Orí 24
Ìhìn Tó Dùn Tó sì Tún Korò
Ìran 6—Ìṣípayá 10:1–11:19
Ohun tó dá lé: Ìran inú àkájọ ìwé kékeré náà; àwọn ìrírí tẹ́ńpìlì; fífun kàkàkí keje
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látìgbà tí Jèhófà ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 títí di ìgbà ìpọ́njú ńlá
1, 2. (a) Kí ni ègbé kejì yọrí sí, ìgbà wo la ó sì polongo pé ègbé yìí ti kásẹ̀? (b) Ta ni Jòhánù rí báyìí tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run?
ÈGBÉ kejì ti ṣọṣẹ́ gan-an. Ó ti kó ìyọnu bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aṣáájú wọn, ìyẹn “ìdá mẹ́ta àwọn ènìyàn,” tí ègbé náà tú àṣírí wọn pé bó bá dọ̀ràn àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, òkú ni wọ́n. (Ìṣípayá 9:15) Lẹ́yìn èyí, Jòhánù ti ní láti ṣe kàyéfì nípa ohun tó máa tìdí ègbé kẹta jáde. Ṣùgbọ́n dúró ná! Ègbé kejì kò tíì parí, àyàfi nígbà tá a bá dé orí kókó kan tó wà lákọsílẹ̀ nínú Ìṣípayá 11:14. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jòhánù yóò rí àwọn nǹkan kan, èyí tóun fúnra rẹ̀ kópa gan-an nínú rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìran kan tó jẹ́ àgbàyanu:
2 “Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tí a fi àwọsánmà ṣe ní ọ̀ṣọ́, òṣùmàrè sì wà ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí ọwọ̀n iná.”—Ìṣípayá 10:1.
3. (a) Ta ni “áńgẹ́lì alágbára” náà? (b) Kí ni òṣùmàrè tí ń bẹ lórí rẹ̀ túmọ̀ sí?
3 Ta ni “áńgẹ́lì alágbára” yìí? Ó dájú pé Jésù Kristi tá a ṣe lógo ni, níbi tó ti ń kópa mìíràn. Òun la fi àwọsánmà tí kò ṣeé fojú rí ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, èyí tó rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jòhánù ti sọ ní ìṣáájú nípa Jésù pé: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà, gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un lọ́kọ̀.” (Ìṣípayá 1:7; fi wé Mátíù 17:2-5.) Òṣùmàrè tó wà lórí rẹ̀ rán wa létí ìran tí Jòhánù ti kọ́kọ́ rí nípa ìtẹ́ Jèhófà, pẹ̀lú ‘òṣùmàrè rẹ̀ tó dà bí òkúta émírádì ní ìrísí.’ (Ìṣípayá 4:3; fi wé Ìsíkíẹ́lì 1:28.) Òṣùmàrè yẹn túmọ̀ sí ìpalọ́lọ́ àti àlàáfíà tó yí ìtẹ́ Ọlọ́run ká. Lọ́nà kan náà, òṣùmàrè yìí, tó wà ní orí áńgẹ́lì náà, fi í hàn gẹ́gẹ́ bí àkànṣe òjíṣẹ́ àlàáfíà, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” tí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀.—Aísáyà 9:6, 7.
4. Kí ló túmọ̀ sí (a) pé ojú áńgẹ́lì alágbára náà “dà bí oòrùn”? (b) pé ẹsẹ̀ áńgẹ́lì náà “dà bí ọwọ̀n iná”?
4 “Bí oòrùn” ni ojú áńgẹ́lì alágbára náà ṣe rí. Nínú ìran tí Jòhánù ti kọ́kọ́ rí nípa Jésù nínú tẹ́ńpìlì ti ọ̀run, ó ṣàkíyèsí pé ojú Jésù “dà bí oòrùn nígbà tí ó bá ń ràn nínú agbára rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:16) Jésù, gẹ́gẹ́ bí “oòrùn òdodo,” ń ràn, pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀, fún àǹfààní àwọn tí wọ́n bẹ̀rù orúkọ Jèhófà. (Málákì 4:2) Tojú tẹsẹ̀ áńgẹ́lì yìí ló jẹ́ ológo “bí ọwọ̀n iná.” Dídúró tó dúró gbọn-in gbọn-in fi hàn pé ó jẹ́ Ẹni tí Jèhófà ti fi ‘gbogbo ọlá àṣẹ fún ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.’—Mátíù 28:18; Ìṣípayá 1:14, 15.
5. Kí ni Jòhánù rí ní ọwọ́ áńgẹ́lì alágbára náà?
5 Jòhánù sọ síwájú sí i pé: “Ó sì ní àkájọ ìwé kékeré tí a ṣí sílẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sórí òkun, ṣùgbọ́n ti òsì rẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 10:2) Àkájọ ìwé mìíràn kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, a kò fi èdìdì di ìwé náà. Àwa àti Jòhánù lè máa retí pé a tún máa tó ṣí ọ̀pọ̀ nǹkan tí ń wúni lórí payá fún wa. Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jòhánù ta wá lólobó nípa Ìṣípayá tí yóò tẹ̀ lé e.
6. (a) Kí nìdí tó fi bá a mu pé ẹsẹ̀ Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé àti òkun? (b) Ìgbà wo ni Sáàmù 8:5-8 nímùúṣẹ ní kíkún?
6 Ẹ jẹ́ ká padà sí àpèjúwe Jésù. Ẹsẹ̀ rẹ̀ oníná wà lórí ilẹ̀ ayé àti lórí òkun, èyí tó ní àṣẹ kíkún lé lórí nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí sáàmù kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ti sọ ló rí: “Ìwọ [Jèhófà] sì tẹ̀ síwájú láti ṣe é [Jésù] ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run, o sì wá fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé. O mú kí ó jọba lé àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ; o ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn ẹran ọ̀sìn kéékèèké àti màlúù, gbogbo wọn, àti àwọn ẹranko pápá gbalasa pẹ̀lú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú òkun, ohunkóhun tí ń la àwọn ipa ọ̀nà òkun kọjá.” (Sáàmù 8:5-8; tún wo Hébérù 2:5-9.) Sáàmù yìí nímùúṣẹ ní kíkún lọ́dún 1914 nígbà tá a fi Jésù jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run tí àkókò òpin sì bẹ̀rẹ̀. Nípa báyìí, ohun tí Jòhánù rí nínú ìran yìí ti ń nímùúṣẹ láti ọdún yẹn wá.—Sáàmù 110:1-6; Ìṣe 2:34-36; Dáníẹ́lì 12:4.
Ààrá Méje
7. Báwo ni áńgẹ́lì alágbára náà ṣe ké, kí sì ni igbe rẹ̀ fi hàn?
7 Áńgẹ́lì alágbára yìí fúnra rẹ̀ ló dá àṣàrò tí Jòhánù ṣì ń ṣe nípa rẹ̀ dúró: “Ó [áńgẹ́lì náà] sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí kìnnìún bá ké ramúramù. Nígbà tí ó sì ké jáde, ààrá méje fọ ohùn tiwọn.” (Ìṣípayá 10:3) Irú igbe tó rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò gba àfiyèsí Jòhánù, á sì túbọ̀ mú kó dájú pé lóòótọ́, Jésù ni “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà.” (Ìṣípayá 5:5) Jòhánù tún mọ̀ pé nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń sọ pé Jèhófà “ké ramúramù.” Jèhófà ké ramúramù nínú àsọtẹ́lẹ̀ láti kéde pé òun á ṣàkójọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí àti láti kéde dídé “ọjọ́ Jèhófà” nínú èyí tí yóò ti pa àwọn ọ̀tá run. (Hóséà 11:10; Jóẹ́lì 3:14, 16; Ámósì 1:2; 3:7, 8) Kíké tí áńgẹ́lì alágbára yìí ké bíi kìnnìún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńláǹlà bẹ́ẹ̀ ṣì máa wáyé nípa òkun àti ilẹ̀ ayé. Ó ké pe àwọn ààrá méje náà láti sọ̀rọ̀.
8. Kí ni ‘ohùn àwọn ààrá méje’ náà?
8 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Jòhánù ti gbọ́ tí ìró àwọn ààrá ń jáde wá látinú ìtẹ́ Jèhófà gangan. (Ìṣípayá 4:5) Nígbà ayé Dáfídì, wọ́n máa ń pe ààrá ní “ohùn Jèhófà” nígbà míì. (Sáàmù 29:3) Lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí Jèhófà kéde pé òun máa ṣe orúkọ òun lógo táwọn èèyàn sì gbọ́ ohun rẹ̀ sétí, bí ààrá ni ohùn rẹ̀ ṣe dún létí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. (Jòhánù 12:28, 29) Fún ìdí yìí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ jáde nípa àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ni ‘ohùn ààrá méje’ náà. Níwọ̀n bí àwọn ààrá náà ti jẹ́ “méje,” èyí túmọ̀ sí pé ohun tí Jòhánù gbọ́ pé pérépéré.
9. Kí ni ohùn kan láti ọ̀run wá pa láṣẹ?
9 Fetí sílẹ̀ ná! Ohùn mìíràn tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í dún. Ohùn náà pàṣẹ kan tó ti ní láti jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Jòhánù: “Wàyí o, nígbà tí ààrá méje náà sọ̀rọ̀, mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé; ṣùgbọ́n mo gbọ́ tí ohùn kan láti ọ̀run wí pé: ‘Fi èdìdì di àwọn ohun tí ààrá méje náà sọ, má sì kọ wọ́n sílẹ̀.’” (Ìṣípayá 10:4) Ara Jòhánù ti ní láti wà lọ́nà láti gbọ́ àwọn iṣẹ́ táwọn ààrá wọnnì fẹ́ jẹ́ kó sì kọ wọ́n sílẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí ti retí lójú méjèèjì pé kí Jèhófà ṣí àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe payá kí wọ́n lè tẹ̀ ẹ́ jáde. Àkókò tí Jèhófà yàn nìkan ni irú àwọn ìṣípayá bẹ́ẹ̀ máa ń wá.—Lúùkù 12:42; tún wo Dáníẹ́lì 12:8, 9.
Àṣírí Mímọ́ Náà Wá sí Ìparí
10. Ta ni áńgẹ́lì alágbára náà fi búra, ìkéde wo ló sì búra nípa rẹ̀?
10 Kí àkókò yẹn tó tó, Jèhófà ní iṣẹ́ mìíràn fún Jòhánù. Lẹ́yìn tí ààrá méje náà ti dún, áńgẹ́lì alágbára náà tún sọ̀rọ̀: “Áńgẹ́lì tí mo rí tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀ ayé sì gbé ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè ọ̀run, ó sì fi Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé, tí ó dá ọ̀run àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ àti ilẹ̀ ayé àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀ àti òkun àti àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀, búra pé: ‘Kì yóò sí ìjáfara kankan mọ́.’” (Ìṣípayá 10:5, 6) Ta ni áńgẹ́lì alágbára náà fi búra? Jésù tá a ti ṣe lógo kò fi ara rẹ̀ búra, bí kò ṣe Ẹni tó ga ju ẹni gbogbo lọ, ìyẹn Jèhófà, Ẹlẹ́dàá tí kò lè kú tó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 45:12, 18) Lẹ́yìn ìbúra yìí, áńgẹ́lì náà mú un dá Jòhánù lójú pé kò sí ohun tó tún ń dá Ọlọ́run dúró mọ́.
11, 12. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé “kì yóò sí ìjáfara kankan mọ́”? (b) Kí la mú wá sí ìparí?
11 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a tú níhìn-ín sí “ìjáfara” ni khroʹnos, èyí tó túmọ̀ ní ti gidi sí “àkókò.” Àwọn kan ti tipa báyìí rò pé bó ṣe yẹ ká tú ìpolongo áńgẹ́lì yìí ni pé: “Kì yóò sí àkókò kankan mọ́,” bí ẹni pé àkókò yóò dópin. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà khroʹnos níhìn-ín la lò láìsí ọ̀rọ̀ atọ́ka kankan. Nítorí náà, kò túmọ̀ sí àkókò ní gbogbo gbòò, kàkà bẹ́ẹ̀, “àkókò kan” tàbí “sáà àkókò kan” ló jẹ́. Lédè mìíràn, kì yóò sí sáà àkókò kankan síwájú sí i (tàbí, ìjáfara) mọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì kan tá a mú jáde látinú khroʹnos yìí náà ni Pọ́ọ̀lù tún lò nínú Hébérù 10:37 níbi tó ti kọ̀wé pé, “ẹni tí ń bọ̀ . . . kì yóò sì pẹ́” nígbà tó ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Hábákúkù 2:3, 4.
12 “Kì yóò sí ìjáfara kankan mọ́.” Gbólóhùn yìí máa fa ẹgbẹ́ Jòhánù tó ń darúgbó lọ lónìí mọ́ra o! Lọ́nà wo ni kò fi sí ìjáfara? Jòhánù sọ fún wa pé: “Ṣùgbọ́n ní àwọn ọjọ́ ìró ti áńgẹ́lì keje, nígbà tí ó máa tó fun kàkàkí rẹ̀, àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí ó polongo fún àwọn ẹrú tirẹ̀, àwọn wòlíì ni a mú wá sí ìparí ní tòótọ́.” (Ìṣípayá 10:7) Àkókò ti tó fún Jèhófà láti mú àṣírí mímọ́ rẹ̀ wá sí ìparí aláyọ̀ pátápátá, pẹ̀lú àṣeyọrí ológo sì ni!
13. Kí ni àṣírí mímọ́ Ọlọ́run?
13 Kí ni àṣírí mímọ́ yìí? Ó ní í ṣe pẹ̀lú irú-ọmọ tá a kọ́kọ́ ṣèlérí ní Édẹ́nì, èyí tí í ṣe Jésù Kristi ní pàtàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 1 Tímótì 3:16) Ó tún ní í ṣe pẹ̀lú ẹni tí obìnrin tó mú Irú-Ọmọ náà jáde jẹ́. (Aísáyà 54:1; Gálátíà 4:26-28) Bákan náà ló sì tún ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ onípò kejì lára ẹgbẹ́ irú-ọmọ náà, àti Ìjọba tí Irú-Ọmọ náà ti ń jọba. (Lúùkù 8:10; Éfésù 3:3-9; Kólósè 1:26, 27; 2:2; Ìṣípayá 1:5, 6) A gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba ọ̀run tí kò láfiwé yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé ní àkókò òpin.—Mátíù 24:14.
14. Kí nìdí tí Ìṣípayá fi so ègbé kẹta mọ́ Ìjọba Ọlọ́run?
14 Dájúdájú, kò sí ìròyìn mìíràn tó dára tó èyí. Síbẹ̀, Ìṣípayá 11:14, 15, so ègbé kẹta mọ́ Ìjọba náà. Kí nìdí? Nítorí pé fífun kàkàkí ìhìn rere náà pé àṣírí mímọ́ Ọlọ́run la ti mú wá sí ìparí, ìyẹn ni pé Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run ti wà níhìn-ín, jẹ́ ìròyìn tó kún fún ègbé fáwọn kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ti Sátánì. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 2:16.) Ó túmọ̀ sí pé ètò ayé tí wọ́n fẹ́ràn gidigidi kò ní pẹ́ pa run. Bí ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà ti ń sún mọ́ tòsí ni àwọn ohùn ààrá méje tó ní àwọn ìkìlọ̀ líle nínú tó sì ń ṣàpẹẹrẹ ohun búburú yìí, túbọ̀ ń ṣe kedere sí i tó sì ń dún kíkankíkan sí i.—Sefanáyà 1:14-18.
Àkájọ Ìwé Tó Wà ní Ṣíṣí
15. Kí ni ohùn tó wá láti ọ̀run àti áńgẹ́lì alágbára náà sọ fún Jòhánù, kí sì ni àbájáde rẹ̀ lórí Jòhánù?
15 Láàárín ìgbà tí Jòhánù fi ń dúró de fífun kàkàkí keje yìí àti mímú àṣírí mímọ́ Ọlọ́run wá sí ìparí, a tún fún un ní iṣẹ́ mìíràn: “Ohùn tí mo sì gbọ́ láti ọ̀run tún ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé: ‘Lọ, gba àkájọ ìwé ṣíṣísílẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ áńgẹ́lì tí ó dúró lórí òkun àti lórí ilẹ̀ ayé.’ Mo sì lọ bá áńgẹ́lì náà, mo sì sọ fún un pé kí ó fún mi ní àkájọ ìwé kékeré náà. Ó sì wí fún mi pé: ‘Gbà á, kí o sì jẹ ẹ́ tán, yóò sì mú ikùn rẹ korò, ṣùgbọ́n ní ẹnu rẹ yóò dùn bí oyin.’ Mo sì gba àkájọ ìwé kékeré náà ní ọwọ́ áńgẹ́lì náà, mo sì jẹ ẹ́ tán, ó sì dùn ní ẹnu mi bí oyin; ṣùgbọ́n nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, ó mú ikùn mi korò. Wọ́n sì wí fún mi pé: ‘Ìwọ gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n àti ọba púpọ̀.’”—Ìṣípayá 10:8-11.
16. (a) Báwo lohun kan tó jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jòhánù ṣe ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Ìsíkíẹ́lì náà? (b) Kí nìdí tí àkájọ ìwé kékeré náà fi dùn lẹ́nu Jòhánù, ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi korò bó ṣe ń dà nínú ikùn rẹ̀?
16 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jòhánù jọ èyí tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Ìsíkíẹ́lì nígbà tó wà nígbèkùn nílẹ̀ Bábílónì. A pàṣẹ fún òun náà láti jẹ àkájọ ìwé kan tó dùn ní ẹnu rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tó kún inú ikùn rẹ̀ tán, ó mú kó lọ sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun kíkorò fún ilé Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 2:8–3:15) Bákan náà, iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ ká jíhìn rẹ̀ ni àkájọ ìwé tó wà ní ṣíṣí yẹn, tí Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo fún Jòhánù. Jòhánù ní láti wàásù nípa “àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n àti ọba púpọ̀.” Jíjẹ àkájọ ìwé yìí dùn mọ́ ọn nítorí pé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. (Fi wé Sáàmù 119:103; Jeremáyà 15:15, 16.) Ṣùgbọ́n ó rí i pé ó korò bó ṣe ń dà nínú ikùn òun. Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bó ti rí fún Ìsíkíẹ́lì níṣàájú, ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí kò dùn mọ́ni tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹ̀dá èèyàn ọlọ̀tẹ̀.—Sáàmù 145:20.
17. (a) Àwọn wo ló sọ fún Jòhánù láti “tún” sàsọtẹ́lẹ̀, kí lèyí sì túmọ̀ sí? (b) Ìgbà wo ni ohun pípabanbarì tí Jòhánù rí yóò ní ìmúṣẹ?
17 Láìsí iyè méjì, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ló sọ fún Jòhánù láti tún sọ àsọtẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti lé Jòhánù lọ sí erékùṣù Pátímọ́sì, ó ti kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn, àti orílẹ̀-èdè, àti ahọ́n àti ọba. Ọ̀rọ̀ náà “tún,” túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ kọ ìyókù ìsọfúnni tá a kọ sílẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá, kó sì kéde rẹ̀. Ṣùgbọ́n rántí pé níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ńṣe ni Jòhánù alára ń kópa nínú ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ká sòótọ́, ohun tó kọ jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó máa nímùúṣẹ lẹ́yìn ọdún 1914, nígbà tí áńgẹ́lì alágbára náà bá ti wà ní ipò rẹ̀, pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ kan lórí ilẹ̀ ayé àti ọ̀kan lórí òkun. Kí wá ni ohun pípabanbarì yìí túmọ̀ sí fún ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí?
Àkájọ Ìwé Kékeré Náà Lónìí
18. Níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, kí ló fi hàn pé ẹgbẹ́ Jòhánù ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá?
18 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹ́ Jòhánù níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ni ohun tí Jòhánù rí ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ lọ́nà tó gbàfiyèsí. Òye wọn nígbà yẹn nípa àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe, títí kan ohun tí ààrá méje náà túmọ̀ sí, kò kún tó. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá, arákùnrin Charles Taze Russell sì ti sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ apá tó wà nínú rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Lẹ́yìn ikú rẹ̀ lọ́dún 1916, wọ́n kó ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé tó kọ jọ, wọ́n sì tẹ̀ wọ́n jáde nínú ìwé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Finished Mystery. Àmọ́ ṣá o, bí àkókò ti ń lọ, àlàyé tí ìwé yìí ṣe lórí ìwé Ìṣípayá di èyí tí kò tẹ́ni lọ́rùn mọ́. Àṣẹ́kù àwọn arákùnrin Kristi ní láti dúró díẹ̀ sí i títí dìgbà táwọn ìran náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ, kí wọ́n lè ní òye tó tọ̀nà nípa àkọsílẹ̀ onímìísí yìí.
19. (a) Báwo ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe lo ẹgbẹ́ Jòhánù kódà kí wọ́n tó tẹ àwọn ohùn ààrá méje náà jáde lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́? (b) Ìgbà wo ni Jésù fún ẹgbẹ́ Jòhánù ní àkájọ ìwé kékeré tó wà ní ṣíṣí náà, kí nìyẹn sì túmọ̀ sí pé wọ́n ní láti ṣe?
19 Àmọ́ ṣá o, bíi ti Jòhánù, Jèhófà ti lò wọ́n, kódà kí wọ́n tó tẹ àwọn ohùn ààrá méje náà jáde lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Wọ́n ti fi ìtara wàásù fún ogójì ọdún ṣáájú ọdún 1914, wọ́n sì sapá gan-an láti máa wàásù nìṣó nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Wọ́n ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn lẹni tó ń fi oúnjẹ fún àwọn ará ilé náà ní àkókò títọ́ nígbà tí ọ̀gá náà dé. (Mátíù 24:45-47) Nípa báyìí, lọ́dún 1919 àwọn ni Jésù fún ní àkájọ ìwé kékeré tó wà ní ṣíṣí náà, ìyẹn ni ìhìn tí kò fara sin, tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n wàásù rẹ̀ fún aráyé. Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, wọ́n ní iṣẹ́ kan láti jẹ́ fún ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ aláìṣòótọ́, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ká sòótọ́, wọn ò sìn ín. Bíi ti Jòhánù, wọ́n ní láti túbọ̀ wàásù nípa “àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n àti ọba púpọ̀.”
20. Kí ni jíjẹ tí Jòhánù jẹ àkájọ ìwé náà dúró fún?
20 Jíjẹ tí Jòhánù jẹ àkájọ ìwé náà dúró fún títẹ́ tí àwọn arákùnrin Jésù tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tá a yàn fún wọn yìí. Ó di ara wọn débi pé, àwọn la wá mọ̀ mọ́ apá yìí nísinsìnyí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a mí sí, wọ́n sì ń gba okun látinú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ní láti wàásù rẹ̀ ní àwọn ìdájọ́ Jèhófà nínú, èyí tí kò dùn mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn rárá. Kódà, àwọn ìyọnu tá a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá orí kẹjọ wà lára rẹ̀. Síbẹ̀, ó dùn mọ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ olóòótọ́ yìí láti mọ àwọn ìdájọ́ wọ̀nyí àti láti mọ̀ pé lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà ń lò wọ́n fún pípòkìkí wọn.—Sáàmù 19:9, 10.
21. (a) Báwo ni ohun tó wà nínú àkájọ ìwé kékeré náà tún ṣe dùn lẹ́nu ogunlọ́gọ̀ ńlá? (b) Kí nìdí tí ìhìn rere náà fi jẹ́ ìhìn búburú fáwọn alátakò?
21 Bí àkókò ti ń lọ, ìhìn tó wà nínú àkájọ ìwé yìí tún di èyí tó dùn lẹ́nu “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Àwọn la rí tí wọ́n ń mí ìmí ẹ̀dùn nítorí àwọn ohun tó burú jáì tí wọ́n rí tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. (Ìṣípayá 7:9; Ìsíkíẹ́lì 9:4) Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí náà ń pòkìkí ìhìn rere náà tọkàn tara, wọ́n ń lo àwọn ọ̀rọ̀ dídùn tó kún fún oore ọ̀fẹ́ láti sọ nípa ìpèsè àgbàyanu Jèhófà fáwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni-bí-àgùntàn. (Sáàmù 37:11, 29; Kólósè 4:6) Ṣùgbọ́n létí àwọn alátakò, ìhìn búburú lèyí jẹ́. Kí nìdí? Nítorí pé ó túmọ̀ sí pé ètò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, tó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó ti mú ìgbádùn onígbà kúkúrú wá fún wọn, gbọ́dọ̀ kọjá lọ. Fún wọn, ìparun ni ìhìn rere náà ń kéde rẹ̀.—Fílípì 1:27, 28; fi wé Diutarónómì 28:15; 2 Kọ́ríńtì 2:15, 16.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 160]
Ẹgbẹ́ Jòhánù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń pòkìkí ìhìn tó dùn tó sì tún korò fún gbogbo aráyé