Idande Lakooko Ifarahan Jesu Kristi
“Ẹ maa yọ, ki ẹyin ki o lè yọ ayọ pupọ nigba ti a bá fi ògo rẹ̀ hàn.”—1 PETERU 4:13.
1. Bawo ni Jehofa ṣe bukun awọn iranṣẹ rẹ̀?
JEHOFA ti fi ọpọlọpọ ẹbun sọ awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ di ọlọ́rọ̀. Gẹgẹ bi Atobilọla Olukọni wa, o ti fi akunwọsilẹ imọ nipa ifẹ-inu ati ète rẹ̀ là wá lóye. Nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, o ti mu agbara iṣe naa lati fi igboya tan ìmọ́lẹ̀ jade dagba ninu wa. Aposteli Paulu ti a misi sọ fun wa ninu 1 Korinti 1:6, 7 pe: “Àní gẹgẹ bi a ti fi idi ẹ̀rí Kristi kalẹ ninu yin: tobẹẹ ti ẹyin kò fi rẹhin ninu ẹbunkẹbun; ti ẹ si ń reti ifarahan Oluwa wa Jesu Kristi.”
2. Ifojusọna alayọ wo ni “ifarahan Oluwa wa Jesu Kristi” mu lọwọ?
2 “Ifarahan Oluwa wa Jesu Kristi”—ki ni iyẹn tumọsi? O tọka si akoko naa nigba ti a fi Jesu hàn gẹgẹ bi Ọba ológo kan, ti ń gbegbeesẹ lati san èrè fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ oluṣotitọ ati lati fi ibinu rẹ̀ hàn si awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. Gẹgẹ bi 1 Peteru 4:13 ṣe fihàn, yoo jẹ́ akoko kan fun awọn Kristian olùpàwàtítọ́mọ́ ti a fi ẹmi yàn ati awọn aduroṣinṣin alabaakẹgbẹpọ wọn ti wọn jẹ́ ti ogunlọgọ nla lati “yọ ayọ pupọ,” nitori pe o sami si eto-igbekalẹ awọn nǹkan Satani.
3. Bawo ni a ṣe gbọdọ duro giri, gẹgẹ bi awọn arakunrin wa ni Tessalonika ti ṣe?
3 Bi akoko yẹn ti ń sunmọle, Satani ninu ibinu rẹ̀ ń mu ìkìmọ́lẹ̀ pọ̀ sii lori wa. Gẹgẹ bi kinniun ti ń ké ramuramu, o ń gbiyanju lati fà wa ya pẹrẹpẹrẹ. A gbọdọ duroṣinṣin! (1 Peteru 5:8-10) Awọn arakunrin wa ni Tessalonika igbaani, nigba ti wọn jẹ́ titun ninu otitọ, jiya ipọnju ti o farajọ eyi ti ọpọlọpọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni iriri rẹ̀ lonii. Nitori naa, awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu si wọn ni itumọ gidigidi fun wa. O kọwe pe: “Bi o ti jẹ pe ohun òdodo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti ń pọn yin loju, ati fun ẹyin ti a ń pọ́n loju, isinmi pẹlu wa, nigba ifarahan Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀, ẹni ti yoo san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti wọn kò si gba ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́.” (2 Tessalonika 1:6-8) Bẹẹni, itura yoo dé!
4. Eeṣe ti awọn alufaa fi lẹtọọ si idajọ ti a o ṣe nigba ifarahan Jesu?
4 Ni akoko Paulu eyi ti o pọju ninu ipọnju naa ni awọn olori isin Ju fà. Bakan naa lonii, atako si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa olufẹ alaafia ni a ti rusoke lati ọwọ́ awọn wọnni ti wọn jẹwọ pe awọn ń ṣoju fun Ọlọrun, ni pataki julọ awọn alufaa Kristẹndọm. Awọn wọnyi díbọ́n pe awọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kọ “Oluwa kan” ti Bibeli silẹ, ni fifi Mẹtalọkan awo rọpo rẹ̀. (Marku 12:29) Wọn kò ṣegbọran si ihinrere nipa Oluwa wa Jesu, ni wiwo iṣakoso eniyan fun itura ati kíkọ ihinrere Ijọba òdodo Kristi tí ń bọ̀ silẹ. Gbogbo awọn alatako isin wọnyi gbọdọ parun ni akoko “ifarahan Jesu Oluwa lati ọrun wá”!
‘Bíbọ̀’ Jesu Kristi
5. Bawo ni a ṣe ṣapejuwe ifarahan Jesu ní kedere ninu Matteu 24:29, 30?
5 Ìfihàn yẹn ni a yaworan ni kedere lati ọwọ Jesu ninu Matteu 24:29, 30. Ni ṣiṣapejuwe oniruuru ẹka ami wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati ti opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan, o sọ pe: “Oorun yoo ṣookun, oṣupa kì yoo sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yoo ti oju ọrun ja silẹ, agbara oju ọrun ni a o sì mì tìtì.” Ni akoko yẹn, “ami Ọmọ eniyan yoo sì fi ara hàn ni ọrun.” Awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé yoo “kaaanu, wọn ó sì ri Ọmọ eniyan [Ọba Messia Ọlọrun] ti yoo maa ti oju ọrun bọ̀ ti oun ti agbara ati ògo nla.” ‘Bíbọ̀’ yii, er·khoʹme·non ni Griki, ń tọkasi ifarahan Jesu gẹgẹ bi Oludalare Jehofa.
6, 7. Bawo ni o ṣe jẹ pe “gbogbo oju ni yoo sì rí i,” awọn wo ni eyi sì ni ninu?
6 ‘Bíbọ̀’ yii ni a ṣapejuwe pẹlu nipasẹ aposteli Johannu ninu Ìfihàn 1:7, nibi ti o ti sọ pe: “Kiyesi i, o ń bọ̀ ninu awọsanmọ.” Óò, awọn ọ̀tá wọnyẹn kò ni ri Jesu pẹlu ojúyòójú niti gidi, nitori pe “awọsanmọ” ń tumọsi pe o ń bọ̀ laiṣeefojuri lati mu idajọ ṣẹ. Bi awọn eniyan lasan bá nilati ri ògo rẹ̀ ti ọrun pẹlu ojúyòójú, oju wọn yoo fọ́, gẹgẹ bi oju Saulu ṣe fọ́, ni oju-ọna si Damasku, nigba ti Jesu ti a ti ṣe logo farahan an ninu ìmọ́lẹ̀ atànyòò nla kan.—Iṣe 9:3-8; 22:6-11.
7 Akọsilẹ Ìfihàn sọ pe “gbogbo oju ni yoo sì ri i, ati awọn ti o gun un ni ọ̀kọ̀; ati gbogbo orilẹ-ede ayé ni yoo sì maa pohunrere ẹkún niwaju rẹ̀.” Eyi tumọsi pe awọn alatako lori ilẹ̀-ayé yoo loye ninu iparun ti Jesu bá rọ̀jò rẹ̀ si wọn lori pe o ti de pẹlu agbara ati ògo nla gẹgẹ bi Olùfìyà-ikú-jẹni ti Jehofa. Eeṣe ti a fi ṣapejuwe awọn ọ̀tá wọnyi gẹgẹ bi “awọn ti o gun un ni ọ̀kọ̀”? O jẹ́ nitori pe iṣarasihuwa wọn kikoro si awọn iranṣẹ Jehofa lonii dabi ti awọn ti o pa Jesu. Niti tootọ, wọn yoo “pohunrere ẹkún niwaju rẹ̀.”
8. Ikilọ wo ni Jesu ati Paulu fifunni nipa iparun ojiji?
8 Bawo ni ọjọ ibinu Jehofa yẹn yoo ṣe de? Ninu asọtẹlẹ inu Luku ori 21, Jesu ṣapejuwe awọn iṣẹlẹ alajaalu-ibi naa eyi ti o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi ami wíwàníhìn-ín rẹ̀ lati 1914. Lẹhin naa, ni ẹsẹ 34 ati 35, Jesu ṣekilọ pe: “Ẹ maa kiyesara yin, ki ọkàn yin ki o maṣe kun fun wọbia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan ayé yii, ti ọjọ naa yoo sì fi dé bá yin lojiji bi ìkẹkùn. Nitori bẹẹ ni yoo de ba gbogbo awọn ti ń gbe ori gbogbo ilẹ̀-ayé.” Bẹẹni, ọjọ ibinu Jehofa yẹn ń bọ̀ lojiji, lọgan! Aposteli Paulu jẹrii si eyi ninu 1 Tessalonika 5:2, 3, ni sisọ pe: “Ọjọ Oluwa ń bọ̀wá gẹgẹ bi olè ni òru. Nigba ti wọn bá ń wi pe, Alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun ojiji yoo dé sori wọn.” Àní nisinsinyi paapaa awọn orilẹ-ede ń sọrọ nipa alaafia ati ailewu ti wọn si ń wewee lati fun Iparapọ Awọn Orilẹ-ede lokun lati ṣoluṣọ awọn agbegbe ti ìjọ̀ngbọ̀n wà nipasẹ agbara ológun.
9. Fun awọn wo ni ‘ìmọ́lẹ̀ ń tàn,’ eesitiṣe?
9 Ni ẹsẹ 4 ati 5, aposteli naa ń baa lọ lati sọ fun wa pe: “Ṣugbọn ẹyin, ará, kò si ninu okunkun, ti ọjọ naa yoo fi de ba yin bi olè. Nitori gbogbo yin ni ọmọ ìmọ́lẹ̀, ati ọmọ ọ̀sán: awa kìí ṣe ti oru, tabi ti okunkun.” A layọ lati jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀—olùtan ìmọ́lẹ̀ si awọn ẹlomiran ti wọn ń yanhanhan fun alaafia ati aabo tootọ ninu ayé titun Ọlọrun. Ninu Orin Dafidi 97:10, 11, a kà pe: “Ẹyin ti o fẹ́ Oluwa, ẹ koriira ibi: o pa ọkàn awọn eniyan mimọ rẹ̀ mọ́: ó gbà wọn ni ọwọ́ awọn eniyan buburu. A funrugbin ìmọ́lẹ̀ fun olódodo, ati inu didun fun aláyà diduro.”
Itolọwọọwọ Awọn Iṣẹlẹ
10. Ikilọ ṣaaju wo ni a gbọdọ ṣegbọran si nipa ọjọ-idajọ Ọlọrun? (Ìfihàn 16:15)
10 Ki ni yoo jẹ́ itolọwọọwọ awọn iṣẹlẹ nigba ti ipọnju nla bá bẹ́ silẹ? Jẹ ki a yiju si Ìfihàn ori 16. Ṣakiyesi bi a ti ṣe ṣapejuwe ninu ẹsẹ 13 titi de 16, pe ẹmi alaimọ, ẹlẹmii eṣu gbá awọn orilẹ-ede gbogbo ilẹ̀-ayé jọ si Har–Mageddoni, ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare. Lẹẹkan sii, isunmọtosi ọjọ iṣiro ti o dabi olè ni a tẹnumọ, a si kilọ fun wa lati jí kalẹ—lati wọ awọn ẹwu tẹmi ti o sami si wa fun igbala. Akoko naa ti de fun ṣiṣedajọ awọn eniyan ori ilẹ̀-ayé, awọn orilẹ-ede, ati—ẹnikan bayii. Ta ni onítọ̀hún?
11. Bawo ni obinrin inu Ìfihàn 17:5 ṣe fi araarẹ̀ hàn yatọ kedere?
11 O jẹ obinrin iṣapẹẹrẹ kan ti o ti gbiyanju niti gidi lati sọ araarẹ̀ di “bàbàrà.” A ṣapejuwe rẹ̀ ninu Ìfihàn 17:5 gẹgẹ bi “OHUN IJINLẸ, BABILONI NLA, IYA AWỌN PANṢAGA ATI AWỌN OHUN IRIRA AYÉ.” Ṣugbọn kìí tun ṣe ohun ijinlẹ fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ. O ti fi araarẹ̀ hàn yatọ kedere gẹgẹ bi ilẹ-ọba isin èké agbaye, eyi ti ẹya-isin Kristẹndọm jẹ́ apa pataki julọ ninu rẹ̀. Lilọwọ ti o ń lọwọ ninu awọn alamọri oṣelu, didi ‘alámuyo ẹ̀jẹ̀ awọn eniyan mimọ’ nipa ṣiṣe inunibini si awọn Kristian oloootọ, ati jijẹbi ti o jẹbi ẹ̀jẹ̀ “gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ̀-ayé,” eyi ti o ni ninu ohun ti o ju ọgọrun million ti a pa ninu awọn ogun ọrundun ogún yii nikanṣoṣo jẹ akoniniriira loju Jehofa.—Ìfihàn 17:2, 6; 18:24.
12. Eeṣe ti a fi dá awọn ẹya-isin Kristẹndọm lẹbi?
12 Eyi ti o buru julọ, awọn ẹya-isin Kristẹndọm ti mu ẹ̀gàn wá sori orukọ Ọlọrun ẹni ti wọn jẹwọ pe awọn ṣoju fun lọna arekereke. Wọn ti kọni ni ẹkọ awọn ara Babiloni ati ọgbọn-imọ-ori Griki dipo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti o mọgaara ti wọn sì ti pakun ìyapòkíì oniwa palapala ti gbogbo orilẹ-ede nipa fifayegba awọn ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye onigbọjẹgẹ eyi ti o tàpá si awọn ilana Bibeli. Awọn ọlọ́gbọ́n-féfé ninu iṣowo laaarin wọn ni a dalẹbi nipa awọn ọ̀rọ̀ Jakọbu 5:1, 5 pe: “Ẹ wa nisinsinyi, ẹyin ọlọrọ, ẹ maa sọkun ki ẹ sì maa pohunrere ẹkun nitori òṣì ti ń bọ̀ wa ta yin. Ẹyin ti jẹ adun ni ayé, ẹyin sì ti fi araayín fun ayé jíjẹ; ẹyin ti bọ́ ni ọjọ pípa.”
Ki Babiloni Nla Di Àfẹ́kù!
13. Bawo ni ibẹrẹ ipọnju nla ṣe dé, ijẹkanjukanju wo ni a sì tẹnumọ ninu Ìfihàn 18:4, 5?
13 Ibẹrẹ ipọnju nla ń bọ̀ pẹlu ìmúdàájọ́ṣẹ Jehofa lori Babiloni Nla. Ìfihàn 17:15-18 ṣapejuwe ni kedere “ifẹ” Ọlọrun—lati fọgbọn dari “iwo mẹwaa,” ti awọn ipá alagbara lati inu “ẹranko ẹhanna,” Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede ti o ni ọpọ orilẹ-ede ninu, lati mu un kuro. “Ati iwo mẹwaa ti iwọ ri, ati ẹranko naa, awọn wọnyi ni yoo koriira agbere naa, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro ati ẹni ihooho, wọn ó si jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn o sì fi iná sun un patapata. Nitori Ọlọrun ti fi sinu ọkàn wọn lati mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ.” Abajọ ti ohùn ọrun kan fi sọ ikilọ kanjukanju kan ninu Ìfihàn 18:4, 5 pe: “Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹyin eniyan mi, ki ẹ ma baa ṣe alabaapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ki ẹ ma baa sì ṣe gba ninu ìyọnu rẹ̀. Nitori awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga àní de ọrun, Ọlọrun sì ti ranti aiṣedeede rẹ̀.” Ìpè naa ń baa lọ lati maa jade pe: Dá gbogbo ibaṣepọ pẹlu isin eke duro, ki o to pẹ́ ju!
14. Ta ni yoo ṣọfọ lori iṣubu Babiloni Nla, eesitiṣe?
14 Ki ni ayé yoo ka iṣubu Babiloni Nla sí? Lati ọ̀nà jijin, awọn oṣelu oniwa ibajẹ—“ọba ayé”—ń ṣọfọ lori rẹ̀ nitori pe wọn ti rí itẹlọrun tọtuntosi ninu agbere tẹmi wọn fun ọpọ ọrundun. Awọn ọkunrin oniṣowo oniwọra, “oniṣowo ayé . . . , ti a tipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ” ń sọkun ti wọn si ń ṣọfọ bakan naa pẹlu. Awọn wọnyi tun lọ jinnarere si i, ni wiwi pe: “Ègbé, ègbé ni fun ilu nla ni, ti a wọ̀ ni aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ ati ti elese aluko, ati ti òdòdó, ati ti a sì fi wura ṣe lọṣọọ, pẹlu okuta iyebiye ati perli! Nitori pe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹẹ di asán.” Gbogbo ẹwa aṣọ alufaa ati itobilọla awọn Katidira ayé ni yoo lọ lae faabada! (Ìfihàn 18:9-17) Ṣugbọn gbogbo eniyan yoo ha ṣọfọ lori Babiloni Nla bi?
15, 16. Idi wo fun ayọ ni awọn eniyan Ọlọrun yoo ni?
15 Ìfihàn 18:20, 21 dahun pe: “Yọ lori rẹ̀, iwọ ọrun, ati ẹyin aposteli mimọ ati wolii; nitori Ọlọrun ti gbẹsan yin lara rẹ̀.” Gẹgẹ bi ọlọ nla kan ti a jù sinu okun, “bayii ni [a ti] fi agbara ju Babiloni ilu nla nì wó, a kì yoo sì ri i mọ́ lae.”
16 Ẹ wo iru idi fun idunnu ti o jẹ́! Ìfihàn 19:1-8 fi eyi hàn. Ni ìgbà mẹrin ìpè naa, “Halleluiah” ń dun jade lati ọrun wa. Mẹta akọkọ ninu awọn Halleluiah wọnyi fìyìn fun Jehofa nitori pe o ti mu idajọ òdodo ṣẹ lori agbere olokiki buruku naa, Babiloni Nla. Ilẹ-ọba isin èké agbaye kò si mọ́! Ohùn kan jade lati inu ìtẹ́ Ọlọrun wá, ti ń wi pe: “Ẹ maa yin Ọlọrun wa, ẹyin iranṣẹ rẹ̀, gbogbo, ẹyin ti o bẹru rẹ̀ ati èwe ati àgbà.” Ẹ wo bi yoo ti jẹ anfaani fun wa tó lati nipin-in ninu orin yẹn!
Igbeyawo Ọdọ-Agutan Naa
17. Ni ṣiṣefiwera Ìfihàn 11:17 ati 19:6, ninu awọn ayika-ọrọ meji wo ni Jehofa gba bẹrẹ sii ṣakoso gẹgẹ bi Ọba?
17 Halleluiah kẹrin nasẹ ẹṣin-ọrọ miiran pe: “Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, ń jọba.” Ṣugbọn a kò ha sọ ohun kan ti o farajọ eyi ní Ìfihàn 11:17 bi? A kà nibẹ pe: “Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, . . . nitori ti iwọ ti gba agbara nla rẹ, iwọ sì ti jọba.” Bẹẹni. Bi o ti wu ki o ri, ayika-ọrọ Ìfihàn 11:17 ń tọka si mimu ti Jehofa mu Ijọba Messia jade ni 1914 lati “fi ọpa irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ede.” (Ìfihàn 12:5) Ìfihàn 19:6 wà ninu ayika-ọrọ iparun Babiloni Nla. Pẹlu imukuro isin ti o dabi aṣẹwo, ipo Ọlọrun Jehofa di eyi ti a dalare. Ijọsin rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba-alaṣẹ Onipo-ajulọ ati Ọba yoo bori nisinsinyi titi ayeraye!
18. Imukuro Babiloni Nla ṣí ọ̀nà silẹ fun ikede alayọ wo?
18 Nitori naa, ikede alayọ naa ni a lè ṣe pe: “Ẹ jẹ ki a yọ̀, ki inu wa ki o sì dùn gidigidi, ki a sì fi ògo fun [Jah]: nitori pe igbeyawo Ọdọ-agutan dé, aya rẹ̀ sì ti muratan. Oun ni a sì fifun pe ki o wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ ti o funfun gbòò: nitori pe aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ nì ni iṣẹ òdodo awọn eniyan mimọ.” (Ìfihàn 19:7, 8) Ìgbà naa gan-an ti awọn ẹni-ami-ororo ti o ṣẹku lori ilẹ̀-ayé yoo gba ajinde wọn ti ọrun ni a kò sọ. Ṣugbọn a mú un da wa loju ninu ayika-ọrọ ti o wa níhìn-ín pe ṣiṣajọpin wọn ninu igbeyawo Ọdọ-agutan naa, Kristi Jesu, yoo jẹ akoko alayọ, eyi yoo sì fi pupọpupọ ri bẹẹ niwọn bi o ti jẹ́ pe wọn yoo jẹrii lakọọkọ si itẹlogo aṣẹwo olokiki buruku naa, Babiloni Nla.
A Pa Ayé Satani Run
19. Idagbasoke miiran wo ni a ṣapejuwe ninu Ìfihàn 19:11-21?
19 Ẹṣin funfun ti a kọkọ mẹnukan ninu Ìfihàn 6:2 farahan lẹẹkan sii. A ka ninu Ìfihàn 19:11 pe: “Ẹni ti o si jokoo lori [ẹṣin funfun naa] ni a ń pe ni Olódodo ati Oloootọ, ninu òdodo ni o si ń ṣe idajọ, ti o si ń jagun.” Nipa bayii “ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA” ń gẹṣin lọ lati lu awọn orilẹ-ede bolẹ ati lati tẹ “ifunti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare.” Lasan ni “awọn ọba ayé, ati awọn ogun wọn” parapọ lati ja ogun Har–Mageddoni. Olùgun ẹṣin funfun naa pari iṣẹgun rẹ̀. Kò si ohun ti o ku ninu eto-ajọ Satani ori ilẹ̀-ayé mọ́.—Ìfihàn 19:12-21.
20. Ki ni o ṣẹlẹ si Eṣu funraarẹ?
20 Ṣugbọn ki ni nipa ti Eṣu funraarẹ? Ninu Ìfihàn 20:1-6, Kristi Jesu ni a ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “angẹli kan ti ń ti ọrun sọkalẹ wa, ti oun ti ìṣíkà ọgbun nì, ati ẹwọn nla kan ni ọwọ rẹ̀.” O gbá dragoni naa mú, Ejo laelae nì, tii ṣe Eṣu ati Satani, o dè é, o sì ju u sinu ọgbun ainisalẹ, o dè é o sì tì í pa mọ́ inu rẹ̀. Pẹlu Satani ti a ti mú kuro ni oju-ọna ti kò sì lè ṣi awọn orilẹ-ede lọna mọ, Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun ológo ti Ọdọ-agutan naa ati iyawo rẹ̀ ń tẹsiwaju. Kò si omije ibanujẹ mọ! Kò si iku Adamu mọ! Kò si ọ̀fọ̀, kò si ẹkun, kò si irora! “Ohun atijọ ti kọja lọ.”—Ìfihàn 21:4.
21. Bi a ti ń fi iharagaga duro de ifarahan Jesu Kristi, ki ni o gbọdọ jẹ ipinnu wa?
21 Nigba ti a ń fi iharagaga duro de ìfihàn Oluwa wa Jesu Kristi, ẹ jẹ ki a fi itara hàn ni sisọ fun awọn ẹlomiran nipa awọn ileri Ijọba onifẹẹ ti Ọlọrun. Igbala ti sunmọ etile! Ǹjẹ́ ki a lè maa rin siwaju, siwaju ati siwaju, gẹgẹ bi awọn ọmọ Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ ti a ti làlóye!
Lati Ṣatunyẹwo
◻ Ki ni o fihàn pe ifarahan Jesu Kristi sunmọle?
◻ Bawo ni ọjọ ibinu Jehofa yoo ṣe de?
◻ Oju wo ni ‘awọn olufẹ Jehofa’ gbọdọ fi wo ipo ayé isinsinyi?
◻ Ọ̀nà wo ni awọn nǹkan yoo gbà ṣẹlẹ nigba ti ipọnju nla ba bẹrẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jesu “ń bọ̀ ninu awọsanmọ,” laiṣeefojuri lati mu idajọ ṣẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Laipẹ gbogbo isin eke, eto-igbekalẹ buburu Satani, ati Satani funraarẹ yoo kọja lọ