Iṣẹ́ Àbójútó Tí Ọlọ́run Ń ṣe Láti Mú Ìpinnu Rẹ̀ Ṣẹ
“[Ọlọ́run] ń mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ pinnu.”—ÉFÉSÙ 1:11.
1. Kí nìdí tí gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa pé jọ ní April 12, 2006?
NÍ ALẸ́ ọjọ́ Wednesday, April 12, 2006, àwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún yóò pé jọ láti ṣèrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Tábìlì kan máa wà ní gbogbo ibi tí wọ́n bá ti pé jọ, èyí tí wọ́n máa gbé búrẹ́dì aláìwú, tó dúró fún ara Kristi sí, àti wáìnì pupa tó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Kristi tí wọ́n ta sílẹ̀. Tí àsọyé tí wọ́n máa sọ láti fi ṣàlàyé ìtumọ̀ Ìrántí Ikú Jésù bá ti ń parí lọ, wọ́n á gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà wá sọ́dọ̀ gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀. Búrẹ́dì ni wọn máa kọ́kọ́ gbé kiri, lẹ́yìn náà ni yóò wá kan wáìnì. Díẹ̀ lára àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ṣe ìrántí yìí la ó ti rí ẹnì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó máa jẹ táa sì mu nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. Àmọ́ nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ, ẹnikẹ́ni kò ní fẹnu kàn án. Kí ló dé tó jẹ́ pé kìkì ìwọ̀nba àwọn Kristẹni díẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń retí àtilọ gbé ní ọ̀run, ni wọ́n ń jẹ tí wọ́n sì ń mu nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà nígbà táwọn tó pọ̀ jù lọ, tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé kì í fẹnu kàn án?
2, 3. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́nà tó bá ohun tó pinnu láti ṣe mu? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi dá ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn?
2 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní àwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe. Ó “ń mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ pinnu” kí àwọn ohun tó pinnu láti ṣe lè rí bó ṣe fẹ́. (Éfésù 1:11) Jèhófà kọ́kọ́ dá Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. (Jòhánù 1:1, 14; Ìṣípayá 3:14) Ó wá tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ yìí dá àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ lọ́run, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá dá oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀ àti ilẹ̀ ayé, ó sì dá èèyàn sínú ayé.—Jóòbù 38:4, 7; Sáàmù 103:19-21; Jòhánù 1:2, 3; Kólósè 1:15, 16.
3 Jèhófà kò dá ayé yìí gẹ́gẹ́ bí ibi tí yóò ti máa dán àwọn èèyàn wò láti mọ̀ bóyá wọ́n á yẹ lẹ́ni tó lè wá bá àwọn áńgẹ́lì gbé lọ́run, bí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe fi ń kọ́ni. Ó ní ìdí kan pàtó tí Ọlọ́run fi dá ayé, ńṣe ló fẹ́ ‘kí á máa gbé inú rẹ̀.’ (Aísáyà 45:18) Ọlọ́run dá ayé fún ènìyàn ó sì dá ènìyàn láti máa gbé ayé. (Sáàmù 115:16) Ó fẹ́ kí gbogbo ayé di Párádísè, kí àwọn olódodo tí yóò máa ro ó, tí yóò sì máa bójú tó o kúnnú rẹ̀. Kò fìgbà kan sọ pé Ádámù àti Éfà tó kọ́kọ́ dá sáyé yóò wá máa gbé lọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:7, 8, 15.
Èṣù Ta Ko Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe
4. Kí ní Èṣù sọ níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀dá èèyàn lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?
4 Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ṣi òmìnira tí Ọlọ́run fún un lò ní ti pé ó di ọlọ̀tẹ̀, ó sì pète láti ba ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe jẹ́. Ó ṣèdíwọ́ fún àlàáfíà gbogbo àwọn tó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹrí ba fún Jèhófà ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Sátánì ti tọkọtaya àkọ́kọ́ débi pé wọ́n wọ́nà láti dòmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Kò sọ pé Jèhófà ò lágbára o. Ohun tó ń sọ ni pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kò tọ̀nà, ó sì tún ń ṣàròyé pé kò tiẹ̀ tọ́ kí Jèhófà máa ṣàkóso ẹ̀dá rárá. Bí àríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ ipò ọba aláṣẹ ṣe wáyé lórí ilẹ̀ ayé níbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nìyẹn.
5. Ọ̀ràn mìíràn wo ni Sátánì dá sílẹ̀, àwọn wo ni ọ̀ràn náà sì wá kàn?
5 Ọ̀ràn kan tún wáyé tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ Jèhófà láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ìgbà ayé Jóòbù ni Sátánì dá a sílẹ̀. Sátánì sọ pé ìtẹríba àti ìjọsìn táwọn ẹ̀dá olóye ń fún Jèhófà kì í ṣe látọkànwá. Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń sún wọn ṣe é, àti pé tí ìdánwò bá bá wọn, kíá ni wọ́n á kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. (Jóòbù 1:7-11; 2:4, 5) Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀dá èèyàn kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni Sátánì ń sọ nígbà náà, àmọ́ ohun tó sọ yìí kan àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, títí kan Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà.
6. Kí ni Jèhófà ṣe láti fi hàn pé ìpinnu òun yóò ṣẹ dandan, òun ò sì ní ṣe ohun tó lòdì sí orúkọ òun?
6 Láti fi hàn pé nǹkan tóun bá pinnu láti ṣe yóò ṣẹ dandan, àti pé òun ò ní ṣe ohun tó lòdì sí orúkọ òun, Jèhófà sọ ara rẹ̀ di Wòlíì àti Olùgbàlà.a Ó sọ fún Sátánì pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Èyí fi hàn pé Jèhófà yóò lo Irú-Ọmọ “obìnrin” rẹ̀, ìyẹn apá tó wà lọ́run lára ètò rẹ̀, láti fi yanjú ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ kí àtọmọdọ́mọ Ádámù lè rí ìgbàlà kí wọ́n sì ní ìyè.—Róòmù 5:21; Gálátíà 4:26, 31.
“Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Ìfẹ́ Rẹ̀”
7. Kí ni Jèhófà gbẹnu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun pinnu láti ṣe?
7 Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà kan sáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù. Inú ẹ̀ ló ti ṣe àlàyé pàtàkì kan nípa bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan láti mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí ó pète nínú ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:9, 10) Ohun àgbàyanu tí Jèhófà pinnu láti ṣe ni pé yóò mú kí gbogbo ẹ̀dá ayé òun ọ̀run wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì fi tìfẹ́tìfẹ́ fi ara wọn sábẹ́ òun ọba aláṣẹ wọn. (Ìṣípayá 4:11) Orúkọ rẹ̀ yóò wá di èyí tá a sọ di mímọ́, yóò sì hàn kedere pé òpùrọ́ ni Sátánì, ìfẹ́ Ọlọ́run yóò sì wá di ṣíṣe ‘lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run.’—Mátíù 6:10.
8. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “iṣẹ́ àbójútó”?
8 “Iṣẹ́ àbójútó” kan ni Jèhófà yóò fi mú “ìdùnnú rere” rẹ̀ tàbí ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Lédè Gíríìkì, ohun tí ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ àbójútó” tí Pọ́ọ̀lù lò yìí túmọ̀ sí ní ìtumọ̀ olówuuru ni “àbójútó agboolé.” Èyí túmọ̀ sí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bójú tó àwọn nǹkan nínú agboolé.b Ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà fẹ́ gbà bójú tó àwọn nǹkan láti mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ jẹ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀” kan tó wá ń ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.—Éfésù 1:10; 3:9, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣí àṣírí ọlọ́wọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?
9 Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, Jèhófà lo onírúurú májẹ̀mú tó bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dá láti fi jẹ́ ká mọ bí ìpinnu rẹ̀ nípa Irú-Ọmọ tó ṣèlérí ní Édẹ́nì yóò ṣe ṣẹ. Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fi hàn pé ìran Ábúráhámù ni Irú-Ọmọ tó ṣèlérí yóò ti jáde wá àti pé ipasẹ̀ Irú-Ọmọ yìí ni “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé” yóò ti bù kún ara wọn. Májẹ̀mú yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn mìíràn ṣì ń bọ̀ wá di ara irú-ọmọ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú olórí irú-ọmọ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá fi hàn pé Jèhófà pinnu láti fi àwọn kan ṣe “ìjọba àwọn àlùfáà.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá fi hàn pé Irú-Ọmọ náà yóò jẹ́ Olórí Ìjọba kan tí yóò wà fún àkókó tó lọ kánrin. (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Sáàmù 89:3, 4) Gbàrà tí májẹ̀mú Òfin sì ti ṣamọ̀nà àwọn Júù dé ọ̀dọ̀ Mèsáyà, Jèhófà tún fi bí apá mìíràn nínú ìpinnu rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ hàn. (Gálátíà 3:19, 24) Ìyẹn ni pé àwọn tó máa di ara irú-ọmọ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú olórí irú-ọmọ náà ni yóò para pọ̀ jẹ́ “ìjọba àwọn àlùfáà” tí Ọlọ́run ṣèlérí. Wọn yóò jẹ́ “Ísírẹ́lì” tuntun, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, tí Ọlọ́run yóò bá “dá májẹ̀mú tuntun.”—Jeremáyà 31:31-34; Hébérù 8:7-9.c
10, 11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi ẹni tó jẹ́ Irú-Ọmọ náà hàn? (b) Kí nìdí tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run fi wá sáyé?
10 Àkókò wá tó wàyí kí Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ wá sí ayé ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ àbójútó tí Ọlọ́run ń ṣe láti mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Jèhófà rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì kó wá sọ fún Màríà pé yóò bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Bá a ṣe mọ Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí nìyẹn o.—Gálátíà 3:16; 4:4.
11 Nígbà tí Jésù, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà bá wá sáyé, yóò rí ìdánwò dé góńgó. Ìgbésí ayé tó bá sì gbé lórí ilẹ̀ ayé ni Jèhófà yóò fi yanjú ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ láìkù síbì kan. Ǹjẹ́ Jésù máa jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ báyìí? Àṣírí ọlọ́wọ̀ nìyẹn náà jẹ́. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ipa tí Jésù kó, ó ní: “Àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí ti fífọkànsin Ọlọ́run ni a gbà pé ó ga lọ́lá: ‘A fi í hàn kedere ní ẹran ara, a polongo rẹ̀ ní olódodo nínú ẹ̀mí, ó fara han àwọn áńgẹ́lì, a wàásù nípa rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, a gbà á gbọ́ nínú ayé, a gbà á sókè nínú ògo.’” (1 Tímótì 3:16) Bí Jésù kò ṣe yẹsẹ̀ rárá nínú ìwà títọ́ rẹ̀ àní títí dójú ikú, ńṣe ló yanjú gbogbo ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ pátápátá porogodo. Ṣùgbọ́n àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ náà ṣì wà tí kò tíì hàn sójú táyé.
“Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Ti Ìjọba Ọlọ́run”
12, 13. (a) Kí ni apá kan nínú “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run”? (b) Kí ni Jèhófà yóò ṣe fún ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ tó yàn pé kí wọ́n lọ sọ́run?
12 Nígbà kan tí Jésù ń wàásù káàkiri Gálílì, ó fi hàn pé àṣírí ọlọ́wọ̀ yẹn jẹ mọ́ Ìjọba Mèsáyà tóun máa ṣàkóso. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba ọ̀run [“ìjọba Ọlọ́run,” Máàkù 4:11].” (Mátíù 13:11) Apá kan nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ yẹn ni yíyàn tí Jèhófà yan “agbo kékeré” tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn kí wọ́n lè di ara irú-ọmọ náà pa pọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, kí wọ́n sì tún bá a ṣàkóso lọ́run.—Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 14:1, 4.
13 Orí ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run dá èèyàn sí kó máa gbé, nítorí náà kí àwọn kan lára wọn tó lè lọ sí ọ̀run, Jèhófà ní láti sọ wọ́n di “ìṣẹ̀dá tuntun.” (2 Kọ́ríńtì 5:17) Àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run yàn tó sì fún nírètí àrà ọ̀tọ̀ pé yóò lọ sí ọ̀run kọ̀wé pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú òkú, sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá. A fi í pa mọ́ ní ọ̀run [dè yín].”—1 Pétérù 1:3, 4.
14. (a) Báwo lọ̀rọ̀ “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run” ṣe kan àwọn tí kì í ṣe Júù? (b) Kí ló jẹ́ ká lè lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” yìí?
14 Apá míì lára àṣírí ọlọ́wọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni pé Ọlọ́run máa yan àwọn tí kì í ṣe Júù kún àwọn èèyàn kéréje tó ní kó wá bá Kristi jọba ní ọ̀run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé apá yìí tó jẹ́ ara “iṣẹ́ àbójútó” tí Jèhófà ń ṣe láti mú ohun tó pinnu ṣẹ, ó ní: “Ní àwọn ìran mìíràn, àṣírí yìí ni a kò sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣí i payá nísinsìnyí fún àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí, èyíinì ni, kí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn ajùmọ̀jogún àti ajùmọ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara àti alábàápín pẹ̀lú wa nínú ìlérí náà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù nípasẹ̀ ìhìn rere.” (Éfésù 3:5, 6) ‘Àwọn àpọ́sítélì mímọ́’ ni Ọlọ́run ṣí apá yìí payá fún nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ rẹ̀. Lónìí bákan náà, bí kò bá jẹ́ ti ẹ̀mí mímọ́ tó ràn wá lọ́wọ́, à bá má lè lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” yìí.—1 Kọ́ríńtì 2:10; 4:1; Kólósè 1:26, 27.
15, 16. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé látinú ayé ni Jèhófà ti mú àwọn tí yóò bá Kristi ṣèjọba?
15 Bíbélì sọ pé “láti ilẹ̀ ayé wá” ni Ọlọ́run ti ra “ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì” tí Jòhánù rí tó dúró pẹ̀lú “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” lórí Òkè Ńlá Síónì ti ọ̀run, àti pé àwọn wọ̀nyí ni “a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ìyẹn Kristi Jésù. (Ìṣípayá 14:1-4) Àkọ́bí Ọlọ́run ní ọ̀run ni Jèhófà yàn ṣe olórí irú-ọmọ tó ṣèlérí ní Édẹ́nì, àmọ́ kí wá nìdí tó fi jẹ́ pé látinú ayé ló ti mú àwọn tó máa bá Kristi ṣèjọba? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ńṣe ni Jèhófà pe àwọn kéréje yìí “ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀,” “ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere ìfẹ́ rẹ̀.”—Róòmù 8:17, 28-30; Éfésù 1:5, 11; 2 Tímótì 1:9.
16 Ìpinnu Jèhófà tàbí ètè rẹ̀ ni pé kí orúkọ ńlá rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́ di èyí tá a yà sí mímọ́, kí gbogbo ẹ̀dá láyé lọ́run sì gbà pé òun ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Jèhófà wá lo ọgbọ́n gíga jù lọ tó fi ń ṣe “iṣẹ́ àbójútó” rẹ̀, ó rán àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ wá sí ilẹ̀ ayé níbi tí wọ́n ti dán an wò àní títí dójú ikú. Jèhófà tún pinnu pé àwọn kan tó jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú sí òun ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run lára àwọn ọmọ ènìyàn yóò bá Ọmọ òun Mèsáyà ṣèjọba.—Éfésù 1:8-12; Ìṣípayá 2:10, 11.
17. Kí nìdí tó fi dùn mọ́ wa pé Kristi àtàwọn tó máa bá a ṣèjọba ti fìgbà kan rí jẹ́ ènìyàn?
17 Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù, ó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, ó tún yàn lára ọmọ aráyé ṣe àjùmọ̀jogún tí yóò bá Ọmọ rẹ̀ ṣèjọba. Àǹfààní wo lèyí máa wá ṣe fáwọn èèyàn yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, bẹ̀rẹ̀ látorí Ébẹ́lì? Inú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú la bí gbogbo ẹ̀dá èèyàn aláìpé sí, nítorí náà wọ́n ń fẹ́ ìmúláradá àtohun tó máa jẹ́ kí wọ́n padà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n sì dẹni pípé bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí nípilẹ̀ṣẹ̀ ayé. (Róòmù 5:12) Ìtùnú gbáà ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé láti mọ̀ pé Ọba àwọn yóò fi ìfẹ́ àti òye bá àwọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gẹ́lẹ́ bó ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé! (Mátíù 11:28, 29; Hébérù 2:17, 18; 4:15; 7:25, 26) Ọkàn wọn sì balẹ̀ gan-an bí wọ́n ṣe mọ̀ pé àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin tí ìgbàgbọ́ wọ́n lágbára, tí àìpé ara àti ìṣòro ti fìgbà kan rí bá àwọn náà fínra bíi tiwa, làwọn ọba àti àlùfáà tí yóò bá Kristi ṣèjọba lọ́run!—Róòmù 7:21-25.
Ìpinnu Jèhófà Tí Kò Lè Kùnà
18, 19. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Éfésù 1:8-11 túbọ̀ yé wa sí i, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
18 Òye ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú Éfésù 1:8-11 túbọ̀ wá yé wa sí i wàyí. Ó sọ pé Jèhófà ti “sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀” fún wọn, pé Ọlọ́run ‘yàn wọ́n ṣe ajogún’ pẹ̀lú Kristi, àti pé a “yàn [wọ́n] ṣáájú gẹ́gẹ́ bí ète ẹni tí ń mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ pinnu.” A róye rẹ̀ pé èyí wà níbàámu pẹ̀lú “iṣẹ́ àbójútó” àgbàyanu tí Jèhófà ń ṣe láti mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Ó sì tún jẹ́ ká rí ìdí tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba kéréje lára àwọn Kristẹni tó ń wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ló ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì náà.
19 Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí bí Ìrántí Ikú Kristi ṣe kan àwọn Kristẹni tó ń retí àtilọ sọ́run. A ó sì tún mọ ìdí tó fi yẹ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé títí láé nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Ìrántí Ikú Kristi dúró fún.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí ní tààràtà ni “Alèwílèṣe.” Jèhófà lè di ohunkóhun tó bá yẹ láti ri í dájú pé ohun tóun fẹ́ ṣe kò yẹ̀.—Ẹ́kísódù 3:14, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
b Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Jèhófà ti ń bá “iṣẹ́ àbójútó” yìí lọ nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àmọ́ ní ti Ìjọba Mèsáyà, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ọdún 1914 ló tó bẹ̀rẹ̀.
c Tó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa àwọn májẹ̀mú tó jẹ mọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ, wo Ilé-Ìṣọ́nà February 1, 1989, ojú ìwé 10 sí 15.
Àtúnyẹ̀wò
• Kí nìdí tí Jèhófà fi dá ayé tó sì dá èèyàn sínú rẹ̀?
• Kí nìdí tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà fi ní láti fojú winá ìdánwò lórí ilẹ̀ ayé?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ara ọmọ aráyé ni Jèhófà ti yan àwọn tí yóò bá Kristi ṣèjọba?