MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘Ilẹ̀ Gbé Odò Náà Mì’
Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aláṣẹ ayé ti ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́. (Ẹsr 6:1-12; Ẹst 8:10-13) Bákan náà lónìí, a ti rí ìgbà tí “ilẹ̀” ìyẹn apá kan lára ètò ayé yìí ti gba tàwọn èèyàn Ọlọ́run rò, tí wọ́n sì “gbé odò” inúnibíni tí “dírágónì náà” ìyẹn Sátánì Èṣù pọ̀ látẹnu rẹ̀ mì. (Ifi 12:16) Nígbà míì, Jèhófà tó jẹ́ ‘Ọlọ́run tó ń gbani là’ lè lo àwọn aláṣẹ ayé yìí láti pèsè ìtura fáwọn èèyàn rẹ̀.—Sm 68:20; Owe 21:1.
Ká wá sọ pé wọ́n jù ẹ́ sẹ́wọ̀n nítorí ohun tó o gbà gbọ́ ńkọ́? Má mikàn rárá, fi sọ́kàn pé Jèhófà ń rí ẹ níbi tó o wà. (Jẹ 39:21-23; Sm 105:17-20) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa san ẹ́ lẹ́san fún ìgbàgbọ́ tó o ní àti pé ìdúróṣinṣin rẹ máa fún àwọn ará kárí ayé níṣìírí.—Flp 1:12-14; Ifi 2:10.
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ WỌ́N DÁ ÀWỌN ARÁ WA SÍLẸ̀ LẸ́WỌ̀N NÍ KOREA, LẸ́YÌN NÁÀ, Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tí wọ́n fi ju ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè South Korea láwọn ọdún yìí wá?
Ìdájọ́ wo ló mú kí wọ́n tètè dá àwọn arákùnrin wa sílẹ̀?
Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n báyìí torí ìgbàgbọ́ wọn?
Báwo ló ṣe yẹ ká lo òmìnira tá a ní báyìí?
Ta ni ìyìn àti ògo yẹ fún àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá ṣe nílé ẹjọ́?