agẹṣinjagun yìí wọ àwo ìgbàyà aláwọ̀ pupa, búlúù, àti yẹ́lò, èyí tó ń ṣàfihàn iná, èéfín, àti imí ọjọ́ tó ń wá látàrí àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ panipani tó ń tẹnu àwọn ẹṣin náà tú jáde. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 19:24, 28; Lúùkù 17:29, 30.) Àwọn eéṣú náà ní ìrù tó dà bíi ti àkekèé láti fi dáni lóró; àwọn ẹṣin yìí ní ìrù tí ó dà bíi ti ejò láti fi pani! Ó dà bí ẹni pé ohun táwọn eéṣú náà bẹ̀rẹ̀ ni agbo agẹṣinjagun yìí fẹ́ máa fi ìtara bá lọ títí tó fi máa parí.
9. Kí ni agbo agẹṣinjagun náà ṣàpẹẹrẹ?
9 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni agbo agẹṣinjagun yìí ṣàpẹẹrẹ? A ti rí bí ẹgbẹ́ Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ẹ̀san tí Jèhófà máa san àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Pẹ̀lú ìpolongo tó ń dún bíi kàkàkí yìí, wọ́n ní ọlá àṣẹ láti ‘tani àti láti ṣọṣẹ́.’ A retí bákan náà pé Jèhófà yóò lo ẹgbẹ́ Jòhánù kan náà yìí tó wà láàyè láti “pa” ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti àwùjọ àwọn àlùfáà rẹ̀, ní ìtumọ̀ pé wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ pé ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti kú fin-ín-fin-ín lójú Ọlọ́run, Jèhófà ti gbá a jù nù, ó sì ti wà ní sẹpẹ́ láti dèrò inú “ìléru oníná” ti ìparun àìnípẹ̀kun. Àní sẹ́, gbogbo Bábílónì Ńlá gbọ́dọ̀ pa run. (Ìṣípayá 9:5, 10; 18:2, 8; Mátíù 13:41-43) Àmọ́ ṣá o, ṣáájú ìparun rẹ̀, ẹgbẹ́ Jòhánù ń lo “idà ẹ̀mí, ìyẹn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” láti fi tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n ti dòkú. Áńgẹ́lì mẹ́rin àtàwọn agẹṣin náà ló ń darí bí wọ́n ṣe ń pa “ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn náà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Éfésù 6:17; Ìṣípayá 9:15, 18) Èyí fi hàn pé bí agbo ọmọ ogun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí ṣe yan wàìwàì lọ sójú ogun, wọ́n wà létòlétò lábẹ́ àbójútó Jésù Kristi Olúwa.
Ẹgbẹẹgbàárùn-ún Méjì Lọ́nà Ẹgbẹẹgbàárùn-ún
10. Lọ́nà wo ni agbo agẹṣinjagun fi jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún?
10 Báwo ni agbo agẹṣinjagun yìí ṣe jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún? Ẹgbàárùn-ún kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. Á wá jẹ́ pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún yóò jẹ́ igba mílíọ̀nù.a Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù làwọn olùpòkìkí Ìjọba ló wà báyìí, ṣùgbọ́n iye wọ́n kéré lọ́pọ̀lọpọ̀ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù! Síbẹ̀, rántí ọ̀rọ̀ Mósè nínú Númérì 10:36: “Jèhófà, padà sọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.” (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 24:60.) Lóréfèé, ìyẹn á túmọ̀ sí, ‘Padà sọ́dọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá Ísírẹ́lì.’ Àmọ́, bíi mílíọ̀nù méjì sí mẹ́ta péré niye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè. Nítorí náà, kí ni Mósè ń sọ? Ó dájú pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á jẹ́ àìmọye bí “àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun,” dípò kí wọ́n ṣeé kà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17; 1 Kíróníkà 27:23) Nítorí náà, ó lo ọ̀rọ̀ náà, “ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” láti sọ iye tó pọ̀ ṣùgbọ́n tí kò lè sọ bó ṣe pọ̀ tó. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì The New English Bible fi túmọ̀ ẹsẹ̀ yìí báyìí: “Sinmi, OLÚWA ẹgbẹẹgbẹ̀rún àìlóǹkà Ísírẹ́lì.” Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ kejì fún ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹẹgbàárùn-ún” tá a rí nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè ti Gíríìkì àti Hébérù: “ògìdìgbó aláìníye,” “ògìdìgbó.”—The New Thayer’s Greek-English Lexicon of the New Testament; A Hebrew and English Lexicon of the Old Testament ti Gesenius, tí Edward Robinson túmọ̀.
11. Kí ni ẹgbẹ́ Jòhánù nílò láti di ẹgbẹẹgbàárùn-ún, kódà kó jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ?
11 Síbẹ̀síbẹ̀, iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ Jòhánù tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá—ó dín ní ẹgbàáàrún kan ní ti gidi. Báwo la ṣe wá lè fi wọ́n wé agbo agẹṣinjagun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àìlóǹkà? Tí wọ́n bá ní láti di ẹgbẹẹgbàárùn-ún, kódà kó jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ṣé wọn ò ní nílò àwọn tó máa tì wọ́n lẹ́yìn? Èyí lohun tí wọ́n ti nílò, wọ́n sì ti rí i gbà lọ́lá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà! Ibo ni àwọn wọ̀nyí ti wá?
12, 13. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún 1918 sí 1935 ló jẹ́ ká rí ibi tí àwọn tó ṣe ìtìlẹ́yìn náà ti wá?
12 Láti ọdún 1918 sí ọdún 1922, ẹgbẹ́ Jòhánù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ìrètí aláyọ̀ fáráyé tó wà nínú ìdààmú pé “ọ̀kẹ́ àìmọye tí wọ́n wà láàyè nísinsìnyí kì yóò kú láé.” Ní 1923 wọ́n tún sọ ọ́ di mímọ̀ pé àwọn àgùntàn inú Mátíù 25:31-34 yóò jogún ìyè lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n tún kéde irú ìrètí yìí nínú ìwé kékeré náà Freedom for the Peoples, tí wọ́n mú jáde ní àpéjọ àgbáyé ti ọdún 1927. Kété lẹ́yìn ọdún 1930, wọ́n fi hàn pé ẹgbẹ́ Jèhónádábù adúróṣinṣin, àti ‘àwọn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn tí wọ́n sì ń kérora’ nítorí ipò tẹ̀mí tó ń ṣeni láàánú táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà, bá àwọn àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ tí wọ́n ní ìrètí ìyè lórí ilẹ̀ ayé mu. (Ìsíkíẹ́lì 9:4; 2 Àwọn Ọba 10:15, 16) Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti August 15, 1934 ń darí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sí ‘àwọn ìlú ńlá ìsádi’ tòde òní, ó sọ pé: “Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jónádábù ti gbọ́ ìró kàkàkí Ọlọ́run wọ́n sì ti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ náà nípa sísá tọ ètò Ọlọ́run lọ àti nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run, ibẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́dọ̀ wà títí lọ.”—Númérì 35:6.
13 Lọ́dún 1935, a ké sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ti agbo Jónádábù yìí ní pàtàkì láti wá sí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Níbẹ̀, lọ́jọ́ Friday, May 31, J. F. Rutherford sọ àsọyé rẹ̀ olókìkí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ògìdìgbó Ńlá Náà,” nínú èyí tó ti fi hàn kedere pé àwọn èèyàn kan náà ni àwùjọ ti Ìṣípayá 7:9 àti àwọn àgùntàn ti Mátíù 25:33, wọ́n jẹ́ àwùjọ olùṣèyàsímímọ́ tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀ lọ́nà, ní àpéjọ yẹn òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun ló ṣèrìbọmi, púpọ̀ jù lọ wọn ló sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá.b
14. Ṣé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà máa kópa nínú fifi ẹṣin jagun lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìpinnu wo la sì ṣe lọ́dún 1963?
14 Ǹjẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ti kópa nínú fifi ẹṣin jagun yìí, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1922, tí wọ́n sì tẹnu mọ́ gan-an ní àpéjọ àgbègbè ti ìlú Tòróńtò lọ́dún 1927? Dájúdájú, lábẹ́ ìdarí áńgẹ́lì mẹ́rin náà, tó túmọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù, wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀! Ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun,” tá a ṣe yí ká ayé lọ́dún 1963, wọ́n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Jòhánù nínú ìpinnu kan tí ń runi sókè. Ìpinnu náà polongo pé ayé “dojú kọ ìjàngbọ̀n tó máa mi gbogbo àgbáyé jìgìjìgì, irú èyí táyé ò tíì rí rí, àti pé gbogbo àwọn ètò ìṣèlú rẹ̀ àti ìsìn Bábílónì rẹ̀ òde òní ni a ó mì títí yóò fi fọ́ sí wẹ́wẹ́.” Wọ́n sọ nínú ìpinnu náà pé “àwa yóò máa bá a nìṣó láti máa polongo ‘ìhìn rere àìnípẹ̀kun’ nípa ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn láìṣègbè, a ó sì máa polongo àwọn ìdájọ́ rẹ̀, èyí tó dà bí ìyọnu fáwọn ọ̀tá rẹ̀, àmọ́ tí yóò fi mú òmìnira wá fún gbogbo àwọn tó fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá náà lọ́nà tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” Tìtaratìtara ni àpapọ̀ iye tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlélógún lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ dín mẹ́tàlélógún [454,977] tó pé jọ fi tẹ́wọ́ gba ìpinnu yìí, tá a bá sì kó ọgọ́rùn èèyàn jọ nínú wọn, iye tó ju márùndínlọ́gọ́rùn-ún lọ ló jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ní àpéjọ mẹ́rìnlélógún [24] káàkiri àgbáyé.
15. (a) Ní ọdún 2005, báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe pọ̀ tó nínú àwọn òṣìṣẹ́ tí Jèhófà ń lò nínú pápá? (b) Báwo ni àdúrà Jésù nínú Jòhánù 17:20, 21 ṣe fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín ogunlọ́gọ̀ ńlá náà àti ẹgbẹ́ Jòhánù hàn?
15 Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti ń bá a lọ láti fi hàn pé àwọn wà ní ìṣọ̀kan látòkèdélẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù nínú títú àwọn ìyọnu dà sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ní ọdún 2005, ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ló pọ̀ jù nínú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí Jèhófà ń lò nínú pápá. Àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá fi tọkàntọkàn fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù, àwọn tí Jésù gbàdúrà nípa wọn nínú Jòhánù 17:20, 21 pé: “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.” Bí ẹgbẹ́ Jòhánù tí í ṣe àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mú ipò iwájú lábẹ́ ìdarí Jésù, ogunlọ́gọ̀ ńlá onítara ń dara pọ̀ mọ́ wọn láti rọ́ lu àwọn ọ̀tá gẹ́gẹ́ bí ara agbo agẹṣinjagun yìí, èyí tó jẹ́ aṣèparun jù lọ látọjọ́ táláyé di dáyé!c
16. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹnu àti ìrù àwọn ẹṣin ìṣàpẹẹrẹ náà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe múra ẹnu àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn? (d) Kí ló bá “ìrù wọ́n [tó] dà bí ejò” mu?
16 Agbo agẹṣinjagun yẹn nílò ohun ìjà fún ogun náà. Ẹ sì wo bí Jèhófà ṣe pèsè rẹ̀ lọ́nà ìyanu! Jòhánù ṣàpèjúwe rẹ̀ pé: “Nítorí ọlá àṣẹ àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn; nítorí ìrù wọ́n dà bí ejò, wọ́n sì ní orí, ìwọ̀nyí ni wọ́n sì fi ń ṣe ìpalára.” (Ìṣípayá 9:19) Jèhófà ti yan àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣèyàsímímọ́ àti ìrìbọmi fún iṣẹ́ ìsìn yìí. Ó ti kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe wàásù ọ̀rọ̀ náà nípasẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ìpàdé ìjọ tó fi mọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn, èyí sì mú kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti fàṣẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ahọ́n àwọn tí a kọ́.” Ó ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí wọn lẹ́nu ó sì ti rán wọn láti lọ sọ àwọn ìdájọ́ rẹ̀ di mímọ̀ “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (2 Tímótì 4:2; Aísáyà 50:4; 61:2; Jeremáyà 1:9, 10; Ìṣe 20:20) Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń fi ọ̀kẹ́ àìmọye Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, èyí sì bá àpèjúwe “ìrù” náà mu. Lójú àwọn alátakò wọn tí wọ́n ń sọ fún nípa “ìpalára” tó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bí ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún ni agbo àwọn agẹṣinjagun wọ̀nyí rí lóòótọ́.—Fi wé Jóẹ́lì 2:4-6.
17. Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa nínú fífi ẹṣin jagun láwọn ilẹ̀ tá ò ti lè pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ torí pé wọ́n fi òfin de iṣẹ́ wa bí? Ṣàlàyé.
17 Àwọn tó ní ìtara jù lọ nínú agbo agẹṣinjagun yìí làwọn arákùnrin tó wà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àwọn àgùntàn láàárín àwọn ìkookò, ó di dandan fáwọn wọ̀nyí láti jẹ́ ‘oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.’ Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gẹ́gẹ́ bí onígbọràn sí Jèhófà, wọn ò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. (Mátíù 10:16; Ìṣe 4:19, 20; 5:28, 29, 32) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n ní lára àwọn ìwé tá a tẹ̀ tàbí bóyá wọn ò tiẹ̀ ní in rárá láti pín kiri ní gbangba, ṣé a lè sọ pé wọn ò dá sí iṣẹ́ fífi ẹṣin jagun náà bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Wọ́n ní ẹnu wọn àti àṣẹ látọ̀dọ̀ Jèhófà láti fi sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Wọ́n ń ṣe èyí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti pẹ̀lú ìyíniléròpadà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń mú ‘ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.’ (Dáníẹ́lì 12:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má fi ìrù wọn tani ní ti pé wọn ò fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbàkan-o-ṣubú sílẹ̀, iná, èéfín, àti imí-ọjọ́ ìṣàpẹẹrẹ ń jáde látẹnu wọn bí wọ́n ti ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti òye wàásù nípa ọjọ́ ìdáláre Jèhófà tó ń sún mọ́lé.
18. Èdè mélòó ni agbo agẹṣinjagun yìí ti fi ṣe ìpínkiri ìwé ọ̀rọ̀ tó ń kó ìyọnu báni, ẹ̀dà mélòó sì ni wọ́n ti pín?
18 Láwọn ibòmíràn, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣì ń bá a lọ láti máa tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn ọ̀nà Bábílónì tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìpalára tó tọ́ sí wọn wá bá wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ní ọdún méjìdínláàádọ́rin [68] ṣáájú 2005, ó ti ṣeé ṣe fún àìmọye àwọn agẹṣinjagun yìí láti fáwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù Bíbélì, ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, àti ìwé pẹlẹbẹ ní èdè tó tó 450, èyí tó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ju ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún gidi lọ, èyí sì ṣeé ṣe nípa lílo àwọn ọ̀nà ìtẹ̀wé ìgbàlódé. Ẹ wo bí oró ìtani tí ìrù wọ̀nyẹn ti dá sílẹ̀ ti pọ̀ tó!
19, 20. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní pàtó la darí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń kó ìyọnu báni náà sí ní tààràtà, kí làwọn tó wà láwọn ilẹ̀ kan tó jìnnà sáwọn ibi tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀ ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà? (b) Ṣùgbọ́n báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ohun táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ṣe lórí ẹ̀?
19 Jèhófà ní in lọ́kàn pé kí ìhìn tí ń kó ìyọnu báni yìí “pa ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn.” Fún ìdí yìí, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì la darí ẹ̀ sí ní tààràtà. Ṣùgbọ́n ó ti dé àwọn ilẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sáwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ ibi táwọn èèyàn ti mọ àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní àmọ̀dunjú. Ṣé àwọn èèyàn tó wà láwọn ilẹ̀ yìí ti sún mọ́ Jèhófà nítorí rírí tí wọ́n ń rí i pé à ń mú ìyọnu bá ètò ìsìn oníwà ìbàjẹ́ yìí? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ti ṣe bẹ́ẹ̀! Àwọn onínú tútù àtàwọn èèyàn tó yááyì tó ń gbé láwọn àgbègbè tó jìnnà sí àgbègbè tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti jẹ gàba ń ṣègbọràn láìlọ́tìkọ̀. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò, Jòhánù ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n ṣe, ó ní: “Ṣùgbọ́n ìyókù àwọn ènìyàn tí ìyọnu àjàkálẹ̀ wọ̀nyí kò pa kò ronú pìwà dà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọ́n má ṣe jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù àti àwọn òrìṣà wúrà àti fàdákà àti bàbà àti òkúta àti igi, tí kò lè ríran tàbí gbọ́ràn tàbí rìn; wọn kò sì ronú pìwà dà àwọn ìṣìkàpànìyàn wọn tàbí iṣẹ́ ìbẹ́mìílò wọn tàbí àgbèrè wọn tàbí olè jíjà wọn.” (Ìṣípayá 9:20, 21) Kò ní í ṣẹlẹ̀ pé kí gbogbo aráyé tí kò ronú pìwà dà yí padà lọ́nà yẹn. Gbogbo àwọn tó bá ń bá a lọ láwọn ọ̀nà burúkú wọn ló máa dojú kọ ìdájọ́ mímúná lẹ́sẹ̀-ò-gbèjì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ ńlá ìdáláre rẹ̀. Ṣùgbọ́n “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”—Jóẹ́lì 2:32; Sáàmù 145:20; Ìṣe 2:20, 21.
20 Ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí jẹ́ ara ègbé kejì. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i láwọn orí tó wà níwájú, púpọ̀ sí i ń bọ̀ lọ́nà kí ègbé náà tó tán.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà, Commentary on Revelation, látọwọ́ Henry Barclay Swete, sọ nípa iye náà, “ẹgbẹẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” pé: “Pẹ̀lú bí iye yìí ṣe pọ̀ tó, kò yẹ ká retí pé báwọn agẹsinjagun náà á ṣe pọ̀ tó nìyẹn nígbà tí ìran náà bá nímùúṣẹ.”
b Wo ojú ìwé 119 sí 126 nínú ìwé yìí; tún wo ojú ìwé 83 àti 84 nínú Vindication, Ìwé Kẹta. Ọdún 1932 ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ ìwé náà jáde.
c Láìdà bí àwọn eéṣú náà, agbo àwọn agẹṣinjagun tí Jòhánù rí yìí ò dé “ohun tí ó rí bí adé tí ó dà bí wúrà.” (Ìṣípayá 9:7) Èyí bá òtítọ́ náà mu pé ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó pọ̀ jù nínú agbo agẹṣinjagun náà lónìí, kò nírètí láti jọba nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149]
Bí áńgẹ́lì náà ṣe fun kàkàkí kẹfà, ègbé kejì wọlé dé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 150, 151]
Àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin ń darí agbo agẹṣinjagun tó tíì lágbára jù lọ látọjọ́ táláyé ti dáyé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 153]
Agbo agẹṣinjagun tí ò lóǹkà ti pín ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì kiri
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 154]
Ìyókù àwọn èèyàn náà kò ronú pìwà dà