‘Ẹ Kún Fún Ìdùnnú’
‘Ìwọ yóò ṣe àjọyọ̀ náà fún Jèhófà, kí ìwọ sì kún fún ìdùnnú.’—DIUTARÓNÓMÌ 16:15.
1. (a) Àwọn ọ̀ràn wo ni Sátánì gbé dìde? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà sọ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí i?
NÍGBÀ tí Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn, ọ̀ràn méjì kan tó ṣe pàtàkì ló tipa bẹ́ẹ̀ dá sílẹ̀. Èkíní, ó sọ pé Jèhófà kì í ṣe olóòótọ́ àti pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso kò tọ̀nà. Èkejì, Sátánì dọ́gbọ́n sọ pé nítorí àǹfààní ti ara wọn làwọn èèyàn á ṣe máa sin Ọlọ́run. Ó sọ èyí ní tààràtà nígbà ayé Jóòbù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Jóòbù 1:9, 10; 2:4, 5) Àmọ́ Jèhófà yára wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn yìí. Kódà, Ádámù àti Éfà kò tíì kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì tí Jèhófà fi sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀nà tóun máa gbà yanjú àwọn ọ̀ràn náà. Ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé “irú-ọmọ” kan yóò wá, ẹni tó jẹ́ pé, lẹ́yìn tí Sátánì bá ti pa á ní gìgísẹ̀, òun náà yóò wá pa Sátánì ní orí.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí ọ̀nà tó máa gbà mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣẹ túbọ̀ ṣe kedere sí i?
2 Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn túbọ̀ ṣe kedere, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò nímùúṣẹ dájúdájú nígbà tó bá tó àkókò. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé láti ara àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni “irú-ọmọ” náà yóò ti jáde wá. (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18) Ọmọ ọmọ Ábúráhámù, ìyẹn Jékọ́bù, di bàbá fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá. Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ẹ̀yà náà di orílẹ̀-èdè kan, Jèhófà fún wọn láwọn òfin, àwọn òfin náà sì ní onírúurú àjọyọ̀ tí wọ́n á máa ṣe lọ́dọọdún nínú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn àjọyọ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀.” (Kólósè 2:16, 17; Hébérù 10:1) Wọ́n ń ṣàpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà yóò gbà mú ohun tó ní lọ́kàn nípa Irú-Ọmọ náà ṣẹ. Àwọn àjọyọ̀ yìí máa ń múnú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn gan-an. Gbígbé wọn yẹ̀ wò ní ṣókí yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára sí i pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣeé gbára lé.
Irú-Ọmọ Náà Fara Hàn
3. Ta ni Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, báwo sì ni Sátánì ṣe pa á ní gìgísẹ̀?
3 Lẹ́yìn ohun tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin ọdún tí Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Irú-ọmọ tó ṣèlérí náà fara hàn. Jésù sì ni irú-ọmọ ọ̀hún. (Gálátíà 3:16) Ẹni pípé ni Jésù, ó sì jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ó wá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé irọ́ pátápátá làwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, níwọ̀n bí Jésù kò ti dẹ́ṣẹ̀ rárá, ikú rẹ̀ jẹ́ ẹbọ tó níye lórí gan-an. Jésù tipasẹ̀ ikú rẹ̀ yìí ṣe ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú fáwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà. Ikú Jésù lórí òpó igi ìdálóró ni pípa tí Sátánì pa Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà ní gìgísẹ̀ túmọ̀ sí.—Hébérù 9:11-14.
4. Kí ló ṣàpẹẹrẹ ẹbọ Jésù?
4 Jésù kú ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.a Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá ni Nísàn 14 jẹ́, ọjọ́ ìdùnnú sì ni. Ní àyájọ́ ọjọ́ yẹn lọ́dọọdún, àwọn ìdílé máa ń jẹun pa pọ̀, oúnjẹ yìí sì máa ń ní ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lábàwọ́n nínú. Èyí ń rán wọn létí ipa tí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn kó nínú dídá àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí nígbà tí áńgẹ́lì aṣekúpani pa àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì ní Nísàn 14 ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́kísódù 12:1-14) Jésù ni ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá náà dúró fún, ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé: “A ti fi Kristi ìrékọjá wa rúbọ.” (1 Kọ́ríńtì 5:7) Bíi ti ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá yẹn, ẹ̀jẹ̀ Jésù táwọn èèyàn ta sílẹ̀ jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní ìdáǹdè.—Jòhánù 3:16, 36.
‘Àkọ́so Nínú Àwọn Tó Ti Kú’
5, 6. (a) Ìgbà wo ni Ọlọ́run jí Jésù dìde, àjọyọ̀ wo ló sì ṣàpẹẹrẹ àjíǹde rẹ̀ yìí nínú Òfin Mósè? (b) Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe jẹ́ kí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 nímùúṣẹ?
5 Lọ́jọ́ kẹta, Jésù jí dìde kó bàa lè gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ lọ fún Bàbá rẹ̀. (Hébérù 9:24) Àjọyọ̀ mìíràn tún ṣàpẹẹrẹ àjíǹde rẹ̀ yìí. Ọjọ́ kejì Nísàn 14 ni Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú máa ń bẹ̀rẹ̀. Lọ́jọ́ kẹta, ìyẹn Nísàn 16, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń mú ìtí ọkà báálì tó jẹ́ àkọ́so wá fún àlùfáà, ìyẹn ìkórè tó kọ́kọ́ máa ń wáyé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, kí àlùfáà lè fì í níwájú Jèhófà. (Léfítíkù 23:6-14) Ẹ ò rí i pé ó bá a mú gẹ́ẹ́ pé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ní àyájọ́ Nísàn 16 yìí gan-an ni Jèhófà sọ gbogbo ìsapá Sátánì di asán, ìyẹn ìsapá rẹ̀ láti pa ẹni tó jẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́” fún Ọlọ́run rẹ́ ráúráú! Ní Nísàn 16, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà jí Jésù dìde nínú ikú, ó sì di ẹni ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́.—Ìṣípayá 3:14; 1 Pétérù 3:18.
6 Jésù di “àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́ríńtì 15:20) Ó yàtọ̀ sáwọn tó ti jíǹde ṣáájú àkókò yẹn nítorí pé òun ò padà kú mọ́ ní tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gòkè re ọ̀run, sí ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà, ó sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí Jèhófà fi sọ ọ́ di Ọba ní ọ̀run. (Sáàmù 110:1; Ìṣe 2:32, 33; Hébérù 10:12, 13) Látìgbà tí Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Ọba ló ti wá lágbára láti pa ọ̀tá ńlá náà, Sátánì, ní orí títí ayérayé, yóò sì tún pa irú-ọmọ rẹ̀ run.—Ìṣípayá 11:15, 18; 20:1-3, 10.
Àwọn Tó Tún Jẹ́ Ara Irú-Ọmọ Ábúráhámù
7. Kí ni Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀?
7 Jésù ni Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí lọ́gbà Édẹ́nì, òun sì lẹni tí Jèhófà máa lò láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Àmọ́ o, nígbà tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kó mọ̀ pé “irú-ọmọ” rẹ̀ yóò ju ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo lọ. Irú-ọmọ náà á dà “bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Àjọyọ̀ mìíràn tó máa ń mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kún fún ìdùnnú ló ṣàpẹẹrẹ bí àwọn tó tún jẹ́ ara “irú-ọmọ” náà yóò ṣe fara hàn. Ní àádọ́ta ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ láti Nísàn 16, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀. Òfin tó dá lórí èyí sọ pé: “Títí dé ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé sábáàtì keje ni kí ẹ kà á, àádọ́ta ọjọ́, kí ẹ sì mú ọrẹ ẹbọ ọkà tuntun wá fún Jèhófà. Láti ibi gbígbé yín ni kí ẹ ti mú ìṣù búrẹ́dì méjì wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì. Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí wọ́n jẹ́. Kí a fi ìwúkàrà yan wọ́n, gẹ́gẹ́ bí àkọ́pọ́n èso fún Jèhófà.”b—Léfítíkù 23:16, 17, 20.
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ló wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
8 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, Pẹ́ńtíkọ́sì (tó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “àádọ́ta”) ni wọ́n mọ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ sí. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Olórí Àlùfáà tó ga jù lọ, ìyẹn Jésù Kristi tí Ọlọ́run jí dìde, tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pé jọ ní Jerúsálẹ́mù. Nípa báyìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà di ọmọ Ọlọ́run tá a fòróró yàn àti arákùnrin Jésù Kristi. (Róòmù 8:15-17) Wọ́n di orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Láti ìwọ̀nba díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè náà yóò di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó bá yá.—Ìṣípayá 7:1-4.
9, 10. Kí ló ń ṣàpẹẹrẹ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lákòókò àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì?
9 Ìṣù búrẹ́dì méjì tó ní ìwúkàrà nínú tí àlùfáà máa ń fì níwájú Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣàpẹẹrẹ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Bí ìṣù búrẹ́dì náà ṣe ní ìwúkàrà nínú fi hàn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró á ṣì ní ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá tó dúró fún ìwúkàrà. Síbẹ̀, wọ́n lè gbàdúrà sí Jèhófà nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú láti ṣe ìràpadà. (Róòmù 5:1, 2) Kí nìdí tí ìṣù búrẹ́dì náà fi jẹ́ méjì? Ó ṣeé ṣe kí èyí máa tọ́ka sí jíjẹ́ tó jẹ́ pé àtinú àwùjọ méjì làwọn ọmọ Ọlọ́run tá a fẹ̀mí yàn yóò ti wá, ìyẹn látinú àwọn Júù àbínibí lákọ̀ọ́kọ́, àti lẹ́yìn náà, látinú àwọn kèfèrí.—Gálátíà 3:26-29; Éfésù 2:13-18.
10 Àkọ́so ìkórè àlìkámà ni wọ́n fi máa ń ṣe ìṣù búrẹ́dì méjì tí wọ́n fi ń rúbọ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Ó sì bá a mú pé Bíbélì pe àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí bí yẹn ní “àkọ́so kan nínú àwọn ẹ̀dá rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:18) Àwọn lẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù táwọn èèyàn ta sílẹ̀, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dẹni tí Ọlọ́run fún ní ìyè àìleèkú ní ọ̀run, níbi tí wọ́n á ti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:53; Fílípì 3:20, 21; Ìṣípayá 20:6) Nítorí ipò wọn yìí, lọ́jọ́ kan láìpẹ́, wọn yóò “fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn [orílẹ̀-èdè]” wọ́n á sì rí i tí ‘Sátánì dẹni tá a tẹ̀ rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.’ (Ìṣípayá 2:26, 27; Róòmù 16:20) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”—Ìṣípayá 14:4.
Ọjọ́ Kan Tó Jẹ́ Ká Mọ Ìjẹ́pàtàkì Ìdáǹdè
11, 12. (a) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù? (b) Àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rí látinú akọ màlúù àti ewúrẹ́ tí wọ́n fi ń rúbọ?
11 Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù Étánímù (tó wá di Tíṣírì nígbà tó yá),c àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣàjọyọ̀ kan tó ṣàpẹẹrẹ ọ̀nà tá a máa gbà lo àwọn àǹfààní tó wá látinú ẹbọ ìràpadà Jésù. Ní ọjọ́ yẹn, gbogbo orílẹ̀-èdè náà máa ń pàdé pọ̀ fún Ọjọ́ Ètùtù kí àlùfáà lè bá wọn ṣe àwọn ìrúbọ tó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.—Léfítíkù 16:29, 30.
12 Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà máa ń pa akọ ọmọ màlúù kan, yóò gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ, yóò sì ta díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ náà sílẹ̀ níwájú ìbòrí Àpótí nígbà méje. Ó ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣojú fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ẹ̀jẹ̀ náà rúbọ níwájú Jèhófà. Ẹbọ yìí wà fún ẹ̀ṣẹ̀ àlùfáà àgbà àti tàwọn ará “ilé rẹ̀,” àti tàwọn tó ń ṣe àlùfáà lábẹ́ rẹ̀ àti tàwọn ọmọ Léfì. Lẹ́yìn èyí, àlùfáà àgbà yóò wá mú ewúrẹ́ méjì. Yóò pa ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ “tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn.” Ó tún máa ń ta díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ yìí sílẹ̀ níwájú ìbòrí Àpótí tó wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Lẹ́yìn náà, àlùfáà àgbà yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ sórí ewúrẹ́ kejì á sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn èyí, yóò sọ pé kí wọ́n mú ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù láti lè kó ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀-èdè náà lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Léfítíkù 16:3-16, 21, 22.
13. Báwo làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù ṣe ṣàpẹẹrẹ ipa tí Jésù kó?
13 Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún, Olórí Àlùfáà tó ga jù lọ, ìyẹn Jésù, ń lo àǹfààní ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ láti pèsè ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn tí àǹfààní ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà fún ni “ilé ti ẹ̀mí,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, èyí tó jẹ́ kí wọ́n lè dẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo tí wọ́n sì wà nípò mímọ́ lójú Jèhófà. (1 Pétérù 2:5; 1 Kọ́ríńtì 6:11) Ẹbọ tí àlùfáà fi màlúù rú yẹn ló ṣàpẹẹrẹ èyí. Ọ̀nà wá tipa báyìí ṣí sílẹ̀ fún wọn láti gba ogún wọn ti ọ̀run. Èkejì, gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ tí àlùfáà fi rúbọ ti fi hàn, ẹ̀jẹ̀ Jésù tún ṣàǹfààní fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Kristi. Àwọn wọ̀nyí yóò gba iyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé níbí, ìyẹn ogún tí Ádámù àti Éfà gbé sọ nù. (Sáàmù 37:10, 11) Lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ táwọn èèyàn ta sílẹ̀, Jésù kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ gẹ́gẹ́ bí ààyè ewúrẹ́ yẹn ṣe kó ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sínú aginjù lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Aísáyà 53:4, 5.
Wọ́n Ń Yọ̀ Níwájú Jèhófà
14, 15. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ lákòókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà, kí lèyí sì ń jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rántí?
14 Lẹ́yìn Ọjọ́ Ètùtù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà, èyí sì jẹ́ àjọyọ̀ tó máa ń múnú wọn dùn jù lọ láàárín ọdún. (Léfítíkù 23:34-43) Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún sí ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Étánímù ni àjọyọ̀ yìí máa ń wáyé, àpéjọ mímọ́ ni wọ́n sì máa ń fi kádìí rẹ̀ lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù náà. Òun ló ń fi hàn pé ìkórèwọlé ti wá sópin, ó sì jẹ́ àkókò ìdúpẹ́ fún ọ̀pọ̀ oore tí Ọlọ́run ṣe fún wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fáwọn tó ń ṣe àjọyọ̀ yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ nínú gbogbo èso rẹ àti nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí ìwọ sì kún fún ìdùnnú.” (Diutarónómì 16:15) Ó dájú pé àkókò ìdùnnú gbáà ni àkókò yẹn ní láti jẹ́!
15 Nígbà tí àjọyọ̀ náà bá ń lọ lọ́wọ́, inú àtíbàbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbé fún ọjọ́ méje. Èyí ń rán wọn létí pé ìgbà kan wà tí wọ́n gbé inú àgọ́ láginjù. Àjọyọ̀ náà máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ bójú tó wọn gẹ́gẹ́ bí bàbá onífẹ̀ẹ́. (Diutarónómì 8:15, 16) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àtolówó àti akúùṣẹ́ wọn ló jọ máa ń gbénú àwọn àtíbàbà tó rí bákan náà, èyí rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé, lákòókò àjọyọ̀ yìí, ẹnì kan kò ga ju ẹnì kan lọ.—Nehemáyà 8:14-16.
16. Kí ni Àjọyọ̀ Àtíbàbà dúró fún?
16 Àjọyọ̀ Àtíbàbà jẹ́ àjọyọ̀ ìkórè. Ó jẹ́ ayẹyẹ ìkórèwọlé tó máa ń múnú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn gan-an, ó sì dúró fún kíkórè àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi wọlé, èyí tó jẹ́ ohun ìdùnnú gan-an. Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìkórèwọlé yìí bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Ọlọ́run fàmì òróró yan ọgọ́fà àwọn ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè di ara àwọn tó máa ṣe “iṣẹ́ àlùfáà mímọ́.” Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbé inú àtíbàbà fún ọjọ́ díẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró mọ̀ pé “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” làwọ́n jẹ́ nínú ayé tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí. Ọ̀run ni Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn. (1 Pétérù 2:5, 11) Kíkórè àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí wọlé máa wá sópin ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, nígbà tí Ọlọ́run bá kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jọ.—2 Tímótì 3:1.
17, 18. (a) Kí ló fi hàn pé yàtọ̀ sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn mìíràn tún jàǹfààní látinú ẹbọ Jésù? (b) Lónìí, àwọn wo ló ń jàǹfààní látinú ìṣẹ̀lẹ̀ tí Àjọyọ̀ Àtíbàbà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ìgbà wo sì ni àjọyọ̀ tó kún fún ìdùnnú yìí yóò dé òpin rẹ̀ pátápátá?
17 Ó yẹ ká mọ̀ pé lákòókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí wọ́n ń ṣe láyé ọjọ́un yẹn, wọ́n máa ń fi àádọ́rin màlúù rúbọ. (Númérì 29:12-34) Àádọ́rin dúró fún méje lọ́nà mẹ́wàá. Nínú Bíbélì, méje dúró fún ìjẹ́pípé ti ọ̀run, mẹ́wàá sì dúró fún ìjẹ́pípé ti orí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú yóò ṣàǹfààní fáwọn tó jẹ́ olóòótọ́ látinú gbogbo àádọ́rin ìdílé aráyé tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 10:1-29) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí sì bá èyí mu rẹ́gí. Ìdí ni pé kíkórè àwọn èèyàn wọlé ti nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ onírúurú èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn tó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jésù tí wọ́n sì nírètí láti gbé nínú ayé tó máa di Párádísè.
18 Àpọ́sítélì Jòhánù rí kíkórè àwọn èèyàn wọlé tó ń wáyé lọ́jọ́ òní yìí nínú ìran. Lákọ̀ọ́kọ́, ó gbọ́ ìkéde kan pé a fi èdìdì di àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Lẹ́yìn èyí ló wá rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà,” tí wọ́n dúró níwájú Jèhófà àti Jésù, “imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.” Àwọn wọ̀nyí jẹ́ “àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà” bọ́ sínú ayé tuntun. Lákòókò yìí, olùgbé fúngbà díẹ̀ làwọn náà jẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan tó máa tó wá sópin yìí, ọkàn wọn sì balẹ̀ bí wọ́n ti ń retí àkókò tí ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, tí yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.’ Lákòókò yẹn, “Ọlọ́run yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:1-10, 14-17) Ìgbà tí Ọlọ́run bá fún àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá àtàwọn òkú tó jẹ́ olóòótọ́ tó máa jí dìde ní ìyè àìnípẹ̀kun, lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí Àjọyọ̀ Àtíbàbà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ yìí á dé òpin rẹ̀ pátápátá.—Ìṣípayá 20:5.
19. Báwo la ṣe jàǹfààní látinú ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì?
19 Ó yẹ káwa náà “kún fún ìdùnnú” bá a ti ń ṣàṣàrò lórí ohun táwọn àjọyọ̀ wọ̀nyí táwọn Júù máa ń ṣe láyé ọjọ́un túmọ̀ sí. Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà jẹ́ ká mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nígbà yẹn lọ́hùn-ún lọ́gbà Édẹ́nì ṣe máa nímùúṣẹ. Inú wa sì tún ń dùn bá a ṣe ń rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ náà ń nímùúṣẹ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé. Lónìí, a mọ̀ pé Irú-Ọmọ náà ti fara hàn àti pé ejò náà ti pa á ní gìgísẹ̀. Ní báyìí, ó ti di Ọba ní ọ̀run. Bákan náà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú. Kí ló wá kù ní ṣíṣe? Báwo ni mímú ìlérí yìí ṣẹ tán pátápátá ṣe máa yá tó? Èyí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Oṣù Nísàn máa ń bọ́ sínú oṣù March sí April lórí kàlẹ́ńdà tá à ń lò lóde òní.
b Nígbà ẹbọ fífì tí wọ́n máa ń lo ìṣù búrẹ́dì méjì fún yìí, àlùfáà sábà máa ń kó àwọn búrẹ́dì náà sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, á gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, á sì máa fi àwọn búrẹ́dì náà sọ́tùn-ún àti sósì. Bó ṣe ń fi àwọn búrẹ́dì wọ̀nyí ń ṣàpẹẹrẹ fífún tí wọ́n fún Jèhófà láwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ náà.—Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 528. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
c Oṣù Étánímù máa ń bọ́ sínú oṣù September sí October lórí kàlẹ́ńdà tá à ń lò lóde òní.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
• Kíkórè àwọn wo wọlé ni Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
• Ní Ọjọ́ Ètùtù, àwọn ohun wo ló máa ń ṣẹlẹ̀ tó tọ́ka sí ọ̀nà tí ẹbọ ìràpadà Jésù gbà ṣàǹfààní?
• Ọ̀nà wo ni Àjọyọ̀ Àtíbàbà gbà ṣàpẹẹrẹ kíkórè àwọn Kristẹni wọlé?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìṣẹ̀lẹ̀: Ohun Tó Dúró Fún:
Ìrékọjá Nísàn 14 Àlùfáà pa ọ̀dọ́ Jésù fi ara rẹ̀ rúbọ
àgùntàn
Àjọyọ̀ Àwọn Nísàn15 Sábáàtì
Àkàrà Aláìwú
(Nísàn15 sí 21) Nísàn16 Àlùfáà fi ọkà Jésù jíǹde
báálì rúbọ
↑
Àádọ́ta ọjọ́
↓
Àjọyọ̀ Àwọn Àlùfáà fi ìṣù Jésù fi àwọn
Ọ̀sẹ̀ Sífánì 6 búrẹ́dì méjì arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì
(Pẹ́ńtíkọ́sì) rúbọ òróró fún Jèhófà
Ọjọ́ Ètùtù Tíṣírì 10 Àlùfáà fi akọ Jésù gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀
màlúù kan àti rẹ̀ lọ síwájú Jèhófà
ewúrẹ́ méjì nítorí gbogbo aráyé
rúbọ̀
Àjọyọ̀ Àtíbàbà Tíṣírì 15 Àwọn ọmọ Kíkó àwọn ẹni àmì
(Ìkórèwọlé, sí 21 Ísírẹ́lì gbé òróró àtàwọn
Àgọ́ Ìjọsìn) lábẹ́ àtíbàbà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ
ayọ̀tayọ̀, ìkórè
mú inú wọn
dùn, àlùfáà fi
àádọ́rin akọ
màlúù rúbọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Bíi ti ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá, ẹ̀jẹ̀ Jésù táwọn èèyàn ta sílẹ̀ jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rí ìgbàlà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àkọ́so ìkórè ọkà báálì tí wọ́n fi ń rúbọ ní Nísàn 16 ṣàpẹẹrẹ àjíńde Jésù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìṣù búrẹ́dì méjì tí àlùfáà fi ń ṣèrúbọ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì dúró fún ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àjọyọ̀ Àtíbàbà ṣàpẹẹrẹ kíkó àwọn ẹni àmì òróró àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” látinú gbogbo orílẹ̀-èdè jọ, èyí tó ń múni kún fún ìdùnnú