Àkókò Láti Wà Lójúfò
“A níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere naa ní gbogbo awọn orílẹ̀-èdè. . . . Ṣugbọn ẹni tí ó bá faradà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbàlà.”—MARKU 13:10, 13.
1. Èé ṣe tí a ní láti lo ìfaradà, kí a sì mọ́kàn le?
AGBỌ́DỌ̀ ní ìfaradà—nínú ìran aláìnígbàgbọ́ àti onímàgòmágó! Láti 1914, ìran àwọn ènìyàn kan ti di oníwà ìbàjẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Jesu. Lónìí, ìwà ìbàjẹ́ náà wà káàkiri àgbáyé. Ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” tí aposteli Paulu ṣàpèjúwe ń bá aráyé fínra. ‘Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ń tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’ Ó hàn gbangba pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,” Satani Èṣù, tí ń ṣe ìsapá rẹ̀ ìkẹyìn nísinsìnyí láti ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Ṣùgbọ́n ẹ mọ́kàn le! “Ìpọ́njú ńlá” kan ń bọ̀, tí yóò mú ìtura pípẹ́ títí wá fún gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òdodo.—2 Timoteu 3:1-5, 13; 1 Johannu 5:19; Ìṣípayá 7:14.
2. Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ ní 1914?
2 A láyọ̀ pé, Jehofa ti gbé Jesu Kristi Oluwa gun orí ìtẹ́ nísinsìnyí ní òkè ọ̀run, ní ìmúrasílẹ̀ fún mímú àwọn ọ̀tá tí ń ni aráyé lára kúrò. (Ìṣípayá 11:15) Gan-an gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, tí Danieli kọ, ṣe ní ìmúṣẹ nígbà tí Messia náà kọ́kọ́ wá, bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọ̀rúndún yìí, àsọtẹ́lẹ̀ pípẹtẹrí kan tí Danieli kọ ti ní ìmúṣẹ. Ní Danieli 4:16, 17, 32, a sọ fún wa nípa dídá ẹ̀tọ́ ṣíṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilẹ̀ ayé dúró fún sáà “ìgbà méje.” Nínú ìmúṣẹ pàtàkì wọn, ìgbà méje wọ̀nyí jẹ́ ọdún méje ti Bibeli, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ 360 ‘ọjọ́,’ tàbí 2,520 ọdún lápapọ̀.a Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní 607 B.C.E., nígbà tí Babiloni bẹ̀rẹ̀ títẹ ìjọba Israeli mọ́lẹ̀, títí di 1914 C.E., ọdún náà tí Jesu gorí ìtẹ́ ní òkè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba aráyé. Nígbà náà, “awọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè” dópin. (Luku 21:24) Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè ti kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀ fún Ìjọba Messia tí ń bọ̀ náà.—Orin Dafidi 2:1-6, 10-12; 110:1, 2.
3, 4. (a) Ìfiwéra wo ni a lè ṣe nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀rúndún kìíní àti àwọn ti àkókò wa? (b) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni a lè béèrè?
3 Bí ọ̀sẹ̀ àádọ́rin ti àwọn ọdún náà (29 sí 36 C.E.) ti ń sún mọ́lé, àti lẹ́ẹ̀kan sí i bí ọdún 1914 ti ń kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọrun ń retí dídé Messia náà. Ó sì dé ní tòótọ́! Ṣùgbọ́n, nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ọ̀nà tí ó gbà dé yàtọ̀ sí ohun tí a ń retí. Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú, lẹ́yìn sáà àkókò kúkúrú díẹ̀ ní ìfiwéra, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “ìran” búburú kan jìyà ikú nípasẹ̀ àṣẹ àtọ̀runwá.—Matteu 24:34.
4 Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí ó ṣáájú, a kíyè sí bí ìran burúkú ti àwọn Júù, tí ó béèrè fún ṣíṣekúpa Jesu, ṣe kàgbákò òpin rẹ̀. Nígbà náà, kí ni ti ìran ọ̀bàyéjẹ́ ti aráyé, tí ó tilẹ̀ ń takò ó tàbí pa á tì nísinsìnyí? Nígbà wo ni a óò múdàájọ́ ṣẹ sórí ìran aláìgbàgbọ́ yìí?
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”!
5. (a) Ìdí rere wo ni kò fi yẹ kí a mọ àkókò “ọjọ́ ati wákàtí” Jehofa? (b) Gẹ́gẹ́ bí Marku ti sọ, ìmọ̀ràn yíyè kooro wo ni Jesu fi kádìí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
5 Lẹ́yìn sísọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò jálẹ̀ sí àkókò “ìpọ́njú ńlá,” Jesu fi kún un pé: “Níti ọjọ́ ati wákàtí yẹn kò sí ẹni kan tí ó mọ̀, kì í ṣe awọn áńgẹ́lì awọn ọ̀run tabi Ọmọkùnrin, bíkòṣe Baba nìkan.” (Matteu 24:3-36; Marku 13:3-32) A kò ní láti mọ àkókò náà pàtó tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yóò ní ìmúṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àfiyèsí wa gbọ́dọ̀ jẹ́ lórí ṣíṣọ́nà, mímú ìgbàgbọ́ lílágbára dàgbà, àti mímú kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa—kì í ṣe lórí ṣíṣírò ọjọ́. Jesu mú àsọtẹ́lẹ̀ kíkàmàmà rẹ̀ wá sí ìparí nípa sísọ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ máa wà lójúfò, nitori ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yànkalẹ̀ jẹ́. . . . Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ohun tí mo wí fún yín ni mo wí fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Marku 13:33-37) Gudugbẹ̀ fẹ́ já sórí ayé òde òní. A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò!—Romu 13:11-13.
6. (a) Kí ni a ní láti gbé ìgbàgbọ́ wa kà? (b) Báwo ni a ṣe lè máa “ka ọjọ́ wa”? (d) Ní pàtàkì, kí ni Jesu ní lọ́kàn nípa “ìran”?
6 Kì í ṣe pé a gbọ́dọ̀ fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí tí ó kan àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ burúkú wọ̀nyí nìkan ni, ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbàgbọ́ wa karí ẹbọ iyebíye ti Kristi Jesu àti àwọn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọrun ṣe tí ó sinmi lé e. (Heberu 6:17-19; 9:14; 1 Peteru 1:18, 19; 2 Peteru 1:16-19) Nítorí ìháragàgà wọn láti rí òpin ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí, nígbà kan, àwọn ènìyàn Jehofa ti méfò nípa àkókò náà tí “ìpọ́njú ńlá” yóò bẹ́ sílẹ̀, àní, wọ́n tilẹ̀ ń fi èyí ṣèṣirò bí àkókò ìgbésí ayé ìran kan láti 1914 ti gùn tó. Bí ó ti wù kí ó rí, a ń “fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n,” kì í ṣe nípa míméfò nípa iye ọdún tàbí ọjọ́ tí ó para pọ̀ jẹ́ ìran kan, bí kò ṣe nípa ríronú nípa bí a óò ṣe máa “ka iye ọjọ́ wa,” láti mu ìyìn aláyọ̀ wá fún Jehofa. (Orin Dafidi 90:12) Kàkà tí a óò fi pèsè ìlànà kan fún dídíwọ̀n àkókò, ọ̀rọ̀ náà “ìran” bí Jesu ṣe lò ó, ń tọ́ka ní pàtàkì sí àwọn ènìyàn alájọgbáyé ní sáà kan pàtó nínú ìtàn, pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tí a fi lè dá wọn mọ̀.b
7. Kí ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ẹ̀kọ́ ìtàn kọ nípa “ìran 1914,” báwo sì ni èyí ṣe bá àsọtẹ́lẹ̀ Jesu mu?
7 Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a sọ lókè yìí, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìtàn, Robert Wohl, kọ ọ́ sínú ìwé rẹ̀ The Generation of 1914 pé: “Kì í ṣe ọjọ́ ni a fi ń túmọ̀ ìran kan nínú ìtàn . . . Kì í ṣe ọ̀ràn àkókò.” Ṣùgbọ́n ó tọ́ka sí i pé Ogun Àgbáyé Kìíní ṣèdásílẹ̀ “ìmọ̀lára ńláǹlà ti ipò rúgúdù nípa àtẹ̀yìnwá,” ó sì fi kún un pé: “Àwọn tí wọ́n la ogun náà já kò lè gbàgbé láé pé ayé kan parí, òmíràn sì bẹ̀rẹ̀ ní August 1914.” Ẹ wo bí ìyẹn ṣe jẹ́ òtítọ́ tó! Ó darí àfiyèsí sí igi wọ́rọ́kọ́ inú ọ̀ràn náà. “Ìran yìí” ti aráyé láti 1914 ti nírìírí àwọn ìyípadà tí ń kó jìnnìjìnnì báni. Ó ti rí i tí a fi ẹ̀jẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ rin ilẹ̀ ayé gbingbin. Ogun, ìpẹ̀yàrun, ìkópayàbáni, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà àìlófin ti sú yọ káàkiri àgbáyé. Ìyàn, àrùn, àti ìwà pálapàla ti gba àgbáyé kan. Jesu sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ̀yin pẹlu, nígbà tí ẹ [àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀] bá rí nǹkan wọnyi tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọrun súnmọ́lé. Ní òótọ́ ni mo wí fún yín pé, Ìran yii kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo awọn nǹkan yoo fi ṣẹlẹ̀.”—Luku 21:31, 32.
8. Báwo ni àwọn wòlíì Jehofa ṣe tẹnu mọ́ àìní náà láti máa bá a nìṣó ní wíwà lójúfò?
8 Bẹ́ẹ̀ ni, ìṣẹ́gun pátápátá ti Ìjọba Messia náà kù sí dẹ̀dẹ̀! Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohunkóhun ha wà tí a lè jèrè, nípa wíwá àkókò tàbí nípa míméfò nípa gígùn àkókò ìgbésí ayé “ìran” kan ní ti olówuuru bí? Dájúdájú kò sí! Habakkuku 2:3 sọ ni kedere pé: “Ìran náà jẹ́ ti ìgbà kan tí a yàn, yóò máa yara sí ìgbẹ̀yìn, kì yóò sì ṣèké, bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò sì pẹ́.” Ọjọ́ ìjíhìn fún Jehofa ń yára sún mọ́lé sí i.—Jeremiah 25:31-33; Malaki 4:1.
9. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo láti 1914, ni ó fi hàn pé àkókò náà kúrú?
9 Nígbà tí ìṣàkóso Ìjọba Kristi bẹ̀rẹ̀ ní 1914, a lé Satani jù sí ilẹ̀ ayé. Èyí ti túmọ̀ sí “ègbé . . . fún ilẹ̀-ayé . . . , nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Ní tòótọ́, àkókò yẹn kúrú, ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Satani. Ìjọba náà kù sí dẹ̀dẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọjọ́ àti wákàtí Jehofa fún mímúdàájọ́ ṣẹ sórí ìran burúkú yìí!—Owe 3:25; 10:24, 25.
“Ìran” Tí Ó Kọjá Lọ
10. Báwo ni “ìran yii” ṣe dà bí tí ọjọ́ Noa?
10 Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò gbólóhùn Jesu ní Matteu 24:34, 35 fínnífínní: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yii kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run ati ilẹ̀-ayé yoo kọjá lọ, ṣugbọn awọn ọ̀rọ̀ mi kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà.” Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí ó tẹ̀ lé e fi hàn pé, ‘kò sí ẹnì kan tí ó mọ ọjọ́ àti wákàtí náà.’ Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó fi hàn pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ìdẹkùn tí ó yí wa ká nínú ìran yìí. Nípa èyí, Jesu fi kún un pé: “Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn ọjọ́ Noa ti rí, bẹ́ẹ̀ naa ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yoo rí. Nitori bí wọ́n ti wà ní awọn ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún-omi, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, awọn ọkùnrin ń gbéyàwó a sì ń fi awọn obìnrin fúnni ninu ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ naa tí Noa wọ inú ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyèsí i títí ìkún-omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ naa ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yoo rí.” (Matteu 24:36-39) Níhìn-ín, Jesu fi ìran ọjọ́ rẹ̀ wé ti ọjọ́ Noa.—Genesisi 6:5, 9; àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.
11. Ìfiwéra wo ni Jesu ṣe nípa ‘àwọn ìran,’ gẹ́gẹ́ bí Matteu àti Luku ṣe ròyìn?
11 Èyí kọ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn aposteli yóò gbọ́ tí Jesu ń fi ‘àwọn ìran’ wé ara wọn, nítorí ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú, ó ti sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Ọmọkùnrin ènìyàn . . . gbọ́dọ̀ faragba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjìyà kí a sì kọ̀ ọ́ tì lati ọwọ́ ìran yii. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní awọn ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ naa ni yoo rí pẹlu ní awọn ọjọ́ Ọmọkùnrin ènìyàn.” (Luku 17:24-26) Nípa báyìí, Matteu orí 24 àti Luku orí 17 ṣe ìfiwéra kan náà. Ní ọjọ́ Noa “olúkúlùkù ènìyàn [tí ó] ti ba ìwà rẹ̀ jẹ́ ní ayé,” tí a sì pa run nígbà Ìkún Omi ni “ìran yìí.” Ní ọjọ́ Jesu, àwọn Júù apẹ̀yìndà tí wọ́n kọ Jesu ni “ìran yìí.”—Genesisi 6:11, 12; 7:1.
12, 13. (a) Lónìí, kí ni “ìran yii” tí ó gbọ́dọ̀ kọjá lọ? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn Jehofa ṣe ń kojú “ìran oníwà wíwọ́ ati onímàgòmágó” yìí?
12 Nítorí náà, nínú ìmúṣẹ ìkẹyìn ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu lónìí, “ìran yìí” ní kedere ń tọ́ka sí àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé tí wọ́n rí àmì wíwà níhìn-ín Kristi, ṣùgbọ́n tí wọ́n kùnà láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀nà wọn. Ní ìyàtọ̀ gédégédé, àwa gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jesu kọ̀ láti jẹ́ kí “ìran yìí” fi àṣà ìgbésí ayé rẹ̀ sọ wa dà bí ó ṣe dà. Bí a tilẹ̀ ń gbé nínú ayé, a kò gbọdọ̀ jẹ́ apá kan rẹ̀, “nitori àkókò tí a yànkalẹ̀ ti súnmọ́lé.” (Ìṣípayá 1:3; Johannu 17:16) Aposteli Paulu gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú ati ìjiyàn, kí ẹ lè wá jẹ́ aláìlẹ́bi ati ọlọ́wọ́mímọ́, awọn ọmọ Ọlọrun láìní àbààwọ́n kan ní àárín ìran oníwà wíwọ́ ati onímàgòmágó, láàárín awọn tí ẹ̀yin ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ ninu ayé.”—Filippi 2:14, 15; Kolosse 3:5-10; 1 Johannu 2:15-17.
13 Kì í ṣe kìkì fífi àkópọ̀ ìwà Kristian mímọ́ tónítóní hàn ni ‘títàn bí atànmọ́lẹ̀’ wa ní nínú, ṣùgbọ́n, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó kan mímú àsọtẹ́lẹ̀ oníṣẹ́ àṣẹ tí Jesu sọ ṣẹ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:14) Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó lè sọ ìgbà ti òpin yẹn yóò jẹ́, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé òpin “ìran yìí” ti àwọn ènìyàn burúkú yóò dé, ní gbàrà tí a bá ti jẹ́rìí náà lọ́nà tí ó tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn “títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.”—Ìṣe 1:8.
“Ọjọ́ ati Wákàtí Naa”
14. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Jesu àti Paulu fún wa ní ti “awọn àkókò ati àsìkò,” báwo sì ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà?
14 Nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí ìjẹ́rìí kárí ayé dé àyè tí Jehofa pète, yóò jẹ́ “ọjọ́ ati wákàtí” rẹ̀ láti palẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ayé yìí mọ́. A kò ní láti mọ àkókò náà ṣáájú. Nípa báyìí, ní títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jesu, aposteli Paulu gbani níyànjú pé: “Wàyí o níti awọn àkókò ati awọn àsìkò, ẹ̀yin ará, ẹ kò nílò kí a kọ̀wé nǹkankan sí yín. Nitori ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jehofa ń bọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà ati ààbò!’ nígbà naa ni ìparun òjijì yoo dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yoo sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.” Kíyè sí àfiyèsí Paulu: ‘Ìgbà tí wọ́n bá ń wí pé.’ Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ “àlàáfíà ati ààbò,” nígbà tí a kò rò tì, ìdájọ́ Ọlọrun yóò dé lójijì. Ẹ wo bí ìmọ̀ràn Paulu ti bá a mu wẹ́kú tó pé: “Nitori bẹ́ẹ̀, nígbà naa, ẹ máṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí awọn yòókù ti ń ṣe, ṣugbọn ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́”!—1 Tessalonika 5:1-3, 6; tún wo ẹsẹ 7-11; Ìṣe 1:7.
15, 16. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a ronú pé Armagedoni ṣì jìnnà gan-an ju bí a ti lè gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀ lọ? (b) Báwo ni a óò ṣe gbé ipò ọba aláṣẹ Jehofa ga ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́?
15 Ojú ìwòye wa tí ó túbọ̀ ṣe pàtó lórí “ìran yìí” ha túmọ̀ sí pé Armagedoni ṣì jìnnà gan-an ju bí a ti rò tẹ́lẹ̀ lọ bí? Rárá o! Bí a kò tilẹ̀ fìgbà kankan mọ “ọjọ́ ati wákàtí,” Jehofa Ọlọrun ti fìgbà gbogbo mọ̀ ọ́n, òun kò sì yí padà. (Malaki 3:6) Ó hàn gbangba pé, ayé túbọ̀ ń rì wọlẹ̀ sí i sí ìparun ìgbẹ̀yìn. Àìní náà láti máa wà lójúfò túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Jehofa ti ṣí “awọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́” payá fún wa, a sì ní láti dáhùn padà pẹ̀lú òye ìjẹ́kánjúkánjú pátápátá.—Ìṣípayá 1:1; 11:18; 16:14, 16.
16 Bí àkókò náà ti ń sún mọ́lé, ẹ máa wà lójúfò, nítorí Jehofa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú àjálù wá sórí gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ Satani! (Jeremiah 25:29-31) Jehofa wí pé: “Èmi óò sì gbé ara mi lékè, èmi óò sì ya ara mi sí mímọ́ lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni Oluwa.” (Esekieli 38:23) “Ọjọ́ Jehofa” tí ó ti pinnu kù sí dẹ̀dẹ̀!—Joeli 1:15, NW; 2:1, 2; Amosi 5:18-20; Sefaniah 2:2, 3.
“Ọ̀run Titun ati Ilẹ̀-Ayé Titun” Ti Òdodo
17, 18. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jesu àti Peteru ti sọ, báwo ni “ìran yii” ṣe kọjá lọ? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà ní ti ìwà àti ìṣe onífọkànsin Ọlọrun?
17 Nípa ‘gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀,’ Jesu wí pé: “Ọ̀run ati ilẹ̀-ayé yoo kọjá lọ, ṣugbọn awọn ọ̀rọ̀ mi kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà.” (Matteu 24:34, 35) Ó ṣeé ṣe kí Jesu ti ní “ọ̀run ati ilẹ̀-ayé”—àwọn aláàkóso àti àwọn tí a ń ṣàkóso—ti “ìran yìí” lọ́kàn. Aposteli Peteru lo ọ̀rọ̀ tí ó jọra nígbà tí ó ń tọ́ka sí “awọn ọ̀run ati ilẹ̀-ayé tí ó wà nísinsìnyí,” tí a “tòjọ pamọ́ fún iná [tí] a sì ń fi wọ́n pamọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ ati ti ìparun awọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun.” Ó tún ṣàpèjúwe bí “ọjọ́ Jehofa yoo [ṣe] dé gẹ́gẹ́ bí olè, ninu èyí tí awọn [ìṣàkóso bí] ọ̀run yoo kọjá lọ,” pa pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn oníwà ìbàjẹ́, tàbí “ilẹ̀-ayé,” ati awọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Aposteli náà gbà wá níyànjú láti máa ní “awọn ìṣe mímọ́ ní ìwà ati awọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọrun, [bí a ti] ń dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jehofa [tí a sì ń ] fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí awọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yoo di yíyọ́ tí awọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yoo sì yọ́!” Ki ni yóò tẹ̀ lé e? Peteru darí àfiyèsí wa sí ‘ọ̀run titun àti ilẹ̀ ayé titun nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé.’—2 Peteru 3:7, 10-13.c
18 “Àwọn ọ̀run titun” wọ̀nyẹn, ìṣàkóso Ìjọba nípasẹ̀ Kristi Jesu àti àwọn ọba amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò rọ̀jò ìbùkún sórí àwùjọ aráyé, “ilẹ̀-ayé titun” òdodo náà. Ó ha ṣeé ṣe kí o jẹ́ mẹ́ḿbà àwùjọ yẹn bí? Bí ó bá ṣeé ṣe, ìdí wà fún ọ láti kún fún ayọ̀ lórí ohun pípabambarì tí ọjọ́ ọ̀la ní nípamọ́!—Isaiah 65:17-19; Ìṣípayá 21:1-5.
19. Àǹfààní ńláǹlà wo ni a lè gbádùn nísinsìnyí?
19 Bẹ́ẹ̀ ni, “ìran” aráyé olódodo ni a ti ń kó jọ pọ̀ nísinsìnyí pàápàá. Lónìí, àwọn ẹni àmì òróró “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ń pèsè ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 78:1, 4 pé: “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, sí òfin mi: ẹ dẹ etí yín sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi . . . , ní sísọ ọ́ pàápàá fún àwọn ìran tí ń bọ̀, ìyìn Jehofa àti okun rẹ̀ àti àwọn nǹkan àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe.” (Matteu 24:45-47) Ní April 14 ọdún yìí, ní iye tí ó lé ní 75,500 ìjọ àti ní ilẹ̀ tí ó lé ní 230, àwọn ènìyàn tí ó lé ní 12,000,000 káàkiri ilẹ̀ ayé pésẹ̀ sí ibi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. O ha wà lára wọn bí? Ǹjẹ́ kí o gbé ìgbàgbọ́ rẹ karí Kristi Jesu, kí o sì ‘pe orúkọ Jehofa fún ìgbàlà.’—Romu 10:10-13.
20. Níwọ̀n bí “àkókò tí ó ṣẹ́kù silẹ̀ ti dínkù,” báwo ni a ṣe gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní wíwà lójúfò, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà wo sì ni?
20 Aposteli Paulu wí pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ ti dínkù.” Nítorí náà, àkókò nìyí láti máa bá a nìṣó ní wíwà lójúfò nígbà gbogbo, kí ọwọ́ wa sì dí nínú iṣẹ́ Jehofa, bí a ti ń fara da àwọn àdánwò àti ìkórìíra tí ìran aráyé burúkú gbé kà wá lórí. (1 Korinti 7:29; Matteu 10:22; 24:13, 14) Ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, ní ṣíṣàkíyèsí gbogbo àwọn ohun tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bibeli pé yóò ṣẹ sórí “ìran yii.” (Luku 21:31-33) Nípa líla nǹkan wọ̀nyí já àti dídúró pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà àtọ̀runwá níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn, a lè rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni sí i lórí “ìgbà méje,” wo ojú ìwé 127 sí 139, 186 sí 189 ìwé náà, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Wo Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ewé 918, nínú ìwé Insight on the Scriptures, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
c Tún wo ojú ewé 152 sí 156 àti 180 sí 181 nínú ìwé Our Incoming World Government—God’s Kingdom, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò:
◻ Níwọ̀n bí a ti kíyè sí ìmúṣẹ Danieli 4:32, báwo ni ó ṣe yẹ kí a máa “bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà”?
◻ Báwo ni Ìhìn Rere Matteu àti Luku ṣe fi “ìran yii” hàn?
◻ Bí a ti ń dúró de “ọjọ́ ati wákàtí naa,” kí ni a ń kíyè sí, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà?
◻ Kí ni ìfojúsọ́nà fún “ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun” yẹ kí ó fún wa níṣìírí láti ṣe?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Aráyé tí ń jìyà yóò rí ìtura àlàáfíà nígbà tí ìran burúkú oníwà ipá yìí bá kọjá lọ
[Credit Line]
Alexandra Boulat/Sipa Press
[Credit Line]
Apá òsì àti ìsàlẹ̀: Luc Delahaye/Sipa Press
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Awọn ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun” ológo wà gẹ́rẹ́ níwájú fún gbogbo ìran ènìyàn